Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Ètò Jèhófà Dunjú

Ẹ Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Ètò Jèhófà Dunjú

Ẹ Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Ètò Jèhófà Dunjú

ÀWỌN ọmọdé máa ń fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́. Ronú nípa àwọn ìbéèrè táwọn ọmọ àwọn ará Ísírẹ́lì tó wà ní Íjíbítì á máa béèrè ní alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe Ìrékọjá: ‘Kí nìdí tí a fi gbọ́dọ̀ pa ọ̀dọ́ àgùntàn náà?’ ‘Kí nìdí tí Bàbá fi ń fi ẹ̀jẹ̀ sí ara àtẹ́rígbà?’ ‘Ibo là ń lọ?’ Àṣẹ tí Jèhófà pa fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ baba jẹ́ ká mọ̀ pé ó fara mọ́ irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Jèhófà ń sọ fún wọn nípa àjọyọ̀ Ìrékọjá tí wọ́n á máa ṣe lọ́jọ́ iwájú, ó sọ pé: “Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá wí fún yín pé, ‘Kí ni iṣẹ́ ìsìn yìí túmọ̀ sí fún yín?’ nígbà náà, kí ẹ wí pé, ‘Ẹbọ ìrékọjá ni sí Jèhófà, ẹni tí ó ré ilé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọjá ní Íjíbítì nígbà tí ó mú ìyọnu àjàkálẹ̀ bá àwọn ará Íjíbítì, ṣùgbọ́n ó dá ilé wa nídè.’” (Ẹ́kís. 12:24-27) Lẹ́yìn náà, Jèhófà rán àwọn òbí tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì létí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n dáhùn ìbéèrè tí àwọn ọmọ wọn bá bi wọ́n nípa “àwọn ìlànà àti àwọn ìpinnu ìdájọ́” tí Jèhófà ti pa láṣẹ.—Diu. 6:20-25.

Èyí mú kó ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ láti rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn bí ohun kán bá rú wọn lójú nípa ìjọsìn tòótọ́, àwọn ìdáhùn tó máa mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run àti Olùgbàlà wọn. Lóde òní ńkọ́? Jèhófà ṣì fẹ́ káwọn ọmọdé máa rí ìdáhùn sí ohun tó bá rú wọn lójú. Ọ̀nà kan táwọn òbí lè gbà gbin ìfẹ́ àtọkànwá fún Ọlọ́run àtàwọn èèyàn rẹ̀ sínú àwọn ọmọ wọn ni pé kí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ètò Jèhófà dunjú kí wọ́n sì lóye bí wọ́n ṣe lè jàǹfààní látinú ohun tí ètò náà ń ṣe fún wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà kan tá a lè gbà ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa ètò Ọlọ́run.

Ìjọ

Ó yẹ káwọn ọmọdé mọ ìjọ tí ìdílé yìn ń dara pọ̀ mọ́ dáadáa. Ọ̀nà tí ẹ̀yin òbí lè gbà ṣèyẹn ni pé kẹ́ ẹ máa mú wọn lọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ. Lọ́nà yìí, ẹ ó máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jèhófà fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tó pàṣẹ fún pé: “Pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké . . . , kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́, bí wọn yóò ti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín, kí wọ́n sì kíyè sára láti mú gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ṣe. Kí àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ̀ sì fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì kọ́ láti bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín.”—Diu. 31:12, 13.

Àwọn ọmọdé lè bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà látìgbà ọmọdé jòjòló. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa Tímótì pé: “Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́.” (2 Tím. 3:15) Kódà, ní àwọn ìpàdé tá à ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn ọmọdé lè bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ohun tí wọ́n ń gbọ́ níbẹ̀, kí wọ́n sì tún mọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run. Níbẹ̀, wọ́n á kọ́ láti máa lo Bíbélì àtàwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì, wọ́n á sì máa fi ojú tó tọ́ wò wọ́n. Síwájú sí i, ní àwọn ìpàdé wa, wọ́n á rí bí àwọn ará ṣe ń fi ojúlówó ìfẹ́ ṣèwà hù, èyí tó jẹ́ ànímọ́ tá a fi ń dá àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ mọ̀. Jésù sọ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:34, 35) Ìfẹ́ ọlọ́yàyà tó máa ń wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba máa fa àwọn ọmọdé mọ́ra, ó sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sọ lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ di ohun tí wọ́n á máa ṣe jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn.

Bẹ́ ẹ bá sọ ọ́ di àṣà láti máa tètè dé sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, tẹ́ ẹ sì ń dúró díẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé, ó máa ṣeé ṣe fáwọn ọmọ yín láti rí ẹni bá ṣọ̀rẹ́. Dípò tí ẹ ó fi jẹ́ kí wọ́n máa bá àwọn ọmọdé bíi tiwọn nìkan kẹ́gbẹ́, ẹ ò ṣe fi ojú wọn mọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra? Bí àwọn ọmọ yín bá di ọ̀rẹ́ àwọn tó jù wọ́n lọ, wọ́n á rí i pé ọ̀pọ̀ ìrírí àti ọgbọ́n ni wọ́n ní. Bí Sekaráyà ìgbàanì tó jẹ́ “olùkọ́ni ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́” ṣe nípa rere lórí Ùsáyà, ọba Júdà tó jẹ́ ọ̀dọ́, bẹ́ẹ̀ náà làwọn tó ti fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣe ní ipa rere lórí àwọn ọ̀dọ́. (2 Kíró. 26:1, 4, 5) Nígbà tẹ́ ẹ bá wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ẹ lè ṣàlàyé fún àwọn ọmọ yín nípa ohun tí ibi ìkówèésí, pátákó ìsọfúnni, àtàwọn nǹkan míì tó wà níbẹ̀, wà fún.

Ètò Ọlọ́run Kárí Ayé

Ó yẹ kó yé àwọn ọmọ pé ìjọ wọn jẹ́ ọ̀kan lára ìjọ Ọlọ́run tó ju ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] lọ, èyí tó wà kárí ayé. Ṣàlàyé àwọn nǹkan tó wà nínú ètò Ọlọ́run fún wọn àti bó ṣe ń ṣiṣẹ́, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ ipa táwọn ọmọdé ń kó láti kọ́wọ́ tì í lẹ́yìn. Jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó o fi máa ń fojú sọ́nà fún àwọn àpéjọ àyíká, àpéjọ àgbègbè àti ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká.—Wo àpótí náà,  “Àwọn Ohun Tẹ́ Ẹ Lè Gbé Yẹ̀ Wò Nígbà Ìjọsìn Ìdílé,” lójú ìwé 28.

Bí àyè bá ṣí sílẹ̀, ẹ lè pe alábòójútó àyíká, àwọn míṣọ́nnárì, ẹni tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì, àtàwọn míì tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún láti wá jẹun nílé yín. Ẹ má ṣe rò pé wọn kò ní àkókò fún àwọn ọmọdé. Àwọn ìránṣẹ́ alákòókò kíkún yìí ń sapá láti fìwà jọ Jésù, tó máa ń kó àwọn ọmọdé mọ́ra tó sì máa ń bá wọn sọ̀rọ̀. (Máàkù 10:13-16) Bí àwọn ọmọ yín ṣe ń gbọ́ tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yìí ń sọ ìrírí wọn tí wọ́n sì ń kíyè sí i pé iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ń fún wọn láyọ̀, àwọn ọmọ yín náà lè fẹ́ láti fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ṣe àfojúsùn wọn.

Gẹ́gẹ́ bí ìdílé, kí lẹ tún lè ṣe láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ mọ ètò Jèhófà dunjú? Àwọn àbá díẹ̀ rèé: Ẹ ṣètò gẹ́gẹ́ bí ìdílé láti ṣàgbéyẹ̀wò ìwé náà Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom. Ẹ tẹnu mọ́ ìfọkànsìn, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ìdúróṣinṣin táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fi hàn. Ẹ jẹ́ káwọn ọmọ rí ọ̀nà tí Jèhófà gbà lò wọ́n láti tan ìhìn rere náà kálẹ̀ jákèjádò ayé. Ẹ lo àwọn fídíò tí ètò Jèhófà ti mú jáde láti kọ́ wọn láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí. Bó bá ṣeé ṣe, ẹ ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ìyẹn Bẹ́tẹ́lì tó wà ní orílẹ̀-èdè yín tàbí èyí tó wà lórílẹ̀-èdè míì pàápàá. Irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ káwọn ọmọ yín túbọ̀ mọrírì bí Jèhófà ṣe ń lo ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye láti ṣètò apá tó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé lára ètò Rẹ̀ láti máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí àti ìtọ́sọ́nà fáwọn ará kárí ayé, bó ṣe ṣe ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni.—Mát. 24:45-47; Ìṣe 15:22-31.

Mímú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bá Ọjọ́ Orí Ọmọ Kọ̀ọ̀kan Mu

Tó o bá ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́, máa rántí ọ̀nà tí Jésù gbà fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní ìtọ́ni. Ó sọ fún wọn nígbà kan pé: “Mo ṣì ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n mọ́ra nísinsìnyí.” (Jòh. 16:12) Jésù kì í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìsọfúnni tó pọ̀ ju èyí tí wọ́n nílò lọ. Ńṣe ló rọra ń kọ́ wọn ní àwọn òtítọ́ tó ṣe pàtàkì kí wọ́n lè lóye wọn dáadáa. Bíi ti Jésù, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ máa pọ̀ jù. Bó o bá ń fi òye ètò Ọlọ́run yé wọn díẹ̀díẹ̀, àmọ́ tó ò ń ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé, kò ní tètè sú wọn, wàá sì jẹ́ kó máa wù wọ́n láti mọ̀ sí i nípa ìjọ Ọlọ́run. Bí ọjọ́ orí wọn bá sì ṣe ń gbé pẹ́ẹ́lí sí i, o lè máa rán wọn létí ohun tí wọ́n ti kọ́ tẹ́lẹ̀, kó o wá fi àwọn nǹkan tí wọn kò tíì mọ̀ kún un.

Ibi tí gbogbo Kristẹni ti lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà ni ìjọ Ọlọ́run jẹ́, ó sì máa ń rọrùn fún àwọn ọmọdé tí wọ́n ń fìtara kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ láti má ṣe jẹ́ kí ayé Sátánì nípa lórí àwọn. (Róòmù 12:2) Ó dá wa lójú pé ẹ máa láyọ̀ gan-an bẹ́ ẹ ti ń ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ ètò Jèhófà dunjú. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ǹjẹ́ káwọn ọmọ náà lè máa bá a nìṣó láti fara mọ́ ètò Jèhófà àti Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tá à ń sìn.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

 Àwọn Ohun Tẹ́ Ẹ Lè Gbé Yẹ̀ Wò Nígbà Ìjọsìn Ìdílé

Díẹ̀ rèé lára àwọn ohun tó jẹ mọ́ ètò Ọlọ́run, èyí tẹ́ ẹ lè gbé yẹ̀ wò nígbà Ìjọsìn Ìdílé ní ìrọ̀lẹ́.

▪ Ẹ sọ̀rọ̀ nípa ìpàdé ìjọ yín. Ìgbà wo ni wọ́n dá a sílẹ̀, báwo sì ni wọ́n ṣe dá a sílẹ̀? Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wo ni ìjọ yín ti lò rí? Fún ìjíròrò yìí, ẹ ò ṣe ní kí ẹnì kan tó ti pẹ́ nínú ìjọ wá sílé yín kó lè dáhùn ìbéèrè táwọn ọmọ ní?

▪ Ẹ ṣàlàyé ohun tá à ń kọ́ ní ìpàdé ìjọ kọ̀ọ̀kan àti àwọn àpéjọ ńlá míì àti bí àwọn ọmọ ṣe lè jàǹfààní látibẹ̀.

▪ Ẹ ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí onírúurú ilé ẹ̀kọ́ tí ètò Jèhófà dá sílẹ̀ wà fún. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìrírí tó dá lórí àwọn àbájáde rere tí àwọn tó ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà ń ní.

▪ Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n di akéde ìhìn rere tó ń ṣe déédéé. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe ipa tiwọn láti fi kún ìròyìn kárí ayé tó máa ń jáde nínú ìwé ọdọọdún náà, Yearbook of Jehovah’s Witnesses.

▪ Ẹ ṣàgbéyẹ̀wò onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tó wà fún àwọn ọ̀dọ́ nínú ètò Jèhófà. Ẹ lè rí ìsọfúnni kíkún ní Orí 10, nínú ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà.

▪ Ẹ ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti mọ ìdí tí a fi ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà kan nínú ìjọ Ọlọ́run. Ẹ ṣàlàyé ìdí tí wọn kò fi gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó yàtọ̀ sí èyí tí ètò Jèhófà fi kọ́ni, àní nínú àwọn nǹkan kéékèèké pàápàá. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà máa mú kí nǹkan lọ létòlétò nínú ìjọ nípa títẹ̀ lé ìtọ́ni látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà.

[Àwòrán]

Àwọn ọmọ rẹ máa jàǹfààní bí wọ́n bá jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Bó ṣe rí ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn òbí lóde òní máa ń sapá láti fún àwọn ọmọ ní ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn nígbà tí wọ́n bá béèrè nǹkan nípa ètò Jèhófà