Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Mú Kí Ọwọ́ Mi Dí Nínú Ètò Jèhófà

Mo Mú Kí Ọwọ́ Mi Dí Nínú Ètò Jèhófà

Mo Mú Kí Ọwọ́ Mi Dí Nínú Ètò Jèhófà

Gẹ́gẹ́ bí Vernon Zubko Ṣe sọ ọ́

ABÚLÉ Stenen, tó wà ní ẹkùn ilẹ̀ Saskatchewan, lórílẹ̀-èdè Kánádà ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Àwọn òbí mi, Fred àti Adella, ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè pèsè fún èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aurellia, àtàwọn àbúrò mi, Alvin, Allegra àti Daryl nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Títí dòní, à ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí wa torí pé wọ́n kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

Bàbá mi tó jẹ́ ẹni àmì òróró, jẹ́ ajíhìnrere tí kì í ṣojo. Ó ń ṣiṣẹ́ kára kó lè pèsè àtijẹ àtimu, àmọ́ ó tún rí i dájú pé gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun. Gbogbo ìgbà ló máa ń sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́. Ìtara àti ìgboyà rẹ̀ kò lè kúrò lọ́kàn mi láé. Ó sábà máa ń sọ fún mi pé, “Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí nínú ètò Jèhófà, wàá lè bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ìṣòro.”

Lemọ́lemọ́ la máa ń ṣe ìjẹ́rìí òpópónà ní abúlé Stenen àtàwọn abúlé míì tó wà nítòsí. Èyí kì í fìgbà gbogbo rọrùn fún mi. Ìlú kọ̀ọ̀kan ló làwọn jàǹdùkú tiẹ̀, tí wọ́n á máa fi àwa tá a jẹ́ ọmọdé ṣe yẹ̀yẹ́. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ, lọ́jọ́ kan mo dúró sí ẹ̀gbẹ́ kan, mo sì kó Ilé Ìṣọ́ àti Jí! dání, ni àwọn ọmọdé kan bá pagbo yí mi ká. Wọ́n ṣí àkẹtẹ̀ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rà lórí mi, wọ́n sì fi lé orí òpó kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Ọpẹ́lọpẹ́ pé arákùnrin àgbàlagbà kan tó ń wò mí rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Ó wá sún mọ́ mi, ó sì béèrè pé, “Vern, ṣé kò síṣòro?” Làwọn ọmọ náà bá sá lọ. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí dùn mí gan-an, síbẹ̀ ó kọ́ mi pé téèyàn bá ń ṣe ìjẹ́rìí òpópónà, kò yẹ kéèyàn máa dúró gbagidi sójú kan. Irú àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà lákòókò tí mò ń dàgbà yìí fún mi ní ìgboyà láti máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.

Èmi àti Alvin ṣe ìrìbọmi ní oṣù May ọdún 1951. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni mí nígbà yẹn. Mo ṣì rántí pé Arákùnrin Jack Nathan tó sọ àsọyé ìrìbọmi rọ̀ wá pé, ká má ṣe jẹ́ kí oṣù kan kọjá lọ láìsọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. a Nínú ìdílé wa, a gbà pé iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà ni iṣẹ́ tó dára jù lọ téèyàn lè fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Torí náà, lẹ́yìn tí mo parí ilé ẹ̀kọ́ lọ́dún 1958, mo lọ sí ìlú Winnipeg, olú ìlú ẹkùn-ìpínlẹ̀ Manitoba, láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wu bàbá mi pé kí n máa bá wọn ṣe iṣẹ́ fífá igi gẹdú tí ìdílé wa ń ṣe, síbẹ̀ òun àti ìyá mi fún mi ní ìṣírí láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, wọ́n sì tì mí lẹ́yìn.

Mo Lọ sí Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tuntun Mo sì Ṣègbéyàwó

Lọ́dún 1959, ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ pé kí àwọn tó bá ṣeé ṣe fún kó lọ sí ẹkùn-ìpínlẹ̀ Quebec, torí wọ́n nílò àwọn ajíhìnrere púpọ̀ sí i níbẹ̀. Mo wá lọ sí ìlú Montreal láti lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ìyípadà ńlá mà lèyí o! Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí mo tíì ṣe rí ní ìgbésí ayé, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Faransé, mo sì tún ní láti kọ́ àṣà ìbílẹ̀ tó yàtọ̀ sí tèmi. Alábòójútó àyíká wa sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Báyìí la ṣe ń ṣe é nígbà tí mo wà nílé.’” Ìmọ̀ràn gidi lèyí jẹ́.—1 Kọ́r. 9:22, 23.

Kò sí aṣáájú-ọ̀nà kankan pẹ̀lú mi nígbà tí mo dé ẹkùn-ìpínlẹ̀ Quebec. Àmọ́, arábìnrin ọ̀dọ́ kan, tí mo pàdé nígbà tí mo wà ní ìlú Winnipeg, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Shirley Turcotte, di ẹnì kejì mi títí gbére, nígbà tá a ṣègbéyàwó ní oṣù February ọdún 1961. Inú ìdílé tí wọ́n ti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lòun náà ti wá. Àmọ́, mi ò mọ̀ pé ó máa wá di orísun ìṣírí fún mi fún ọ̀pọ̀ ọdún.

A Wàásù Jákèjádò Ìlú Gaspé

Ọdún méjì lẹ́yìn ìgbéyàwó wa ni wọ́n yàn wá láti lọ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìlú Rimouski, ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Quebec. Nígbà ìrúwé ọdún tó tẹ̀ lé e, ẹ̀ka ọ́fíìsì ní ká wàásù jákèjádò Gaspé Peninsula, ìyẹn àgbègbè kan tí omi yí ká ní etíkun ìhà ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Kánádà. Iṣẹ́ tí wọ́n ní ká ṣe ni pé ká gbin irúgbìn òtítọ́ sọ́kàn àwọn èèyàn níbẹ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Oníw. 11:6) A kó ìwé ìròyìn tó lé ní ẹgbẹ̀rún [1,000] kan àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ tó irínwó [400] sínú ọkọ̀ wa, a tún kó oúnjẹ àti aṣọ, a sì gbéra ìrìn-àjò iṣẹ́ ìwàásù tó gba oṣù kan gbáko. A fọgbọ́n wàásù ní àwọn abúlé kéékèèké tó wà ní ìlú Gaspé. Ilé iṣẹ́ rédíò tó wà lágbègbè náà kìlọ̀ fún àwọn èèyàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bọ̀, wọ́n sì ní wọn kò gbọ́dọ̀ gba àwọn ìwé wa. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣi ìkéde náà lóye, wọ́n rò pé ńṣe ni wọ́n ń kéde àwọn ìwé wa, torí náà wọ́n gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa.

Láwọn ọdún wọ̀nyẹn, òmìnira tá a ní láti wàásù láwọn apá ibì kan ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Quebec ṣì ṣàjèjì sáwọn èèyàn, torí náà kì í ṣe ohun tuntun pé kí àwọn ọlọ́pàá dá wa dúró. Èyí ṣẹlẹ̀ ní ìlú kan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ilé la ti ń pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. Ọlọ́pàá kan ní àfi ká bá òun dé àgọ́ ọlọ́pàá, a kò sì bá a janpata. Mo wá gbọ́ pé lọ́yà kan ní ìlú yẹn ló pàṣẹ pé kí wọ́n dá iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe dúró. Níwọ̀n bí ọ̀gá ọlọ́pàá kò ti sí nílé lọ́jọ́ yẹn, mo fún lọ́yà náà ní lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Toronto fún wa, èyí tó ṣàlàyé ẹ̀tọ́ tá a ní láti wàásù lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Lẹ́yìn tó ka lẹ́tà náà, kíá ló sọ pé: “Wò ó, mi ò fẹ́ wàhálà kankan o. Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tó wà níbí ló ní kí n dáa yín dúró.” Torí pé a fẹ́ kí àwọn èèyàn tó wà ládùúgbò yẹn mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù wa bófin mu, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lá pa dà sí àdúgbò tí ọlọ́pàá ti dá wa dúró láti lọ máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ.

Lọ́jọ́ kejì tá a pa dà lọ rí ọ̀gá ọlọ́pàá náà, inú bí i gan-an pé wọ́n dá wa dúró lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Ó fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí lọ́yà náà! Ọlọ́pàá yẹn wá sọ fún wa pé, tá a bá tún ní ìṣòro èyíkéyìí, ká pe òun ní tààràtà, òun á sì bójú tó ọ̀ràn náà fúnra òun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjèjì ni wá, tí a kò sì fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Faransé, síbẹ̀ àwọn èèyàn fi inú rere hàn sí wa, wọ́n sì gbà wá tọwọ́ tẹsẹ̀. Àmọ́, à ń rò ó pé, ‘Ṣé wọ́n á mọ òtítọ́ báyìí?’ A rí ìdáhùn ìbéèrè wa ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà nígbà tá a pa dà lọ kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba jákèjádò ìlú Gaspé. A rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn tá a wàásù fún ló ti wá di Ẹlẹ́rìí. Ká sòótọ́, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń mú kó dàgbà.—1 Kọ́r. 3:6, 7.

A Rí Ogún Kan Gbà

A bí ọmọbìnrin wa tó ń jẹ́ Lisa lọ́dún 1970. Ogún pàtàkì yìí látọ̀dọ̀ Jèhófà mú ayọ̀ tá a ní nígbèésí ayé wa pọ̀ sí i. Ìyàwó mi àti Lisa ọmọ wa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú mi lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Lẹ́yìn tí Lisa parí ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Bàbá mi àti ìyá mi, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èmi ni mo gbé e yín kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún àkókò díẹ̀, màá gbìyànjú láti dí i fún un yín nípa títẹ́wọ́ gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.” Ó ti lé ní ogún ọdún báyìí tí Lisa ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ṣùgbọ́n òun àti ọkọ rẹ̀ Sylvain, ni báyìí. Àwọn méjèèjì ti láǹfààní láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé káàkiri ayé. Àfojúsùn wa gẹ́gẹ́ bí ìdílé ni pé ká jẹ́ kí ohun ìní tara díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, ká sì yọ̀ǹda ara wa fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Mi ò tíì gbàgbé ọ̀rọ̀ tí Lisa sọ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Kódà òun ló mú kí ń pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ́dún 2001, mo sì ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà bọ̀ látìgbà yẹn. Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ti kọ́ mi láti fọkàn tán Jèhófà nínú ohun gbogbo tí mo bá ń ṣe, kí ohun ìní tara díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, mo sì láyọ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

Iṣẹ́ Ìkọ́lé Gba Pé Kéèyàn Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́, Adúróṣinṣin àti Olóòótọ́

Jèhófà ti kọ́ mi pé, tá a bá yọ̀ǹda ara wa, tá a sì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ èyíkéyìí tí òun bá fún wa, ọ̀pọ̀ ìbùkún ló wà téèyàn máa rí gbà. Àǹfààní iyebíye ni sísìn pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn àti lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé pẹ̀lú àwọn ará lọkùnrin àti lóbìnrin jákèjádò ẹkùn-ìpínlẹ̀ Quebec àti níbòmíì jẹ́ fún mi.

Lóòótọ́ o, àwọn kọ́lékọ́lé kan lè má máa sọ àsọyé tó fakíki lórí pèpéle, àmọ́ wọ́n máa ń tàn yòò bí ìràwọ̀ níbi iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Tọkàntọkàn làwọn ẹni ọ̀wọ́n yìí fi ń ṣe iṣẹ́ wọn, ẹ̀bùn àbínibí wọn sì ń hàn gbangba. Ohun tó máa ń yọrí sí ni ilé rèǹtè-rente tá à ń lò nínú ìjọsìn Jèhófà.

Wọ́n ti bi mí rí pé, “Àwọn ànímọ́ pàtàkì wo ló yẹ kí ẹni tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní?” Ohun tí mo mọ̀ ni pé, ẹni náà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ àti àwọn ará. (1 Kọ́r. 16:14) Lẹ́yìn náà, ó ní láti jẹ́ adúróṣinṣin àti olóòótọ́. Bí nǹkan ò bá lọ bá a ṣe fẹ́ kó lọ, èyí tó di dandan kó rí bẹ́ẹ̀, ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin kò ní yéé ṣètìlẹ́yìn fún ìṣètò Ọlọ́run. Ìṣòtítọ́ á sì mú kó yọ̀ǹda ara rẹ̀ bí iṣẹ́ ìkọ́lé míì bá yọjú.

A Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà

Lóòótọ́, ọdún 1985 ni bàbá mi ti kú, síbẹ̀ ìmọ̀ràn tó fún mi pé kí n jẹ́ kí ọwọ́ mi dí nínú ètò Jèhófà kò kúrò lọ́kàn mi. Bíi ti àwọn ẹni àmì òróró míì tó ti gba iṣẹ́ wọn nínú apá ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà, ó dájú pé ọwọ́ tirẹ̀ náà dí. (Ìṣí. 14:13) Ìyá mi ti di ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [97] báyìí. Torí pé ó ní àrùn rọpárọsẹ̀, kò lè sọ̀rọ̀ dáadáa bó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀; síbẹ̀ ó mọ Bíbélì rẹ̀. Ó máa ń tọ́ka sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú àwọn lẹ́tà tó bá kọ sí wa, ó sì máa ń fún wa ní ìṣírí pé ká má ṣe jáwọ́ nínú sísin Jèhófà tọkàntọkàn. Gbogbo àwa ọmọ la dúpẹ́ pé a ní irú àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ bẹ́ẹ̀!

Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún Shirley aya mi olóòótọ́. Kò gbàgbé ìmọ̀ràn tí ìyá rẹ̀ fún un, pé, “Ọwọ́ Vern ọkọ rẹ máa dí gan-an nínú ètò Ọlọ́run, o sì gbọ́dọ̀ mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ọkọ rẹ á máa wà pẹ̀lú rẹ.” Nígbà tá a ṣègbéyàwó ní ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta [49] sẹ́yìn, a jọ pinnu pé, a máa jọ darúgbó pa pọ̀, a óò jọ máa sin Jèhófà pa pọ̀, tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé a la òpin ayé yìí kọjá, a jọ má pa dà di ọ̀dọ́, a óò sì jọ máa sin Jèhófà títí láé. Dájúdájú, a ti ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe . . . nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58) Jèhófà náà sì ti bójú tó wa ní tòótọ́, ó sì ti rí i pé kò sígbà tá a ṣe aláìní ohun tó dára.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Jack Halliday Nathan nínú Ilé Ìṣọ́nà, September 1, 1990, ojú ìwé 10 sí 14.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

“Àfojúsùn wa gẹ́gẹ́ bí ìdílé ni pé ká jẹ́ kí ohun ìní tara díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ká sì yọ̀ǹda ara wa fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà”