Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Máa Ń mú Ipò Iwájú Nínú Bíbọlá Fún Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́?

Ǹjẹ́ O Máa Ń mú Ipò Iwájú Nínú Bíbọlá Fún Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́?

Ǹjẹ́ O Máa Ń mú Ipò Iwájú Nínú Bíbọlá Fún Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́?

“Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.”—RÓÒMÙ 12:10.

1, 2. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Róòmù níyànjú láti ṣe nínú lẹ́tà rẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?

 NÍNÚ lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ó tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó fún àwa Kristẹni láti máa fi ìfẹ́ bá ara wa lò nínú ìjọ. Ó rán wa létí pé ìfẹ́ wa gbọ́dọ̀ wà “láìsí àgàbàgebè.” Ó tún mẹ́nu kan “ìfẹ́ ará,” ó sì sọ pé ó yẹ ká fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn pẹ̀lú “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.”—Róòmù 12:9, 10a.

2 Àmọ́, níní ìfẹ́ ará kọjá kéèyàn wulẹ̀ máa fìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíì. Ó pọn dandan ká máa ṣe ohun tó fi hàn pé a ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tó máa mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan àyàfi tá a bá fi hàn nínú ìwà wa. Torí náà, Pọ́ọ̀lù fi kún ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ̀ pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10b) Báwo lèèyàn ṣe máa ń bu ọlá fún ẹlòmíì? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti mú ipò iwájú nínú bíbu ọlá fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́? Báwo la ṣe lè bu ọlá fún wọn?

Ọ̀wọ̀ àti Ọlá

3. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ọlá” nínú àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀?

3 Lóréfèé, ògidì ọ̀rọ̀ Hébérù tá a lò fún “ọlá” ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ sí “ìwúwo.” A máa ń ka ẹni tí a bá bu ọlá fún sí ẹni tó tóbi lọ́wọ́ èèyàn tàbí ẹni tó ṣe pàtàkì. Nínú Ìwé Mímọ́, wọ́n sábà máa ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù kan náà yìí sí “ògo,” èyí tó fi hàn síwájú sí i pé ọ̀wọ̀ tó ga la máa ń fún ẹni tá a bá ń bu ọlá fún. (Jẹ́n. 45:13) Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “ọlá” ní àwọn ìtumọ̀ bí iyì, ìjẹ́pàtàkì, iyebíye. (Lúùkù 14:10) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn tí à ń bu ọlá fún ṣe iyebíye, a sì kà wọ́n sí ẹni pàtàkì.

4, 5. Báwo ni bíbu ọlá fúnni àti fífi ọ̀wọ̀ hàn ṣe jọra? Ṣàpèjúwe.

4 Báwo lèèyàn ṣe máa ń bu ọlá fún ẹlòmíì? Orí ká bọ̀wọ̀ fúnni ló ti bẹ̀rẹ̀. Kódà, àwọn ọ̀rọ̀ náà “ọlá” àti “ọ̀wọ̀” la sábà máa ń lò pa pọ̀ torí pé wọ́n jọra gan-an. Bíbọlá fúnni túmọ̀ sí kéèyàn bọ̀wọ̀ fún ẹnì kan lọ́nà tó hàn gbangba. Ní èdè míì, ọ̀wọ̀ túmọ̀ sí ojú tá a fi ń wo àwọn ará wa, ṣùgbọ́n bíbọlá fún wọn túmọ̀ sí ọ̀nà tá a gbà ń bá wọn lò.

5 Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè bọlá fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni, bí kò bá ní ọ̀wọ̀ àtọkànwá fún wọn? (3 Jòh. 9, 10) Bí igi ṣe máa ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ tó sì máa ń tọ́jọ́ bí wọ́n bá gbìn ín sórí ilẹ̀ tó dáa, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíì máa ń tọ́jọ́ tó sì máa ń jẹ́ ojúlówó, bó bá ti inú ọkàn wá. Àmọ́ nítorí pé ọ̀wọ̀ tí kì í ṣe ojúlówó ló máa ń mú kéèyàn fi ẹnu lásán bọlá fáwọn ẹlòmíì, kò ní pẹ́ táá fi rọ bíi koríko, táá sì rẹ̀ dà nù. Abájọ tó fi jẹ́ pé, kí Pọ́ọ̀lù tó gbani níyànjú láti bọlá fún àwọn ẹlòmíì, ó sọ lọ́nà tó ṣe kedere pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí àgàbàgebè.”—Róòmù 12:9; ka 1 Pétérù 1:22.

Ẹ Bọlá fún Àwọn Tá A Dá “ní Ìrí Ọlọ́run”

6, 7. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn?

6 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ ní ọ̀wọ̀ àtọkànwá ká tó lè bọlá fúnni, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu tá a fi gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ará wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbé méjì lára àwọn ìdí wọ̀nyẹn yẹ̀ wò.

7 Nínú gbogbo ẹ̀dá yòókù tí Ọlọ́run dá sórí ilẹ̀ ayé, àwa èèyàn nìkan ni a dá “ní ìrí Ọlọ́run.” (Ják. 3:9) Torí náà, a fi àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ọgbọ́n àti ìdájọ́ òdodo jọ Ọlọ́run. Tún kíyè sí ohun mìíràn tí Ẹlẹ́dàá wa fi jíǹkí wa. Onísáàmù sọ pé: “Ìwọ Jèhófà . . . , a ń ròyìn iyì rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ lókè ọ̀run! . . . Ìwọ sì tẹ̀ síwájú láti ṣe [ènìyàn] ní ẹni rírẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ẹni bí Ọlọ́run, o sì wá fi ògo àti ọlá ńlá [“ọlá,” Bibeli Mimọ] dé e ládé.” (Sm. 8:1, 4, 5; 104:1) a Gbogbo ẹ̀dá èèyàn lápapọ̀ ni Ọlọ́run fi iyì, ògo àti ọlá dé ládé tàbí ká sọ pé ó fi ṣe wọ́n lọ́ṣọ̀ọ́. Torí náà, bá a bá ṣe ohun tó buyì kún àwọn ẹlòmíì, ńṣe là ń fi hàn pé a fara mọ́ Jèhófà, tó jẹ́ Orísun iyì ẹ̀dá èèyàn. Torí náà, bá a bá ní ìdí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tá a fi gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn lápapọ̀, mélòómélòó ló wá yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́!—Jòh. 3:16; Gál. 6:10.

Ara Ìdílé Kan Náà ni Wá

8, 9. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé a gbọ́dọ̀ máa torí rẹ̀ bọ̀wọ̀ fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

8 Pọ́ọ̀lù tún sọ ìdí míì tá a fi gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ara wa. Ṣáájú ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ̀ pé ká máa bu ọlá fúnni, ó sọ pé: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” Gbólóhùn èdè Gíríìkì náà, “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” tọ́ka sí ìdè lílágbára tó so ìdílé onífẹ̀ẹ́, tí wọ́n máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ pa pọ̀. Torí náà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù lo gbólóhùn yẹn, ńṣe ló ń tẹnu mọ́ ọn pé àjọṣe àárín wa nínú ìjọ gbọ́dọ̀ lágbára, kó sì fìfẹ́ hàn bí èyí tó máa ń wà nínú ìdílé tó wà ní ìṣọ̀kan. (Róòmù 12:5) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, rántí pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni Pọ́ọ̀lù kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sí, Baba kan náà, ìyẹn Jèhófà ló sì gba gbogbo wọn ṣọmọ. Torí náà, lọ́nà kan tó ṣe pàtàkì, wọ́n jẹ́ ìdílé tó sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí ìdí tó lágbára fi wà fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà láyé nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí láti máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Bí ọ̀rọ̀ àwọn ẹni àmì òróró ṣe rí lónìí náà nìyẹn.

9 Àwọn tó jẹ́ ara “àwọn àgùntàn mìíràn” ńkọ́? (Jòh. 10:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kò gbà wọ́n ṣọmọ, ó tọ́ kí wọ́n máa pe ara wọn ní arákùnrin àti arábìnrin torí pé wọ́n para pọ̀ di ìdílé Kristẹni kan ṣoṣo tó wà ní ìṣọ̀kan kárí ayé. (1 Pét. 2:17; 5:9) Torí náà, bí àwọn àgùntàn mìíràn bá ní òye kíkún nípa ohun tí wọ́n ń sọ nígbà tí wọ́n bá ń lo gbólóhùn náà “arákùnrin” tàbí “arábìnrin,” a jẹ́ pé àwọn pẹ̀lú ní ìdí tó lágbára láti máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ látinú ọkàn wọn wá.—Ka 1 Pétérù 3:8.

Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Gan-an?

10, 11. Kí nìdí tí bíbọ̀wọ̀ àti bíbọlá fúnni fi ṣe pàtàkì gan-an?

10 Kí nìdí tí bíbọ̀wọ̀ àti bíbọlá fúnni fi ṣe pàtàkì gan-an? Ìdí nìyí: Bá a bá ń bọlá fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, ńṣe là ń pa kún ire àti ìṣọ̀kan ìjọ lápapọ̀.

11 Àmọ́ ṣá o, a mọ̀ pé níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà àti rírí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ gbà ni orísun okun tó lágbára jù lọ, èyí tá a ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́. (Sm. 36:7; Jòh. 14:26) Lẹ́sẹ̀ kan náà, nígbà tí àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá fi hàn pé àwọn mọrírì wa, ó máa ń fún wa níṣìírí. (Òwe 25:11) Ọ̀rọ̀ tó fi ìmọrírì àti ọ̀wọ̀ hàn tí wọ́n bá sọ látọkàn wá máa ń gbé wa ró gan-an. Ó máa ń fún wa lókun tó pọ̀ sí i láti máa fi ayọ̀ bá a nìṣó láìyẹsẹ̀ lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára ìwọ náà nìyẹn.

12. Báwo ni àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe lè pa kún ẹ̀mí ìfẹ́ àti ọ̀yàyà tó wà nínú ìjọ?

12 Níwọ̀n bí Jèhófà ti mọ̀ pé a fẹ́ káwọn ẹlòmíì máa bọ̀wọ̀ fún wa, ó ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ wá pé “niti ọla, ẹ [máa] fi ẹnikeji yin ṣaaju.” (Róòmù 12:10, Bibeli Ajuwe; ka Mátíù 7:12.) Gbogbo Kristẹni tó bá ń fi ìmọ̀ràn tó ṣeé fi sílò nígbà gbogbo yìí sọ́kàn máa pa kún ọ̀yàyà àti ìfẹ́ tó wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará tó jẹ́ Kristẹni. Fún ìdí yìí, ó dára ká sinmẹ̀dọ̀ ká sì bi ara wa pé, ‘Ìgbà wo ni mo fi ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ hàn fún arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú ìjọ gbẹ̀yìn, yálà nípa ìṣesí tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu mi?’—Róòmù 13:8.

Iṣẹ́ Tí Gbogbo Wa Ní Láti Ṣe

13. (a) Ta ló yẹ kó mú ipò iwájú nínú bíbọlá fún àwọn ẹlòmíì? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Róòmù 1:7 fi hàn?

13 Ta ló yẹ kó mú ipò iwájú nínú bíbọlá fúnni? Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Hébérù, ó ṣàlàyé pé àwọn alàgbà ìjọ Kristẹni jẹ́ “àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín.” (Héb. 13:17) Lóòótọ́, àwọn alàgbà máa ń mú ipò iwájú nínú onírúurú ìgbòkègbodò ìjọ. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn agbo, ó dájú pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa mú ipò iwájú nínú bíbọlá fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́, tó fi mọ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ alàgbà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn alàgbà bá pàdé pọ̀ láti ṣàgbéyẹ̀wò ipò tẹ̀mí ìjọ, wọ́n ń bọlá fún ara wọn nípa fífara balẹ̀ tẹ́tí sí àlàyé tí èyíkéyìí lára àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ alàgbà bá ń ṣe. Síwájú sí i, wọ́n ń bọlá fún ara wọn nípa gbígbé èrò àti ọ̀rọ̀ tí gbogbo alàgbà yòókù bá sọ yẹ̀ wò kó tó di pé wọ́n ṣe ìpinnu. (Ìṣe 15:6-15) Àmọ́, a gbọ́dọ̀ máa rántí pé ìjọ lápapọ̀ ni Pọ́ọ̀lù darí lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Róòmù sí, kì í ṣe àwọn alàgbà nìkan. (Róòmù 1:7) Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo wa lónìí ni ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù pé ká máa mú ipò iwájú nínú bíbu ọlá fúnni kàn.

14. (a) Ṣe àpèjúwe ìyàtọ̀ tó wà láàárín bíbọlá fúnni àti mímú ipò iwájú nínú bíbọlá fúnni. (b) Ìbéèrè wo la lè bi ara wa?

14 Tún fiyè sí apá mìíràn yìí nínú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù. Kò wulẹ̀ rọ àwọn ará Róòmù tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé kí wọ́n máa bọlá fúnni, àmọ́ ó sọ pé kí wọ́n máa mú ipò iwájú nínú bíbọlá fúnni. Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú méjèèjì? Ronú nípa àpèjúwe yìí ná. Ǹjẹ́ olùkọ́ kan jẹ́ sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ̀wé kà pé kí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ béèyàn ṣe ń kàwé? Rárá o. Ìdí ni pé wọ́n ti mọ béèyàn ṣe ń kàwé. Ńṣe ni olùkọ́ náà á wulẹ̀ fẹ́ láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ kí ìwé kíkà wọn lè sunwọ̀n sí i. Bákan náà, bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wa, èyí tó ń mú ká bọlá fúnni, ti jẹ́ àmì tá a fi ń dá àwa Kristẹni tòótọ́ mọ̀. (Jòh. 13:35) Àmọ́, bí akẹ́kọ̀ọ́ tó ti mọ̀wé kà ṣe lè tẹ̀ síwájú nípa mímú kí ìwé kíkà rẹ̀ sunwọ̀n sí i, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà ṣe lè tẹ̀ síwájú nípa mímú ipò iwájú nínú bíbọlá fúnni. (1 Tẹs. 4:9, 10) Ohun tó sì yẹ kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe nìyẹn. A lè bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń ṣe bẹ́ẹ̀, nípa jíjẹ́ ẹni tó kọ́kọ́ ń bọlá fúnni nínú ìjọ?’

Bọlá fún “Àwọn Ẹni Rírẹlẹ̀”

15, 16. (a) Àwọn wo ni kò yẹ ká gbójú fò dá tí a bá ń bọlá fúnni, kí sì nìdí? (b) Kí ló máa fi hàn pé a ní ọ̀wọ̀ àtọkànwá fún gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin?

15 Àwọn wo ni kò yẹ ká gbójú fò dá nínú ìjọ tí a bá ń bọlá fúnni? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, Òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.” (Òwe 19:17) Báwo la ṣe lè máa fi àwọn ìlànà tó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí sílò bá a ṣe ń sakun láti máa mú ipò iwájú nínú bíbọlá fúnni?

16 Wàá gbà pé àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ máa ń bọlá fún ẹni tó bá wà nípò tó ga ju tiwọn lọ, síbẹ̀ wọ́n lè ṣàì fún ẹni tí wọ́n gbà pé ó rẹlẹ̀ sí wọn ní ọ̀wọ̀ tó pọ̀ tó tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ bọ̀wọ̀ fún un rárá. Àmọ́, Jèhófà kì í ṣe bẹ́ẹ̀ o. Ó sọ pé: “Àwọn tí ń bọlá fún mi ni èmi yóò bọlá fún.” (1 Sám. 2:30; Sm. 113:5-7) Jèhófà máa ń bọlá fún gbogbo àwọn tó bá ń sìn ín tí wọ́n sì ń bọlá fún un. Kì í fojú tín-ínrín “àwọn ẹni rírẹlẹ̀.” (Ka Aísáyà 57:15; 2 Kíró. 16:9) Àmọ́ ṣá o, a fẹ́ láti máa fara wé Jèhófà. Nípa bẹ́ẹ̀, bá a bá ń bọlá fún àwọn ẹlòmíì, tá a sì fẹ́ láti mọ bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó, ó dáa ká bi ara wa pé, ‘Báwo ni mo ṣe ń ṣe sí àwọn tí kò ní iṣẹ́ kankan nínú ìjọ tí wọ́n ń bójú tó?’ (Jòh. 13:14, 15) Ìdáhùn wa sí ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká mọ bí ọ̀wọ̀ tá a ní fún àwọn ẹlòmíì ṣe jẹ́ àtọkànwá tó.—Ka Fílípì 2:3, 4.

Bá A Ṣe Lè Máa Bọlá Fúnni Nípa Yíyọ̀ǹda Àkókó Wa

17. Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà máa bọlá fúnni, kí sì nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

17 Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà máa mú ipò iwájú nínú bíbọlá fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa yíyọ̀ǹda àkókò wa. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ọwọ́ wa máa ń dí gan-an, bíbójú tó ọ̀pọ̀ ìgbòkègbodò tó ṣe pàtàkì nínú ìjọ sì máa ń gba èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wa. Torí náà, kì í ṣe ohun ìyàlẹ́nu pé ọwọ́ pàtàkì la fi ń mú àkókò. A kì í retí pé kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa máa fi gbogbo àkókò wọn gbọ́ tiwa. Bákan náà, a máa ń mọrírì rẹ̀ bí àwọn míì nínú ìjọ bá mọ̀ pé kò yẹ kí àwọn máa fẹ́ ká fi gbogbo àkókò wa gbọ́ tiwọn.

18. Gẹ́gẹ́ bí àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18 ṣe fi hàn, báwo la ṣe lè fi hàn pé a ti múra tán láti yọ̀ǹda díẹ̀ lára àkókò wa fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

18 Pẹ̀lú bí ọwọ́ wa ṣe ń dí tó yìí, (pàápàá jù lọ àwọn tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ láàárín wa) a mọ̀ pé bá a bá múra tán láti dá ohun tá à ń ṣe dúró díẹ̀ ká bàa lè fi díẹ̀ lára àkókò wa gbọ́ ti àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, ìyẹn á fi hàn pé a ní ọ̀wọ̀ fún wọn. Lọ́nà wo? Bá a bá dá ohun tá à ń ṣe dúró, tá a sì fi àkókò díẹ̀ gbọ́ ti àwọn ará wa, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tá à ń sọ fún wọn pé, ‘O ṣeyebíye lójú mi débi pé ó ṣe pàtàkì jù fún mi láti lo àkókò díẹ̀ pẹ̀lú rẹ ju kí n máa bá ohun tí mò ń ṣe nìṣó.’ (Máàkù 6:30-34) Bó sì ṣe rí náà nìyẹn bá ò bá dá ohun tá à ń ṣe dúró láti gbọ́ tàwọn ará, a lè mú kí wọ́n rí ara wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan lójú wa. Àmọ́ ṣá o, a mọ̀ pé àwọn àkókò kan wà tí a kò ní lè dá àwọn ọ̀ràn tó jẹ́ kánjúkánjú dúró. Síbẹ̀, mímúra tán láti wá àkókò díẹ̀ gbọ́ tàwọn ẹlòmíì tàbí lílọ́ tìkọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, máa sọ púpọ̀ nípa bí ọ̀wọ̀ tá a ní fún àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe jinlẹ̀ tó.—1 Kọ́r. 10:24.

Múra Tán Láti Mú Ipò Iwájú

19. Yàtọ̀ sí yíyọ̀ǹda àkókò wa, ọ̀nà míì wo la tún lè gbà bọlá fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

19 Àwọn ọ̀nà pàtàkì míì wà tá a lè gbà máa bọlá fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá yọ̀ọ̀da àkókò wa fún wọn, ó tún yẹ ká pọkàn pọ̀ sórí ohun tí wọ́n ń sọ. Jèhófà tún fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa nínú èyí. Onísáàmù náà, Dáfídì, sọ pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.” (Sm. 34:15) À ń sapá láti fara wé Jèhófà nípa jíjẹ́ kí ojú wa wà lọ́dọ̀ àwọn ará wa, kí etí wa sì ṣí sí wọn, ìyẹn ni pé ká pọkàn pọ̀ dáadáa sorí ohun tí wọ́n ń sọ, pàápàá jù lọ nígbà tí wọ́n bá wá ìrànlọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ wa. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, á máa fi hàn pé a bọlá fún wọn.

20. Àwọn ìránnilétí wo nípa bíbọlá fúnni ló yẹ ká fi sọ́kàn?

20 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, kò yẹ ká gbàgbé ìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ látọkàn wá fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Síwájú sí i, a ó máa wá ọ̀nà láti jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí yóò máa bọlá fún gbogbo èèyàn, tó fi mọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀. Bá a bá ń ṣe àwọn ohun tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, okùn ìfẹ́ tó so wá pọ̀ àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ á máa lágbára sí i. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó ní bíbọlá fún ara wa lẹ́ni kìíní kejì, àti ní pàtàkì jù lọ ká máa mú ipò iwájú nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé o ti múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù Kẹjọ tún jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó ń tọ́ka sí ọkùnrin pípé náà Jésù Kristi.—Héb. 2:6-9.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo ni ọlá àti ọ̀wọ̀ ṣe jọra?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bọlá fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa bọlá fún ara wa lẹ́nì kìíní kejì?

• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà máa bọlá fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Báwo la ṣe lè máa bọlá fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?