Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín ṣe?

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín ṣe?

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín ṣe?

“Bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́.”—1 KỌ́R. 9:26.

1, 2. Kó o lè ṣàṣeyọrí bó o ti ń dàgbà di géńdé, kí lo gbọ́dọ̀ ní?

 TÓ O bá fẹ́ rìnrìn àjò gba ojú ọ̀nà kan tí o kò mọ̀, wàá nílò ohun méjì, ìwé àwòrán ojú ọ̀nà àti ẹni tó lè júwe ọ̀nà fún ẹ. Ìwé àwòrán ojú ọ̀nà ló máa jẹ́ kó o mọ ibi tó o wà, á sì jẹ́ kó o mọ ọ̀nà tó yẹ kó o yà sí. Ẹni tó ń júwe ọ̀nà fún ẹ ni kò ní jẹ́ kó o ṣìnà. Àmọ́, ìwé àwòrán ojú ọ̀nà àti irú ẹni tó ń júwe ọ̀nà bẹ́ẹ̀ kò ní ṣe ẹ́ láǹfààní kankan tí ìwọ fúnra rẹ kò bá mọ ibi tí ò ń lọ gan-an. Kó má bàa wá di pé wàá kàn máa rìn gbéregbère kiri, ó yẹ kó o mọ ibi tí ò ń lọ.

2 Irú ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ nìyí bó o ṣe ń dàgbà. O ní àwòrán ojú ọ̀nà àti ẹni tó lè júwe ọ̀nà fún ẹ dáadáa lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ. Bíbélì ni àwòrán ojú ọ̀nà tó máa jẹ́ kó o mọ ọ̀nà tó yẹ kó o gbà. (Òwe 3:5, 6) Tó o bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an tí o kò fi ní ṣìnà. (Róòmù 2:15) Ẹ̀rí ọkàn èèyàn máa ń ṣiṣẹ́ bí ẹni tó ń júwe ọ̀nà fúnni. Kí o bàa lè ṣàṣeyọrí ní ìgbésí ayé rẹ, o tún ní láti mọ ibi tí o forí lé gan-an. Ìyẹn ni pé, kó o mọ ohun tó o fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe.

3. Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn ní àfojúsùn bí Pọ́ọ̀lù ṣe tọ́ka sí i nínú 1 Kọ́ríńtì 9:26?

3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàkópọ̀ àǹfààní tó wà nínú kéèyàn ní àfojúsùn, kó sì sapá láti jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ tẹ àfojúsùn náà, nígbà tó kọ̀wé pé: “Bí mo ti ń sáré kì í ṣe láìní ìdánilójú; bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́.” (1 Kọ́r. 9:26) Tó o bá ní àfojúsùn, wàá lè máa fi ìdánilójú ṣe àwọn ohun tó o bá ń ṣe. Láìpẹ́ láìjìnnà, wàá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan nípa ìjọsìn, iṣẹ́, ìgbéyàwó àti ìdílé, ká kàn mẹ́nu ba díẹ̀. Nígbà míì ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti gbé yẹ̀ wò tó sì ṣòro fún ẹ láti ṣe ìpinnu nípa rẹ̀. Àmọ́, tó o bá ti ṣètò ara rẹ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò, tó o sì gbé ìpinnu rẹ karí òtítọ́ àti àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, o kò ní ṣe ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání.—2 Tím. 4:4, 5.

4, 5. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí o kò bá ní àfojúsùn kankan? (b) Kí nìdí tí ìfẹ́ láti ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí fi gbọ́dọ̀ darí ìpinnu tó o bá ṣe?

4 Bí o kò bá ní àfojúsùn kankan, ó ṣeé ṣe kí àwọn ojúgbà rẹ àtàwọn olùkọ́ rẹ mú kó o ṣe ohun tí wọ́n rò pé ó tọ́ fún ẹ. Lóòótọ́ o, tó o bá tiẹ̀ ní àfojúsùn, àwọn kan ṣì lè fún ẹ ní ìmọ̀ràn tiwọn. Tó o bá ń gbọ́ àwọn àbá tí wọ́n ń dá fún ẹ, bi ara rẹ pé, ‘Ṣé àwọn ohun tí wọ́n sọ pé kí n máa lépa á jẹ́ kí n rántí Ẹlẹ́dàá mi nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, àbí ńṣe ló máa jẹ́ kó ṣòro fún mi láti ṣe bẹ́ẹ̀?’—Ka Oníwàásù 12:1.

5 Kí nìdí tó fi yẹ kí ìfẹ́ láti ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí máa darí àwọn ìpinnu tó o bá ń ṣe nígbèésí ayé rẹ? Ìdí kan ni pé Jèhófà ló fún wa ní gbogbo ohun rere tá a ní. (Ják. 1:17) Ní tòótọ́ gbogbo wa la jẹ Jèhófà ní gbèsè ọpẹ́. (Ìṣí. 4:11) Ọ̀nà wo ló tún dára jù lọ láti fi ẹ̀mí ìmoore rẹ hàn ju pé kó o fi Jèhófà sọ́kàn nígbà tó o bá fẹ́ yan àwọn ohun tí wàá fi ṣe àfojúsùn rẹ? Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó o lè fi ṣe àfojúsùn rẹ àti ohun tó o lè ṣe kọ́wọ́ rẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn náà.

Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn Rẹ?

6. Àfojúsùn pàtàkì wo lo lè ní, kí sì nìdí?

6 Bá a ṣe sọ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, àfojúsùn pàtàkì tó o lè ní ni pé kó o mú un dá ara rẹ lójú pé òótọ́ ni gbogbo ohun tí Bíbélì sọ. (Róòmù 12:2; 2 Kọ́r. 13:5) Àwọn ojúgbà rẹ lè gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ tàbí onírúurú ẹ̀kọ́ èké míì tí àwọn onísìn fi ń kọ́ni torí pé àwọn kan ti sọ fún wọn pé ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ nìyẹn. Àmọ́, ó yẹ kó o ti mọ̀ ju ìyẹn lọ pé o kò ní láti gba ohun kan gbọ́ torí pé àwọn kan sọ fún ẹ pé ohun tó o gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ nìyẹn. Rántí pé Jèhófà fẹ́ kó o fi gbogbo èrò inú rẹ sin òun. (Ka Mátíù 22:36, 37.) Baba wa ọ̀run fẹ́ kó o gbé ìgbàgbọ́ rẹ karí àwọn ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀.—Héb. 11:1.

7, 8. (a) Àfojúsùn tí ọwọ́ rẹ lè tètè tẹ̀ wo ló máa mú kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára? (b) Kí lo máa rí bó o ṣe ń sapá láti jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn àfojúsùn rẹ?

7 Kí ìgbàgbọ́ rẹ lè lágbára, kí ló dé tí o kò fi ní àwọn àfojúsùn kan tí ọwọ́ rẹ lè tètè tẹ̀? O lè fi gbígbàdúrà lójoojúmọ́ ṣe àfojúsùn rẹ. Kó má bàa di pé ohun kan náà ni wàá máa sọ ṣáá ní gbogbo ìgbà tó o bá ń gbàdúrà, o lè ṣe àkọsílẹ̀ tàbí kó o ronú nípa àwọn ohun pàtó kan tó o gbé ṣe lọ́jọ́ náà, kó o sì fi wọ́n sínú àdúrà. Rí i dájú pé kì í ṣe ìṣòro tó o bá pàdé nìkan lo mẹ́nu kàn àmọ́ kó o tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó o gbádùn. (Fílí. 4:6) Ohun míì tó o tún lè fi ṣe àfojúsùn rẹ ni láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé tó o bá ń ka ojú ìwé mẹ́rin lóòjọ́, wàá ka odindi Bíbélì tán láàárín ọdún kan? a Ìwé Sáàmù 1:1, 2 sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí . . . inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.”

8 Nǹkan kẹta tọ́wọ́ rẹ lè tètè tẹ̀ tó o lè fi ṣe àfojúsùn rẹ ni pé kó o máa múra sílẹ̀ láti dáhùn láwọn ìpàdé. Níbẹ̀rẹ̀, o lè máa ka ìdáhùn tàbí kó o ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Lẹ́yìn náà o lè wá fi ṣe àfojúsùn rẹ láti máa dáhùn lọ́rọ̀ ara rẹ. Kò sí àní-àní pé, ńṣe lò ń rú ẹbọ ìyìn sí Jèhófà ní gbogbo ìgbà tó o bá dáhùn ní ìpàdé. (Héb. 13:15) Tọ́wọ́ rẹ bá ti tẹ àwọn kan lára àwọn àfojúsùn yìí, á ṣeé ṣe fún ẹ láti túbọ̀ ní ìgboyà, ìmọrírì tó o ní fún Jèhófà á sì túbọ̀ pọ̀ sí i, wàá sì múra tán láti ní àwọn àfojúsùn tó máa pẹ́ kí ọwọ́ rẹ tó lè tẹ̀ wọ́n.

9. Bí o kò bá tíì di akéde Ìjọba Ọlọ́run, àfojúsùn tó máa pẹ́ díẹ̀ kí ọwọ́ rẹ tó tẹ̀ wo lo lè ní?

9 Àwọn nǹkan tó máa pẹ́ kí ọwọ́ rẹ tó tẹ̀ wo lo lè máa fojú sùn? Bí o kò bá tíì máa polongo ìhìn rere ní gbangba, àfojúsùn tó máa pẹ́ kí ọwọ́ rẹ tó tẹ̀ lè jẹ́ láti di akéde Ìjọba Ọlọ́run. Bí ọwọ́ rẹ bá ti tẹ àfojúsùn àtàtà yìí, wàá fẹ́ láti máa ṣe é déédéé kó o sì jẹ́ ọ̀jáfáfá lẹ́nu rẹ̀, o kò sì ní fẹ́ kí oṣù kan kọjá lọ láìjẹ́ pé o lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Wàá tún fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ láti máa lo Bíbélì lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Bó o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o rí i pé ò ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù sí i. Á sì wù ẹ́ láti fi kún àkókò tí ò ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tàbí kó o gbìyànjú láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí wàá máa darí. Gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi, àfojúsùn tó dára wo lo tún lè ní ju pé kó o kúnjú ìwọ̀n láti ṣe ìrìbọmi, kó o sì di Ẹlẹ́rìí tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run tó sì ti ṣe ìrìbọmi?

10, 11. Àfojúsùn tó máa pẹ́ kí ọwọ́ tó tẹ̀ wo ni àwọn ọ̀dọ́ tó ti ṣe ìrìbọmi lè ní?

10 Tó o bá jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣe ìrìbọmi, díẹ̀ rèé lára àwọn ohun tó máa pẹ́ díẹ̀ kí ọwọ́ rẹ tó tẹ̀ èyí tó o lè fi ṣe àfojúsùn rẹ. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè fẹ́ láti máa lọ ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí wọn kì í ti í wàásù déédéé. O sì tún lè pinnu láti lo okun àti ìlera rẹ tó jí pépé lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ náà á sọ fún ẹ pé iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún jẹ́ ọ̀nà kan láti gbà rántí Ẹlẹ́dàá rẹ nígbà tó o wà lọ́dọ̀ọ́, èrè sì wà níbẹ̀. Ọwọ́ rẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn wọ̀nyí nígbà tó o ṣì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ. Ìjọ tó o wà náà á sì jàǹfààní tí ọwọ́ rẹ bá tẹ àwọn àfojúsùn náà.

11 Àwọn àfojúsùn míì tó máa pẹ́ kí ọwọ́ rẹ tó lè tẹ̀ lè mú kó o kúrò ní ìjọ tí àwọn òbí rẹ wà. Bí àpẹẹrẹ, o lè ṣètò láti lọ sìn ní àgbègbè míì lórílẹ̀-èdè rẹ tàbí lórílẹ̀-èdè míì níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. O lè fẹ́ láti ṣèrànwọ́ nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì nílẹ̀ òkèèrè. Kódà o lè wọ iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì tàbí kó o di míṣọ́nnárì. Àmọ́, kí ọwọ́ rẹ tó lè tẹ àwọn àfojúsùn tá a mẹ́nu kàn níbí yìí, o ní láti kọ́kọ́ ṣe ìrìbọmi. Tí o kò bá tíì ṣe ìrìbọmi, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó o máa ní láti ṣe kí ọwọ́ rẹ lè tẹ ohun pàtàkì yìí ní ìgbésí ayé rẹ.

Bí Ọwọ́ Rẹ Ṣe Lè Tẹ Àfojúsùn Rẹ Láti Ṣe Ìrìbọmi

12. Kí nìdí tí àwọn kan fi ń ṣèrìbọmi, kí ló sì mú kí ìdí yìí máà lẹ́sẹ̀ nílẹ̀?

12 Kí lo lè sọ nípa ohun tí ìrìbọmi wà fún? Àwọn kan rò pé ohun tó wà fún ni láti má ṣe jẹ́ kí àwọn máa dẹ́ṣẹ̀. Àwọn míì lè sọ pé àwọn fẹ́ ṣe ìrìbọmi torí pé àwọn ojúgbà àwọn ti ṣèrìbọmi. Àwọn ọ̀dọ́ míì lè fẹ́ ṣe é láti tẹ́ àwọn òbí wọn lọ́rùn. Àmọ́ ìrìbọmi kì í ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kó o lè ṣe ohun tó máa wù ẹ́ láti ṣe níkọ̀kọ̀; kò sì yẹ kó o ṣe ìrìbọmi torí pé àwọn kan ní kó o ṣe é. Kó o tó ṣe ìrìbọmi, rí i pé o mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kó o sì rí i pé o ti múra tán látọkàn wá láti tẹ́wọ́ gba ojúṣe yìí.—Oníw. 5:4, 5.

13. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣe ìrìbọmi?

13 Ìdí kan tó fi yẹ kó o ṣe ìrìbọmi ni pé Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n sì máa batisí wọn.’ Òun fúnra rẹ̀ sì fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní ti pé ó ṣe ìrìbọmi. (Ka Mátíù 28:19, 20; Máàkù 1:9.) Síwájú sí i, ìrìbọmi jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì kan fún àwọn tó fẹ́ rí ìgbàlà. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù ti sọ̀rọ̀ nípa bí Nóà ṣe kan ọkọ̀ áàkì tí Ọlọ́run lò láti dáàbò bo òun àti ìdílé rẹ̀ nígbà Ìkún-omi, ó sọ pé: “Èyíinì tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èyí ni ó ń gbà yín là nísinsìnyí pẹ̀lú, èyíinì ni, ìbatisí, . . . nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi.” (1 Pét. 3:20, 21) Àmọ́ èyí kò túmọ̀ sí pé ìrìbọmi dà bí ìwé ìlànà ìbánigbófò tó o gbà nítorí bí ìjábá bá ṣẹlẹ̀ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, o ṣe ìrìbọmi torí pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o sì fẹ́ láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn àyà rẹ, ọkàn rẹ, èrò inú rẹ àti okun rẹ.—Máàkù 12:29, 30.

14. Kí ló lè mú kí àwọn kan má fẹ́ ṣe ìrìbọmi, àmọ́ ìdánilójú wo lo ní?

14 Àwọn kan lè máa fà sẹ́yìn láti ṣe ìrìbọmi torí wọ́n ń bẹ̀rù pé wọ́n lè yọ àwọn lẹ́gbẹ́ tó bá yá. Ṣé ohun tó ń ba ìwọ náà lẹ́rù nìyẹn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ yẹn náà burú jù. Ó lè túmọ̀ sí pé o mọ ìjẹ́pàtàkì ojúṣe tó rọ̀ mọ́ jíjẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ǹjẹ́ nǹkan míì tún lè wà tó mú kẹ́rù máa bà ẹ́? Bóyá kò tíì dá ẹ lójú pé títẹ̀lé àwọn ìlànà Ọlọ́run ni ọ̀nà tó dára jù lọ téèyàn lè gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ríronú lórí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó kọ̀ láti fi ìlànà Bíbélì sílò lè mú kó o ṣe ìpinnu. Ó sì lè jẹ́ pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run, àmọ́ kó o má fọkàn tán ara rẹ pé o lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà. Lóòótọ́ ìyẹn lè jẹ́ àmì tó dáa, torí ó fi hàn pé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé ọkàn àyà àwọn èèyàn aláìpé ṣe àdàkàdekè. (Jer. 17:9) Àmọ́ o lè kẹ́sẹ járí tó o bá ń ‘ṣọ́ra nígbà gbogbo ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’ (Ka Sáàmù 119:9.) Ohun yòówù kó máa dá ẹ dúró láti ṣe ìrìbọmi, o gbọ́dọ̀ yanjú àwọn ọ̀ràn náà àti ohun tó bá ń jẹ ọ́ lọ́kàn. b

15, 16. Báwo lo ṣe lè mọ̀ pé o ti ṣe tán láti ṣe ìrìbọmi?

15 Báwo lo ṣe lè mọ̀ pé o ti ṣe tán láti ṣe ìrìbọmi? Ọ̀nà kan ni pé kó o bi ara rẹ láwọn ìbéèrè wọ̀nyí: ‘Ṣé mo lè ṣàlàyé àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì fún àwọn èèyàn? Ǹjẹ́ mo máa ń lọ sí òde ẹ̀rí bí àwọn òbí mi kò bá tiẹ̀ lọ? Ṣé mo máa ń sapá láti lọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ? Ǹjẹ́ mo lè rántí ìgbà kan tí mo kọ ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe? Ṣé màá máa sin Jèhófà nìṣó kódà bí àwọn òbí mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi kò bá sin Jèhófà mọ́? Ǹjẹ́ mo ti gbàdúrà nípa àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run? Ṣé mo sì ti ya ara mi sí mímọ́ láìkù síbì kan fún Jèhófà nínú àdúrà?’

16 Ìrìbọmi jẹ́ ìgbésẹ̀ kan tó máa ń yí ìgbésí ayé ẹni pa dà, kò sì yẹ kéèyàn fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú un. Ṣé òtítọ́ ti jinlẹ̀ nínú rẹ débi tí wàá fi lè ronú jinlẹ̀ lórí ìgbésẹ̀ yìí? Jíjẹ́ ẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ kọjá pé kí èèyàn ṣe iṣẹ́ tó dáa lórí pèpéle tàbí kó máa dáhùn lọ́nà tó wúni lórí nípàdé. Ó gba pé kéèyàn lè ṣe ìpinnu tó dá lórí bó ṣe lóye àwọn ìlànà Bíbélì sí. (Ka Hébérù 5:14.) Tí o bá ti wà ní ipò tó o fi lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nígbèésí ayé rẹ, àǹfààní tó tóbi jù lọ ti ṣí sílẹ̀ fún ẹ nìyẹn, ìyẹn àǹfààní láti sin Jèhófà tọkàntọkàn, kó o sì máa gbé ìgbé ayé rẹ lọ́nà to fi hàn pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún un lóòótọ́.

17. Kí ló máa jẹ́ kó o lè borí àwọn àdánwò tó lè wáyé lẹ́yìn ìrìbọmi rẹ?

17 Kété lẹ́yìn tó o bá ṣe ìrìbọmi, o lè rí i pé ìtara rẹ láti sin Ọlọ́run túbọ̀ pọ̀ sí i. Àmọ́, ó lè máà pẹ́ tí wàá fi dojú kọ àwọn ohun tó máa dán ìgbàgbọ́ rẹ àti ìforítì rẹ wò. (2 Tím. 3:12) Má ronú pé o máa dá kojú àwọn àdánwò yìí. Gba ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ. Wá ìrànlọ́wọ́ àwọn tó dàgbà nípa tẹ̀mí nínú ìjọ. Máa bá àwọn tó máa tì ẹ́ lẹ́yìn ṣọ̀rẹ́. Má ṣe gbàgbé pé Jèhófà bìkítà nípa rẹ, yóò sì fún ẹ ní okun táá jẹ́ kó o lè kojú àwọn ìṣòro tó bá yọjú.—1 Pét. 5:6, 7.

Báwo Ni Ọwọ́ Rẹ Ṣe Lè Tẹ Àfojúsùn Rẹ?

18, 19. Báwo lo ṣe máa jàǹfààní tó o bá ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó o fi sí ipò àkọ́kọ́?

18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ní èrò tó dáa, ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o kò lè ní àyè tó pọ̀ tó láé láti ṣe ohun tó o fẹ́ àti ohun tó yẹ kó o ṣe? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o ní láti ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó o fi sípò àkọ́kọ́. Láti ṣàkàwé: Kó àwọn òkúta ńlá mélòó kan sínú ike kan. Kó o wá rọ iyẹ̀pẹ̀ sínú ike náà títí tó fi máa kún. Ó túmọ̀ sí pé òkúta àti iyẹ̀pẹ̀ ló wà nínú ike náà. Wá kó gbogbo nǹkan tó wà nínú ike náà kúrò. Kó o sì tún kó gbogbo rẹ̀ padà sínú ike náà, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, iyẹ̀pẹ̀ ni kó o kọ́kọ́ kó sí i, kó o tó kó àwọn òkúta náà sínú rẹ̀. Kò gbà á, àbí? Kò lè gbà á torí pé iyẹ̀pẹ̀ yẹn lo kọ́kọ́ kó sínú rẹ̀.

19 Irú ìṣòro tó o ní nìyí tó bá dọ̀rọ̀ lílo àkókò rẹ. Tó o bá fi àwọn nǹkan bí eré ìnàjú sípò àkọ́kọ́, ńṣe ló máa dà bíi pé o kò lè ní àyè nígbèésí ayé rẹ láti ṣe àwọn nǹkan ńlá, ìyẹn lílépa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Àmọ́ tó o bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì pé kó o máa “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” wàá rí i pé á ṣeé ṣe fún ẹ láti rí àyè fún àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti eré ìnàjú dé ìwọ̀n àyè kan.—Fílí. 1:10.

20. Tí o bá ń ṣe àníyàn àti iyè méjì láti sapá kọ́wọ́ rẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn rẹ, kí ló yẹ kó o ṣe?

20 Bó o ti ń sapá kọ́wọ́ rẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn rẹ, tó fi mọ́ ṣíṣe ìrìbọmi, nígbà míì o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àníyàn àti iyè méjì. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o “ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” (Sm. 55:22) Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, o láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ tó ń múni lórí yá jù lọ àti iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé. (Ìṣe 1:8) O lè yàn láti jẹ́ èrò ìwòran, kó o sì máa wo àwọn míì bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ náà. O sì lè wà lára àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ọ̀hún. Má ṣe fà sẹ́yìn nínú lílo àwọn ẹ̀bùn tó o ní láti mú kí àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú. O kò ní kábàámọ̀ láé pé o sin “Ẹlẹda rẹ nisisiyi li ọjọ ewe rẹ.”—Oníw. 12:1, Bibeli Mimọ.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ilé Ìṣọ́ August 1, 2009, ojú ìwé 15 sí 18.

b Tó o bá fẹ́ ìrànlọ́wọ́ síwájú sí i lórí ọ̀ràn yìí, wo ìwé náà Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń BéèrèÀwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́,Apá 2, orí 34.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí tó fi yẹ kó o ní àfojúsùn?

• Kí ni díẹ̀ lára àwọn àfojúsùn tó yẹ kéèyàn lé bá?

• Kí lo ní láti ṣe kọ́wọ́ rẹ tó lè tẹ àfojúsùn rẹ láti ṣe ìrìbọmi?

• Báwo ni ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó o fi sípò àkọ́kọ́ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn rẹ?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ǹjẹ́ o fi ṣe àfojúsùn rẹ láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àfojúsùn rẹ láti ṣe ìrìbọmi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú àpèjúwe yìí?