Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfẹ́ So Wá Pọ̀ Ìròyìn Ìpàdé Ọdọọdún

Ìfẹ́ So Wá Pọ̀ Ìròyìn Ìpàdé Ọdọọdún

Ìfẹ́ So Wá Pọ̀ Ìròyìn Ìpàdé Ọdọọdún

ÌDÙNNÚ ṣubú layọ̀ fún gbogbo àwọn tó pé jọ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Jersey City, ní ìpínlẹ̀ New Jersey, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ní àárọ̀ October 3, 2009, ó lé ní ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000] èèyàn tó pé jọ fún ìpàdé ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, ẹlẹ́ẹ̀karùnlélọ́gọ́fà [125] irú rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn míì, ní àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì mẹ́ta tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti èyí tó wà lórílẹ̀-èdè Kánádà, ló gbádùn ìpàdé ọdọọdún náà nípasẹ̀ ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán alátagbà. Lápapọ̀, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá àti òjìlérúgba ó dín márùn-ún [13,235] èèyàn ni ìfẹ́ fún Jèhófà so pọ̀ ṣọ̀kan láti gbádùn ìpàdé oníwákàtí-mẹ́ta náà.

Arákùnrin Geoffrey Jackson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ni alága ìpàdé náà. Ó bẹ̀rẹ̀ ìpàdé náà nípa kíké sí àwọn kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì láti kọ díẹ̀ lára àwọn orin tó wà nínú ìwé orin wa tuntun. Arákùnrin David Splane, tí òun náà jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí, tó sì ṣe àlàyé ṣókí nípa bí orin ti ṣe pàtàkì tó nínú ìjọsìn tòótọ́, ló darí àwọn akọrin náà. Wọ́n ké sí àwùjọ láti kọ mẹ́ta lára àwọn orin tuntun náà ní ìpàdé yẹn; àwọn akọrin náà ló máa kọ́kọ́ gbé ohun rẹ̀, lẹ́yìn náà àwọn àti àwùjọ yóò wá jọ kọ ọ́. Ìpàdé àkànṣe yìí nìkan la ti lo àwọn akọrin o; a kò ní máa lo àwọn akọrin ní ìpàdé ìjọ, àpéjọ àkànṣe, àyíká tàbí àgbègbè o!

Ìròyìn Láti Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì

Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tó wá sí ìpàdé náà sọ ìròyìn láti ẹ̀ka ọ́fíìsì márùn-ún. Kenneth Little ròyìn pé Kánádà máa tó bẹ̀rẹ̀ sí tẹ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìwé ìròyìn tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Kánádà á máa lò, èyí á sì fi ìlọ́po mẹ́wàá ju iye tí wọ́n ń tẹ̀ níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ lọ. Kí èyí lè ṣeé ṣe, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rà, á máa ṣiṣẹ́ láìdáwọ́dúró fún wákàtí mẹ́rìndínlógún lójúmọ́.

Arákùnrin Reiner Thompson ròyìn bí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń lọ sí lórílẹ̀-èdè Dominican Republic, Arákùnrin Albert Olih sì ṣàlàyé ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù wa lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Arákùnrin Emile Kritzinger láti orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì ṣàlàyé pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n fi ṣe inúnibíni sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè náà, wọ́n fi orúkọ wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dún 1992. Àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ní ìbísí tó gọntíọ nínú iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Arákùnrin Viv Mouritz láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Ọsirélíà sọ nípa bí iṣẹ́ wa ṣe ń tẹ̀ síwájú ní erékùṣù East Timor, èyí tí àwọn ará wa ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ń bójú tó.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ní ọdún 1976, gbogbo ìgbòkègbodò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ni a mú wá sábẹ́ àbójútó ìgbìmọ̀ mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Nígbà tó yá, a yan àwọn kan lára àwọn àgùntàn mìíràn láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́. Ní báyìí, àwọn mẹ́tàlélógún [23] ló ń ran àwọn ìgbìmọ̀ yìí lọ́wọ́. Wọ́n fọ̀rọ̀ wá mẹ́fà lára wọn lẹ́nu wò. Lápapọ̀, àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ti lo òjìlélọ́ọ̀ọ́dúnrún ọdún ó lé kan [341] lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, èyí sì jẹ́ ìpíndọ́gba ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [57] fún ẹnì kan.

Arákùnrin Don Adams, tó dé Bẹ́tẹ́lì lọ́dún 1943, ṣàlàyé pé àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí ló ń ṣe kòkáárí ìgbìmọ̀ márùn-ún tó kù, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún ìgbìmọ̀ márààrún láti máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀ lọ́nà tó gún régé. Ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó àwọn ọ̀ràn pàjáwìrì tó légbá kan, inúnibíni, ọ̀ràn ẹjọ́, ìjábá, àtàwọn ọ̀ràn kánjúkánjú míì tó kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé.

Arákùnrin Dan Molchan sọ iṣẹ́ Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Àwọn Òṣìṣẹ́. Ó ṣàlàyé pé ìgbìmọ̀ yìí ló ń rí sí àbójútó tara àti tẹ̀mí fún ọ̀kẹ́ kan ó dín mọ́kàndínláàádọ́jọ [19,851] èèyàn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì kárí ayé. Arákùnrin David Sinclair sọ̀rọ̀ nípa bí Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde ṣe ń bójú tó ríra àwọn ohun èlò àti irinṣẹ́ fún àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kárí ayé. Lẹ́yìn náà ni Arákùnrin Robert Wallen tó ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì fún ọgọ́ta [60] ọdún sọ bí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ṣe ń bójú tó ìgbòkègbodò àwọn èèyàn Jèhófà tó wà ní pápá àti nínú ìjọ. Arákùnrin William Malenfant ṣàlàyé iṣẹ́ ribiribi tí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe láti ṣètò àpéjọ àgbègbè. Níkẹyìn, Arákùnrin John Wischuk ṣàlàyé bí Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé ṣe ń fara bálẹ̀ ṣàkójọ àwọn ìsọfúnni tó ń jáde nínú àwọn ìwé wa àti àwọn ètò míì tó ń bá a rìn. a

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2010 Dá Lórí Ìfẹ́

Lẹ́yìn náà, àwọn tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ àsọyé mẹ́ta. Arákùnrin Gerrit Lösch fi ìbéèrè kan bẹ̀rẹ̀ àsọyé rẹ̀, ó ní: “Ṣé o fẹ́ kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ rẹ?” Ó ṣàlàyé pé gbogbo èèyàn ló nílò ìfẹ́, òun ló sì ń jẹ́ ká wà láàyè. Ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan tí Jèhófà ní ló jẹ́ kó ṣẹ̀dá èèyàn. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló mú ká máa wàásù, ká sì máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.

Kì í ṣe àwọn aládùúgbò wa nìkan la máa ń fi ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà hàn sí, a tún máa ń fi hàn sí àwọn ọ̀tá wa pẹ̀lú. (Mát. 5:43-45) Ó rọ àwùjọ láti ronú lórí ìyà tí Jésù jẹ nítorí tiwa, wọ́n lù ú, wọ́n bú u, wọ́n tutọ́ sí i lára, wọ́n sì fi ọ̀kọ̀ gún un. Síbẹ̀, ó gbàdúrà fún àwọn ọmọ ogun tí wọ́n kàn án mọ́gi. Ǹjẹ́ èyí kò mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Lẹ́yìn náà, Arákùnrin Lösch wá sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2010. A gbé e ka 1 Kọ́ríńtì 13:7, 8, tó sọ pé, ‘Ìfẹ́ a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.’ A nírètí láti wà láàyè títí láé, ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, káwọn náà sì máa nífẹ̀ẹ́ wa títí láé.

Ṣé Epo Wà Nínú Ọkọ̀ Rẹ?

Àpèjúwe kan ni Arákùnrin Samuel Herd fi bẹ̀rẹ̀ àsọyé rẹ̀. Ká sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ kan sọ pé kó o bá òun rin ìrìn àjò tó jìn tó nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà. Níbi tó o jókòó sí nínú ọkọ̀ náà, o kíyè sí i pé ohun tó máa ń díwọ̀n epo ọkọ̀ ń fi hàn pé epo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán nínú ọkọ̀ náà. O sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ pé epo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán nínú ọkọ̀ rẹ̀. Ó sì ní kó o má ṣèyọnu; ó ṣì ku bíi gálọ́ọ̀nù epo kan nínú táǹkì. Àmọ́ kò pẹ́ tí epo fi tán pátápátá. Ṣó yẹ kó máa bá ìrìn àjò náà lọ, nígbà tó mọ̀ pé epo ti tán, àti pé ọkọ̀ náà kò ní gbé yín dé ibi tí ẹ̀ ń lọ? Ẹ ò rí i pé ó máa sàn kó kúkú rọ epo kún inú ọkọ̀ yẹn! Lọ́nà àpẹẹrẹ, ó yẹ kí epo, ìyẹn ìmọ̀ tá a ní nípa Jèhófà, wà nínú ọkọ̀ tiwa náà.

Torí náà, ó yẹ ká máa rọ epo kún inú ọkọ̀ wa, ká sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Ọ̀nà mẹ́rin wà tá a lè gbà ṣe èyí. Èyí àkọ́kọ́ ni pé ká máa dá kẹ́kọ̀ọ́, ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ ká lè mọ ohun tó wà nínú rẹ̀. Èyí kọjá ká kàn máa ka ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ o, ohun tá a kà gbọ́dọ̀ yé wa. Èkejì, ẹ rí i pé ẹ̀ ń jàǹfààní látinú Ìjọsìn Ìdílé.Ṣé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la máa ń tipasẹ̀ irú ìṣètò yìí rọ epo kún inú ọkọ̀ wa, àbí ìwọ̀nba epo tó wà là ń gbé kiri? Ẹ̀kẹta, ìpàdé ìjọ àti lílọ sí ìpàdé déédéé. Ìkẹrin, ṣíṣe àṣàrò níbi tó dákẹ́ rọ́rọ́ tí kò ti sí ìdíwọ́ láti máa ronú nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà. Sáàmù 143:5 sọ pé: “Mo ti rántí àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn; mo ti ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ.”

“Àwọn Olódodo Yóò Máa Tàn Yòò”

Arákùnrin John Barr ló sọ àsọyé kẹta àti èyí tó kẹ́yìn, èyí tó ṣàlàyé àpèjúwe Jésù nípa èpò àti àlìkámà. (Mát. 13:24-30, 38, 43) “Ìkórè” ni àpèjúwe yẹn tọ́ka sí, ìyẹn ìgbà tí a máa kó “àwọn ọmọ ìjọba náà” jọ, tí a ó sì ya àwọn èpò sọ́tọ̀ láti fi iná sun wọ́n.

Arákùnrin Barr jẹ́ kó ṣe kedere pé ìkójọ náà kò ní máa bá a lọ títí láé. Ó tọ́ka sí Mátíù 24:34 tó sọ pé: “Ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.” Ìgbà méjì ló ka gbólóhùn tó sọ pé: “Ó ṣe kedere pé ohun tí Jésù ń sọ ni pé àwọn ẹni àmì òróró tí ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà máa ṣojú wọn ṣì máa gbé ayé lákòókò kan pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró tó rí àmì náà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914.” A kò mọ bí “ìran yìí” ṣe máa pẹ́ tó, àmọ́ ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn àwùjọ méjì yìí tí wọ́n gbé ayé láàárín àkókò kan náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ orí àwọn ẹni àmì òróró yàtọ̀ síra, àwùjọ méjèèjì tó para pọ̀ di ìran náà jẹ́ alájọgbáyé láàárín àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ó mà tuni nínú o, láti mọ̀ pé àwọn ẹni àmì òróró tọ́jọ́ orí wọ́n ṣì kéré tó jẹ́ alájọgbáyé pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró tó ti dàgbà tí wọ́n fòye mọ àmì náà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 kò ní kú tán kí ìpọ́njú ńlá náà tó bẹ̀rẹ̀!

“Àwọn ọmọ ìjọba náà” ń fi ìháragàgà dúró de èrè wọn ní ọ̀run, àmọ́ gbogbo wa la gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́, ká máa tàn yòò títí dé òpin. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa pé kíkó “àlìkámà” náà jọ lásìkò tá à ń gbé yìí ṣojú wa.

Lẹ́yìn orin ìparí, Arákùnrin Theodore Jaracz tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí fi àdúrà parí ìpàdé náà. Ìpàdé ọdọọdún yìí mà gbéni ró gan-an ni o!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ilé Ìṣọ́ May 15, 2008, ojú ìwé 29, ṣàlàyé iṣẹ́ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìgbìmọ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń ṣe.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN ALÀGBÀ

Ní ìpàdé ọdọọdún náà, Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ìfilọ̀ pé, a ó máa bá a lọ ní dídá àwọn alàgbà ìjọ lẹ́kọ̀ọ́. Ilé ẹ̀kọ́ àwọn alàgbà tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2008 ní ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní Patterson, nílùú New York. A ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíláàsì kejì-lé-láàádọ́rin [72] ni, a sì ti dá àwọn alàgbà tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n dín ọgọ́rin [6,720 ] lẹ́kọ̀ọ́. A ṣì ní púpọ̀ láti ṣe. Àwọn alàgbà tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan ju ọ̀kẹ́ mẹ́rin lé ẹgbàáta lọ [86,000]. Torí náà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti fọwọ́ sí i pé ká dá ilé ẹ̀kọ́ míì sílẹ̀ ní Brooklyn, New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èyí á sì bẹ̀rẹ̀ ní December 7, 2009.

Fún oṣù méjì, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò mẹ́rin máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti di olùkọ́ ní Patterson. Àwọn la máa rán lọ sí Brooklyn láti lọ di olùkọ́, a ó sì tún dá àwọn mẹ́rin míì lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn mẹ́rin yìí ló máa wá lọ di olùkọ́ ní Brooklyn, tí àwọn mẹ́rin tá a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀ á sì kọjá lọ máa ṣe olùkọ́ ní àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ohun tí a ó máa ṣe nìyí títí tá a fi máa ní àwọn olùkọ́ méjìlá táá máa kọ́ kíláàsì mẹ́fà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn náà la máa dá àwọn mẹ́rin míì lẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi èdè Sípáníìṣì darí ilé ẹ̀kọ́ náà. Ilé ẹ̀kọ́ yìí kò ní rọ́pò Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́; ìdí tá a fi dá a sílẹ̀ ni láti mú kí ipò tẹ̀mí àwọn alàgbà sunwọ̀n sí i. Ọdún iṣẹ́ ìsìn 2011 làwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kárí ayé máa bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ilé ẹ̀kọ́ yìí láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

A bẹ̀rẹ̀ ìpàdé ọdọọdún pẹ̀lú kíkọ orin látinú ìwé orin wa tuntun, “Kọrin sí Jèhófà”