Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Jésù Ṣe Gbé Òdodo Ọlọ́run Lárugẹ

Bí Jésù Ṣe Gbé Òdodo Ọlọ́run Lárugẹ

Bí Jésù Ṣe Gbé Òdodo Ọlọ́run Lárugẹ

“Ọlọ́run gbé [Kristi] kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fún ìpẹ̀tù nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Èyí jẹ́ láti fi òdodo tirẹ̀ hàn.” —RÓÒMÙ 3:25.

1, 2. (a) Kí ni Bíbélì kọ́ wa nípa ipò tí aráyé wà? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 A MỌ ìtàn tí Bíbélì sọ nípa ìwà ọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì bí ẹní mowó. Gbogbo wa là ń jìyà àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ, ó ní: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Bó ti wù ká sapá tó láti ṣe ohun tó tọ́, a máa ń ṣe àṣìṣe, torí náà a nílò ìdáríjì Ọlọ́run. Kódà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kédàárò pé: “Rere tí mo fẹ́ ni èmi kò ṣe, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́ ni èmi fi ń ṣe ìwà hù. Èmi abòṣì ènìyàn!”—Róòmù 7:19, 24.

2 Nítorí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ó bọ́gbọ́n mu láti béèrè àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí pé: “Kí ló fà á tí Jésù ará Násárétì kò fi jogún ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n bí i, kí sì nìdí tó fi ṣèrìbọmi? Báwo ni bí Jésù ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀ ṣe gbé òdodo Jèhófà lárugẹ? Ní pàtàkì jù lọ, àwọn nǹkan wo ni ikú Kristi mú kó ṣeé ṣe?

A Pe Ẹ̀tọ́ Ọlọ́run Láti Ṣàkóso Níjà

3. Báwo ni Sátánì ṣe tan Éfà jẹ?

3 Àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, hùwà tí kò mọ́gbọ́n dání nígbà tí wọ́n kọ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ sílẹ̀ tí wọ́n sì fara mọ́ ọn pé kí “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì” máa ṣàkóso àwọn. (Ìṣí. 12:9) Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bí èyí ṣe wáyé. Sátánì pe ẹ̀tọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ní láti máa ṣàkóso níjà. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nípa bíbéèrè lọ́wọ́ Éfà pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” Éfà sọ fún un pé ọ̀kan pàtó lára igi ọgbà náà ni Ọlọ́run pàṣẹ pé àwọn kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn, àti pé bí àwọn bá fọwọ́ kàn án, àwọn máa kú. Lẹ́yìn náà ni Sátánì fi ẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé irọ́ ló ń pa. Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.” Èṣù tipa bẹ́ẹ̀ tan Éfà láti mú kó gbà gbọ́ pé ńṣe ni Ọlọ́run ń fi ohun rere kan pa mọ́ fún un, àti pé bó bá jẹ nínú èso igi náà, ó máa dà bí Ọlọ́run á sì lè máa dá pinnu ohun tó bá fẹ́.—Jẹ́n. 3:1-5.

4. Báwo ni aráyé ṣe wá sábẹ́ àkóso Sátánì tó ń bá àkóso Ọlọ́run figa gbága?

4 Ní kúkúrú ṣá, ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé aráyé á túbọ̀ láyọ̀ bí wọ́n bá kọ ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n máa tọ̀ sílẹ̀. Dípò tí Ádámù ì bá fi fara mọ́ ọn pé Ọlọ́run ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso, ńṣe lòun náà dara pọ̀ mọ́ aya rẹ̀ nípa jíjẹ èso tó sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ. Nípa báyìí, Ádámù ba ìdúró rere tó ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ó sì mú wa wá sábẹ́ àjàgà rírorò ti ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Lọ́wọ́ kan náà ẹ̀wẹ̀, aráyé wá sábẹ́ àkóso tó ń bá àkóso Ọlọ́run figa gbága, ìyẹn àkóso Sátánì, “ọlọrun aiye yi.”—2 Kọ́r. 4:4, Bibeli Mimọ; Róòmù 7:14.

5. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ? (b) Báwo ni Ọlọ́run ṣe mú kí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa?

5 Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí kì í kùnà, ó dájọ́ ikú fún Ádámù àti Éfà. (Jẹ́n. 3:16-19) Àmọ́, ìyẹn kò fi hàn pé ète Ọlọ́run ti forí ṣánpọ́n. Ká má rí i! Nígbà tí Jèhófà ń dájọ́ ikú fún Ádámù àti Éfà, ó ṣe ohun tó mú kí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn mọ̀ pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó polongo pé òun máa gbé “irú-ọmọ” kan dìde, Sátánì sì máa pa á ní gìgísẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ọgbẹ́ gìgísẹ̀ Irú-ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí náà máa san, òun náà á sì “pa [Sátánì] ní orí.” (Jẹ́n. 3:15) Bíbélì ṣàlàyé síwájú sí i lórí kókó yìí, ó sì sọ nípa Jésù Kristi pé: “Fún ète yìí ni a ṣe fi Ọmọ Ọlọ́run hàn kedere, èyíinì ni, láti fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòh. 3:8) Àmọ́, báwo ni ìwà àti ikú Jésù ṣe gbé òdodo Ọlọ́run lárugẹ?

Ohun Tí Ìrìbọmi Jésù Túmọ̀ Sí

6. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù kò jogún ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ádámù?

6 Ipò tí Jésù máa wà lẹ́yìn tó bá ti dàgbà tán máa ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ipò tí Ádámù wà kó tó dẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 5:14; 1 Kọ́r. 15:45) Èyí tó túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ bí Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ṣe àlàyé kedere fún Màríà tó jẹ́ ìyá Jésù nípa èyí. Ó sọ pé: “Ẹ̀mí mímọ́ yóò bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:35) Nígbà tí Jésù wà lọ́mọdé, Màríà ti ní láti ṣe àwọn àlàyé kan fún un nípa bí òun ṣe bí i. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà kan tí Màríà àti Jósẹ́fù tó jẹ́ alágbàtọ́ Jésù wá a kàn nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run, ọmọ kékeré náà béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?” (Lúùkù 2:49) Ó dájú pé ìgbà tí Jésù ti wà lọ́mọdé, ló ti mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ni òun. Torí náà, ó ka gbígbé ògo Ọlọ́run lárugẹ sí ohun pàtàkì.

7. Àwọn ohun ìní ṣíṣeyebíye wo ni Jésù ní?

7 Jésù ní ìmọrírì tó ga fún àwọn nǹkan tẹ̀mí, torí náà ó máa ń lọ sí àwọn ìpàdé fún ìjọsìn déédéé. Níwọ̀n bó sì ti ní ọpọlọ pípé, ó dájú pé ó máa gbọ́ àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ni níbẹ̀ lágbọ̀ọ́yé, àwọn ohun tó sì kà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù máa yé e yékéyéké. (Lúùkù 4:16) Ó tún ní ohun ìní ṣíṣeyebíye míì, ìyẹn ni ara ẹ̀dá èèyàn pípé tó lè fi ṣèrúbọ nítorí aráyé. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó ń gbàdúrà, ó sì ṣeé ṣe kó máa ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Sáàmù 40:6-8.—Lúùkù 3:21; ka Hébérù 10:5-10. a

8. Kí nìdí tí Jòhánù Oníbatisí kò fi fẹ́ kí Jésù ṣèrìbọmi?

8 Jòhánù Oníbatisí ti kọ́kọ́ fẹ́ sọ fún Jésù pé kó má ṣèrìbọmi. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìrìbọmi tí Jòhánù ń ṣe fún àwọn Júù jẹ́ àmì pé wọ́n ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá lòdì sí Òfin. Ìbátan Jésù ni Jòhánù, torí náà ó ṣeé ṣe kó ti mọ̀ pé olódodo ni Jésù kò sì sí ìdí fún un láti ronú pìwà dà. Àmọ́, Jésù mú kó dá Jòhánù lójú pé ó tọ̀nà fún òun láti di ẹni tí a batisí. Ó ṣàlàyé pé: “Ní ọ̀nà yẹn ni ó yẹ fún wa láti mú gbogbo èyí tí ó jẹ́ òdodo ṣẹ.”—Mát. 3:15.

9. Kí ni ìrìbọmi Jésù ṣàpẹẹrẹ?

9 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé, Jésù ti lè ronú pé, bíi ti Ádámù, òun lè di baba fún ìran èèyàn pípé. Àmọ́, Jésù kò fẹ́ láti gbé irú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀ torí pé kì í ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe nìyẹn. Ńṣe ni Ọlọ́run rán an wá sáyégẹ́gẹ́ bí Irú-ọmọ, tàbí Mèsáyà tó ṣèlérí. Ó fẹ́ kí Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn rúbọ. (Ka Aísáyà 53:5, 6, 12.) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ohun kan náà kọ́ ni ìrìbọmi tiwa àti ti Jésù túmọ̀ sí. Ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí Ọlọ́run ti yà sí mímọ́ fún ara rẹ̀ ni Jésù, torí náà kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tipasẹ̀ ìrìbọmi náà ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìrìbọmi Jésù ṣàpẹẹrẹ bó ṣe yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà máa ṣe.

10. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, báwo lèyí sì ṣe rí lára Jésù?

10 Lára ohun tí Jèhófà fẹ́ kí Jésù ṣe ni pé kó máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, kó máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn, kó sì máa múra wọn sílẹ̀ fún iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Bí Jésù ṣe yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tún kan bó ṣe múra tán láti fara da inúnibíni tó sì ṣe tán láti kú ikú oró láti fi hàn pé ipò ọba aláṣẹ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ òdodo lòun fara mọ́. Torí pé Jésù nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run tọkàntọkàn, inú rẹ̀ dùn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sì wù ú láti fi ara rẹ̀ ṣe ìrúbọ. (Jòh. 14:31) Ó tún mú inú rẹ̀ dùn láti mọ̀ pé òun lè fún Ọlọ́run ní ìtóye ìwàláàyè pípé òun gẹ́gẹ́ bí ìràpadà kó lè gbà wá kúrò ní oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ǹjẹ́ Ọlọ́run fara mọ́ bí Jésù ṣe yọ̀ǹda ara rẹ̀ kó lè bójú tó iṣẹ́ bàǹtà-banta yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó fara mọ́ ọn!

11. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, tàbí Kristi tá a ṣèlérí?

11 Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó kọ ìwé Ìhìn Rere jẹ́rìí sí i pé nígbà tí Jésù ń jáde bọ̀ látinú Odò Jọ́dánì, Jèhófà Ọlọ́run sọ ní kedere pé òun tẹ́wọ́ gbà á. Jòhánù Oníbatisí jẹ́rìí sí èyí, ó ní: “Mo rí tí ẹ̀mí ń sọ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àdàbà láti ọ̀run, ó sì bà lé [Jésù]. . . . Mo sì ti rí i, mo sì ti jẹ́rìí pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.” (Jòh. 1:32-34) Síwájú sí i, Jèhófà sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.”—Mát. 3:17; Máàkù 1:11; Lúùkù 3:22.

Ó Jẹ́ Olóòótọ́ Títí Dójú Ikú

12. Kí ni Jésù ṣe fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ lẹ́yìn tó ti ṣèrìbọmi?

12 Ní ọdún mẹ́tà àti ààbọ̀ lẹ́yìn náà, Jésù dara dé iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn nípa Baba rẹ̀ àti bó ṣe jẹ́ pé Ọlọ́run ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ̀ ẹ́ bó ṣe ń fẹsẹ̀ rìnrìn àjò jákèjádò Ilẹ̀ Ìlérí, síbẹ̀ kò sí ohun tó lè dá a dúró láti má ṣe jẹ́rìí kúnnákúnná nípa òtítọ́. (Jòh. 4:6, 34; 18:37) Jésù kọ́ àwọn mìíràn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Bó ṣe ń wo àwọn aláìsàn sàn lọ́nà ìyanu, tó ń bọ́ àwùjọ àwọn èèyàn tí ebi ń pa, tó sì ń jí àwọn òkú dìde, ńṣe ló ń fi àpẹẹrẹ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé hàn.—Mát. 11:4, 5.

13. Kí ni Jésù kọ́ wa nípa àdúrà?

13 Jésù kò wá iyì àti ọlá fún ara rẹ̀ nítorí ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni àti nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ń ṣe, kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀ darí gbogbo ìyìn sọ́dọ̀ Jèhófà. (Jòh. 5:19; 11:41-44) Jésù tún jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ ká máa gbàdúrà fún. Lára ohun tó yẹ ká máa béèrè fún nínú àdúrà wa ni pé kí orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, di “sísọ di mímọ́” àti pé kí ìṣàkóso òdodo Ọlọ́run rọ́pò àkóso búburú ti Sátánì ‘kí ìfẹ́ Ọlọ́run lè ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’ (Mát. 6:9, 10) Jésù tún rọ̀ wá láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú irú àdúrà bẹ́ẹ̀ nípa “wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́.”—Mát. 6:33.

14. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, kí nìdí tó fi gba pé kó sapá kó tó lè ṣe ipa tirẹ̀ nínú mímú ète Ọlọ́run ṣẹ?

14 Bí àkókò ikú ìrúbọ Jésù ṣe ń sún mọ́lé, ó túbọ̀ ṣe kedere sí i pé iṣẹ́ ńlá ló já lé òun léjìká. Bí Ọlọ́run ṣe máa mú ète rẹ̀ ṣẹ àti bí ohunkóhun kò ṣe ní kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀ sinmi lórí pé kí Jésù fara da ìṣègbè àti ikú oró. Ní ọjọ́ márùn-ún ṣáájú ikú Jésù, ó gbàdúrà pé: “Wàyí o, ọkàn mi dààmú, kí ni èmi yóò sì sọ? Baba, gbà mí là kúrò nínú wákàtí yìí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìdí nìyí tí mo fi wá sí wákàtí yìí.” Lẹ́yìn tí Jésù ti sọ ọ̀rọ̀ tá a retí pé kí ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí sọ yìí, Jésù darí ọkàn rẹ̀ sí ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù lọ, ó gbàdúrà pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà dáhùn pé: “Èmi ti ṣe é lógo, èmi yóò sì tún ṣe é lógo dájúdájú.” (Jòh. 12:27, 28) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù múra tán láti fojú winá ìdánwò ìṣòtítọ́ tó ga jù lọ tí èèyàn èyíkéyìí tíì fojú winá rẹ̀ rí. Àmọ́, kò sí iyè méjì pé bí Jésù ṣe gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Baba rẹ̀ ọ̀run sọ fún un yẹn fún un ní ìgboyà tó lágbára pé ó máa ṣàṣeyọrí láti ya orúkọ Jèhófà sí mímọ́ kó sì dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre. Ó sì dájú pé ó ṣàṣeyọrí!

Ohun Tí Ikú Jésù Mú Kó Ṣeé Ṣe

15. Kí Jésù tó kú, kí nìdí tó fi sọ pé: “A ti ṣe é parí”?

15 Kí Jésù tó gbẹ́mìí mì lórí òpó igi oró tí wọ́n gbé e kọ́ sí, ó sọ pé: “A ti ṣe é parí!” (Jòh. 19:30) Ọ̀pọ̀ ohun ńlá ni Jésù ti gbé ṣe nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, lẹ́yìn ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó ti ṣèrìbọmi títí di ìgbà ikú rẹ̀! Nígbà tí Jésù kú, ìsẹ̀lẹ̀ líle nípá kan ṣẹlẹ̀, ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogún Róòmù tó ń bójú tó pípa Jésù sì sọ pé: “Dájúdájú, Ọmọ Ọlọ́run ni èyí.” (Mát. 27:54) Ọ̀gá àwọn ọmọ ogun náà ti ní láti rí i tẹ́lẹ̀ pé wọ́n fi Jésù ṣe ẹlẹ́yà torí pé ó sọ fún wọn pé Ọmọ Ọlọ́run lòun. Láìka gbogbo ohun tí Jésù jìyà rẹ̀ sí, ó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, ó sì fi hàn pé òpùrọ́ paraku ni Sátánì. Gbogbo àwọn tó wá fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ńkọ́? Sátánì pe àwọn náà níjà pé: “Ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.” (Jóòbù 2:4) Bí Jésù ṣe dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ fi hàn pé bí Ádámù àti Éfà bá fẹ́ láti dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ nígbà tí wọ́n dojú kọ ìdánwò tí kò tó ti Jésù, wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì ju gbogbo rẹ̀ lọ ni pé, ìgbésí ayé Jésù àti ikú rẹ̀ fìdí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ múlẹ̀, ó sì tún gbé e lárugẹ. (Ka Òwe 27:11.) Ṣé ohun mìíràn tún wà tí ikú Jésù mú kó ṣeé ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà!

16, 17. (a) Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ẹlẹ́rìí fún Jèhófà tí wọ́n wà ṣáájú ẹ̀sìn Kristẹni láti di ẹni tí Ọlọ́run kà sí olódodo? (b) Èrè wo ni Jèhófà san fún Ọmọ rẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ olóòótọ́, kí sì ni Jésù Kristi Olúwa ń bá a nìṣó láti máa ṣe?

16 Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló ti gbé láyé kí Jésù tó wá sáyé. Ọlọ́run kà wọ́n sí olódodo ó sì mú kí wọ́n ní ìrètí àjíǹde. (Aísá. 25:8; Dán. 12:13) Àmọ́, ìlànà tó bá òfin mu wo ló lè mú kí Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni mímọ́ bù kún àwọn ẹ̀dá èèyàn aláìpé ní ọ̀nà àgbàyanu bẹ́ẹ̀? Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run gbé [Jésù Kristi] kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fún ìpẹ̀tù nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Èyí jẹ́ láti fi òdodo tirẹ̀ hàn, nítorí òun ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wáyé ní ìgbà tí ó ti kọjá jì nígbà tí Ọlọ́run ń lo ìmúmọ́ra; kí òun lè fi òdodo tirẹ̀ hàn ní àsìkò ìsinsìnyí, kí òun bàa lè jẹ́ olódodo àní nígbà tí ó bá ń polongo ènìyàn tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù ní olódodo.”—Róòmù 3:25, 26. b

17 Gẹ́gẹ́ bí èrè iṣẹ́ tí Jésù ṣe, Jèhófà jí i dìde ó sì fi í sí ipò tó ga ju èyí tó wà kó tó wá sí ilẹ̀ ayé. Ní báyìí, Jésù ti jogún àìleèkú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tá a ṣe lógo. (Héb. 1:3) Gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà àti Ọba, Jésù Kristi Olúwa ń bá a nìṣó láti máa ran àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè máa gbé òdodo Ọlọ́run lárugẹ. Ẹ wo bó ṣe yẹ ká kún fún ọpẹ́ tó, pé Jèhófà, Baba wa ọ̀run ni Olùsẹ̀san fún gbogbo àwọn tó bá ń gbé òdodo rẹ̀ lárugẹ tí wọ́n sì ń sìn ín ní àfarawé Ọmọ rẹ̀!—Ka Sáàmù 34:3; Hébérù 11:6.

18. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn tá a máa kẹ́kọ̀ọ́?

18 Àwọn ẹ̀dá èèyàn olóòótọ́ látìgbà Ébẹ́lì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà torí pé wọ́n lo ìgbàgbọ́, wọ́n sì ní ìgbọ́kànlé nínú Irú-ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí. Jèhófà mọ̀ pé Ọmọ òun máa pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ àti pé ikú rẹ̀ máa jẹ́ ètùtù tó kúnjú ìwọ̀n fún “ẹ̀ṣẹ̀ ayé.” (Jòh. 1:29) Ikú Jésù tún ṣàǹfààní fáwọn èèyàn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé lónìí. (Róòmù 3:26) Torí náà, àwọn ìbùkún wo la lè rí látinú ìràpadà Kristi? Ìyẹn ni kókó tá a máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn tá a máa kẹ́kọ̀ọ́.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fà yọ níbí wá látinú Sáàmù 40:6-8 ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ Septuagint lédè Gíríìkì, èyí tó fi gbólóhùn náà, “o pèsè ara kan fún mi” kún un. Gbólóhùn yìí kò sí nínú àwọn ẹ̀dà ìwé àfọwọ́kọ ayé àtijọ́ tó wà di báyìí lára àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo ni Sátánì ṣe pe ẹ̀tọ́ Ọlọ́run láti ṣàkóso níjà?

• Kí ni ìrìbọmi Jésù ṣàpẹẹrẹ?

• Kí ni ikú Jésù mú kó ṣeé ṣe?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ǹjẹ́ o mọ ohun tí ìrìbọmi Jésù ṣàpẹẹrẹ?