Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Níwọ̀n bí Jèhófà ti dẹ́bi fún ìbọ̀rìṣà, kí nìdí tí kò fi fìyà jẹ Áárónì nítorí pé ó ṣe ère ọmọ màlúù?

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Ẹ́kísódù orí 32, nígbà tí Áárónì ṣe ère ọmọ màlúù, ńṣe ló rú òfin Ọlọ́run tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbọ̀rìṣà. (Ẹ́kís. 20:3-5) Nítorí èyí, “ìbínú Jèhófà ru sókè . . . gidigidi [sí Áárónì] títí dé orí pípa á rẹ́ ráúráú; ṣùgbọ́n [Mósè] tún rawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní tìtorí Áárónì ní àkókò yẹn gan-an.” (Diu. 9:19, 20) Ǹjẹ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ Mósè tó jẹ́ olódodo “ní ipá púpọ̀” lórí ọ̀ràn ti Áárónì? (Ják. 5:16) Bẹ́ẹ̀ ni. Nítorí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ yẹn àti nítorí ìdí méjì mìíràn, ó dà bíi pé Jèhófà dáhùn àdúrà Mósè kò sì fìyà jẹ Áárónì.

Ọ̀kan lára àwọn ìdí náà ni pé Áárónì jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run. Nígbà tí Ọlọ́run pàṣẹ fún Mósè pé kó tọ Fáráò lọ kó sì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, Jèhófà yan Áárónì pé kó bá Mósè lọ kó sì ṣe agbẹnusọ fún un. (Ẹ́kís. 4:10-16) Àwọn ọkùnrin méjì yìí ṣègbọràn, wọ́n sì tọ ọba Íjíbítì lọ lọ́pọ̀ ìgbà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní láti fara da bí Fáráò ṣe ń warùnkì. Torí náà, kí wọ́n tó kúrò ní Íjíbítì, Áárónì ti fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ àti adúróṣinṣin nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.—Ẹ́kís. 4:21.

Tún ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó mú kí Áárónì ṣe ère ọmọ màlúù fún wọn. Mósè ti wà lórí Òkè Sínáì fún ogójì [40] ọjọ́. Nígbà tí “àwọn ènìyàn náà rí i pé ó pẹ́ Mósè kí ó tó sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè ńlá náà,” wọ́n sọ fún Áárónì pé kó ṣe ère kan fún àwọn. Áárónì gbọ́ sí wọn lẹ́nu ó sì fi wúrà ṣe ère ọmọ màlúù kan. (Ẹ́kís. 32:1-6) Àmọ́, ìgbésẹ̀ tí Áárónì gbé lẹ́yìn náà fi hàn pé kò fara mọ́ ìbọ̀rìṣà tó wáyé náà. Ó dájú pé àwọn èèyàn náà ló sún un láti lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Mósè ṣe tán láti fòpin sí ìbọ̀rìṣà náà, gbogbo àwọn ọmọ Léfì, tó fi mọ́ Áárónì alára, ni wọ́n dúró gbọn-in sí ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà. Ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] èèyàn tó ṣe agbátẹrù ìbọ̀rìṣà náà ni wọ́n sì pa.—Ẹ́kís. 32:25-29.

Lẹ́yìn èyí ni Mósè sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.” (Ẹ́kís. 32:30) Èyí fi hàn pé kì í ṣe Áárónì nìkan ló jẹ̀bi ìwà àìtọ́ náà. Òun àtàwọn èèyàn náà ló sì jàǹfààní àánú Jèhófà.

Lẹ́yìn tí ọ̀ràn ère ọmọ màlúù wúrà náà ti kọjá lọ, Jèhófà pàṣẹ fún Mósè pé kó yan Áárónì gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà. Ọlọ́run sọ fún un pé: “Kí o sì fi ẹ̀wù mímọ́ wọ Áárónì, kí o sì fòróró yàn án, kí o sì sọ ọ́ di mímọ́, nípa bẹ́ẹ̀, kí ó sì máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi.” (Ẹ́kís. 40:12, 13) Ó dájú pé Jèhófà dárí ji Áárónì nítorí ohun tí àìpé mú kó hù níwà. Nínú ọkàn-àyà Áárónì lọ́hùn-ún, adúróṣinṣin ló jẹ́ bó bá di ọ̀ràn ìjọsìn Jèhófà, kì í ṣe ọlọ̀tẹ̀ àti abọ̀rìṣà.