Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Tútù Máa Ń mú Kí Àjọṣe Wa Pẹ̀lú Àwọn Míì Sunwọ̀n Sí I

Ọ̀rọ̀ Tútù Máa Ń mú Kí Àjọṣe Wa Pẹ̀lú Àwọn Míì Sunwọ̀n Sí I

Ọ̀rọ̀ Tútù Máa Ń mú Kí Àjọṣe Wa Pẹ̀lú Àwọn Míì Sunwọ̀n Sí I

“Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.”—KÓL. 4:6.

1, 2. Nígbà tí arákùnrin kan sọ ọ̀rọ̀ tútù, ohun rere wo ló tìdí ẹ̀ yọ?

 ARÁKÙNRIN kan sọ pé: “Nígbà tí mò ń wàásù láti ilé dé ilé, mo bá ọkùnrin kan pàdé. Inú bí ọkùnrin yìí débi pé ètè rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n, gbogbo ara rẹ̀ sì ń wárìrì. Mo fi ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ fèròwérò pẹ̀lú rẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́, àmọ́ ńṣe ni ìbínú rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Ìgbà tó yá, ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí bú mi, ìgbà yẹn ni mo wá mọ̀ pé ó tó àkókò fún mi láti kúrò níbẹ̀. Mo jẹ́ kó dá ìdílé náà lójú pé àlàáfíà ni mo bá wá àti pé mo fẹ́ kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà. Mo fi ìwé Gálátíà 5:22, 23 hàn wọ́n níbi tó ti sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́, ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Lẹ́yìn náà ni mo kúrò níbẹ̀.

2 “Ó wá ṣẹlẹ̀ pé, bí mo ṣe ń lọ láti ilé dé ilé ní òdì kejì ibi tí ilé wọn wà, mo rí i tí ìdílé náà jókòó sórí àtẹ̀gùn iwájú ilé wọn. Wọ́n ké sí mi. Mo wá ronú pé, ‘Èwo ló tún dé o.’ Ọkùnrin náà gbé ife omi tútù dání, ó sì fi omi lọ̀ mí. Ó bẹ̀ mí pé kí n má ṣe bínú torí ìwà àìlọ́wọ̀ tí òun hù sí mi, ó sì gbóríyìn fún mi nítorí ìgbàgbọ́ lílágbára tí mo ní. Mo sì fi ibẹ̀ sílẹ̀ láìsí ìkùnsínú kankan.”

3. Kí nìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn míì máa mú wa bínú?

3 Nínú ayé tó kún fún pákáǹleke yìí, kò sí bí a kò ṣe ní máa bá àwọn èèyàn tí inú ń bí pàdé, kódà nígbà tá a bá ń wàásù. Bí a bá sì bá wọn pàdé, ó ṣe pàtàkì pé ká fi “inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” hàn. (1 Pét. 3:15) Ká sọ pé arákùnrin wa yẹn jẹ́ kí ìbínú onílé àti ìwà àìnífẹ̀ẹ́ tó hù mú kí òun náà bínú ni, ó ṣeé ṣe kí ìwà ọkùnrin náà máà yí pa dà; inú sì lè bí i jùyẹn lọ. Àmọ́, torí pé arákùnrin náà kó ara rẹ̀ níjàánu, tó sì sọ̀rọ̀ tútù, ìbẹ̀wò náà yọrí sí rere.

Báwo La Ṣe Lè Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Tútù?

4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa sọ ọ̀rọ̀ tútù?

4 Yálà àwọn tó jẹ́ ará là ń bá da nǹkan pọ̀ ni o tàbí àwọn tí kì í ṣe ará, ì báà sì jẹ́ àwọn tó wà nínú ìdílé wa pàápàá, ó ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.” (Kól. 4:6) Irú àsọjáde tó dùn mọ́ni, tó sì bójú mu bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán, ó sì máa ń jẹ́ kí àlàáfíà jọba.

5. Kí ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dára kò túmọ̀ sí? Ṣàpèjúwe.

5 Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dára kò túmọ̀ sí pé kéèyàn máa sọ gbogbo ohun tó bá wá síni lọ́kàn àti bí ọ̀rọ̀ bá ṣe rí lára ẹni nígbàkigbà, pàápàá jù lọ bí inú bá ń bíni. Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ìwà òmùgọ̀ ni féèyàn láti máa fi ìbínú sọ̀rọ̀, kì í ṣe ìwà ọmọlúwàbí. (Ka Òwe 25:28; 29:11.) Ìgbà kan wà tí Mósè, tó “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù” ju gbogbo èèyàn tó wà láyé nígbà yẹn, jẹ́ kí ìwà ọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sún òun láti bínú tó sì wá kùnà láti fi ògo fún Ọlọ́run. Mósè sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, àmọ́ ohun tó ṣe kò dùn mọ́ Jèhófà nínú. Lẹ́yìn ogójì ọdún tí Mósè fi jẹ́ aṣáájú fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò ní àǹfààní láti kó wọn wọ Ilẹ̀ Ìlérí.—Núm. 12:3; 20:10, 12; Sm. 106:32.

6. Kí ló túmọ̀ sí pé ká máa fi òye sọ̀rọ̀?

6 Ìwé Mímọ́ gbóríyìn fún àwọn tó bá ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu, òye tàbí làákàyè nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Bíbélì sọ pé: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.” (Òwe 10:19; 17:27) Síbẹ̀, lílo òye tá a bá ń sọ̀rọ̀ kò túmọ̀ sí pé ká má ṣe sọ̀rọ̀ rárá. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ká máa sọ̀rọ̀ “pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́,” ìyẹn ni pé ká máa sọ̀rọ̀ tútù, nípa lílo ahọ́n wa láti gbéni ró, ká má ṣe lò ó láti kó ẹ̀dùn ọkàn báni.—Ka Òwe 12:18; 18:21.

“Ìgbà Dídákẹ́ Jẹ́ẹ́ àti Ìgbà Sísọ̀rọ̀”

7. Àwọn nǹkan wo ni kò yẹ ká máa sọ, kí sì nìdí?

7 Bó ṣe yẹ ká máa lo òye ká sì máa kóra wa níjàánu nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn alábàáṣiṣẹ́ wa tàbí àwọn àjèjì tí a bá bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa ṣe nínú ìjọ àti nínú ilé. Fífaraya láìronú lórí ibi tó máa já sí lè ba àjọṣe wa àti àjọṣe àwọn míì pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa, kó sì tún kó bá ìlera wa. (Òwe 18:6, 7) A gbọ́dọ̀ ṣàkóso ìmọ̀lára tí kò tọ̀nà, èyí tí àìpé máa ń fà. Ọ̀rọ̀ èébú, ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn, títẹ́ńbẹ́lú ẹni, àti ìbínú tó ń múni kórìíra, kò dára. (Kól. 3:8; Ják. 1:20) Wọ́n lè ba àjọṣe tó ṣeyebíye tá a ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì àti èyí tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Jésù kọ́ wa pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a lọ ní kíkún fún ìrunú sí arákùnrin rẹ̀ yóò jíhìn fún kóòtù ìgbẹ́jọ́; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ ìfojú-tín-ín-rín tí kò ṣeé fẹnu sọ sí arákùnrin rẹ̀ yóò jíhìn fún Kóòtù Gíga Jù Lọ; nígbà tí ó jẹ́ pé, ẹnì yòówù tí ó bá wí pé, ‘Ìwọ òmùgọ̀ òkúùgbẹ́!’ yóò yẹ fún Gẹ̀hẹ́nà oníná.”—Mát. 5:22.

8. Ìgbà wo ló yẹ ká sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wa, ọ̀nà wo ló sì yẹ ká gbà sọ ọ́?

8 Àmọ́ ṣá o, àwọn ohun kan wà tá a lè rí i pé ó pọn dandan ká sọ̀rọ̀ lé lórí. Bí ohun tí arákùnrin kan sọ tàbí ohun tó ṣe bá dùn ẹ́ débi pé o kò lè gbójú fò ó dá, má ṣe jẹ́ kí ìkórìíra fún irú arákùnrin bẹ́ẹ̀ máa pọ̀ sí i lọ́kàn rẹ. (Òwe 19:11) Bí ẹnì kan bá ṣe ohun tó dùn ẹ́, ṣàkóso ìmọ̀lára rẹ, lẹ́yìn náà ni kó o wá gbé ìgbésẹ̀ tó bá pọn dandan láti yanjú ọ̀ràn náà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.” Torí pé ọ̀rọ̀ náà kò kúrò lọ́kàn rẹ bọ̀rọ̀, fi pẹ̀lẹ́tù bójú tó o ní àkókò tó yẹ. (Ka Éfésù 4:26, 27, 31, 32.) Bá arákùnrin rẹ sọ ọ̀rọ̀ náà láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n, àmọ́ kó o lo ohùn tútù, kí àárín yín lè pa dà gún.—Léf. 19:17; Mát. 18:15.

9. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣàkóso ìmọ̀lára wa ká tó lọ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?

9 Àmọ́ ṣá o, o gbọ́dọ̀ wá àkókò tó dáa láti bójú tó ọ̀ràn náà. Torí pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníw. 3:1, 7) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, “ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.” (Òwe 15:28) Èyí tó túmọ̀ sí pé ó lè gba pé kéèyàn dúró di àkókò kan kó tó sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro náà. Bí ìjíròrò náà bá wáyé nígbà tí inú ń bíni, ó lè mú kí ọ̀rọ̀ náà burú sí i; àmọ́ kò tún dáa kó pẹ́ jù.

Ìwà Rere Máa Ń Mú Kí Àjọṣe Àwọn Èèyàn Sunwọ̀n sí I

10. Báwo ni híhùwà rere ṣe lè mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì sunwọ̀n sí i?

10 Ọ̀rọ̀ tútù àti ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán lè mú ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn, kí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ sì tọ́jọ́. Ká sòótọ́, bá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú kí àjọse wa pẹ̀lú àwọn míì sunwọ̀n sí i, ìyẹn lè mú kó túbọ̀ rọrùn láti bá wọn sọ̀rọ̀. Bá a bá ń lo ìdánúṣe láti ṣe ohun rere fáwọn èèyàn látọkàn wá, bíi ká ràn wọ́n lọ́wọ́, ká fínnú fíndọ̀ fún wọn ní ẹ̀bùn, ká sì fi ìwà ọ̀làwọ́ hàn sí wọn, ìyẹn lè mú ká máa bára wa sọ̀rọ̀ fàlàlà. Ó sì tún lè “kó òkìtì ẹyín iná” léni lórí, èyí ni pé kó mú àwọn ànímọ́ tó dára jù lọ jáde, kó sì wá túbọ̀ rọrùn láti yanjú àwọn ìṣòro tó bá wáyé.—Róòmù 12:20, 21.

11. Báwo ni Jékọ́bù ṣe lo ìdánúṣe kó lè pa dà bá Ísọ̀ rẹ́, ibo lọ̀rọ̀ náà sì yọrí sí?

11 Jékọ́bù baba ńlá mọ̀ pé ohun tó yẹ kéèyàn ṣe gan-an nìyẹn. Ísọ̀ bínú gan-an sí Jékọ́bù tó jẹ́ ìbejì rẹ̀; Jékọ́bù sì ní láti sá lọ kí Ísọ̀ má bàa pa á. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, Jékọ́bù pa dà wálé. Ísọ̀ wá pàdé rẹ̀ tòun ti irínwó [400] ọkùnrin. Jékọ́bù gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà ló rán àwọn èèyàn ṣáájú pé kí wọ́n lọ kó ẹ̀bùn onírúurú ẹran ọ̀sìn fún Ísọ̀. Ẹ̀bùn náà ṣe iṣẹ́ tí Jékọ́bù torí rẹ̀ kó wọn ránṣẹ́. Nígbà tí wọ́n fi máa fojú kojú, ọkàn Ísọ̀ ti yọ́, ó sáré wá bá Jékọ́bù, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.—Jẹ́n. 27:41-44; 32:6, 11, 13-15; 33:4, 10.

Máa Fi Ọ̀rọ̀ Tútù Gba Àwọn Míì Níyànjú

12. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tuni lára?

12 Ọlọ́run ni àwa Kristẹni ń sìn kì í ṣe ẹ̀dá èèyàn. Síbẹ̀, a máa ń fẹ́ kí àwọn ẹlòmíì gba tiwa. Bá a bá ń sọ̀rọ̀ tútù, ó lè mú kí ara tu àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Àmọ́, bá a bá ń rí sí wọn lọ́nà tó le koko, a lè pa kún ìnira wọn ká sì jẹ́ káwọn kan máa rò pé àwọn ti pàdánù ojú rere Jèhófà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi tọkàntọkàn gba àwọn míì níyànjú, ká máa sọ “àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.”—Éfé. 4:29.

13. Kí ló yẹ káwọn alàgbà fi sọ́kàn (a) nígbà tí wọ́n bá ń gbani nímọ̀ràn? (b) nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kọ lẹ́tà?

13 Ní pàtàkì jù lọ, ó yẹ kí àwọn alàgbà jẹ́ ẹni “pẹ̀lẹ́” kí wọ́n sì máa fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ bójú tó agbo. (1 Tẹs. 2:7, 8) Bí àwọn alàgbà bá ní láti fúnni ní ìmọ̀ràn, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ àfojúsùn wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ “pẹ̀lú ìwà tútù,” kódà bó bá jẹ́ pé àwọn “tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere,” ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀. (2 Tím. 2:24, 25) Ó tún yẹ kí àwọn alàgbà máa sọ̀rọ̀ tútù nígbà tó bá pọn dandan pé kí wọ́n kọ lẹ́tà sí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ mìíràn tàbí sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Mátíù 7:12, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ onínúure àti ẹni tó ń fòye báni lò.

Sísọ Ọ̀rọ̀ Tútù Nínú Ìdílé

14. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn ọkọ, kí ló sì mú kó ṣe bẹ́ẹ̀?

14 A lè má tètè kíyè sí i pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa, ìwò ojú wa àti ìṣesí wa máa ń nípa gan-an lórí àwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọkùnrin kan lè ṣàì mọ bí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ṣe máa ń rí lára àwọn obìnrin. Arábìnrin kan sọ pé, “Ẹ̀rù máa ń bà mí bí ọkọ mi bá fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí mi.” Ohùn líle máa ń já obìnrin láyà ju ọkùnrin lọ, wọn kì í sì í gbàgbé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ bọ̀rọ̀. (Lúùkù 2:19) Àgàgà tó bá jẹ́ pé ẹni tí obìnrin náà nífẹ̀ẹ́ tó sì fẹ́ láti máa bọ̀wọ̀ fún ló sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù fún àwọn ọkọ nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.”—Kól. 3:19.

15. Fúnni ní àpẹẹrẹ ìdí tí ọkọ fi gbọ́dọ̀ máa fọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú aya rẹ̀.

15 Látàrí èyí, baálé ilé kan tó ti ṣègbéyàwó tipẹ́ fúnni ní àpẹẹrẹ ìdí tí ọkọ fi gbọ́dọ̀ máa fi ìwà pẹ̀lẹ́ bójú tó aya rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí “ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera.” Ó sọ pé: “Bí o bá gbé orù òdòdó kan tó jẹ́ ẹlẹgẹ́ dání, o gbọ́dọ̀ dì í mú dáadáa kó má bàa gbá nǹkan kó sì sán. Torí pé bó bá sán tó o sì tún un ṣe, ibi tó sán náà kò ní pa rẹ́. Bí ọkọ bá ń sọ ọ̀rọ̀ tó le koko jù sí aya rẹ̀, ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá a, ìyẹn sì lè ba àjọṣe wọn jẹ́.”—Ka 1 Pétérù 3:7.

16. Báwo ni aya ṣe lè gbé ìdílé rẹ̀ ró?

16 Ọ̀rọ̀ táwọn míì bá sọ lè gbé àwọn ọkùnrin ró pẹ̀lú, ó sì lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn, kódà bó bá jẹ́ pé aya wọn ló sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. “Aya olóye,” tí ọkàn-àyà olúwa rẹ̀ “gbẹ́kẹ̀ lé,” máa ń gba èrò ọkọ rẹ̀ rò, bí òun náà ṣe ń fẹ́ kó máa gba tòun rò. (Òwe 19:14; 31:11) Kódà, aya lè ní ipa tó pọ̀ lórí ìdílé, yálà sí rere tàbí sí búburú. “Obìnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti tòótọ́ ti kọ́ ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ òmùgọ̀ a fi ọwọ́ ara rẹ̀ ya á lulẹ̀.”—Òwe 14:1.

17. (a) Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn ọmọ máa bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn àgbà máa bá àwọn ọmọdé sọ̀rọ̀, kí sì nìdí?

17 Ó yẹ kí àwọn òbí àtàwọn ọmọ máa bára wọn sọ̀rọ̀ tútù. (Mát. 15:4) Ríro àròjinlẹ̀ tá a bá ń bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ máa ràn wá lọ́wọ́ tí a kò fi ní máa ‘dá wọn lágara’ tàbí ká ‘mú inú bí wọn.’ (Kól. 3:21; Éfé. 6:4) Kódà, bí àwọn òbí àtàwọn alàgbà bá ní láti bá àwọn ọmọdé wí, ó ṣì yẹ kí wọ́n bá wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Nípa báyìí, àwọn àgbà máa mú kó rọrùn fáwọn ọmọdé láti mú ọ̀nà wọn tọ́ kí ohunkóhun má sì ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Ìyẹn á dáa gan-an ju kí wọ́n jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ náà sú àwọn, èyí tó lè mú káwọn ọmọ náà máa ronú pé ọ̀rọ̀ àwọn ti kọjá àtúnṣe. Àwọn ọmọdé lè ṣàì rántí gbogbo ìmọ̀ràn tí wọ́n ti rí gbà, ṣùgbọ́n wọ́n máa rántí ọ̀nà táwọn míì gbà bá wọn sọ̀rọ̀.

Sísọ Àwọn Ohun Tó Dára Látinú Ọkàn Wá

18. Báwo la ṣe lè mú èrò tí kò tọ́ àti ohun tó ń dunni kúrò lọ́kàn?

18 Fífiyè dénú nígbà tí inú bá ń bíni kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn pé kí ojú ẹni tutù pẹ̀sẹ̀. Kò yẹ kí àfojúsùn wa mọ sórí pípa ìbínú yẹn mọ́ra. Bá a bá ń gbìyànjú láti ṣe ojú fúrú bíi pé kò sí nǹkan, àmọ́ tí ìbínú ń ru gùdù nínú wa, a máa kó ìdààmú ọkàn bá ara wa. Ńṣe ló máa dà bí ìgbà téèyàn tẹ ìjánu ọkọ̀ àti ohun èlò ìtẹná ọkọ̀ pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Ńṣe ni ẹ́ńjìnnì ọkọ náà á máa pariwo, ó sì lè bà jẹ́. Torí náà, má ṣe fi ìbínú sínú, débi tó fi máa bú gbàù tó bá yá. Máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mú èrò tó lè ṣèpalára kúrò lọ́kàn rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀mí Jèhófà yí èrò àti ọkàn rẹ pa dà kó o lè máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.—Ka Róòmù 12:2; Éfésù 4:23, 24.

19. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún fífi ìbínú hàn?

19 Gbé ìgbésẹ̀ tó bọ́gbọ́n mu. Bó o bá bá ara rẹ nínú ipò tó le koko, tó o sì rí i pé inú ti fẹ́ máa bí ẹ, ó máa dára kó o kúrò ní sàkáání ibẹ̀, kí ọkàn rẹ lè rọlẹ̀ pẹ̀sẹ̀. (Òwe 17:14) Bí inú bá fẹ́ máa bí ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀, sapá láti sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tuni lára. Rántí pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Kódà, bí a bá fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀ ìbínú tàbí tá a jágbe mọ́ni, ńṣe ló máa dà bí ìgbà téèyàn bu bẹtiróò sínú iná. (Òwe 26:21) Torí náà, bí ohun kan bá ṣẹlẹ̀ tó gba pé kó o lo ìkóra-ẹni-níjàánu, ńṣe ni kó o “lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ” kó o sì “lọ́ra nípa ìrunú.” Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fi ẹ̀mí rẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa sọ àwọn ohun tó dára, kì í ṣe ohun tó burú.—Ják. 1:19.

Máa Dárí Jini Látọkàn Wá

20, 21. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa dárí ji àwọn míì, kí sì nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀?

20 Ó bani nínú jẹ́ pé, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó lè kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu lọ́nà pípé. (Ják. 3:2) Bí àwọn tó jẹ́ ara ìdílé wa àti àwọn ará wa ọ̀wọ́n nínú ìjọ ṣe ń sapá tó, ìgbà míì ṣì wà tí wọ́n á sọ ọ̀rọ̀ tó lè múni bínú. Dípò tá a ó fi tètè jẹ́ kí inú bí wa, ó máa dára ká kọ́kọ́ gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò ká lè mọ ohun tó mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Oníwàásù 7:8, 9.) Ṣé wọ́n dojú kọ ìṣòro kan ni, àbí ẹ̀rù ń bà wọ́n, bóyá ara wọn kò le, tàbí kó jẹ́ pé ìṣòrò kan ń bá wọn fínra?

21 Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan yìí tó yẹ kéèyàn torí ẹ̀ fa ìbínú yọ. Àmọ́, bá a ṣe mọ̀ pé wọ́n lè ṣẹlẹ̀ máa mú ká lóye ìdí rẹ̀ táwọn èèyàn fi máa ń sọ irú ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ, tàbí hu irú ìwà tí wọ́n hù nígbà míì, ìyẹn á sì jẹ́ ká lè dárí jì wọ́n. Gbogbo wa náà la ti ṣẹ àwọn ẹlòmíì rí, yálà nínú ìwà tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wa, tá a sì retí pé kí wọ́n dárí jì wá. (Oníw. 7:21, 22) Jésù sọ pé bí a bá fẹ́ kí Ọlọ́run máa dárí jì wá, àwa náà gbọ́dọ̀ máa dárí ji àwọn ẹlòmíì. (Mát. 6:14, 15; 18:21, 22, 35) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa tètè tọrọ àforíjì, kí àwa náà máa tètè dárí jini, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ìfẹ́, tí í ṣe “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé,” máa wà nìṣó láàárín ìdílé àti nínú ìjọ.—Kól. 3:14.

22. Kí nìdí tó fi tọ́ tó sì yẹ ká máa sapá láti sọ ọ̀rọ̀ tútù?

22 Bí ètò ìsinsìnyí tó kún fún ìbínú ti ń sún mọ́ òpin rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó túbọ̀ ṣòro fún wa láti máa láyọ̀ ká sì máa wà ní ìṣọ̀kan. Bá a bá ń fi àwọn ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, ó máa jẹ́ ká lè máa lo ahọ́n wa lọ́nà tó tọ́, kì í ṣe lọ́nà tí kò tọ́. A ó lè túbọ̀ máa bára wa gbé ní àlàáfíà nínú ìjọ àti nínú ìdílé, àpẹẹrẹ wa á sì jẹ́ ẹ̀rí tó tayọ lọ́lá fáwọn ẹlòmíì pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀.”—1 Tím. 1:11.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti wá àkókò tó yẹ láti jíròrò àwọn ìṣòro tó bá wáyé?

• Kí nìdí tó fi yẹ kí ọ̀rọ̀ àwọn tó jẹ́ ara ìdílé kan náà máa jẹ́ “pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́”?

• Báwo la ṣe lè yẹra fún sísọ àwọn ohun tó lè kó ẹ̀dùn ọkàn báni?

• Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa dárí jini?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Jẹ́ kí ọkàn rẹ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, lẹ́yìn náà ni kó o wá àkókò tó yẹ láti sọ̀rọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìgbà gbogbo ló yẹ kí ọkọ máa bá aya rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́