Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Ọmọ Rẹ Máa Sọ?

Kí Ni Ọmọ Rẹ Máa Sọ?

Kí Ni Ọmọ Rẹ Máa Sọ?

Ẹ̀YIN ÒBÍ: Nínú Ilé Ìṣọ́ January 15, 2010, ojú ìwé 16 sí 20, a sọ̀rọ̀ lórí bẹ́ ẹ ṣe lè máa ṣe ìfidánrawò pẹ̀lú àwọn ọmọ yín. Àpilẹ̀kọ yìí pèsè àwọn àbá tó máa ràn yín lọ́wọ́ láti múra àwọn ọmọ yín sílẹ̀ láti kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n ń bá pàdé níléèwé. Ẹ lè fẹ́ láti ṣe àwọn ìfidánrawò yìí nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé.

ÀWỌN ọmọ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bá ọ̀pọ̀ ìṣòro pàdé níléèwé. Àwọn ọmọ iléèwé wọn sábà máa ń béèrè ìdí tí wọn kì í fi í lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò kan, irú bíi kíkí àsíá, ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àtàwọn ohun míì bíi yíya àwòrán bàbá Kérésì, igi Kérésì àti ṣíṣe àwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ ayẹyẹ ọdún. Bí wọ́n bá bi ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin ní irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀, kí ló máa sọ?

Ńṣe ni àwọn ọmọ kan tí wọ́n jẹ́ Kristẹni á wulẹ̀ sọ pé: “Mi ò jẹ́ ṣerú ẹ̀. Kò bá ẹ̀sìn mi mu.” Ó yẹ ká yin irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ torí pé wọn kò ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn. Ohun tí wọ́n sọ sì lè mú kí àwọn èèyàn má fi ìbéèrè yọ wọ́n lẹ́nu mọ́. Àmọ́ Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká “wà ní ìmúratán . . . láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ [wa] ìdí” fún ìgbàgbọ́ tá a ní. (1 Pét. 3:15) Ṣíṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ kọjá wíwulẹ̀ sọ pé, “Mi ò jẹ́ ṣerú ẹ̀.” Kódà bí àwọn yòókù kò bá gba ohun tá a sọ, àwọn kan ṣì lè fẹ́ mọ ìdí tí a fi ṣe ìpinnu tá a ṣe.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ti lo àwọn ìtẹ̀jáde bíi Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà láti sọ ìtàn inú Bíbélì fún àwọn ọmọléèwé wọn. Wọ́n lè lo irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀ láti ṣàlàyé ìdí tí àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí fi máa ń ṣe àwọn ohun kan àti ìdí tí wọn kì í fi í ṣe àwọn nǹkan míì. Àwọn ọmọléèwé kan máa ń tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ láti gbọ́ àwọn ìtàn inú Bíbélì náà, ìyẹn sì ti yọrí sí bíbẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó máa ń ṣòro fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ míì láti fara balẹ̀ gbọ́ ìtàn Bíbélì kan látòkèdélẹ̀. Bí àwọn ọmọléèwé kò bá rí ẹni ṣàlàyé àwọn ìtàn kan tó wà nínú Bíbélì fún wọn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ó lè ṣòro gan-an fún wọn láti lóye rẹ̀. Nígbà tí ọ̀rẹ́ Minhee tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá sọ fún un pé kó wá síbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí òun, ó sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà pé: “Bíbélì kò sọ pé ká máa ṣe ọjọ́ ìbí, kódà wọ́n pa Jòhánù Olùbatisí nígbà tẹ́nì kan ṣe ọjọ́ ìbí.” Àmọ́ Minhee rántí pé, kò jọ pé ọ̀rẹ́ òun yẹn lóye ìdáhùn tí òun fún un.

Nígbà míì, ó máa dára kí àwọn ọmọ fi àwòrán tàbí ìtàn kan nínú àwọn ìwé wa han ọmọ míì níléèwé. Ká wá sọ pé àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ sọ pé àwọn kò fẹ́ kí àwọn ọmọ iléèwé máa fi àwọn ìwé tó jẹ́ ti ẹ̀sìn han ara wọn ńkọ́? Ǹjẹ́ àwọn ọmọ wa lè wàásù lọ́nà tó gbéṣẹ́ láìlo ìtẹ̀jáde èyíkéyìí? Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti gbèjà ìgbàgbọ́ wọn?

Ẹ Máa Ṣe Ìfidánrawò

Ṣíṣe ìfidánrawò nílé máa ń ṣèrànwọ́ gan-an, àwọn òbí sì lè ṣe bí ọmọ iléèwé lákòókò ìfidánrawò náà. Bí àwọn ọmọ bá ṣe ń gbìyànjú láti gbèjà ìgbàgbọ́ wọn, àwọn òbí á máa gbóríyìn fún wọn nítorí ìsapá wọn, wọ́n á sì máa sọ ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí ìrònú wọn jinlẹ̀ sí i àti ìdí tó fi yẹ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ sọ fún wọn pé kí wọ́n máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tó máa yé àwọn ojúgbà wọn níléèwé. Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án kan tó ń jẹ́ Joshua sọ pé, àwọn ọmọ iléèwé òun kò lóye àwọn ọ̀rọ̀ bí “ẹ̀rí ọkàn” àti “ìdúróṣinṣin.” Torí náà, ó ní láti lo àwọn ọ̀rọ̀ tí kò le láti fèrò wérò pẹ̀lú wọn.—1 Kọ́r. 14:9.

Àwọn ọmọ iléèwé kan tí wọ́n béèrè ìbéèrè lè mọ́kàn kúrò nínú ìjíròrò náà bí ìdáhùn bá ti gùn jù. Àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí lè mú kí wọ́n máa fọkàn bá ìjíròrò náà lọ tí wọ́n bá ń ju ìbéèrè sí wọn, tí wọ́n sì ń fèrò wérò pẹ̀lú wọn. Ọmọ ọdún mẹ́wàá kan tó ń jẹ́ Haneul sọ pé, “Àwọn ọmọléèwé mi kì í fẹ́ kí n máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fáwọn, ńṣe ni wọ́n máa ń fẹ́ ká jọ máa jíròrò.” Tó o bá fẹ́ kó jẹ́ ìjíròrò, máa bi wọ́n ní ìbéèrè, kó o sì wá fara balẹ̀ gbọ́ èrò wọn.

Ìjíròrò tó wà níbí yìí máa jẹ́ ká rí bí àwọn ọmọ tó jẹ́ Kristẹni ṣe lè fèrò wérò pẹ̀lú àwọn ọmọléèwé wọn. Kò pọn dandan láti há ìjíròrò yìí sórí, torí pé ọmọ yàtọ̀ sọ́mọ, bí ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan bá sì ṣe rí ló máa pinnu ohun tí ọmọ kọ̀ọ̀kan máa sọ. Torí náà, ó dára kí àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí fi àbá yìí sọ́kàn, kí wọ́n sọ ọ́ lọ́rọ̀ ara wọn, lẹ́yìn náà kí wọ́n wá ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó bá ipò tó yọjú mu, tó sì máa yé àwọn ọmọléèwé náà. Tó o bá ní àwọn ọmọ tó ṣì ń lọ síléèwé, gbìyànjú láti fi ìjíròrò yìí dánra wò pẹ̀lú wọn.

Ó máa ń gba àkókò àti ìsapá láti tọ́ àwọn ọmọ. Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa ń fẹ́ láti gbin àwọn ìlànà Bíbélì sọ́kàn àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì máa ń fẹ́ yí wọn lérò pa dà láti gbé ìgbé ayé wọn lọ́nà tó bá àwọn ìlànà yẹn mu.—Diu. 6:7; 2 Tím. 3:14.

Nígbà tẹ́ ẹ bá tún ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín, ẹ gbìyànjú láti fi àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí dánra wò. Ẹ máa rí bó ṣe gbéṣẹ́ tó. Ẹ fi sọ́kàn pé àfojúsùn yín kì í ṣe láti há àwọn ìdáhùn tàbí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sórí. Kódà, ẹ lè fi àpẹẹrẹ ohun kan tó ṣeé ṣe kó wáyé dánra wò nígbà mélòó kan, kẹ́ ẹ sọ ọ̀rọ̀ tó yàtọ̀ síra, kẹ́ ẹ sì kíyè sí bí àwọn ọmọ yín ṣe máa fèsì. Bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ béèyàn ṣe ń lo òye àti ọgbọ́n. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ẹ ó lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ débi tí wọ́n á fi lè gbèjà ìgbàgbọ́ wọn níwájú àwọn ọmọléèwé wọn, níwájú àwọn ará àdúgbò àti àwọn olùkọ́.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

ṢÍṢE ỌJỌ́ ÌBÍ

Bùnmi: Kúnlé, báwo ni? Mo fẹ́ kó o wá síbi ọjọ́ ìbí mi.

Kúnlé: Bùnmi, o ṣeun tó o rántí mi. Tiẹ̀ gbọ́ ná, kí nìdí tó o fi fẹ́ ṣe ọjọ́ ìbí?

Bùnmi: Kí n kàn fi rántí ọjọ́ tí wọ́n bí mi náà ni. Ṣéwọ kì í ṣọjọ́ ìbí tìẹ ni?

Kúnlé: Rárá o, mi ò kí ń ṣọjọ́ ìbí.

Bùnmi: Kí ló dé? Inú àwọn òbí mi dùn nígbà tí wọ́n bí mi.

Kúnlé: Inú àwọn òbí tèmi náà dùn nígbà tí wọ́n bí mi. Àmọ́ mi ò rò pé ìyẹn tó ohun tí mo lè máa torí ẹ̀ ṣe ọjọ́ ìbí lọ́dọọdún. Ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́jọ́ ìbí máa ń rò pé àwọn làwọn ṣe pàtàkì jù. Àmọ́ ta ló ṣe pàtàkì tó Ọlọ́run? Ṣé kò sì yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó mú ká wà láàyè?

Bùnmi: Ṣé ohun tó ò ń sọ ni pé kò yẹ kí n máa ṣe ọjọ́ ìbí mi?

Kúnlé: Ọwọ́ ẹ nìyẹn kù sí o. Àmọ́, o kò ṣe ronú nípa èyí ná? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ràn kí wọ́n máa gba ẹ̀bùn lọ́jọ́ ìbí wọn, ohun tí Bíbélì sọ ni pé ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ. Dípò tí a ó fi máa ro tara wa nìkan lọ́jọ́ ìbí wa, ṣé kò yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ká máa ronú nípa àwọn ẹlòmíì, ká sì máa ṣe ohun rere fún wọn?

Bùnmi: Mi ò dẹ̀ rò ó lọ síbẹ̀ yẹn rí o. Ṣé ohun tó o wá ń sọ ni pé àwọn òbí rẹ kì í fún ẹ lẹ́bùn?

Kúnlé: Wọ́n máa ń fún mi lẹ́bùn, àmọ́ kò dìgbà tí mo bá ṣọjọ́ ìbí. Ìgbàkigbà tó bá tọkàn wọn wá ni wọ́n máa ń fún mi lẹ́bùn. Tiẹ̀ gbọ́ ná Bùnmi, ṣé wàá fẹ́ mọ bí ṣíṣe ọjọ́ ìbí ṣe bẹ̀rẹ̀?

Bùnmi: Ṣé o lè sọ fún mi?

Kúnlé: Tó bá dọ̀la màá sọ ìtàn tó dùn kan fún ẹ nípa ọjọ́ ìbí tí wọ́n ṣe nígbà kan sẹ́yìn.

KÍKÍ ÀSÍÁ

Fúnmi: Ṣadé, kí ló dé tóò kì ń kí àsíá?

Ṣadé: O ṣeun tó o béèrè, Fúnmi. Ṣùgbọ́n jẹ́ n kọ́kọ́ bi ẹ́ ná, kí ló dé tíwọ fi ń kí àsíá?

Fúnmi: Torí pé mo fẹ́ràn orílẹ̀-èdè mi ni.

Ṣadé: Ó dáa, Fúnmi, mo mọ̀ pé o fẹ́ràn mọ́mì rẹ. Àmọ́, ṣé o máa ń kí wọn bó o ṣe ń kí àsíá?

Fúnmi: Rárá o. Ṣùgbọ́n torí pé mo bọ̀wọ̀ fún àsíá ni mo ṣe máa ń kí i. Ṣéwọ ò bọ̀wọ̀ fún àsíá ni?

Ṣadé: Mo bọ̀wọ̀ fún un. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn tá a bọ̀wọ̀ fún àti ohun tá a bọ̀wọ̀ fún la máa ń kí bí wọ́n ṣe ń kí àsíá, àbí?

Fúnmi: Mo bọ̀wọ̀ fún olùkọ́ wa, ṣùgbọ́n mi ò kí ń kí wọn báwọn èèyàn ṣe ń kí àsíá. A jẹ́ pé mi ò mọ ìdí tí mo fi ń kí àsíá nìyẹn.

Ṣadé: Fúnmi, ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé àsíá dúró fún orílẹ̀-èdè àwọn. Wọ́n sì ń kí àsíá láti fi hàn pé àwọn ṣe tán láti ṣe ohunkóhun fún orílẹ̀-èdè àwọn. Àmọ́ èmi ò firú ojú yẹn wò ó. Mi ò lè kú fún orílẹ̀-èdè mi torí pé Ọlọ́run ló dá mi. Mo sì ti pinnu láti fi ayé mi fún un. Torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo bọ̀wọ̀ fún àsíá, mi ò kí ń kí i.

Fúnmi: Ó ti wá yé mi báyìí.

Ṣadé: Inú mi dùn pé ó mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ yìí, Fúnmi. Tó o bá sì fẹ́ mọ ìdí tí mo fi ń ṣe ohun kan tàbí ìdí tí mi ò fi ń ṣe é, ìwọ ṣá ti béèrè lọ́wọ́ mi. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ọba Bábílónì pàṣẹ pé kí àwọn èèyàn forí balẹ̀ fún ère kan. Àwọn kan kọ̀ láti forí balẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè pa wọ́n nítorí ẹ̀.

Fúnmi: Hẹ̀n-ẹ́n, kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí wọn?

Ṣadé: Màá sọ fún ẹ tó bá di àkókò oúnjẹ ọ̀sán.

ÌṢÈLÚ ILÉÈWÉ

Kọ́lá: Báyọ̀, ta lo rò pé ó yẹ kí wọ́n fi jẹ kápútéènì wa?

Báyọ̀: Èmi ò gbè sẹ́yìn èyíkéyìí lára àwọn tó ń du ipò náà o.

Kọ́lá: Kí ló dé?

Báyọ̀: Torí pé mo ti ní aṣáájú tó dára jù lọ ni. Kristẹni ni mí, mo sì ti pinnu láti máa tọ Jésù lẹ́yìn. Torí náà mi ò lè yan aṣáájú míì. Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ ìdí tí mo fi gbà pé Jésù ni Aṣáájú tó dára jù lọ?

Kọ́lá: Mi ò mọ̀, mi ò sì fẹ́ mọ̀.

Báyọ̀: Ó dára, tó o bá ṣe tán láti mọ̀, inú mi á dùn láti sọ fún ẹ.

[Àwòrán]

“Kúnlé, báwo ni? Mo fẹ́ kó o wá síbi ọjọ́ ìbí mi”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

“Kí nìdí tí o kì í fi í kí àsíá?”