Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Ṣe Jẹ́ Kí Èrò Àwọn Èèyàn Máa Darí Rẹ

Má Ṣe Jẹ́ Kí Èrò Àwọn Èèyàn Máa Darí Rẹ

Má Ṣe Jẹ́ Kí Èrò Àwọn Èèyàn Máa Darí Rẹ

OJÚ táwọn èèyàn fi ń wo nǹkan yàtọ̀ síra. Ohun tó tọ́ lójú ẹnì kan lè ṣàìtọ́ lójú ẹlòmíì; ohun tí ẹnì kan kà sí lè kó ẹlòmíì nírìíra. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ojú táwọn èèyàn fi ń wo nǹkan tún máa ń yí pa dà. Torí náà, nígbà tá a bá ń ka ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé nígbà àtijọ́, ó yẹ ká ṣàgbéyẹ̀wò èrò tó wọ́pọ̀ àti ohun táwọn èèyàn kà sí pàtàkì lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì dípò tí a ó fi máa túmọ̀ rẹ̀ síbi tó wù wá.

Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ohun méjì kan tí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì mẹ́nu bà léraléra, ìyẹn ọlá àti ẹ̀gàn. Ká lè lóye àwọn ẹsẹ tó sọ̀rọ̀ nípa ọlá àti ẹ̀gàn dáadáa, a gbọ́dọ̀ ronú lórí ojú táwọn èèyàn fi ń wò wọ́n nígbà yẹn lọ́hùn-ún.

Ohun Táwọn Èèyàn Kà sí Pàtàkì ní Ọ̀rúndún Kìíní

Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Àwọn ará Gíríìsì, àwọn ará Róòmù àtàwọn ará Jùdíà ka ọlá àti ẹ̀gàn sí ohun tó ṣe pàtàkì gidigidi nínú àṣà ìbílẹ̀ wọn. A ti rí àwọn tó fi ẹ̀mí jinkú bí wọ́n ti ń fi gbogbo ayé wọn wá ọlá, orúkọ, òkìkí, jíjẹ́ ẹni táwọn èèyàn gba tiẹ̀ àti ẹni tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún.” Irú ìlépa bí ìwọ̀nyí máa ń jẹ́ kí wọ́n tètè di ẹni tí èrò àwọn èèyàn ń darí.

Ní àwùjọ táwọn èèyàn ti ka ipò sí bàbàrà, látorí ipò ọlá dórí ipò ẹrú, ohun tó bá gbà làwọn èèyàn máa ń ṣe nítorí ipò àti ibi tí wọ́n fẹ́ kí wọ́n to àwọn sí láwùjọ. Wọ́n ka ọlá sí bí ẹnì kan ti ṣe pàtàkì tó lójú ara rẹ̀ àti lójú àwọn míì pẹ̀lú. Wọ́n máa ń bọlá fún ẹni tó bá ṣe ohun táwọn èèyàn retí pé kó ṣe. Nígbà míì, bíbọlá fúnni lè túmọ̀ sí pé kí ọrọ̀, ipò àti bí ẹnì kan ti ṣe pàtàkì tó máa dáni lọ́rùn, kéèyàn sì torí rẹ̀ máa gbóṣùbà fún un. Àwọn míì máa ń dẹni ọlá nígbà tí wọ́n bá ṣe ohun tó ṣe àwọn míì láǹfààní tàbí tí wọ́n bá ta àwọn ẹlòmíràn yọ. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ìtìjú tàbí ẹ̀tẹ́ ló máa ń já sí bí wọ́n bá wọ́ ẹnì kan nílẹ̀ tàbí tí wọ́n fi ṣẹ̀sín ní gbangba. Ohun tí ẹnì kan bá rò tàbí ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá sọ nípa irú ìtìjú tàbí ẹ̀tẹ́ bẹ́ẹ̀ kò sì ṣe pàtàkì tó ojú tí àwùjọ bá fi wò ó.

Nígbà tí Jésù sọ pé wọ́n lè ní kí ẹnì kan lọ jókòó “ní ibi yíyọrí ọlá jù lọ” tàbí “ibi rírẹlẹ̀ jù lọ” níbi àsè, ara ọ̀nà tí wọ́n gbà ń bọlá fúnni tàbí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kó ìtìjú báni nígbà yẹn lọ́hùn-ún ló ń tọ́ka sí. (Lúùkù 14:8-10) Ó kéré tán, ìgbà méjì ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá ara wọn ṣe awuyewuye nípa “èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.” (Lúùkù 9:46; 22:24) Irú ẹ̀mí tó wọ́pọ̀ jù lọ láàárín àwùjọ tí wọ́n gbé ni wọ́n fi hàn yẹn. Ìdí nìyẹn tí àwọn aṣáájú ìsìn Júù, tí wọ́n jẹ́ agbéraga àti olùbára-ẹni-díje, fi rí iṣẹ́ ìwàásù Jésù gẹ́gẹ́ bí èyí tó ń tàbùkù sí ọlá àti àṣẹ wọn. Gbogbo ìgbà sì ni ìgbìyànjú wọn láti borí rẹ̀ nínú àríyànjiyàn ní gbangba máa ń já sí pàbó.—Lúùkù 13:11-17.

Èrò míì tó tún wọ́pọ̀ láàárín àwọn Júù, àwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù ní ọ̀rúndún kìíní ni ìtìjú tó máa ń já sí bí wọ́n bá “gbá ẹnì kan mú ní gbangba, tí wọ́n sì fi ẹ̀sùn ìwà àìtọ́ kàn án.” Ìrẹ̀sílẹ̀ gbáà ló jẹ́ bí wọ́n bá de ẹnì kan tọwọ́ tẹsẹ̀ tàbí tí wọ́n bá jù ú sí àtìmọ́lé. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń tàbùkù síni lójú àwọn ọ̀rẹ́, ìdílé àti láwùjọ, yálà ẹni náà jẹ̀bi ìwà ọ̀daràn tàbí kò jẹ̀bi. Ẹ̀gbin tó lè tipa bẹ́ẹ̀ ta lé orúkọ rere rẹ̀ kò ní jẹ́ kó níyì mọ́, ó sì lè ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwọn míì jẹ́. Ohun tó tini lójú ju kí wọ́n deni tọwọ́ tẹsẹ̀ ni kí wọ́n fini ṣẹ̀sín nípa bíbọ́ni láṣọ kí wọ́n sì nani lẹ́gba. Èyí máa ń mú káwọn èèyàn fojú tẹ́ńbẹ́lú ẹni tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ sí tàbí kí wọ́n pẹ̀gàn rẹ̀, á sì dẹni táwọn èèyàn ń tàbùkù sí.

Pabanbarì rẹ̀ wá ni pé bí wọ́n bá pa irú ẹni bẹ́ẹ̀ lórí òpó igi oró, ẹ̀tẹ́ tó ju ẹ̀tẹ́ lọ ni wọ́n fi kàn án yẹn. Ọ̀mọ̀wé Martin Hengel, sọ pé àwọn “ẹrú ni wọ́n máa ń fi ìyà” irú ikú bẹ́ẹ̀ jẹ. “Torí náà, ó dúró fún wíwọ́ni nílẹ̀, dídójú tini àti ìdánilóró tó lékenkà.” Àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ á sì máa wá bí wọ́n á ṣe kọ̀ ọ́ sílẹ̀, torí ojú tí wọ́n á fi máa wò wọ́n láwùjọ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé irú ikú tí Kristi kú nìyí, ó di dandan fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ di ọmọlẹ́yìn Kristi ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni láti fojú winá ìfiniṣẹ̀sín láwùjọ. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn rí i bí ohun tí kò bọ́gbọ́n mu fún ẹnì kan láti sọ pé ohun jẹ́ ọmọlẹ́yìn ẹni tí wọ́n kàn mọ́gi. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwa ń wàásù Kristi tí a kàn mọ́gi, lójú àwọn Júù okùnfà fún ìkọ̀sẹ̀ ṣùgbọ́n lójú àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀rọ̀ òmùgọ̀.” (1 Kọ́r. 1:23) Báwo làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe kojú ìṣòro yìí?

Èrò Wọn Yàtọ̀ sí Ti Ọ̀pọ̀ Èèyàn

Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣègbọràn sí òfin, wọ́n sì sapá láti yẹra fún ìtìjú tí ìwà àìtọ́ máa ń kó báni. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má jìyà gẹ́gẹ́ bí òṣìkàpànìyàn tàbí olè tàbí aṣebi tàbí gẹ́gẹ́ bí olùyọjúràn sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn.” (1 Pét. 4:15) Àmọ́ ṣá o, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n á ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn òun nítorí orúkọ òun. (Jòh. 15:20) Pétérù kọ̀wé pé: “Bí [ẹnì kan] bá jìyà gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, kí ó má ṣe tijú, ṣùgbọ́n kí ó máa bá a nìṣó ní yíyin Ọlọ́run lógo.” (1 Pét. 4:16) Nígbà yẹn, èrò tó yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé kéèyàn má ṣe tijú bó bá ń jìyà gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi.

Àwọn Kristẹni kò lè gbà kí ìlànà táwọn míì ń tẹ̀ lé máa pinnu ìwà táwọn á máa hù. Ìwà òpònú ni wọ́n kà á sí ní ọ̀rúndún kìíní pé kéèyàn gba ẹni tí wọ́n kàn mọ́gi gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà. Fífi ojú wo nǹkan lọ́nà yẹn ì bá ti mú káwọn Kristẹni máa ronú bíi ti ọ̀pọ̀ èèyàn káwọn náà sì di ara wọn. Àmọ́, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní pé Jésù ni Mèsáyà ló mú kí wọ́n máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ń fi wọ́n ṣẹ̀sín. Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá tijú èmi àti àwọn ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, Ọmọ ènìyàn pẹ̀lú yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé nínú ògo Baba rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì mímọ́.”—Máàkù 8:38.

Lóde òní, àwọn èèyàn lè máa yọ wá lẹ́nu lónírúurú ọ̀nà ká bàa lè fi ìsìn Kristẹni sílẹ̀. Irú ìyọlẹ́nu bẹ́ẹ̀ lè wá látọ̀dọ̀ àwọn ọmọléèwé wa, aládùúgbò tàbí àwọn alábàáṣiṣẹ́ tí wọ́n ń gbìyànjú láti mú ká lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe, ìwà àìṣòótọ́, tàbí àwọn ìgbòkègbodò míì tí ń kọni lóminú. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè gbìyànjú láti mú kí ojú máa tì wá nítorí pé ìlànà títọ́ là ń tẹ̀ lé. Kí ló yẹ ká ṣe?

Fara Wé Àwọn Tí Wọ́n Tẹ́ńbẹ́lú Ìtìjú

Kí Jésù bàa lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà mọ́, ó fara da ikú ẹ̀sín. “Ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú.” (Héb. 12:2) Àwọn ọ̀tá Jésù gbá a létí, wọ́n tutọ́ sí i lára, wọ́n bọ́ aṣọ kúrò lára rẹ̀, wọ́n nà án lẹ́gba, wọ́n kàn án mọ́gi, wọ́n sì kẹ́gàn rẹ̀. (Máàkù 14:65; 15:29-32) Síbẹ̀, Jésù tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú tí wọ́n gbìyànjú láti kó bá a. Lọ́nà wo? Kò fà sẹ́yìn nítorí ohun tí wọ́n ṣe fún un. Jésù mọ̀ pé òun kì í ṣe ẹni àbùkù lójú Jèhófà, òun ò sì wá ògo látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kú ikú ẹrú, Jèhófà buyì kún un nípa jíjí i dìde àti fífi ipò tó lọ́lá jù lọ jíǹkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igbá kejì Òun. Nínú Fílípì 2:8-11, a kà pé: “[Kristi Jésù] rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró. Fún ìdí yìí gan-an pẹ̀lú ni Ọlọ́run fi gbé e sí ipò gíga, tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.”

Jésù mọ̀ pé àwọn èèyàn máa ka ikú òun sí ikú ẹ̀sín. Bí wọ́n ṣe máa dá Ọmọ Ọlọ́run yìí lẹ́bi pé ó sọ̀rọ̀ òdì àti bí ìyẹn ṣe máa mú kí wọ́n kẹ́gàn Baba rẹ̀ sì ti ní láti dùn ún gan-an. Jésù gbàdúrà sí Jèhófà pé kó mú ẹ̀gàn yìí kúrò. Ó ní: “Mú ife yìí kúrò lórí mi.” Ṣùgbọ́n ó gbà kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. (Máàkù 14:36) Síbẹ̀, Jésù dúró gbọn-in jálẹ̀ gbogbo ìṣòro yìí ó sì tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú. Ó ṣe tán, àwọn tó bá ń ronú bíi tí ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà ayé rẹ̀ ni irú ìtìjú bẹ́ẹ̀ máa bá. Ó dájú pé Jésù kò ronú bíi tiwọn.

Wọ́n fàṣẹ ọba mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà, wọ́n sì nà wọ́n lẹ́gba. Èyí mú kí wọ́n dẹni yẹ̀yẹ́ lójú ọ̀pọ̀ èèyàn. Àwọn èèyàn ò kà wọ́n sí, wọ́n sì fojú tẹ́ńbẹ́lú wọn. Síbẹ̀, wọn kò rẹ̀wẹ̀sì. Àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn kò jẹ́ kí èrò àwọn èèyàn nípa lórí àwọn, wọ́n sì tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú. (Mát. 10:17; Ìṣe 5:40; 2 Kọ́r. 11:23-25) Wọ́n mọ̀ pé ó yẹ kí àwọn ‘gbé òpó igi oró àwọn kí àwọn sì máa tọ Jésù lẹ́yìn nígbà gbogbo.’—Lúùkù 9:23, 26.

Àwa náà ń kọ́ lónìí? Àwọn ohun tí aráyé kà sí òmùgọ̀, aláìlera àti àwọn ohun tí kò gbayì, ni Ọlọ́run kà sí ọlọ́gbọ́n, alágbára àti èyí tó ní ọlá. (1 Kọ́r. 1:25-28) Ǹjẹ́ kò ní dà bí ìwà òmùgọ̀ àti àìláròjinlẹ̀, bá a bá ń jẹ́ kí èrò àwọn èèyàn máa darí wa?

Ó di dandan kí èrò àwọn èèyàn máa darí ẹni tó bá ń wá ọlá fún ara rẹ̀. Àmọ́, bíi ti Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní, Jèhófà la fẹ́ kó jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa. Torí náà, ohun tó bá ní ọlá lójú Ọlọ́run la ó máa kà sí, a ó sì máa ka ohun tó bá jẹ́ ohun ìtìjú lójú rẹ̀ sí ohun ìtìjú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ojú táráyé fi ń wo ìtìjú kọ́ ni Jésù fi wò ó