Máa Fi Taratara Wá Ìbùkún Jèhófà
Máa Fi Taratara Wá Ìbùkún Jèhófà
“[Ọlọ́run] ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—HÉB. 11:6.
1, 2. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń wá ìbùkún Ọlọ́run? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kó wù wá láti rí ìbùkún Jèhófà gbà?
“ỌLỌ́RUN á bù kún ẹ!” Ní àwọn ilẹ̀ kan, ó wọ́pọ̀ kí àjèjì kan sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún ẹni tó bá sín. Àwọn àlùfáà onírúurú ẹ̀sìn náà máa ń tọrọ ìbùkún Ọlọ́run sórí àwọn èèyàn, àwọn ẹranko àtàwọn nǹkan tí kò lẹ́mìí. Ó lè wu àwọn kan láti rìnrìn àjò lọ sáwọn ibì kan lórúkọ ẹ̀sìn nítorí àtirí ìbùkún gbà. Àwọn olóṣèlú náà máa ń tọrọ ìbùkún Ọlọ́run sórí orílẹ̀-èdè wọn. Ṣé o rò pé ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa gbà tọrọ ìbùkún Ọlọ́run nìyí? Ṣé wọ́n máa ń rí irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ gbà? Àwọn wo gan-an ni wọ́n máa ń rí ìbùkún Ọlọ́run gbà, kí sì nìdí?
2 Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn èèyàn mímọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni àlàáfíà, tí wọ́n wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè, máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé láìka ìkórìíra àti inúnibíni sí. (Aísá. 2:2-4; Mát. 24:14; Ìṣí. 7:9, 14) Àwa tá a ti gbà láti di ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí, ń fẹ́ ìbùkún Ọlọ́run, a sì nílò rẹ̀ torí pé ìyẹn ni ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà ṣàṣeyọrí. (Sm. 127:1) Àmọ́, báwo la ṣe lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà?
Ìbùkún Máa Ń Dé Bá Àwọn Onígbọràn
3. Ká ní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣègbọràn, kí ni ì bá ti jẹ́ àbájáde rẹ̀?
3 Ka Òwe 10:6, 7. Kó tó di pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Jèhófà sọ fún wọn pé wọ́n máa láásìkí, òun sì máa dáàbò bò wọ́n lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ bí wọ́n bá ṣègbọràn sí àṣẹ òun. (Diu. 28:1, 2) Kì í wulẹ̀ ṣe pé àwọn èèyàn Jèhófà yìí máa rí ìbùkún Ọlọ́run gbà nìkan ni, àmọ́ ńṣe ló máa “dé bá” wọn. Ó dájú gbangba pé àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn máa rí ìbùkún Ọlọ́run gbà.
4. Kí ló wé mọ́ jíjẹ́ onígbọràn látọkàn wá?
4 Ọ̀nà wo ló yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà jẹ́ onígbọràn? Òfin Ọlọ́run sọ pé inú Ọlọ́run kò ní dùn sí i bí àwọn èèyàn rẹ̀ bá kùnà láti “fi ayọ̀ yíyọ̀ àti ìdùnnú ọkàn-àyà” sìn ín. (Ka Diutarónómì 28:45-47.) Jèhófà ò fẹ́ ká máa ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ òun lọ́nà gbà-má-póò-rọ́wọ́ọ̀-mi, irú èyí tá a lè retí pé káwọn ẹranko tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá ṣe. (Máàkù 1:27; Ják. 3:3) Ìfẹ́ fún Ọlọ́run ló máa ń mú kéèyàn ṣègbọràn sí i látọkàn wá. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ á máa láyọ̀ torí pé ó gbà gbọ́ pé àwọn àṣẹ Jèhófà kì í ṣe ẹrù ìnira àti pé “òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Héb. 11:6; 1 Jòh. 5:3.
5. Báwo ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Jèhófà ṣe lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti pa òfin tó wà nínú Diutarónómì 15:7, 8 mọ́?
5 Ṣe àgbéyẹ̀wò bí níní ìgbẹ́kẹ̀lé pé èèyàn máa rí ìbùkún Ọlọ́run gbà ṣe lè mú kéèyàn pa òfin tó wà nínú Diutarónómì 15:7, 8 mọ́. (Kà á.) Béèyàn bá ń fi ìlọ́tìkọ̀ pa òfin yẹn mọ́, ó ṣeé ṣe kí ara tu àwọn òtòṣì dé ìwọ̀n àyè kan, àmọ́ ṣé irú ìgbọràn oréfèé bẹ́ẹ̀ lè mú káwọn èèyàn Ọlọ́run ní àjọṣe tó dáa láàárín ara wọn kí wọ́n sì máa láyọ̀? Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, ǹjẹ́ irú ìgbọràn gbà-máà-bínú bẹ́ẹ̀ á fi hàn pé èèyàn ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà lè pèsè ohun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe aláìní àti pé èèyàn mọrírì àǹfààní tóun ní láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà ọ̀làwọ́ Ọlọ́run? Rárá! Ọlọ́run máa ń kíyè sí ohun tó wà lọ́kàn gbogbo àwọn tó bá ń hùwà ọ̀làwọ́ láì lọ́ tìkọ̀, ó sì ṣèlérí pé òun máa bù kún wọn nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá dáwọ́ lé. (Diu. 15:10) Béèyàn bá ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí yẹn, ó máa fẹ́ láti ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀, ìyẹn sì máa yọrí sí ìbùkún jìngbìnnì.—Òwe 28:20.
6. Ìdánilójú wo ló yẹ kí ìwé Hébérù 11:6 mú ká ní?
6 Ní àfikún sí níní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùsẹ̀san, ìwé Hébérù 11:6 tànmọ́lẹ̀ sórí ànímọ́ míì tá a nílò ká tó lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà. Kíyè sí i pé àwọn tí Jèhófà ń san ẹ̀san fún ni àwọn tó “ń fi taratara wá a.” Ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a lò níhìn-ín túmọ̀ sí ohun tá a fi gbogbo ara ṣe àti ohun tá a ṣe láìsí ìpínyà ọkàn. Ẹ sì wo bí ìyẹn ṣe jẹ́ ká rí àrídájú nípa ọ̀nà tí ìbùkún Ọlọ́run ń gbà wá! Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà, “ẹni tí kò lè purọ́,” ló ń gbà wá. (Títù 1:2) Ó ti fi hàn láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá pé gbogbo ìlérí tóun ṣe pátá ló ṣeé fọkàn tán. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò jẹ́ kùnà láé; gbogbo ìgbà ló máa ń nímùúṣẹ. (Aísá. 55:11) Torí náà, ó dá wa lójú hán-ún-hán-ún pé tá a bá ní ojúlówó ìgbàgbọ́, Ọlọ́run máa di Olùsẹ̀san fún wa.
7. Báwo la ṣe lè rí ìbùkún gbà nípasẹ̀ “irú-ọmọ” Ábúráhámù?
7 Jésù Kristi ni apá àkọ́kọ́ lára “irú-ọmọ” Ábúráhámù. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni apá kejì lára “irú-ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí náà. A ti pàṣẹ fún wọn láti “polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá ẹni tí ó pè [wọ́n] jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (Gál. 3:7-9, 14, 16, 26-29; 1 Pét. 2:9) Kò sí bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà bí a kò bá ka àwọn tí Jésù ti yàn sípò láti máa bójú tó àwọn ohun ìní rẹ̀ sí. Láìsí ìrànlọ́wọ́ tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè, a kò lè mọ bí àwọn ohun tá à ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó, a kò sì lè lóye bá a ṣe lè fi wọ́n sílò. (Mát. 24:45-47) Bá a bá ń fi àwọn ohun tá à ń kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ sílò, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti rí ìbùkún Ọlọ́run gbà.
Bá A Ṣe Lè Máa Fi Ṣíṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run Sípò Àkọ́kọ́
8, 9. Báwo ni Jékọ́bù, tó jẹ́ baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó ń tọrọ lọ́wọ́ Ọlọ́run?
8 Bá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ ká sapá tokuntokun ká tó lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà, ó máa mú ká rántí Jékọ́bù, tó jẹ́ baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kò mọ bí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù ṣe máa nímùúṣẹ, àmọ́ ó gbà gbọ́ pé Jèhófà máa sọ àtọmọdọ́mọ bàbá rẹ̀ àgbà di púpọ̀ rẹpẹtẹ, wọ́n sì máa di orílẹ̀-èdè ńlá. Torí náà, lọ́dún 1781 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jékọ́bù rìnrìn àjò lọ sí ìlú Háránì láti wá ìyàwó. Kì í wulẹ̀ ṣe alábàákẹ́gbẹ́ rere ló ń wá; kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń wá obìnrin tó jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà tí àwọn nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, tó sì máa jẹ́ ìyá rere fún àwọn ọmọ tó bá bí.
9 A mọ̀ pé Jékọ́bù bá ìbátan rẹ̀ tó ń jẹ́ Rákélì pàdé. Ó nífẹ̀ẹ́ Rákélì ó sì gbà láti ṣiṣẹ́ fún Lábánì tó jẹ́ bàbá rẹ̀, fún ọdún méje kó bàa lè di ìyàwó rẹ̀. Èyí kì í ṣe ìtàn eré ìfẹ́ tó kàn gbádùn mọ́ni ṣá o. Ó dájú pé Jékọ́bù mọ̀ nípa ìlérí tí Ọlọ́run Olódùmarè ti ṣe fún baba ńlá rẹ̀ Ábúráhámù, èyí tó tún sọ fún Ísáákì tó jẹ́ baba rẹ̀. (Jẹ́n. 18:18; 22:17, 18; 26:3-5, 24, 25) Ísáákì náà sì sọ ọ́ fún ọmọ rẹ̀ Jékọ́bù pé: “Ọlọ́run Olódùmarè yóò sì bù kún ọ, yóò sì mú ọ máa so èso, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, dájúdájú, ìwọ yóò di ìjọ àwọn ènìyàn. Òun yóò sì fi ìbùkún Ábúráhámù fún ọ, fún ìwọ àti fún irú-ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ, kí o lè gba ilẹ̀ tí o ti ṣe àtìpó, èyí tí Ọlọ́run ti fi fún Ábúráhámù.” (Jẹ́n. 28:3, 4) Torí náà, gbogbo ìsapá Jékọ́bù láti wá aya rere kó sì ní ìdílé tirẹ̀ fi hàn pé ohun tí Jèhófà sọ dá a lójú.
10. Kí nìdí tó fi dùn mọ́ Jèhófà nínú láti bù kún Jékọ́bù?
10 Jékọ́bù ò wá bó ṣe máa di ọlọ́rọ̀ kó lè rówó tọ́jú ìdílé rẹ̀ o. Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ló gbà á lọ́kàn. Bí Jèhófà ṣe máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ ló ń rò. Jékọ́bù ti múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe kó lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà láìka ìdènà sí. Irú ẹ̀mí yìí ló wà lọ́kàn rẹ̀ títí tó fi dàgbà, ó sì rí ìbùkún Jèhófà gbà nítorí rẹ̀.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 32:24-29.
11. Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣí payá, kí ló yẹ ká sapá láti ṣe?
11 Bíi ti Jékọ́bù, a kò mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa mú ète rẹ̀ ṣẹ. Síbẹ̀, bá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ohun tó yẹ ká máa fojú sọ́nà fún nípa “ọjọ́ Jèhófà” kò ní ṣókùnkùn sí wa. (2 Pét. 3:10, 17) Bí àpẹẹrẹ, a kò mọ ìgbà tí ọjọ́ Jèhófà máa dé, àmọ́ a mọ̀ pé ó ti sún mọ́lé. A ní ìgbàgbọ́ nínú ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé bá a bá ń jẹ́rìí kúnnákúnná ní ìwọ̀nba àkókò kúkúrú tó ṣẹ́ kù yìí, a máa gba ara wa àti àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wa là.—1 Tím. 4:16.
12. Kí ló yẹ kó dá wa lójú?
12 A mọ̀ pé òpin lè dé ní ìgbàkigbà; Jèhófà kò ní dúró dìgbà tá a bá tó jẹ́rìí fún gbogbo àwọn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Mát. 10:23) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, à ń rí ìtọ́sọ́nà gbà nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́nà tó gbéṣẹ́. Nípa ìgbàgbọ́, à ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí dé ibi tí agbára wa bá gbé e dé, a sì ń lo àwọn ohun èlò èyíkéyìí tó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa. Ṣé ìpínlẹ̀ ìwàásù táwọn èèyàn bá ti ń tẹ́tí sí wa nìkan lá o ti máa ṣiṣẹ́? Báwo tiẹ̀ la ṣe lè mọ̀ tẹ́lẹ̀ bóyá wọ́n a gbọ́rọ̀ wa ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kan tàbí wọn kò ní gbọ́? (Ka Oníwàásù 11:5, 6.) Tiwa ni pé ká ṣáà máa wàásù, ká sì ní ìgbọ́kànlé pé a máa rí ìbùkún Jèhófà gbà. (1 Kọ́r. 3:6, 7) Ó dá wa lójú pé Jèhófà ń kíyè sí bá a ṣe ń sapá tokuntokun, òun náà á sì máa tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ pèsè ìtọ́sọ́nà tá a bá nílò fún wa.—Sm. 32:8.
Bá A Ṣe Lè Máa Wá Ẹ̀mí Mímọ́
13, 14. Kí ló jẹ́ ká mọ ọ̀nà tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà ń mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kúnjú ìwọ̀n?
13 Bó bá ń ṣe wá bíi pé a kò kúnjú ìwọ̀n láti ṣe ojúṣe kan tàbí pé a kò lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ńkọ́? A gbọ́dọ̀ béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé kó tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún wa lókun kí ànímọ́ èyíkéyìí tá a bá ń lò nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lè sunwọ̀n sí i. (Ka Lúùkù 11:13.) Ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú káwọn èèyàn tóótun láti ṣe iṣẹ́ kan tàbí kí wọ́n ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan láìka ipò wọn tàbí ohun tí wọ́n mọ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ, kété tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò nílùú Íjíbítì, ẹ̀mí Ọlọ́run fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn àtàwọn ẹrú lágbára láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tó wá gbéjà kò wọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò nírìírí iṣẹ́ ogun jíjà. (Ẹ́kís. 17:8-13) Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ẹ̀mí Ọlọ́run yìí tún fún Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù ní ọgbọ́n láti lo àwòrán ìkọ́lé rírẹwà tí Ọlọ́run mí sí fún kíkọ́ àgọ́.—Ẹ́kís. 31:2-6; 35:30-35.
14 Lóde òní, ẹ̀mí tó lágbára yẹn mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti máa bójú tó àwọn ohun tí ètò Ọlọ́run nílò nígbà tó pọn dandan pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀wé fúnra wọn. Nínú lẹ́tà kan, Arákùnrin R. J. Martin, tó jẹ́ alábòójútó ibi ìtẹ̀wé nígbà yẹn, ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbé ṣe ní ọdún 1927. Ó sọ pé: “Ní àkókò yíyẹ, Olúwa ṣí ilẹ̀kùn sílẹ̀ fún wa; ẹ̀rọ [ìtẹ̀wé] alátẹ̀yípo ńlá náà sì tẹ̀ wá lọ́wọ́, ó bọ́ sọ́wọ́ àwa tí a kò mọ ohunkóhun nípa bí wọ́n ṣe ṣe é àti bó ṣe ń ṣiṣẹ́. Àmọ́, Olúwa mọ bó ṣe lè ta ọkàn àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún un jí. . . . Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré, ó ṣeé ṣe fún wa láti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ẹ̀rọ náà; ó ń ṣiṣẹ́ títí di báyìí, iṣẹ́ tí àwọn tó ṣe é gan-an ò mọ̀ pé ó lè ṣe.” Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa bù kún irú ìsapá àfi-taratara-ṣe bẹ́ẹ̀ títí di òní yìí.
15. Báwo ni ìwé Róòmù 8:11 ṣe lè fún àwọn tó ń dojú kọ àdánwò ní ìṣírí?
15 Onírúurú ọ̀nà ni ẹ̀mí Jèhófà ń gbà ṣiṣẹ́. Ẹ̀mí yẹn wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn àtakò líle koko. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé a dojú kọ àdánwò tó pọ̀ ńkọ́? A lè rí okun gbà látinú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Róòmù 7:21, 25 àti 8:11. Bẹ́ẹ̀ ni, “ẹ̀mí ẹni tí ó gbé Jésù dìde kúrò nínú òkú” lè ṣiṣẹ́ fún wa, kó sì sọ wá di alágbára ká bàa lè borí nínú ìjàkadì wa lòdì sí àwọn ìfẹ́ ọkàn ti ẹran ara. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró la darí gbólóhùn yẹn sí, síbẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni ìlànà yẹn kàn. Gbogbo wa lè jèrè ìyè bá a bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Kristi, tá à ń sapá láti sọ àwọn ìfẹ́ ọkàn tí kò tọ́ di òkú, tá a sì ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń fúnni.
16. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká bàa lè rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà?
16 Ǹjẹ́ a lè retí pé kí Ọlọ́run fún wa ní ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ láìjẹ́ pé a sapá láti rí i gbà? Rárá o. Yàtọ̀ sí gbígbàdúrà fún un, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó mí sí taápọntaápọn. (Òwe 2:1-6) Ní àfikún, ẹ̀mí Ọlọ́run wà lórí ìjọ Kristẹni. Bá a bá ń wá sí ìpàdé déédéé, ìyẹn á fi hàn pé a fẹ́ láti máa “gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.” (Ìṣí. 3:6) A sì tún gbọ́dọ̀ máa fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ sílò tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀. Ìwé Òwe 1:23 gbà wá níyànjú pé: “Yí padà nítorí ìbáwí àfitọ́nisọ́nà mi. Nígbà náà, èmi yóò mú kí ẹ̀mí mi tú jáde sórí yín.” Ó dájú pé Ọlọ́run máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ “fún àwọn tí ń ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso.”—Ìṣe 5:32.
17. Kí la lè fi ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà bù kún ìsapá wa wé?
17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a nílò ìsapá àfi-taratara-ṣe ká tó lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà, ó yẹ ká rántí pé iṣẹ́ àṣekára nìkan kò tó láti mú ká rí ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ohun rere tí Jèhófà ń fi fún àwọn èèyàn rẹ̀. A lè fi ipa tí ìbùkún yìí ń ní lórí ìsapá wa wé ọ̀nà tí oúnjẹ tó dára ń gbà ṣe ara wa lóore. Ọlọ́run ṣe ara wa lọ́nà tó fi jẹ́ pé a máa ń gbádùn oúnjẹ a sì máa ń rí àwọn ohun aṣaralóore látinú rẹ̀. Ọlọ́run náà ló pèsè oúnjẹ tá à ń jẹ. A kò ní òye kíkún nípa bí èròjà tó ń ṣara lóore ṣe dé inú oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀ nínú wa kò lè ṣàlàyé bí ara wa ṣe ń sọ oúnjẹ tá à ń jẹ di agbára tó ń gbé wa ṣiṣẹ́. Ohun tá a kàn mọ̀ ni pé oúnjẹ ń ṣiṣẹ́ lára wa, a sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípa jíjẹ oúnjẹ. Bá a bá yàn láti jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore, àbájáde rẹ̀ á túbọ̀ dára gan-an. Bákan náà, Jèhófà ti jẹ́ ká mọ ohun tí ẹni tó bá máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun gbọ́dọ̀ ṣe, ó sì pèsè ìrànlọ́wọ́ tá a nílò kọ́wọ́ wa lè tẹ àwọn nǹkan náà. Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ náà, torí náà, ó yẹ láti gba ìyìn wa. Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ká máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ká lè rí ìbùkún rẹ̀ gbà.—Hág. 2:18, 19.
18. Kí lo pinnu láti ṣe, kí sì nìdí?
18 Nítorí náà, máa fi gbogbo agbára rẹ ṣe ojúṣe rẹ nínú ohun gbogbo. Nígbà gbogbo, máa ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà ló máa mú kó o ṣàṣeyọrí. (Máàkù 11:23, 24) Bó o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé “olúkúlùkù ẹni tí ń wá kiri ń rí.” (Mát. 7:8) Ọlọ́run máa bù kún àwọn ẹni àmì òróró nípa fífún wọn ní “adé ìyè” ní ọ̀run. (Ják. 1:12) Inú àwọn “àgùntàn mìíràn” Kristi tí wọ́n ń sapá láti rí ìbùkún Ọlọ́run gbà nípasẹ̀ irú-ọmọ Ábúráhámù máa dùn nígbà tí Kristi bá ké sí wọn pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Jòh. 10:16; Mát. 25:34) Bẹ́ẹ̀ ni, “àwọn ẹni tí [Ọlọ́run] ń bù kún ni àwọn tí yóò ni ilẹ̀ ayé, . . . wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sm. 37:22, 29.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ló wé mọ́ ojúlówó ìgbọràn?
• Kí la lè ṣe ká bàa lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà?
• Báwo la ṣe lè rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà, báwo ló sì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Jékọ́bù wọ̀yá ìjà pẹ̀lú áńgẹ́lì kan kó bàa lè rí ìbùkún Jèhófà gbà.
Ṣé ìwọ náà máa ń fi taratara sapá bẹ́ẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fún Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù láti ní òye tó ta yọ