Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Nífẹ̀ẹ́ sí Ìwé Kíkà àti Ìkẹ́kọ̀ọ́
Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Nífẹ̀ẹ́ sí Ìwé Kíkà àti Ìkẹ́kọ̀ọ́
KÒ SÍ ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti pinnu bí ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ rẹ ṣe máa rí tó kọjá pé kó o kọ́ wọn láti máa kàwé àti láti máa kẹ́kọ̀ọ́. Ìyẹn sì jẹ́ ohun tó máa ń fúnni láyọ̀! Ohun tó máa ń gbádùn mọ́ àwọn kan jù lọ nípa ìgbà ọmọdé wọn ni bí àwọn òbí wọn ṣe máa ń kàwé fún wọn. Ìwé kíkà àti àbájáde rẹ̀ máa ń gbádùn mọ́ni. Èyí sì ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, níwọ̀n bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti máa ń mú kó túbọ̀ rọrùn láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Kristẹni kan tó jẹ́ òbí sọ ohun tó kíyè sí, ó ní, “Àwọn ohun tá a mọrírì rẹ̀ jù lọ ni àwọn ohun tó bá ti ní í ṣe pẹ̀lú ìwé kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́.”
Bí àwọn ọmọ rẹ bá mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. (Sm. 1:1-3, 6) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò di dandan kéèyàn mọ ìwé kà kó tó lè rí ìgbàlà, síbẹ̀, Bíbélì fi hàn pé mímọ ìwé kà máa ń ṣèèyàn láǹfààní púpọ̀ nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, Ìṣípayá 1:3 sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tí ń gbọ́.” Àti pé, àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa pọkàn pọ̀, èyí tó jẹ́ apá pàtàkì nínú ìkẹ́kọ̀ọ́, wà lára ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú kó ṣe kedere nínú ìmọ̀ràn onímìísí tó kọ sí Tímótì, pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá.” Kí nìdí? “Kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere.”—1 Tím. 4:15.
Àmọ́ ṣá o, béèyàn bá mọ ìwé kà, tó sì mọ bó ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn kì í ṣe ẹ̀rí pé ó máa jàǹfààní látinú rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ní àǹfààní yìí kì í lò ó; kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní ni wọ́n ń lo àkókò wọn lé lórí. Torí náà, báwo ni àwọn òbí ṣe lè mú kó máa wu àwọn ọmọ wọn láti ní ìmọ̀ tó ṣàǹfààní?
Ìfẹ́ àti Àpẹẹrẹ Rẹ
Ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń dùn mọ́ àwọn ọmọdé bá a bá ń fìfẹ́ hàn sí wọn lákòókò tí ìkẹ́kọ̀ọ́ ń lọ lọ́wọ́. Owen àti Claudia, tí wọ́n jẹ́ Kristẹni sọ ohun tí wọ́n rántí nípa àwọn ọmọ wọn méjèèjì. Wọ́n sọ pé: “Ńṣe ni wọ́n máa ń retí ìgbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ máa bẹ̀rẹ̀, torí pé àkókò pàtàkì ló jẹ́ fún wọn, ọkàn wọn máa ń balẹ̀, ara sì máa ń tù wọ́n. Wọ́n kà á sí àkókò tá a máa ń fìfẹ́ hàn sí àwọn.” Kódà, bí àwọn ọmọ bá ti wà láàárín ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún, tó jẹ́ ìgbà tó máa ń nira jù lọ fáwọn ọ̀dọ́, ìfẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń fi hàn sí wọn lákòókò ìkẹ́kọ̀ọ́ á máa mú kí wọ́n ní èrò tó tọ́ nípa rẹ̀. Àwọn ọmọ Owen àti Claudia ti di aṣáájú-ọ̀nà báyìí, wọ́n sì ń bá a nìṣó láti máa jàǹfààní látinú bí àwọn òbí wọn ṣe mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́.
Ohun tó máa fi kún ìfẹ́ fún ìwé kíkà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ ni àpẹẹrẹ tiyín gẹ́g̣ẹ́ bí òbí. Bí àwọn ọmọ bá sábà máa ń rí i tí àwọn òbí wọn ń kàwé tí wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́, àwọn náà lè rí i bí ohun tó yẹ káwọn náà máa ṣe. Àmọ́, báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè fi irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ lélẹ̀ fún àwọn ọmọ yín, bí kò bá rọrùn fún ẹ̀yin fúnra yín láti máa kàwé? Ó lè gba pé kẹ́ ẹ túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìwé kíkà, tàbí kẹ́ ẹ yí ojú tẹ́ ẹ fi ń wò ó pa dà. (Róòmù 2:21) Bí ẹ̀yin òbí bá ń kàwé lójoojúmọ́, ó dájú pé ọwọ́ pàtàkì làwọn ọmọ yín náà á fi mú ìwé kíkà. Bẹ́ ẹ bá jẹ́ aláápọn, pàápàá jù lọ nínú kíka Bíbélì, mímúra àwọn ìpàdé sílẹ̀ àti ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, àwọn ọmọ yín á rí i pé wọ́n ṣe pàtàkì ní tòótọ́.
Nípa bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń fi hàn àti àpẹẹrẹ yín ṣe pàtàkì láti mú kí àwọn ọmọ yín nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà. Àmọ́, àwọn ìgbésẹ̀ tó wúlò wo lẹ lè gbé láti fún wọn níṣìírí?
Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Lọ́wọ́ Láti Nífẹ̀ẹ́ sí Ìwé Kíkà
Àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì wo ló yẹ kẹ́ ẹ gbé láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà? Láti kékeré ni kẹ́ ẹ ti jẹ́ kí ìwé wà fún wọn láti kà. Kristẹni alàgbà kan táwọn òbí rẹ̀ mú kó nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà dábàá pé: “Jẹ́ kó mọ́ àwọn ọmọ rẹ lára láti máa lo ìwé. Ìyẹn ló máa mú kí ìwé wù wọ́n, kí wọ́n sì máa fẹ́ láti lò ó nígbà gbogbo.” Ohun tó ń mú kí àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì, irú bíi Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà àti Ìwé Ìtàn Bíbélì, máa di kòríkòsùn fún ọ̀pọ̀ ọmọdé nìyẹn kó tó di pé wọ́n mọ ìwé kà. Bí ẹ̀yin àtàwọn ọmọ yín bá ń ka irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀, kì í wulẹ̀ ṣe pé ẹ̀ ń là wọ́n lójú sí sísọ èdè nìkan ni, àmọ́ ńṣe lẹ tún ń jẹ́ kí wọ́n mọyì “àwọn nǹkan ti ẹ̀mí” àti “àwọn ọ̀rọ̀ ti ẹ̀mí.”—1 Kọ́r. 2:13.
Ẹ máa kàwé sókè ketekete nígbà gbogbo. Ẹ jẹ́ kó mọ́ ọn yín lára láti máa kàwé pẹ̀lú àwọn ọmọ yín lójoojúmọ́. Bẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á mọ ọ̀rọ̀ pè dáadáa, ìwé kíkà á sì mọ́ wọn lára. Ọ̀nà tẹ́ ẹ gbà ń kàwé tún ṣe pàtàkì. Ẹ máa lo ìtara, àwọn náà á sì jẹ́ onítara. Kódà, àwọn ọmọ yín lè máa sọ fún yín pé kẹ́ ẹ ka ìtàn kan náà fún àwọn ní àkàtúnkà. Ẹ ṣáà máa kà á fún wọn! Bó bá yá, wọ́n á fẹ́ láti ka àwọn nǹkan míì tó yàtọ̀. Àmọ́, ẹ ṣọ́ra kó má lọ di pé ńṣe lẹ̀ ń fipá mú wọn láti kàwé. Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa kíkọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ “bí wọ́n ti lè fetí sílẹ̀ tó.” (Máàkù 4:33) Bí ẹ kò bá fipá mú àwọn ọmọ yín, ńṣe ni á máa wù wọ́n pé kí àkókò tẹ́ ẹ fi ìwé kíkà sí tètè tó, á sì túbọ̀ rọrùn fún yín láti mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà, èyí tó jẹ́ àfojúsùn yín.
Ẹ jẹ́ káwọn ọmọ máa kópa, kẹ́ ẹ sì máa jíròrò ohun tẹ́ ẹ bá kà. Ó máa dùn mọ́ ọn yín láti rí i pé láìpẹ́ láìjìnnà, ó máa ṣeé ṣe fáwọn ọmọ yín láti dá ọ̀rọ̀ mọ̀, láti pe ọ̀rọ̀, kí wọ́n sì lóye ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó pọ̀. Wọ́n á túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú bẹ́ ẹ bá ń jíròrò ohun tẹ́ ẹ kà pẹ̀lú wọn. Ìwé kan tó ṣàlàyé nípa bá a ṣe lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti mọ ìwé kà dáadáa sọ pé ìjíròrò máa ń ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti “kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó máa yẹ kí wọ́n dá mọ̀ kí wọ́n sì lóye nígbà tí wọ́n bá ń kàwé.” Ìwé náà wá sọ síwájú sí i pé: “Ní ti àwọn ọmọdé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ láti mọ ìwé kà, ọ̀rọ̀ sísọ ṣe pàtàkì, ó sì máa dáa kí irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa dá lórí ohun tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́.”
Ẹ jẹ́ káwọn ọmọ yín máa kàwé fún yín, kẹ́ ẹ sì rọ̀ wọ́n láti máa béèrè ìbéèrè. Ẹ̀yin fúnra yín lè béèrè ìbéèrè kẹ́ ẹ sì sọ ìdáhùn rẹ̀ fún wọn. Lọ́nà yẹn, àwọn ọmọ á mọ̀ pé ńṣe ni ìwé máa ń pèsè ìsọfúnni àti pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń kà ní ìtumọ̀. Ṣíṣe báyìí máa ṣèrànwọ́ jù lọ bó bá jẹ́ pé ìwé tó ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó jẹ́ àkọsílẹ̀ tó nítumọ̀ jù lọ, lẹ̀ ń kà.—Héb. 4:12.
Àmọ́ ṣá o, ẹ má ṣe gbàgbé pé ìwé kíkà kì í ṣe ohun tó rọrùn o. Ó máa ń gba àkókò àti ìdánrawò kéèyàn tó lè mọ ìwé kà dáadáa. a Torí náà, ẹ rí i dájú pé ẹ tanná ran ìfẹ́ tí àwọn ọmọ yín ní fún ìwé kíkà nípa fífún wọn ní ìṣírí. Bẹ́ ẹ bá ń fún àwọn ọmọ yín ní ìṣírí á jẹ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà.
Ìwé Kíkà Lérè Ó sì Ń Gbádùn Mọ́ni
Bó o bá ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti kẹ́kọ̀ọ́, ó máa mú kí ìwé tí wọ́n ń kà nítumọ̀. Nípasẹ̀ ìwé kíkà lèèyàn fi ń mọ òkodoro ọ̀rọ̀ àti bí wọ́n ṣe tán mọ́ra. Ó gba pé kéèyàn mètò, kó máa rántí nǹkan, kó sì máa fi ìsọfúnni sílò. Bí ọmọ kan bá ti mọ bó ṣe lè máa kẹ́kọ̀ọ́, tó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí Oníw. 10:10.
bí ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣe wúlò tó, á wá rí i pé ìwé kíkà lérè ó sì ń gbádùn mọ́ni.—Ẹ kọ́ wọn láwọn ohun tó ṣe pàtàkì nípa ìkẹ́kọ̀ọ́. Ìjọsìn Ìdílé nírọ̀lẹ́, ìjíròrò ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́, àtàwọn ìjíròrò míì tó fara jọ ọ́, máa ń jẹ́ àkókò tó dára jù lọ fún jíjẹ́ káwọn ọmọ mọ bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́. Bí wọ́n bá ń jókòó sójú kan tí wọ́n sì ń pe àfiyèsí sórí kókó ẹ̀kọ́ pàtó kan fún àkókò díẹ̀, ó máa jẹ́ kí wọ́n mọ béèyàn ṣe ń pọkàn pọ̀, èyí sì ṣe pàtàkì fún kíkẹ́kọ̀ọ́. Síwájú sí i, o lè ní kí ọmọ rẹ ọkùnrin sọ bí ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kà ṣe tan mọ́ ohun tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Èyí á jẹ́ kó mọ béèyàn ṣe ń ṣe ìfiwéra. Ó sì lè jẹ́ pé ọmọ rẹ obìnrin ni wàá ní kó ṣe àkópọ̀ ohun tó kà ní ọ̀rọ̀ ara rẹ̀. Èyí á jẹ́ kó yé e, á sì tún máa rántí rẹ̀. Ẹ tún lè kọ́ wọn láti máa ṣe àtúnyẹ̀wò, ìyẹn ni pé kí wọ́n sọ kókó pàtàkì inú àpilẹ̀kọ tí wọ́n kà lọ́nà mìíràn, èyí sì jẹ́ ọ̀nà míì tí wọ́n lè gbà máa rántí ohun tí wọ́n bá kọ́. Ẹ lè kọ́ àwọn ọmọdé pàápàá láti máa ṣe àkọsílẹ̀ ṣókí bí ìkẹ́kọ̀ọ́ bá ń lọ lọ́wọ́ tàbí láwọn ìpàdé ìjọ. Ìyẹn á sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ máa pọkàn pọ̀ bí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́! Àwọn ọ̀nà tó rọrùn yìí á mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ tu ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lára kó sì nítumọ̀.
Ṣètò àwọn nǹkan lọ́nà táá mú kó rọrùn láti kẹ́kọ̀ọ́. Ó máa rọrùn láti pọkàn pọ̀ bẹ́ ẹ bá ń kẹ́kọ̀ọ́ níbi tí atẹ́gùn wà, tó ní ìmọ́lẹ̀, tó pa rọ́rọ́, tó sì tuni lára. Àmọ́ ṣá o, ojú tí àwọn òbí fi ń wo ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣe pàtàkì. Màmá kan sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí máa wá àkókò fún ìwé kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Èyí máa ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti wà létòlétò. Wọ́n á mọ àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n mú ṣe àti ìgbà tó yẹ kí wọ́n ṣe é.” Ọ̀pọ̀ òbí ni kì í jẹ́ káwọn ọmọ ṣe nǹkan mìíràn bí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ bá ti tó. Ọ̀mọ̀wé kan tiẹ̀ sọ pé ọ̀nà yìí lèèyàn lè gbà kọ́ àwọn ọmọ láti mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́.
Tẹnu mọ́ bí ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ṣe pàtàkì tó. Lákòótán, ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti rí àǹfààní tó wà nínú ìkẹ́kọ̀ọ́. Torí kéèyàn bàa lè fi ohun tó ń kọ́ sílò lèèyàn ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́. Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ sọ pé: “Bí mi ò bá rí àǹfààní kankan nínú ohun tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kì í yá mi lára. Àmọ́, bí mo bá rí i pé ó wúlò fún mi, ńṣe ló máa ń wù mí láti lóye rẹ̀.” Bí àwọn ọ̀dọ́ bá rí i pé ẹ̀kọ́ ló máa jẹ́ káwọn lè ṣe ohun táwọn bá fẹ́ ṣe ní àṣeyege, wọ́n á fẹ́ láti fi ara fún un. Wọ́n á máa wọ̀nà fún ìkẹ́kọ̀ọ́, bí wọ́n ṣe ń wọ̀nà fún ìwé kíkà.
Èrè Tó Dára Jù Lọ
Àǹfààní tó wà nínú kíkàwé fún àwọn ọmọ yín pọ̀ débi pé a kò lè to gbogbo wọn lẹ́sẹẹsẹ síbí yìí. Díẹ̀ lára àwọn àǹfààní náà ni àṣeyọrí nílé ẹ̀kọ́, lẹ́nu iṣẹ́, nínú àjọṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn, lílóye àwọn nǹkan tó ń lọ nínú ayé àti àjọṣe tímọ́tímọ́ láàárín òbí àti ọmọ, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ìtẹ́lọ́rùn tí ìwé kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń mú wá.
Lékè gbogbo rẹ̀, bí àwọn ọmọ yín bá nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́, ó lè mú kí wọ́n di ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn Jèhófà. Ìfẹ́ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ló máa ṣí ọkàn wọn payá láti mọ “ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” àwọn òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́. (Éfé. 3:18.) Àmọ́ ṣá o, àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ní ohun tó pọ̀ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn. Bí àwọn òbí ṣe ń wá àkókò láti fún àwọn ọmọ wọn ní àfiyèsí, tí wọ́n sì ń sa gbogbo ipá wọn láti fi ẹsẹ̀ wọn lé ọ̀nà tó tọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn, wọ́n nírètí pé bó bá yá, àwọn ọmọ náà máa yàn láti di olùjọsìn Jèhófà. Bẹ́ ẹ ṣe ń kọ́ àwọn ọmọ yín láti mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ á mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Torí náà, ní gbogbo ọ̀nà, ẹ máa gbàdúrà fún ìbùkún Jèhófà bẹ́ ẹ ṣe ń ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́.—Òwe 22:6.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣòro gan-an fún àwọn ọmọdé tí wọ́n bá ní ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́. Ohun tí àwọn òbí lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ wà nínú Jí! February 22, 1997, ojú ìwé 3 sí 10.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìwé kíkà . . .
• Ẹ jẹ́ kí ìwé wà fún wọn láti kà
• Ẹ kàwé sókè ketekete
• Ẹ jẹ́ kí wọ́n lóhùn sí i
• Ẹ jíròrò ohun tẹ́ ẹ kà
• Ẹ ní káwọn ọmọ kàwé fún yín
• Ẹ rọ àwọn ọmọ yín láti máa béèrè ìbéèrè
Ìkẹ́kọ̀ọ́ . . .
• Ẹ fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òbí
• Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín pé kí wọ́n máa . . .
○ pa ọkàn pọ̀
○ ṣe ìfiwéra
○ ṣe àkópọ̀
○ ṣe àtúnyẹ̀wò
○ kọ àkọsílẹ̀
• Ẹ ṣètò àwọn nǹkan lọ́nà táá mú kó rọrùn fún yín láti kẹ́kọ̀ọ́
• Ẹ tẹnu mọ́ bí ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ṣe pàtàkì tó