Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá a Ṣe Lè Rí Ìtura Nínú Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí

Bá a Ṣe Lè Rí Ìtura Nínú Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí

Bá a Ṣe Lè Rí Ìtura Nínú Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí

“Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín . . . , ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.” —MÁT. 11:29.

1. Ètò wo ni Ọlọ́run ṣe ní Òkè Sínáì, kí sì nìdí?

 NÍGBÀ tí Ọlọ́run fi májẹ̀mú Òfin lélẹ̀ ní Òkè Sínáì, pípa Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mọ́ wà lára ètò tó ṣe. Jèhófà tipasẹ̀ Mósè tó jẹ́ agbẹnusọ rẹ̀ pàṣẹ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò máa fi ṣe iṣẹ́ rẹ; ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje, kí ìwọ ṣíwọ́, kí akọ màlúù rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ lè sinmi, kí ọmọ ẹrúbìnrin rẹ àti àtìpó sì lè tu ara wọn lára.” (Ẹ́kís. 23:12) Bẹ́ẹ̀ ni o, torí pé Jèhófà gba tàwọn tó wà lábẹ́ Òfin náà rò, ó fìfẹ́ ṣètò ọjọ́ ìsinmi kan kí àwọn èèyàn náà lè “tu ara wọn lára.”

2. Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jàǹfààní látinú pípa Sábáàtì mọ́?

2 Ṣé ọjọ́ fàájì lásán ni ọjọ́ Sábáàtì? Rárá o, apá pàtàkì nínú ìjọsìn Jèhófà ló jẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Pípa Sábáàtì mọ́ á fún àwọn olórí ìdílé láyè láti kọ́ ìdílé wọn láti máa “pa ọ̀nà Jèhófà mọ́ láti ṣe òdodo.” (Jẹ́n. 18:19) Á tún jẹ́ kí àwọn ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ kóra jọ láti ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe, kí wọ́n sì ṣe àjọyọ̀. (Aísá. 58:13, 14) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé Sábáàtì jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi, ìyẹn àkókò tí ìtura tòótọ́ yóò wà. (Róòmù 8:21) Àmọ́ àsìkò tiwa yìí ńkọ́? Ibo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀nà Jèhófà ti lè rí irú ìtura bẹ́ẹ̀, báwo sì ni wọ́n ṣe lè rí i?

O Lè Rí Ìtura Látinú Kíkẹ́gbẹ́ Pẹ̀lú Àwọn Ará

3. Ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbà ti ara wọn lẹ́yìn, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe ìjọ Kristẹni ní “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” (1 Tím. 3:15) Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní rí ìtìlẹ́yìn púpọ̀ látinú bí wọ́n ṣe ń fún ara wọn ní ìṣírí tí wọ́n sì ń gbé ara wọn ró nínú ìfẹ́. (Éfé. 4:11, 12, 16) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní ìlú Éfésù, àwọn ará ìjọ Kọ́ríńtì ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ láti fún un ní ìṣírí. Wo ohun tó jẹ́ àbájáde rẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Mo yọ̀ lórí wíwàníhìn-ín Sítéfánásì àti Fọ́túnátù àti Ákáíkọ́sì, nítorí pé wọ́n ti tu ẹ̀mí mi lára.’ (1 Kọ́r. 16:17, 18) Bákan náà, nígbà tí Títù lọ sí ìlú Kọ́ríńtì láti jíṣẹ́ fún àwọn ará tó wà níbẹ̀, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pa dà sí ìjọ yẹn pé: “Gbogbo yín ti tu ẹ̀mí rẹ̀ lára.” (2 Kọ́r. 7:13) Bákan náà lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń rí ojúlówó ìtura látinú ìbákẹ́gbẹ́ Kristẹni tó ń gbéni ró.

4. Báwo ni àwọn ìpàdé ìjọ ṣe máa ń tù wá lára?

4 Ìwọ fúnra rẹ á ti mọ̀ látinú ìrírí rẹ pé àwọn ìpàdé ìjọ máa ń fúnni láyọ̀ tó pọ̀. Níbẹ̀ a máa ń rí “pàṣípààrọ̀ ìṣírí . . . láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kejì.” (Róòmù 1:12) Àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa kì í ṣe ojúlùmọ̀ lásán, tàbí àwọn ọ̀rẹ́ ojú tá a wulẹ̀ ń bá pàdé lẹ́ẹ̀kan lọ́gbọ̀n. Ọ̀rẹ́ àtàtà ni wọ́n, a nífẹ̀ẹ́ wọn a sì bọ̀wọ̀ fún wọn. A máa ń rí ayọ̀ púpọ̀ àti ìtùnú bá a ṣe ń pé jọ déédéé pẹ̀lú wọn ní àwọn ìpàdé wa.—Fílém. 7.

5. Báwo la ṣe lè máa mú ìtura bá ara wa àtàwọn míì ní àwọn àpéjọ àgbègbè, àyíká àti àkànṣe?

5 A tún máa ń rí ìtura gbà nípasẹ̀ àwọn àpéjọ àgbègbè, àyíká àti àkànṣe, tá à ń ṣe lọ́dọọdún. Yàtọ̀ sí pé àwọn àpéjọ ńlá wọ̀nyí ń pèsè omi òtítọ́ tó ń fúnni ní ìyè látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí í ṣe Bíbélì, ó tún ń fún wa ní àǹfààní láti “gbòòrò síwájú” nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ará. (2 Kọ́r. 6:12, 13) Àmọ́ tá a bá jẹ́ onítìjú èèyàn ńkọ́, tó sì ṣòro fún wa láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀? Ọ̀nà kan tá a lè gbà di ojúlùmọ̀ àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa ni pé ká máa yọ̀ǹda ara wa fún iṣẹ́ nígbà tá a bá lọ sí àpéjọ. Lẹ́yìn tí arábìnrin kan yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ní àpéjọ àgbáyé kan, ó sọ pé: “Yàtọ̀ sí àwọn mọ̀lẹ́bí mi àti àwọn ọ̀rẹ́ díẹ̀, mi ò mọ ọ̀pọ̀ èèyàn níbí. Àmọ́ nígbà tí mo bá ẹ̀ka ìmọ́tótó ṣiṣẹ́, mo pàdé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn arákùnrin àti arábìnrin! Ohun amóríyá gidi ló jẹ́!”

6. Ọ̀nà wo la lè gbà rí ìtura nígbà ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́?

6 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rìnrìn-àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù nígbà mẹ́ta lọ́dún fún àjọyọ̀. (Ẹ́kís. 34:23) Èyí sábà máa ń gba pé kí wọ́n fi oko wọn àti ìsọ̀ wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì fẹsẹ̀ rìnrìn-àjò lórí ọ̀nà eléruku fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Síbẹ̀ lílọ sí tẹ́ńpìlì máa ń yọrí sí “ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà” torí pé àwọn tó pé jọ máa ń “mú ìyìn wá fún Jèhófà.” (2 Kíró. 30:21) Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí máa ń rí i pé tí àwọn àti ìdílé àwọn bá ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì, ìyẹn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè wọn, ó máa ń yọrí sí ayọ̀ ńláǹlà. Ṣé o lè ṣètò irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ fún ìdílé rẹ nígbà tó o bá tún ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́?

7. (a) Báwo ni àpèjẹ ṣe lè ṣàǹfààní? (b) Kí ló lè mú kí àpèjẹ kan jẹ́ mánigbàgbé kó sì gbéni ró?

7 Pípéjọ pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí àti ọ̀rẹ́ fún àpèjẹ tún lè fúnni ní ìṣírí. Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì kéde pé: “Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó máa jẹ kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.” (Oníw. 2:24) Yàtọ̀ sí pé àpèjẹ máa ń mára tuni, ó tún máa ń mú kí ìfẹ́ tó wà láàárín àwa tá a jọ jẹ́ Kristẹni lágbára bá a ṣe túbọ̀ ń mọ ara wa dunjú. Kó o lè mú kí irú àpèjẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ mánigbàgbé kó sì gbéni ró, ó dára kó o jẹ́ kó mọ níwọ̀n, kó o sì rí i pé ẹ bójú tó o dáadáa, ní pàtàkì bí ọtí líle bá máa wà níbẹ̀.

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ń Mára Tuni

8, 9. (a) Sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀rọ̀ Jésù àti ọ̀rọ̀ àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí. (b) Báwo la ṣe ń jàǹfààní nígbà tá a bá sọ òtítọ́ Bíbélì fún àwọn èèyàn?

8 Jésù ní ìtara fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí àwọn náà jẹ́ onítara. Èyí hàn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mát. 9:37, 38) Ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára ni Jésù fi kọ́ni; “ìhìn rere” ló jẹ́. (Mát. 4:23; 24:14) Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ẹrù ìnira tí àwọn Farisí dì ru àwọn èèyàn.—Ka Mátíù 23:4, 23, 24.

9 Nígbà tá a bá ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, ńṣe ni à ń fún wọn ní ìtura nípa tẹ̀mí, lẹ́sẹ̀ kan náà, a tún ń mú kí òtítọ́ Bíbélì tó ṣeyebíye fìdí múlẹ̀ gbọn-in lọ́kàn tiwa náà. Onísáàmù sọ ọ́ lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú pé: “Ẹ yin Jáà, nítorí tí ó dára láti máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run wa; nítorí tí ó dùn mọ́ni.” (Sm. 147:1) Ǹjẹ́ o lè fi kún ayọ̀ tó ò ń ní nínú yíyin Jèhófà lójú àwọn aládùúgbò rẹ?

10. Ǹjẹ́ ìgbà tí àwọn èèyàn bá fetí sí ọ̀rọ̀ wa lóde ẹ̀rí ló fi hàn pé a ṣe àṣeyọrí? Ṣàlàyé.

10 Ó ṣe kedere pé láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù kan àwọn èèyàn máa ń fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa ju bó ṣe máa ń rí lápá ibòmíì. (Ka Ìṣe 18:1, 5-8.) Tó bá jẹ́ àdúgbò tí àwọn èèyàn kì í ti í fẹ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lò ń gbé, ńṣe ni kó o pọkàn pọ̀ sorí ohun rere tí ò ń gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Máa rántí pé ìsapá rẹ láti máa bá a lọ ní pípolongo orúkọ Jèhófà kò ní já sí asán. (1 Kọ́r. 15:58) Síwájú sí i, kì í ṣe bí àwọn èèyàn ṣe ń tẹ́tí sí ìhìn rere la fi ń díwọ̀n àṣeyọrí wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa rí sí i pé àwọn èèyàn tó lọ́kàn títọ́ ní àǹfààní láti tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ Ìjọba náà.—Jòh. 6:44.

Ìjọsìn Ìdílé Máa Ń Mára Tuni

11. Ojúṣe wo ni Jèhófà ti gbé lé àwọn òbí lọ́wọ́, báwo sì ni wọ́n ṣe lè ṣe ojúṣe náà?

11 Ojúṣe àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Jèhófà àti àwọn ọ̀nà rẹ̀. (Diu. 11:18, 19) Tó o bá jẹ́ òbí, ǹjẹ́ o máa ń ṣètò àkókò láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ nípa Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́? Kó o lè bójú tó ojúṣe pàtàkì yìí àti àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìdílé rẹ, Jèhófà ti pèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó ń mára tuni, nípasẹ̀ àwọn ìwé, ìwé ìròyìn, fídíò àtàwọn ọ̀rọ̀ tá a ti gba ohun wọn sílẹ̀.

12, 13. (a) Báwo ni àwọn ìdílé ṣe lè jàǹfààní látinú Ìjọsìn Ìdílé ní ìrọ̀lẹ́? (b) Báwo làwọn òbí ṣe lè rí i dájú pé ìjọsìn ìdílé wọn jẹ́ orísun ìtura?

12 Láfikún sí i, ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ti ṣètò Ìjọsìn Ìdílé ní ìrọ̀lẹ́. Èyí jẹ́ ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ìdílé yà sọ́tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ ti rí i pé ìṣètò yìí ti mú kí àwọn sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí nínú ìfẹ́, ó sì ti mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i. Àmọ́ báwo làwọn òbí ṣe lè rí i dájú pé ìjọsìn ìdílé ń fún àwọn ní ìtura nípa tẹ̀mí?

13 Kò yẹ kí ìjọsìn Ìdílé ní ìrọ̀lẹ́ jẹ́ ohun tó ń súni tàbí èyí tó le koko jù. Ó ṣe tán “Ọlọ́run aláyọ̀” là ń sìn, ó sì fẹ́ ká máa láyọ̀ bá a ṣe ń sin òun. (1 Tím. 1:11; Fílí. 4:4) Ìbùkún gidi ló jẹ́ láti ya ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún jíjíròrò nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa látinú Bíbélì. Kò yẹ kí àwọn òbí le koko nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọ́ni, ó yẹ kí wọ́n máa lo ìfòyemọ̀ àti ìdánúṣe. Bí àpẹẹrẹ, ìdílé kan ní kí ọmọ wọn ọlọ́dún mẹ́wàá tó ń jẹ́ Brandon, sọ̀rọ̀ lórí àkòrí tó sọ pé, “Kí Nìdí Tí Jèhófà Fi Lo Ejò Láti Ṣàpẹẹrẹ Sátánì?” Ọ̀ràn yìí ti ń jẹ Brandon lọ́kàn tipẹ́, torí pé ó fẹ́ràn ejò, àmọ́ inú rẹ̀ kì í dùn torí pé wọ́n fi Sátánì wé ejò. Àwọn ìdílé kan máa ń ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé náà á sì kópa, wọ́n á ka apá tó kàn wọ́n látinú Bíbélì, tàbí kí wọ́n fi ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́. Kì í ṣe pé ọ̀nà ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ń múni lórí yá nìkan ni, ó tún máa mú kí àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ nínú rẹ̀, èyí á sì jẹ́ kí àwọn ìlànà Bíbélì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. a

Máa Ṣọ́ra fún Àwọn Nǹkan Tó Lè Dẹrù Pa Ẹ́

14, 15. (a) Báwo ni másùnmáwo àti àìsí ààbò ṣe ń pọ̀ sí i láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí? (b) Kí ló lè mú kí pákáǹleke tá à ń kojú légbá kan sí i?

14 Másùnmáwo àti àìsí ààbò ń pọ̀ sí i láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò nǹkan búburú ìsinsìnyí. Àìníṣẹ́lọ́wọ́ àtàwọn ìṣòro ọrọ̀ ajé míì ti fa ìnira fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn. Kódà ó ń ṣe àwọn tó níṣẹ́ lọ́wọ́ bíi pé inú ajádìí àpò ni àwọ́n ń pawó sí, èyí tó mú kí àǹfààní tí ìdílé wọn ń rí máà tó nǹkan. (Fí wé Hágárì 1:4-6.) Àwọn olóṣèlú àtàwọn aṣáájú kò rí nǹkan ṣe sí ọ̀ràn àwọn apániláyà àtàwọn àjálù míì tó ń wáyé. Àṣemáṣe àwọn ẹlòmíì ló sì ń fìyà jẹ wọ́n.—Sm. 38:4.

15 Ìṣòro àti pákáǹleke tó kúnnú ayé Sátánì yìí kò yọ àwọn Kristẹni tòótọ́ sílẹ̀. (1 Jòh. 5:19) Kódà láwọn ọ̀nà kan, pákáǹleke táwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ń kojú lè légbá kan sí i bí wọ́n ti ń sapá láti máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Jésù sọ pé: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòh. 15:20) Àmọ́, bí wọ́n bá tiẹ̀ “ṣe inúnibíni” sí wa pàápàá, a kò “fi wá sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́.” (2 Kọ́r. 4:9) Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

16. Kí ni kò ní jẹ́ ká pàdánù ayọ̀ wa?

16 Jésù sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.” (Mát. 11:28) Tá a bá ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, ńṣe là ń fi ara wa sí ìkáwọ́ Jèhófà. Nípa bẹ́ẹ̀, a máa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́r. 4:7) Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà tó jẹ́ “olùrànlọ́wọ́ náà,” ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun kó lè ṣeé ṣe fún wa láti fara da àdánwò àti ìpọ́njú tá à ń dojú kọ, ká má sì tún pàdánù ayọ̀ wa.—Jòh. 14:26; Ják. 1:2-4.

17, 18. (a) Ẹ̀mí wo la ní láti ṣọ́ra fún? (b) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ fàájì là ń fi gbogbo ọjọ́ lépa?

17 Àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún jíjẹ́ kí fàájì tó kúnnú ayé Sátánì yìí ní ipa tí kò tọ́ lórí àwọn. (Ka Éfésù 2:2-5.) Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀ “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími” lè dẹkùn mú wa. (1 Jòh. 2:16) Tàbí ká gba èrò òdì láyè pé ara máa tù wá tá a bá ń lọ́wọ́ sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara. (Róòmù 8:6) Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan gbà pé oògùn olóró, ọtí àmupara, wíwo ohun tó ń mú ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe, eré ìdárayá tó léwu àti onírúuru ohun àṣerégèé ló máa mú àwọn lórí yá. Ara “ètekéte” tí Sátánì ń lò láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà ni mímú kí wọ́n ní èrò tí kò tọ́ nípa ohun tó ń mára tuni.—Éfé. 6:11.

18 Lóòótọ́, kò sí ohun tó burú nínú jíjẹ, mímu, àti lílọ́wọ́ nínú eré ìnàjú tó yááyì, béèyàn ò bá ti ki àṣejù bọ̀ ọ́. Síbẹ̀, a kò ní jẹ́ kí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ di ohun tá à ń fi ojoojúmọ́ ayé lépa. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe é ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ká sì máa kó ara wa níjàánu, àgàgà nítorí àkókò tá à ń gbé yìí. Ìlépa àwọn nǹkan tara ẹni lè dẹrù pa wá débi tí a ó fi “di aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso ní ti ìmọ̀ pípéye nípa Olúwa wa Jésù Kristi.”—2 Pét. 1:8.

19, 20. Báwo la ṣe lè rí ìtura tòótọ́?

19 Tá a bá mú ìrònú wa bá àwọn ìlànà Jèhófà mu, a ó rí i pé fàájì èyíkéyìí tí ayé yìí lè fi fúnni kì í tọ́jọ́. Mósè mọ̀ bẹ́ẹ̀, àwa náà sì gbọ́dọ̀ mọ̀ bẹ́ẹ̀. (Héb. 11:25) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ṣíṣe ìfẹ́ inú Baba wa ọ̀run nìkan ló lè jẹ́ ká ní ìtura tòótọ́, èyí tó fini lọ́kàn balẹ̀, táá sì jẹ́ kéèyàn ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tó wà pẹ́ títí.—Mát. 5:6.

20 Ǹjẹ́ ká máa bá a nìṣó láti máa rí ìtura nínú àwọn nǹkan tẹ̀mí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè máa “kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé . . . bí a ti ń dúró de ìrètí aláyọ̀ àti ìfarahàn ológo ti Ọlọ́run ńlá náà àti ti Olùgbàlà wa, Kristi Jésù.” (Títù 2:12, 13) Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a kò ní kúrò lábẹ́ àjàgà Jésù, nípa títẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò ní ayọ̀ àti ìtura tòótọ́!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ mọ ọ̀nà míì tó o lè gbà mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé gbádùn mọ́ni kó sì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1991, ojú ìwé 4.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo ni àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń rí ìtura lónìí?

• Ọ̀nà wo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń gbà mú ara tu àwa àtàwọn tá à ń wàásù fún?

• Kí ni àwọn olórí ìdílé lè ṣe láti rí i dájú pé ìjọsìn ìdílé wọn ń mára tuni?

• Àwọn nǹkan wo ló máa ń dẹrù pa wá nípa tẹ̀mí?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Tá a bá gba àjàgà Jésù sí ọrùn wa, a óò rí ọ̀pọ̀ ohun tí á máa mú ìtura bá wa