Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ó Ń Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Mi Wọ Àwọn Èèyàn Lọ́kàn”

“Ó Ń Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Mi Wọ Àwọn Èèyàn Lọ́kàn”

“Ó Ń Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Mi Wọ Àwọn Èèyàn Lọ́kàn”

NÍGBÀ kan, wọ́n ṣe àpérò àgbáyé kan tó dá lórí ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ní ìlú Porto Alegre tó wà létíkun, lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Brazil. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn láti orílẹ̀-èdè márùnléláàádóje [135] ló pésẹ̀ síbi àpérò náà. Lákòókò ìsinmi, àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí láti ìjọ kan ní ìlú Porto Alegre sún mọ́ àwọn àlejò náà, kí wọ́n lè wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. Báwo ni wọ́n ṣe wàásù fún wọn?

Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Elizabete, sọ pé: “A lo ìwé kékeré náà Good News for People of All Nations.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó wá síbi àpérò náà kò tíì gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run rí, àmọ́ wọ́n fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. A bá àwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè Bòlífíà, Ṣáínà, Faransé, Íńdíà, Ísírẹ́lì àti Nàìjíríà sọ̀rọ̀. A ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lédè àwọn kan, wọ́n sì fayọ̀ gbà á lọ́wọ́ wa.”

Lórílẹ̀ èdè Mẹ́síkò, aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Raúl náà lo ìwé kékeré náà, ó sì yọrí sí rere. Nígbà kan, ó bá ẹni ọgọ́rin [80] ọdún kan láti ilẹ̀ Arébíà, tí ìyàwó rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú, sọ̀rọ̀. Ńṣe ni bàbá yìí bú sẹ́kún ayọ̀ nígbà tó ka apá tó sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run lédè Lárúbáwá. Kí nìdí? Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ikú kò ní sí mọ́, tó wà nínú Ìṣípayá 21:3, 4, wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an nígbà tó kà á ní èdè ìbílẹ̀ rẹ̀. Nígbà mìíràn tí Raúl ń wàásù láìjẹ́-bí-àṣà, ó pàdé ọkùnrin kan tó ń sọ èdè Potogí. Ọkùnrin yìí náà ti pàdánù ẹnì kan tó fẹ́ràn, ìyẹn ọmọkùnrin rẹ̀. Raúl jẹ́ kó ka ojú ìwé tí èdè Potogí wà nínú ìwé náà. Lẹ́yìn tí ọkùnrin yìí kà á, ó ṣàpèjúwe fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́.

Raúl ti lo ìwé kékeré náà Good News for People of All Nations láti wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè Armenian, Chinese, Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, German, Híńdì, Korean, Mixe, Persian, Russian àti Zapotec. Ó sọ pé: “Mo ti rí bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa lo ohun èlò yìí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi. Ó ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, bí mi ò tiẹ̀ gbọ́ èdè wọn.”

Bí àwọn èèyàn ṣe ń rìnrìn-àjò, tí wọ́n sì ń gbé nílẹ̀ òkèèrè, a ní àǹfààní tó pọ̀ láti bá àwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa pàdé. A máa lè wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún wọn tá a bá ń lo ìwé kékeré náà, Good News for People of All Nations. Ṣé ìwé yìí máa ń wà pẹ̀lú rẹ?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Ìwé kékeré tó ran Raúl lọ́wọ́ látijẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè lọ́kàn ló mú dání yìí