Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Nínú Jẹ́nẹ́sísì 6:3, a kà pé: “Ẹ̀mí mi kò ní fi àkókò tí ó lọ kánrin gbé ìgbésẹ̀ sí ènìyàn nítorí pé ó jẹ́ ẹlẹ́ran ara pẹ̀lú. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọgọ́fà ọdún.” Ṣé Jèhófà dín báwọn èèyàn á ṣe máa pẹ́ tó láyé kù sí ọgọ́fà [120] ọdún ni, àti pé, ṣé Nóà wàásù nípa Ìkún Omi tó ń bọ̀ fún àkókò tó gùn tóyẹn?

Rárá, ni ìdáhùn sí ìbéèrè méjèèjì yẹn.

Ṣáájú Ìkún Omi, ọ̀pọ̀ èèyàn lo ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún láyé. Ẹni ẹgbẹ̀ta [600] ọdún ni Nóà nígbà tí Ìkún Omi bẹ̀rẹ̀, ó sì lo àádọ́ta-dín-lẹ́gbẹ̀rún [950] ọdún láyé. (Jẹ́n. 7:6; 9:29) Àwọn kan tí wọ́n bí lẹ́yìn Ìkún Omi náà lò ju ọgọ́fà ọdún lọ láyé, bí àpẹẹrẹ, Ápákíṣádì kú lẹ́ni irínwó ọdún ó lé méjìdínlógójì [438], Ṣélà ọmọ rẹ̀ sì kú lẹ́ni irínwó ọdún ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [433]. (Jẹ́n. 11:10-15) Síbẹ̀, nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Mósè, àwọn èèyàn kì í sábà lò ju àádọ́rin [70] sí ọgọ́rin [80] ọdún láyé. (Sm. 90:10) Fún ìdí yìí, ìwé Jẹ́nẹ́sísì 6:3 kò dá gbèdéke lé e pé ọgọ́fà ọdún lèèyàn á máa lò láyé.

Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn ń sọ ni pé Ọlọ́run sọ fún Nóà pé ọgọ́fà ọdún ló máa fi kìlọ̀ fún àwọn èèyàn nípa ìparun tó ń bọ̀? Rárá o. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run bá Nóà sọ̀rọ̀. Ní ẹsẹ kẹtàlá orí kẹfà ìwé Jẹ́nẹ́sísì, a kà pé: “Ọlọ́run wí fún Nóà pé: ‘Òpin gbogbo ẹlẹ́ran ara ti dé iwájú mi, nítorí tí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nítorí wọn.’” Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, Nóà parí iṣẹ́ bàǹtà-banta tí Ọlọ́run gbé fún un pé kó kan ọkọ̀ áàkì, ní àkókò yẹn “Jèhófà sọ fún Nóà pé: ‘Lọ, ìwọ àti gbogbo agbo ilé rẹ, sínú áàkì náà.’” (Jẹ́n. 6:13; 7:1) Àwọn ìgbà míì sì wà tí Jèhófà sọ àwọn ọ̀rọ̀ pàtó kan fún Nóà.—Jẹ́n. 8:15; 9:1, 8, 17.

Àmọ́, ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 6:3 yàtọ̀ sí èyí; kò mẹ́nu ba Nóà, kò sì sọ pé òun ni Ọlọ́run ń bá sọ̀rọ̀. Ó kàn lè jẹ́ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe tàbí ìpinnu rẹ̀ ló ń sọ. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 8:21.) Ó gbàfiyèsí pé, nínú àkọsílẹ̀ tó wà nípa ohun tí Ọlọ́run sọ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kó tó dá Ádámù, a rí àwọn gbólóhùn bíi: “Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé.” (Jẹ́n. 1:6, 9, 14, 20, 24) Ó ṣe kedere pé kì í ṣe èèyàn èyíkéyìí lórí ilẹ̀ ayé ni Jèhófà ń bá sọ̀rọ̀, torí pé kò tíì dá èèyàn kankan sáyé nígbà yẹn.

Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti parí èrò sí pé ìpinnu Ọlọ́run láti fòpin sí ìwà ìbàjẹ́ tó wà lórí ilẹ̀ ayé ni ìwé Jẹ́nẹ́sísì 6:3 ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Jèhófà kéde ìdájọ́ pé òun máa ṣe bẹ́ẹ̀ láàárín ọgọ́fà ọdún, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Nóà kò mọ̀ nípa rẹ̀. Àmọ́ kí nìdí tí Ọlọ́run fi pinnu àkókò kan pàtó? Kí nìdí tó fi ní láti dúró?

Àpọ́sítélì Pétérù jẹ́ ká mọ ìdí abájọ, ó ní: “Sùúrù Ọlọ́run ń dúró ní àwọn ọjọ́ Nóà, nígbà tí a ń kan ọkọ̀ áàkì lọ́wọ́, nínú èyí tí a gbé àwọn ènìyàn díẹ̀ la omi já láìséwu, èyíinì ni, ọkàn mẹ́jọ.” (1 Pét. 3:20) Ó dájú pé nígbà tí Ọlọ́run sọ ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe ní ọgọ́fà ọdún sígbà yẹn, ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì kù tó fẹ́ láti ṣe. Nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn náà ni Nóà àti ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. (Jẹ́n. 5:32; 7:6) Àwọn ọmọkùnrin wọn mẹ́ta náà dàgbà, wọ́n sì fẹ́yàwó, ìdílé náà sì tipa bẹ́ẹ̀ di “ọkàn mẹ́jọ.” Lẹ́yìn náà ni wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í kan ọkọ̀ áàkì, èyí sì jẹ́ iṣẹ́ tó máa gba ọ̀pọ̀ àkókò tá a bá wo ti bí ọkọ̀ náà ṣe tóbi tó àti iye èèyàn tó wà nínú ìdílé Nóà. Bẹ́ẹ̀ ni, bí Ọlọ́run ṣe mú sùúrù fún ọgọ́fà ọdún jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ṣeé ṣe, ó sì lànà sílẹ̀ fún gbígba ẹ̀mí àwọn olóòótọ́ èèyàn mẹ́jọ là, nípa ‘gbígbé wọn la omi já láìséwu.’

Bíbélì kò sọ ọdún náà gan-an tí Jèhófà sọ fún Nóà pé Ìkún Omi máa wáyé. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ó ti bí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, tí wọ́n ti dàgbà, tí wọ́n sì ti gbéyàwó, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nǹkan bí ogójì [40] sí àádọ́ta [50] ọdún ló kù kí Ìkún Omi náà wáyé. Jèhófà wá sọ fún Nóà pé: “Òpin gbogbo ẹlẹ́ran ara ti dé iwájú mi.” Ó sì fi kún un pé, kí Nóà kan ọkọ̀ áàkì ńlá kan, kí òun àti ìdílé rẹ̀ sì wọnú rẹ̀. (Jẹ́n. 6:13-18) Láàárín àwọn ọdún tó kù kí Ìkún Omi náà wáyé, Nóà jẹ́ olódodo nínú ọ̀nà tó gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò mọ síbẹ̀, ó tún jẹ́ “oníwàásù òdodo,” tó ní iṣẹ́ ìkìlọ̀ tó ṣe kedere láti jẹ́, ìyẹn ni pé Ọlọ́run ti pinnu láti pa àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nígbà yẹn run. Kì í ṣe pé Nóà ti mọ àkókò tí ìyẹn máa jẹ́ látìgbà pípẹ́, ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé ó máa dé dandan ni. Ìwọ náà sì mọ̀ pé ó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́.—2 Pét. 2:5.