Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Ṣàkóso Ìbínú Rẹ Kó o Lè “Máa Fi Ire Ṣẹ́gun Ibi”

Máa Ṣàkóso Ìbínú Rẹ Kó o Lè “Máa Fi Ire Ṣẹ́gun Ibi”

Máa Ṣàkóso Ìbínú Rẹ Kó o Lè “Máa Fi Ire Ṣẹ́gun Ibi”

“Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, . . . ṣùgbọ́n [ẹ] máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” —RÓÒMÙ 12:19, 21.

1, 2. Àpẹẹrẹ rere wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí kan tó ń rìnrìn àjò fi lélẹ̀?

 ÀWÙJỌ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] kan ń rìnrìn àjò lọ síbi ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan, àmọ́ wọn ò lè débẹ̀ lọ́jọ́ náà torí pé ọkọ̀ òfuurufú tí wọ́n wọ̀ ní ìṣòro kan tí kò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ dáadáa. Bí ohun tí kò yẹ kó gbà ju wákàtí kan lọ ṣe di ohun tó gba wákàtí mẹ́rìnlélógójì [44] mọ́ wọn lọ́wọ́ ní ibùdókọ̀ òfuurufú tó wà níbi àdádó nìyẹn o. Kò sí oúnjẹ àti omi tó pọ̀ tó níbẹ̀; ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti ilé ìwẹ̀ tó wà níbẹ̀ kò sì tó nǹkan. Inú bí ọ̀pọ̀ lára àwọn èrò ọkọ̀ òfuurufú náà, wọ́n sì halẹ̀ mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ibùdókọ̀ òfuurufú náà. Àmọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà níbẹ̀ ò janpata.

2 Nígbà tó yá, àwọn Ẹlẹ́rìí náà dé ibi tí wọ́n ń lọ, àmọ́ apá tó gbẹ̀yìn nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìyàsímímọ́ náà ni wọ́n bá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, wọn ò tètè kúrò níbẹ̀ lẹ́yìn tí ìyàsímímọ́ náà parí, kí wọ́n lè fara rora pẹ̀lú àwọn ará. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ni wọ́n wá mọ̀ pé àwọn èrò ọkọ̀ tó kù kíyè sí sùúrù àti ìkóra-ẹni-níjàánu àwọn. Ọ̀kan lára àwọn èrò náà tiẹ̀ sọ fún ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú náà pé, “Bí kì í bá ṣe tàwọn Kristẹni mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] tó wà nínú ọkọ̀ náà ni, wàhálà ì bá ti bẹ́ sílẹ̀ ní ibùdókọ̀ òfuurufú náà.”

Inú Ayé Oníbìínú Là Ń Gbé

3, 4. (a) Báwo ni ìbínú oníwà ipá ṣe ń fi ojú aráyé rí màbo, látìgbà wo sì ni? (b) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún Kéènì láti ṣàkóso ìbínú rẹ̀? Ṣàlàyé.

3 Pákáǹleke inú ètò búburú ìsinsìnyí lè mú kí inú máa bí àwọn èèyàn. (Oníw. 7:7) Ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni irú ìbínú bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí ìkórìíra àti ìwà ipá. Kódà, ìbínú máa ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè bára wọn jagun, ó máa ń dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàárín ìlú, ó sì ń mú kí ọ̀pọ̀ ìdílé forí gbárí. Ọjọ́ pẹ́ tí ìbínú àti ìwà ipá ti wà. Owú mú kí Kéènì, àkọ́bí Ádámù àti Éfà, fi ìbínú pa àbúrò rẹ̀, Ébẹ́lì. Kéènì hu ìwà búburú yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti rọ̀ ọ́ pé kó ṣàkóso ìmọ̀lára rẹ̀, tó sì ṣèlérí fún un pé òun á bù kún un tó bá ṣe bẹ́ẹ̀.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 4:6-8.

4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kéènì jogún àìpé, ó ṣì lè pinnu láti ṣe ohun tó tọ́. Ó lè yàn láti ṣàkóso ìbínú rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi dá a lẹ́bi torí ìwà ipá tó hù. Bákan náà, ara àìpé wa túbọ̀ ń mú kó ṣòro fún wa láti má ṣe bínú, ká má sì fara ya. Àwọn agbára míì tó ń darí ẹ̀dá láti ṣe ohun tí kò tọ́ tún ń fi kún wàhálà tó ń bá “àwọn àkókò lílekoko” yìí rìn. (2 Tím. 3:1) Bí àpẹẹrẹ, ìṣòro ìṣúnná owó lè mú kí ọkàn èèyàn má balẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá àtàwọn àjọ tó ń ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ tiẹ̀ máa ń sọ pé ìṣòro ìṣúnná owó máa ń pa kún ìbínú fùfù àti ìwà ipá nínú ilé.

5, 6. Ojú wo ni aráyé fi ń wo ìbínú, báwo ló sì ṣe lè ràn wá?

5 Láfikún sí ìyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn tá à ń bá pàdé ló jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn,” “onírera” àti “òǹrorò” pàápàá. Ó rọrùn kí àwọn ìwà búburú wọ̀nyí ràn wá kí wọ́n sì máa mú wa bínú. (2 Tím. 3:2-5) Kódà, àwọn fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n sábà máa ń fi hàn pé gbígbẹ̀san àti híhùwà ipá jẹ́ ọ̀nà tó dára tó sì bẹ́tọ̀ọ́ mu jù lọ láti yanjú ìṣòro. Ọ̀pọ̀ eré onítàn ló ń mú káwọn òǹwòran máa fojú sọ́nà fún ìgbà tí “ọwọ́ máa ba” ọ̀daràn inú eré náà, ìyẹn ìgbà tí akọni inú eré náà máa pa á nípa ìkà.

6 Kì í ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu ni irú àwọn ìpolongo èké bẹ́ẹ̀ ń gbé lárugẹ, bí kò ṣe “ẹ̀mí ayé” àti ìfẹ́ ọkàn Sátánì, tó ń fi ìbínú ṣàkóso ayé. (1 Kọ́r. 2:12; Éfé. 2:2; Ìṣí. 12:12) Ìfẹ́ ti ara aláìpé ni irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ń gbé lárugẹ, ìyẹn sì lòdì pátápátá sí ẹ̀mí Ọlọ́run àti àwọn ànímọ́ rẹ̀. Kódà, lára ohun tí Kristẹni kan gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ̀ ni pé kò dára láti máa gbẹ̀san bí wọ́n bá tilẹ̀ mú un bínú. (Ka Mátíù 5:39, 44, 45.) Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, báwo la wá ṣe lè túbọ̀ máa fi àwọn ẹ̀kọ́ Jésù sílò?

Àwọn Àpẹẹrẹ Rere àti Búburú

7. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Síméónì àti Léfì kùnà láti ṣàkóso ìbínú wọn?

7 Ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn nípa bá a ṣe lè ṣàkóso ìbínú ló wà nínú Bíbélì. Ó sì tún fúnni ní ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tá a lè máa tẹ̀ lé nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bí a bá ṣàkóso ìbínú wa tàbí tí a kò bá ṣàkóso rẹ̀. Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ Jékọ́bù, Síméónì àti Léfì, gbẹ̀san nítorí àbúrò wọn Dínà tí Ṣékémù fipá bá lò pọ̀. Inú wọn “bàjẹ́, inú sì bí wọn gidigidi.” (Jẹ́n. 34:7) Lẹ́yìn ìyẹn ni àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù yòókù lọ pa olúkúlùkù ọkùnrin tó wà ní ìlú Ṣékémù, wọ́n sì kó àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀ lẹ́rú. Kì í ṣe torí Dínà nìkan ni wọ́n ṣe ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ṣe yẹn, ó tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbéraga ló mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé wọn ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ìwọ̀sí lọ̀ wọ́n. Èrò wọn ni pé Ṣékémù ti ṣẹ bàbá wọn, Jékọ́bù. Àmọ́, kí lèrò Jékọ́bù nípa ìwà tí wọ́n hù yìí?

8. Kí ni ìtàn Síméónì àti Léfì kọ́ wa nípa gbígbẹ̀san?

8 Inú Jékọ́bù ti ní láti bà jẹ́ gidigidi pé Dínà ko irú àgbákò yẹn; síbẹ̀, ó dá àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́bi torí pé wọ́n gbẹ̀san. Síbẹ̀ náà, Síméónì àti Léfì gbìyànjú láti dá ìwà tí wọ́n hù láre, nípa sísọ pé: “Ṣé ó yẹ kí ẹnikẹ́ni hùwà sí arábìnrin wa bí ẹni pé kárùwà ni?” (Jẹ́n. 34:31) Àmọ́, ọ̀rọ̀ náà kò parí síbẹ̀, torí pé kò dùn mọ́ Jèhófà nínú. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jékọ́bù sọ tẹ́lẹ̀ pé nítorí ìbínú Síméónì àti Léfì tó mú wọn hùwà ipá, àwọn àtọmọdọ́mọ wọn máa tú ká sáàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:5-7.) Èyí fi hàn pé wọn kò rí ojú rere Ọlọ́run àti ti bàbá wọn torí pé wọn kò ṣàkóso ìbínú wọn.

9. Ìgbà wo ló kù díẹ̀ kí Dáfídì ṣi inú bí?

9 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì Ọba yàtọ̀ sí èyí. Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló ṣí sílẹ̀ fún un láti gbẹ̀san, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Sám. 24:3-7) Àmọ́, nígbà kan, díẹ̀ ló kù kó ṣi inú bí. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó ń jẹ́ Nábálì rọ̀jò èébú lé àwọn ọkùnrin Dáfídì lórí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n bá a dáàbò bo agbo ẹran rẹ̀ àti àwọn olùṣọ́ àgùntàn rẹ̀. Bóyá nítorí pé ohun tí Nábálì ṣe yìí dun Dáfídì, ó gbéra láti lọ gbéjà kò ó. Àmọ́ kí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ tó dé ilé Nábálì kí wọ́n sì gbéjà ko òun àti agbo ilé rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin kan lọ sọ ọ̀rọ̀ náà létí Ábígẹ́lì, ìyàwó Nábálì tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ó sì rọ̀ ọ́ pé kó yára wá nǹkan ṣe sí i. Lójú ẹsẹ̀, Ábígẹ́lì ṣa ẹ̀bùn rẹpẹtẹ jọ ó sì gbéra láti lọ pàdé Dáfídì. Ó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Dáfídì tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó ní òun gbà pé olùbẹ̀rù Jèhófà ni, torí náà kó má ṣe bínú nítorí ìwà àfojúdi Nábálì. Ọ̀rọ̀ yìí pe orí Dáfídì wálé, ó sì wí pé: “Ìbùkún sì ni fún ìwọ tí o ti dá mi dúró lónìí yìí kí n má bàa wọnú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.”—1 Sám. 25:2-35.

Ìwà Kristẹni

10. Dípò kí àwọn Kristẹni máa gbẹ̀san, ìwà wo ló yẹ kí wọ́n máa hù?

10 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Síméónì àti Léfì àti ohun tó wáyé láàárín Dáfídì àti Ábígẹ́lì fi hàn láìsí iyè méjì pé Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ sí kéèyàn máa bínú sódì kó sì máa hùwà ipá, àti pé ẹni tó bá ń wá àlàáfíà máa ń bá ojú rere rẹ̀ pàdé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’ Ṣùgbọ́n, ‘bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní ohun kan láti mu; nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò máa kó òkìtì ẹyín iná lé e ní orí.’ Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.”—Róòmù 12:18-21. a

11. Báwo ni arábìnrin kan ṣe dẹni tó ń ṣàkóso ìbínú rẹ̀?

11 A lè fi ìmọ̀ràn yẹn sílò. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan sọ̀rọ̀ ọ̀gá rẹ̀ obìnrin lójú alàgbà kan. Ó sọ pé ó máa ń ṣe ojúṣàájú kò sì láàánú. Èyí ń múnú bí arábìnrin yìí sí ọ̀gá rẹ̀, ó sì fẹ́ fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Alàgbà náà rọ̀ ọ́ pé kó má fi ìkánjú ṣe ìpinnu. Ó fòye gbé e pé inú tó ń bí arábìnrin náà sí ìwà tí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn tí ọ̀gá rẹ̀ ń hù ló ń mú kí ọ̀ràn náà burú sí i. (Títù 3:1-3) Alàgbà náà ṣàlàyé fún un pé bó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé ó rí iṣẹ́ míì, ó ṣì máa pọn dandan pé kó yí bó ṣe ń hùwà sí àwọn tó bá ṣẹ̀ ẹ́ pa dà. Ó gbà á níyànjú pé kó má ṣe máa fi nǹkan tí òun fúnra rẹ̀ ò ní gbà lọ ọ̀gá rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti kọ́ wa. (Ka Lúùkù 6:31.) Arábìnrin náà ní òun á gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ìwà ọ̀gá rẹ̀ yí pa dà, ó sì gbóríyìn fún arábìnrin náà torí iṣẹ́ tó ń ṣe.

12. Kí nìdí tó fi máa ń dùn wá wọra bí èdèkòyédè bá wáyé láàárín àwa tá a jọ jẹ́ Kristẹni?

12 Ó lè ṣàì yà wá lẹ́nu bí irú ìṣòro yìí bá wáyé láàárín àwa àti ẹni tí kì í ṣe ará. A mọ̀ pé àwọn èèyàn sábà máa ń ṣe ojúsàájú nínú ayé Sátánì, a sì ní láti máa sapá ní gbogbo ọ̀nà kí àwọn aṣebi má bàa máa mú wa bínú. (Sm. 37:1-11; Oníw. 8:12, 13; 12:13, 14) Àmọ́, bí ìṣòro bá wáyé láàárín àwa tá a jọ jẹ́ Kristẹni, ó máa ń dùn wá wọra. Ẹlẹ́rìí kan rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Olórí ìṣòro tí mo ní nígbà tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni bí mo ṣe máa fara mọ́ òtítọ́ náà pé aláìpé ni àwọn èèyàn Jèhófà.” A kúrò nínú ayé aláìnífẹ̀ẹ́, níbi tí kò ti sí ẹni tó ń gba ti ẹlòmíì rò, a sì ń retí pé ńṣe ni gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ á máa fi ìfẹ́ bá ara wọn lò. Torí náà, bí ẹni tá a jọ jẹ́ Kristẹni, pàápàá ẹni tó ní ojúṣe nínú ìjọ, bá sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wa tàbí tó hùwà tí kò tọ́, ó máa dùn wá gan-an, ó sì lè mú wa bínú. A lè béèrè pé, ‘Báwo ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe lè máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Jèhófà?’ Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pàápàá nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì. (Gál. 2:11-14; 5:15; Ják. 3:14, 15) Kí ló yẹ ká ṣe bó bá jẹ́ pé àwa ni ọ̀ràn náà ṣẹlẹ̀ sí?

13. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa yanjú èdèkòyédè, báwo ló sì ṣe yẹ ká máa yanjú rẹ̀?

13 Arábìnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ mí. Ìgbà gbogbo ni ìyẹn sì máa ń ràn mí lọ́wọ́.” Bá a sì ṣe kà á ní ìpínrọ̀ kẹfà, Jésù kọ́ wa láti máa gbàdúrà fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wa. (Mát. 5:44) Ṣé kò wá yẹ ká máa gbàdúrà fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa! Bí bàbá kan ṣe ń fẹ́ káwọn ọmọ tó bí fẹ́ràn ara wọn, bẹ́ẹ̀ ló ṣe ń wu Jèhófà pé káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé máa bá ara wọn gbé ní ìrẹ́pọ̀. À ń wọ̀nà fún ìgbà tí a ó máa gbé ní àlàáfíà àti ayọ̀ títí láé, Jèhófà sì ti ń kọ́ wa báyìí láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ó fẹ́ ká máa ṣe iṣẹ́ bàǹtà-banta tó gbé lé wa lọ́wọ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa yanjú àwọn ìṣòro tàbí ká máa “gbójú fo” ìrélànàkọjá ká lè máa bá a nìṣó láti gbé ní ìṣọ̀kan. (Ka Òwe 19:11.) Dípò tí a ó fi máa yẹra fún àwọn arákùnrin wa nígbà tí ìṣòro bá wáyé, ńṣe ló yẹ ká máa ran ara wa lọ́wọ́ láti wà pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run, ká lè jọ wà ní àìséwu lábẹ́ ‘apá ayérayé’ Jèhófà.—Diu. 33:27, Bibeli Mimọ.

Jíjẹ́ Ẹni Pẹ̀lẹ́ sí Gbogbo Èèyàn Máa Ń Sèso Rere

14. Báwo la ṣe lè máa gbéjà ko àwọn ohun tí Sátánì fi ń fa ìpínyà?

14 Kí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù lè dí wa lọ́wọ́ ká má bàa tan ìhìn rere kálẹ̀, wọ́n ń gbìyànjú lójú méjèèjì láti ba ayọ̀ àwọn ìdílé àti ìjọ jẹ́. Wọ́n ń gbìyànjú láti dá ìyapa sílẹ̀, torí wọ́n mọ̀ pé ọ̀tẹ̀ abẹ́lé máa ń ṣèpalára tó pọ̀. (Mát. 12:25) Ká má bàa gbà wọ́n láyè láti da àárín wa rú, ó máa dára ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.” (2 Tím. 2:24) Ẹ rántí pé ìjà wa “kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí . . . àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú.” Ká bàa lè kẹ́sẹ járí nínú ìjà yìí, a gbọ́dọ̀ máa gbé ìhámọ́ra tẹ̀mí wọ̀, lára rẹ̀ sì ni “ohun ìṣiṣẹ́ ìhìn rere àlàáfíà.”—Éfé. 6:12-18.

15. Kí ló yẹ ká máa ṣe bí àwọn ará ìta bá gbéjà kò wá?

15 Àwọn ọ̀tá Jèhófà ń ṣe àtakò líle koko sí àwọn èèyàn Jèhófà tí wọ́n jẹ́ èèyàn àlàáfíà láti ẹ̀yìn òde ìjọ Ọlọ́run. Àwọn kan lára àwọn ọ̀tá yìí máa ń fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn míì máa ń fi ọ̀rọ̀ èké bà wá jẹ́ nínú ìròyìn tàbí ní àwọn ilé ẹjọ́. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa retí irú nǹkan bẹ́ẹ̀. (Mát. 5:11, 12) Kí ló yẹ ká ṣe? A kò gbọ́dọ̀ “fi ibi san ibi,” yálà nínú ọ̀rọ̀ tàbí nínú ìwà wa.—Róòmù 12:17; ka 1 Pétérù 3:16.

16, 17. Ipò tí ń dánni wò wo ni ìjọ kan dojú kọ?

16 Ohun yòówù kí Sátánì ṣe sí wa, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́rìí fáwọn ẹlòmíì tí a bá ń “fi ire ṣẹ́gun ibi.” Bí àpẹẹrẹ, ìjọ kan ní erékùṣù Pàsífíìkì rẹ́ǹtì gbọ̀ngàn kan láti fi ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Nígbà tí àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì kan tó wà ládùúgbò náà gbọ́ pé wọ́n fẹ́ lo ibẹ̀, wọ́n sọ fún àwọn ọmọ ìjọ wọn pé kí wọ́n lọ pé jọ sínú gbọ̀ngàn náà fún ìjọsìn lákòókò tó yẹ kí àwọn Ẹlẹ́rìí náà bẹ̀rẹ̀ Ìrántí Ikú Kristi. Àmọ́, ọ̀gá ọlọ́pàá sọ fún àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì náà pé kí wọ́n kúrò níbẹ̀ kí àkókò Ìrántí Ikú Kristi tó tó. Síbẹ̀, nígbà tí àkókò tó, ṣíbá ni àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì náà kún inú gbọ̀ngàn yìí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn wọn.

17 Bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń gbára dì láti lọ fi ipá lé wọn kúrò nínú gbọ̀ngàn náà, ààrẹ ṣọ́ọ̀ṣì yẹn lọ bá ọ̀kan lára àwọn alàgbà, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ ohun àkànṣe èyíkéyìí wà tẹ́ ẹ fẹ́ ṣe nírọ̀lẹ́ yìí?” Arákùnrin náà sọ fún un pé a fẹ́ ṣe Ìrántí Ikú Kristi, ọkùnrin náà sì fèsì pé: “Áà, mi ò mọ̀!” Ìgbà yẹn ni ọlọ́pàá kan wá fìtara sọ pé: “Ṣebí a sọ fún yín láàárọ̀ yìí!” Ààrẹ ṣọ́ọ̀ṣì yìí yíjú sí alàgbà náà, ó rẹ́rìn-ín ìyàngì, ó wá bi í pé: “Kí lẹ máa wá ṣe báyìí? Àwọn èèyàn wa ti kún inú gbọ̀ngàn. Ṣé ẹ máa ní káwọn ọlọ́pàá lé wa jáde ni?” Ó ti dọ́gbọ́n yí ọ̀rọ̀ náà kó bàa lè dà bíi pé àwọn Ẹlẹ́rìí náà ló ń ṣenúnibíni sáwọn! Kí ni àwọn ará wa máa ṣe?

18. Kí ni àwọn ará ṣe sí ẹ̀gbin tí wọ́n fi lọ̀ wọ́n, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

18 Àwọn Ẹlẹ́rìí náà yọ̀ọ̀da pé kí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yìí jọ́sìn fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, káwọn tó wá bẹ̀rẹ̀ Ìrántí Ikú Kristi. Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì náà kò parí ìjọsìn wọn lákòókò tí wọ́n dá, àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n jáde kúrò nínú gbọ̀ngàn náà, àwọn ará wọlé wọ́n sì ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ní ọjọ́ kejì, ìjọba gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ láti wádìí ohun tó ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò, ìgbìmọ̀ náà kàn án nípa fún àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yìí pé kí wọ́n kéde pé ààrẹ ṣọ́ọ̀ṣì ló dá wàhálà náà sílẹ̀, kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí. Ìgbìmọ̀ náà tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí bí wọ́n ṣe fi sùúrù bójú tó ipò líle koko náà. Ìsapá àwọn Ẹlẹ́rìí láti “jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn” ti sèso rere.

19. Kí ló tún lè mú ká máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn?

19 Ohun mìíràn tó lè mú ká máa bá àwọn ẹlòmíì gbé ní àlàáfíà ni pé ká máa sọ̀rọ̀ tútù. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò ohun tí ọ̀rọ̀ tútù túmọ̀ sí, bá a ṣe lè kọ́ ọ̀rọ̀ tútù àti bá a ṣe lè máa sọ ọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Ẹyín iná” ń tọ́ka sí ọ̀nà kan tí wọ́n máa ń gbà yọ́ irin nígbà àtijọ́. Wọ́n á kó ẹyín iná sókè irin náà àti sí abẹ́ rẹ̀ kí ìdàrọ́ inú rẹ̀ lè kúrò kó sì ṣẹ́ ku èyí tó jẹ́ ojúlówó. Bí a bá ń fi inú rere hàn sáwọn tí kò níwà rere, èyí lè mú kí wọ́n yíwà pa dà kí wọ́n sì máa hùwà tó dáa.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Kí nìdí táwọn tó wà nínú ayé fi máa ń bínú gan-an lóde òní?

• Àwọn àpẹẹrẹ wo nínú Bíbélì ló jẹ́ ká mọ ohun tí ṣíṣe àkóso ìbínú ẹni àti àìṣàkóso rẹ̀ máa ń yọrí sí?

• Kí ló yẹ ká ṣe bí arákùnrin tàbí arábìnrin wa kan bá ṣe ohun tó dùn wá?

• Kí ló yẹ ká ṣe bí àwọn ará ìta bá ṣe àtakò sí wa?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Síméónì àti Léfì pa dà, ìyẹn lẹ́yìn tí wọ́n ti kùnà láti ṣàkóso ìbínú wọn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn míì lè yí ìwà pa dà bá a bá fi inú rere hàn sí wọn