Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Pa Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Lára Bó O Bá Ń Tọ́jú Ìbátan Rẹ Tó Ń Ṣàìsàn
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Pa Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Lára Bó O Bá Ń Tọ́jú Ìbátan Rẹ Tó Ń Ṣàìsàn
LẸ́YÌN tí àyẹ̀wò fi hàn pé ibì kan wú nínú egungun ògóóró ẹ̀yìn arábìnrin kan tó ń jẹ́ Kim, wọ́n sọ pé àrùn jẹjẹrẹ ló ń ṣe é. a Steve tó jẹ́ ọkọ arábìnrin yìí sọ pé: “Lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fi mú ibi tó wú lára Kim ìyàwó mi kúrò, wọ́n tún fi ẹ̀rọ̀ ya fọ́tò inú ara rẹ̀ lọ́hùn ún, wọ́n sì tún fún un ní ìtọ́jú oníkẹ́míkà. Kò fi bẹ́ẹ̀ lókun nínú mọ́ nítorí ìtọ́jú tí wọ́n fún un yìí. Kò sì rọrùn fún un láti máa lọ káàkiri.”
Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí nǹkan á ṣe rí lára Steve bó ṣe ń wo olólùfẹ́ rẹ̀ tó ń jẹ̀rora látàrí àìsàn tó ń tánni lókun yìí? Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ní mọ̀lẹ́bí kan tó ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn tó máa ń sọ ara di hẹ́gẹhẹ̀gẹ tàbí tí ọjọ́ ogbó ń yọ lẹ́nu. (Oníw. 12:1-7) Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá ti mọ̀ pé kó o lè bójú tó ẹni ọ̀wọ́n yìí dáadáa, ìwọ náà gbọ́dọ̀ tọ́jú ara rẹ. Tí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run kò bá dán mọ́rán, ìrònú lè sorí rẹ kodò, kí okun rẹ sì tán, èyí ò sì ní jẹ́ kó o lè pèsè ìrànwọ́ tí mọ̀lẹ́bí rẹ yìí nílò. Kí lo wá lè ṣe tí ohunkóhun ò fi ní pa àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run lára bó o bá ń tọ́jú ìbátan rẹ kan tó ń ṣàìsàn tàbí tó jẹ́ àgbàlagbà? Ṣé àwọn nǹkan kan wà táwọn ará lè ṣe láti fi ìgbatẹnirò hàn fún irú àwọn tó bá ń ṣàìsàn?
Báwo Ni Ojúṣe Kan Kò Ṣe Ní Pa Òmíràn Lára?
Bí o kò bá fẹ́ kí ohunkóhun pa àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run lára, tí ìwọ náà ò sì fẹ́ wó kalẹ̀ torí pé ò ń tọ́jú ìbátan rẹ tó ń ṣàìsàn, o ní láti mọ bó o ṣe lè mú ara rẹ bá ipò tó o wà mu, kó o sì ṣètò àkókò rẹ àti bí wàá ṣe máa lo okun rẹ. Ìwé Òwe 11:2 sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” Gbólóhùn náà ‘ìmẹ̀tọ́mọ̀wà’ túmọ̀ sí pé kó o mọ ibi tí agbára rẹ̀ mọ. Kó má bàa di pé wàá máa ṣe kọjá agbára rẹ, ó yẹ kó o ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tó wà nílẹ̀ fún ẹ láti ṣe àti àwọn ojúṣe míì tó o ní.
Steve lo ọgbọ́n àti ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ní ti pé ó ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó wà nílẹ̀ fún un láti ṣe. Láfikún sí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ̀, òun tún ni olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn nínú ọ̀kan lára ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Ireland. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn lágbègbè rẹ̀. Steve sọ pé: “Kim kò ṣàròyé pé mò ń pa òun tì torí pé mò ń fún àwọn ojúṣe yìí láfiyèsí tó pọ̀. Àmọ́ mo mọ̀ pé mò ń lo ara mi ju bó ṣe yẹ lọ.” Kí wá ni Steve ṣe sí ọ̀ràn yìí? Ó ní: “Lẹ́yìn tí mo ti gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà, mo pinnu pé màá fi iṣẹ́ olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà sílẹ̀ ná. Alàgbà ṣì ni mí, àmọ́ bí mo ṣe fa díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ tí mò ń bójú tó nínú ìjọ lé àwọn míì lọ́wọ́ mú kí n ní àyè láti fún Kim ní àfiyèsí tó nílò.”
Nígbà tó yá, ara Kim balẹ̀. Steve àti Kim ìyàwó rẹ̀ tún ipò wọn gbé yẹ̀ wò, ó sì ṣeé ṣe fún Steve láti pa dà gba àwọn ojúṣe rẹ̀ nínú ìjọ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ aya rẹ̀. Steve ṣàlàyé pé: “Àwa méjèèjì ti kọ́ láti máa ṣe nǹkan tí agbára wa gbé, níwọ̀n ibi tí àìsàn náà gbà wá láyè dé. Mo kún fún ìmoore sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, mo sì tún mọrírì ìtìlẹ́yìn ìyàwó mi àti bí kì í ṣe ṣàròyé láìka ti àìlera rẹ̀ sí.”
Jẹ́ ká tún gbé ìrírí Jerry tó jẹ́ alábòójútó àyíká àti Maria, ìyàwó rẹ̀ yẹ̀ wò. Wọ́n ní láti yí àfojúsùn wọn pa dà, kí wọ́n lè bójú tó àwọn obí wọn àgbà. Maria sọ pé: “Àfojúsùn èmi àti ọkọ mi ni pé ká di míṣọ́nnárì nílẹ̀ òkèèrè. Àmọ́ Jerry nìkan làwọn òbí rẹ̀ bí, wọ́n sì nílò abójútó. Torí náà, a pinnu láti dúró sí orílẹ̀-èdè Ireland ká lè máa tọ́jú wọn. Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe fún wa láti lè máa lọ wo bàbá Jerry nígbà tó wà nílé ìwòsàn kó tó ṣaláìsí. Ní báyìí, a ò jìnnà sí màmá Jerry, a sì máa ń tètè yọ sí i tó bá nílò ìrànlọ́wọ́. Àwọn ará ìjọ tí màmá Jerry ń dara pọ̀ mọ́ ń ṣèrànwọ́, wọ́n sì ń tì wá lẹ́yìn, ìyẹn ló jẹ́ ká ṣì lè wà lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjo.”
Bí Àwọn Míì Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tara tó yẹ kí ìjọ pèsè fún àwọn opó tó jẹ́ àgbàlagbà nínú ìjọ, ó kọ̀wé pé: “Bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni létí pé bí wọ́n bá fẹ́ kí àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe “ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run,” wọ́n gbọ́dọ̀ máa wá owó fi ṣètọ́jú àwọn òbí wọn àtàwọn òbí wọn àgbà. (1 Tím. 5:4, 8) Àmọ́ ṣá o, àwọn míì nínú ìjọ náà lè ṣèrànwọ́, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe ìrànlọ́wọ́ tó bá yẹ.
Wo ọ̀ràn tọkọtaya àgbàlagbà kan lórílẹ̀-èdè Sweden, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Hakan àti Inger. Hakan sọ pé: “Nígbà tí wọ́n sọ pé àrùn jẹjẹrẹ ló ń ṣe ìyàwó mi, ńṣe lọ̀rọ̀ náà kàn wá ku. Koko lara Inger le látilẹ̀wá. Àmọ́ ní báyìí, a ní láti máa lọ sílé ìwòsàn lójoojúmọ́ láti lọ gba ìtọ́jú, àwọn oògùn tí wọ́n sì ń fún un lágbára gan-an. Ilé ni Inger wà ní gbogbo àkókò yìí, mo sì ní láti dúró tì í kí n lè máa tọ́jú rẹ̀.” Báwo làwọn ará ìjọ ṣe ran Hakan àti Inger lọ́wọ́?
Àwọn alàgbà ìjọ ṣètò pé kí àwọn tọkọtaya yìí máa fetí sí ìpàdé látorí ẹ̀rọ tẹlifóònù. Láfikún sí i, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń lọ kí wọn nílé tàbí kí wọ́n kí wọn lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù. Wọ́n tún máa ń kọ lẹ́tà sí wọn, wọ́n sì máa ń fi káàdì ránṣẹ́. Hakan sọ pé: “A mọyì ìrànlọ́wọ́ tí àwọn ará wa àti Jèhófà ṣe fún wa. Àfiyèsí tí wọ́n fún wa yìí jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run dán mọ́rán. A dúpẹ́ pé ara Inger ti yá, a sì tún láǹfààní láti máa pésẹ̀ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.” Tí àwọn ará ìjọ bá ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran àwọn aláìlera àtàwọn àgbàlagbà tó wà láàárín wọn lọ́wọ́, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé ‘alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ tó máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, tó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà,’ ni àwọn jẹ́.—Òwe 17:17.
Jèhófà Mọrírì Ìsapá Rẹ
Títọ́jú ìbátan ẹni tó ń ṣàìsàn máa ń tánni lókun. Síbẹ̀, Dáfídì Ọba kọ̀wé pé: “Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀,” bí irú àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ nítorí àìlera.—Sm. 41:1.
Kí nìdí tí àwọn tó ń bójú tó àwọn aláìlera tàbí àwọn tó ń jìyà fi lè láyọ̀? Ìwé Òwe 19:17 sọ pé: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, Òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.” Ọwọ́ pàtàkì ni Ọlọ́run tòótọ́ fi mú ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tó ń ṣàìsàn, ó sì máa ń bù kún àwọn tó bá fojú rere hàn sí wọn. Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé [irú ẹni bẹ́ẹ̀] ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi; gbogbo ibùsùn rẹ̀ ni ìwọ yóò yí padà dájúdájú nígbà àìsàn rẹ̀.” (Sm. 41:3) Ó yẹ kó dá wa lójú pé tí ẹni tó ń bójú tó aláìsàn bá kojú ìṣòro tàbí àjálù kan, Jèhófà yóò ràn án lọ́wọ́.
Ó dára gan-an bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run ń kíyè sí ohun tá à ń ṣe láti bójú tó àwọn mọ̀lẹ́bí wa tó ń ṣàìsàn, kódà inú rẹ̀ dùn sí i! Bó tílẹ̀ jẹ́ pé ó gba ìsapá ká tó lè pèsè irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó dá wa lójú pé “irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.”—Héb. 13:16.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ wọn pa dà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run dán mọ́rán, kó o sì gba ìrànwọ́ látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíì