Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ẹ Jẹ́ Ká Gbé Àwọn Ọrẹ Ẹbọ Wá fún Jèhófà’

‘Ẹ Jẹ́ Ká Gbé Àwọn Ọrẹ Ẹbọ Wá fún Jèhófà’

‘Ẹ Jẹ́ Ká Gbé Àwọn Ọrẹ Ẹbọ Wá fún Jèhófà’

BÍ ẸNÌ kan bá ṣoore fún ẹ, kí lo máa ṣe láti fi hàn pé o moore? Ṣàgbéyẹ̀wò bí àwọn olórí ogun kan ní Ísírẹ́lì ṣe fi ìmoore hàn nígbà tí wọ́n bá àwọn ọmọ Mídíánì jagun. Ẹ̀yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀ nípa bíbọ òrìṣà Báálì ti Péórù ni wọ́n lọ jagun yìí. Ọlọ́run mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣẹ́gun, wọ́n sì pín ohun tí wọ́n kó bọ̀ látojú ogun láàárín àwọn ọmọ ogun tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlá [12,000] àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù. Bí Jèhófà ṣe fún wọn ní ìtọ́ni, àwọn ọmọ ogun náà fún àwọn àlùfáà lára ohun tó kàn wọ́n, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù náà sì fún àwọn ọmọ Léfì lára ohun tó kàn wọ́n.—Núm. 31:1-5, 25-30.

Àmọ́, àwọn olórí ogun náà fẹ́ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n sọ fún Mósè pé: “Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ti ka iye àwọn ọkùnrin ogun tí ó wà lábẹ́ àbójútó wa, kò sì sí ọ̀kan nínú wa tí a ròyìn pé ó sọnù.” Wọ́n wá pinnu láti mú wúrà àtàwọn ohun ọ̀ṣọ́ míì wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fún Jèhófà. Ohun ọ̀ṣọ́ wúrà náà wọ̀n tó àádọ́wàá [190] kìlógíráàmù, ìyẹn sì wúwo tó nǹkan bí àpò sìmẹ́ǹtì mẹ́rin.—Núm. 31:49-54.

Lóde òní, ẹ̀mí ìmoore ń mú kí ọ̀pọ̀ fi ìmọrírì hàn fún ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn. Àmọ́, kì í ṣe àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ti ya ara wọn sí mímọ́ nìkan ló ń fi irú ìmọrírì bẹ́ẹ̀ hàn. Gbé àpẹẹrẹ yìí yẹ̀ wò, ẹnì kan tó ń wa ọkọ̀ bọ́ọ̀sì gbé àwọn ará lọ sí àpéjọ àgbáyé tí wọ́n ṣe ní ìlú Bologna, lórílẹ̀-èdè Ítálì lọ́dún 2009. Torí pé ó fara balẹ̀ wakọ̀, tó sì ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, àwọn tó wọ ọkọ̀ rẹ̀ pinnu láti kọ̀wé ìdúpẹ́, wọ́n sì fi ẹ̀bùn owó àti ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? sínú lẹ́tà náà. Awakọ̀ náà wá sọ pé: “Mo mọrírì káàdì ìdúpẹ́ àti ìwé tẹ́ ẹ fún mi, àmọ́ mo dá owó yìí pa dà torí pé mo fẹ́ fi ṣètọrẹ kẹ́ ẹ lè lò ó láti máa fi ṣe iṣẹ́ yín. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó wù mí láti ṣe ìtọrẹ yìí torí mo rí i pé ìfẹ́ lẹ fi ń ṣe àwọn ohun tí ẹ̀ ń ṣe.”

Tí a bá mọrírì àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, ọ̀nà kan tá a lè gbà fi ìmoore hàn ni pé ká ṣe ìtọrẹ láti fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. (Mát. 24:14) Ọ̀nà tí àwọn kan gbà láti ṣe ìtọrẹ la tò sínú àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

ÀWỌN Ọ̀NÀ TÁWỌN KAN Ń GBÀ ṢÈTỌRẸ

ỌRẸ FÚN IṢẸ́ KÁRÍ AYÉ

Ọ̀pọ̀ máa ń ya iye kan sọ́tọ̀ tí wọ́n á máa fi sínú àpótí ọrẹ tá a kọ “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé” sí lára.

Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè wọn. O sì lè fi ọrẹ owó tó o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. (O tún lè fi ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn nísàlẹ̀ yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.) Tó o bá fẹ́ fi sọ̀wédowó ránṣẹ́ sí wa, “Watch Tower” ni kó o kọ sórí rẹ̀ pé kí wọ́n san án fún. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ tó ṣeyebíye tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ. Kí o sì kọ lẹ́tà ṣókí mọ́ ohun tó o fẹ́ fi ránṣẹ́ láti fi hàn pé ẹ̀bùn ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́.

ỌRẸ TÉÈYÀN WÉWÈÉ

Yàtọ̀ sí pé ká dìídì fowó ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà mìíràn tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ tó máa ṣàǹfààní fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Lára àwọn ọ̀nà náà rèé:

Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́.

Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó tá a ní sí báńkì, tàbí owó tá a fi pa mọ́ sí báńkì fún àkókò pàtó kan (fixed deposit), tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́, síkàáwọ́ Watch Tower láti máa lò ó tàbí ká ṣètò pé kí wọ́n san owó náà fún Watch Tower lẹ́yìn ikú ẹni níbàámu pẹ̀lú ìlànà báńkì náà.

Ìpín Ìdókòwò (Shares), Ẹ̀tọ́ Orí Owó Ìdókòwò (Debenture Stocks) àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó (Bonds): A lè fi ẹ̀tọ́ ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta Watch Tower lọ́rẹ. A sì lè ní kí ẹ̀tọ́ náà di ti Watch Tower lẹ́yìn ikú ẹni.

Ilẹ̀ àti Ilé: A lè fi ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ fún Watch Tower, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí tó bá jẹ́ ilẹ̀ tí ilé wà lórí rẹ̀ téèyàn ṣì ń gbé inú rẹ̀, olùtọrẹ náà lè fi tọrẹ àmọ́ kó sọ pé òun á ṣì máa gbé inú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tóun bá ṣì wà láàyè. Kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè rẹ kó o tó fi ìwé àṣẹ sọ ilẹ̀ tàbí ilé èyíkéyìí di èyí tó o fi ta wá lọ́rẹ.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Téèyàn Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká ṣe ìwé pé Watch Tower ni ẹni tí yóò ni ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́.

Àwọn ọrẹ tá a mẹ́nu bà wọ̀nyí lábẹ́ àkòrí tá a pè ní “ọrẹ téèyàn wéwèé” gba pé kí ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ náà fara balẹ̀ wéwèé wọn kó tó ṣe irú ìtọrẹ bẹ́ẹ̀.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, o lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tá a kọ sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o fi nọ́ńbà tẹlifóònù tó wà níbi àdírẹ́sì náà pè wá, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.

Jehovah’s Witnesses

P.M.B. 1090,

Benin City 300001,

Edo State, Nigeria.

Tẹlifóònù wa ni: 07080662020