Ìṣọ̀kan Àwa Kristẹni Ń fi Ògo Fún Ọlọ́run
Ìṣọ̀kan Àwa Kristẹni Ń fi Ògo Fún Ọlọ́run
“Ẹ máa fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́.”—ÉFÉ. 4:3.
1. Báwo ni àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Éfésù ní ọ̀rúndún kìíní ṣe fi ògo fún Ọlọ́run?
ÌṢỌ̀KAN tó wà nínú ìjọ Kristẹni nílùú Éfésù ní ọ̀rúndún kìíní fi ògo fún Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́. Ìlú Éfésù jẹ́ ìlú táwọn èèyàn ti rí tajé ṣe, ó sì dájú pé a rí lára àwọn ará tó wà níbẹ̀ tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ tí wọ́n sì ní àwọn ẹrú tó ń ṣiṣẹ́ fún wọn. A sì rí àwọn míì tó jẹ́ ẹrú tó sì ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ òtòṣì. (Éfé. 6:5, 9) Àwọn míì jẹ́ Júù tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láàárín oṣù mẹ́ta tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù wọn. Àwọn míì ti jọ́sìn òrìṣà Átẹ́mísì rí, wọ́n sì ti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ idán pípa. (Ìṣe 19:8, 19, 26) Ó ṣe kedere pé ìsìn Kristẹni tòótọ́ máa ń fa àwọn èèyàn tí ipò wọn yàtọ̀ síra mọ́ra. Pọ́ọ̀lù rí i pé bí ìjọ náà ṣe wà ní ìṣọ̀kan fi ògo fún Jèhófà. Ó kọ̀wé pé: “Òun ni kí ògo wà fún nípasẹ̀ ìjọ.”—Éfé. 3:21.
2. Kí ló fẹ́ ba ìṣọ̀kan àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù jẹ́?
2 Àmọ́, ohun kan wà tó fẹ́ ba ìṣọ̀kan àgbàyanu tó wà nínú ìjọ Éfésù jẹ́. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn alàgbà pé: “Láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:30) Àwọn arákùnrin kan sì tún wà tí ẹ̀mí ìyapa kò tíì kúrò lára wọn, ìyẹn ẹ̀mí tí Pọ́ọ̀lù sọ pé ó ‘ń ṣiṣẹ́ nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.’—Éfé. 2:2; 4:22.
Lẹ́tà Kan Tó Sọ Bí Ìṣọ̀kan Ti Ṣe Pàtàkì Tó
3, 4. Báwo ni lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Éfésù ṣe sọ bí ìṣọ̀kan ti ṣe pàtàkì tó?
3 Pọ́ọ̀lù rí i pé bí àwọn Kristẹni bá ní láti máa bá ara wọn gbé ní ìṣọ̀kan, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gbọ́dọ̀ máa fi taratara sapá láti gbé ìṣọ̀kan lárugẹ. Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ lẹ́tà kan tó dá lórí ìṣọ̀kan sí àwọn ará Éfésù. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa ète Ọlọ́run láti “tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi.” (Éfé. 1:10) Ó tún fi àwọn Kristẹni wé òkúta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó para pọ̀ di ilé kan. Ó sọ pé: “Gbogbo ilé náà, níwọ̀n bí a ti so ó pọ̀ ní ìṣọ̀kan, ń dàgbà di tẹ́ńpìlì mímọ́ fún Jèhófà.” (Éfé. 2:20, 21) Síwájú sí i, Pọ́ọ̀lù sọ ìjẹ́pàtàkì ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tó di Kristẹni ó sì tún rán àwọn ará létí pé Ọlọ́run kan náà ló dá gbogbo wọn. Ó pe Jèhófà ní “Baba, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí olúkúlùkù ìdílé ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé ti gba orúkọ rẹ̀.”—Éfé. 3:5, 6, 14, 15.
4 Bá a ti ń ṣe àgbéyẹ̀wò orí 4 nínú ìwé Éfésù, a máa rí ìdí tí ìṣọ̀kan fi gba ìsapá, bí Jèhófà ṣe ń mú ká wà ní ìṣọ̀kan àti irú ànímọ́ tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa wà ní ìṣọ̀kan. Ṣé wàá kúkú ka gbogbo orí náà kó o lè jàǹfààní púpọ̀ sí i látinú àpilẹ̀kọ yìí?
Ìdí Tí Wíwà ní Ìṣọ̀kan Fi Gba Ìsapá Àfi-Taratara-Ṣe
5. Kí nìdí tí àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run fi lè máa sìn ín ní ìṣọ̀kan, àmọ́ kí nìdí tó fi lè ṣòro fún wa láti wà ní ìṣọ̀kan?
5 Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará tó wà ní Éfésù níyànjú pé kí wọ́n “máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́.” (Éfé. 4:3) Láti lè mọ bí èyí ṣe gba ìsapá tó, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run. Kò sí ohun abẹ̀mí méjì tí wọn kò fi ohunkóhun yàtọ̀ síra lórí ilẹ̀ ayé, torí náà ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ó máa ní ohun tí Jèhófà fi mú kí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ áńgẹ́lì tí ń bẹ lọ́run yàtọ̀ síra. (Dán. 7:10) Síbẹ̀, wọ́n lè máa sin Jèhófà ní ìṣọ̀kan torí pé gbogbo wọn ń fetí sí i, wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Ka Sáàmù 103:20, 21.) Bíi ti àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ làwọn Kristẹni náà ṣe ní àwọn ànímọ́ tó yàtọ̀ síra, ṣùgbọ́n àwọn Kristẹni tún wá ní àwọn àléébù kún tiwọn. Èyí lè mú kó túbọ̀ ṣòro láti wà ní ìṣọ̀kan.
6. Àwọn ànímọ́ wo ló máa mú ká lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa tí àléébù wọn yàtọ̀ sí tiwa?
6 Nígbà táwọn èèyàn aláìpé bá ń gbìyànjú láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ó ṣeé ṣe kí àwọn ìṣòro díẹ̀ wáyé. Bí àpẹẹrẹ, bí arákùnrin kan tó jẹ́ onínú-tútù ṣùgbọ́n tó máa ń pẹ́ lẹ́yìn bá ní láti sin Jèhófà pẹ̀lú arákùnrin míì tí kì í fàkókò ṣeré ṣùgbọ́n tó tètè máa ń fara ya ńkọ́? Ọ̀kan lè gbà pé èkejì ní àléébù, àmọ́ àwọn méjèèjì lè ti gbàgbé pé ó ní ibi tí àwọn kù sí. Báwo ni àwọn méjèèjì ṣe lè sin Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan? Wo bí ànímọ́ tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé e ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà kó o wá ronú lórí bá a ṣe lè gbé ìṣọ̀kan lárugẹ tá a bá ní irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “[Mo] pàrọwà fún yín láti máa rìn lọ́nà tí ó yẹ . . . pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú àti ìwà tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́, kí ẹ máa fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.”—Éfé. 4:1-3.
7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wá bá a ṣe lè máa wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn Kristẹni mìíràn tí wọ́n jẹ́ aláìpé?
7 Ó ṣe pàtàkì ká kọ́ láti máa sin Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn míì tí wọ́n jẹ́ aláìpé torí pé àwùjọ àwọn olùjọsìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà. “Ara kan ní ń bẹ, àti ẹ̀mí kan, àní gẹ́gẹ́ bí a ti pè yín nínú ìrètí kan ṣoṣo tí a pè yín sí; Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìbatisí kan; Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo ènìyàn.” (Éfé. 4:4-6) Ẹgbẹ́ ará kan ṣoṣo tí Jèhófà ń lò ló máa ń fi ẹ̀mí rẹ̀ darí, òun náà ló sì máa ń gbádùn àwọn ìbùkún rẹ̀. Kódà, bí ẹnì kan nínú ìjọ bá mú ẹ bínú, ibo ló tún kù tó o lè gbà lọ? Kò sí ibòmíì tá a ti lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tó lè jẹ́ kéèyàn rí ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 6:68.
“Àwọn Ẹ̀bùn Tí Ó Jẹ́ Ènìyàn” Ń Gbé Ìṣọ̀kan Lárugẹ
8. Kí ni Kristi ń lò láti sọ wá di alágbára ká má bàa ṣe ohun tó lè ba ìṣọ̀kan wa jẹ́?
8 Pọ́ọ̀lù lo àṣà kan tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọmọ ogun látijọ́ láti ṣàpèjúwe bí Jésù ṣe pèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” láti mú kí ìjọ wà níṣọ̀kan. Ọmọ ogún kan tó ja àjàṣẹ́gun lè mú òǹdè wálé láti ilẹ̀ àjèjì kó lè máa bá ìyàwó rẹ̀ ṣiṣẹ́ ilé. (Sm. 68:1, 12, 18) Bákan náà, bí Jésù ṣe ṣẹ́gun ayé ti mú kó ní ọ̀pọ̀ ẹrú tí wọ́n fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn. (Ka Éfésù 4:7, 8.) Báwo ló ṣe ń lo àwọn tó dà bí òǹdè fún un yìí? “Ó . . . fúnni ní àwọn kan gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì, àwọn kan gẹ́gẹ́ bí wòlíì, àwọn kan gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, àwọn kan gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́, láti lè ṣe ìtọ́sọ́nàpadà àwọn ẹni mímọ́, fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, fún gbígbé ara Kristi ró, títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́.”—Éfé. 4:11-13.
9. (a) Báwo ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” ṣe ń mú ká lè máa wà ní ìṣọ̀kan? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pa kún ìṣọ̀kan ìjọ?
9 Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́, “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” yìí ń mú ká wà níṣọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, bí alàgbà kan nínú ìjọ bá kíyè sí àwọn arákùnrin méjì tí wọ́n ń ‘ru ìdíje sókè pẹ̀lú ara wọn,’ ó lè pa kún ìṣọ̀kan ìjọ dáadáa bó bá fún wọn ní ìmọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́ tó sì ‘tọ́ wọn sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù.’ (Gál. 5:26–6:1) Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” yìí máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára èyí tá a gbé ka àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń gbé ìṣọ̀kan ìjọ lárugẹ, wọ́n sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti di Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí. Pọ́ọ̀lù sọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní: “Kí a má bàa tún jẹ́ ìkókó mọ́, tí a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí nínú dídọ́gbọ́n hùmọ̀ ìṣìnà.” (Éfé. 4:13, 14) Àwọn Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ máa pa kún ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ àwọn ará, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ẹ̀yà ara wa ṣe ń gbé ara wọn ró nípa ṣíṣe ohun tí wọ́n nílò fún wọn.—Ka Éfésù 4:15, 16.
Máa Hùwà Tuntun
10. Báwo ni ìṣekúṣe ṣe lè ba ìṣọ̀kan wa jẹ́?
10 Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé orí kẹrin lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Éfésù fi hàn pé fífi ìfẹ́ bá ara wa gbé ló lè mú ká wà níṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí? Lẹ́yìn náà ló wá ṣàlàyé àwọn ohun tó wé mọ́ ìfẹ́. Ohun kan ni pé bá a bá ń ṣe ohun tó fi ìfẹ́ hàn, a kò ní ṣe àgbèrè, a kò sì ní máa hùwà àìníjàánu. Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará pé kí wọ́n “má ṣe máa bá a lọ mọ́ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ti ń rìn.” Àwọn èèyàn wọ̀nyẹn ti “ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere,” wọ́n sì ti “fi ara wọn fún ìwà àìníjàánu.” (Éfé. 4:17-19) Ayé oníwà ìbàjẹ́ tá à ń gbé tún máa ń mú kó ṣòro fún wa láti wà ní ìṣọ̀kan. Àwọn èèyàn máa ń fi ìbálòpọ̀ dápàárá, wọ́n máa ń kọ ọ́ lórin, wọ́n máa ń wò ó bí eré ìnàjú, wọ́n sì máa ń ṣe é ní ìkọ̀kọ̀ tàbí ní gbangba. Kódà, títage èyí tó lè mú kó o máa ṣe bíi pé ọkàn rẹ ń fà sí ẹnì kan, láìní in lọ́kàn láti fẹ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀, lè fà ẹ́ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà kó o sì fi ìjọ Ọlọ́run sílẹ̀. Kí nìdí? Torí pé ó máa ń tètè mú kéèyàn ṣe àgbèrè. Bákan náà, bí títage bá mú kí ẹni tó ti ṣègbéyàwó ṣe panṣágà, ó lè mú kí òun àtàwọn ọmọ má lè gbé pọ̀ mọ́, kí ìpínyà sì wáyé láàárín òun àti ọkọ tàbí aya rẹ̀. Ìyapa gbáà lèyí jẹ́! Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin kò kẹ́kọ̀ọ́ Kristi bẹ́ẹ̀”!—Éfé. 4:20, 21.
11. Ìyípadà wo ni Bíbélì rọ àwọn Kristẹni láti ṣe?
11 Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé a gbọ́dọ̀ pa ọ̀nà ìrònú ayé tó máa ń ba ìṣọ̀kan jẹ́ tì ká sì máa hùwà tó máa jẹ́ ká lè wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn míì. Ó sọ pé: “Kí ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé, tí a sì ń sọ di ìbàjẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ [ti ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà] atannijẹ; . . . kí ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfé. 4:22-24) Báwo la ṣe lè sọ wa ‘di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú wa ṣiṣẹ́’? Bí ìmọrírì tá a ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá mú ká máa ṣe àṣàrò lórí ohun tá à ń kọ́, tá a sì tún ń ronú lórí àpẹẹrẹ rere àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, ó dájú pé ìsapá yìí á mú ká gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, “èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run.”
Máa Sọ̀rọ̀ Tó Dáa Lẹ́nu
12. Báwo ni sísọ òtítọ́ ṣe lè mú ká máa wà ní ìṣọ̀kan, kí sì nìdí tó fi ṣòro fáwọn kan láti máa sọ òótọ́?
12 Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn tó jẹ́ ara ìdílé kan náà tàbí tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ máa bára wọn sọ òtítọ́. Àwọn èèyàn túbọ̀ máa ń sún mọ́ra, bí wọ́n bá ń sọ ojú abẹ níkòó, tí wọn kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. (Jòh. 15:15) Àmọ́, béèyàn bá purọ́ fún arákùnrin rẹ̀ ńkọ́? Bí arákùnrin rẹ̀ bá mọ̀ pé irọ́ ló pa, kò ní lè fọkàn tán an mọ́. Ẹ lè wá rí ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì ni wá.” (Éfé. 4:25) Ó lè ṣòro gan-an fún ẹnì kan tó bá ti mọ́ lára láti máa purọ́, bóyá látìgbà kékeré, láti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ òtítọ́. Àmọ́, Jèhófà máa mọrírì rẹ̀ bó bá sapá láti yí pa dà, yóò sì ràn án lọ́wọ́.
13. Báwo lèèyàn ṣe lè mú ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀?
13 Jèhófà ń kọ́ wa pé ká máa ní ọ̀wọ̀ fún ara wa ká sì máa wà ní ìṣọ̀kan nínú ìjọ àti nínú ìdílé nípa ṣíṣọ́ ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu wa jáde. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde . . . Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.” (Éfé. 4:29, 31) Ọ̀nà kan tá a lè gbà yẹra fún ọ̀rọ̀ èébú ni pé ká máa hùwà tó túbọ̀ fi ọ̀wọ̀ hàn sí àwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin tó bá máa ń bú ìyàwó rẹ̀ gbọ́dọ̀ sapá láti yí ìwà rẹ̀ pa dà, pàápàá jù lọ bí òye bá ṣe ń yé e nípa bí Jèhófà ṣe ń fi ọlá fún àwọn obìnrin. Kódà, Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yan àwọn obìnrin kan, ó sì mú kí wọ́n nírètí láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú Kristi. (Gál. 3:28; 1 Pét. 3:7) Bákan náà, obìnrin tó sábà máa ń pariwo lé ọkọ rẹ̀ lórí gbọ́dọ̀ fẹ́ láti ṣe ìyípadà bó bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jésù ṣe kó ara rẹ̀ níjàánu nígbà tí wọ́n mú un bínú.—1 Pét. 2:21-23.
14. Kí nìdí tó fi léwu láti máa bínú?
14 Ìwà míì tó tún burú bíi kéèyàn máa bu èébú ni pé kéèyàn má lè pa ìbínú mọ́ra. Èyí pẹ̀lú lè ba ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn tó fẹ́ràn ara wọn jẹ́. Bí iná ni ìbínú rí. Ó lè kọjá bó ṣe yẹ kó sì dá wàhálà sílẹ̀. (Òwe 29:22) Bó bá tiẹ̀ yẹ kéèyàn bínú nítorí ohun kan, ó ṣì yẹ kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ fọwọ́ wọ́nú, torí pé ìbínú rẹ̀ lè ba àjọṣe tó dáa jẹ́. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lórí dídárí jini, kí wọ́n má ṣe máa di kùnrùngbùn, kí wọ́n sì máa gbàgbé ọ̀rọ̀ àná. (Sm. 37:8; 103:8, 9; Òwe 17:9) Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Éfésù níyànjú pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.” (Éfé. 4:26, 27) Béèyàn bá kọ̀ láti ṣàkóso ìbínú rẹ̀ ó máa gba Èṣù láyè láti mú ìyapa àti ìjà wọnú ìjọ.
15. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tá a bá mú ohun tí kì í ṣe tiwa?
15 Ìṣọ̀kan máa pọ̀ sí i nínú ìjọ tá a bá ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún ohun ìní àwọn ẹlòmíì. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́.” (Éfé. 4:28) Níbi gbogbo, àwọn èèyàn Jèhófà máa ń fọkàn tán ara wọn. Bí Kristẹni kan bá wá torí ìyẹn mú ohun tí kì í ṣe tirẹ̀, ó máa ba ìṣọ̀kan tó ń fún wa láyọ̀ yẹn jẹ́.
Ìfẹ́ fún Ọlọ́run Ń Mú Ká Wà ní Ìṣọ̀kan
16. Báwo la ṣe lè lo ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró láti mú kí ìṣọ̀kan wa lágbára sí i?
16 Torí pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run mú kí gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ Kristẹni máa fi ìfẹ́ bá ara wa gbé ló mú ká wà ní ìṣọ̀kan. Bá a ṣe mọrírì inú rere tí Jèhófà fi hàn sí wa ló mú ká máa fi taratara sapá láti fi ìlànà rẹ̀ sílò. Ó sọ pé: “[Ẹ máa sọ] àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́. . . . Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.” (Éfé. 4:29, 32) Inú rere Jèhófà máa ń mú kó dárí ji àwa èèyàn aláìpé. Bí àìpé bá wá mú káwọn míì ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó, ṣé kò wá yẹ ká dárí jì wọ́n?
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá taratara láti gbé ìṣọ̀kan lárugẹ?
17 Ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run ń fi ògo fún Jèhófà. Onírúurú ọ̀nà ni ẹ̀mí rẹ̀ ń gbà mú ká gbé ìṣọ̀kan lárugẹ. Ó dájú pé a kò ní fẹ́ láti dí ẹ̀mí mímọ́ lọ́wọ́ láti máa darí wa. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.” (Éfé. 4:30) Ìṣọ̀kan jẹ́ ìṣúra iyebíye tó yẹ kéèyàn pa mọ́. Ó máa ń mú kí gbogbo àwọn tó bá wà ní ìṣọ̀kan láyọ̀, ó sì máa ń fi ògo fún Jèhófà. “Nítorí náà, ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.”—Éfé. 5:1, 2.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ànímọ́ wo ló ń mú kí àwọn Kristẹni lè máa gbé ìṣọ̀kan lárugẹ?
• Báwo ni ìwà wa ṣe lè mú ká máa wà ní ìṣọ̀kan nínú ìjọ?
• Báwo ni ọ̀rọ̀ ẹnu wa ṣe lè mú ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn èèyàn tó wá láti ibi tó yàtọ̀ síra wà ní ìṣọ̀kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ǹjẹ́ o mọ ewu tó wà nínú títage?