Wíwà Lójúfò Ń So Èso Rere
Wíwà Lójúfò Ń So Èso Rere
ǸJẸ́ o máa ń wà lójúfò láti wàásù nígbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín? Ohun tí àwọn ará wa tó wà ní ìlú Turku tó ní ibùdókọ̀ òkun lórílẹ̀-èdè Finland ṣe nìyẹn, ìwàlójúfò wọn sì so èso rere.
Nígbà kan, àwọn ará wa ní erékùṣù Turku kíyè sí i pé àwùjọ àwọn ọkùnrin kan láti ilẹ̀ Éṣíà ti dé sí ìlú àwọn láti parí iṣẹ́ lórí ọkọ̀ òkun ńlá tí wọ́n fi ń rìnrìn-àjò afẹ́, èyí tí wọ́n ń kàn ní ọgbà tí wọ́n ti ń kan ọkọ̀ òkun lágbègbè náà. Lẹ́yìn náà, arákùnrin kan mọ hòtẹ́ẹ̀lì tí àwọn àlejò náà dé sí. Ó sì tún gbọ́ pé wọ́n máa ń fi bọ́ọ̀sì kó àwọn òṣìṣẹ́ náà lọ́wọ́ àárọ̀ láti hòtẹ́ẹ̀lì náà lọ sí etíkun. Kíá ló fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn arákùnrin tó wà ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ìlú Turku létí.
Àwọn alàgbà ìjọ náà rí èyí bí àǹfààní láti ṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó dé sí ìlú wọn yìí, torí náà wọ́n ṣètò ìjẹ́rìí àkànṣe láìjáfara. Lọ́jọ́ Sunday ọ̀sẹ̀ yẹn, àwọn akéde mẹ́wàá kóra jọ sítòsí ibi tí wọ́n ti ń wọ bọ́ọ̀sì ní aago méje àárọ̀. Ó ṣẹlẹ̀ pé wọn kò rí òṣìṣẹ́ kankan. Àwọn arákùnrin náà wá ń ronú pé, ‘Àbí a ti pẹ́ jù ni. Ṣé wọ́n ti kúrò ní Turku ni?’ Àfi bí ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ náà ṣe dé pẹ̀lú aṣọ iṣẹ́ lọ́rùn rẹ̀. Kò pẹ́ tí òṣìṣẹ́ míì tún fi dé, bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í dé lọ́kọ̀ọ̀kan nìyẹn. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ náà ti kóra jọ sí ibi tí wọ́n ti máa wọ bọ́ọ̀sì. Bí àwọn akéde náà ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nìyẹn, tí wọ́n ń fi àwọn ìtẹ̀jáde èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ àwọn òṣìṣẹ́ náà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó wákàtí kan kí àwọn òṣìṣẹ́ náà tó rí àyè jókòó nínú bọ́ọ̀sì, èyí sì fún àwọn ará láǹfààní láti bá èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn sọ̀rọ̀. Nígbà tí bọ́ọ̀sì náà fi máa ṣí, àwọn òṣìṣẹ́ náà ti gba ìwé kékeré mẹ́rìndínláàádóje [126] àti ìwé ìròyìn ọ̀ọ́dúnrún ó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [329]!
Àṣeyọrí tí wọ́n ṣe yìí fún àwọn ará náà ní ìṣírí láti pa dà lọ wàásù fún wọn ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, èyí sì jẹ́ ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òjò ń rọ̀ lọ́jọ́ yìí, síbẹ̀ alábòójútó àyíká darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní aago mẹ́fà ààbọ̀ àárọ̀, àwọn akéde mẹ́rìnlélógún [24] sì gbéra lọ sí ibùdókọ̀ náà. Lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n kó àwọn ìtẹ̀jáde lédè Tagalog dání, torí wọ́n rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn àlejò náà ló wá láti orílẹ̀-èdè Philippines. Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, kí bọ́ọ̀sì náà tó ṣí, àwọn òṣìṣẹ́ náà ti gba ìwé ńlá méje, ìwé kékeré mọ́kàndínláàádọ́rin [69] àti ìwé ìròyìn irínwó ó lé mọ́kàndínlọ́gọ́rin [479]. Ẹ wo bí inú àwọn ará tó lọ́wọ́ nínú ìjẹ́rìí àkànṣe náà á ṣe dùn tó tí ara wọn á sì yá gágá!
Kí àwọn òṣìṣẹ́ náà tó pa dà sí orílẹ̀-èdè wọn, àwọn ará pa dà bẹ mélòó kan wò lára wọn ní hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n dé sí, wọ́n sì ṣàlàyé kíkún fún wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn òṣìṣẹ́ kan sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí ti wàásù fún àwọn rí lórílẹ̀-èdè míì. Wọ́n sì sọ pé àwọn mọrírì bí àwọn ará ṣe lo ìdánúṣe láti wàásù fún àwọn lásìkò tí àwọn fi wà lórílẹ̀-èdè Finland.
Ǹjẹ́ ìwọ náà máa ń wà lójúfò láti wàásù nígbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín? Ṣé o máa ń lo ìdánúṣe láti wàásù fún àwọn tó ti orílẹ̀-èdè míì wá? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ náà lè ní irú ìrírí tí àwọn ará wa tó wà ní ìlú Turku ní.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
FINLAND
HELSINKI
Turku