Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ̀mí Ń Wá Inú . . . Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”

“Ẹ̀mí Ń Wá Inú . . . Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”

“Ẹ̀mí Ń Wá Inú . . . Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”

“Ẹ̀mí ń wá inú ohun gbogbo, àní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.”—1 KỌ́R. 2:10.

1. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 2:10, ipa wo ni ẹ̀mí mímọ́ ń kó, ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ?

 AMỌRÍRÌ iṣẹ́ tí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń ṣe gan-an ni! Ìwé Mímọ́ pe ẹ̀mí mímọ́ ní olùrànlọ́wọ́ àti ẹ̀bùn. Ó tún sọ pé ó ń jẹ́rìí ó sì tún ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa. (Jòh. 14:16; Ìṣe 2:38; Róòmù 8:16, 26, 27) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ipa pàtàkì míì tí ẹ̀mí mímọ́ ń kó, ó ní: “Ẹ̀mí ń wá inú ohun gbogbo, àní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 2:10) Ká sòótọ́, Jèhófà ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ṣí àwọn òtítọ́ tẹ̀mí tó jinlẹ̀ payá. Tí kò bá sí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ ni, báwo là bá ṣe mọ àwọn ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe? (Ka 1 Kọ́ríńtì 2:9-12.) Àmọ́, ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìbéèrè ló jẹ yọ, irú bíi: Báwo ni ‘ẹ̀mí ṣe ń wá inú àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run’? Ipasẹ̀ ta ni Jèhófà gbà ṣí àwọn nǹkan wọ̀nyí payá ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni? Báwo ni ẹ̀mí ṣe ń wá inú àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lónìí, nípasẹ̀ àwọn wo sì ni?

2. Oríṣi ọ̀nà méjì wo ni ẹ̀mí mímọ́ ń gbà ṣiṣẹ́?

2 Jésù sọ ọ̀nà méjì tí ẹ̀mí mímọ́ ń gbà ṣiṣẹ́. Nígbà tó kù díẹ̀ kó kú, ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, èyí tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, èyíinì ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, tí yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín.” (Jòh. 14:26) Torí náà, ẹ̀mí mímọ́ ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àti aránnilétí. Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, ó máa jẹ́ kí àwọn Kristẹni lóye àwọn ohun tí kò yé wọn nígbà kan rí. Gẹ́gẹ́ bí aránnilétí, ó máa jẹ́ kí wọ́n máa rántí ohun tí wọ́n ti mọ̀, kí wọ́n sì fi í sílò.

Ní Ọ̀rúndún Kìíní

3. Ọ̀rọ̀ wo ni Jésù sọ tó fi hàn pé ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ni a ó máa ṣí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” payá?

3 Jésù fúnra rẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jẹ́ tuntun sí wọn. Àmọ́, wọ́n ṣì ní ohun púpọ̀ láti kọ́. Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Mo ṣì ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n mọ́ra nísinsìnyí. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí èyíinì bá dé, ẹ̀mí òtítọ́ náà, yóò ṣamọ̀nà yín sínú òtítọ́ gbogbo.” (Jòh. 16:12, 13) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, a ó máa ṣí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ tẹ̀mí payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.

4. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àti aránnilétí ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?

4 Lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, “ẹ̀mí òtítọ́ náà” dé, a sì tú u sórí àwọn Kristẹni tí iye wọ́n tó ọgọ́fà [120], tí wọ́n pé jọ sí Jerúsálẹ́mù. Wọ́n fojú rí i, wọ́n sì tún gbọ́ ìró rẹ̀. (Ìṣe 1:4, 5, 15; 2:1-4) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi onírúurú èdè sọ̀rọ̀ “nípa àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.” (Ìṣe 2:5-11) Àkókò nìyí láti ṣí nǹkan tuntun payá. Wòlíì Jóẹ́lì ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa títú ẹ̀mí mímọ́ jáde lọ́nà yẹn. (Jóẹ́lì 2:28-32) Àwọn tó wà níbẹ̀ ń rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà lọ́nà tí wọn kò retí, àpọ́sítélì Pétérù sì mú ipò iwájú nínú ṣíṣe àlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀. (Ka Ìṣe 2:14-18.) Ẹ̀mí mímọ́ wá tipa bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, ó mú kó ṣe kedere sí Pétérù pé ohun tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí yìí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ìgbàanì kan. Ẹ̀mí mímọ́ tún ṣe iṣẹ́ aránnilétí, torí pé ó mú kí Pétérù tọ́ka sí àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì, kódà ó tún tọ́ka sí méjì lára sáàmù tí Dáfídì kọ. (Sm. 16:8-11; 110:1; Ìṣe 2:25-28, 34, 35) Ohun tí gbogbo àwọn tó pé jọ rí tí wọ́n sì gbọ́ jẹ́ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.

5, 6. (a) Lẹ́yìn ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn ìbéèrè pàtàkì wo nípa májẹ̀mú tuntun ló nílò ìdáhùn? (b) Ipasẹ̀ àwọn wo ni àwọn ìbéèrè yìí ti jẹ yọ, báwo sì ni wọ́n ṣe dórí ìpinnu?

5 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ń fẹ́ ìlàlóye nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìbéèrè kan wà nípa májẹ̀mú tuntun, èyí tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì. Ṣé àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù nìkan ni májẹ̀mú tuntun náà wà fún? Ṣé àwọn Kèfèrí náà lè wọnú májẹ̀mú yẹn, ká sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n? (Ìṣe 10:45) Ṣé àwọn Kèfèrí tó jẹ́ ọkùnrin ní láti kọ́kọ́ dádọ̀dọ́, kí wọ́n sì wá sábẹ́ Òfin Mósè? (Ìṣe 15:1, 5) Ìbéèrè pàtàkì làwọn ìbéèrè yìí. A nílò ẹ̀mí Jèhófà láti wá inú àwọn ohun ìjìnlẹ̀ yìí. Ipasẹ̀ ta ni ẹ̀mí mímọ́ máa gbà dáhùn àwọn ìbéèrè náà?

6 Àwọn ọkùnrin tó wà ní ipò àbójútó tí àwọn ìbéèrè yìí jẹ yọ látọ̀dọ̀ wọn ni ẹ̀mí mímọ́ máa lò láti dáhùn rẹ̀. Pétérù, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wà ní ìpàdé tí ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe yìí, wọ́n sì ròyìn bí Jèhófà ṣe ń bá àwọn Kèfèrí tí kò dádọ̀dọ́ lò. (Ìṣe 15:7-12) Ìgbìmọ̀ olùdarí dórí ìpinnu lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí yẹ̀ wò ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́. Wọ́n wá kọ ìpinnu wọn ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ.—Ka Ìṣe 15:25-30; 16:4, 5; Éfé. 3:5, 6.

7. Ipasẹ̀ kí ni a gbà ṣí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ payá?

7 Ọ̀pọ̀ ọ̀ràn mìíràn la mú ṣe kedere nípasẹ̀ àwọn lẹ́tà onímìísí tí Jòhánù, Pétérù, Jákọ́bù àti Pọ́ọ̀lù kọ. Àmọ́, lẹ́yìn tí kíkọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ti parí, ìsọtẹ́lẹ̀ àti ṣíṣí ìmọ̀ payá lọ́nà ìyanu dáwọ́ dúró. (1 Kọ́r. 13:8) Ǹjẹ́ ẹ̀mí mímọ́ á ṣì máa ṣe iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àti aránnilétí? Ṣé á ṣì máa bá a lọ láti máa ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti wá inú àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run? Àsọtẹ́lẹ̀ fi hàn pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀.

Ní Àkókò Òpin

8, 9. Àwọn wo ni yóò máa “tàn” pẹ̀lú òye tẹ̀mí ní àkókò òpin?

8 Nígbà tí áńgẹ́lì kan ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò òpin, ó sọ pé: “Àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò sì máa tàn bí ìtànyòò òfuurufú; àwọn tí wọ́n sì ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo yóò máa tàn bí ìràwọ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé. . . . Ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.” (Dán. 12:3, 4) Àwọn wo ló máa ní ìjìnlẹ̀ òye àwọn wo lá sì máa tàn? Jésù sọ bá a ṣe máa mọ̀ ọ́n nínú àpèjúwe àlìkámà àti àwọn èpò. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó sọ pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo yóò máa tàn yòò bí oòrùn nínú ìjọba Baba wọn.” (Mát. 13:39, 43) Nínú àlàyé tí Jésù ṣe, ó fi hàn pé “àwọn olódodo” náà ni “àwọn ọmọ ìjọba náà,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró.—Mát. 13:38.

9 Ṣé gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni yóò máa “tàn”? A lè sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, torí pé gbogbo Kristẹni ló máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn àti gbígbé ara wa ró láwọn ìpàdé. Àwọn ẹni àmì òróró ló sì máa fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. (Sek. 8:23) Àmọ́, láfikún sí èyí, Ọlọ́run máa ṣí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ payá lákòókò òpin. A fi ‘èdìdì di’ àsọtẹ́lẹ̀ tí Dáníẹ́lì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ yìí títí di àkókò náà. (Dán. 12:9) Báwo ni ẹ̀mí ṣe máa wá inú àwọn ohun ìjìnlẹ̀ yìí, nípasẹ̀ àwọn wo sì ni?

10. (a) Ipasẹ̀ àwọn wo ẹ̀mí mímọ́ ń gbà ṣí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ payá láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí? (b) Ṣàlàyé bá a ṣe túbọ̀ mú kí òtítọ́ nípa tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Jèhófà yéni kedere.

10 Tí àkókò bá tó láti mú kí ọ̀ràn tẹ̀mí kan túbọ̀ ṣe kedere lóde òní, ẹ̀mí mímọ́ máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ọkùnrin tó wà nípò àbójútó tí wọ́n ń ṣojú “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ní oríléeṣẹ́ láti fòye mọ òtítọ́ jíjinlẹ̀ tí wọn kò lóye tẹ́lẹ̀. (Mát. 24:45; 1 Kọ́r. 2:13) Ìgbìmọ̀ Olùdarí á jùmọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò àlàyé tó bá yàtọ̀ sí ohun tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. (Ìṣe 15:6) Wọ́n á wá tẹ ohun tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ jáde fún àǹfààní gbogbo èèyàn. (Mát. 10:27) Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, a lè nílò ìlàlóye síwájú sí i, wọ́n á sì ṣàlàyé rẹ̀ bó ṣe rí gan-an.—Wo àpótí náà  “Bí Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Ṣí Ìtumọ̀ Tẹ́ńpìlì Tẹ̀mí Payá.”

Bá A Ṣe Lè Jàǹfààní Nínú Ipa Tí Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Kó Lónìí

11. Báwo ni gbogbo Kristẹni lóde òní ṣe ń jàǹfààní látinú ipa tí ẹ̀mí mímọ́ ń kó nínú ṣíṣí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run payá?

11 Gbogbo Kristẹni olóòótọ́ ló ń jàǹfààní nínú ipa tí ẹ̀mí mímọ́ ń kó nínú ṣíṣí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run payá. Bíi ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àwa náà lónìí ń kẹ́kọ̀ọ́, à ń rántí àwọn ohun tí ẹ̀mí mímọ́ ti ràn wá lọ́wọ́ láti lóye, a sì ń fi wọ́n sílò. (Lúùkù 12:11, 12) Kò dìgbà tá a bá kàwé rẹpẹtẹ ká tó lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ tá a ti tẹ̀ jáde. (Ìṣe 4:13) Báwo la ṣe lè mú kí òye wa nípa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run pọ̀ sí i? Jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

12. Ìgbà wo ló yẹ ká gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́?

12 Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́. Tá a bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ ohun kan tó dá lórí Ìwé Mímọ́, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà. Kódà bá a bá dá nìkan wà tàbí tí àkókò tá a ní kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, ó ṣì yẹ ká béèrè fún ẹ̀mí mímọ́. Tá a bá fìrẹ̀lẹ̀ tọrọ ẹ̀mí mímọ́ lọ́nà yìí, ó máa ń mú inú Baba wa ọ̀run dùn. Bí Jésù ṣe fi hàn, Jèhófà á fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ tá a bá béèrè fún un tọkàntọkàn.—Lúùkù 11:13.

13, 14. Ipa wo ni mímúra àwọn ìpàdé sílẹ̀ ń kó nínú lílóye àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run?

13 Múra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé. A ń gba ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu’ nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ẹrú náà. “Ẹrú” náà ń ṣe ojúṣe rẹ̀ nípa pípèsè àwọn ohun tó dá lórí Ìwé Mímọ́, wọ́n sì ń ṣètò bá a ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ wọn àti bá a ṣe máa ṣe àwọn ìpàdé. Wọ́n ti máa ń ronú jinlẹ̀ dáadáa kí wọ́n tó sọ pé kí “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará” gbé ìsọfúnni pàtó kan yẹ̀ wò. (1 Pét. 2:17; Kól. 4:16; Júúdà 3) Ńṣe là ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tẹ̀ lé àwọn àbá tí ẹrú olóòótọ́ bá fún wa.—Ìṣí. 2:29.

14 Tá a bá ń múra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀, ó dára ká máa wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n tọ́ka sí, ká sì sapá láti fòye mọ bó ṣe kan kókó tá à ń jíròrò lọ́wọ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, òye wa nínú Bíbélì á máa jinlẹ̀ sí i. (Ìṣe 17:11, 12) Tá a bá ń ṣí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n tọ́ka sí náà tá a sì ń kà wọ́n, wọ́n máa wọ̀ wá lọ́kàn débi pé ẹ̀mí mímọ́ á mú ká máa rántí wọn. Láfikún sí i, tá a bá fojú ara wa rí ẹsẹ náà lójú ìwé tó wà gan-an nínú Bíbélì, a ó lè fojú yàwòrán ibi tó wà, èyí á sì jẹ́ kó rọrùn láti wá a rí nígbà tá a bá nílò rẹ̀.

15. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ka àwọn ìtẹ̀jáde wa ní gbàrà tí wọ́n bá ti tẹ̀ wá lọ́wọ́, báwo lo ṣe ń ṣe é?

15 Máa ka àwọn ìtẹ̀jáde wa ní gbàrà tí wọ́n bá ti jáde. A kì í ka àwọn àpilẹ̀kọ kan láwọn ìpàdé wa, àmọ́ torí tiwa ni wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde. Kódà àwa náà wà lára àwọn tí wọ́n torí rẹ̀ ṣe ẹ̀dà ìwé ìròyìn wa tá à ń fi sóde. Nínú ayé tí gbogbo nǹkan ti lọ́jú pọ̀ yìí, a sábà máa ń dúró de ẹnì kan tàbí ohun kan. Tá a bá mú ìtẹ̀jáde tí a kò tíì kà tàbí èyí tó jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ la ṣì kà nínú rẹ̀ dání, a lè lo àǹfààní àkókò tá a fi ń dúró láti ka díẹ̀ lára rẹ̀. Àwọn míì máa ń tẹ́tí sí àwọn ìtẹ̀jáde wa tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà lórí ìrìn tàbí nígbà tí wọ́n bá ń wakọ̀. A fara balẹ̀ ṣèwádìí lórí àwọn ìtẹ̀jáde náà, gbogbo èèyàn ló sì lè kà wọ́n lákàgbádùn, wọ́n sì ń jẹ́ kí ìmọrírì tá a ní fún àwọn nǹkan tẹ̀mí pọ̀ sí i.—Háb. 2:2.

16. Àǹfààní wo ló wà nínú pé ká kọ àwọn ìbéèrè tó bá wá sí wa lọ́kàn sílẹ̀, ká sì wá ìdáhùn sí i?

16 Ṣe àṣàrò. Bó o bá ka Bíbélì tàbí àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì, ronú lé ohun tó o kà lórí. Bó o bá ṣe ń fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀nà tí wọ́n gbà gbé ọ̀rọ̀ inú àpilẹ̀kọ yẹn kalẹ̀, àwọn ìbéèrè lè wá sí ẹ lọ́kàn. O lè kọ àwọn ìbéèrè náà sílẹ̀, kó o sì wá ìdáhùn sí wọn lẹ́yìn náà. Ìgbà tá a bá ń wá ìdáhùn sí ohun kan tó gbà wá lọ́kàn la sábà máa ń ṣèwádìí tó jinlẹ̀ nípa rẹ̀. Òye tá a ní nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn yóò sì di ìṣúra fún wa, èyí tá a lè mú lò nígbàkigbà.—Mát. 13:52.

17. Báwo lo ṣe ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tàbí ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ?

17 Ṣètò àkókò fún ìjọsìn ìdílé. Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti fún wa ní ìṣírí láti ya àkókò kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ yálà lọ́wọ́ alẹ́ tàbí ní àkókò míì tó rọrùn, láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí láti fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Ìyípadà tó bá àkókò ìpàdé wa ti mú kó rọrùn láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò. Kí lẹ máa ń jíròrò nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé ní ìrọ̀lẹ́? Àwọn kan máa ń ka Bíbélì, wọ́n á ṣe ìwádìí lórí àwọn ẹsẹ tí kò yé wọn tó, wọ́n á sì kọ àlàyé ṣókí nípa rẹ̀ sínú Bíbélì wọn. Ọ̀pọ̀ ìdílé máa ń jùmọ̀ wá bí wọ́n ṣe lè fi ohun tí wọ́n bá gbé yẹ̀ wò sílò. Àwọn olórí ìdílé kan máa ń yan ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ìṣòro ìdílé wọn tàbí kí wọ́n jíròrò àkòrí tàbí ìbéèrè kan tí ìdílé lápapọ̀ fẹnu kò lé lórí pé kí àwọn jíròrò. Kò sí iyè méjì pé bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ẹ tún máa ronú kan àkòrí míì tẹ́ ẹ lè jíròrò. a

18. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fà sẹ́yìn nínú kíkọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

18 Jésù sọ pé ẹ̀mí mímọ́ máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́. Torí náà, kò yẹ ká fà sẹ́yìn nínú kíkọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Irú ẹ̀kọ́ òtítọ́ bẹ́ẹ̀ wà lára “ìmọ̀ Ọlọ́run” èyí tó ṣeyebíye, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì rọ̀ wá pé ká wá ìmọ̀ yẹn. (Ka Òwe 2:1-5.) Wọ́n ṣí púpọ̀ payá nípa “àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Bá a ṣe ń sapá láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀mí mímọ́ á máa ràn wá lọ́wọ́, torí pé, “ẹ̀mí ń wá inú ohun gbogbo, àní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.”—1 Kọ́r. 2:9, 10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2008, ojú ìwé 8.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Ọ̀nà méjì wo ni ẹ̀mí mímọ́ ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti wá inú “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”?

• Ipasẹ̀ ta ni ẹ̀mí mímọ́ gbà ṣí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ payá ní ọ̀rúndún kìíní?

• Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń mú kí àwọn ọ̀ràn túbọ̀ ṣe kedere lóde òní?

• Kí lo lè ṣe kó o lè jàǹfààní nínú ipa tí ẹ̀mí mímọ́ ń kó?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

 Bí Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Ṣí Ìtumọ̀ Tẹ́ńpìlì Tẹ̀mí Payá

Lára “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” tí ẹ̀mí mímọ́ ṣí payá ní ọ̀rúndún kìíní ni pé àgọ́ ìjọsìn tó wá di tẹ́ńpìlì nígbà tó yá ṣàpẹẹrẹ ohun gidi tó jẹ́ tẹ̀mí. Pọ́ọ̀lù pe ohun gidi náà ní “àgọ́ tòótọ́, tí Jèhófà gbé ró, kì í sì í ṣe ènìyàn.” (Héb. 8:2) Èyí jẹ́ tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí, ìyẹn ètò tí Ọlọ́run ṣe láti mú kí àwọn èèyàn lè tọ̀ ọ́ wá lọ́lá ẹbọ àti ipò àlùfáà Jésù Kristi.

“Àgọ́ tòótọ́” náà wá sójú táyé lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jésù ṣe batisí, tí Jèhófà sì tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tó máa di ẹbọ pípé. (Héb. 10:5-10) Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jésù, ó wọlé sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, ó sì gbé ìtóye ẹbọ rẹ̀ lọ ‘síwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀.’—Héb. 9:11, 12, 24.

Níbòmíì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé wọ́n “ń dàgbà di tẹ́ńpìlì mímọ́ fún Jèhófà.” (Éfé. 2:20-22) Ṣé tẹ́ńpìlì kan náà ni tẹ́ńpìlì yìí àti “àgọ́ tòótọ́” tó ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn Hébérù? Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà rò pé tẹ́ńpìlì kan náà ni. Ó jọ pé ńṣe là ń múra àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sílẹ̀ láti jẹ́ “òkúta” nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà lọ́run.—1 Pét. 2:5.

Àmọ́, bí ọdún 1971 ti ń sún mọ́lé, àwọn tó wà nípò àbójútó lára ẹgbẹ́ ẹrú náà bẹ̀rẹ̀ sí í fòye mọ̀ pé tẹ́ńpìlì tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú ìwé Éfésù kò lè jẹ́ tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Jèhófà. Tó bá jẹ́ pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó jíǹde ló para pọ̀ di “àgọ́ tòótọ́,” a jẹ́ pé lẹ́yìn àjíǹde wọn, èyí tó bẹ̀rẹ̀ nígbà “wíwàníhìn-ín Olúwa,” ni àgọ́ tòótọ́ náà ákọ́kọ́ fara hàn. (1 Tẹs. 4:15-17) Àmọ́, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí àgọ́ ìjọsìn, ó kọ̀wé pé: “Àgọ́ yìí gan-an jẹ́ àpèjúwe fún àkókò tí a yàn kalẹ̀ tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí.”Héb. 9:9.

Nípa fífara balẹ̀ fi ẹsẹ yìí wé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì, ó wá ṣe kedere pé kì í ṣe pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kì í sì í ṣe “òkúta” tí a ń múra sílẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé láti di ara tẹ́ńpìlì náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń sìn nínú àgbàlá àti nínú Ibi Mímọ́ tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, wọ́n sì ń rú “ẹbọ ìyìn” sí Ọlọ́run lójoojúmọ́.—Héb. 13:15.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Báwo la ṣe lè mú kí òye wa nípa “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” pọ̀ sí i?