Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Gbé Ìjọ Ró

Ẹ Máa Gbé Ìjọ Ró

Ẹ Máa Gbé Ìjọ Ró

“Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yin ró lẹ́nì kìíní-kejì.”—1 TẸS. 5:11.

1. Àwọn ìbùkún wo là ń rí gbà bá a ṣe wà nínú ìjọ Kristẹni, àmọ́ àwọn ìṣòro wo ló tún ṣeé ṣe ká ní?

 ÌBÙKÚN ńlá ló jẹ́ láti wà nínú ìjọ Kristẹni. Ó mú kó o ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Bó o ṣe fọkàn tán Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń dáàbò bò ẹ́ lọ́wọ́ àbájáde búburú tó máa ń wá látinú gbígbé ìgbé ayé tí kò bá ìlànà Bíbélì mu. Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tó fẹ́ kó o ṣe àṣeyọrí ló yí ẹ ká. Ká sòótọ́, àwọn ìbùkún náà kò lóǹkà. Àmọ́, ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ń bá onírúurú ìṣòro yí. Àwọn kan lára wọn lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti lóye àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run. Àìsàn àti ẹ̀dùn ọkàn ni àwọn míì ń bá yí, àwọn míì sì ń jìyà àbájáde ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn fà. Gbogbo wa la sì ń gbé nínú ayé tí àwọn èèyàn kò ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.

2. Kí ló yẹ ká ṣe nípa ìṣòro tí àwọn arákùnrin wa ń bá yí, kí sì nìdí?

2 Kò sí ẹni tó wù nínú wa pé kí àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni máa jìyà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìjọ wé ara èèyàn, ó sì sọ pé: “Bí ẹ̀yà ara kan bá sì ń jìyà, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a jìyà.” (1 Kọ́r. 12:12, 26) Ó yẹ ká sapá láti ran àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa tó bá wà nírú ipò yìí lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ ló wà nínú Ìwé Mímọ́ níbi tí àwọn ará ìjọ ti ran ara wọn lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro, kí wọ́n sì borí rẹ̀. Bá a ṣe ń gbé àwọn ìtàn yẹn yẹ̀ wò, ronú nípa bó o ṣe lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ bí wọ́n ti ṣe. Báwo lo ṣe lè ran àwọn arákùnrin rẹ lọ́wọ́ kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run lè dára, kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ gbé ìjọ Jèhófà ró?

“Wọ́n Mú Un Wọ Àwùjọ Ẹgbẹ́ Wọn”

3, 4. Ọ̀nà wo ni Ákúílà àti Pírísílà gbà ran Àpólò lọ́wọ́?

3 Ajíhìnrere onítara ni Àpólò nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìlú Éfésù. Àkọsílẹ̀ ìwé Ìṣe fi hàn pé “bí iná ẹ̀mí ti ń jó nínú rẹ̀, ó ń sọ̀rọ̀, ó sì ń fi àwọn nǹkan nípa Jésù kọ́ni pẹ̀lú ìpérẹ́gí, ṣùgbọ́n ìbatisí Jòhánù nìkan ni ó mọ̀.” Níwọ̀n bí Àpólò kò ti mọ̀ nípa ìbatisí ní “orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù Arinibọmi ló wàásù fún un tàbí kó jẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó ti wà ṣáájú ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Àpólò ní ìtara, ọ̀pọ̀ nǹkan ni kò tíì mọ̀. Báwo ni àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ṣe ràn án lọ́wọ́?—Ìṣe 1:4, 5; 18:25; Mát. 28:19.

4 Àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni, tórúkọ wọn ń jẹ́ Ákúílà àti Pírísílà gbọ́ tí Àpólò ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù, wọ́n mú un wọ àwùjọ ẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì túbọ̀ kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. (Ka Ìṣe 18:24-26.) Ohun tó dára gan-an ni wọ́n ṣe yìí. Ó ṣe kedere pé, ńṣe ni Ákúílà àti Pírísílà á rọra fọgbọ́n bá Àpólò sọ̀rọ̀ lọ́nà táá ràn án lọ́wọ́, tí wọn ò sì ní jẹ́ kó dà bíi pé ńṣe làwọn ń ṣe àríwísí rẹ̀. Kò kàn mọ ìtàn nípa bí ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe bẹ̀rẹ̀ ni. Kò sì sí iyè méjì pé Àpólò mọrírì bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tuntun ṣe fún un ní àwọn ìsọfúnni pàtàkì yìí. Pẹ̀lú ohun tí Àpólò ti wá mọ̀ yìí, ó “ṣe ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà” fún àwọn ará tó wà ní Ákáyà, ó sì jẹ́rìí fún wọn lọ́nà tó lágbára.—Ìṣe 18:27, 28.

5. Ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ wo ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ń ṣe, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

5 Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni lónìí ló máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn tó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ti di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé, kéèyàn tó lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó gba pé kí èèyàn máa bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀ déédéé fún ọ̀pọ̀ oṣù. Àmọ́, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run múra tán láti ṣe ohun tó bá gbà torí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ìyè àti ikú ni. (Jòh. 17:3) Ó sì máa ń mú wa láyọ̀ láti rí bí àwọn èèyàn ṣe ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́, tí wọ́n ń fi òtítọ́ ṣèwà hù, tí wọ́n sì ń gbé ìgbé ayé wọn lọ́nà tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu!

‘Wọ́n Ròyìn Rẹ̀ Dáadáa’

6, 7. (a) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi yan Tímótì pé kó bá òun rìnrìn-àjò? (b) Ìtẹ̀síwájú wo ni èyí mú kí Tímótì ní?

6 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Sílà ṣèbẹ̀wò sí Lísírà nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì wọn kejì, wọ́n rí ọ̀dọ́ kan níbẹ̀ tó ń jẹ́ Tímótì, tó ṣeé ṣe kó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún ọdún nígbà yẹn. “Àwọn ará ní Lísírà àti Íkóníónì sì ròyìn rẹ̀ dáadáa.” Kristẹni tó ti ṣèyàsímímọ́ ni Yùníìsì ìyá Tímótì àti Lọ́ìsì ìyá ìyá rẹ̀, àmọ́ aláìgbàgbọ́ ni bàbá rẹ̀. (2 Tím. 1:5) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ṣe ìbẹ̀wò sí àgbègbè yìí ní ọdún mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn ló ti mọ ìdílé náà. Àmọ́ ní báyìí Pọ́ọ̀lù wá pe àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí Tímótì torí ó jọ pé ọ̀dọ́kùnrin tó ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ ni. Torí náà, Tímótì di olùrànlọ́wọ́ Pọ́ọ̀lù lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì, nígbà tí àwọn alàgbà ìjọ rẹ̀ fọwọ́ sí i.—Ka Ìṣe 16:1-3.

7 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Tímótì máa rí kọ́ lára ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ àgbàlagbà yìí. Ó sì rí nǹkan kọ́ débi pé, ọkàn Pọ́ọ̀lù balẹ̀ láti rán an pé kó lọ máa bẹ àwọn ìjọ wò gẹ́gẹ́ bí aṣojú òun. Fún nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí Tímótì fi bá Pọ́ọ̀lù rìn, Tímótì tí kò ní ìrírí tó sì tún jẹ́ onítìjú èèyàn tẹ̀ síwájú débi pé ó di alábòójútó tó dáńgájíá.—Fílí. 2:19-22; 1 Tím. 1:3.

8, 9. Kí ni àwọn ará ìjọ lè ṣe láti fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan.

8 Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wà nínú ìjọ ló ní ẹ̀bùn tó dára gan-an. Tí àwọn tó dàgbà nípa tẹ̀mí bá fún wọn ní ìṣírí tí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà, àwọn ọ̀dọ́ yìí lè sapá kí ọwọ́ wọn lè tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó pọ̀ sí i láàárín àwọn èèyàn Jèhófà. Ronú nípa ìjọ rẹ! Ǹjẹ́ o rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n lè yọ̀ǹda ara wọn bí Tímótì ti ṣe? Bó o bá ràn wọ́n lọ́wọ́, tó o sì fún wọn ní ìṣírí, wọ́n lè di aṣáájú-ọ̀nà, òṣìṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, míṣọ́nnárì tàbí alábòójútó arìnrìn-àjò. Kí lo lè ṣe láti ran àwọn ọ̀dọ́ yìí lọ́wọ́ láti wá àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí?

9 Martin tó ti jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì fún ogún ọdún mọrírì bí alábòójútó àyíká kan ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ òun jẹ ẹ́ lọ́kàn, ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn nígbà tí àwọn méjèèjì wà lóde ẹ̀rí. Alábòójútó àyíká náà fi ìdùnnú sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Ó fún Martin ní ìṣírí pé kó ronú nípa rẹ̀ bóyá á ṣeé ṣe fún un láti yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún ètò Jèhófà ní irú ọ̀nà yẹn. Martin gbà pé ọ̀rọ̀ tó bá òun sọ yẹn kò kúrò lọ́kàn òun títí, ó sì wà lára ohun tó mú kí òun ṣe àwọn ìpinnu tí òun ṣe lẹ́yìn náà. Ta ló sì mọ oore tó o lè ṣe fún àwọn ọ̀dọ́ yìí tó o bá bá wọn sọ̀rọ̀ nípa lílépa àwọn nǹkan tẹ̀mí.

“Ẹ Máa Sọ̀rọ̀ Ìtùnú fún Àwọn Ọkàn Tí Ó Soríkọ́”

10. Báwo lọ̀rọ̀ ṣe rí lára Ẹpafíródítù, kí sì nìdí?

10 Ẹpafíródítù rin ìrìn-àjò tó jìn tó sì ń tánni lókun láti ìlú Fílípì lọ sí ìlú Róòmù kó lè lọ wo àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó lọ síbẹ̀ láti lọ ṣojú fún àwọn ará tó wà ní ìlú Fílípì. Kì í ṣe pé ó kàn lọ fi ẹ̀bùn àwọn ará Fílípì jíṣẹ́ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nìkan ni, ó tún ní in lọ́kàn láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́ nínú ipò lílekoko tó wà. Àmọ́, nígbà tí Ẹpafíródítù wà ní Róòmù, ó ṣàìsàn “títí ó fi fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ojú ikú.” Ẹpafíródítù wá soríkọ́, torí pé kò lè ṣe ohun tó gbé e wá síbẹ̀.—Fílí. 2:25-27.

11. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu tí àwọn kan nínú ìjọ bá soríkọ́? (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù dábàá lórí ọ̀ràn Ẹpafíródítù?

11 Onírúurú pákáǹleke ló lè mú kí àwọn èèyàn soríkọ́ lónìí. Ìṣirò tí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe fi hàn pé nínú èèyàn márùn-ún, ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan ní ìsoríkọ́ láàárín àkókò kan nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà kò sì yọ àwọn èèyàn Jèhófà sílẹ̀. Ìṣòro pípèsè ohun tí ìdílé nílò, àìlera, ìrẹ̀wẹ̀sì nítorí ìkùdíẹ̀–káàtó èèyàn, tàbí àwọn nǹkan míì lè mú kí èèyàn soríkọ́. Kí làwọn ará Fílípì lè ṣe láti ran Ẹpafíródítù lọ́wọ́? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí àṣà nínú Olúwa pẹ̀lú ìdùnnú gbogbo; ẹ sì máa ka irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n, nítorí pé ní tìtorí iṣẹ́ Olúwa ni ó fi sún mọ́ bèbè ikú, ó fi ọkàn rẹ̀ wewu, kí òun ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lè dí àlàfo àìsí níhìn-ín yín láti ṣe iṣẹ́ ìsìn ti ara ẹni fún mi.”—Fílí. 2:29, 30.

12. Kí ló lè fún àwọn tó soríkọ́ ní ìtùnú?

12 Ó yẹ kí àwa náà máa fún àwọn ará tó bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí wọ́n soríkọ́ ní ìṣírí. Kò sí iyè méjì pé ọ̀pọ̀ nǹkan rere ló wà tá a lè sọ nípa iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà. Wọ́n lè ti ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé wọn kí wọ́n tó di Kristẹni tàbí kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. A mọrírì àwọn ìsapá yìí, a sì lè mú un dá wọn lójú pé Jèhófà náà mọrírì rẹ̀. Tí ọjọ́ ogbó tàbí àìlera ò bá jẹ́ káwọn olóòótọ́ kan lè ṣe tó bí wọ́n ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, ó tọ ká máa bọ̀wọ̀ fún wọn torí ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ìṣòro yòówù kí wọ́n máa dojú kọ, Jèhófà gba gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tẹs. 5:14.

“Ẹ Fi Inú Rere Dárí Jì Í, Kí Ẹ sì Tù Ú Nínú”

13, 14. (a) Ìgbésẹ̀ tó lágbára wo ni àwọn ará Kọ́ríńtì gbé, kí sì nìdí? (b) Kí ni ìgbésẹ̀ ìyọlẹ́gbẹ́ máa ń yọrí sí?

13 Ìjọ Kọ́ríńtì ọ̀rúndún kìíní dojú kọ ọ̀ràn kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ọkùnrin kan tó ń ṣe àgbèrè tí kò sì ronú pìwà dà. Ìwà rẹ̀ ń ṣàkóbá fún ìjẹ́mímọ́ ìjọ, kódà àwọn aláìgbàgbọ́ máa ń kẹ́gàn ẹni tó bá ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀. Torí náà, ó tọ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ pé kí wọ́n mú ọkùnrin náà kúrò nínú ìjọ.—1 Kọ́r. 5:1, 7, 11-13.

14 Ìbáwí tí wọ́n fún un yìí so èso rere. Ó dáàbò bo ìjọ lọ́wọ́ ohun tó lè sọ ọ́ dìbàjẹ́, ó mú kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà pe orí ara rẹ̀ wálé, kó sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Torí pé ọkùnrin náà ṣe ohun tó fi hàn pé ó ti ronú pìwà dà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí ìjọ Kọ́ríńtì, ó sọ pé kí wọ́n gba ọkùnrin náà pa dà. Àmọ́ kì í ṣe kìkì ohun tá a béèrè nìyẹn o. Pọ́ọ̀lù tún sọ fún ìjọ náà pé: “Kí ẹ fi inú rere dárí jì í [ìyẹn, ẹlẹ́sẹ̀ tó ronú pìwà dà náà], kí ẹ sì tù ú nínú, pé lọ́nà kan ṣáá, kí ìbànújẹ́ rẹ̀ tí ó pàpọ̀jù má bàa gbé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ mì.”—Ka 2 Kọ́ríńtì 2:5-8.

15. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, tá a sì gbà pa dà sínú ìjọ?

15 Kí la rí kọ́ látinú àkọsílẹ̀ yìí? Ó máa ń dùn wá tó bá di pé wọ́n yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́. Wọ́n lè ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì ti tàbùkù sí ìjọ. Kódà wọ́n lè ti ṣẹ àwa fúnra wa. Síbẹ̀, tí àwọn alàgbà tí wọ́n yàn láti bójú tó ọ̀ràn náà bá ti bójú tó o lọ́nà tó bá ìtọ́ni Jèhófà mu, tí wọ́n sì rí i pé ó yẹ kí àwọn gba ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà náà pa dà sínú ìjọ, ńṣe ni ìyẹn ń fi hàn pé Jèhófà ti darí ji onítọ̀hún. (Mát. 18:17-20) Ṣé kò wá yẹ kí àwa náà fẹ́ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà? Ká sòótọ́, tá a bá le koko mọ́ ọn, tí a kò sì dárí jì í, ohun tó túmọ̀ sí ni pé à ń tako Jèhófà. Ká lè ṣe àlékún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ Ọlọ́run, ká sì rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà, ṣé kò yẹ ká ‘fìdí ìfẹ́ wa múlẹ̀’ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tá a sì gbà pa dà?—Mát. 6:14, 15; Lúùkù 15:7.

“Ó Wúlò fún Mi”

16. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi gbà pé Máàkù já òun kulẹ̀?

16 Àkọsílẹ̀ míì nínú Ìwé Mímọ́ fi hàn pé a kò gbọ́dọ̀ máa gbin èrò tí kò dáa sọ́kàn nípa àwọn tó bá já wa kulẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù Máàkù já àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kulẹ̀, ó sì dun Pọ́ọ̀lù gan-an pé ó ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́nà wo? Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò míṣọ́nnárì wọn àkọ́kọ́, Máàkù bá wọn lọ kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́, Jòhánù Máàkù fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n tó parí ìrìn-àjò náà, a kò sì mọ ohun tó fà á. Ìpinnu tí Máàkù ṣe yìí dun Pọ́ọ̀lù gan-an débi pé nígbà tí wọ́n ń múra ìrìn-àjò míṣọ́nnárì wọn kejì, òun àti Bánábà ní èdèkòyédè lórí bóyá kí Máàkù tún bá wọn lọ. Torí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìrìn-àjò wọn àkọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù kò fẹ́ kí Máàkù bá àwọn rìnrìn-àjò.—Ka Ìṣe 13:1-5, 13; 15:37, 38.

17, 18. Báwo la ṣe mọ̀ pé èdèkòyédè tó wà láàárín Pọ́ọ̀lù àti Máàkù yanjú, kí la sì lè rí kọ́ látinú èyí?

17 Ó ṣe kedere pé, Máàkù kò jẹ́ kí kíkọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ òun kó ìrẹ̀wẹ̀sì tó pọ̀ jù bá òun, torí ó ń bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀ lọ ní ìpínlẹ̀ míì pẹ̀lú Bánábà. (Ìṣe 15:39) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ nípa Máàkù ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà fi hàn pé ó dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ àti ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù, ó kọ̀wé sí Tímótì pé kó wá. Nínú lẹ́tà yẹn Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mú Máàkù, kí o sì mú un wá pẹ̀lú rẹ, nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́.” (2 Tím. 4:11) Bẹ́ẹ̀ ni o, Pọ́ọ̀lù ti wá gbà báyìí pé Máàkù ti tẹ̀ síwájú.

18 A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú èyí pẹ̀lú. Máàkù ti ní àwọn ànímọ́ tó yẹ kí míṣọ́nnárì rere ní. Kò jẹ́ kí kíkọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ òun lákọ̀ọ́kọ́ yẹn mú òun kọsẹ̀. Ẹni tẹ̀mí ni Máàkù àti Pọ́ọ̀lù, kò sì sí ìkùnsínú tó wà pẹ́ títí láàárín wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù mọyì ìrànlọ́wọ́ tí Máàkù ṣe fún un lẹ́yìn náà. Torí náà, tí àwọn ará bá borí ìṣòro kan tí ìṣòro náà sì ti tán nílẹ̀, ohun tó tọ́ ni pé kí wọ́n máa bá àjọṣe wọn lọ, kí wọ́n sì máa ran àwọn míì lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́. Mímọyì ànímọ́ táwọn míì ní máa ń gbé ìjọ ró.

Ojú Tó Yẹ Kó O Máa Fi Wo Ìjọ

19. Ìrànlọ́wọ́ wo ni gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni lè ṣe fún ara wọn?

19 Ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí, o nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú ìjọ, wọ́n sì nílò ìrànlọ́wọ́ tìrẹ náà. (2 Tím. 3:1) Àwọn Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè má mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láti bójú tó ìṣòro tó bá jẹ yọ kí wọ́n sì borí rẹ̀, àmọ́ Jèhófà mọ̀ ọ́n. Ó sì lè lo ẹnikẹ́ni nínú ìjọ títí kan ìwọ náà láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti tọ ọ̀nà tó tọ́. (Aísá. 30:20, 21; 32:1, 2) Torí náà, ẹ máa fi ọ̀rọ̀ ìyànjú tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni sọ́kàn! Ó sọ pé: “Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yin ró lẹ́nì kìíní-kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe ní tòótọ.”—1 Tẹs. 5:11.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbé ara wa ró nínú ìjọ Kristẹni?

• Irú àwọn ìṣòro wo lo lè ran àwọn míì lọ́wọ́ láti borí?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ran àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ lọ́wọ́?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Bí ẹni tá a jọ jẹ́ Kristẹni bá ń bá ìṣòro kan yí, a lè ràn án lọ́wọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ Kristẹni lóde òní ló ní ẹ̀bùn tó dáa