Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Má Fòyà. Èmi Fúnra Mi Yóò Ràn Ọ́ Lọ́wọ́”

“Má Fòyà. Èmi Fúnra Mi Yóò Ràn Ọ́ Lọ́wọ́”

“Má Fòyà. Èmi Fúnra Mi Yóò Ràn Ọ́ Lọ́wọ́”

JÉSÙ kìlọ̀ ṣáájú fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èṣù yóò máa bá a nìṣó ní sísọ àwọn kan nínú yín sí ẹ̀wọ̀n kí a lè dán yín wò ní kíkún.” Àmọ́, ṣáájú ìkìlọ̀ yẹn, Jésù sọ pé: “Má fòyà àwọn ohun tí ìwọ máa tó jìyà rẹ̀.” Níwọ̀n bí Sátánì ti ń bá a nìṣó láti máa fi ìfinisẹ́wọ̀n halẹ̀ mọ́ wa ká lè dá iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run dúró, ó dájú pé àwọn aláṣẹ kan á ṣì máa ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni tòótọ́. (Ìṣí. 2:10; 12:17) Torí náà, kí ló máa mú wa gbára dì fún ètekéte Sátánì, ‘ká má sì fòyà,’ bí Jésù ṣe gbà wá nímọ̀ràn?

Lóòótọ́, kò sẹ́ni tí kò bẹ̀rù rí nínú gbogbo wa. Síbẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kó dá wa lójú pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a kò ní juwọ́ sílẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù. Lọ́nà wo? Ọ̀nà kan tí Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ ká lè kojú àtakò ni pé, ó ń jẹ́ ká mọ àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì àtàwọn aṣojú rẹ̀ ń lò. (2 Kọ́r. 2:11) Láti mọ ìdí tí ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. A tún máa ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìrírí òde òní nípa àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọ́n “dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.”—Éfé. 6:11-13.

Olùṣàkóso Búburú Kan Gbéjà Ko Ọba Kan Tó Bẹ̀rù Ọlọ́run

Ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Senakéríbù Ọba Ásíríà tó jẹ́ ẹni burúkú ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan tẹ̀ léra wọn. Èyí ló fún un ní ìgboyà tó fi wá dojú ìjà kọ àwọn èèyàn Jèhófà àti Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú wọn, níbi tí Hesekáyà Ọba tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. (2 Ọba 18:1-3, 13) Kò sí iyè méjì pé Sátánì ló wà nídìí ọ̀rọ̀ yìí, òun ló ń ti Senakéríbù kó bàa lè mú ètekéte Sátánì ṣẹ, kí ìjọsìn tòótọ́ lè pa rẹ́ ráúráú kúrò lórí ilẹ̀ ayé.—Jẹ́n. 3:15.

Senakéríbù wá rán àwọn aṣojú sí Jerúsálẹ́mù láti sọ fún wọn pé kí wọ́n juwọ́ sílẹ̀. Rábúṣákè wà lára àwọn aṣojú yẹn, òun ló sì ṣe olórí agbẹnusọ fún ọba. a (2 Ọba 18:17) Ńṣe ni Rábúṣákè fẹ́ kó jìnnìjìnnì bá àwọn Júù, kí wọ́n lè juwọ́ sílẹ̀ fún un láìjanpata. Ọgbọ́n wo ni Rábúṣákè dá láti mú àwọn Júù láyà pami?

Wọ́n Jẹ́ Olóòótọ́ Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Wọ́n Dá Wà

Rábúṣákè sọ fún àwọn aṣojú Hesekáyà pé: “Èyí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà wí: ‘Kí ni ohun ìgbọ́kànlé yìí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé? . . . Wò ó! ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé ìtìlẹyìn esùsú fífọ́ yìí, Íjíbítì, tí ó jẹ́ pé, bí ènìyàn bá fara tì í, ṣe ni yóò wọ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, tí yóò sì gún un.’” (2 Ọba 18:19, 21) Irọ́ gbuu ni ẹ̀sùn tí Rábúṣákè fi kan Hesekáyà yìí, torí pé kò wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Íjíbítì. Síbẹ̀, ẹ̀sùn yìí túbọ̀ mú kí ohun tí Rábúṣákè fẹ́ kí àwọn Júù rántí ṣe kedere, ìyẹn ni pé: ‘Kò sẹ́ni tó máa gbèjà yín. Ńṣe lẹ dá wà.’

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn alátakò ìjọsìn tòótọ́ ti lo ọ̀ràn ìdánìkanwà láti fi halẹ̀ mọ́ àwọn Kristẹni nítorí àtimú wọn láyà pami. Arábìnrin kan tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀, tí wọn ò sì jẹ́ kó wà láàárín àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ ohun tó ràn án lọ́wọ́ tí ìbẹ̀rù kò fi borí rẹ̀. Ó sọ pé: “Àdúrà ràn mí lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà . . . Mo rántí ọ̀rọ̀ ìdánilójú tó wà nínú Aísáyà 66:2, pé, Ọlọ́run máa ń wo ‘ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́, tí ó sì ní ìròbìnújẹ́ nínú ẹ̀mí.’ Ohun tó ń fún mi lókun tó sì ń tù mí nínú gan-an rèé.” Bákan náà, arákùnrin kan tó lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lóun nìkan nínú àhámọ́ sọ pé: “Mo wá rí i pé tí èèyàn bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, yàrá ẹ̀wọ̀n kékeré tún lè dà bí ayé àtọ̀run tí ohunkóhun kò ti lè dí èèyàn lọ́wọ́.” Ó dájú pé bí àwọn ará méjèèjì yìí ṣe ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà ló fún wọn lókun tí wọ́n nílò láti fara da ìdánìkanwà. (Sm. 9:9, 10) Àwọn tó ń ṣenúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí lè yà wọ́n kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́, àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n mọ̀ pé àwọn alátakò àwọn kò lè ya àwọn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà.—Róòmù 8:35-39.

Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká máa lo gbogbo àǹfààní tá a bá ní láti mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára! (Ják. 4:8) Ó yẹ ká máa bi ara wa nígbà gbogbo pé: ‘Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni gidi sí mi tó? Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń nípa lórí àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe lójoojúmọ́, yálà ìpinnu ńlá tàbí kékeré?’ (Lúùkù 16:10) Tá a bá ń ṣiṣẹ́ kára kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run má bàa bà jẹ́, kò sídìí fún wa láti máa bẹ̀rù. Nígbà tí wòlíì Jeremáyà ń gbẹnu sọ fún àwọn Júù tí ìyà ń jẹ, ó wí pé: “Mo ti ké pe orúkọ rẹ, Jèhófà, láti inú kòtò irú èyí tí ó jìn jù lọ . . . O ti sún mọ́ tòsí ní ọjọ́ tí mo ń pè ọ́ ṣáá. Ìwọ wí pé: ‘Má fòyà.’”—Ìdárò 3:55-57.

Iyè Méjì Tó Ń Gbìn Sọ́kàn Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Forí Ṣánpọ́n

Rábúṣákè lo ẹ̀tàn láti mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ṣiyè méjì. Ó wí pé: “[Jèhófà] ha kọ́ ni ẹni tí Hesekáyà ti mú àwọn ibi gíga rẹ̀ àti àwọn pẹpẹ rẹ̀ kúrò? . . . Jèhófà tìkára rẹ̀ wí fún mi pé, ‘Gòkè lọ gbéjà ko ilẹ̀ yìí, kí o sì run ún.’” (2 Ọba 18:22, 25) Rábúṣákè tipa bẹ́ẹ̀ sọ pé Jèhófà kò ní jà fún àwọn èèyàn rẹ̀, torí pé inú rẹ̀ kò dùn sí wọn. Àmọ́ irọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Inú Jèhófà dùn sí Hesekáyà àtàwọn Júù tó ti pa dà sínú ìjọsìn tòótọ́.—2 Ọba 18:3-7.

Lóde òní, àwọn tó ń ṣe inúnibíni lè sọ ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ òótọ́ kó lè dà bíi pé tiwa ni wọ́n ń ṣe, àmọ́ wọ́n á wá lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti da irọ́ pọ̀ mọ́ òótọ́ náà, kí wọ́n lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà míì wà tí wọ́n á sọ fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n pé arákùnrin kan tó ń mú ipò iwájú lórílẹ̀-èdè náà ti pa ìgbàgbọ́ rẹ̀ tì, pé kò sóhun tó burú bí àwọn náà bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì juwọ́ sílẹ̀. Àmọ́, irú èrò yìí kò mú kí àwọn Kristẹni tó jẹ́ olóye ṣiyè méjì.

Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan lásìkò Ogun Àgbáyé Kejì yẹ̀ wò. Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, wọ́n fi ìwé kan hàn án, tó fi hàn pé arákùnrin kan tó wà nípò àbójútó ti pa ìgbàgbọ́ rẹ̀ tì. Ẹni tó fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò béèrè bóyá ó gba Ẹlẹ́rìí yẹn gbọ́. Arábìnrin yẹn dáhùn pé, “Aláìpé ẹ̀dá ni.” Ó wá fi kún un pé, Ọlọ́run ń lò ó ní gbogbo àkókò tó fi ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. “Àmọ́ nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti yàtọ̀ sí ohun tí Bíbélì sọ yìí, kì í ṣe arákùnrin mi mọ́.” Arábìnrin olóòótọ́ yìí fọgbọ́n tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.”—Sm. 146:3.

Tá a bá ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń fi àwọn ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò, ìyẹn máa jẹ́ ká ṣọ́ra fún ọgbọ́n àyínìke tó lè sọ ìpinnu wa láti fara dà á dé òpin di èyí tí kò lágbára. (Éfé. 4:13, 14; Héb. 6:19) Torí náà, ká bàa lè gbára dì láti ronú lọ́nà tó já gaara nígbà tá a bá wà lábẹ́ àdánwò, a ní láti fọwọ́ pàtàkì mú kíka Bíbélì lójoojúmọ́ ká sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́. (Héb. 4:12) Bẹ́ẹ̀ ni o, àkókò yìí gan-an ló yẹ ká jẹ́ kí ìmọ̀ wa jinlẹ̀ sí i, ká sì mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. Arákùnrin kan tí wọ́n fi sínú àhámọ́ lóun nìkan fún ọ̀pọ̀ ọdún, sọ pé: “Mo fẹ́ gba gbogbo èèyàn níyànjú láti máa fi ìmọrírì hàn fún gbogbo oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń rí gbà, níwọ̀n bí a kò ti mọ ìgbà tó máa wúlò fún wa.” Ká sòótọ́, tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà ń pèsè fún wa lónìí, nígbà tá a bá dojú kọ ìṣòro nígbèésí ayé, ẹ̀mí mímọ́ á mú ohun tí a ti kọ́ “padà wá sí ìrántí [wa].”—Jòh. 14:26.

A Gbà Wá Lọ́wọ́ Ìhalẹ̀mọ́ni

Rábúṣákè gbìyànjú láti ṣẹ̀rù ba àwọn Júù. Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ mú ohun ìdúró wá fún olúwa mi ọba Ásíríà, kí ẹ sì jẹ́ kí n fún yín ní ẹgbàá ẹṣin láti rí i bóyá ẹ̀yin, níhà ọ̀dọ̀ yín, lè fi olùgun ẹṣin sórí wọn. Báwo wá ni ẹ ṣe lè yí ojú gómìnà kan padà lára èyí tí ó kéré jù lọ nínú àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi?” (2 Ọba 18:23, 24) Tá a bá fojú èèyàn wo ọ̀ràn yìí, Hesekáyà àtàwọn èèyàn rẹ̀ kò lè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ogun Asíríà alágbára.

Lóde òní, ó lè dà bíi pé àwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa lágbára gan-an, àgàgà tí àwọn alákòóso bá wà lẹ́yìn wọn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn nígbà inúnibíni tó wáyé lákòókò ìṣàkóso Násì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Wọ́n sapá láti halẹ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin wa tó lo ọ̀pọ̀ ọdún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n sọ bí wọ́n ṣe halẹ̀ mọ́ òun. Nígbà kan, ológun kan béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé o rí bí wọ́n ṣe yìnbọn pá arákùnrin rẹ? Kí ni ìyẹn kọ́ ẹ?” Arákùnrin náà dáhùn pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, mi ò sì ní yí pa dà.” Lẹ́yìn náà, ó wá halẹ̀ mọ́ mi pé: “Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ìwọ ni ikú kàn nìyẹn.” Síbẹ̀ náà, arákùnrin wa dúró gbọn-in, àwọn ọ̀tá ò sì halẹ̀ mọ́ ọn mọ́. Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti kojú irú ìhalẹ̀mọ́ni yẹn? Ìdáhùn rẹ̀ ni pé: “Mo gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ Jèhófà.”—Òwe 18:10.

Tá a bá ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú Jèhófà, apata ńlá tó máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ ohunkóhun tí Sátánì lè lò láti gbéjà kò wá kó sì pa wá lára nípa tẹ̀mí la gbé dání yẹn. (Éfé. 6:16) Torí náà, ó dára gan-an ká bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. (Lúùkù 17:5) A tún ní láti máa tẹ̀ lé àwọn ètò tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà ti ṣe láti mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ wa, a máa lókun tá a bá rántí ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Jèhófà sọ fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì, tó ní láti jíṣẹ́ fún àwọn èèyàn tó jẹ́ olórí kunkun. Jèhófà sọ fún un pé: “Mo ti mú kí ojú rẹ le gan-an bí ojú wọn, mo sì mú kí iwájú orí rẹ le gan-an bí iwájú orí wọn. Bí dáyámọ́ǹdì, tí ó le ju akọ òkúta lọ, ni mo ti ṣe iwájú orí rẹ.” (Ìsík. 3:8, 9) Bí ọ̀rọ̀ bá gbà bẹ́ẹ̀, Jèhófà lè mú kí àwa náà dúró gbọn-in bíi ti Ìsíkíẹ́lì.

Dènà Ìdẹwò

Àwọn alátakò ti rí i pé, bí gbogbo ọgbọ́n tí àwọn ta bá já sí pàbó, àwọn lè lo ẹ̀bùn tó fani mọ́ra láti ba ìwà títọ́ ẹnì kan jẹ́. Rábúṣákè náà ta ọgbọ́n yìí. Ó sọ fún àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù pé: “Èyí ni ohun tí ọba Ásíríà wí: ‘Ẹ túúbá fún mi, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá . . . títí èmi yóò fi wá, tí èmi yóò sì kó yín lọ ní ti tòótọ́ sí ilẹ̀ tí ó dà bí ilẹ̀ tiyín, ilẹ̀ ọkà àti ti wáìnì tuntun, ilẹ̀ oúnjẹ àti ti àwọn ọgbà àjàrà, ilẹ̀ àwọn igi ólífì àti ti oyin; kí ẹ sì máa wà láàyè nìṣó, kí ẹ má bàa kú.’” (2 Ọba 18:31, 32) Jíjẹ búrẹ́dì òòjọ́ àti mímu wáìnì tuntun ti ní láti fa àwọn èèyàn tó ti wà nínú àhámọ́ yìí lọ́kàn mọ́ra!

Wọ́n ti fi irú jíjẹ, mímu bẹ́ẹ̀ lọ míṣọ́nnárì kan tó wà lẹ́wọ̀n rí kí wọ́n lè sọ ìpinnu rẹ̀ di èyí tí kò lágbára. Wọ́n sọ fún un pé àwọn máa mú un kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n láti lọ lo oṣù mẹ́fà nínú “ilé tó tura” nínú “ọgbà tó lẹ́wà,” kó bàa lè ronú lórí ohun tí wọ́n fi lọ̀ ọ́. Àmọ́ ṣá, arákùnrin náà wà lójúfò nípa tẹ̀mí, kò sì juwọ́ sílẹ̀ lórí àwọn ìlànà Kristẹni. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Àlàyé tó ṣe lẹ́yìn náà rèé: “Mo máa ń ronú nípa Ìjọba Ọlọ́run pé ó jẹ́ ìrètí tòótọ́. . . . Ìmọ̀ tí mo ní nípa Ìjọba Ọlọ́run, bó ṣe dá mi lójú, tí mi ò sì ṣiyè méjì nípa rẹ̀ fúngbà kankan, ló fún mi lókun, kò sí ohun tí wọ́n lè fi tàn mí.”

Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe jẹ́ gidi sí wa tó? Bàbá ńlá náà Ábúráhámù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Jésù fúnra rẹ̀ fara da àdánwò líle koko, torí pé ó dá wọn lójú pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ohun gidi. (Fílí. 3:13, 14; Héb. 11:8-10; 12:2) Tá a bá ń bá a nìṣó láti fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa, tá a sì ń fi ìbùkún ayérayé tó máa mú wá fún wa sọ́kàn, àwa náà lè dènà ìdẹwò gbígba ohun táá jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ àdánwò fúngbà díẹ̀.—2 Kọ́r. 4:16-18.

Jèhófà Kò Ní Fi Wá Sílẹ̀

Pẹ̀lú gbogbo ìsapá Rábúṣákè láti ṣẹ̀rù ba àwọn Júù, Hesekáyà àtàwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ gbọ́kàn lé Jèhófà. (2 Ọba 19:15, 19; Aísá. 37:5-7) Jèhófà sì dáhùn àdúrà tí wọ́n gbà fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tó rán áńgẹ́lì kan ṣoṣo láti ṣá ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] ọmọ ogun balẹ̀ nínú ibùdó àwọn ará Ásíríà. Díẹ̀ ló ṣẹ́ kù lára àwọn ọmọ ogun Senakéríbù, torí náà, lọ́jọ́ kejì, ó yára fi ìtìjú pa dà sí olú ìlú rẹ̀, Nínéfè.—2 Ọba 19:35, 36.

Ó ṣe kedere pé Jèhófà kò fi àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e sílẹ̀. Àpẹẹrẹ òde òní nípa àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó dúró gbọn-in nígbà àdánwò fi hàn pé ohun kan náà ni Jèhófà ṣì ń ṣe lóde òní. Abájọ tí Baba wa ọ̀run fi mú un dá wa lójú pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’”—Aísá. 41:13.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Rábúṣákè jẹ́ orúkọ oyè ìjòyè ọlọ́lá kan lórílẹ̀-èdè Ásíríà. Àkọsílẹ̀ yẹn kò sọ orúkọ tí ọkùnrin náà ń jẹ́ gangan.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

Ó lé ní ìgbà ọgbọ̀n [30] tí Jèhófà fúnra rẹ̀ mú un dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lójú nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Má fòyà”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Báwo làwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Rábúṣákè ṣe jọ èyí tí àwọn ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run ń lò lóde òní?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ nígbà àdánwò