Ìṣọ̀kan La Fi Ń dá Ìsìn Tòótọ́ Mọ̀
Ìṣọ̀kan La Fi Ń dá Ìsìn Tòótọ́ Mọ̀
“Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀ ní ìṣọ̀kan, bí agbo ẹran nínú ọgbà ẹran.”—MÍKÀ 2:12.
1. Báwo ni ìṣẹ̀dá ṣe jẹ́rìí sí ọgbọ́n Ọlọ́run?
ONÍSÁÀMÙ kan fi ìtara sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe. Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ.” (Sm. 104:24) Ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe kedere nínú ọ̀nà tó gbà dá àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àti ọ̀kan-kò-jọ̀kan ewéko, kòkòrò, ẹranko, àtàwọn ẹ̀dá akéréjojú sórí ilẹ̀ ayé. Gbogbo wọn ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti gbé ìwàláàyè ara wọn ró. Bákan náà, ó tún dá ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀yà ara ńlá àti ẹ̀yà ara tín-tìn-tín sínú ara rẹ lọ́hùn-ún, gbogbo wọn sì ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti mú kí ara rẹ jí pépé, kó o sì ní ìlera tó dáa.
2. Bá a ṣe fi hàn nínú àwòrán tó wà lójú ìwé 13, kí nìdí tó fi ní láti jẹ́ ohun ìyanu pé àwọn Kristẹni wà ní ìṣọ̀kan?
2 Jèhófà dá àwa ẹ̀dá èèyàn ká lè jọ máa wà pa pọ̀. Onírúurú ẹ̀yà ló wà; ìrísí, ànímọ́ àti ẹ̀bùn wa sì yàtọ̀ síra. Ọlọ́run tún fún ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ ní àwọn ànímọ́ bíi tirẹ̀, èyí táá mú kí wọ́n lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀, kí wọ́n sì máa ran ara wọn lọ́wọ́. (Jẹ́n. 1:27; 2:18) Síbẹ̀, aráyé lápapọ̀ ti di àjèjì sí Ọlọ́run báyìí, kò sì tíì ṣeé ṣe fún gbogbo wọn láti máa gbé ní ìṣọ̀kan. (1 Jòh. 5:19) Torí náà, bí a bá rántí pé onírúurú èèyàn, tó fi mọ́ àwọn ẹrú tó jẹ́ ará Éfésù, àwọn gbajúmọ̀ obìnrin tó jẹ́ ará ìlú Gíríìsì, àwọn ọkùnrin Júù tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé, àtàwọn tó jẹ́ abọ̀rìṣà tẹ́lẹ̀rí, ni wọ́n para pọ̀ di ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, ohun ìyanu ni ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn ní láti jẹ́ lójú wa.—Ìṣe 13:1; 17:4; 1 Tẹs. 1:9; 1 Tím. 6:1.
3. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn Kristẹni, kí la sì máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Ìsìn tòótọ́ mú kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti jọ máa gbé ní ìṣọ̀kan bí àwọn ẹ̀yà inú ara wa. (Ka 1 Kọ́ríńtì 12:12, 13.) Díẹ̀ rèé lára àwọn apá tá a máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí: Báwo ni ìjọsìn tòótọ́ ṣe ń mú káwọn èèyàn wà ní ìṣọ̀kan? Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè mú kí àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ èèyàn láti orílẹ̀-èdè gbogbo wà ní ìṣọ̀kan? Àwọn ohun tó lè dènà ìṣọ̀kan wo ni Jèhófà ń mú ká borí? Ní ti ìṣọ̀kan, báwo ni ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ṣe yàtọ̀ sí tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?
Báwo Ni Ìsìn Tòótọ́ Ṣe Ń Mú Káwọn Èèyàn Wà ní Ìṣọ̀kan?
4. Báwo ni ìsìn tòótọ́ ṣe ń mú káwọn èèyàn wà ní ìṣọ̀kan?
4 Àwọn èèyàn tó ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ mọ̀ pé nítorí pé Jèhófà ló dá ohun gbogbo, òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. (Ìṣí. 4:11) Torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ ń gbé nínú ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ àwùjọ àti lábẹ́ ipò tó yàtọ̀ síra, òfin Ọlọ́run kan náà ni gbogbo wọn ń tẹ̀ lé, wọ́n sì ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà inú Bíbélì. Lọ́nà tó bá a mú gẹ́lẹ́, gbogbo àwọn olùjọsìn tòótọ́ máa ń pe Jèhófà ni “Baba.” (Aísá. 64:8; Mát. 6:9) Nípa bẹ́ẹ̀, arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí ni gbogbo wọn jẹ́ síra wọn, wọ́n sì lè máa gbádùn ìṣọ̀kan tí onísáàmù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lọ́nà tó wuni. Ó sọ pé: “Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!”—Sm. 133:1.
5. Ànímọ́ wo ló ń pa kún ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn olùjọsìn tòótọ́?
5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni àwọn Kristẹni tòótọ́, wọ́n ń jọ́sìn pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan torí pé wọ́n ti kọ́ láti máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Jèhófà ń kọ́ wọn láti máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́nà tí ẹlòmíì ò lè gbà nífẹ̀ẹ́ wọn. (Ka 1 Jòhánù 4:7, 8.) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kól. 3:12-14) Ìfẹ́, tó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé yìí, ni ànímọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. Àbí ìwọ náà ò ti rí i pé ìṣọ̀kan yìí ni ohun pàtàkì tó mú kí ìsìn tòótọ́ yàtọ̀?—Jòh. 13:35.
6. Báwo ni ìrètí Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń mú ká gbádùn ìṣọ̀kan?
6 Ohun míì tó tún mú káwọn olùjọsìn tòótọ́ wà ní ìṣọ̀kan ni pé wọ́n ń fojú sọ́nà fún Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé. Wọ́n mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó rọ́pò ìjọba èèyàn, ó sì máa mú ojúlówó àlàáfíà tó máa tọ́jọ́ wá fún aráyé. (Aísá. 11:4-9; Dán. 2:44) Torí náà, àwọn Kristẹni ń ṣègbọràn sí ohun tí Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòh. 17:16) Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í dá sí rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé; ìyẹn ló fà á tí wọ́n fi ń bára wọn gbé ní ìṣọ̀kan bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń gbé láyìíká wọn ń bára wọn jagun.
Ibì Kan Ṣoṣo Tá A Ti Ń Rí Ìtọ́ni Ọlọ́run Gbà
7, 8. Ọ̀nà wo ni ìtọ́ni tá à ń rí nínú Bíbélì ń gbà mú ká wà ní ìṣọ̀kan?
7 Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní wà ní ìṣọ̀kan torí pé gbogbo wọn ń rí ìṣírí gbà láti orísun kan náà. Wọ́n gbà pé Jésù ló ń kọ́ ìjọ tó sì ń darí rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn yìí máa ń gbé ìpinnu wọn ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń rán àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò láti mú ìtọ́ni yìí lọ sí àwọn ìjọ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀. Bíbélì sọ nípa díẹ̀ lára irú àwọn alábòójútó bẹ́ẹ̀ pé: “Bí wọ́n ti ń rin ìrìn àjò la àwọn ìlú ńlá náà já, wọn a fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù ti ṣe ìpinnu lé lórí jíṣẹ́ fún àwọn tí ń bẹ níbẹ̀, kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́.”—Ìṣe 15:6, 19-22; 16:4.
8 Bákan náà lónìí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó para pọ̀ di Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń pa kún ìṣọ̀kan àwọn ìjọ kárí ayé. Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń tẹ àwọn ìwé tó ń fúnni níṣìírí nípa tẹ̀mí jáde ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè. Orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ń gbé oúnjẹ tẹ̀mí náà kà. Torí náà, ohun tí wọ́n ń kọ́ni kò wá látọ̀dọ̀ èèyàn, ọ̀dọ̀ Jèhófà ló ti ń wá.—Aísá. 54:13.
9. Báwo ni iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ ṣe ń mú ká wà ní ìṣọ̀kan?
9 Àwọn Kristẹni alábòójútó pẹ̀lú ń gbé ìṣọ̀kan yìí lárugẹ nípa mímú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù. Àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín àwọn tó jùmọ̀ ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lágbára gan-an ju àjọṣe tó wà láàárín àwọn tó wulẹ̀ ń bára wọn kẹ́gbẹ́ pọ̀ nínú ayé. Ìjọ Kristẹni kò dà bí ẹgbẹ́ táwọn èèyàn máa ń dá sílẹ̀. A dá a sílẹ̀ ká lè máa tipasẹ̀ rẹ̀ bọlá fún Jèhófà ká sì ṣe iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́, ìyẹn ni iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere, sísọni di ọmọ ẹ̀yìn àti gbígbé ìjọ ró. (Róòmù 1:11, 12; 1 Tẹs. 5:11; Héb. 10:24, 25) Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lè sọ nípa àwọn Kristẹni pé: “Ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú ẹ̀mí kan, pẹ̀lú ọkàn kan tí ẹ ń làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ fún ìgbàgbọ́ ìhìn rere.”—Fílí. 1:27.
10. Kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà tí àwa èèyàn Ọlọ́run gbà wà ní ìṣọ̀kan?
10 Nípa báyìí, àwa èèyàn Jèhófà wà ní ìṣọ̀kan torí pé á fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, a fẹ́ràn àwọn ará wa, a nírètí nínú Ìjọba Ọlọ́run, a sì ń bọ̀wọ̀ fún àwọn tí Ọlọ́run ń lò láti máa mú ipò iwájú láàárín wa. Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìwà kan tó lè ba ìṣọ̀kan wa jẹ́ nítorí pé a jẹ́ aláìpé.—Róòmù 12:2.
Bá A Ṣe Lè Borí Ìgbéraga àti Owú
11. Kí nìdí tí ìgbéraga fi máa ń ba ìṣọ̀kan jẹ́, báwo sì ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí rẹ̀?
11 Ìgbéraga máa ń pín àwọn èèyàn níyà. Agbéraga máa ń ka ara rẹ̀ sí ẹni tó sàn ju àwọn míì lọ. Ó sì máa ń wá ìgbádùn onímọtara-ẹni-nìkan nípa fífọ́nnu. Àmọ́ ńṣe lèyí máa ń ba ìṣọ̀kan jẹ́; àwọn tó gbọ́ bó ṣe ń fọ́nnu lè bẹ̀rẹ̀ sí í jowú rẹ̀. Jákọ́bù ọmọlẹ́yìn sọ láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ pé: “Irú gbogbo ìyangàn bẹ́ẹ̀ burú.” (Ják. 4:16) Kò fi hàn pé èèyàn ní ìfẹ́ tó bá ń hùwà sí àwọn míì bíi pé ó sàn jù wọ́n lọ. Ó gbàfiyèsí pé Jèhófà ni àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀ tó ta yọ lọ́lá jù lọ torí pé ó ń bá àwọn èèyàn aláìpé bíi tiwa da nǹkan pọ̀. Dáfídì kọ̀wé pé: “Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ [Ọlọ́run] sì ni ó sọ mí di ńlá.” (2 Sám. 22:36) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìgbéraga nípa kíkọ́ wa láti ronú bó ṣe yẹ. Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti béèrè pé: “Ta ní mú ọ yàtọ̀ sí ẹlòmíràn? Ní tòótọ́, kí ni ìwọ ní tí kì í ṣe pé ìwọ gbà? Wàyí o, bí ó bá jẹ́ pé gbígbà ni ìwọ gbà á ní tòótọ́, èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣògo bí ẹni pé ìwọ kò gbà á?”—1 Kọ́r. 4:7.
12, 13. (a) Kí nìdí tó fi rọrùn láti di òjòwú? (b) Kí ló máa ń yọrí sí béèyàn bá ń fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ẹlòmíì wò wọ́n?
12 Ohun mìíràn tó tún máa ń ba ìṣọ̀kan jẹ́ ni owú. Nítorí àìpé tá a ti jogún, gbogbo wa ní “ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara,” kódà ẹnì kan tó ti jẹ́ Kristẹni láti ìgbà pípẹ́ lè máa jowú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí bí nǹkan ṣe rí fáwọn míì, nítorí ohun ìní wọn, àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń gbádùn, tàbí nítorí ànímọ́ tí wọ́n ní. (Ják. 4:5) Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan tó ti bímọ lè máa jowú àwọn àǹfààní tí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan ń gbádùn, láìmọ̀ pé òjíṣẹ́ alákòókò kíkún náà lè máa jowú òun náà torí pé ó ní àwọn ọmọ. Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí irú owú bẹ́ẹ̀ ba ìṣọ̀kan wa jẹ́?
13 Ká bàa lè máa yẹra fún owú jíjẹ, ẹ jẹ́ ká rántí pé Bíbélì fi àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ara ìjọ Kristẹni wé àwọn ẹ̀yà ara ẹ̀dá èèyàn. (Ka 1 Kọ́ríńtì 12:14-18.) Bí àpẹẹrẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí kò fara sin ni ojú rẹ wà, tí ọkàn rẹ sì wà ní kọ́lọ́fín, ǹjẹ́ a rí èyí tí kò ṣe pàtàkì sí ẹ nínú méjèèjì? Bákan náà, Jèhófà mọrírì gbogbo àwọn tó jẹ́ ara ìjọ bó tilẹ̀ jẹ́ pé láwọn àkókò kan àwọn kan lè gbajúmọ̀ ju àwọn míì lọ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn arákùnrin wa wò wọ́n. Dípò tí a ó fi máa jowú àwọn míì, a lè fi hàn pé ọ̀ràn wọn jẹ wá lógún. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò túbọ̀ jẹ́ kí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ àti àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì máa ṣe kedere.
Kò Sí Ìṣọ̀kan Láàárín Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì
14, 15. Báwo ni ẹ̀sìn Kristẹni tó di apẹ̀yìndà ṣe yapa síra wọn?
14 Ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ yàtọ̀ pátápátá sí gbọ́nmi-si omi-ò-to tó ń wáyé láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Ní ọ̀rúndún kẹrin, ẹ̀sìn Kristẹni tó di apẹ̀yìndà gbilẹ̀ débi pé olú ọba Róòmù tó jẹ́ abọ̀rìṣà bẹ̀rẹ̀ sí í darí rẹ̀, tó sì pa kún ìmúgbòòrò ẹ̀sìn Kristẹni tó di apẹ̀yìndà. Lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè bẹ̀rẹ̀ sí í yapa kúrò lára ìlú Róòmù, wọ́n sì ń dá ṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ ti Orílẹ̀-èdè wọn sílẹ̀.
15 Ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè yẹn bá ara wọn jagun fún ọ̀pọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún. Ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún àti ìkejìdínlógún, àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ilẹ̀ Faransé àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gbé ìjọsìn Orílẹ̀-èdè wọn lárugẹ, débi pé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè wọn wá dà bí ẹ̀sìn. Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún àti ọ̀rúndún ogún, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni bẹ̀rẹ̀ sí í gba gbogbo aráyé pátá lọ́kàn. Nígbà tó ṣe, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pera wọn ní Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í pín sí onírúurú ẹ̀ya ẹ̀sìn, èyí tó pọ̀ jù lára wọn sì fàyè gba ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni. Kódà, àwọn tó ń lọ sì ṣọ́ọ̀ṣì ti bá àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè míì jagun. Lóde òní, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yapa síra wọn, yálà ní ti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tàbí ní ti ojú tí wọ́n fi ń wo ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni.
16. Irú àwọn ọ̀ràn wo ló mú káwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yapa síra wọn?
16 Ní ọ̀rúndún ogún, àwọn kan lára ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹ̀ya ẹ̀sìn tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pín sí ṣe àgbékalẹ̀ àjọ ìsọdọ̀kan àwọn ṣọ́ọ̀ṣì torí kí wọ́n lè wà ní ìṣọ̀kan. Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti wà lẹ́nu ẹ̀, díẹ̀ làwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó sọra wọn dọ̀kan, síbẹ̀ ẹnu àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò kò lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ìṣẹ́yún, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ àti yíyan àwọn obìnrin sípò àlùfáà. Àwọn aṣáájú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ń ṣera wọn lọ́kan pẹ̀lú àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn tó yàtọ̀ sí tiwọn nípa gbígbójú fo àwọn ẹ̀kọ́ tó mú kí wọ́n yapa síra tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ṣá o, gbígbójú fo irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ ń sọ ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn di ahẹrẹpẹ ni, ó sì dájú pé ìyẹn ò lè mú kí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣera wọn lọ́kan.
Ìsìn Tòótọ́ Kò Fara Mọ́ Ìfẹ́ Orílẹ̀-Èdè Ẹni
17. Ọ̀nà wo ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìsìn tòótọ́ máa gbà so àwọn èèyàn pọ̀ ṣọ̀kan “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́”?
17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aráyé ti yapa síra wọn ju ti ìgbàkigbà rí lọ báyìí, síbẹ̀ ìṣọ̀kan la fi ń dá àwọn olùjọsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀. Míkà tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run sọ pé: “Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀ ní ìṣọ̀kan, bí agbo ẹran nínú ọgbà ẹran.” (Míkà 2:12) Míkà sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí a ṣe máa gbé ìsìn tòótọ́ ga ju àwọn ìsìn kéékèèké mìíràn lọ, yálà wọ́n jẹ́ ẹ̀sìn èké tàbí ti Orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn sọ di ọlọ́run. Ó kọ̀wé pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ síbẹ̀. Nítorí gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa.”—Míkà 4:1, 5.
18. Àwọn ìyípadà wo ni ìjọsìn tòótọ́ ti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe?
18 Míkà tún ṣàlàyé bí ìsìn tòótọ́ ṣe máa mú kí àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá síra wọn tẹ́lẹ̀ wà ní ìṣọ̀kan. Ó sọ pé: “[Àwọn èèyàn láti] ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà àti sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù; òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.‘ . . . Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Míkà 4:2, 3) Àwọn tó ń fi ìbọ̀rìṣà tàbí orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn sọ di ọlọ́run sílẹ̀ kí wọ́n lè máa sin Jèhófà ń gbádùn ìṣọ̀kan níbikíbi tí wọ́n bá wà lágbàáyé. Ọlọ́run ń kọ́ wọn láti máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn.
19. Bí Ọlọ́run ṣe ń mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn wà ní ìṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́ jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere nípa kí ni?
19 Bí Ọlọ́run ṣe ń mú káwọn Kristẹni wà ní ìṣọ̀kan kárí ayé jẹ́ ohun àrà ọ̀tọ̀ àti ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́nà. Ó túbọ̀ ń mú kí olúkúlùkù èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè wà ní ìṣọ̀kan ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Lọ́nà àgbàyanu, èyí jẹ́ ìmúṣẹ ohun tí ìwé Ìṣípayá 7:9, 14 ń tọ́ka sí, ó sì fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run máa tó tú “ẹ̀fúùfù” tó máa pa ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí run sílẹ̀. (Ka Ìṣípayá 7:1-4, 9, 10, 14.) Nígbà náà, ǹjẹ́ àǹfààní ńlá kọ́ ló jẹ́ láti wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé? Báwo ni gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe lè pa kún ìṣọ̀kan yẹn? Èyí ni ohun tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni ìsìn tòótọ́ ṣe ń mú káwọn èèyàn wà ní ìṣọ̀kan?
• Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí owú ba ìṣọ̀kan wa jẹ́?
• Kí nìdí tí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni kò fi lè mú káwọn olùjọsìn tòótọ́ yapa síra?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ibi táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ti wá yàtọ̀ síra
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Báwo ni bó o ṣe ń bá wọn lọ́wọ́ sí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe ń pa kún ìṣọ̀kan?