Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Kó Ipa Tó Jọjú Nínú Ìkórè Tẹ̀mí

Máa Kó Ipa Tó Jọjú Nínú Ìkórè Tẹ̀mí

Máa Kó Ipa Tó Jọjú Nínú Ìkórè Tẹ̀mí

‘Máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.’—1 KỌ́R. 15:58.

1. Kí ni Jésù ké sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣe?

 NÍGBÀ tí Jésù ń rìnrìn-àjò lágbègbè Samáríà lọ́wọ́ ìparí ọdún 30 Sànmánì Kristẹni, ó dúró díẹ̀ láti sinmi létí kànga kan nítòsí ìlú Síkárì. Ibẹ̀ ló ti sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.” (Jòh. 4:35) Kì í ṣe ìkórè àwọn ohun ọ̀gbìn ni Jésù ń sọ, ìkórè tẹ̀mí ló ní lọ́kàn, ìyẹn kíkó àwọn èèyàn tó lọ́kàn títọ́ jọ láti di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Torí náà, ńṣe ló ń ké sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkórè náà. Iṣẹ́ pọ̀ láti ṣe, àkókò díẹ̀ ló sì wà láti ṣe iṣẹ́ ọ̀hún láṣeparí!

2, 3. (a) Kí ló fi hàn pé àkókò ìkórè la wà yìí? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Ó yẹ kí àwa tá à ń gbé lóde òní fi ọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa ìkórè. Àkókò tí aráyé lápapọ̀ dà bíi pápá, tó “funfun fún kíkórè” la wà yìí. Lọ́dọọdún, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń gba ìkésíni láti wá gba òtítọ́ tó ń fúnni ní ìyè, tí a sì ń batisí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun. Àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti máa kópa nínú iṣẹ́ ìkórè ńlá tó ju ti ìgbàkígbà rí lọ, lábẹ́ ìdarí Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ọ̀gá ìkórè náà. Ṣé ò ń ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe” nínú iṣẹ́ ìkórè yìí?—1 Kọ́r. 15:58.

3 Láàárín ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó múra àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ ìkórè. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa ṣàgbéyẹ̀wò mẹ́ta lára àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì pàtàkì tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan máa jẹ́ ká mọ ànímọ́ tó ṣe pàtàkì pé ká ní bá a ṣe ń sapá láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ kíkó àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ lóde òní. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ànímọ́ yìí yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.

Ìrẹ̀lẹ̀ Ṣe Pàtàkì

4. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ bí ìrẹ̀lẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó?

4 Fojú inú wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀: Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣẹ̀ṣẹ̀ jiyàn tán nípa ẹni tó tóbi jù láàárín wọn ni. Ó ṣeé ṣe kó ṣì hàn lójú wọn pé wọn ò fọkàn tán ara wọn, kí wọ́n sì ní ìkùnsínú síra wọn. Jésù wá pe ọmọdé kan pé kó dúró láàárín wọn. Ó pe àfiyèsí wọn sí ọmọdé náà, ó sì sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yìí ni ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú ìjọba ọ̀run.” (Ka Mátíù 18:1-4.) Dípò tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn á fi máa ronú bí àwọn èèyàn ayé, tó jẹ́ pé agbára, ọrọ̀ àti ipò ni wọ́n fi ń díwọ̀n èèyàn ńlá, wọ́n ní láti lóye pé ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ ẹni ńlá gbọ́dọ̀ ‘rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀’ lójú àwọn ẹlòmíì. Bí wọ́n bá fi hàn pé àwọn ní ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ nìkan ni Jèhófà máa tó bù kún wọn táá sì lò wọ́n.

5, 6. Kí nìdí tó o fi gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kó o tó lè máa kó ipa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìkórè náà? Ṣe àpèjúwe.

5 Títí dòní olónìí, agbára, ọrọ̀ àti ipò ni ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé máa ń fi gbogbo ìgbésí ayé wọn lépa. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àkókò díẹ̀ ni wọ́n máa ń ní fún nǹkan tẹ̀mí, tí wọ́n bá tiẹ̀ ní àkókò fún un rárá. (Mát. 13:22) Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà yàtọ̀, wọ́n máa ń láyọ̀ láti ‘rẹ ara wọn sílẹ̀’ lójú àwọn ẹlòmíì, kí wọ́n lè rí ìbùkún àti ìtẹ́wọ́gbà Ọ̀gá ìkórè náà.—Mát. 6:24; 2 Kọ́r. 11:7; Fílí. 3:8.

6 Gbé àpẹẹrẹ Arákùnrin Francisco tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù yẹ̀ wò. Nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, ó fi yunifásítì sílẹ̀ kó lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wá fẹ́ ṣe ìgbéyàwó, ǹ bá wá iṣẹ́ táá máa mú owó gidi wọlé fún èmi àti ìyàwó mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, a pinnu láti má ṣe lépa ọrọ̀, a sì ń bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nìṣó. Nígbà táá wá ní àwọn ọmọ, ìṣòro wa túbọ̀ pọ̀ sí i. Àmọ́, Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe yí ìpinnu wa pa dà.” Arákùnrin Francisco parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí: “Ó lé ní ọgbọ̀n [30] ọdún tí mo fi sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, mo sì tún ní àǹfààní ọ̀pọ̀ àkànṣe iṣẹ́ ìsìn míì. Kò sígbà kankan tá a kábàámọ̀ pé a pinnu láti má ṣe lépa ọrọ̀.”

7. Ǹjẹ́ o ti gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Róòmù 12:16 sílò rí?

7 Tó o bá kọ àwọn “ohun gíga fíofío” tó wà nínú ayé yìí, tó o sì jẹ́ “kí a máa ṣamọ̀nà [rẹ] lọ pẹ̀lú àwọn ohun rírẹlẹ̀,” ìwọ náà lè máa fojú sọ́nà láti gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún àtàwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ìkórè náà.—Róòmù 12:16; Mát. 4:19, 20; Lúùkù 18:28-30.

Jíjẹ́ Aláápọn Ń Mérè Wá

8, 9. (a) Sọ àpèjúwe Jésù nípa tálẹ́ńtì ní ṣókí. (b) Àwọn wo ni àpèjúwe yìí lè fún ní ìṣírí gan-an?

8 Ànímọ́ míì tá a tún nílò ká lè máa kó ipa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìkórè náà ni pé ká jẹ́ aláápọn. Jésù ṣàpèjúwe èyí nínú àkàwé tó ṣe nípa tálẹ́ńtì. a Àkàwé náà dá lórí ọkùnrin kan tó fa ohun ìní rẹ̀ lé àwọn ẹrú rẹ̀ mẹ́ta lọ́wọ́ nígbà tó fẹ́ rìnrìn-àjò. Ẹrú àkọ́kọ́ gba tálẹ́ńtì márùn-ún, èkejì gba tálẹ́ńtì méjì; ó sì fún ọ̀kan tó kù ní tálẹ́ńtì kan. Lẹ́yìn tí ọ̀gá wọn rìnrìn àjò, ẹrú àkọ́kọ́ àti ẹrú kejì ṣiṣẹ́ kára nípa fífi tálẹ́ńtì wọn “ṣòwò.” Àmọ́, “onílọ̀ọ́ra” ni ẹrú kẹta, kò sì ṣe bíi tàwọn tó kù. Ńṣe ló lọ ri tálẹ́ńtì tirẹ̀ mọ́lẹ̀. Nígbà tí ọkùnrin náà pa dà dé, ó san àwọn ẹrú méjì tó kù lẹ́san nípa yíyàn wọ́n sípò “lórí ohun ìní púpọ̀.” Ó gba tálẹ́ńtì tó fún ẹrú kẹta náà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì lé e kúrò ní ilé rẹ̀.—Mát. 25:14-30.

9 Kò sí iyè méjì pé ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́ ni pé kó o máa fara wé àwọn ẹrú tó jẹ́ aláápọn nínú àkàwé Jésù, kó o sì máa kó ipa tó jọjú nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́ tí ipò nǹkan kò bá jẹ́ kó o lè ṣe tó bó ṣe yẹ ńkọ́? Ó ṣeé ṣe kí ètò ọrọ̀ ajé tí kò fara rọ mú kó o máa fi ọ̀pọ̀ àkókò ṣiṣẹ́ kó o lè máa pèsè fún ìdílé rẹ. Ó sì lè jẹ́ pé ara tó ti ń dara àgbà tàbí àìlera míì ló ń yọ ẹ́ lẹ́nu. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, àkàwé Jésù nípa tálẹ́ńtì á fún ẹ níṣìírí gan-an.

10. Báwo ni ọ̀gá inú àkàwé nípa tálẹ́ńtì ṣe lo ìfòyemọ̀, báwo lèyí sì ṣe fún ẹ ní ìṣírí?

10 Kíyè sí i pé ọ̀gá inú àkàwé náà mọ ibi tí agbára ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹrú rẹ̀ mọ. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé, ó “fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú agbára ìlèṣe-nǹkan tirẹ̀.” (Mát. 25:15) Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí ẹrú àkọ́kọ́ fi jèrè gan-an ju ẹrú kejì lọ. Àmọ́, ọ̀gá náà mọ̀ pé àwọn méjèèjì ló jẹ́ aláápọn, abájọ tó fi pè wọ́n ní “ẹrú rere àti olùṣòtítọ́” tó sì fún wọn ní èrè kan náà. (Mát. 25:21, 23) Bákan náà, Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ọ̀gá ìkórè náà mọ̀ pé ipò tó o wà máa nípa lórí ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Kò ní gbàgbé ìsapá tó o ṣe tọkàntọkàn láti sìn ín, á sì fún ẹ ní èrè tó tọ́ sí ẹ.—Máàkù 14:3-9; ka Lúùkù 21:1-4.

11. Ṣàpèjúwe bí jíjẹ́ aláápọn nígbà tí ipò nǹkan bá le ṣe máa ń yọrí sí ìbùkún.

11 Àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Selmira lórílẹ̀-èdè Brazil jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe ìgbà tí nǹkan bá ń lọ dáadáa fúnni nìkan lèèyàn lè jẹ́ aláápọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ní ogún ọdún sẹ́yìn, àwọn olè yìnbọn pa ọkọ rẹ̀, ó sì fi ọmọ mẹ́ta sílẹ̀ fún un láti tọ́. Iṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ni arábìnrin yìí ń ṣe, ó sì gba pé kó máa ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí, á sì tún rìnrìn-àjò ọ̀nà jíjìn nínú ọkọ̀ tí èrò kún inú rẹ̀ fọ́fọ́. Láìka gbogbo ìṣòro yìí sí, ó ṣètò àkókò rẹ̀ kó lè ṣeé ṣe fún un láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Lẹ́yìn náà, méjì lára àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta di aṣáájú-ọ̀nà déédéé pẹ̀lú rẹ̀. Ó sọ pé: “Bí ọdún ti ń gorí ọdún, mo ti kọ́ àwọn èèyàn tó ju ogún [20] lọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ti di ara ‘ìdílé’ mi. Títí di báyìí, wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi, a sì jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wa. Ìṣúra tí kò ṣeé fowó rà lèyí jẹ́.” Ọ̀gá ìkórè náà ti san Selmira lẹ́san fún ìsapá aláápọn rẹ̀!

12. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ aláápọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

12 Tí ipò tó o wà báyìí kò bá jẹ́ kó o lè máa lo wákàtí tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, o ṣì lè gbìyànjú láti fi kún ohun tó ò ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìkórè náà nípa jíjẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ túbọ̀ sèso. Tó o bá ń fi àwọn àbá tó gbéṣẹ́ tá à ń rí gbà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn sílò, wàá túbọ̀ mú ọ̀nà tó ò ń gbà wàásù sunwọ̀n sí i, wàá sì tún lè wá àwọn ọ̀nà míì tó o lè máa gbà wàásù. (2 Tím. 2:15) Bákan náà, tó bá ṣeé ṣe, o lè tún àwọn ètò kan ṣe tàbí kó o yááfì àwọn ìgbòkègbodò tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan, kó o lè máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá pẹ̀lú ìjọ rẹ déédéé.—Kól. 4:5.

13. Kí ló máa jẹ́ kó o di aláápọn, kó o sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀?

13 Ìfẹ́ àti ìmọrírì tá a ní fún Ọlọ́run ló máa ń mú ká jẹ́ aláápọn. (Sm. 40:8) Ẹrú kẹta tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àkàwé yẹn bẹ̀rù ọ̀gá rẹ̀, ojú ẹni tó máa ń rin kinkin, tí kì í sì í fòye báni lò ló fi ń wo ọ̀gá rẹ̀. Torí náà, ọkùnrin náà ri tálẹ́ńtì tirẹ̀ mọ́lẹ̀, dípò tí ì bá fi lò ó láti mú kí ohun ìní ọ̀gá rẹ̀ pọ̀ sí i. Ká lè yẹra fún irú ìwà àìka-nǹkan-sí bẹ́ẹ̀, a ní láti sún mọ́ Jèhófà tí í ṣe Ọ̀gá ìkórè náà tímọ́tímọ́, ká má sì jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ bà jẹ́. Ya àkókò sọ́tọ̀ fún kíkẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó fani mọ́ra, ìyẹn ìfẹ́, sùúrù àti àánú. Lọ́nà yẹn, ọkàn rẹ á sún ẹ láti máa ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.—Lúùkù 6:45; Fílí. 1:9-11.

“Ẹ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́”

14. Ohun pàtàkì wo ni Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn tó fẹ́ máa ṣiṣẹ́ ìkórè ṣe?

14 Àpọ́sítélì Pétérù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó sì lò ó láti ṣàlàyé ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé ṣe. Ó ní: “Ní ìbámu pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ tí ó pè yín, kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín, nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.’” (1 Pét. 1:15, 16; Léf. 19:2; Diu. 18:13) Gbólóhùn yìí tẹnu mọ́ bó ṣe pọn dandan tó pé káwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkórè wà ní mímọ́ nínú ìwà àti nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. A lè kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ọlọ́run ń béèrè yìí bá a bá ṣe ohun tó máa jẹ́ ká di ẹni tá a wẹ̀ mọ́, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Báwo lá ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ òtítọ́ ló máa ràn wá lọ́wọ́.

15. Kí ni òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára láti ṣe fún wa?

15 A fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí í ṣe òtítọ́ wé omi tó máa ń fọ nǹkan mọ́. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run, bí ìyàwó oníwà mímọ́ fún Kristi, ẹni tó wẹ̀ ẹ́ mọ́ “pẹ̀lú ìwẹ̀ omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà . . . , pé kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti láìsí àbààwọ́n.” (Éfé. 5:25-27) Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù pẹ̀lú ti sọ̀rọ̀ nípa agbára ìwẹ̀mọ́ tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní, èyí tí òun fúnra rẹ̀ polongo. Nígbà tí ó ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ ti mọ́ nísinsìnyí nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín.” (Jòh. 15:3) Torí náà, òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní agbára láti sọ èèyàn di mímọ́ nínú ìwà àti nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Bá a bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ wá di mímọ́ lọ́nà yìí nìkan ni ìjọsìn wa fi lè ní ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Rẹ̀.

16. Báwo la ṣe lè máa wà ní mímọ́ nínú àjọṣe wa àti nínú ìwà wa?

16 Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ká bàa lè di òṣìṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìkórè Ọlọ́run, akọ́kọ́ mú gbogbo àṣà tó ń sọni di ẹlẹ́gbin nínú ìwà wa àti nínú àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run kúrò nínú ìgbésí ayé wa. Ó dájú pé kí àǹfààní tá a ní láti jẹ́ òṣìṣẹ́ ìkórè yìí má bàa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú bá a ṣe ń fi àwọn ìlànà Jèhófà, èyí tí kò ṣeé fọwọ́ yẹpẹrẹ mú, sílò nínú ìwà wa àti nínú àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. (Ka 1 Pétérù 1:14-16.) Bá a ṣe ń rí i pé ara wa wà ní mímọ́ tónítóní, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe gbọ́dọ̀ máa jọ̀wọ́ ara wa nígbà gbogbo láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí í ṣe òtítọ́ wẹ̀ wá mọ́. Èyí gba pé ká máa ka Bíbélì, ká sì máa lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni. Ó tún gba pé ká máa sapá tọkàntọkàn láti fi àwọn ohun tí Ọlọ́run ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rán wa létí sílò nígbèésí ayé wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè sá fún èrò tó máa ń mú ká fẹ́ láti dẹ́sẹ̀ àti àwọn ohun tó lè sọ wá di eléèérí nínú ayé. (Sm. 119:9; Ják. 1:21-25) Ó tuni lára gan-an láti mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí í ṣe òtítọ́ lè ‘wẹ̀ wá mọ́’ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá!—1 Kọ́r. 6:9-11.

17. Ìmọ̀ràn Bíbélì wo ló yẹ ká máa fi sílò ká lè máa bá a lọ ní jíjẹ́ mímọ́?

17 Ǹjẹ́ o gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí í ṣe òtítọ́ láyè nígbèésí ayé rẹ láti sọ ẹ́ di mímọ́? Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa ń ṣe tí wọ́n bá pe àfiyèsí rẹ sí ewu tó wà nínú eré ìnàjú tó ń sọni di ẹlẹ́gbin tó kúnnú ayé? (Sm. 101:3) Ṣé o máa ń yẹra fún ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ọmọléèwé tàbí òṣìṣẹ́, tí ìgbàgbọ́ wọn kò bá tìrẹ mu? (1 Kọ́r. 15:33) Ṣé o kì í tan ara rẹ jẹ tó bá di pé kó o sapá láti borí ìkùdíẹ̀ káàtó tó lè mú kó o jẹ́ aláìmọ́ lójú Jèhófà? (Kól. 3:5) Ṣé o kì í lọ́wọ́ sí awuyewuye ìṣèlú àti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tó kúnnú ọ̀pọ̀ eré ìdárayá?—Ják. 4:4.

18. Báwo ni jíjẹ́ mímọ́ nínú ìwà àti ìjọsìn wa ṣe lè mú kí iṣẹ́ ìkórè wa máa méso jáde?

18 Tó o bá ń fi òótọ́ inú ṣe àwọn nǹkan tá a mẹ́nu bà yìí, wàá kẹ́sẹ járí. Nígbà tí Jésù ń fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró wé ẹ̀ka igi àjàrà, ó sọ pé: “Gbogbo ẹ̀ka tí ń bẹ nínú mi tí kì í so èso ni [Bàbá mi] ń mú kúrò, gbogbo èyí tí ó sì ń so èso ni ó ń wẹ̀ mọ́, kí ó lè so èso púpọ̀ sí i. (Jòh. 15:2) Bó o ṣe ń jọ̀wọ́ ara rẹ fún omi òtítọ́ Bíbélì tó ń wẹni mọ́, wàá máa so èso púpọ̀ sí i.

Ìbùkún Nísinsìnyí àti Lọ́jọ́ Iwájú

19. Báwo la ṣe bù kún ìsapá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lẹ́nu iṣẹ́ ìkórè?

19 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó jẹ́ olóòótọ́ fi ìdálẹ́kọ̀ọ́ Jésù sílò, wọ́n sì gba agbára nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, láti jẹ́ ẹlẹ́rìí “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Wọ́n sìn gẹ́gẹ́ bí ara ìgbìmọ̀ olùdarí, míṣọ́nnárì àti alábòójútó arìnrìn-àjò, wọ́n sì tún kópa pàtàkì nínú wíwàásù ìhìn rere náà “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kól. 1:23) Ìbùkún àti ayọ̀ tí wọ́n rí àti èyí tí wọ́n mú bá àwọn ẹlòmíì mà kọyọyọ o!

20. (a) Àwọn ìbùkún wo lo ti rí gbà torí pé ò ń kó ipa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí? (b) Kí lo ti pinnu láti ṣe?

20 Bẹ́ẹ̀ ni o, tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tá a jẹ́ aláápọn, tá a sì rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà tó dára gan-an tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ó máa bá a lọ láti máa kó ipa tó jọjú nínú ìkórè tẹ̀mí tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí. Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń fojú winá ìrora àti ìjákulẹ̀ tó ń wá látàrí lílépa ọrọ̀ àti ìgbésí ayé fàájì, àwa ń ní ojúlówó ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. (Sm. 126:6) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé, “òpò [wa] kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58) Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ọ̀gá ìkórè yóò san wá lẹ́san títí láé fún “iṣẹ́ [wa] àti ìfẹ́ tí [a] fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—Héb. 6:10-12.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àkàwé Jésù nípa tálẹ́ńtì ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró, àmọ́ ó tún ní àwọn ìlànà tí gbogbo Kristẹni lè fi sílò nínú.

Ǹjẹ́ O Rántí?

Bó o ṣe ń sapá láti máa kó ipa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìkórè náà . . .

• kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

• báwo lo ṣe lè jẹ́ aláápọn, kó o sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀?

• kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o jẹ́ mímọ́ nínú ìwà àti nínú ìjọsìn rẹ?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ìrẹ̀lẹ̀ lè jẹ́ ká gbé ìgbé ayé tó dá lórí wíwá ire Ìjọba Ọlọ́run