Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Dé Lásìkò?
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Dé Lásìkò?
GBOGBO ìgbà kọ́ ló máa ń rọrùn láti dé lásìkò. Lára ohun tó máa ń ṣèdíwọ́ ni ìrìn-àjò ọ̀nà jíjìn, sún kẹẹrẹ fà kẹẹrẹ ọkọ̀ àti kí ọwọ́ èèyàn dí gan-an. Síbẹ̀ náà, ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa dé lásìkò. Bí àpẹẹrẹ, níbi iṣẹ́ wọ́n gbà pé ẹni tó bá ń dé lásìkò jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tí kì í sì í fiṣẹ́ ṣeré. Àmọ́, ẹni tó bá ń pẹ́ lẹ́yìn lè ṣàkóbá fún iṣẹ́ àwọn ẹlòmíì àti bí iṣẹ́ wọn ṣe máa dára sí. Pípẹ́ lẹ́yìn lè mú kí akẹ́kọ̀ọ́ kan pa kíláàsì jẹ, kó má sì ṣe dáadáa lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ̀. Pípẹ́ dé ibi tí èèyàn ti fẹ́ lọ gba ìtọ́jú lè mú kí èèyàn máà rí ìtọ́jú tó péye gbà.
Àmọ́ láwọn apá ibì kan, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ka dídé lásìkò sí pàtàkì. Ní irú àwọn ibi bẹ́ẹ̀, ó lè di àṣà wa láti máa pẹ́ lẹ́yìn. Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká sọ ọ́ di àṣà wa láti máa dé lásìkò. Tá a bá mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa dé lásìkò, ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ apẹ́lẹ́yìn. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tó fi yẹ ká máa dé lásìkò? Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa pẹ́ lẹ́yìn? Kí sì ni àǹfààní tó máa ṣe wá tá a bá ń tètè dé?
Jèhófà Kì Í Fi Àkókò Falẹ̀
Olórí ìdí tó fi yẹ ká máa dé lásìkò ni pé a fẹ́ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run tá à ń sìn. (Éfé. 5:1) Jèhófà pèsè àpẹẹrẹ tó dára jù lọ tó bá dọ̀rọ̀ dídé lásìkò. Kò fi àkókò falẹ̀ rí. Ó máa ń mú ète rẹ̀ ṣẹ lásìkò tó yàn pé òun máa ṣe é gẹ́lẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà pinnu láti fi àkúnya omi pa àwọn èèyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run rẹ́, ó sọ fún Nóà pé: “Fi igi ṣe áàkì kan fún ara rẹ láti ara igi olóje.” Bí àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà máa wáyé ti ń sún mọ́lé, Jèhófà sọ fún Nóà pé kó wọ inú áàkì náà, ó sì sọ fún un pé: “Ní ọjọ́ méje péré sí i, èmi yóò mú kí òjò rọ̀ sórí ilẹ̀ ayé fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru; èmi yóò sì nu gbogbo ohun tí ó wà tí mo ti ṣe kúrò ní orí ilẹ̀.” Bó ṣe sọ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ náà rí, “ní ọjọ́ méje lẹ́yìn náà, ó wá ṣẹlẹ̀ pé omi àkúnya náà dé sórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́n. 6:14; 7:4, 10) Ronú nípa ohun tí ì bá ṣẹlẹ̀ sí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ká sọ pé wọn ò wọnú áàkì náà lásìkò. Bíi ti Ọlọ́run tí wọ́n ń jọ́sìn, wọn kò gbọ́dọ̀ fi àkókò falẹ̀.
Ní nǹkan bí àádọ́ta lé nírínwó [450] ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún baba ńlá náà Ábúráhámù pé ó máa bí ọmọkùnrin kan, ipasẹ̀ rẹ̀ sì ni Irú-ọmọ tó ṣèlérí náà á gbà wá. (Jẹ́n. 17:15-17) Ọlọ́run sọ pé wọn yóò bí Ísáákì “ní àkókò tí a yàn kalẹ̀ yìí ní ọdún tí ń bọ̀.” Ǹjẹ́ ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́? Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Sárà sì lóyún, ó sì wá bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ní àkókò tí a yàn kalẹ̀ nípa èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún un.”—Jẹ́n. 17:21; 21:2.
Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run kì í fi àkókò falẹ̀. (Jer. 25:11-13; Dán. 4:20-25; 9:25) Bíbélì sọ fún wa pé ká máa retí ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Kódà tó bá tiẹ̀ dà bíi pé ó ń “falẹ̀” lójú àwa èèyàn, Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé “kì yóò pẹ́.”—Háb. 2:3.
Àìfi Àkókò Falẹ̀ Ṣe Pàtàkì Nínú Ìjọsìn
Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti pésẹ̀ sí ibi tí wọ́n yàn láti ṣe “àwọn àjọyọ̀ abágbàyí ti Jèhófà,” wọ́n sì gbọ́dọ̀ dé lásìkò. (Léf. 23:2, 4) Ọlọ́run tún yan àkókò pàtó tí wọ́n gbọ́dọ̀ rú irú àwọn ẹbọ kan. (Ẹ́kís. 29:38, 39; Léf. 23:37, 38) Ǹjẹ́ èyí kò fi hàn pé Ọlọ́run kò fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa fi àkókò falẹ̀ nínú ìjọsìn wọn?
Ní ọ̀rúndún kìíní nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń fún àwọn ará Kọ́ríńtì ní ìtọ́ni nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa darí ìpàdé Kristẹni, ó rọ̀ wọ́n pé: ‘Ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.’ (1 Kọ́r. 14:40) Lọ́nà kan náà, ìpàdé àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rẹ̀ ní àkókò tí a yàn pé kó bẹ̀rẹ̀. Ojú tí Jèhófà fi ń wo àìfi àkókò falẹ̀ kò tíì yí pa dà. (Mál. 3:6) Nígbà náà, kí làwọn ohun tó yẹ ká ṣe tí a ó fi máa dé lásìkò sí àwọn ìpàdé Kristẹni?
Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Máa Dé Lásìkò
Àwọn kan ti rí i pé mímúra sílẹ̀ máa ń ṣèrànwọ́ gan-an. (Òwe 21:5) Bí àpẹẹrẹ, bí ibi tá à ń lọ bá jìn, tó sì ní àkókò pàtó tá a gbọ́dọ̀ débẹ̀, ṣé ó bọ́gbọ́n mu ká pẹ́ ká tó gbéra nílé tí a kò fi ní dé ibẹ̀ lásìkò? Ǹjẹ́ kò ní mọ́gbọ́n dání tá a bá tètè kúrò nílé ká má bàa pẹ́ dé ibi tí à ń lọ, kódà bí “ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” bá tiẹ̀ wáyé lọ́nà? (Oníw. 9:11) Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ José a tí kì í fi àkókò ṣeré sọ pé: “Ohun kan tó lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti máa dé lásìkò ni pé kó mọ iye àkókò tí ìrìn tí òun fẹ́ rìn máa gba òun.”
Fún àwọn kan, ó lè gba pé kí wọ́n ṣètò láti tètè kúrò níbi iṣẹ́ wọn kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti dé sí ìpàdé ìjọ lásìkò. Ohun tí Ẹlẹ́rìí kan lórílẹ̀-èdè Etiópíà ṣe nìyẹn nígbà tó rí i pé ìṣẹ́jú márùnlélógójì lòun á fi pẹ́ dé ìpàdé, torí pé àkókò pàtó kan wà tí ẹni tó máa gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ máa dé. Ó ṣètò pé kí òṣìṣẹ́ míì máa tètè wá gba iṣẹ́ lọ́wọ́ òun lálẹ́ ọjọ́ tó bá fẹ́ lọ sí ìpàdé. Ẹlẹ́rìí náà á wá ṣe àfikún iṣẹ́ wákàtí méje pa dà fún ẹni yẹn.
Tá a bá ní àwọn ọmọ kéékèèké, títètè dé sí ìpàdé á túbọ̀ ṣòro. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyá ló sábà máa ń múra fún àwọn ọmọ, síbẹ̀ àwọn tó kù nínú ìdílé lè ṣèrànwọ́, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe é. Ìyá kan lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Esperanza, ti dá tọ́jú ọmọ mẹ́jọ. Ní báyìí, ọjọ́ orí àwọn ọmọ náà ti wà láàárín ọdún márùn-ún sí ọdún mẹ́tàlélógún. Esperanza ṣàlàyé ètò tí ìdílé wọn ṣe tó jẹ́ kí wọ́n tètè máa dé ìpàdé. Ó ní: “Ọmọbìnrin mi àgbà máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti múra fún àwọn àbúrò rẹ̀. Èyí máa ń jẹ́ kí n ráyè parí àwọn iṣẹ́ ilé tó kù, kí n sì múra ká lè kúrò nílé lásìkò tá a fohùn sí.” Ìdílé yìí ní àkókò tí wọ́n fohùn sí láti máa kúrò nílé, gbogbo wọn ló sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò yìí.
Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Dídé sí Ìpàdé Lásìkò
Ríronú lórí àǹfààní tá à ń jẹ látinú dídé sí ìpàdé Kristẹni lásìkò lè mú kó túbọ̀ máa wù wá láti máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká lè máa tètè dé sí ìpàdé. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Sandra, tó ti mọ́ lára láti máa dé ìpàdé lásìkò sọ pé: “Ohun tí mo gbádùn látinú dídé sí ìpàdé lásìkò ni pé ó máa ń fún mi láǹfààní láti kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin, kí n bá wọn sọ̀rọ̀, kí n sì túbọ̀ mọ̀ wọ́n dáadáa.” Tá a bá ń tètè dé sí Gbọ̀ngàn Héb. 10:24, 25.
Ìjọba, a lè jàǹfààní látinú gbígbọ́ ọ̀rọ̀ látẹnu àwọn tó wà níkàlẹ̀ nípa ohun tí wọ́n ń fara dà àti iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe tọkàntọkàn. Tá a bá wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a sì ní ìjíròrò tó ń gbéni ró pẹ̀lú àwọn ará, a lè tipa bẹ́ẹ̀ ní ipa rere lórí wọn, ká sì ‘ru wọ́n sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.’—Apá pàtàkì lára ìjọsìn wa ni orin àti àdúrà tá a fi ń bẹ̀rẹ̀ àwọn ìpàdé wa jẹ́. (Sm. 149:1) Àwọn orin wa ń fìyìn fún Jèhófà, ó ń rán wa létí àwọn ànímọ́ tó yẹ ká ní, ó sì ń fún wa ní ìṣírí láti máa fi tayọ̀tayọ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àdúrà ìbẹ̀rẹ̀ wá ńkọ́? Láyé ìgbàanì, Jèhófà pe tẹ́ńpìlì ní “ilé àdúrà” òun. (Aísá. 56:7) Lóde òní, a máa ń pé jọ láti gbàdúrà sí Ọlọ́run láwọn ìpàdé wa. A máa ń fi àdúrà ìbẹ̀rẹ̀ tọrọ ìtọ́sọ́nà Jèhófà àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó sì tún ń múra èrò wa àti ọkàn wa sílẹ̀ láti gba àwọn ìsọfúnni tá a máa gbé yẹ̀ wò. Ó yẹ ká fi ṣe ìpinnu wa láti máa dé sí ìpàdé ṣáájú orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀.
Nígbà tí Helen tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún ń sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi máa ń tètè dé sí ìpàdé, ó sọ pé: “Mo ronú pé ó jẹ́ ọ̀nà láti fi ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà hàn, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ló pèsè àwọn ìsọfúnni tá a máa jíròrò, tó fi mọ́ orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀.” Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà máa fi irú ojú yẹn wo títètè dé sí ìpàdé? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ bẹ́ẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ ọ́ di àṣà wa láti máa dé lásìkò nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe, ní pàtàkì jù lọ nínú àwọn ohun tó bá jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Múra sílẹ̀ dáadáa ṣáájú àkókò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Fi àyè sílẹ̀ nítorí “ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Jẹ àǹfààní dídé sí ìpàdé lásìkò