Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ojú Tí Àwọn Kristẹni Ọ̀rúndún Kìíní Fi Wo Òrìṣà Àwọn Ará Róòmù

Ojú Tí Àwọn Kristẹni Ọ̀rúndún Kìíní Fi Wo Òrìṣà Àwọn Ará Róòmù

Ojú Tí Àwọn Kristẹni Ọ̀rúndún Kìíní Fi Wo Òrìṣà Àwọn Ará Róòmù

NÍNÚ lẹ́tà kan tí Pliny Kékeré tó jẹ́ gómìnà Bítíníà kọ sí Tírájánì Olú Ọba Róòmù, ó sọ pé: “Ohun tí mo ṣe nípa àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn níwájú mi pé wọ́n jẹ́ Kristẹni rèé. Mo máa ń bi wọ́n pé ṣe Kristẹni ni wọ́n lóòótọ́, tí wọ́n bá jẹ́wọ́, màá tún bi wọ́n nígbà kejì àti nígbà kẹta, màá sì halẹ̀ mọ́ wọn pé màá fìyà jẹ wọ́n. Tí wọn kò bá yéé sọ pé Kristẹni làwọn, màá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ pa wọ́n.” Ní ti àwọn tó bá sẹ́ pé àwọn kì í ṣe Kristẹni, tí wọ́n gégùn-ún fún Kristi, tí wọ́n sì jọ́sìn ère olú ọba àti àwọn ère òrìṣà tí Pliny gbé wá sílé ẹjọ́, ó kọ̀wé pé: “Mo wò ó pé ó bẹ́tọ̀ọ́ mu láti dá wọn sílẹ̀.”

Wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní torí pé wọ́n kọ̀ láti jọ́sìn olú ọba àti ère onírúurú òrìṣà. Àwọn ẹ̀sìn míì tó wà jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù ńkọ́? Àwọn òrìṣà wo ni wọ́n ń bọ, ojú wo sì làwọn ará Róòmù fi ń wò wọ́n? Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni torí pé wọ́n kọ̀ láti rúbọ sí àwọn òrìṣà àwọn ará Róòmù? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí á jẹ́ ká mọ ohun tá a máa ṣe lóde òní tí a bá dojú kọ ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìdúróṣinṣin wa sí Jèhófà.

Ẹ̀sìn Tí Wọ́n Ń Ṣe ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù

Bí èdè àti àṣà ìbílẹ̀ ṣe pọ̀ lọ jàra ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù náà ni òrìṣà tí wọ́n ń bọ níbẹ̀ ṣe pọ̀ lọ jàra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsìn àwọn Júù jẹ́ àjèjì lójú àwọn ará Róòmù, síbẹ̀ wọ́n kà á sí, wọ́n sì dáàbò bò ó. Nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ìgbà méjì lójúmọ́ ni wọ́n máa ń fi ọ̀dọ́ àgùntàn méjì àti màlúù kan rúbọ sí Késárì àti ilẹ̀ Róòmù. Yálà òrìṣà kan ni ẹbọ yìí ń tù lójú ni o tàbí ọ̀pọ̀ òrìṣà, ìyẹn ò ṣe pàtàkì lójú àwọn ará Róòmù. Ohun tó ṣe pàtàkì sí wọn ni pé àṣà yìí ń fi hàn pé àwọn Júù dúró ṣinṣin sí Róòmù.

Ìbọ̀rìṣà lónírúurú ọ̀nà gbòde kan jákèjádò ilẹ̀ Róòmù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tẹ́wọ́ gba ìtàn àròsọ àwọn Gíríìkì, iṣẹ́ wíwò sì wọ́pọ̀ gan-an. Àwọn ẹ̀sìn awo tó wá láti Ìlà Oòrùn ayé mú un dá àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn náà lójú pé, ọkàn wọn ò ní kú, wọ́n á máa ríran, wọ́n á sì máa kàn sí àwọn òrìṣà nípasẹ̀ àwọn ètùtù. Ẹ̀sìn yìí tàn jákèjádò ilẹ̀ ọba náà. Àwọn ará Íjíbítì tó ń bọ òrìṣà Serapis àti abo òrìṣà Isis, àwọn ará Síríà tó ń sin Yemọja Atargatis àti àwọn ará Páṣíà tó ń bọ òrìṣà oòrùn Mithra, gbajúmọ̀ gan-an ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni.

Kedere ni ìwé Ìṣe ṣàlàyé bí àwọn abọ̀rìṣà ṣe yí àwọn Kristẹni ká ní ọ̀rúndún kìíní. Bí àpẹẹrẹ, Júù kan tó jẹ́ oníṣẹ́ oṣó wà lọ́dọ̀ alákòóso ìbílẹ̀ Róòmù ní Kípírọ́sì. (Ìṣe 13:6, 7) Ní ìlú Lísírà àwọn èèyàn fi Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pe òrìṣà àwọn Gíríìkì tó ń jẹ́ Hẹ́mísì àti Súúsì. (Ìṣe 14:11-13) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní ìlú Fílípì, ó pàdé ìránṣẹ́bìnrin kan tó ní ẹ̀mí Èṣù ìwoṣẹ́. (Ìṣe 16:16-18) Ní ìlú Áténì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ‘ó jọ pé àwọn olùgbé ìlú náà kún fún ìbẹ̀rù àwọn ọlọ́run àjúbàfún ju àwọn mìíràn lọ.’ Ní ìlú yìí kan náà ló ti rí pẹpẹ kan tí wọ́n kọ “Sí Ọlọ́run Àìmọ̀” sára rẹ̀. (Ìṣe 17:22, 23) Àwọn olùgbé ìlú Éfésù ń jọ́sìn abo òrìṣà Átẹ́mísì. (Ìṣe 19:1, 23, 24, 34) Ní erékùṣù Málítà, àwọn èèyàn pe Pọ́ọ̀lù ní ọlọ́run torí pé kò sí ohun tó ṣe é nígbà tí ejò bù ú ṣán. (Ìṣe 28:3-6) Ní irú ipò yìí, àwọn Kristẹni ní láti máa ṣọ́ra fún àṣà tó lè ṣàkóbá fún ìjọsìn mímọ́ tí wọ́n ń ṣe.

Ẹ̀sìn Àwọn Ará Róòmù

Bí ilẹ̀ ọba yìí ṣe ń gbòòrò sí i, àwọn ará Róòmù bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn àwọn òrìṣà ilẹ̀ àjèjì, wọ́n gbà pé wọn ò yàtọ̀ sáwọn òrìṣà tí àwọn ń bọ tẹ́lẹ̀, wọ́n kàn fara hàn lọ́nà míì ni. Dípò tí àwọn ará Róòmù ì bá fi fòpin sí àwọn ẹ̀sìn yìí, ńṣe ni wọ́n gbà wọ́n wọlé, tí wọ́n sì sọ wọ́n di ti ilẹ̀ Róòmù. Bí onírúurú àṣà ìbílẹ̀ ṣe pọ̀ nílẹ̀ Róòmù náà ni ẹ̀sìn ṣe wà lónírúurú. Àwọn ará Róòmù kò fi dandan lé e pé ẹ̀sìn kan ṣoṣo ni ẹnì kan gbọ́dọ̀ máa ṣe. Àwọn èèyàn lè máa bọ ọ̀kan-ò-jọ̀kan òrìṣà lẹ́ẹ̀kan náà.

Èyí tó gbawájú jù lọ lára òrìṣà tó jẹ́ táwọn ará Róòmù ni Júpítà, tí wọ́n tún ń pè ní Optimus Maximus, tó túmọ̀ sí, èyí tó dára jù lọ tó sì tóbi jù lọ. Èrò wọn ni pé ó máa ń fara hàn nínú ẹ̀fúùfù, òjò, mànàmáná àti àrá. Wọ́n gbà pé òrìṣà òṣùpá ni Juno tó jẹ́ ìbátan obìnrin àti alábàárò fún Júpítà. Wọ́n sì tún sọ pé òun ló ń bójú tó gbogbo ohun tó bá ti jẹ mọ́ ọ̀ràn àwọn obìnrin. Wọ́n sọ pé Minerva, tó jẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ni òrìṣà àwọn oníṣẹ́ ọwọ́, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, àwọn oníṣẹ́ ọnà àti ogun.

Òrìṣà tí àwọn ará Róòmù ń bọ kò lóǹkà. Lares àti Penates jẹ́ òrìṣà ìdílé. Vesta ni abo òrìṣà ààrò. Ère Janus tó ní orí méjì, ọ̀kan níwájú àti èkejì lẹ́yìn, ni wọ́n gbà pé ó jẹ́ ọlọ́run ìbẹ̀rẹ̀. Gbogbo òwò tí wọ́n ń ṣe ló ní òrìṣà tiẹ̀. Àwọn ará Róòmù tún máa ń bọ onírúurú èròǹgbà bí ẹní bọ òrìṣà. Pax ló ń pa àlàáfíà mọ́, Salus jẹ́ òrìṣà ìlera, Pudicitia, ni òrìṣà ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni àti ti ìwà mímọ́, Fides ni òrìṣà ìṣòtítọ́, Virtus ni òrìṣà ìgboyà, Voluptas sì ni òrìṣà fàájì. Gbogbo ohun táwọn ará Róòmù bá ń ṣe ní gbangba tàbí ní kọ̀rọ̀ ni wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn òrìṣà kan ló ń darí rẹ̀. Torí náà kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí nínú ohun kan tí wọ́n bá dáwọ́ lé, wọ́n máa ní láti tu òrìṣà tí wọ́n gbà pé ó ń bójú tó nǹkan yẹn lójú, nípasẹ̀ ètùtù, ìrúbọ àti àjọyọ̀.

Ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà mọ ohun tí àwọn òrìṣà fọwọ́ sí ni wíwo àwọn àmì àpẹẹrẹ. Pàtàkì jù lọ lára ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò tinú ẹran tí wọ́n bá fi rúbọ. Èrò wọn ni pé ipò tí tinú ẹran náà bá wà àti bó ṣe rí ló máa fi hàn bóyá àwọn òrìṣà náà fọwọ́ sí ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe tàbí wọn ò fọwọ́ sí i.

Nígbà tó fi máa di ọwọ́ ìparí ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Róòmù ti wá gbà pé ọ̀kan náà ni àwọn òrìṣà pàtàkì pàtàkì táwọn ń bọ jẹ́ pẹ̀lú òrìṣà àwọn Gíríìkì. Wọ́n gbà pé Júpítà ni Súúsì òrìṣà àwọn Gíríìkì, Juno ni Hera àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ará Róòmù sì gba ìtàn àròsọ àwọn Gíríìkì tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn òrìṣà wọ̀nyí. Wọn ò fi àwọn ìtàn àròsọ yìí bu àwọn òrìṣà náà kù rárá, torí pé wọ́n ní àléébù tiwọn, ó sì ní ibi tí agbára wọ́n mọ bíi tàwọn tó ń bọ wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣàpèjúwe Súúsì pé ó máa ń fipá báni lòpọ̀ àti pé ó máa ń bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe, ó sì máa ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti aláìlẹ́mìí. Ìwà àìnítìjú àwọn òrìṣà yìí, tí àwọn èèyàn máa ń lọ wò ní gbọ̀ngàn ìwòran, mú kí àwọn tó ń sin àwọn òrìṣà náà máa rò pé kò burú tí àwọn bá ń hu irú ìwà pálapàla yìí.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé díẹ̀ lára àwọn ọ̀mọ̀wé ló gba àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu yìí sóòótọ́. Àwọn kan sì gbà pé àlọ́ lásán ni wọ́n. Ó lè jẹ́ èyí ló fà á tí Pọ́ńtù Pílátù fi béèrè pé, “Kí ni òtítọ́?” (Jòh. 18:38) Àwọn kan máa ń rí ìbéèrè yìí bí “ohun tí àwọn ọ̀mọ̀wé sábà máa ń ní lọ́kàn bí wọ́n bá sọ pé kò ṣeé ṣe láti mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa ohunkóhun.”

Ìjọsìn Olú Ọba

Ìgbà ìṣàkóso Ọ̀gọ́sítọ́sì (ọdún 27 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọdún 14 Sànmánì Kristẹni) ni wọ́n dá ìjọsìn olú ọba sílẹ̀. Àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì ní àgbègbè Ìlà Oòrùn, fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí Ọ̀gọ́sítọ́sì, tó jẹ́ kí aásìkí àti àlàáfíà wà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti fi jagun. Àwọn èèyàn ń fẹ́ máa wà ní ààbò nìṣó lábẹ́ alákòóso kan tí wọ́n á máa fojú rí. Wọ́n fẹ́ àjọ kan tó máa mú ọ̀ràn kẹ́lẹ́sìnmẹ̀sìn kúrò, táá gbé ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lárugẹ, táá sì pèsè ẹni tó máa mú kí aráyé wà ní ìṣọ̀kan. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi sọ olú ọba di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀gọ́sítọ́sì kò gbà kí wọ́n máa pe òun ní ọlọ́run nígbà tó wà láyé, síbẹ̀ ó fi dandan lé e pé kí wọ́n máa bọ ìlú Róòmù gẹ́gẹ́ bí abo ọlọ́run, wọ́n pè é ní Roma Dea. Wọ́n wá sọ Ọ̀gọ́sítọ́sì di òrìṣà lẹ́yìn ikú rẹ̀. Gbogbo ẹ̀sìn tó wà ní ìlú Róòmù wá darí èrò wọn àti ìfọkànsìn wọn sí ilẹ̀ ọba náà àti àwọn alákòóso. Ìjọsìn olú ọba tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ tàn kálẹ̀ jákèjádò àgbègbè náà, ó sì wá di ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà fi ọ̀wọ̀ àti ìdúróṣinṣin wọn fún Orílẹ̀-èdè náà hàn.

Dòmítíà tó ṣàkóso láti ọdún 81 sí 96 Sànmánì Kristẹni ni olú ọba àkọ́kọ́ ní ìlú Róòmù tó ní kí àwọn èèyàn máa jọ́sìn òun bí ọlọ́run. Nígbà ayé rẹ̀, àwọn Róòmù ti ya ẹ̀sìn Kristẹni sọ́tọ̀ lára ẹ̀sìn àwọn Júù, wọ́n sì ń ta ko ohun tí wọ́n pè ní ẹ̀sìn tuntun yìí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà ìṣàkóso Dòmítíà ni wọ́n rán àpọ́sítélì Jòhánù lọ sígbèkùn ní erékùṣù Pátímọ́sì nítorí “jíjẹ́rìí Jésù.”—Ìṣí. 1:9.

Ìgbà tí Jòhánù wà ní ìgbèkùn ló kọ ìwé Ìṣípayá. Nínú ìwé náà, ó tọ́ka sí Kristẹni kan tó ń jẹ́ Áńtípà, ẹni tí wọ́n pa ní Págámù, ojúkò ìjọsìn olú ọba. (Ìṣí. 2:12, 13) Nígbà yẹn, ó ṣeé ṣe kí olú ọba ti máa fi dandan lé e pé kí àwọn Kristẹni tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀ máa lọ́wọ́ sí ààtò ìjọsìn Orílẹ̀-èdè. Yálà ọ̀rọ̀ yìí jóòótọ́ tàbí kì í ṣòótọ́, nígbà tó fi máa di ọdún 112 Sànmánì Kristẹni, bó ṣe wà nínú lẹ́tà tí Pliny kọ sí Tírájánì, èyí tá a fi bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, irú ààtò ìjọsìn yìí ni Pliny fi dandan lé e pé kí àwọn Kristẹni tó wà ní Bítíníà lọ́wọ́ sí.

Tírájánì gbóríyìn fún Pliny fún bó ṣe ń bójú tó ọ̀ràn àwọn Kristẹni tí wọ́n bá gbé wá síwájú rẹ̀, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n máa pa àwọn Kristẹni tó bá kọ̀ láti jọ́sìn àwọn òrìṣà àwọn ará Róòmù. Tírájánì wá kọ̀wé pé: “Àmọ́ ṣá o, tí ẹni náà bá sọ pé òun kì í ṣe Kristẹni, tó sì fi hàn gbangba nípa gbígbàdúrà sí àwọn ọlọ́run wa, kí o forí ji ẹni náà (láìka ìfura èyíkéyìí sí) lẹ́yìn tó bá ti ronú pìwà dà.”

Àwọn ará Róòmù kò jẹ́ gbà pé ẹ̀sìn èyíkéyìí wà tó ń béèrè ìfọkànsìn tá a yà sọ́tọ̀ gédégbé látọ̀dọ̀ àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn náà. Òrìṣà àwọn Róòmù kó béèrè fún èyí, kí nìdí tí Ọlọ́run àwọn Kristẹni á fi wá máa béèrè fún un? Wọ́n gbà pé jíjọ́sìn Orílẹ̀-èdè ẹni wulẹ̀ ń fi hàn pé èèyàn fara mọ́ ètò ìṣèlú orílẹ̀-èdè yẹn ni. Torí náà, wọ́n ka kíkọ̀ láti jọ́sìn rẹ̀ sí ìdìtẹ̀ sí orílẹ̀-èdè ẹni. Pliny rí i pé kò sí bí àwọn ṣe lè fipá mú èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni láti máa jọ́sìn orílẹ̀-èdè wọn. Lójú àwọn Kristẹni, irú àṣà bẹ́ẹ̀ jẹ́ àìṣòótọ́ sí Jèhófà, àìmọye àwọn Kristẹni ló sì ṣe tán láti kú dípò tí wọ́n á fi lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà nípa jíjọ́sìn olú ọba.

Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn yìí lóde òní? Ní àwọn ilẹ̀ kan, wọ́n retí pé kí àwọn ará ìlú bọ̀wọ̀ fún àmì ìlú wọn. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ó dájú pé a bọ̀wọ̀ fún àwọn olùṣàkóso ìjọba. (Róòmù 13:1) Àmọ́, tó bá dọ̀rọ̀ ayẹyẹ tó kan kíkí àsíá orílẹ̀-èdè, a kì í lọ́wọ́ sí i torí pé Jèhófà Ọlọ́run béèrè ìfọkànsìn tá a yà sọ́tọ̀ gédégbé àti pé ó kìlọ̀ fún wa nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ká máa “sá fún ìbọ̀rìṣà” àti pé ká “máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.” (1 Kọ́r. 10:14; 1 Jòh. 5:21; Náh. 1:2) Jésù sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.” (Lúùkù 4:8) Ǹjẹ́ ká máa bá a lọ láti máa fi ìdúróṣinṣin wa hàn sí Ọlọ́run tí à ń sìn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń fún Jèhófà ní ìfọkànsìn tá a yà sọ́tọ̀ gédégbé

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kò jọ́sìn olú ọba tàbí ère àwọn òrìṣà

Olú Ọba Dòmítíà

Súúsì

[Àwọn Credit Line]

Olú Ọba Domitian: Todd Bolen/Bible Places.com; Súúsì: Fọ́tò tí Todd Bolen/Bible Places.com yà ní ibi-ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti Archaeological Museum of Istanbul

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù kọ̀ láti jọ́sìn abo òrìṣà Átẹ́mísì tó gbajúmọ̀.—Ìṣe 19:23-41