Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á bí Ọkọ Tàbí Aya Rẹ Bá Já Ẹ Jù Sílẹ̀

Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á bí Ọkọ Tàbí Aya Rẹ Bá Já Ẹ Jù Sílẹ̀

Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á bí Ọkọ Tàbí Aya Rẹ Bá Já Ẹ Jù Sílẹ̀

MARGARITA àti ọkọ rẹ̀ Raúl ti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. a Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bí ọmọ wọn àkọ́bí, Raúl bẹ̀rẹ̀ sí fi Jèhófà sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣèṣekúṣe, wọ́n sì yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni. Margarita sọ pé: “Nígbà tí gbogbo èyí ṣẹlẹ̀, mo rò pé mo máa kú ni. Ọkàn mi bà jẹ́, mi ò sì mọ ohun tí màá ṣe.”

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jane náà ṣègbéyàwó tí ọkọ rẹ̀ fi já a kulẹ̀ tó sì da ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ sí lù ú. Jane sọ pé: “Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi nígbà tó kọ́kọ́ lù mí, ọ̀rọ̀ náà kó ìtìjú bá mi, kódà ó bù mí kù. Ó sì wá di àṣà rẹ̀ láti máa lù mí, lẹ́yìn náà á wá bẹ̀ mí pé kí n dárí ji òun. Mo ronú pé ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni ni láti máa dárí jini nígbà gbogbo kí n sì mọ́kàn kúrò níbẹ̀. Mo tún kà á sí pé ìwà ọ̀dàlẹ̀ ni láti sọ ìṣòro wa fún àwọn ẹlòmíì, tó fi mọ́ àwọn alàgbà nínú ìjọ. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi ń lù mí tí mo sì ń dárí jì í. Ní gbogbo àkókò yẹn, mo lérò pé ó yẹ kí nǹkan kan wà tí mo lè ṣe tí ọkọ mi á fi nífẹ̀ẹ́ mi. Nígbà tó wá já èmi àti ọmọbìnrin wa sílẹ̀, ńṣe ló ń ṣe mi bíi pé mo ti kùnà, pé ó yẹ kí n ti ṣe nǹkan kan tàbí kí n ti sọ̀rọ̀ ju bí mo ti ṣe lọ kí ìgbéyàwó wa má bàa tú ká.”

Bíi ti Margarita àti Jane, ìwọ náà lè ní ẹ̀dùn ọkàn, ìṣòro ìgbọ́bùkátà, kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run má sì fi bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán torí pé ọkọ rẹ dà ẹ́. Ó sì lè jẹ́ pé ìwọ ọkọ lò ń kojú ẹ̀dùn ọkàn tàbí ìnira torí ti ìyàwó rẹ̀ tó di aláìṣòótọ́. Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, kò sí àní-àní pé “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la wà yìí. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi hàn pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ìṣòro á máa wà nínú ìdílé, kò sì ní sí ìfẹ́ni àdánidá. Ojú lásán sì ni àwọn kan á fi máa sin Ọlọ́run, wọn kò ní fọkàn sìn ín. (2 Tím. 3:1-5) Àwọn ìṣòro yìí kò yọ àwa Kristẹni tòótọ́ sílẹ̀; torí náà kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí ọkọ tàbí aya rẹ bá já ẹ jù sílẹ̀?

Máa Wo Ara Rẹ bí Jèhófà Ṣe Ń Wò Ẹ́

Ó lè kọ́kọ́ ṣòro fún ẹ láti gbà pé ẹnì kan tó o nífẹ̀ẹ́ lè ṣe ohun tó dùn ẹ́ tó bẹ́ẹ̀. Kódà o lè máa dá ara rẹ lẹ́bi nítorí ìwà àìdáa tí ọkọ tàbí aya rẹ hù.

Má gbàgbé pé ẹni tí Jésù ọkùnrin pípé fọkàn tán tó sì nífẹ̀ẹ́ dà á. Ẹ̀yìn tí Jésù ti gbàdúrà gidigidi ló ṣẹ̀ṣẹ̀ yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, tó jẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ ọn jù lọ. Nígbà yẹn, gbogbo àwọn méjìlá náà ló jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ṣe é fọkàn tán. Torí náà, kò sí iyè méjì pé ó máa dun Jésù gan-an nígbà tí Júdásì “di ọ̀dàlẹ̀.” (Lúùkù 6:12-16) Àmọ́, Jèhófà kò sọ pé Jésù ló máa dáhùn fún ohun tí Júdásì ṣe.

Lóòótọ́, kò sí ọkọ tàbí aya kankan lóde òní tó jẹ́ ẹni pípé. Kò sí ẹni tí kò lè ṣàṣìṣe nínú àwọn méjèèjì. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù sọ ọ̀rọ̀ tí kò ṣeé já ní koro yìí pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sm. 130:3) Àwọn tọkọtaya ní láti fìwà jọ Jèhófà, kí wọ́n máa gbójú fo àìpé ẹnì kejì wọn.—1 Pét. 4:8.

Àmọ́ “olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12) Tí ọkọ tàbí aya kan bá sọ ọ́ dàṣà láti máa sọ̀rọ̀ èébú sí ẹnì kejì rẹ̀ tàbí kó máa lù ú, ẹni yẹn gan-an ló máa dáhùn fún ohun tó ṣe níwájú Jèhófà. Jèhófà kórìíra ìwà ipá àti ọ̀rọ̀ èébú, torí náà kò sí ìdí tó fi yẹ kí ọkọ tàbí aya máa hùwà tí kò fi ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ hàn fún ẹnì kejì rẹ̀. (Sm. 11:5; Éfé. 5:33; Kól. 3:6-8) Kódà, bí Kristẹni kan bá ti sọ ọ́ dàṣà láti máa bínú sódì, tí kò ronú pìwà dà tí kò sì jáwọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni. (Gál. 5:19-21; 2 Jòh. 9, 10) Kò yẹ kí ọkọ tàbí aya kan dá ara rẹ̀ lẹ́bi tó bá fi ẹjọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sun àwọn alàgbà. Ní tòótọ́, àánú àwọn tó ń dojú kọ irú ìwà àìdáa bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe Jèhófà.

Nígbà tí ọkọ tàbí aya kan bá ṣe panṣágà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣẹ ẹnì kejì rẹ̀, ó sì tún dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà. (Mát. 19:4-9; Héb. 13:4) Tí ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ náà bá ti ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ní ìgbésí ayé rẹ̀, kò sí ìdí fún un láti máa dá ara rẹ̀ lẹ́bi fún ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí onípanṣágà náà hù.

Máa rántí pé Jèhófà mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ. Ó ṣàpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ olówó orí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kún fún àwọn ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn nípa bó ṣe dùn ún pé orílẹ̀-èdè náà di aláìṣòótọ́ nínú ìjọsìn wọn. (Aísá. 54:5, 6; Jer. 3:1, 6-10) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà rí omijé rẹ tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkọ tàbí aya rẹ dà ẹ́ lọ́nà èyíkéyìí. (Mál. 2:13, 14) Ó mọ̀ pé o nílò ìtùnú àti ìṣírí.

Bí Jèhófà Ṣe Ń Pèsè Ìtùnú

Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà pèsè ìtùnú jẹ́ nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni. Jane tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan rí irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ gbà. Jane sọ pé: “A ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká lásìkò kan tí nǹkan ti tojú sú mi pátápátá. Ó mọ bí ìdààmú ọkàn mi ṣe pọ̀ tó nítorí ti ọkọ mi tó lọ jáwèé ìkọ̀sílẹ̀. Ó bá mi fèrò wérò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi 1 Kọ́ríńtì 7:15. Ẹsẹ Bíbélì yẹn àti àwọn ọ̀rọ̀ onínúure tó sọ mú kí èrò tí mo ní pé mo jẹ̀bi dín kù, ó sì jẹ́ kí n ní ìbàlẹ̀ ọkàn.” b

Margarita, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà máa ń pèsè ìrànwọ́ nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni. Margarita sọ pé: “Nígbà tó ti wá hàn gbangba pé ọkọ mi kò ronú pìwà dà, mo kó àwọn ọmọ mi mo sì lọ sí ìlú míì. Nígbà tí mo débẹ̀ mo rí yàrá méjì gbà. Lọ́jọ́ kejì, ìbànújẹ́ dorí mi kodò, bí mo sì ti ń tú ẹrù mi, mo gbọ́ tí àwọn kan ń kanlẹ̀kùn. Mo rò pé ìyá onílé wa tí yàrá rẹ̀ kángun sí tiwa ni. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé arábìnrin tó kọ́ mọ́mì mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì ran ìdílé wa lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni. Kò ronú pé èmi lòun máa bá níbẹ̀, ìdí tó fi wá síbẹ̀ ni pé òun ló ń kọ́ ìyá onílé wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ara tù mí pẹ̀sẹ̀, mo sì bú sẹ́kún. Mo sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un, òun náà sì bá mi sunkún. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó ṣètò bá a ṣe máa lọ sí ìpàdé lọ́jọ́ yẹn. Àwọn ará ìjọ gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀, àwọn alàgbà sì ṣètò bí wọ́n á ṣe ran ìdílé wa lọ́wọ́ láti máa bojú tó wa nípa tẹ̀mí.”

Bí Àwọn Ẹlòmíì Ṣe Lè Ṣèrànwọ́

Láìsí àní-àní, àwọn ará ìjọ lè pèsè ìrànwọ́ ní onírúurú ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, Margarita ní láti wá iṣẹ́ tó máa ṣe. Ìdílé kan nínú ìjọ yọ̀ǹda láti máa bá a bójú tó àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n bá dé láti ilé ìwé, nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀.

Margarita sọ pé: “Mo máa ń mọrírì rẹ̀ gan-an tí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin bá yọ̀ǹda láti bá èmi àti àwọn ọmọ mi jáde òde ẹ̀rí.” Nípa ṣíṣe irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀, àwọn ará ìjọ ń ṣèrànwọ́ láti ‘ru àwọn ẹrù ìnira ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì,’ wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ “mú òfin Kristi ṣẹ.”—Gál. 6:2.

Àwọn tó ń jìyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíì máa ń mọrírì irú ìrànlọ́wọ́ yìí. Monique, tí ọkọ rẹ̀ já sílẹ̀, tó sì tún fi gbèsè ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] owó Dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti ọmọ mẹ́rin sílẹ̀ fún un, sọ pé: “Àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi mà nífẹ̀ẹ́ o. Mi ò mọ bí mi ò bá ṣe borí ìṣòro náà láìsí ìrànlọ́wọ́ wọn. Mo gbà pé Jèhófà dìídì fi àwọn arákùnrin tó lo ara wọn nítorí àwọn ọmọ mi jíǹkí wa ni. Ó dùn mọ́ mi láti rí àwọn ọmọ mi tí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí látàrí ìrànlọ́wọ́ àwọn ará. Tí mo bá nílò ìmọ̀ràn, àwọn alàgbà máa ń ràn mí lọ́wọ́. Tí mo bá ń fẹ́ ẹni tí màá fọ̀rọ̀ lọ̀, wọ́n máa ń tẹ́tí sí mi.”—Máàkù 10:29, 30.

Lóòótọ́, ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ ẹni máa fòye mọ ìgbà tí kò yẹ kó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn tó kó ìbànújẹ́ bá ẹnì kan. (Oníw. 3:7) Margarita sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń gbádùn kí n máa bá àwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ wa tuntun sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù, àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ọmọ wa, àtàwọn nǹkan míì yàtọ̀ sí ìṣòro tí mo ní. Mo mọyì bí wọ́n ṣe jẹ́ kí n mọ́kàn kúrò lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, kí n sì máa bá ìgbésí ayé mi lọ.”

Yẹra fún Ẹ̀mí Ìgbẹ̀san

Nígbà míì, dípò tí wàá fi máa ronú pé ìwọ lo jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí ọkọ tàbí aya rẹ bá dà ẹ́, ó lè máa bí ẹ nínú pé ò ń jìyà nítorí àṣemáṣe ọkọ tàbí aya rẹ. Tí irú èrò bẹ́ẹ̀ bá gbilẹ̀ lọ́kàn rẹ, ìbínú yìí lè ṣàkóbá fún ìpinnu rẹ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, o lè wá bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà tí wàá fi gbẹ̀san lára ẹnì kejì tó di aláìṣòótọ́.

Tó o bá rí i pé irú èrò bẹ́ẹ̀ ti gbà ẹ́ lọ́kàn, o lè ronú nípa àpẹẹrẹ Jóṣúà àti Kálébù. Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí fẹ̀mí ara wọn wewu láti lọ ṣe amí Ilẹ̀ Ìlérí. Àwọn amí tó kù kò nígbàgbọ́, wọ́n sì yí ọkàn àwọn èèyàn náà pa dà kúrò nínú ṣíṣègbọràn sí Jèhófà. Kódà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ sọ Jóṣúà àti Kálébù ní òkúta nígbà tí wọ́n gbìyànjú láti fún orílẹ̀-èdè náà ní ìṣírí láti jẹ́ olóòótọ́. (Núm. 13:25–14:10) Nítorí ìwà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìí, Jóṣúà àti Kálébù rìn kiri nínú aginjù fún ogójì ọdún, kì í ṣe torí àṣemáṣe tiwọn, bí kò ṣe torí àṣemáṣe àwọn ẹlòmíì.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn náà dun Jóṣúà àti Kálébù gan-an, wọn kò jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn arákùnrin wọn mú kí wọ́n bínú sódì. Àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run ló jẹ wọ́n lógún. Lẹ́yìn ogójì [40] ọdún tí wọ́n lò nínú aginjù, àwọn àti àwọn ọmọ Léfì, gba èrè ní ti pé àwọn nìkan ló ṣẹ́ kù lára ìran náà, wọ́n sì tún wọ Ilẹ̀ Ìlérí.—Núm. 14:28-30; Jóṣ. 14:6-12.

Ohun tí ẹnì kejì rẹ tó di aláìṣòótọ́ ṣe lè mú kó o jìyà fún àwọn àkókò kan. Ìgbéyàwó náà lè tú ká, o sì lè ní ìrora ọkàn àti ìṣòro ìgbọ́bùkátà lẹ́yìn náà. Àmọ́, dípò tí wàá fi jẹ́ kí ìbànújẹ́ dorí rẹ kodò, máa rántí pé Jèhófà mọ bó ṣe lè bójú tó ọ̀ràn àwọn tó dìídì ṣá ìlànà rẹ̀ tì, bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìgbàgbọ́ ṣe wá mọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.—Héb. 10:30, 31; 13:4.

O Lè Fara Dà Á!

Dípò tí wàá fi jẹ́ kí èròkérò dẹrù pa ẹ́, fi àwọn èrò Jèhófà kún inú ọkàn rẹ. Jane sọ pé: “Mo rí i pé títẹ́tí sí Ilé Ìṣọ́ àti tá a gba ohùn wọn sílẹ̀ ràn mí lọ́wọ́ láti fara dà á. Ìpàdé tún wà lára ohun tó jẹ́ orísun okun fún mi. Bí mo tún ṣe ń kópa déédéé nínú ìpàdé ràn mí lọ́wọ́ láti mọ́kàn kúrò nínú àwọn ìṣòro mi. Ọ̀nà tí iṣẹ́ ìwàásù gbà ràn mí lọ́wọ́ náà nìyẹn. Bí mo ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, mò ń tipa bẹ́ẹ̀ fún ìgbàgbọ́ tèmi náà lókun. Bákan náà, bíbójú tó àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ràn mí lọ́wọ́ láti máa fọkàn mi sí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”

Monique, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Bí mo ṣe ń lọ sí ìpàdé déédéé, tí mo sì ń lọ sóde ẹ̀rí débi tí agbára mi gbé e dé, ti jẹ́ kí n lè fara dà á. Ìdílé mi ti mọwọ́ ara wọn gan-an, a sì sún mọ́ àwọn ará ìjọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti jẹ́ kí n mọ ibi tí èmi alára kù sí. A ti dán mi wò, àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà mo dúró gbọn-in.”

Ìwọ náà lè fara da irú àdánwò bẹ́ẹ̀. Láìka ti ìrora tí ìwà ọ̀dàlẹ̀ ẹnì kejì rẹ lè fà bá ẹ sí, sapá láti fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sílò: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”—Gál. 6:9.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b Tó o bá fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ojú tí Bíbélì fi wo ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀, wo ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run,’ ojú ìwé 125 sí 130, 219 sí 221.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn tí ọkọ tàbí aya wọn já sílẹ̀ máa ń mọyì àwọn tó ń bá wọn jáde òde ẹ̀rí