Aṣáájú Wa Lóde Òní
Aṣáájú Wa Lóde Òní
“Ó sì jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.”—ÌṢÍ. 6:2.
1, 2. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ìṣàkóso Kristi tó bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1914? (b) Àwọn ohun wo ni Kristi ti gbé ṣe látìgbà tí Ọlọ́run ti gbé e gorí ìtẹ́?
ỌDÚN 1914 ni Ọlọ́run gbé Kristi gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Mèsáyà ti Jèhófà. Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wò ó báyìí? Ṣé ọba kan tó jókòó lórí ìtẹ́ to ń ronú ohun tó máa ṣe, tó sì ń bojú wolẹ̀ látìgbàdégbà láti rí bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ìjọ àwọn èèyàn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ni? Tó bá jẹ́ irú ojú tá a fi ń wò ó nìyẹn, a ní láti tún èrò wa pa. Ìwé Sáàmù àti ìwé Ìṣípayá fi hàn pé ó jẹ́ ọba alágbára kan tó ń gun ẹṣin lọ, tó sì ń bá a lọ “ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀,” ó sì ń tẹ̀ síwájú dé “àṣeyọrí” sí rere.—Ìṣí. 6:2; Sm. 2:6-9; 45:1-4.
2 Ohun àkọ́kọ́ tí Kristi ṣe lẹ́yìn tó di ọba ni bó ṣe ṣẹ́gun “dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bíi Máíkẹ́lì olú áńgẹ́lì tó ń darí àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, Kristi lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí Èṣù rẹ̀ kúrò ní ọ̀run mímọ́, ó sì lé wọn jù sórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣí. 12:7-9) Lẹ́yìn náà, bí Jésù ṣe ń ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé e lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà,” òun àti Baba rẹ̀ wá sínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí láti ṣàyẹ̀wò rẹ̀. (Mál. 3:1) Ó ṣèdájọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, torí pé àwọn ni ẹ̀bi wọn pọ̀ jù lọ lára “Bábílónì Ńlá,” wọ́n jẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti àgbèrè tẹ̀mí pẹ̀lú ètò ìṣèlú ayé yìí.—Ìṣí. 18:2, 3, 24.
Ó Yọ́ Àwọn Ẹrú Rẹ̀ Tó Wà Lórí Ilẹ̀ Ayé Mọ́
3, 4. (a) Iṣẹ́ wo ni Kristi ṣàṣeparí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ońṣẹ́” Jèhófà? (b) Kí ni àyẹ̀wò tẹ́ńpìlì fi hàn, ìyànsípò wo sì ni Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ, ṣe?
3 Àyẹ̀wò tí Jèhófà àti “ońṣẹ́” rẹ̀ ṣe nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tó wà lórí ilẹ̀ ayé tún fi hàn pé àwùjọ àwọn Kristẹni tòótọ́ kan wà nínú tẹ́ńpìlì náà tí kì í ṣe apá kan àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Síbẹ̀ náà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yìí, tàbí “àwọn ọmọ Léfì” nílò ìyọ́mọ́. Ńṣe ló rí bí wòlíì Málákì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé: “[Jèhófà] yóò sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń yọ́ fàdákà, tí ó sì ń fọ̀ ọ́ mọ́, yóò sì fọ àwọn ọmọ Léfì mọ́; yóò sì mú wọn mọ́ kedere bí wúrà àti bí fàdákà, dájúdájú, wọn yóò di àwọn ènìyàn tí ń mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn wá fún Jèhófà nínú òdodo.” (Mál. 3:3) Jèhófà lo Kristi Jésù tí í ṣe “ońṣẹ́ májẹ̀mú” rẹ̀ láti yọ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí yìí mọ́.
4 Síbẹ̀, Kristi bá àwọn Kristẹni olóòótọ́ tó jẹ́ ẹni àmì òróró yìí tí wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sí àkókò fún àwọn ará ilé ìgbàgbọ́. Láti ọdún 1879 ni wọ́n ti ń tẹ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì nípa Ìjọba Ọlọ́run jáde nínú ìwé ìròyìn yìí, yálà lásìkò tó rọgbọ tàbí lásìkò wàhálà. Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà tí òun “bá dé” láti ṣàyẹ̀wò àwọn ará ilé ní “ìparí ètò àwọn nǹkan,” òun máa bá ẹrú náà tó ń pèsè “oúnjẹ [fún] wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” Jésù yóò sì pe ẹrú náà ní aláyọ̀, á sì “yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀” tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 24:3, 45-47) Gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ Kristẹni, Kristi ti lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà láti máa bójú tó gbogbo àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Jésù ti pèsè ìtọ́sọ́nà fún àwọn “ará ilé” tí í ṣe àwọn ẹni àmì òróró, ó sì tún pèsè fún àwọn “àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn nípasẹ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí.—Jòh. 10:16.
Kíkórè Ilẹ̀ Ayé
5. Iṣẹ́ wo ni Jòhánù rí tí Mèsáyà Ọba náà ń ṣe nínú ìran?
5 Àpọ́sítélì Jòhánù rí nǹkan míì tí Mèsáyà Ọba tún máa ṣe ní “ọjọ́ Olúwa,” lẹ́yìn tó gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914. Ó kọ̀wé pé: “Mo sì rí, sì wò ó! àwọsánmà funfun kan, àti lórí àwọsánmà náà ẹnì kan jókòó bí ọmọ ènìyàn, pẹ̀lú adé wúrà ní orí rẹ̀ àti dòjé mímú ní ọwọ́ rẹ̀.” (Ìṣí. 1:10; 14:14) Jòhánù gbọ́ tí áńgẹ́lì kan láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ń sọ fún Olùkórè yìí pé kó ti dòjé rẹ̀ bọ̀ ọ́, nítorí pé “ìkórè ilẹ̀ ayé [ti] gbó kárakára.”—Ìṣí. 14:15, 16.
6. Kí ni Jésù sọ pé ó máa wáyé bí àkókò ti ń lọ?
6 “Ìkórè ilẹ̀ ayé” yìí rán wa létí àkàwé Jésù nípa àlìkámà àti àwọn èpò. Jésù fi ara rẹ̀ wé ọkùnrin kan tó gbin èso àlìkámà sínú pápá rẹ̀, tó sì ní in lọ́kàn láti kórè irúgbìn àlìkámà tó kún rẹ́rẹ́ èyí tó ṣàpẹẹrẹ “àwọn ọmọ ìjọba náà,” ìyẹn àwọn Kristẹni tòótọ́ tá a ti fòróró yàn láti ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀tá kan, ìyẹn “Èṣù” fi òru bojú, ó sì lọ fún èpò, ìyẹn “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà” sínú pápá náà. Afúnrúgbìn náà wá sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n fi àlìkámà àti àwọn èpò náà sílẹ̀ títí fi di ìgbà ìkórè, ìyẹn ni “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Nígbà yẹn, ó máa rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti ya àlìkámà kúrò lára àwọn èpò.—Mát. 13:24-30, 36-41.
7. Báwo ni Kristi ṣe ń ṣe iṣẹ́ “ìkórè ilẹ̀ ayé”?
7 Ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí Jòhánù rí, Jésù ti ń ṣe iṣẹ́ ìkórè kárí ayé. “Ìkórè ilẹ̀ ayé” bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe àkójọ àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì “ọmọ ìjọba náà,” ìyẹn “àlìkámà” inú àkàwé Jésù. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ àtàwọn èké Kristẹni hàn gbangba lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, débi pé ó pa kún ṣíṣe àkójọ àwọn àgùntàn mìíràn, tó jẹ́ apá kejì lára “ìkórè ilẹ̀ ayé.” Àwọn wọ̀nyí kì í ṣe “ọmọ ìjọba náà” o, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó fínnúfíndọ̀ fi ara wọn sábẹ́ Ìjọba náà. A kórè wọn látara gbogbo “àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè.” Wọ́n tẹrí ba fún Ìjọba Mèsáyà, tó ní nínú Kristi Jésù àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì “àwọn ẹni mímọ́,” tó máa jọba pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìjọba ọ̀run náà.—Dán. 7:13, 14, 18; Ìṣí. 7:9, 10.
Bí Kristi Ṣe Ń Darí Àwọn Ìjọ
8, 9. (a) Kí ló fi hàn pé yàtọ̀ sí bí ìjọ lápapọ̀ ṣe ń ṣe sí, Kristi tún ń wo bí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ̀? (b) Bá a ṣe fi hàn nínú àwòrán tó wà lójú ìwé 26, àwọn “ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì” wo la gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún?
8 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a rí bí Kristi ṣe ń fojú sí àwọn ohun tó ń lọ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni. Lọ́jọ́ wa yìí, Kristi Aṣáájú wa tó jẹ́ Ọba tí Ọlọ́run ti gbé “gbogbo ọlá àṣẹ . . . ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé” lé lọ́wọ́, ń lo ipò orí rẹ̀ lórí ìjọ àti lórí àwọn alábòójútó tó wà nínú ìjọ kárí ayé. (Mát. 28:18; Kól. 1:18) Jèhófà ti “fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ” àwọn ẹni àmì òróró. (Éfé. 1:22) Fún ìdí yìí, kò sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] tí kì í rí.
9 Jésù rán iṣẹ́ yìí sí ìjọ Tíátírà ayé ìgbàanì pé: “Ìwọ̀nyí ni ohun tí Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú tí ó ní dà bí ọwọ́ iná ajófòfò, . . . ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ.’” (Ìṣí. 2:18, 19) Ó bá àwọn ará ìjọ náà wí nítorí ìwà ìṣekúṣe àti ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì tí wọ́n ń gbé, ó sọ fún wọn pé: “Èmi ni ẹni tí ń wá inú kíndìnrín àti ọkàn-àyà, èmi yóò sì fi fún yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ yín.” (Ìṣí. 2:23) Gbólóhùn yìí fi hàn pé kì í ṣe bí ìjọ lápapọ̀ ṣe ń ṣe sí nìkan ni Kristi ń rí, àmọ́ ó tún ń wo bí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ náà ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ̀. Jésù gbóríyìn fún àwọn Kristẹni kan ní ìjọ Tíátírà “tí kò mọ ‘àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì.’” (Ìṣí. 2:24) Bákan náà, lóde òní, ó fọwọ́ sí àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbàlagbà tí kò tọwọ́ bọ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì” nípasẹ̀ wíwò wọ́n lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí gbígbá àwọn géèmù tó ń gbé ìwà ipá lárugẹ lórí kọ̀ǹpútà tàbí tí wọn kò fàyè gba èròkérò tó gbòde kan láàárín àwọn èèyàn. Inú rẹ̀ mà ń dùn gan-an o, bó ṣe ń wo ìsapá ọ̀pọ̀ Kristẹni lóde òní àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n ní bí wọ́n ti ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ ní gbogbo apá ìgbésí ayé wọn!
10. Báwo la ṣe ṣàpẹẹrẹ bí Kristi ṣe ń darí àwọn alàgbà, àmọ́ kí ni wọ́n ní láti mọ̀?
10 Kristi ń ṣe àbójútó onífẹ̀ẹ́ lórí àwọn ìjọ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ àwọn alàgbà tá a yàn sípò. (Éfé. 4:8, 11, 12) Gbogbo àwọn alábòójútó ní ọ̀rúndún kìíní la fẹ̀mí bí. Ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe wọn pé wọ́n jẹ́ ìràwọ̀ lọ́wọ́ ọ̀tún Kristi. (Ìṣí. 1:16, 20) Lóde òní, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn alàgbà ló jẹ́ ara àgùntàn mìíràn. Ẹ̀yìn tá a ti gbàdúrà fún ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run la yàn wọ́n, torí náà a lè máa wo àwọn náà pé wọ́n wà lábẹ́ ìdarí Kristi. (Ìṣe 20:28) Síbẹ̀, wọ́n mọ̀ pé Kristi ń lo àwùjọ kékeré ti àwọn Kristẹni ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró gẹ́gẹ́ bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí láti máa darí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé kí wọ́n sì máa tọ́ wọn sọ́nà.—Ka Ìṣe 15:6, 28-30.
“Máa Bọ̀, Jésù Olúwa”
11. Kí nìdí tá a fi ń hára gàgà pé kí Aṣáájú wa dé kíákíá?
11 Nínú ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù rí, Jésù sọ ní ìgbà mélòó kan pé òun ń bọ̀ kíákíá. (Ìṣí. 2:16; 3:11; 22:7, 20) Kò sí iyè méjì pé bíbọ̀ tó ń bọ̀ láti ṣèdájọ́ Bábílónì Ńlá àti ìyókù ètò búburú Sátánì ló ń tọ́ka sí. (2 Tẹs. 1:7, 8) Bí àpọ́sítélì Jòhánù tó ti darúgbó ṣe ń hára gàgà láti rí ìmúṣẹ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu tá a ti sọ tẹ́lẹ̀, ó kígbe pé: “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.” Àwa tá à ń gbé ní àkókò òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí náà ń hára gàgà láti rí Aṣáájú wa àti Ọba wa kó dé nínú agbára Ìjọba láti ya orúkọ Bàbá rẹ̀ sí mímọ́, kó sì dá ipò Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre.
12. Iṣẹ́ wo ni Kristi máa ṣàṣeparí rẹ̀ ká tó tú ẹ̀fúùfù ìparun sílẹ̀?
12 Èyí tó gbẹ̀yìn lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, tí wọ́n jẹ́ ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí yóò gba èdìdì ìkẹyìn, kí Jésù tó wá gbéjà ko ètò Sátánì tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì fi hàn kedere pé a kò ní tú ẹ̀fúùfù ìparun lórí ètò Sátánì sílẹ̀ kí fífi èdìdì di àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó parí.—Ìṣí. 7:1-4.
13. Báwo ni Kristi ṣe máa mú kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ ní apá àkọ́kọ́ “ìpọ́njú ńlá” náà?
13 Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé ni kò mọ̀ nípa “wíwàníhìn-ín” Kristi láti ọdún 1914. (2 Pét. 3:3, 4) Àmọ́, láìpẹ́, wọ́n máa mọ̀ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ nígbà tó bá mú ìdájọ́ Jèhófà wá sórí onírúurú apá ẹ̀ka ètò àwọn nǹkan Sátánì. Ìparun “ọkùnrin oníwà àìlófin” náà, ìyẹn àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, yóò jẹ́ ẹ̀rí “ìfarahàn wíwàníhìn-ín rẹ̀” tí kò ṣeé já ní koro. (Ka 2 Tẹsalóníkà 2:3, 8.) Yóò tún jẹ́ ẹ̀rí tó hàn gbangba pé Kristi ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ tí Jèhófà yàn. (Ka 2 Tímótì 4:1.) Ìparun àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ apá tó jẹ̀bi jù lọ lára Bábílónì Ńlá ló máa kọ́kọ́ wáyé, kí Bábílónì Ńlá tó jẹ́ ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé tó pa run yán-ányán-an. Jèhófà máa fi sọ́kàn àwọn aṣáájú òṣèlú láti jẹ aṣẹ́wó ìsìn yìí run. (Ìṣí. 17:15-18) Ìyẹn ló máa jẹ́ apá àkọ́kọ́ lára “ìpọ́njú ńlá” náà.—Mát. 24:21.
14. (a) Kí nìdí tí a ó fi ké apá àkọ́kọ́ lára ìpọ́njú ńlá náà kúrú? (b) Kí ni “àmì Ọmọ ènìyàn” máa túmọ̀ sí fún àwọn èèyàn Jèhófà?
14 Jésù sọ pé a máa ké ọjọ́ ìpọ́njú ńlá náà kúrú “ní tìtorí àwọn àyànfẹ́,” ìyẹn àwọn àṣẹ́kù lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 24:22) Jèhófà kò ní jẹ́ kí ìgbéjàkò tó máa fa ìparun ìsìn èké yìí pa àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn rẹ́. Jésù wá fi kún un pé “lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọnnì,” àmì yóò wà nínú oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀, “nígbà náà sì ni àmì Ọmọ ènìyàn yóò fara hàn ní ọ̀run.” Èyí yóò mú kí àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé “lu ara wọn nínú ìdárò.” Àmọ́, ọ̀rọ̀ kò ní rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹni àmì òróró tó nírètí ti ọ̀run, àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ní ìrètí ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé. Ńṣe ni wọ́n máa ‘gbé ara wọn nà ró ṣánṣán, tí wọ́n á sì gbé orí wọn sókè, nítorí pé ìdáǹdè wọn ń sún mọ́lé.’—Mát. 24:29, 30; Lúùkù 21:25-28.
15. Iṣẹ́ wo ni Kristi máa ṣe tó bá dé?
15 Kí Ọmọ ènìyàn tó parí ìṣẹ́gun rẹ̀, ó tún máa wá lọ́nà míì. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀, yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́. Yóò sì fi àwọn àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ewúrẹ́ sí òsì rẹ̀.” (Mát. 25:31-33) Èyí túmọ̀ sí pé Kristi máa wá gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ láti pín àwọn èèyàn “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” sí apá méjì: “àwọn àgùntàn,” ìyẹn àwọn tó ti máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn arákùnrin rẹ̀ (àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé), àti “àwọn ewúrẹ́,” ìyẹn àwọn “tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” (2 Tẹs. 1:7, 8) Àwọn àgùntàn tí Bíbélì pè ní “àwọn olódodo” yóò jèrè “ìyè àìnípẹ̀kun” lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ewúrẹ́ “yóò sì lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun,” tàbí ìparun.—Mát. 25:34, 40, 41, 45, 46.
Jésù Parí Ìṣẹ́gun Rẹ̀
16. Báwo ni Kristi Aṣáájú wa ṣe máa parí ìṣẹ́gun rẹ̀?
16 Tá a bá ti fi èdìdì di gbogbo àwọn tó máa jẹ́ ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Kristi, tí àwọn tó kà sí àgùntàn sì ti wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ fún ìgbàlà, nígbà náà Kristi lè máa bá a lọ láti “parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” (Ìṣí. 5:9, 10; 6:2) Jésù yóò ṣáájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn áńgẹ́lì alágbára, tí kò sí àní-àní pé wọ́n jẹ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ tó jíǹde, yóò sì pa gbogbo ètò ìṣèlú Sátánì run, tó fi mọ́ ètò ìjọba ológun àti ètò ọrọ̀ ajé lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣí. 2:26, 27; 19:11-21) Kristi yóò parí ìṣẹ́gun rẹ̀ nígbà tó bá pa ètò búburú Sátánì run. Lẹ́yìn náà á wá sọ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí Èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún.—Ìṣí. 20:1-3.
17. Ibo ni Kristi máa darí àwọn àgùntàn mìíràn rẹ̀ lọ nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún, kí ló sì yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
17 Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti àwọn àgùntàn mìíràn tó máa la ìpọ́njú ńlá náà já, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀dọ́ Àgùntàn, tí ó wà ní àárín ìtẹ́ náà, yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, yóò sì máa ṣamọ̀nà wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè.” (Ìṣí. 7:9, 17) Bẹ́ẹ̀ ni o, nípasẹ̀ Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún rẹ̀, Kristi yóò máa bá a lọ láti darí àwọn àgùntàn mìíràn, tó ń fetí sí ohùn rẹ̀ lóòótọ́, á sì ṣamọ̀nà wọn dé ìyè àìnípẹ̀kun. (Ka Jòhánù 10:16, 26-28.) Ǹjẹ́ ká máa fi ìṣòtítọ́ tẹ̀ lé Aṣáájú wa tó jẹ́ ọba, nísinsìnyí àti títí dé inú ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí!
Àtúnyẹ̀wò
• Àwọn ohun wo ni Kristi gbé lẹ́yìn tí Ọlọ́run gbé e gorí ìtẹ́?
• Ta ni Kristi ń lò lórí ilẹ̀ ayé láti darí ìjọ?
• Àwọn ọ̀nà míì wo ni Kristi Aṣáájú wa ṣì máa gbà wá?
• Báwo ni Kristi á ṣe máa bá a lọ láti darí wa nínú ayé tuntun?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn èèyàn á mọ̀ nípa wíwàníhìn-ín Kristi nígbà tó bá pa ètò búburú Sátánì run