Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwàásù Àkànṣe Lórílẹ̀-èdè Bulgaria Kẹ́sẹ Járí

Ìwàásù Àkànṣe Lórílẹ̀-èdè Bulgaria Kẹ́sẹ Járí

Ìwàásù Àkànṣe Lórílẹ̀-èdè Bulgaria Kẹ́sẹ Járí

“Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.”​—MÁT. 9:37, 38.

Ọ̀RỌ̀ Jésù yìí mà bá ohun tó wáyé lórílẹ̀-èdè Bulgaria mu o! Orílẹ̀-èdè rírẹwà yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè Balkan ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù. A nílò àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i, tó máa wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méje tó ń gbé lórílẹ̀-èdè náà. Àwọn akéde ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [1,700] ló wà lórílẹ̀-èdè Bulgaria, àmọ́ wọn ò lè kárí gbogbo ìpínlẹ̀ ìwàásù náà. Torí náà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí wọ́n ké sí àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń sọ èdè Bulgarian, tí wọ́n ń gbé káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè Yúróòpù mélòó kan pé kí wọ́n wá lọ́wọ́ nínú ìwàásù àkànṣe kan ní ọdún 2009. Ọ̀sẹ̀ méje ni wọ́n á fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Máa Sọ́nà!” tí wọ́n máa ṣe ní ìlú Sofia, ní August 14 sí 16, 2009, ló sì máa kádìí rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ Àwọn Ará Yọ̀ǹda Láti Lọ

Àwọn arákùnrin tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní ìlú Sofia kò lè sọ bí àwọn tó máa wá láti orílẹ̀-èdè Faransé, Jámánì, Gíríìsì, Ítálì, Poland àti Sípéènì ṣe máa pọ̀ tó. Ó máa gba pé kí wọ́n fi owó ara wọn rìnrìn-àjò lọ sí orílẹ̀-èdè Bulgaria, wọ́n á sì lo àkókò ìsinmi wọn láti wàásù. Ó mà wúni lórí o, láti rí i pé bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, iye àwọn tó forúkọ sílẹ̀ ń pọ̀ sí i, títí tó fi di ọ̀ọ́dúnrún ó dín mẹ́jọ [292]! Nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn forúkọ sílẹ̀, ó máa ṣeé ṣe láti yàn wọ́n sí oríṣi ìlú mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè Bulgaria, àwọn ìlú náà ni: Kazanlak, Sandanski àti Silistra. Àwọn alábòójútó àyíká lórílẹ̀-èdè Bulgaria sọ fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè náà láti kọ́wọ́ ti ìwàásù àkànṣe yìí. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn èèyàn tí iye wọn jẹ́ irínwó ó dín méjìdínlógún [382] fi ìtara wàásù ní ìpínlẹ̀ tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ń wàásù ìhìn rere níbẹ̀.

A rán àwọn arákùnrin tó wà ní àwọn ìjọ àdúgbò láti ṣètò ibi tí àwọn àlejò máa dé sí. Wọ́n háyà àwọn ilé àtàwọn òtẹ́ẹ̀lì olówó pọ́ọ́kú. Àwọn ará tó wà lórílẹ̀-èdè náà ṣiṣẹ́ takuntakun láti ran àwọn àlejò náà lọ́wọ́ kí ara wọn lè mọlé, wọ́n sì pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn. Wọ́n tún háyà àwọn ilé tí wọ́n á ti máa ṣe ìpàdé ní àwọn ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Wọ́n ṣètò pé kí àwọn arákùnrin tó jẹ́ àlejò máa darí àwọn ìpàdé ìjọ. Ó wúni lórí láti rí i pé àwọn akéde àádọ́ta ń pé jọ láti yin Jèhófà ní àwọn ibi tí kò tiẹ̀ ti sí Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo.

Ìtara tí àwọn ará tó wá láti orílẹ̀-èdè míì ní fún ìwàásù àkànṣe yìí ṣàrà ọ̀tọ̀. Lákòókò ẹ̀ẹ̀rùn, ojú ọjọ́ máa ń gbóná gan-an lórílẹ̀-èdè Bulgaria. Àmọ́ ṣá o, kò sí ohun tó lè dí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin onítara yìí lọ́wọ́. Láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta àkọ́kọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn tó lé ní ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000] tó wà ní ìlú Silistra tó wà létí Odò Danube ló gbọ́ ìwàásù. Nígbà tó yá, àwọn ará wàásù dé àwọn abúlé tó wà nítòsí, kódà wọ́n dé abúlé Tutrakan, tó wà ní kìlómítà márùndínlọ́gọ́ta [55] ní ìwọ̀ oòrùn Silistra. Aago mẹ́sàn-án ààbọ̀ àárọ̀ ni wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán, wọ́n máa ń báṣẹ́ lọ di aago méje alẹ́ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bákan náà, torí pé àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn yìí fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù àkànṣe náà, ó ṣeé ṣe fún àwọn tó ṣiṣẹ́ ní ìlú Kazanlak àti Sandanski láti mú ìhìn rere dé àwọn ìlú àtàwọn abúlé tó wà nítòsí.

Kí Ni Wọ́n Gbé Ṣe?

Wọ́n jẹ́rìí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ méje náà. Bí àwọn kan ṣe sọ nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì, àwọn tó ń gbé ní àwọn ìlú wọ̀nyí lè sọ pé, ‘Ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún ìlú wa.’ (Ìṣe 5:28) Àwọn Ẹlẹ́rìí tó lọ́wọ́ nínú ìwàásù àkànṣe yìí fi ìwé ìròyìn bí ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000] sóde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọgọ́rin lé nírínwó àti méjì [482]. Ó dùn mọ́ni pé a dá ìjọ tuntun sílẹ̀ ní ìlú Silistra, ní September 1, 2009, a sì tún ní àwọn àwùjọ ní ìlú Kazanlak àti Sandanski. Ó múni lọ́kàn yọ̀ láti rí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ ìhìn rere fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbà ìwàásù àkànṣe náà tí wọ́n ń tẹ̀ síwájú dáadáa nípa tẹ̀mí.

Ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ ìwàásù àkànṣe náà, arábìnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Sípéènì, tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó ń sọ èdè Bulgarian, wàásù fún Karina, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń ta ìwé ìròyìn ní òpópónà nílùú Silistra. Karina fìfẹ́ hàn sí òtítọ́, ó sì wá sípàdé. Ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọkọ obìnrin yìí kò gbà pé Ọlọ́run wà, torí náà obìnrin yìí sọ pé ibi ìgbafẹ́ kan ni kí wọ́n ti wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì ni wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Daniela, tó dàgbà jù fi ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Ó ka ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tán ní ọ̀sẹ̀ kan, ó sì fi ohun tí Bíbélì sọ pé lílo ère nínú ìjọsìn kò dá a sílò láìjáfara. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré lẹ́yìn tó wá sí ìpàdé ìjọ fún ìgbà àkọ́kọ́, ó sọ fún arábìnrin tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pé: “Ó ń ṣe mí bíi pé mo ti di ọ̀kan lára yín. Kí ni mo ní láti ṣe kí èmi náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù?” Daniela, ń tẹ̀ síwájú dáadáa, pẹ̀lú ìyá rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀.

Ní Kazanlak, arákùnrin kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Bulgaria, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Orlin, tó wá láti orílẹ̀-èdè Ítálì fún ìwàásù àkànṣe náà, ń rìn pa dà lọ sí ibi tó dé sí lẹ́yìn iṣẹ́ ìsìn pápá. Kó tó délé ó wàásù fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì tí wọ́n jókòó sí orí bẹ́ǹṣì ní ibi ìgbafẹ́. Ó fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ó sì sọ fún wọn pé òun máa pa dà wá lọ́jọ́ kejì. Nígbà tí Orlin pa dà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Svetomir, wọ́n sì ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ lọ́jọ́ kejì. Láàárín ọjọ́ mẹ́sàn-án, ìgbà mẹ́jọ ni Orlin kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Svetomir wá sọ pé: “Ọjọ́ méjì ṣáájú kí n tó pàdé rẹ, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí n mọ òun. Mo sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún un pé tó bá lè ràn mí lọ́wọ́, gbogbo ìgbésí ayé mi ni màá fi sìn ín.” Lẹ́yìn tí Orlin pa dà sí orílẹ̀-èdè Ítálì, àwọn ará ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Svetomir lọ, ó sì ń sọ òtítọ́ náà di tirẹ̀.

Àwọn Tó Yọ̀ǹda Ara Wọn Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Gbà

Báwo lọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn tó fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda àkókò ìsinmi wọn, tí wọ́n sì fowó ara wọn rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè míì láti lọ wàásù ìhìn rere? Alàgbà kan tó ń sìn lórílẹ̀-èdè Sípéènì kọ̀wé pé: “Ìwàásù àkànṣe yìí ti mú kí àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Sípéènì, tí wọ́n ń wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Bulgarian, túbọ̀ sún mọ́ra. Ó ní ipa rere lórí àwọn ará tó lọ́wọ́ nínú rẹ̀.” Tọkọtaya kan láti orílẹ̀-èdè Ítálì sọ pé: “Oṣù yìí ló jẹ́ oṣù àgbàyanu jù lọ ní ìgbésí ayé wa!” Wọ́n fi kún un pé: “Ìwàásù àkànṣe yìí ti yí ìgbésí ayé wa pa dà! A ti wá di ẹni ọ̀tun báyìí.” Àwọn tọkọtaya yìí bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa kíkó wá sí orílẹ̀-èdè Bulgaria pátápátá láti lè lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Carina jẹ́ arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tí kò tíì lọ́kọ, ó wá láti orílẹ̀-èdè Sípéènì, ó sì lọ́wọ́ nínú ìwàásù àkànṣe náà ní ìlú Silistra. Lẹ́yìn náà, ó fi iṣẹ́ tó ń ṣe lórílẹ̀-èdè Sípéènì sílẹ̀, ó sì kó wá sí orílẹ̀-èdè Bulgaria láti wá ṣèrànwọ́ fún ìjọ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ní ìlú Silistra. Ó ti tọ́jú owó tó pọ̀ tó táá máa ná lórílẹ̀-èdè Bulgaria fún ọdún kan. Ohun tí Carina sọ nípa ìpinnu rẹ̀ nìyí: “Inú mi dùn gan-an pé Jèhófà jẹ́ kí n lè wá ṣiṣẹ́ sìn lórílẹ̀-èdè Bulgaria níbí, mo sì nírètí pé màá lè dúró pẹ́. Mo ti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì márùn-ún, mẹ́ta lára wọn sì ń wá sípàdé.”

Arábìnrin kan láti orílẹ̀-èdè Ítálì fẹ́ lọ́wọ́ nínú ìwàásù àkànṣe yìí, àmọ́ torí pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tuntun, kò ní àkókò ìsinmi tó pọ̀ tó. Síbẹ̀ kò jẹ́ kí ìyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun, ó ní kí wọ́n fún òun ní ìsinmi oṣù kan tí wọ́n kò ní sanwó rẹ̀, ó sì múra tán láti fiṣẹ́ náà sílẹ̀ tí wọ́n ò bá fọwọ́ sí i. Ó yà á lẹ́nu pé ẹni tó gbà á síṣẹ́ sọ pé: “Kò burú, ìyẹn bó o bá lè fi káàdì ìkíni pélébé ránṣẹ́ sí mi láti orílẹ̀-èdè Bulgaria.” Kò sí iyè méjì pé arábìnrin náà gbà pé Jèhófà ló dáhùn àdúrà òun.

Arábìnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Stanislava tó ń gbé ìlú Varna lórílẹ̀-èdè Bulgaria, tó sì ń ṣiṣẹ́ ní ibì kan tí wọ́n ti ń sanwó gidi fún un, gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ láti lọ́wọ́ nínú ìwàásù àkànṣe náà ní ìlú Silistra. Nígbà tó rí ayọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wá láti ọ̀nà jíjìn kí wọ́n lè wá wàásù ìhìn rere lórílẹ̀-èdè rẹ̀, ńṣe ló bú sẹ́kún. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí bó ṣe ń fi ìgbésí ayé rẹ̀ wá iṣẹ́ ajé kiri. Nígbà tó pa dà sílé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, ó fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ní báyìí, ó láyọ̀ gan-an torí pé ó rántí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ nígbà èwe.—Oníw. 12:1.

Ìbùkún ńlá ló jẹ́ láti máa ṣe déédéé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kò sí ohun míì tó o lè ṣe tó dáa ju pé kó o máa fi àkókò rẹ àti okun rẹ ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí, ìyẹn iṣẹ́ kíkọ́ni àti wíwàásù ìhìn rere. Ǹjẹ́ àwọn ọ̀nà kan wà tí ìwọ fúnra rẹ lè gbà mú ipa tó ò ń kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń gbẹ̀mí là yìí gbòòrò sí i? Àwọn apá ibì kan lè wà lórílẹ̀-èdè rẹ tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ǹjẹ́ o lè kó lọ sí irú àgbègbè bẹ́ẹ̀? O sì tún lè ronú nípa kíkọ́ èdè míì láti ran àwọn èèyàn tí òùngbẹ òtítọ́ Bíbélì ń gbẹ lórílẹ̀-èdè rẹ lọ́wọ́. Ìyípadà yòówù kó o ṣe láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i, mọ̀ dájú pé Jèhófà yóò bù kún ẹ jìngbìnnì.—Òwe 10:22.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Ọjọ́ Mánigbàgbé

Ọ̀pọ̀ àwọn tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míì ní ilẹ̀ Yúróòpù láti lọ́wọ́ nínú ìwàásù àkànṣe yìí ní orílẹ̀-èdè Bulgaria ṣètò láti lọ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Máa Ṣọ́nà!” tí wọ́n ṣe ní ìlú Sofia. Ìṣírí ńlá ló jẹ́ fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lórílẹ̀-èdè Bulgaria láti rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àlejò láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Inú àwọn àwùjọ tó jẹ́ ẹgbàá àti mọ́kàndínlógójì [2,039] dùn jọjọ nígbà tí Arákùnrin Geoffrey Jackson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú odindi Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun lédè Bulgarian jáde! Gbogbo àwọn tó wà níkàlẹ̀ lọ́sàn-án ọjọ́ Friday fi ìmọrírì àtọkànwá wọn hàn nípasẹ̀ àtẹ́wọ́ wọn tó ń ró wàá-wàá fún àkókò gígùn. Kódà ọ̀pọ̀ ló sunkún ayọ̀ lọ́jọ́ náà. Ìtumọ̀ Bíbélì tó péye tó sì rọrùn láti lóye yìí yóò ran àwọn olóòótọ́ ọkàn ọmọ orílẹ̀-èdè Bulgaria lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 30, 31]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

BULGARIA

SOFIA

Sandanski

Silistra

Kazanlak

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

A jẹ́rìí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ méje náà