“Irú Ènìyàn Wo Ni ó Yẹ Kí ẹ Jẹ́!”
“Irú Ènìyàn Wo Ni ó Yẹ Kí ẹ Jẹ́!”
“Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run!” —2 PÉT. 3:11.
1. Kí nìdí tí lẹ́tà kejì tí Pétérù kọ fi jẹ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú tó bọ́ sákòókò fún àwọn Kristẹni nígbà yẹn?
NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pétérù fi kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì, tí ó ní ìmísí, ìjọ Kristẹni ti fara da ọ̀pọ̀ inúnibíni kọjá, àmọ́ èyí kò bomi paná ìtara ìjọ Kristẹni tàbí kó dín ìbísí rẹ̀ kù. Torí náà, Èṣù dá ọgbọ́n míì tó ti kẹ́sẹ járí lọ́pọ̀ ìgbà kó tó di ìgbà yẹn. Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe sọ, Sátánì gbìyànjú láti mú àwọn èèyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àwọn olùkọ́ èké tí wọ́n ní “ojú tí ó kún fún panṣágà” àti “ọkàn-àyà tí a fi ojúkòkòrò kọ́.” (2 Pét. 2:1-3, 14; Júúdà 4) Ìyẹn ló mú kí lẹ́tà kejì tí Pétérù kọ jẹ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú àtọkànwá fún àwọn Kristẹni kí wọ́n bàa lè dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́.
2. Kí ni 2 Pétérù orí 3 dá lé, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?
2 Pétérù kọ̀wé pé: “Mo kà á sí pé ó tọ̀nà, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nínú àgọ́ yìí, láti ta yín jí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti rán yín létí, bí mo ti mọ̀ ní tòótọ́ pé bíbọ́ àgọ́ mi kúrò yóò wáyé láìpẹ́ . . . Nítorí náà, ṣe ni èmi yóò sa gbogbo ipá mi pẹ̀lú ní gbogbo ìgbà pé, lẹ́yìn lílọ mi, kí ẹ lè fúnra yín mẹ́nu kan nǹkan wọ̀nyí.” (2 Pét. 1:13-15) Bẹ́ẹ̀ ni, Pétérù mọ̀ pé àkókò ikú òun ti sún mọ́lé, ṣùgbọ́n kò fẹ́ kí wọ́n gbàgbé àwọn ìránnilétí tó fún wọn. Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn, torí pé ó di apá kan Bíbélì, gbogbo wa sì lè rí i kà lónìí. Ó sì yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí Orí 3 ìwé Pétérù kejì torí pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ dá lé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí àti ìparun àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ìṣàpẹẹrẹ. (2 Pét. 3:3, 7, 10) Ìmọ̀ràn wo ni Pétérù ní fún wa? Bá a bá fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò, báwo ló ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà?
3, 4. (a) Kí ni Pétérù sọ, ìkìlọ̀ wo ló sì fún wa? (b) Àwọn kókó mẹ́ta wo la máa gbé yẹ̀ wò?
3 Lẹ́yìn tí Pétérù ti ṣàlàyé nípa bí ayé Sátánì ṣe máa di èyí tí kò sí mọ́, ó sọ pé: “Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run!” (2 Pét. 3:11, 12) Kì í ṣe ìbéèrè ni Pétérù ń bi wá, ọ̀rọ̀ tó lè ta wá jí táá sì mú ká ronú jinlẹ̀ ló ń sọ. Pétérù mọ̀ pé kìkì àwọn tó bá ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń hùwà tó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni a óò pa mọ́ la “ọjọ́ ẹ̀san” Jèhófà tó ń bọ̀ wá já. (Aísá. 61:2) Torí náà, àpọ́sítélì yìí sọ síwájú sí i pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ẹ ti ní ìmọ̀ èyí tẹ́lẹ̀, ẹ ṣọ́ ara yín kí a má bàa mú yín lọ pẹ̀lú wọn [àwọn olùkọ́ èké] nípa ìṣìnà àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà, kí ẹ sì ṣubú kúrò nínú ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin tiyín.”—2 Pét. 3:17.
4 Níwọ̀n bí Pétérù ti wà lára àwọn tó ní “ìmọ̀ èyí tẹ́lẹ̀,” ó mọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ wà lójú fò gidigidi kí wọ́n lè pa ìwà títọ́ wọn mọ́. Nígbà tó ṣe, àpọ́sítélì Jòhánù wá ṣàlàyé kedere nípa ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Nínú ìran, ó rí bí a ṣe lé Sátánì kúrò ní ọ̀run àti bó ṣe ń fi “ìbínú ńlá” hàn sí àwọn “tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣí. 12:9, 12, 17) Ó dájú pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tá a fẹ̀mí yàn, tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin àtàwọn “àgùntàn mìíràn” olùṣòtítọ́, tí wọ́n jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn máa di aṣẹ́gun. (Jòh. 10:16) Àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan wá ńkọ́? Ṣé a ó máa bá a nìṣó láti jẹ́ adúróṣinṣin? A máa rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti jẹ́ adúróṣinṣin bá a bá ń sapá láti máa (1) fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù, (2) wà láìní èérí àti ní àìlábààwọ́n nínú ìwà wa àti nínú àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run, tá a sì ń (3) fi ojú tó tọ́ wo àdánwò. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Máa Fi Àwọn Ànímọ́ Ọlọ́run Ṣèwà Hù
5, 6. Àwọn ànímọ́ wo la gbọ́dọ̀ sapá láti ní, kí sì nìdí tí èyí fi gba “ìsapá àfi-taratara-ṣe”?
5 Ohun tí Pétérù fi bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà rẹ̀ kejì ni pé: “Nípa fífi gbogbo ìsapá àfi-taratara-ṣe ṣètìlẹyìn ní ìdáhùnpadà, ẹ pèsè ìwà funfun kún ìgbàgbọ́ yín, ìmọ̀ kún ìwà funfun yín, ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀ yín, ìfaradà kún ìkóra-ẹni-níjàánu yín, ìfọkànsin Ọlọ́run kún ìfaradà yín, ìfẹ́ni ará kún ìfọkànsin Ọlọ́run yín, ìfẹ́ kún ìfẹ́ni ará yín. Nítorí bí nǹkan wọ̀nyí bá wà nínú yín, tí wọ́n sì kún àkúnwọ́sílẹ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ di aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso ní ti ìmọ̀ pípéye nípa Olúwa wa Jésù Kristi.”—2 Pét. 1:5-8.
6 Ní tòótọ́, ó gba “ìsapá àfi-taratara-ṣe” ká tó lè máa lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ó gba ìsapá láti máa lọ sí gbogbo ìpàdé Kristẹni, láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ká sì ní ètò tó ṣe gúnmọ́ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́. Ó sì lè gba pé ká ṣiṣẹ́ kára ká sì ní ètò tó jíire ká tó lè máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé tó gbádùn mọ́ni, tó sì nítumọ̀. Àmọ́, gbàrà tí ètò tá a ṣe bá ti bọ́ sójú ẹ̀, kì í pẹ́ tí irú ètò tó jíire bẹ́ẹ̀ fi máa ń mọ́ni lára, pàápàá jù lọ tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀.
7, 8. (a) Kí ni àwọn kan ti sọ nípa Ìjọsìn Ìdílé ní ìrọ̀lẹ́? (b) Báwo lo ṣe ń jàǹfààní látinú Ìjọsìn Ìdílé rẹ?
7 Nínú ìwé tí arábìnrin kan kọ nípa ìṣètò Ìjọsìn Ìdílé, ó sọ pé: “Onírúurú nǹkan la máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ nígbà Ìjọsìn Ìdílé.” Arábìnrin míì sọ pé: “Kí n sòótọ́, kò wù mí bí wọ́n ṣe fòpin sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Òun ni ìpàdé tí mo gbádùn jù lọ. Àmọ́, ní báyìí tí Ìjọsìn Ìdílé ti rọ́pò rẹ̀, ó yé mi pé Jèhófà mọ ohun tá a nílò àti ìgbà tá a nílò rẹ̀.” Olórí ìdílé kan sọ pé: “Ìjọsìn Ìdílé ń ràn wá lọ́wọ́ gan-an ni. Bó ṣe jẹ́ ìpàdé tá a lè fi bójú tó ọ̀ràn ara wa gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya, ti mú kó ṣe wá láǹfààní gan-an! Àwa méjèèjì nímọ̀lára pé a túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú sí i nínú ọ̀nà tá a gbà ń fi èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù, ayọ̀ tá à ń rí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sì ń pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Olórí ìdílé míì sọ pé: “Àwọn ọmọ máa ń ṣe ìwádìí tiwọn, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀, wọ́n sì ń gbádùn rẹ̀. Ìṣètò náà mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà mọ àwọn ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wa, ó sì ń dáhùn àwọn àdúrà wa.” Ṣé irú ojú yìí ni ìwọ náà fi wo ìpèsè àgbàyanu tẹ̀mí yìí?
8 Má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun tí kò tó nǹkan dí Ìjọsìn Ìdílé lọ́wọ́. Tọkọtaya kan sọ pé: “Láti ọ̀sẹ̀ mẹ́rin sẹ́yìn, ohun kan máa ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo alẹ́ ọjọ́ Thursday tó fẹ́rẹ̀ẹ́ dá ìkẹ́kọ̀ọ́ wa dúró, ṣùgbọ́n a kò jẹ́ kó dí wa lọ́wọ́.” Àmọ́ ṣá o, ó lè pọn dandan nígbà míì pé kẹ́ ẹ yí ìtòlẹ́sẹẹsẹ yín pa dà. Síbẹ̀, ẹ pinnu pé ẹ kò ní jẹ́ kí ọ̀sẹ̀ kan kọjá lọ láìṣe Ìjọsìn Ìdílé!
9. Báwo ni Jèhófà ṣe gbé Jeremáyà ró, kí la sì rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ̀?
9 Àpẹẹrẹ àtàtà ni wòlíì Jeremáyà jẹ́ fún wa. Ó nílò ohun tó máa gbé e ró nípa tẹ̀mí èyí tó rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì mọrírì rẹ̀ gidigidi. Ìpèsè tẹ̀mí yẹn fún un ní okun tó mú kó fi ìfaradà wàásù fún àwọn èèyàn tí wọn kò fẹ́ gbọ́. Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà . . . sì wá dà bí iná tí ń jó, tí a sé mọ́ inú egungun mi.” (Jer. 20:8, 9) Ó tún ràn án lọ́wọ́ láti fara da àwọn àkókò tí nǹkan kò rọgbọ èyí tó ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù. Lóde òní, a ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lódindi. Bá a bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tá a sì sọ èrò Ọlọ́run di tiwa, bíi ti Jeremáyà àwa náà á lè máa fi ìdùnnú fara dà á nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a máa dúró bí olóòótọ́ nígbà àdánwò, a óò sì jẹ́ mímọ́ nínú ìwà àti nípa tẹ̀mí.—Ják. 5:10.
Ẹ Wà ní “Àìléèérí àti ní Àìlábààwọ́n”
10, 11. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti wà ní “àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n,” kí nìyẹn sì ń béèrè pé ká ṣe?
10 Àwa Kristẹni mọ̀ pé àkókò òpin là ń gbé yìí. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra kún inú ayé fọ́fọ́, àwọn nǹkan bí ìwọra, ìṣekúṣe àti ìwà ipá. A lè ṣe àkópọ̀ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì ń lò lọ́nà yìí: ‘Bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò bá ṣeé kó jìnnìjìnnì bá, bóyá á ṣeé ṣe láti mú wọn dẹ́ṣẹ̀.’ (Ìṣí. 2:13, 14) Nítorí èyí, a gbọ́dọ̀ fi ọ̀rọ̀ ìyànjú onífẹ̀ẹ́ tí Pétérù fúnni sọ́kàn, pé: “Ẹ sa gbogbo ipá yín kí [Ọlọ́run] lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.”—2 Pét. 3:14.
11 Gbólóhùn náà, “ẹ sa gbogbo ipá yín” jọ ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pétérù kọ́kọ́ sọ pé ká fi “gbogbo ìsapá àfi-taratara-ṣe ṣètìlẹyìn.” Ó dájú pé, Jèhófà, tó mí sí Pétérù láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sílẹ̀, mọ ohun tá a nílò ká bàa lè tiraka láti wà “ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n,” kí ìwà ìbàjẹ́ ayé Sátánì má bàa sọ wá di ẹlẹ́gbin. Ọ̀nà míì tá a lè máa gbà sapá ni pé ká máa dáàbò bo ọkàn-àyà wa nípa ṣíṣàì gba èrò búburú láyè láti mú wa ṣe ohun tí kò tọ́. (Ka Òwe 4:23; Jákọ́bù 1:14, 15.) Ó tún gba pé ká máa dúró gbọn-in lòdì sí àwọn tí ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni ń rú lójú tí wọ́n sì “ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ [wa] tèébútèébú.”—1 Pét. 4:4.
12. Kí ni ìwé Lúùkù 11:13 mú dá wa lójú?
12 Torí pé a jẹ́ aláìpé, ó máa ń ṣòro fún wa láti ṣe ohun tó tọ́. (Róòmù 7:21-25) Bá a bá nírètí nínú Jèhófà nìkan la lè ṣàṣeyọrí, torí pé ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ máa ń jẹ́ kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tó bá ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ tọkàntọkàn. (Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí yẹn á wá mú ká ní àwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ ká rí ojú rere Ọlọ́run, táá sì jẹ́ ká lè borí àwọn ìdẹwò àti àdánwò tá à ń kojú nínú ìgbésí ayé bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé.
Jẹ́ Kí Àdánwò Fún Ẹ Lókun
13. Nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò nínú ìgbésí ayé, kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á?
13 Níwọ̀n ìgbà tá a bá ṣì ń gbé nínú ètò àwọn nǹkan ògbólógbòó yìí, kò sí bí onírúurú àdánwò ò ṣe ní máa dojú kọ wá. Ṣùgbọ́n, dípò tí wàá fi rẹ̀wẹ̀sì, o ò ṣe wo àwọn àdánwò náà bí ohun tó máa fún ẹ láǹfààní láti fi bí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run ṣe jinlẹ̀ tó hàn, kó o sì sọ ìgbàgbọ́ rẹ nínú rẹ̀ àti nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dọ̀tun? Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn náà kọ̀wé pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ ní tòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yìí tí a ti dán wò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.” (Ják. 1:2-4) Má sì gbàgbé pé, “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.”—2 Pét. 2:9.
14. Báwo ni àpẹẹrẹ Jósẹ́fù ṣe ń fún ẹ níṣìírí?
14 Gbé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù tó jẹ́ ọmọ Jékọ́bù yẹ̀ wò, ẹni tí àwọn arákùnrin rẹ̀ tà sí oko ẹrú. (Jẹ́n. 37:23-28; 42:21) Ǹjẹ́ ìwà òǹrorò tí wọ́n hù sí Jósẹ́fù yẹn ba ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́? Ǹjẹ́ ó bínú sí Ọlọ́run lọ́nà kíkorò torí pé ó yọ̀ọ̀da kí ibi ṣẹlẹ̀ sí òun? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀! Àti pé ìyẹn gan-an kọ́ ni àdánwò tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù kẹ́yìn. Nígbà tó ṣe, wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé ó fẹ́ fipá bá aya ọ̀gá rẹ̀ lò pọ̀, wọ́n sì sọ ọ́ sẹ́wọ̀n. Síbẹ̀, ó tún fi hàn lẹ́ẹ̀kan sí i pé òun kò ní yẹsẹ̀ lórí ìfọkànsìn òun sí Ọlọ́run. (Jẹ́n. 39:9-21) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí àwọn àdánwò náà fún òun lókun, Ọlọ́run sì san èrè tó pọ̀ fún un.
15. Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Náómì?
15 Òótọ́ ni pé àdánwò lè bà wá lọ́kàn jẹ́ tàbí kó kó ìdààmú bá wa. Bóyá ó máa ń ṣe Jósẹ́fù náà bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ó dájú pé ó ṣe àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ bẹ́ẹ̀. Gbé àpẹẹrẹ ti Náómì yẹ̀ wò, ẹni tí ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì kú. Ó sọ pé: “Ẹ má pè mí ní Náómì. Márà [tó túmọ̀ sí “Korò”] ni kí ẹ máa pè mí, nítorí Olódùmarè ti mú kí ó korò gan-an fún mi.” (Rúùtù 1:20, 21) Ó rọrùn láti lóye ìdí tí Náómì fi sọ bẹ́ẹ̀, ìyẹn sì bá ìwà ẹ̀dá mu. Àmọ́, bíi ti Jósẹ́fù lòun náà ṣe, àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run kò yingin, kò sì dẹ́kun láti máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Jèhófà pẹ̀lú sì san èrè tó ṣeyebíye fún un. (Rúùtù 4:13- 17, 22) Ó ṣe tán, nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀, Ọlọ́run máa mú gbogbo àdánù tí Sátánì àti ayé búburú rẹ̀ ti fà kúrò. “Àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.”—Aísá. 65:17.
16. Ọwọ́ wo ló yẹ ká máa fi mú àdúrà gbígbà, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
16 Àdánwò yòówù kó dé bá wa, ìfẹ́ Ọlọ́run á máa bá a nìṣó láti gbé wa ró. (Ka Róòmù 8:35-39.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì kò ní yé máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, ó máa kùnà bá a bá ń jẹ́ ẹni tó “yè kooro ní èrò inú” tá a sì “wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ [wá] lọ́kàn.” (1 Pét. 4:7) Jésù sọ pé: “Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn.” (Lúùkù 21:36) Ẹ kíyè sí bí Jésù ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀bẹ̀,” tó jẹ́ irú àdúrà kan tá a gbà tọkàntọkàn. Bí Jésù ṣe gbà wá níyànjú pé ká máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀, mú ká rí i pé àkókò yìí kọ́ ló yẹ ká máa fi ọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ìdúró wa níwájú Jésù àti Baba rẹ̀. Kìkì àwọn tó bá wà ní ipò tó ṣètẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run ló máa la ọjọ́ Jèhófà já.
Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Dí Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
17. Bí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín bá jẹ́ ibi tó ṣòro láti wàásù, báwo lẹ ṣe lè jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ rere àwọn wòlíì ìgbà àtijọ́?
17 Lílọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí máa ń tù wá lára. Èyí mú ká rántí ọ̀rọ̀ Pétérù pé: “Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run!” (2 Pét. 3:11) Èyí tó gbawájú jù lọ nínú àwọn iṣẹ́ wọ̀nyẹn ni pípolongo ìhìn rere. (Mát. 24:14) Òótọ́ ni pé àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù kan lè ṣòro, bóyá nítorí ẹ̀mí ìdágunlá tàbí àtakò tàbí kó wulẹ̀ jẹ́ nítorí pé ọwọ́ àwọn èèyàn ti dí jù nítorí àníyàn ìgbésí ayé. Nígbà àtijọ́, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófànáà dojú kọ irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, wọn kò juwọ́ sílẹ̀, àmọ́ wọ́n ń mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán wọn tọ àwọn èèyàn náà lọ “léraléra.” (Ka 2 Kíróníkà 36:15, 16; Jer. 7:24-26) Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara dà á? Ojú tí Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ tó gbé lé wọn lọ́wọ́ ni wọ́n fi ń wò ó; wọn kò fi ojú ti ayé wò ó. Wọ́n tún kà á sí ọlá tó ga jù lọ láti jẹ́ ẹni tá à ń fi orúkọ Ọlọ́run pè.—Jer. 15:16.
18. Ipa wo ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run máa ní lórí ìgbéga orúkọ Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú?
18 Àwa pẹ̀lú ní àǹfààní láti máa polongo orúkọ Jèhófà àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé. Ronú nípa èyí ná: Nítorí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe, àwọn ọ̀tá Ọlọ́run kò ní lè wí àwíjàre kankan nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ wá sórí wọn ní ọjọ́ ńlá rẹ̀. Wọ́n á wá gbà bíi ti Fáráò ilẹ̀ Íjíbítì pé Jèhófà ló ń gbéjà ko àwọn. (Ẹ́kís. 8:1, 20; 14:25) Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jèhófà máa bọlá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ nípa mímú kó ṣe kedere pé aṣojú rẹ̀ ni wọ́n jẹ́ ní tòótọ́.—Ka Ìsíkíẹ́lì 2:5; 33:33.
19. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fẹ́ lo àkókò tí Jèhófà fi ń ní sùúrù yìí lọ́nà rere?
19 Ní apá ìparí lẹ́tà rẹ̀ kejì, Pétérù kọ̀wé sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà.” (2 Pét. 3:15) Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ jẹ́ ká máa lo àkókò tí Jèhófà fi ń ní sùúrù yìí lọ́nà rere. Lọ́nà wo? Ká máa fi àwọn ànímọ́ tó wu Ọlọ́run ṣèwà hù, ká máa wà ní “àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n,” ká máa fi ojú tó tọ́ wo àdánwò, ká sì máa jẹ́ kí ọwọ́ wá dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi ara wa sí ipò tí a ó fi lè gba ìbùkún ayérayé ní ìsopọ̀ pẹ̀lú “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.”—2 Pét. 3:13, 14.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo la ṣe lè ní àwọn ànímọ́ Ọlọ́run?
• Báwo la ṣe lè máa wà ní “àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n”?
• Kí la lè rí kọ́ látara Jósẹ́fù àti Náómì?
• Kí nìdí tó fi jẹ́ àǹfààní láti máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Kí ló máa mú kó ṣeé ṣe fún ẹ̀yin ọkọ àti ìdílé yín láti ní àwọn ànímọ́ tó wu Ọlọ́run?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kí la lè rí kọ́ látinú ọwọ́ tí Jósẹ́fù fi mú àdánwò?