Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Yóò Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́ wa!

Àwa Yóò Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́ wa!

Àwa Yóò Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́ wa!

“Ní tèmi, èmi yóò máa rìn nínú ìwà títọ́ mi.”—SM. 26:11.

1, 2. Kí ni Jóòbù sọ nípa ìwà títọ́ rẹ̀, kí sì ni Jóòbù orí 31 fi hàn nípa rẹ̀?

 LÁYÉ ìgbàanì, orí òṣùwọ̀n tí wọ́n fi igi ṣe ni wọ́n tí máa ń wọn nǹkan. Òṣùwọ̀n yìí máa ń ní igi gbọọrọ kan tí wọ́n gbé dábùú igi kan tó wà lóòró. Wọ́n á wá fi okùn tàbí ẹ̀wọ̀n gbé abọ́ kan kọ́ sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún àti ẹ̀gbẹ́ òsì igi gbọọrọ náà. Wọ́n á kó ohun tí wọ́n fẹ́ wọ̀n sínú abọ́ kan, wọ́n á sì kó adíwọ̀n sínú abọ́ kejì. Àwọn èèyàn Ọlọ́run kò gbọ́dọ̀ ki èrú bọ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lo òṣùwọ̀n wọn.—Òwe 11:1.

2 Nígbà tí Jóòbù tó jẹ́ èèyàn rere ń jìyà látàrí ìkọlù Sátánì, ó sọ pé: “[Jèhófà] yóò wọ̀n mí lórí òṣùwọ̀n pípéye, Ọlọ́run yóò sì wá mọ ìwà títọ́ mi.” (Jóòbù 31:6) Lórí kókó yẹn, Jóòbù mẹ́nu kan àwọn ipò kan tó lè dán ìwà títọ́ ẹni wò. Àmọ́ kò sí àní-àní pé Jóòbù yege ìdánwò náà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà nínú Jóòbù orí 31 ṣe fi hàn. Àpẹẹrẹ rere rẹ̀ lè mú kí àwa náà fẹ́ ṣe ohun kan náà, ká sì sọ pẹ̀lú ìdánilójú bíi ti onísáàmù náà Dáfídì, pé: “Ní tèmi, èmi yóò máa rìn nínú ìwà títọ́ mi.”—Sm. 26:11.

3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run nínú nǹkan ńlá àti kékeré?

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdánwò Jóòbù lágbára gan-an, síbẹ̀ ó dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Àwọn kan tiẹ̀ lè sọ pé ìdánwò tó lágbára tí Jóòbù dojú kọ àti bó ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Ìyà kò jẹ wá bó ṣe jẹ Jóòbù. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run nínú ọ̀ràn kékeré àti ńlá tá a bá fẹ́ kó túbọ̀ fìdí múlẹ̀ pé à ń pa ìwà títọ́ wa mọ́ àti pé ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ la fara mọ́.—Ka Lúùkù 16:10.

Ìwà Títọ́ Pọn Dandan

4, 5. Àwọn ìwà wo ni Jóòbù yẹra fún gẹ́gẹ́ bí olùpa ìwà títọ́ mọ́?

4 Ká lè máa jẹ́ oníwà títọ́ sí Jèhófà nìṣó, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà rere rẹ̀ bí Jóòbù ti ṣe. Jóòbù kéde pé: “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú. Nítorí náà, èmi yóò ha ṣe tẹjú mọ́ wúńdíá? . . . Bí ọkàn-àyà mi bá ti di rírélọ sọ́dọ̀ obìnrin kan, tí mo sì ń lúgọ àní ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé alábàákẹ́gbẹ́ mi, kí aya mi fi ọlọ lọ nǹkan fún ọkùnrin mìíràn, kí àwọn ọkùnrin mìíràn sì kúnlẹ̀ lórí rẹ̀.”—Jóòbù 31:1, 9, 10.

5 Jóòbù ti pinnu pé kò sí ohun tó máa ba ìwà títọ́ òun sí Ọlọ́run jẹ́, torí náà ó yẹra fún wíwo obìnrin débi tó fi máa wù ú láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Níwọ̀n bí Jóòbù ti ní ìyàwó tirẹ̀, kì í bá àwọn ọ̀dọ́bìnrin tage tàbí kó máa sapá láti yan ìyàwó ọkùnrin mìíràn lálè. Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù sọ̀rọ̀ kan tó lágbára nípa ṣíṣe ìṣekúṣe, ó sì dájú pé èyí jẹ́ ohun kan tí àwọn tó fẹ́ pa ìwà títọ́ wọn mọ́ gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn.—Ka Mátíù 5:27, 28.

Má Ṣe Di Oníbékebèke

6, 7. (a) Kí ni Ọlọ́run ń lò láti díwọ̀n ìwà títọ́ wa, bí ọ̀ràn ti Jóòbù ṣe fi hàn? (b) Kí nìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ di oníbékebèke tàbí ẹlẹ́tàn?

6 A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ oníbékebèke tá a bá fẹ́ jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́. (Ka Òwe 3:31-33.) Jóòbù sọ pé: “Bí ó bá ṣe pé mo bá àwọn ènìyàn tí kì í sọ òtítọ́ rìn, tí ẹsẹ̀ mi sì ṣe kánkán sí ẹ̀tàn, [Jèhófà] yóò wọ̀n mí lórí òṣùwọ̀n pípéye, Ọlọ́run yóò sì wá mọ ìwà títọ́ mi.” (Jóòbù 31:5, 6) Jèhófà máa ń wọn gbogbo èèyàn lórí “òṣùwọ̀n pípéye.” Bí ọ̀ràn Jóòbù ṣe fi hàn, Ọlọ́run máa ń lo ìlànà òdodo rẹ̀ pípé láti díwọ̀n ìwà títọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún un.

7 Tá a ba lọ di oníbékebèke tàbí ẹlẹ́tàn, a jẹ́ pé a kò pa ìwà títọ́ wa sí Ọlọ́run mọ́ nìyẹn. Àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ ti “kọ àwọn ohun má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ tí ń tini lójú sílẹ̀ ní àkọ̀tán” wọn kò sì “rin ìrìn àlùmọ̀kọ́rọ́yí.” (2 Kọ́r. 4:1, 2) Àmọ́ tá a bá jẹ́ oníbékebèke nínú ọ̀rọ̀ ẹnu wa tàbí ìwà wa ńkọ́, tí ìyẹn sì mú kí àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ fà wá lé Ọlọ́run lọ́wọ́? Ìyẹn á mà burú jáì fún wa o! Onísáàmù kan kọrin pé: “Jèhófà ni mo ké pè nínú wàhálà mi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lóhùn. Jèhófà, dá ọkàn mi nídè lọ́wọ́ ètè èké, lọ́wọ́ ahọ́n àgálámàṣà.” (Sm. 120:1, 2) Ó dára ká rántí pé Ọlọ́run lè ṣàyẹ̀wò irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, kó sì “dán ọkàn-àyà àti àwọn kíndìnrín [wa] wò,” kó lè mọ̀ bóyá lóòótọ́ la jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́.—Sm. 7:8, 9.

Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere Nínú Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Àwọn Èèyàn

8. Báwo ni Jóòbù ṣe hùwà sí àwọn èèyàn?

8 Ká lè máa pa ìwà títọ́ wa mọ́, a ní láti fìwà jọ Jóòbù tó jẹ́ olódodo, onírẹ̀lẹ̀ àti olùgbatẹnirò. Ó sọ pé: “Bí ó bá ṣe pé mo ti máa ń kọ ìdájọ́ ẹrúkùnrin mi, tàbí ti ẹrúbìnrin mi nínú ẹjọ́ wọn lábẹ́ òfin pẹ̀lú mi, nígbà náà, kí ni mo lè ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde? Nígbà tí ó bá sì béèrè fún ìjíhìn, kí ni mo lè fi dá a lóhùn? Kì í ha ṣe Ẹni tí ó ṣẹ̀dá mi nínú ikùn ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀, kì í ha sì í ṣe Ẹnì kan ṣoṣo ni ó bẹ̀rẹ̀ sí pèsè wa sílẹ̀ nínú ilé ọlẹ̀?”—Jóòbù 31:13-15.

9. Ànímọ́ wo ni Jóòbù fi hàn nínú bó ṣe ń hùwà sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, báwo ló ṣe yẹ kí àwa náà máa ṣe nínú ọ̀ràn yìí?

9 Ó ṣe kedere pé kì í ṣe ohun tó ṣòro láti gbọ́ ẹjọ́ nígbà ayé Jóòbù. Wọ́n máa ń gbọ́ ẹjọ́ lọ́nà tó wà létòlétò, kódà àwọn ẹrú ní ilé ẹjọ́ tí wọ́n lè gbé ẹjọ́ wọn lọ. Jóòbù jẹ́ olódodo àti aláàánú nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Tá a bá fẹ́ máa rìn nínú ìwà títọ́, a gbọ́dọ̀ ní irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì jù lọ tá a bá jẹ́ alàgbà nínú ìjọ Kristẹni.

Jẹ́ Ọ̀làwọ́, Má Ṣe Jẹ́ Olójúkòkòrò

10, 11. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jóòbù jẹ́ ọ̀làwọ́ tó sì ń ranni lọ́wọ́? (b) Ìmọ̀ràn míì wo nínú Ìwé Mímọ́ ni Jóòbù 31:16-25, lè rán wa létí?

10 Jóòbù jẹ́ ọ̀làwọ́, ó sì máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan tàbí olójúkòkòrò. Ó sọ pé: “Bí ó bá ṣe pé mo ti . . . mú kí ojú opó kọṣẹ́, tí mo sì máa ń dá nìkan jẹ òkèlè mi, nígbà tí ọmọdékùnrin aláìníbaba kò jẹ nínú rẹ̀ . . . Bí mo bá ń rí ẹnikẹ́ni tí n ṣègbé lọ nítorí tí kò ní ẹ̀wù . . . Bí mo bá fi ọwọ́ mi síwá-sẹ́yìn lòdì sí ọmọdékùnrin aláìníbaba, nígbà tí mo bá rí i pé a nílò ìrànwọ́ mi ní ẹnubodè, kí ibi palaba èjìká mi já bọ́ kúrò ní èjìká, kí apá mi sì ṣẹ́ kúrò ní egungun apá òkè.” Jóòbù kò ní jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́ ká ní ó sọ fún wúrà pé: “Ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi!”—Jóòbù 31:16-25.

11 Àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ ewì yìí lè mú wa rántí ọ̀rọ̀ Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn tó sọ pé: “Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.” (Ják. 1:27) A tún lè rántí ìkìlọ̀ Jésù pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò, nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” Jésù wa sọ àkàwé ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó jẹ́ olójúkòkòrò, tó kú gẹ́gẹ́ bí ẹni “tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:15-21) Ká lè jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́, a kò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ ojúkòkòrò àti ìwọra. Ojúkòkòrò jẹ́ ìbọ̀rìṣà torí pé ohun tí oníwọra èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ sí kò ní jẹ́ kó rántí Jèhófà mọ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ dí òrìṣà. (Kól. 3:5) Ìwà títọ́ àti ìwọra kò bára wọn tan!

Má Ṣe Fi Ìsìn Tòótọ́ Sílẹ̀

12, 13. Àpẹẹrẹ wo ni Jóòbù fi lélẹ̀ nípa sísá fún ìbọ̀rìṣà?

12 Àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ kì í fi ìsìn tòótọ́ sílẹ̀. Jóòbù kò ṣe bẹ́ẹ̀, torí ó polongo pé: “Bí mo bá ń rí ìmọ́lẹ̀ nígbà tí ó bá kọ mànà, tàbí òṣùpá ọ̀wọ́n tí ń rìn lọ, tí ọkàn-àyà mi sì bẹ̀rẹ̀ sí di rírélọ ní ìkọ̀kọ̀ tí ọwọ́ mi sì bẹ̀rẹ̀ sí ko ẹnu mi, ìyẹn pẹ̀lú yóò jẹ́ ìṣìnà fún àfiyèsí àwọn adájọ́, nítorí èmi ì bá ti sẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó wà lókè.”—Jóòbù 31:26-28.

13 Jóòbù kò jọ́sìn ohun aláìlẹ́mìí èyíkéyìí. Ká sọ pé ọkàn Jóòbù bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí àwọn ohun tó wà lójú sánmà, bí òṣùpá, tí ‘ọwọ́ rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í ko ẹnu rẹ̀’ bóyá kó máa tẹrí ba fún wọn bí ẹni pé ó ń jọ́sìn wọn, a jẹ́ pé ó ti di abọ̀rìṣà tó sẹ́ Ọlọ́run nìyẹn. (Diu. 4:15, 19) Ká lè máa bá a nìṣó láti pa ìwà títọ́ wa sí Ọlọ́run mọ́, a gbọ́dọ̀ sá fún gbogbo ìbọ̀rìṣà.—Ka 1 Jòhánù 5:21.

Má Ṣe Máa Gbẹ̀san Tàbí Kó O Jẹ́ Alágàbàgebè

14. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jóòbù kì í ṣe èèyànkéèyàn?

14 Jóòbù kì í ṣe èèyànkéèyàn tàbí òǹrorò ẹ̀dá. Ó mọ̀ pé irú àṣà bẹ́ẹ̀ kò ní fi hàn pé èèyàn jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́, torí ó sọ pé: ‘Bí mo bá yọ̀ sí àkúrun ẹni tí ó kórìíra mi lọ́nà gbígbóná janjan, tàbí tí mo ní ìmọ̀lára ìrusókè nítorí pé ibi ti dé bá a, èmi kò jẹ́ kí òkè ẹnu mi dẹ́ṣẹ̀ nípa bíbéèrè fún ìbúra lòdì sí ọkàn rẹ̀.’—Jóòbù 31:29, 30.

15. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa yọ̀ nígbà tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan tó kórìíra wa?

15 Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ kì í yọ̀ bí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó kórìíra rẹ̀. Òwe kan sọ lẹ́yìn náà pé: “Nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú, má yọ̀; nígbà tí a bá sì mú un kọsẹ̀, kí ọkàn-àyà rẹ má ṣe kún fún ìdùnnú, kí Jèhófà má bàa rí i, kí ó sì burú ní ojú rẹ̀, òun a sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lára rẹ̀ dájúdájú.” (Òwe 24:17, 18) Níwọ̀n bí Jèhófà ti lè rí ohun tó wà lọ́kàn wa, ó mọ̀ tí inú wa bá ń yọ́ dùn nítorí àjálù tó dé bá ẹlòmíì, ó sì dájú pé kò nífẹ̀ẹ́ sí irú ìwà bẹ́ẹ̀. (Òwe 17:5) Ọlọ́run tiẹ̀ lè fìyà jẹ wa tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, torí ó sọ pé: “Tèmi ni ẹ̀san, àti ẹ̀san iṣẹ́.”—Diu. 32:35.

16. Kódà tí a kò bá jẹ́ ọlọ́rọ̀, báwo la ṣe lè ní ẹ̀mí aájò àlejò?

16 Jóòbù ní ẹ̀mí aájò àlejò. (Jóòbù 31:31, 32) Lóòótọ́, a lè máà jẹ́ ọlọ́rọ̀, síbẹ̀ a lè “máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.” (Róòmù 12:13) A lè ṣàjọpín ìpápánu pẹ̀lú àwọn èèyàn, ká máa rántí pé “oúnjẹ tí a fi ọ̀gbìn oko sè, níbi tí ìfẹ́ wà, sàn ju akọ màlúù tí a bọ́ yó ní ibùjẹ ẹran tòun ti ìkórìíra.” (Òwe 15:17) Jíjẹ oúnjẹ pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń pa ìwà títọ́ mọ́ níbi tí ìfẹ́ wà máa mú kí ìpápánu lásán gbádùn mọ́ni, ó sì dájú pé ó máa ṣe wá láǹfààní nípa tẹ̀mí.

17. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fi ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì pa mọ́?

17 Téèyàn bá jàǹfààní látara ẹ̀mí aájò àlejò Jóòbù, ó máa gbéni ró nípa tẹ̀mí torí pé Jóòbù kì í ṣe alágàbàgebè ẹ̀dá. Kò dà bí àwọn ọkùnrin aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run tó yọ́ wọnú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, tí wọ́n “ń kan sáárá sí àwọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn nítorí àǹfààní ti ara wọn.” (Júúdà 3, 4, 16) Jóòbù kò sì bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ tàbí kó máa fi ‘ìṣìnà rẹ̀ pa mọ́ sínú àpò ṣẹ́ẹ̀tì rẹ̀,’ kó má ṣe fẹ́ kí àwọn èèyàn tẹ́ńbẹ́lú òun nígbà tí wọ́n bá gbọ́ nípa rẹ̀. Ó múra tán láti jẹ́ kí Ọlọ́run ṣàyẹ̀wò rẹ̀, ó sì máa fẹ́ láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un. (Jóòbù 31:33-37) Tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, ẹ má ṣe jẹ́ ká fi irú ìwà àìtọ́ bẹ́ẹ̀ pa mọ́ torí pé a kò fẹ́ kí ojú tì wá. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń sapá láti máa pá ìwà títọ́ mọ́ nìṣó? A ní láti máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, ká ronú pìwà dà, ká wá ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, ká sì sa gbogbo ipá wa láti ṣàtúnṣe tó bá yẹ.—Òwe 28:13; Ják. 5:13-15.

Jóòbù Gbà Kí Ọlọ́run Dán Ìwà Títọ́ Òun Wò

18, 19. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jóòbù kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ rí? (b) Kí ni Jóòbù múra tán láti ṣe ká sọ pé ó jẹ̀bi?

18 Jóòbù jẹ́ aláìlábòsí, ó sì máa ń ṣẹ̀tọ́. Torí náà, ẹnu rẹ̀ gbà á láti sọ pé: “Bí ilẹ̀ mi bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ lòdì sí mi, tí àwọn aporo rẹ̀ sì jọ sunkún; bí mo bá jẹ èso rẹ̀ láìsan owó, tí mo sì mú kí ọkàn ẹni tí ó ni ín mí hẹlẹ, dípò àlìkámà, kí èpò ẹlẹ́gùn-ún hù jáde, àti èpò tí ń ṣíyàn-án dípò ọkà bálì.” (Jóòbù 31:38-40) Jóòbù kò gba ilẹ̀ àwọn ẹlòmíì, kò sì rẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ jẹ. Bíi ti Jóòbù, a ní láti máa pa ìwà títọ́ wa sí Jèhófà mọ́ nìṣó nínú àwọn ọ̀ràn kékeré àti ńlá.

19 Iwájú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Jóòbù mẹ́ta àti Élíhù tó jẹ́ ọ̀dọ́ ni Jóòbù ti sọ bó ṣe gbé ìgbésí ayé rẹ̀. Jóòbù ké sí ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹjọ́ lòdì sí i pé kó lọ pẹjọ́ nípa bí òun ṣe gbé ìgbésí ayé òun. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé Jóòbù jẹ̀bi, ó múra tán láti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Torí náà ó gbé ẹjọ́ rẹ̀ kalẹ̀, ó sì dúró de ìdájọ́ Ọlọ́run. Bí ‘ọ̀rọ̀ Jóòbù ṣe wá sí òpin’ nìyẹn o.—Jóòbù 31:35, 40.

Ìwọ Náà Lè Pa Ìwà Títọ́ Mọ́

20, 21. (a) Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún Jóòbù láti pa ìwà títọ́ mọ́? (b) Báwo la ṣe lè dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?

20 Ohun tó mú kó ṣeé ṣe fún Jóòbù láti pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ ni pé ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, Jèhófà náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ràn án lọ́wọ́. Jóòbù sọ pé: “Ìyè àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni ìwọ ti mú ṣiṣẹ́ nípa mi; àbójútó rẹ sì ti ṣọ́ ẹ̀mí mi.” (Jóòbù 10:12) Síwájú sí i, Jóòbù fi ìfẹ́ hàn sí àwọn èèyàn, ó mọ̀ pé ńṣe ni ẹni tó bá ń fawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ máa pa ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Olódùmarè tì. (Jóòbù 6:14) Àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wọn.—Mát. 22:37-40.

21 A lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójoojúmọ́, tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Nínú àdúrà àtọkànwá tá à ń gbà, a lè yin Jèhófà ká sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí àwọn ohun rere tó ṣe fún wa. (Fílí. 4:6, 7) A lè kọrin sí Jèhófà, ká sì jàǹfààní látinú pípéjọ déédéé pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀. (Héb. 10:23-25) Bákan náà, ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run á túbọ̀ gbèrú bá a ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá a sì ń polongo “ìhìn rere ìgbàlà rẹ̀.” (Sm. 96:1-3) Láwọn ọ̀nà yẹn, a lè pa ìwà títọ́ mọ́, bí onísáàmù náà ti ṣe, ẹni tó kọ ọ́ lórin pé: “Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi. Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni mo fi ṣe ibi ìsádi mi.”—Sm. 73:28.

22, 23. Níwọ̀n bá a ti fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, báwo ni àwọn ìgbòkègbodò wa ṣe jọ tàwọn olùpàwàtítọ́mọ́ láyé ìgbàanì?

22 Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń fún àwọn olùpàwàtítọ́mọ́ ní onírúurú iṣẹ́ láti ṣe. Nóà kan ọkọ̀ áàkì, ó sì tún jẹ́ “oníwàásù òdodo.” (2 Pét. 2:5) Jóṣúà ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé Ilẹ̀ Ìlérí, àmọ́ ohun tó mú kó kẹ́sẹ járí ni pé ó ń ka “Ìwé òfin . . . ní ọ̀sán àti ní òru,” ó sì tẹ̀ lé àwọn ohun tó kà nínú rẹ̀. (Jóṣ. 1:7, 8) Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n sì ń pàdé déédéé láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́.—Mát. 28:19, 20.

23 À ń fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, a sì ń pa ìwà títọ́ wa mọ́ nípa wíwàásù òdodo, sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, fífi ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ sílò àti pípéjọ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká, àkànṣe àti àgbègbè. Irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ ká ní ìgboyà, ká lágbára nípa tẹ̀mí, ká sì kẹ́sẹ járí nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Èyí kò ṣòro jù fún wa láti ṣe torí pé Baba wa ọ̀run àti Ọmọ rẹ̀ ń tì wá lẹ́yìn. (Diu. 30:11-14; 1 Ọba 8:57) Lákòótán, a ní ìtìlẹ́yìn “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará,” tí àwọn náà ń rìn nínú ìwà títọ́ tí wọ́n sì ń bọlá fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọba Aláṣẹ wọn.—1 Pét. 2:17.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn ìlànà ìwà rere tí Jèhófà fi lélẹ̀ fún wa?

• Àwọn ànímọ́ Jóòbù wo ló fà ẹ́ mọ́ra jù lọ?

• Bí Jóòbù 31:29-37 ṣe fi hàn, báwo ni Jóòbù ṣe hùwà?

• Kí nìdí tó fi ṣeé ṣe fún wa láti pa ìwà títọ́ wa sí Ọlọ́run mọ́?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Jóòbù pa ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà mọ́. Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

A lè pa ìwà títọ́ wa mọ́!