Mo Sìn Lásìkò Ìmúgbòòrò Tó Bùáyà
Mo Sìn Lásìkò Ìmúgbòòrò Tó Bùáyà
Gẹ́gẹ́ bí Harley Harris ṣe sọ ọ́
Ní ọjọ́ kejì oṣù September ọdún 1950, ní àgbègbè Kennett, ní ìpínlẹ̀ Missouri, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, a wà ní àpéjọ àyíká, àwọn jàǹdùkú sì yí wa ká. Olórí ìlú náà mú àwọn Ẹ̀ṣọ́ Orílẹ̀-èdè wá kí wọ́n lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú náà. Àwọn ọmọ ogun tó gbé ìbọn tó ní ọ̀bẹ tí wọ́n ń fi sí ìdí ìbọn dání kún ojú pópó. Àwọn èèyàn ń bú wa bá a ṣe ń lọ sídìí ọkọ̀ wa, a sì wà á lọ sí ìlú Cape Girardeau ní ìpínlẹ̀ Missouri láti lọ parí apá tó kù lára àpéjọ náà níbẹ̀. Ibẹ̀ ni mo ti ṣe ìrìbọmi lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá. Àmọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ bí mo ṣe dẹni tó ń sin Jèhófà nígbà rúkèrúdò yẹn.
NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ àwọn ọdún 1930, àwọn òbí dádì mi àtàwọn ọmọ wọn mẹ́jọ gbọ́ àsọyé Arákùnrin Rutherford tí wọ́n gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀, ó sì dá wọn lójú pé wọ́n ti rí òtítọ́. Àwọn òbí mi, Bay àti Mildred Harris, ṣe ìrìbọmi ní ọdún 1935 ní àpéjọ tá a ṣe ní ìlú Washington, D.C., olú ìlú orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Inú wọn dùn gan-an láti mọ̀ pé àwọn jẹ́ ara “ọ̀pọlọpọ enia” tàbí “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá mọ̀ ní àpéjọ yẹn!—Ìṣí. 7:9, 14; Bibeli Mimọ.
Ọdún tó tẹ̀ lé e ni wọ́n bí mi. Ọdún kan lẹ́yìn náà, àwọn òbí mi kó lọ sí àgbègbè àdádó kan ní ìpínlẹ̀ Mississippi. Ní àkókò tá a fi ń gbé ní ìpínlẹ̀ yẹn, kò sí alábòójútó àyíká tó bẹ̀ wá wò. Ìdílé mi máa ń bá àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì sọ̀rọ̀, fún àwọn àkókò kan a máa ń lọ sí àwọn àpéjọ, àjọṣepọ̀ tá a ní pẹ̀lú àwọn ará kò sì jùyẹn lọ.
A Fara Da Inúnibíni
Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n ṣe inúnibíni tó pọ̀ gan-an sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí pé wọn kò dá sí ọ̀ràn ìṣèlú. Ìlú Mountain Home, ní ìpínlẹ̀ Arkansas, là ń gbé nígbà yẹn. Lọ́jọ́ kan, èmi àti dádì mi wà lẹ́nu iṣẹ́ ìjẹ́rìí òpópónà. Ńṣe ni ọkùnrin kan ṣàdédé já ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ dádì mi gbà, ó finá sí i, ó sì sún un lójú ẹsẹ̀ níbẹ̀. Ó sọ pé ojo ni wá torí pé a kò lọ jagun. Mi ò ju ọmọ ọdún márùn-ún lọ nígbà yẹn, ńṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Dádì mi kò bá ọkùnrin náà janpata, ńṣe ni wọ́n ń wò ó títí tó fi bá tiẹ̀ lọ.
Àwọn èèyàn rere tó hùwà dáadáa sí wa náà wà níbẹ̀. Nígbà kan tí àwọn jàǹdùkú yí mọ́tò wa ká, agbẹjọ́rò kan tó ń bójú tó àdúgbò náà kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa. Ó wá béèrè pé: “Kí ló ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ yẹn?” Ọkùnrin kan dáhùn pé, “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí kì í jà fún orílẹ̀-èdè wọn!” Ni agbẹjọ́rò náà bá bẹ́ gìjà sórí ibi ìgbẹ́sẹ̀lé ọkọ̀ Ìṣe 27:3.
wa, ó sì pariwo pé: “Mo ja Ogun Àgbáyé Kìíní, mo sì tún máa jà nínú eléyìí náà! Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn yìí máa lọ. Wọn ò pa ẹnikẹ́ni lára!” Bí àwọn èrò yẹn ṣe fi wá sílẹ̀ wọ́ọ́rọ́wọ́ nìyẹn. A mà mọyì àwọn èèyàn rere tí wọ́n fi inú rere hàn sí wa yìí o!—Àwọn Àpéjọ Fún Wa Lókun
Àpéjọ tá a ṣe ní ìlú St. Louis, ní ìpínlẹ̀ Missouri, ṣe wá láǹfààní gan-an. Ìṣirò kan fi hàn pé àwọn tó pé jọ lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [115,000]. Iye àwọn tó ṣèrìbọmi sì wúni lórí gan-an, wọ́n jẹ́ ẹgbàajì ó dín mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [3,903]! Mi ò jẹ́ gbàgbé àsọyé Arákùnrin Rutherford, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àwọn Ọmọ Ọba Náà.” Ó bá àwa ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀ ní tààràtà, gbogbo wa sì gba ẹ̀dà ìwé aláwọ̀ búlúù kan, ìyẹn ìwé Children. Àpéjọ yìí fún mi lókun láti kojú ohun tó wáyé ní ọdún tó tẹ̀ lé e, ìyẹn ọdún tó yẹ kí n bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Wọ́n lé èmi àti àwọn ọmọ èèyàn dádì mi kúrò nílé ìwé torí pé a kò kí àsíá. A máa ń pa dà lọ sí ilé ìwé lójoojúmọ́, ká lè mọ̀ bóyá àwọn tó ń bójú tó ilé ìwé náà ti yí èrò wọn pa dà. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ló jẹ́ pé inú igbó là ń gbà dé ilé ìwé, àmọ́ síbẹ̀ náà ńṣe ni wọ́n á lé wa pa dà sílé. Ṣùgbọ́n mo gbà pé èyí jẹ́ ọ̀nà kan láti gbà fi hàn pé mo jẹ́ adúróṣinṣin sí Ìjọba Ọlọ́run.
Kò pẹ́, kò jìnnà, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣèdájọ́ pé kíkí àsíá kì í ṣe ọ̀ranyàn. Bá a ṣe tún pa dà sílé ìwé nìyẹn. Olùkọ́ wa ṣèèyàn gan-an ni, ó jẹ́ ká ṣe àwọn iṣẹ́ tá a ti pàdánù. Àwọn ọmọ ilé ìwé wa náà sì fọ̀wọ̀ hàn fún wa.
Mo tún rántí àpéjọ tá a ṣe ní ìlú Cleveland, ní ìpínlẹ̀ Ohio lọ́dún 1942. Arákùnrin Nathan H. Knorr sọ àsọyé kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àlàáfíà—Ǹjẹ́ Ó Lè Wà Pẹ́?” Ó ṣàlàyé ìwé Ìṣípayá orí kẹtàdínlógún lẹ́sẹẹsẹ, ó sì fi hàn pé àlàáfíà máa wà dé ìwọ̀n àyè kan lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì. Torí náà, a nírètí pé ìbísí ṣì máa wà. Láti múra sílẹ̀ fún èyí, wọ́n dá Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì sílẹ̀ lọ́dún 1943. Mi ò mọ̀ pé èyí ṣì máa nípa lórí ìgbésí ayé mi lọ́jọ́ iwájú. Àlàáfíà dé lẹ́yìn tí ogun parí, inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wa sì dín kù. Àmọ́, lẹ́yìn tí Ogun Kòríà bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1950, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í ta ko iṣẹ́ ìwàásù wa, bí mo ṣe ṣàlàyé níbẹ̀rẹ̀.
Mo Kópa Tó Pọ̀ Nínú Ìbísí Náà
Mo jáde ilé ẹ̀kọ́ girama lọ́dún 1954, oṣù kan lẹ́yìn náà sì ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lẹ́yìn tí mo ti sìn ní àgbègbè Kennett, ní ìpínlẹ̀ Missouri, níbi tí àwọn jàǹdùkú ti yí wa ká lọ́dún 1950, wọ́n pè mí sí Bẹ́tẹ́lì ní oṣù March, ọdún 1955. Gbàgede tí wọ́n ń pè ní Times Square tó wà ní àárín gbùngbùn ìlú New York City wà lára ìpínlẹ̀ ìjọ tí wọ́n yàn mí sí. Èyí yàtọ̀ sí ibi tí mo ti ń gbé tẹ́lẹ̀! Ó ṣeé ṣe fún mi láti gba àfiyèsí àwọn èèyàn ìlú New York tọ́wọ́ wọn dí gan-an. Ohun tí mo máa ń ṣe ni pé, màá ṣí ìwé ìròyìn wa sí àpilẹ̀kọ tó ní àkòrí tó gba àròjinlẹ̀, màá sì sọ pé, “Ǹjẹ́ o ti béèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ ara rẹ rí?” Ọ̀pọ̀ sì máa ń gba ìwé ìròyìn náà lọ́wọ́ mi.
Apá tí mo gbádùn jù lọ lára iṣẹ́ ìsìn mi ní Bẹ́tẹ́lì ni ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ tí Arákùnrin Knorr máa ń darí. Ó mọ béèyàn ṣe ń ṣàlàyé Bíbélì, ó sì máa ń jẹ́ ká rí bá a ṣe lè fi í sílò! Ó máa ń bá àwa ọ̀dọ́kùnrin tí a kò tíì ṣègbéyàwó sọ̀rọ̀ bí ìgbà tí òbí ń bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì sábà máa ń fún wa ní ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ lórí bó ṣe yẹ ká máa ṣe sí àwọn obìnrin. Nígbà tó di ọdún 1960, mo pinnu láti gbéyàwó.
Mo ti fìwé sílẹ̀ ní oṣù kan ṣáájú pé mo máa kúrò ní Bẹ́tẹ́lì, àmọ́ mi ò rí èsì. Lẹ́yìn oṣù kan, pẹ̀lú bí ojú ṣe máa ń tì mí tó, mo ṣọkàn akin, mo sì béèrè bóyá wọ́n rí ìwé tí mo kọ láti fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀. Arákùnrin Robert Wallen ló gbé fóònù, ó sì wá sí ibi tí mo ti ń ṣiṣẹ́. Ó béèrè lọ́wọ́ mi bóyá mo nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tàbí alábòójútó àyíká. Mo fèsì pé: “Àmọ́ Robert, ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún péré ni mí, mi ò sì ní ìrírí.”
Mo Di Alábòójútó Àyíká
Nígbà tí mo wọlé lálẹ́ ọjọ́ yẹn mo bá àpò ìwé ńlá kan nínú yàrá mi. Ohun tó wà nínú rẹ̀ ni ìwé ìbéèrè fún iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti ti alábòójútó
àyíká. Èyí ga o! Béèyàn bá gun ẹṣin nínú mi kò ní kọsẹ̀! Mo wá ní àǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká ní apá gúúsù ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Missouri àti ní ìlà oòrùn ìpínlẹ̀ Kansas. Àmọ́ kí n tó kúrò ní Bẹ́tẹ́lì, mo lọ sí ìpàdé fún àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò. Nínú ọ̀rọ̀ ìparí tí Arákùnrin Knorr sọ, ó ní: “Jíjẹ́ tẹ́ ẹ jẹ́ alábòójútó àyíká àti alábòójútó àgbègbè kò túmọ̀ sí pé ẹ ní ìmọ̀ ju àwọn ará tẹ́ ẹ máa lọ bẹ̀ wò lọ o. Àwọn kan ní ìrírí jù yín lọ. Àmọ́ ipò wọn kò jẹ́ kí wọ́n lè ní àǹfààní tẹ́ ẹ ní. Ẹ lè kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ lọ́dọ̀ wọn.”Òótọ́ mà lọ̀rọ̀ yìí já sí o! Arákùnrin Fred Molohan àti ìyàwó rẹ̀ àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó ń jẹ́ Charley, tó ń gbé ní ìlú Parsons ní ìpínlẹ̀ Kansas jẹ́ àpẹẹrẹ àrà ọ̀tọ̀. Wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láti ọwọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1900. Ó máa ń dùn mọ́ mi gan-an láti gbọ́ àwọn ìrírí tí wọ́n ní ṣáájú kí wọ́n tó bí èmi alára! Arákùnrin míì ni Arákùnrin John Wristen, àgbàlagbà ni ó sì jẹ́ onínúure, ó ń gbé ní ìlú Joplin, ní ìpínlẹ̀ Missouri, ó sì ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn arákùnrin ọ̀wọ́n yìí ní ọ̀wọ̀ fún ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà darí ètò rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni mí, wọ́n jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn mọyì mi gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká wọn.
Lọ́dún 1962, mo gbé Cloris Knoche, aṣáájú-ọ̀nà kan tó lọ́yàyà tó sì ní irun pupa ní ìyàwó. Mò ń bá iṣẹ́ alábòójútó àyíká lọ pẹ̀lú Cloris aya mi. Bá a ṣe ń dé sílé àwọn ará máa ń jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀ wọ́n dáadáa. Ó ṣeé ṣe fún wa láti fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bíi pé irú ìṣírí bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọ̀dọ́ méjì kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Jay Kosinski àti JoAnn Kresyman ń retí. Bá a ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, tá a sì ń sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀ tó wà nínú kéèyàn yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run mú kí àwọn náà fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe àfojúsùn wọn. JoAnn di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, Jay sì lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Nígbà tó yá àwọn méjèèjì fẹ́ra wọn, wọ́n sì ti wà lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká fún nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún báyìí.
Iṣẹ́ Ìsìn Míṣọ́nnárì
Lọ́dún 1966, Arákùnrin Knorr béèrè lọ́wọ́ wa bóyá a nífẹ̀ẹ́ láti lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè. A fèsì pé: “À ń gbádùn ibi tá a wà yìí náà. Àmọ́ bí àìní bá wà níbòmíì, a múra tán láti lọ.” Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà ni wọ́n pè wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Inú mi dùn gan-an láti tún pa dà sí Bẹ́tẹ́lì nígbà tá a fi wà ní ilé ẹ̀kọ́ náà, tí mo sì tún wà pẹ̀lú àwọn tí mo ti nífẹ̀ẹ́ tí mo sì bọ̀wọ̀ fún! A tún di ọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n ṣì ń sìn tọkàntọkàn títí dòní.
Wọ́n rán èmi àti Cloris aya mi lọ sí orílẹ̀-èdè Ecuador ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù, pẹ̀lú Dennis àti Edwina Crist, Ana Rodríguez àti Delia Sánchez. Ìdílé Crist lọ sí Quito tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Bíi tiwa, wọ́n yan Ana àti Delia sí ìlú Cuenca, ìlú kẹta tó tóbi jù lọ lórílẹ̀-èdè Ecuador. Ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tún ní ẹkùn ìpínlẹ̀ méjì. Inú yàrá wa ni ìjọ àkọ́kọ́ tá a dá sílẹ̀ ní ìlú Cuenca ti ń ṣe ìpàdé. Ibẹ̀ ni àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àtàwọn èèyàn méjì míì wà. A kò mọ bá a ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà láṣeyọrí.
Ṣọ́ọ̀ṣì pọ̀ gan-an ní ìlú Cuenca, láwọn ọjọ́ tí wọ́n bá sì pè ní ọjọ́ mímọ́, ńṣe ni wọ́n máa
ń yíde kiri. Síbẹ̀ náà, àwọn èèyàn ìlú Cuenca ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ pàdé Mario Polo, tó gbégbá orókè nínú ìdíje kẹ̀kẹ́ ní ìlú Cuenca, ó béèrè ìbéèrè kan tó yà mí lẹ́nu, ó ní, “Ta ni aṣẹ́wó tí wọ́n sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá?”Lálẹ́ ọjọ́ kan, Mario wá sílé wa, ó sì hàn lójú rẹ̀ pé nǹkan kan wà lọ́kàn rẹ̀. Pásítọ̀ kan ti fún un ní ìwé kan tó fẹ̀sùn búburú kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo sọ fún Mario pé ó yẹ kí ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn lè wí àwíjàre fún ara rẹ̀. Torí náà lọ́jọ́ kejì, Mario pe èmi àti pásítọ̀ náà sí ilé rẹ̀ láti dáhùn àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá. Nígbà ìjíròrò yẹn, mo dábàá pé ká sọ̀rọ̀ nípa Mẹ́talọ́kan nìkan. Lẹ́yìn tí pásítọ̀ náà ka Jòhánù 1:1, Mario fúnra rẹ̀ ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà nínú “Ọlọ́run” àti “ọlọ́run kan” lédè Gíríìkì. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí pẹ̀lú gbogbo ẹsẹ Bíbélì tó kù tá a kà nìyẹn. Kò yà wá lẹ́nu pé, pásítọ̀ náà kúrò níbẹ̀ láìlè fìdí àlàyé Mẹ́talọ́kan múlẹ̀. Èyí mú kó dá Mario àti ìyàwó rẹ̀ lójú pé òtítọ́ la fi ń kọ́ni, wọ́n sì wá di olùgbèjà àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Inú wa dùn jọjọ láti rí i pé ìjọ tó wà ní Cuenca di mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33], tí gbogbo ìjọ tó wà ní ìpínlẹ̀ gbígbòòrò tá a ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sì di mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63], ìbísí tó kọyọyọ mà lèyí o!
À Ń Rí Ìbísí Náà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì
Lọ́dún 1970, wọ́n ní kí èmi àti Al Schullo lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Guayaquil. Àwa méjèèjì là ń bójú tó iṣẹ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì. Joe Sekerak máa ń lo díẹ̀ lára àkókò rẹ̀ láti kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ mẹ́rìndínláàádọ́ta tó wà lórílẹ̀-èdè náà. Fún àwọn àkókò kan Cloris aya mi ń bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì nìṣó ní pápá, èmi sì ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Aya mi ti ran àwọn èèyàn márùnléláàádọ́ta [55] lọ́wọ́ débi tí wọ́n fi ṣe ìrìbọmi, lọ́pọ̀ ìgbà mẹ́ta sí márùn-ún lára àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ kan ṣoṣo.
Bí àpẹẹrẹ, Cloris kọ́ obìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ máa ń ṣàtakò lẹ́kọ̀ọ́, Lucresia lorúkọ obìnrin yìí. Síbẹ̀ náà Lucresia pàpà ṣe ìrìbọmi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ó kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ní àwọn ìlànà Jèhófà. Méjì lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà báyìí, ọ̀kan jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe; ọmọbìnrin rẹ̀ sì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ọmọ ọmọ rẹ̀ obìnrin fẹ́ arákùnrin kan tó ń ṣe dáadáa, àwọn náà sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ìdílé yìí ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Lọ́dún 1980, nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000] akéde ló wà ní Ecuador. Ọ́fíìsì kékeré tá à ń lò kò sì gbà wá mọ́. Arákùnrin kan yọ̀ǹda hẹ́kítà ilẹ̀ méjìlélọ́gbọ̀n [32], ìyẹn ọgọ́rin [80] sarè ilẹ̀, fún wa ní ẹ̀yìn ìlú Guayaquil. A bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ sórí ilẹ̀ náà lọ́dún 1984, a sì yà á sí mímọ́ lọ́dún 1987.
Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Mú Kí Ìbísí Náà Pọ̀ Sí I
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, inú wa ń dùn láti rí ọ̀pọ̀ àwọn akéde àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà láti àwọn orílẹ̀-èdè míì tó ń wá sí Ecuador láti wá ṣèrànwọ́ láwọn àgbègbè tá a ti nílò àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i. Àpẹẹrẹ ẹnì kan tó wú mi lórí jù lọ ni ti Andy Kidd, tó jẹ́ olùkọ́ tó ti fẹ̀yìn tì lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ó kó wá sí orílẹ̀-èdè Ecuador lọ́dún 1985 lẹ́ni àádọ́rin [70] ọdún, ó sì sìn níbẹ̀ títí tó fi kú lọ́dún 2008 lẹ́ni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [93]. Nígbà tí mo kọ́kọ́ rí i níbi tó ti ń sìn, òun nìkan ni alábòójútó tó wà ní ìjọ kékeré yẹn. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ èdè Sípáníìṣì táátààtá ni, ó sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, ó sì tún darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ó tún darí ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ó sì tún ṣe èyí tó pọ̀ jù lára iṣẹ́ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn! Ìjọ méjì tó ń ṣe dáadáa ti wà ní àgbègbè náà báyìí, wọ́n sì ní nǹkan bí igba [200] akéde àti ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà.
Arákùnrin míì tí òun àti ìdílé rẹ̀ wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn Ernesto Diaz, sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti lo oṣù mẹ́jọ ní Ecuador. Ó ní: “Àwọn ọmọ wa mẹ́ta ti mọ èdè náà, wọ́n sì ti di olùkọ́ tó dáńgájíá. Gẹ́gẹ́ bíi bàbá, ọwọ́ mi ti tẹ ohun tó dà bíi pé ọwọ́ mi ò lè tẹ̀ nínú ètò àwọn nǹkan yìí, ìyẹn ni jíjẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àti lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún pẹ̀lú ìdílé mi. Gbogbo wa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] báyìí. Gbogbo èyí ti mú kí ìdílé wa túbọ̀
wà ní ìṣọ̀kan, pabanbarì rẹ̀ wá ni pé, a ti wá sún mọ́ Jèhófà gan-an lọ́nà tí mi ò rírú rẹ̀ rí.” A mà mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọ̀nyí gan-an ni o!A mú ẹ̀ka ọ́fíìsì wa gbòòrò sí i lọ́dún 1994, ó sì tó ìlọ́po méjì èyí tá a ní tẹ́lẹ̀. Lọ́dún 2005, àwọn akéde wa lé ní ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000], èyí sì mú kó pọn dandan fún wa láti mú ẹ̀ka ọ́fíìsì wa gbòòrò sí i. Lára ohun tá a ṣe ni mímú Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa tóbi sí i, kíkọ́ ilé gbígbé tuntun kan, àti ọ́fíìsì fún àwọn atúmọ̀ èdè. A ṣe ìyàsímímọ́ àwọn ilé tuntun yìí ní October 31, 2009.
Nígbà tí wọ́n lé mi kúrò níléèwé lọ́dún 1942, ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000] ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ní báyìí wọ́n ti lé ní mílíọ̀nù kan dáadáa. Nígbà tá a dé orílẹ̀-èdè Ecuador lọ́dún 1966, egbèje [1,400] ni àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà níbẹ̀. Ní báyìí, wọ́n ti lé ní ẹgbàá mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [68,000]. Ó sì dájú pé ọ̀pọ̀ ṣì ń bọ̀, tá a bá fojú ti ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000] ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń darí àti àwọn tó lé ní ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gọ́fà [232,000] tó wá sí ibi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2009 wò ó. Lóòótọ́, Jèhófà ti bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́nà kan tí èèyàn ò lè ronú kàn. Inú wa dùn gan-an láti gbé ní ibi tí ìbísí tó bùáyà yìí ti wáyé o, a sì dúpẹ́ pé ó ṣojú wa! a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí à ń múra láti tẹ àpilẹ̀kọ yìí jáde ni Arákùnrin Harley Harris kú gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ sí Jèhófà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Àpéjọ tá a ṣe níta gbangba lọ́dún (1981) àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ Guayaquil tá a kọ́ sórí ilẹ̀ náà lọ́dún (2009)