“Ìsinsìnyí Gan-an Ni Àkókò Ìtẹ́wọ́gbà”
“Ìsinsìnyí Gan-an Ni Àkókò Ìtẹ́wọ́gbà”
“Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.” —2 KỌ́R. 6:2.
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká fòye mọ ohun tó yẹ ká ṣe ní àkókò èyíkéyìí?
“OHUN gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, àní ìgbà fún gbogbo àlámọ̀rí lábẹ́ ọ̀run.” (Oníw. 3:1) Ohun tí Sólómọ́nì ń kọ̀wé nípa rẹ̀ ni bó ti ṣe pàtàkì tó láti fòye mọ àkókò tó dára jù lọ láti ṣe ohun pàtàkì èyíkéyìí tá a bá dáwọ́ lé, irú bí oko dídá, ìrìn-àjò, okòwò tàbí bíbá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀. Bákan náà, a tún gbọ́dọ̀ fòye mọ iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a gbọ́dọ̀ ṣe ní àkókò èyíkéyìí. Lédè mìíràn, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn ohun tó yẹ ká fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa.
2. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù mọ ìjẹ́pàtàkì àkókò tó fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù?
2 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó mọ ìjẹ́pàtàkì àkókò tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì tún mọ ohun tó yẹ kí òun ṣe. Torí pé Jésù mọ ohun tó yẹ kó fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ̀, ó mọ̀ pé àkókò tí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tá a ti ń fojú sọ́nà fún tipẹ́ máa nímùúṣẹ ti sún mọ́lé. (1 Pét. 1:11; Ìṣí. 19:10) Iṣẹ́ wà fún un láti ṣe kó bàa lè fi hàn gbangba fún àwọn èèyàn pé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Ó ní láti jẹ́rìí kúnnákúnná nípa òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run, kó sì ṣe àkójọ àwọn tó máa jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba Ọlọ́run. Bákan náà, ó ní láti ṣe ìdásílẹ̀ ìjọ Kristẹni tí yóò máa bá iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lọ títí dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé.—Máàkù 1:15.
3. Báwo ni bí Jésù ṣe mọ ìjẹ́pàtàkì àkókò tó fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù ṣe nípa lórí àwọn ohun tó ṣe?
3 Bí Jésù ṣe mọ ìjẹ́pàtàkì àkókò tó fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù yẹn ní ipa rere lórí ìgbésí ayé rẹ̀, ó sì sún un láti fi ìtara ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ìkórè pọ̀, ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ kéré níye. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Lúùkù 10:2; Mál. 4:5, 6) Jésù kọ́kọ́ yan àwọn méjìlá lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn náà ló wá yan àwọn àádọ́rin, ó fún wọn ní àwọn ìtọ́ni pàtó, ó sì rán wọn jáde pé kí wọ́n lọ máa wàásù ìhìn rere tó ń múni lára yá gágá náà pé: “Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” A kà nípa Jésù fúnra rẹ̀ pé: “Nígbà tí [ó] parí fífún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá ní àwọn ìtọ́ni, ó mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n láti ibẹ̀ láti kọ́ni àti láti wàásù nínú àwọn ìlú ńlá wọn.”—Mát. 10:5-7; 11:1; Lúùkù 10:1.
4. Ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà jẹ́ aláfarawé Jésù Kristi?
4 Tó bá dọ̀rọ̀ ìtara àti ìfọkànsìn, àpẹẹrẹ pípé ni Jésù jẹ́ fún gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí nìyẹn nígbà tó rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.” (1 Kọ́r. 11:1) Àwọn ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà jẹ́ aláfarawé Kristi? Ó jẹ́ nípa ṣíṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere. Nínú àwọn lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ìjọ, ó lo àwọn gbólóhùn bí “ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó yín,” “sìnrú fún Jèhófà,” “ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa,” àti “ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà.” (Róòmù 12:11; 1 Kọ́r. 15:58; Kól. 3:23) Pọ́ọ̀lù kò gbàgbé ìjíròrò tó wáyé láàárín òun àti Jésù Kristi Olúwa nígbà tó ń lọ sí Damásíkù àti ọ̀rọ̀ Jésù tó ṣeé ṣe kí ọmọ ẹ̀yìn náà Ananíà ti sọ fún un, pé: “Ohun èlò tí a ti yàn ni ọkùnrin yìí jẹ́ fún mi láti gbé orúkọ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”—Ìṣe 9:15; Róòmù 1:1, 5; Gál. 1:16.
“Àkókò Ìtẹ́wọ́gbà”
5. Kí ló sún Pọ́ọ̀lù láti fi ìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
5 Tá a bá ka ìwé Ìṣe, kò sí iyè méjì pé a ó rí bí Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìgboyà àti ìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Ìṣe 13:9, 10; 17:16, 17; 18:5) Pọ́ọ̀lù mọ ìjẹ́pàtàkì àkókò nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.” (2 Kọ́r. 6:2) Ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni jẹ́ àkókò ìtẹ́wọ́gbà fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì láti pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. (Aísá. 49:8, 9) Àmọ́ àkókò ìtẹ́wọ́gbà wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ṣáájú àti lẹ́yìn ẹsẹ náà jẹ́ ká mọ ohun tó ní lọ́kàn.
6, 7. Àǹfààní ńláǹlà wo ni Ọlọ́run fi jíǹkí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lóde òní, àwọn wo ló sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró?
6 Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní ńláǹlà tí Ọlọ́run fi jíǹkí òun àti àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró ní ìbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà rẹ̀. (Ka 2 Kọ́ríńtì 5:18-20.) Ó ṣàlàyé pé Ọlọ́run pe àwọn fún ìdí pàtàkì kan, ìyẹn ni láti ṣe “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́,” láti bẹ àwọn èèyàn pé kí wọ́n “padà bá Ọlọ́run rẹ́.” Ìyẹn túmọ̀ sí mímú kí àwọn èèyàn pa dà di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tàbí kí wọ́n mú wọn wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run.
7 Látìgbà ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì ni gbogbo aráyé ti di àjèjì sí Jèhófà. (Róòmù 3:10, 23) Bí ìran èèyàn lápapọ̀ ṣe di àjèjì sí Jèhófà yìí ti mú kí wọ́n wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí, èyí sì ti yọrí sí ìjìyà àti ikú. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwa mọ̀ pé gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” (Róòmù 8:22) Àmọ́ Ọlọ́run ti gbé ìgbésẹ̀ láti pàrọwà, kódà ńṣe ló ń “bẹ̀bẹ̀” pé kí àwọn èèyàn pa dà wá, tàbí kí wọ́n pa dà bá òun rẹ́. Ìyẹn ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Ọlọ́run fi sí ìkáwọ́ Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró nígbà yẹn. “Àkókò ìtẹ́wọ́gbà” náà lè jẹ́ “ọjọ́ ìgbàlà” fún àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù. Gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ìyẹn àwọn “àgùntàn mìíràn” tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn, ń bá a nìṣó láti máa ké sí àwọn èèyàn kí wọ́n lè jàǹfààní látinú “àkókò ìtẹ́wọ́gbà” náà.—Jòh. 10:16.
8. Kí ló mú kí ìkésíni láti pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ ṣàrà ọ̀tọ̀?
8 Ohun tó mú kí ìkésíni láti pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ túbọ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀ ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn fúnra wọn ló jẹ̀bi ìrélànàkọjá náà, èyí tí ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì fà, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ láti ṣàtúnṣe ọ̀ràn náà. (1 Jòh. 4:10, 19) Kí ni Ọlọ́run ṣe? Pọ́ọ̀lù dáhùn pé: “Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi ń mú ayé kan padà bá ara rẹ̀ rẹ́, láìṣírò àwọn àṣemáṣe wọn sí wọn lọ́rùn, ó sì fi ọ̀rọ̀ ìpadàrẹ́ náà lé wa lọ́wọ́.”—2 Kọ́r. 5:19; Aísá. 55:6.
9. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe láti fi hàn pé òun mọrírì àánú Ọlọ́run?
9 Bí Jèhófà ṣe pèsè ẹbọ ìràpadà náà mú kó ṣeé ṣe fún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ láti rí ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wọn, kí wọ́n sì pa dà di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tàbí kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀. Síwájú sí i, ó rán àwọn aṣojú rẹ̀ láti rọ àwọn èèyàn níbi gbogbo pé kí wọ́n bá Ọlọ́run làjà kó tó di pé ó pẹ́ jù fún wọn. (Ka 1 Tímótì 2:3-6.) Níwọ̀n bí Pọ́ọ̀lù ti mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìjẹ́pàtàkì àkókò nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, èyí mú kó lo ara rẹ̀ tokuntokun láìkáàárẹ̀ lẹ́nu “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́.” Ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà kò tíì yí pa dà. Ó ṣì fẹ́ kí àwọn èèyàn pa dà bá òun rẹ́. Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé, “ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà” àti pé “ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà” ṣì kàn wá. Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run aláàánú àti oníyọ̀ọ́nú ni Jèhófà!—Ẹ́kís. 34:6, 7.
Ẹ Má Ṣe “Tàsé Ète Rẹ̀”
10. Kí ni “ọjọ́ ìgbàlà” túmọ̀ sí fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró látijọ́ àti lóde òní?
10 Àwọn tó wà “ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi” ló kọ́kọ́ jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 5:17, 18) “Ọjọ́ ìgbàlà” wọn sì bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Láti ìgbà yẹn lọ ni Ọlọ́run ti gbé iṣẹ́ pípolongo “ọ̀rọ̀ ìpadàrẹ́ náà” lé wọn lọ́wọ́. Lóde òní, àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣì ń bá “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́” náà nìṣó. Wọ́n mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nínú ìran kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ṣì ń “di ẹ̀fúùfù mẹ́rin ilẹ̀ ayé mú pinpin, kí ẹ̀fúùfù kankan má bàa fẹ́ sórí ilẹ̀ ayé.” Torí náà, “ọjọ́ ìgbàlà” àti “àkókò ìtẹ́wọ́gbà” la ṣì wà yìí. (Ìṣí. 7:1-3) Fún ìdí yìí, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún ni àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró ti ń fi ìtara ṣe “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́,” wọ́n sì ti ṣe é dé apá ibi tó jìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.
11, 12. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, báwo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe fi hàn pé àwọn mọ ìjẹ́pàtàkì àkókò tí àwọn ní láti fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù? (Wo àwòrán tó wà lójú ìwé 15.)
11 Bí àpẹẹrẹ, bá a ṣe fi hàn nínú ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, nígbà tí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ń parí lọ, “Arákùnrin C. T. Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ gbà gbọ́ dájú pé àkókò ìkórè làwọn wà àti pé àwọn èèyàn ní láti gbọ́rọ̀ òtítọ́ tó ń sọni di òmìnira.” Kí ni wọ́n wá ṣe nípa rẹ̀? Níwọ̀n bí àwọn arákùnrin yìí ti mọ̀ pé àkókò ìkórè tó jẹ́ “àkókò ìtẹ́wọ́gbà” làwọn wà, wọn ò wulẹ̀ máa pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá ṣe ìsìn. Ohun tí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ti ń ṣe látọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yìí bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ míì tí wọ́n lè gbà máa tan ìhìn rere náà kálẹ̀. Lára àwọn ohun tí wọ́n sì ṣe ni pé wọ́n lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé láti mú ìtẹ̀síwájú bá iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.
12 Kí àwùjọ kékeré ti àwọn òjíṣẹ́ onítara yìí lè máa tan ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kálẹ̀, wọ́n lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé ìléwọ́, ìwé ìròyìn àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n tún ṣètò ìwàásù àtàwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ń tẹ̀ jáde nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé ìròyìn. Wọ́n tún lo ilé iṣẹ́ rédíò láti fi gbé àwọn ètò tó dá lórí Ìwé Mímọ́ sáfẹ́fẹ́ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan àti kárí ayé. Kó tiẹ̀ tó di pé ilé iṣẹ́ sinimá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn fíìmù tó ń gbé ohùn àti àwòrán jáde ni wọ́n ti ń ṣe àwòrán ara ògiri àti sinimá tó ń gbé ohùn àtàwòrán jáde tí wọ́n sì ń lò ó láti fi wàásù fáwọn èèyàn. Kí ni fífi ìtara ṣe iṣẹ́ náà láìkáàárẹ̀ yìí yọrí sí? Lóde òní, nǹkan bíi mílíọ̀nù méje èèyàn ti tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà pé: “Ẹ padà bá Ọlọ́run rẹ́,” àwọn náà sì ń ké sí àwọn ẹlòmíì láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ká sòótọ́, ìtara táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yẹn ní jẹ́ àpẹẹrẹ rere, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kéré níye tí wọ́n kò sì fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí.
13. Kí ni ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe tó yẹ ká fi sọ́kàn?
13 Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà” ṣì jẹ́ òótọ́. Àwa tá a ti jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà ń ṣọpẹ́ pé Ọlọ́run ti fún wa láǹfààní láti gbọ́ ìhìn iṣẹ́ ìpadàrẹ́ náà ká sì tẹ́wọ́ gbà á. Dípò tí a ó fi máa ronú pé èyí tá a ṣe ti tó, à ń fi ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí sọ́kàn pé: “Àwa ń pàrọwà fún yín pẹ̀lú pé kí ẹ má ṣe tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí ẹ sì tàsé ète rẹ̀.” (2 Kọ́r. 6:1) Ohun tí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wà fún ni pé kó lè “mú ayé kan padà bá ara rẹ̀ rẹ́” nípasẹ̀ Kristi.—2 Kọ́r. 5:19.
14. Àǹfààní wo ló ṣí sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀?
14 Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí Sátánì ti fọ́ lójú ṣì jẹ́ àjèjì sí Ọlọ́run, wọn kò sì mọ ohun tí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wà fún. (2 Kọ́r. 4:3, 4; 1 Jòh. 5:19) Àmọ́, ipò ayé tó ń burú sí i ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ tẹ́wọ́ gba ìhìn rere nígbà tí wọ́n fi hàn wọ́n pé jíjẹ́ tí àwọn èèyàn jẹ́ àjèjì sí Ọlọ́run ló ń fa ibi àti ìyà tó ń jẹ aráyé. Kódà láwọn ilẹ̀ tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn kì í ti í kọbi ara sí iṣẹ́ ìwàásù wa, ọ̀pọ̀ ló ti wá ń tẹ́wọ́ gba ìhìn rere tí wọ́n sì ń ṣe ohun tó yẹ láti pa dà bá Ọlọ́run rẹ́. Ǹjẹ́ a kò wá rí i báyìí pé àkókò nìyí fún wa láti túbọ̀ máa fi ìtara lo ara wa lẹ́nu iṣẹ́ pípàrọwà fún àwọn èèyàn pé: “Ẹ padà bá Ọlọ́run rẹ́”?
15. Dípò tí a ó fi máa wàásù fún àwọn èèyàn pé Ọlọ́run á yanjú gbogbo ìṣòro wọn lójú ẹsẹ̀, kí la fẹ́ kí àwọn èèyàn níbi gbogbo mọ̀?
15 Iṣẹ́ ìwàásù wa kò dá lórí sísọ fún àwọn èèyàn pé tí wọ́n bá wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ó máa bá wọn yanjú gbogbo ìṣòro wọn lójú ẹsẹ̀, ara á sì tù wọ́n. Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń wá lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì nìyẹn, àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì sì ti múra tán láti ṣe ohun tí àwọn èèyàn ń fẹ́. (2 Tím. 4:3, 4) Kì í ṣe ohun tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa dá lé lórí nìyẹn. Ìhìn rere tá à ń wàásù ni pé, nítorí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa, ó múra tán láti dárí àwọn àṣemáṣe wa jì wá nípasẹ̀ Kristi. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan lè mú ara rẹ̀ kúrò nípò jíjẹ́ àjèjì sí Ọlọ́run, kó sì pa dà bá Ọlọ́run rẹ́. (Róòmù 5:10; 8:32) Àmọ́ ṣá, “àkókò ìtẹ́wọ́gbà” náà ti ń yára kánkán lọ sópin.
“Kí Iná Ẹ̀mí Máa Jó Nínú Yín”
16. Kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti fi ìgboyà àti ìtara wàásù?
16 Nítorí náà, báwo la ṣe lè jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́ kí ìtara wa má sì jó rẹ̀yìn? Àwọn kan lè jẹ́ onítìjú èèyàn tàbí kó ṣòro fún wọn láti máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, ìyẹn sì lè mú kí ara wọn máà yá mọ́ni. Àmọ́, ó dára ká rántí pé kì í ṣe béèyàn ṣe ní ìháragàgà sí ló ń fi hàn pé ó ní ìtara; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe ìwà tí onítọ̀hún ń hù. Pọ́ọ̀lù sọ bá a ṣe lè ní ìtara ká sì máa lò ó nígbà tó rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé kí wọ́n jẹ́ “kí iná ẹ̀mí máa jó nínú” wọn. (Róòmù 12:11) Ẹ̀mí Jèhófà kó ipa pàtàkì nínú bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ onígboyà tó sì lókun láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Láàárín ọgbọ̀n ọdún tí Jésù ti pe Pọ́ọ̀lù títí dìgbà tí wọ́n fi jù ú sẹ́wọ̀n kẹ́yìn tó sì kú ikú ajẹ́rìíkú ní ìlú Róòmù, ìtara rẹ̀ kò dín kù. Gbogbo ìgbà ni Pọ́ọ̀lù máa ń wojú Ọlọ́run tó ń tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ fún un lókun. Ó sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílí. 4:13) A máa jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀!
17. Báwo la ṣe lè jẹ́ “kí iná ẹ̀mí máa jó nínú” wa?
17 Ní olówuuru, ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí “jó” túmọ̀ sí “kí nǹkan máa hó.” (Kingdom Interlinear) Tá a bá fẹ́ kí omi tá a gbé kaná máa hó, a kò ní jẹ́ kí iná kú nídìí rẹ̀. Bákan náà, “kí iná ẹ̀mí” lè “máa jó nínú” wa, ẹ̀mí Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé wa láìdáwọ́ dúró. Bá a bá sì fẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ nínú wa láìdáwọ́ dúró, a gbọ́dọ̀ máa lo gbogbo nǹkan tí Jèhófà ń pèsè láti fún wa lókun nípa tẹ̀mí. Ìyẹn gba pé ká fọwọ́ pàtàkì mú Ìjọsìn Ìdílé wa àti ìpàdé ìjọ, ká máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa déédéé, ká máa gbàdúrà ká sì máa péjọ déédéé pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Èyí ló máa dà bí epo tó ń mú kí “iná ẹ̀mí máa jó nínú” wa.—Ka Ìṣe 4:20; 18:25.
18. Kí ló yẹ kí àwa Kristẹni tá a ti ya ara wa sí mímọ́ fi ṣe àfojúsùn wa?
18 Ẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ ni ẹni tó ní ohun pàtó kan tó fi ṣe àfojúsùn rẹ̀, tí kò sì sí ohun tó lè tètè pín ọkàn rẹ̀ níyà tàbí táá mú kó rẹ̀wẹ̀sì kí ọwọ́ rẹ̀ má bàa tẹ àfojúsùn rẹ̀. Àfojúsùn àwa Kristẹni tá a ti ya ara wa sí mímọ́ ni láti ṣe ohunkóhun tí Jèhófà bá fẹ́ ká ṣe, bí Jésù ti ṣe. (Héb. 10:7) Lóde òní, ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà ni pé kí gbogbo àwọn tó bá ṣeé ṣé fún pa dà bá òun rẹ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù àti Pọ́ọ̀lù, ká máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó sì tún jẹ́ kánjúkánjú, èyí tá a gbọ́dọ̀ ṣe lákòókò tá a wà yìí.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́” tí Ọlọ́run gbé lé Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yòókù lọ́wọ́?
• Báwo ni àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró ṣe lo “àkókò ìtẹ́wọ́gbà” náà lọ́nà tó dára gan-an?
• Báwo ni àwọn Kristẹni tó jẹ́ òjíṣẹ́ ṣe lè jẹ́ “kí iná ẹ̀mí máa jó nínú” wọn?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Pọ́ọ̀lù kò gbàgbé ìjíròrò tó wáyé láàárín òun àti Jésù Kristi Olúwa