Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Lo Agbára Ìwòye Rẹ

Máa Lo Agbára Ìwòye Rẹ

Máa Lo Agbára Ìwòye Rẹ

Ó MÁA ń dùn mọ́ni láti rí àwọn ògbóǹkangí eléré ìdárayá tí wọ́n ń fi ara pitú! Bíbélì rọ àwọn Kristẹni láti kọ́ ara wọn láti mọ inú rò, gẹ́gẹ́ bí eléré ìdárayá ṣe máa ń dá ara rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́.

Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, ó sọ pé: “Oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ [bíi ti eléré ìdárayá] agbára ìwòye wọn [Lóréfèé, “àwọn ẹ̀yà ara tó ń jẹ́ kéèyàn ní ìmọ̀lára”] láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Héb. 5:14) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi rọ àwọn Kristẹni láti máa lo agbára ìrònú wọn gẹ́gẹ́ bí ògbóǹkangí eléré ìdárayá kan ṣe ń lo àwọn iṣan ara rẹ̀? Báwo la ṣe lè kọ́ agbára ìwòye wa?

“Ó Yẹ Kí Ẹ Jẹ́ Olùkọ́”

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé ipò Jésù gẹ́gẹ́ bí “àlùfáà àgbà ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì,” ó kọ̀wé pé: “Nípa [Jésù], a ní púpọ̀ láti sọ, tí ó sì ṣòro láti ṣàlàyé, níwọ̀n bí ẹ ti yigbì ní gbígbọ́. Nítorí, ní tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ ní ojú ìwòye ibi tí àkókò dé yìí, ẹ tún nílò kí ẹnì kan máa kọ́ yín láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run; ẹ sì ti di irúfẹ́ àwọn tí ó nílò wàrà, kì í ṣe oúnjẹ líle.”—Héb. 5:10-12.

Ó ṣe kedere pé, òye àwọn Júù tó di Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní kò kún sí i, wọn kò sì tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣòro fún wọn láti tẹ́wọ́ gba ìlàlóye tẹ̀mí nípa Òfin àti ìdádọ̀dọ́. (Ìṣe 15:1, 2, 27-29; Gál. 2:11-14; 6:12, 13) Ó nira fún àwọn kan láti fi àwọn àṣà àbáláyé tó ní í ṣe pẹ̀lú Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ àti Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún sílẹ̀. (Kól. 2:16, 17; Héb. 9:1-14) Torí náà, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wọ́n láti kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, kí wọ́n sì “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.” (Héb. 6:1, 2) Ìmọ̀ràn tó fún wọn yìí lè ti mú kí àwọn kan nínú wọn ronú nípa bí wọ́n ṣe ń lo agbára ìrònú wọn, ó sì ṣeé ṣe kí ìyẹn ti mú kí wọ́n tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Àwa ńkọ́?

Máa Lo Agbára Ìwòye Rẹ

Báwo la ṣe lè máa lo agbára ìrònú wa ká lè dàgbà nípa tẹ̀mí? Pọ́ọ̀lù sọ pé, ‘nípasẹ̀ lílò.’ Bí eléré ìdárayá kan ṣe máa ń ṣe ìdánrawò kó lè kọ́ àwọn iṣan ara rẹ̀ àti àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ yòókù láti ṣe irú eré ìdárayá kan tó fani mọ́ra tó sì ṣòro, àwa náà gbọ́dọ̀ máa lo agbára ìrònú wa ká lè máa fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.

Igbá kejì ọ̀jọ̀gbọ́n nípa àrùn ọpọlọ ní ilé ẹ̀kọ́ ìṣègùn Harvard Medical School, sọ pé: “Ohun tó dára jù lọ téèyàn lè ṣe fún ọpọlọ ni pé kó máa lò ó.” Ọ̀gbẹ́ni Gene Cohen, olùdarí àjọ kan tó ń rí sí ọ̀ràn ọjọ́ ogbó, ìlera àti ọmọnìyàn ní ilé ẹ̀kọ́ gíga George Washington University, sọ pé: “Tá a bá fún ọpọlọ wa ní iṣẹ́ ṣe, àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ọpọlọ á mú àwọn sẹ́ẹ̀lì tuntun jáde, èyí á sì mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí túbọ̀ so kọ́ra, kí wọ́n sì lè máa gba ìsọfúnni púpọ̀ sí i dúró.”

Torí náà, ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ fún wa láti máa lo agbára ìrònú wa, ká sì mú kí ìmọ̀ wa nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pọ̀ sí i. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè túbọ̀ gbára dì láti ṣe ‘ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tí ó pé.’—Róòmù 12:1, 2.

Jẹ́ Kí “Oúnjẹ Líle” Máa Wù Ẹ́ Jẹ

Tí a bá fẹ́ “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú” a ní láti bi ara wa pé: ‘Ṣé òye mi nínú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ń jinlẹ̀ sí i? Ǹjẹ́ àwọn míì ń wò mí bí ẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí?’ Inú abiyamọ máa ń dùn láti fún ọmọ rẹ̀ ní wàrà àti oúnjẹ ọmọ nígbà tó ṣì wà ní ìkókó. Àmọ́, wo bọ́rọ̀ náà ṣe máa rí lára rẹ̀ bí ọdún ti ń gorí ọdún tí ọmọ náà kò sì jẹ oúnjẹ líle. Lọ́nà kan náà, inú wa máa ń dùn tá a bá ń rí i tí ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń tẹ̀ síwájú débi tó fi ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tó sì ṣe ìrìbọmi. Àmọ́ bí ẹni náà kò bá wá tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí lẹ́yìn náà ńkọ́? Ṣé ìyẹn kò ní kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa? (1 Kọ́r. 3:1-4) Ohun tí ẹni tó ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ á máa retí ni pé kí ọmọ ẹ̀yìn tuntun náà di olùkọ́.

Ká tó lè máa lo agbára ìwòye láti ro àròjinlẹ̀, ó gba pé ká máa ṣàṣàrò, èyí sì gba ìsapá. (Sm. 1:1-3) A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohun tó ń pín ọkàn níyà, irú bíi wíwo tẹlifíṣọ̀n tàbí ṣíṣe eré ìgbà-ọwọ́-dilẹ̀, èyí tí kò nílò pé ká ronú jinlẹ̀, gba àkókò tó fi yẹ ká ro àròjinlẹ̀ mọ́ wa lọ́wọ́. Ká lè mú agbára ìrònú wa gbòòrò sí i, ó ṣe pàtàkì pé kó máa wù wá láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mát. 24:45-47) Láfikún sí dídá ka Bíbélì déédéé, ó tún ṣe pàtàkì fún wa láti ya àkókò sọ́tọ̀ fún Ìjọsìn Ìdílé àti kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì kan pàtó jinlẹ̀.

Alábòójútó àyíká kan lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jerónimo, sọ pé òun máa ń kẹ́kọ̀ọ́ gbogbo ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ gbàrà tó bá ti jáde. Ó tún máa ń ya àkókò sọ́tọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀. Jerónimo sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya, ó ti di àṣà wa láti jọ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, a sì máa ń lo àwọn ìtẹ̀jáde tó ń jẹ́ kí kíka Bíbélì túbọ̀ yéni, irú bí ìwé pẹlẹbẹ Wo ‘Ilẹ̀ Dáradára’ Náà.” Kristẹni kan tó ń jẹ́ Ronald sọ pé òun kì í jẹ́ kí ọ̀sẹ̀ kan kọjá lọ láìka Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó tún ní ìdákẹ́kọ̀ọ́ kan tàbí méjì tó ń bá a lọ fún àkókò gígùn. Ronald sọ pé: “Èyí ń jẹ́ kí n máa fojú sọ́nà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tó kàn tí màá ṣe.”

Àwa ńkọ́? Ṣé à ń ya àkókò tó pọ̀ tó sọ́tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ṣíṣe àṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ṣé à ń lo agbára ìrònú wa, ṣé a sì ti ń mọ bá a ṣe lè ṣe àwọn ìpinnu tó bá àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ mu? (Òwe 2:1-7) Ǹjẹ́ ká fi ṣe àfojúsùn wa láti jẹ́ ẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí, ká ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n bíi tàwọn tó ti kọ́ agbára ìwòye wọn láti máa fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

À ń “tipasẹ̀ lílò” kọ́ agbára ìrònú wa