Jèhófà Ni Olúwa Ọba Aláṣẹ Wa!
Jèhófà Ni Olúwa Ọba Aláṣẹ Wa!
“Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni mo fi ṣe ibi ìsádi mi.”—SM. 73:28.
1. Kí ni ó dájú pé Pọ́ọ̀lù ń dọ́gbọ́n tọ́ka sí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 7:31?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” (1 Kọ́r. 7:31) Ó ṣe kedere pé ńṣe ló ń fi ayé yìí wé eré orí ìtàgé níbi tí àwọn òṣèré tó ń kópa nínú eré ti ń ṣe apá tí wọ́n yàn fún wọn, yálà kí wọ́n ṣe èèyàn rere tàbí èèyàn burúkú, títí tí eré náà á fi parí.
2, 3. (a) Kí la lè fi pípè tí wọ́n pé ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run níjà wé? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
2 Lóde òní, eré orí ìtàgé tó ṣe pàtàkì jù lọ ń lọ lọ́wọ́, ó sì kàn ẹ́! Ní pàtàkì jù lọ, ó tan mọ́ ìdáláre ipò Jèhófà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. A lè fi ohun tí eré náà dá lé lórí ṣàpèjúwe ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ kan. Ní ìlú náà, olùṣàkóso kan wà tí wọ́n yàn lọ́nà tó bẹ́tọ̀ọ́ mu, tó sì ń ṣètò bí nǹkan á ṣe máa lọ dáadáa láàárín ìlú. Lọ́wọ́ kejì, àwọn jàǹdùkú kan wà ní ìlú náà, tí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣèjọba fi hàn pé wọ́n jẹ́ oníjìbìtì, oníwà ipá àti apànìyàn. Ìpèníjà ni àwọn tó ń ṣàkóso lọ́nà tí kò bófin mu yẹn máa jẹ́ fún ọba aláṣẹ tó wà lórí àlééfà, á sì tún mú kó ṣòro fún àwọn aráàlú láti jẹ́ adúróṣinṣin sí ìjọba.
3 Irú ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ láyé àti lọ́run. Ìjọba kan wà tó bá òfin mu, ìyẹn ni ìjọba “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” (Sm. 71:5) Àmọ́ àwọn jàǹdùkú kan wà tí wọn kò jẹ́ kí nǹkan rọgbọ fún ìran èèyàn, “ẹni burúkú náà” ló sì jẹ́ aṣáájú wọn. (1 Jòh. 5:19) Ó ń pe ìṣàkóso tó bẹ́tọ̀ọ́ mu èyí tó jẹ́ ti Ọlọ́run níjà, ó sì ń dán ìdúróṣinṣin gbogbo àwọn alátìlẹyìn ìjọba náà wò. Báwo lọ̀ràn náà ṣe wáyé? Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gbà á? Kí ni àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè ṣe nípa rẹ̀?
Àwọn Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Nínú Eré Orí Ìtàgé Náà
4. Àwọn ọ̀ràn méjì tó tan mọ́ra wo ló wé mọ́ eré orí ìtàgé tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí nípa ẹni tó jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run?
4 Eré orí ìtàgé tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí nípa ẹni tó jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀ràn méjì kan tó tan mọ́ra, àwọn ni: Ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run àti ìwà títọ́ àwọn èèyàn. Ìwé Mímọ́ sábà máa ń pe Jèhófà ní “Olúwa Ọba Aláṣẹ.” Bí àpẹẹrẹ, onísáàmù tó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run láìkù síbì kan kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni mo fi ṣe ibi ìsádi mi.” (Sm. 73:28) “Ọba Aláṣẹ” ni agbára rẹ̀ tóbi jù lọ nínú ìṣàkóso. Ọba aláṣẹ máa ń lo ọlá àṣẹ gíga jù lọ lórí àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀. A ní ìdí tó pọ̀ láti máa wo Jèhófà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ẹni Gíga Jù Lọ.—Dán. 7:22.
5. Kí nìdí tó fi yẹ ká fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run?
5 Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá, Jèhófà Ọlọ́run ni Ọba aláṣẹ láyé àti lọ́run. (Ka Ìṣípayá4:11.) Jèhófà náà tún ni Onídàájọ́, Ẹni Tó Ń Fúnni Lófin àti Ọba wa, torí pé òun nìkan ṣoṣo náà ni onídàájọ́, aṣòfin àti aláṣẹ nínú ìjọba ayé àtọ̀run. (Aísá. 33:22) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá wa, tó sì jẹ́ pé ojú rẹ̀ là ń wò fún ìrànlọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ gbà pé òun ni Olúwa Ọba Aláṣẹ wa. A ó máa fi hàn pé ipò rẹ̀ tó ga fíofío la fara mọ́ tá a bá ń fi sọ́kàn ní gbogbo ìgbà pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ti fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ọ̀run gan-an; àkóso rẹ̀ sì ń jọba lórí ohun gbogbo.”—Sm. 103:19; Ìṣe 4:24.
6. Kí ni ìwà títọ́?
6 Ká lè máa ti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run lẹ́yìn, á gbọ́dọ̀ pa ìwà títọ́ wa sí i mọ́. “Ìwà títọ́” gba pé kéèyàn máa hùwà rere láìkù síbì kan. Ẹni tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ ni ẹni tó jẹ́ aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán. Irú ẹni tí Jóòbù, ọ̀kan lára àwọn àgbààgbà ayé ìgbàanì, jẹ́ nìyẹn.—Jóòbù 1:1.
Bí Eré Orí Ìtàgé Náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀
7, 8. Báwo ni Sátánì ṣe pe ẹ̀tọ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run níjà?
7 Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún sẹ́yìn, ẹ̀dá ẹ̀mí kan pe ẹ̀tọ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run níjà. Ọ̀rọ̀ tí ọlọ̀tẹ̀ yìí sọ àti ìwà tó hù fi hàn pé, ohun tó mú kó ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ kí àwọn ẹ̀dá máa jọ́sìn òun. Ó sún àwọn ẹ̀dá èèyàn méjì àkọ́kọ́ Ádámù àti Éfà láti di aláìdúróṣinṣin sí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láyé àti lọ́run, ó sì gbìyànjú láti ba Jèhófà lórúkọ jẹ́ nípa sísọ pé irọ́ ni Ọlọ́run pa. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5.) Ọlọ̀tẹ̀ yìí wá di Elénìní ńlá náà Sátánì (Alátakò), Èṣù (Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́), ejò (atannijẹ) àti dírágónì (apanijẹ).—Ìṣí. 12:9.
8 Sátánì gbé ara rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọba alátakò. Kí wá ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ máa ṣe sí ìpèníjà yìí? Ṣé ńṣe ló máa pa Sátánì, Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ yìí run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? Ó dájú pé ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ì bá sì ti yanjú ọ̀ràn ẹni tó lágbára jù lọ. Á sì tún fi hàn pé òótọ́ ni Jèhófà sọ nípa ìyà tó sọ pé òun máa fi jẹ àwọn tó bá rú òfin òun. Kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi gbé irú ìgbésẹ̀ yẹn?
9. Kí ni Sátánì pè níjà?
9 Nígbà tí Sátánì parọ́ fún Ádámù àti Éfà, tó sì tàn wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ńṣe ló ń pe ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní pé kí aráyé máa ṣègbọràn sí òun níjà. Síwájú sí i, nígbà tí Sátánì tan àwọn èèyàn àkọ́kọ́ láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ohun tó ń sọ ni pé gbogbo àwọn ẹ̀dá tó ní làákàyè kò lè jẹ́ adúróṣinṣin. Bí ọ̀ràn ti Jóòbù tó jẹ́ adúróṣinṣin sí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ṣe fi hàn, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé òun lè yí gbogbo èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run.—Jóòbù 2:1-5.
10. Kí ni Ọlọ́run fàyè gbà bí kò ṣe tètè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni ọba aláṣẹ láyé àti lọ́run?
10 Bí Jèhófà kò ṣe tètè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni ọba aláṣẹ láyé àti lọ́run, ńṣe ló fún Sátánì ní àkókò láti fi hàn pé òun lè ṣe ohun tí òun sọ. Ọlọ́run sì tún fún àwọn èèyàn ní àǹfààní láti fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin sí òun gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Kí ló ti wá ṣẹlẹ̀ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́? Sátánì ti dá ìjọba jàǹdùkú kan tó lágbára sílẹ̀. Jèhófà yóò pa ìjọba náà àti Èṣù run, á sì fi ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro hàn pé ẹ̀tọ́ òun ni láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ohun tó máa gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà dá Jèhófà Ọlọ́run lójú débi pé ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ìṣọ̀tẹ̀ náà wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì.—Jẹ́n. 3:15.
11. Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti ṣe nípa ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run?
11 Ọ̀pọ̀ èèyàn ti lo ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, wọ́n sì tún ń fi hàn pé ìsọdimímọ́ orúkọ rẹ̀ jẹ àwọn lógún. Lára wọn ni Ébẹ́lì, Énọ́kù, Nóà, Ábúráhámù, Sárà, Mósè, Rúùtù, Dáfídì, Jésù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ọ̀rúndún kìíní àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùpàwàtítọ́mọ́ lóde òní. Àwọn tó fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run yìí ti fi Sátánì hàn ní òpùrọ́, wọ́n sì ti mú ẹ̀gàn tí Èṣù ti kó bá orúkọ Jèhófà kúrò, ìyẹn bó ṣe fọ́nnu pé òun máa yí gbogbo ìran èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run.—Òwe 27:11.
A Mọ Ibi Tọ́rọ̀ Náà Máa Já Sí
12. Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé Ọlọ́run kò ní máa fàyè gba ìwà ibi títí gbére?
12 Ó yẹ kó dá wa lójú pé láìpẹ́, Jèhófà máa lo agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run torí pé kò ní máa fàyè gba ìwà ibi títí gbére, a sì mọ̀ pé ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé yìí. Jèhófà pa àwọn ẹni ibi run nígbà Ìkún-omi. Ó pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run, ó sì tún pa Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ náà run. Sísérà àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀, Senakéríbù àtàwọn ẹgbẹ́ ogun Ásíríà tó kó sòdí kò rọ́wọ́ mú níwájú Ẹni Gíga Jù Lọ. (Jẹ́n. 7:1, 23; 19:24, 25; Ẹ́kís. 14:30, 31; Oníd. 4:15, 16; 2 Ọba 19:35, 36) Torí náà, ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run kò kàn ní máa wo àwọn tó ń hùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ níṣekúṣe níran títí láé. Síwájú sí i, a ti ń rí ẹ̀rí àmì wíwàníhìn-ín Jésù àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan búburú yìí.—Mát. 24:3.
13. Kí la lè ṣe tí a kò fi ní pa run pẹ̀lú àwọn ọ̀tá Jèhófà?
13 Kí Ọlọ́run má bàa pa wá run pẹ̀lú àwọn ọ̀tá rẹ̀, a gbọ́dọ̀ fi hàn pé ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run la fara mọ́. Báwo la ṣe máa ṣe é? Nípa yíya ara wa sọ́tọ̀ kúrò lára ìṣàkóso Sátánì tí kò bófin mu, ká má sì jẹ́ kí àwọn aṣojú rẹ̀ dẹ́rù bà wá. (Aísá. 52:11; Jòh. 17:16; Ìṣe 5:29) Ìgbà tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan la lè fi hàn pé a fara mọ́ ipò Baba wa ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, ká sì ní ìrètí pé Jèhófà máa dá wa sí nígbà tó bá fẹ́ mú ẹ̀gàn tí wọ́n ti kó bá orúkọ rẹ̀ kúrò, kó sì fi hàn pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run.
14. Kí ni àwọn ẹsẹ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀?
14 Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa ìran èèyàn àti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run wà nínú Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Orí mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ fún wa nípa ìṣẹ̀dá àti bí àwa èèyàn ṣe ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí orí mẹ́tà tó gbẹ̀yìn sọ̀rọ̀ nípa bí ìràn èèyàn ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Àwọn ojú ìwé tó wà láàárín fúnni ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa àwọn ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti ṣe láti mú ètè rẹ̀ fún ìràn èèyàn, ilẹ̀ ayé àti ọ̀run ṣẹ. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa bí Sátánì àti ìwà ibi ṣe dénú ayé, apá tó gbẹ̀yìn ìwé Ìṣípayá sì sọ bí ìwà ibi ṣe máa kúrò láyé, bí a ó ṣe pa Èṣù run àti bí ìfẹ́ Ọlọ́run yóò ṣe di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé bí wọ́n ti ń ṣe é ní ọ̀run. Kódà Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó fa ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, ó sì jẹ́ ká mọ bí wọ́n ṣe máa kásẹ̀ nílẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀ ayé, tí ayọ̀ tí kò lópin àti ìyè ayérayé á sì jẹ́ ti àwọn tó pa ìwà títọ́ wọn mọ́.
15. Ká bàa lè jàǹfààní nígbà tí eré orí ìtàgé nípa ọ̀ràn ẹni tó jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run bá wá sópin, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
15 Láìpẹ́ ìrísí ìràn ayé yìí yóò yí pa dà pátápátá, eré orí ìtàgé nípa ẹni tó jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run tó ti ń bá a bọ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún yóò sì parí. A óò mú Sátánì kúrò lórí ìtàgé, á sì di ẹni ìgbàgbé títí láé, ìfẹ́ Ọlọ́run yóò sì wá gbilẹ̀ dájúdájú. Àmọ́ ká tó lè jàǹfààní látinú èyí, ká sì gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, a gbọ́dọ̀ fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run nísinsìnyí. A kò lè jẹ́ kò-ṣeku-kò-ṣẹyẹ lórí ọ̀ràn yìí. Ká tó lè sọ pé: “Jèhófà ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ mi,” àwa náà gbọ́dọ̀ wà ní ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà.—Sm. 118:6, 7.
A Lè Pa Ìwà Títọ́ Wa Mọ́!
16. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé ó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti pa ìwà títọ́ wọn sí Ọlọ́run mọ́?
16 A lè fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run ká sì pa ìwà títọ́ wa mọ́, torí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò sí ìdẹwò kankan tí ó ti bá yín bí kò ṣe ohun tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.” (1 Kọ́r. 10:13) Ibo ni ìdẹwò tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn ti máa wá, báwo sì ni Ọlọ́run ṣe máa ṣe ọ̀nà àbáyọ?
17-19. (a) Àwọn ìdẹwò wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà láyè ní aginjù? (b) Báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe fún wa láti máa pa ìwà títọ́ wa sí Jèhófà mọ́?
17 Bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù ṣe fi hàn, “ìdẹwò” lè wá látinú àwọn ipò kan tó lè tì wá sínú rírú òfin Ọlọ́run. (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:6-10.) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ì bá ti dènà ìdẹwò náà, àmọ́ wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí “àwọn ohun tí ń ṣeni léṣe” nígbà tí Jèhófà pèsè àparò tí wọ́n máa jẹ fún oṣù kan fún wọn lọ́nà ìyanu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn náà kò rí ẹran jẹ fún àwọn àkókò kan, Ọlọ́run sì ti pèsè mánà tó pọ̀ tó fún wọn láti jẹ. Síbẹ̀ wọ́n fàyè gba ìdẹwò jíjẹ́ olójúkòkòrò nígbà tí wọ́n ń ko àparò tí wọ́n máa jẹ.—Núm. 11:19, 20, 31-35.
18 Ṣáájú àkókò yìí nígbà tí Mósè lọ gba Òfin lórí Òkè Sínáì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di abọ̀rìṣà, wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn ère ọmọ màlúù oníwúrà àti ìbálòpọ̀ tí kò tọ́. Níwọ̀n bí kò ti sí aṣáájú wọn tí wọ́n lè fojú rí nílé, kò sẹ́ni tó máa yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò. (Ẹ́kís. 32:1, 6) Gẹ́rẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àwọn ọmọbìnrin Móábù sún ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára wọn dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì bá àwọn ọmọbìnrin náà ṣèṣekúṣe. Ní àkókò yẹn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ náà. (Núm. 25:1, 9) Ní àwọn ìgbà míì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fàyè gba ìdẹwò nípa jíjẹ́ kí ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀ mú kí wọ́n ráhùn, ní àkókò kan wọ́n sọ̀rọ̀ lòdì sí Mósè àti sí Ọlọ́run fúnra rẹ̀! (Núm. 21:5) Kódà àwọn èèyàn Ísírẹ́lì kùn lẹ́yìn ìparun Kórà, Dátánì, Ábírámù àtàwọn ìsọ̀ǹgbè wọn, wọ́n gbà pé kò tọ́ bí àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ṣe kú. Látàrí èyí, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [14,700] ni òjòjò àrànkálẹ̀ tí Ọlọ́run mú kó kọlù wọ́n pa.—Núm. 16:41, 49.
19 Kò sí èyíkéyìí lára àwọn ìdẹwò tá a mẹ́nu kàn lókè yìí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè borí. Àwọn èèyàn náà juwọ́ sílẹ̀ fún ìdẹwò torí pé wọ́n ti sọ ìgbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà nù, wọ́n sì ti gbàgbé bó ṣe ń fìfẹ́ bójú tó wọn àti bí àwọn ọ̀nà rẹ̀ ṣe tọ́. Bíi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìdẹwò tí à ń dójú kọ jẹ́ irú èyí tí ó ń dojú kọ ìran èèyàn lápapọ̀. Tá a bá sa gbogbo ipá wa láti dènà wọn, tá a sì gbára lé Ọlọ́run pé kó gbé wa ró, a lè máa jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́ nìṣó. Èyí lè dá wa lójú torí pé “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́,” kò sì ní jẹ́ “kí a dẹ [wa] wò ré kọjá ohun tí [a] lè mú mọ́ra.” Jèhófà kò ní pa wa tì débi tó fi máa gbà ká wà nínú ipò tí kò ti ní ṣeé ṣe fún wa láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Sm. 94:14.
20, 21. Tá a bá rí ìdẹwò, báwo ni Ọlọ́run ṣe ń ṣe “ọ̀nà àbáyọ”?
20 Jèhófà ń ṣe “ọ̀nà àbáyọ” nípa fífún wa lókun láti dènà ìdẹwò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alátakò lè fìyà jẹ wá ká bàa lè sẹ́ ìgbàgbọ́ wa. Irú ìfìyàjẹni bẹ́ẹ̀ lè mú ká juwọ́ sílẹ̀, ká lè bọ́ lọ́wọ́ lílù, ìdálóró tàbí ikú pàápàá. Àmọ́ látàrí ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ èyí tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 10:13, a mọ̀ pé àwọn ipò tó ń fa ìdẹwò kò ní pẹ́ dópin. Jèhófà kò ní fàyè gbà á débi tí a kò fi ní lè jẹ́ olóòótọ́ sí i mọ́. Ọlọ́run lè mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, kó sì fún wa lókun tá a nílò nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́ ká lè pa ìwà títọ́ wa mọ́.
21 Jèhófà ń mẹ́sẹ̀ wa dúró nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí yìí máa ń jẹ́ ká rántí àwọn ohun kan látinú Ìwé Mímọ́, èyí tá a nílò láti dènà ìdẹwò. (Jòh. 14:26) Torí náà, kì í ṣe pé wọ́n tàn wá jẹ láti máa tọ ipa ọ̀nà tí kò tọ́. Bí àpẹẹrẹ, a lóye àwọn ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run àti ìwà títọ́ àwa èèyàn. Ìmọ̀ yìí ti jẹ́ kí Ọlọ́run mẹ́sẹ̀ àwọn kan dúró títí dójú ikú. Àmọ́, kì í ṣe ikú ní ó ṣe ọ̀nà àbáyọ fún wọn; ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ló mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti fara dà á láìjuwọ́ sílẹ̀ fún ìdẹwò. Ó lè ṣe ohun kan náà fún wa. Kódà, ó tún máa ń lo àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ olóòótọ́ nítorí wa gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ gbogbo èèyàn “tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà.” (Héb. 1:14) Bí àpilẹ̀kọ tó kàn ṣe fi hàn, kìkì àwọn tó bá pa ìwà títọ́ mọ́ ló máa ní àǹfààní ayọ̀ tó ń wá látinú fífara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run títí láé. Àwa náà lè wà lára wọn tá a bá rọ̀ mọ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọba Aláṣẹ wa.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ gbà pé Jèhófà ni Olúwa Ọba Aláṣẹ wa?
• Kí ló túmọ̀ sí láti pa ìwà títọ́ wa sí Ọlọ́run mọ́?
• Báwo la ṣe mọ̀ pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Jèhófà fi máa fi ìdí ọ̀ràn ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run múlẹ̀?
• Gẹ́gẹ́ bí ìwé 1 Kọ́ríńtì 10:13 ṣe sọ, kí nìdí tó fi ṣeé ṣe láti pa ìwà títọ́ mọ́?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Sátánì sún Ádámù àti Éfà láti di aláìdúróṣinṣin sí Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Pinnu láti fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run