Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

• Ọ̀dọ̀ ta ni àwọn ẹ̀sìn tó ní ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ ti ṣẹ̀ wá?

Ẹ̀kọ́ nípa àyànmọ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ẹ̀kọ́ ìsìn Calvin. Àwọn ẹ̀kọ́ tí Jean Cauvin (John Calvin), tó jẹ́ Alátùn-únṣe Ìsìn tẹ́lẹ̀ rí náà fi kọ́ni wà nínú ẹ̀ka ṣọ́ọ̀ṣì àwọn tó ń ṣàtúnṣe ìsìn bíi ṣọ́ọ̀ṣì Reformed, Presbyterian, Congregational àti Puritan.—9/1, ojú ìwé 18 sí 21.

• Ibo ni Kéènì ti rí ìyàwó rẹ̀?

Ìyàwó Kéènì ní láti jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ ọmọ Éfà, torí pé Éfà bí “àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.” (Jẹ́n. 5:4)—9/1, ojú ìwé 25.

• Áńgẹ́lì wo ni Ọlọ́run rán ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tó kó wọn jáde ní ilẹ̀ Íjíbítì? (Ẹ́kís. 23:20, 21)

Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé áńgẹ́lì ‘tí orúkọ Jèhófà wà lára rẹ̀’ yìí jẹ́ àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run, tá a wá mọ̀ sí Jésù lẹ́yìn náà.—9/15, ojú ìwé 21.

• Kí nìdí tí ìwé 1 Kọ́ríńtì fi sọ̀rọ̀ nípa ẹran tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà?

Wọ́n máa ń fi àwọn ẹran rúbọ nínú tẹ́ńpìlì àwọn Gíríìkì àti ti àwọn ará Róòmù, àmọ́ wọ́n lè gbé àwọn ẹran tó bá ṣẹ́ kù lẹ́yìn ayẹyẹ náà lọ sí ọjà tí wọ́n ti ń ta ẹran. Àwọn Kristẹni kì í lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà; síbẹ̀, wọn kò ní láti máa wo ẹran tó bá ṣẹ́ kù lẹ́yìn ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́ bí wọ́n bá ta irú ẹran bẹ́ẹ̀ ní ọjà ẹran. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ohun gbogbo tí a ń tà ní ọjà ẹran ni kí ẹ máa jẹ, láìṣe ìwádìí kankan ní tìtorí ẹ̀rí-ọkàn yín; nítorí pé ‘ti Jèhófà ni ilẹ̀ ayé àti ohun tí ó kún inú rẹ̀.’” (1 Kọ́r. 10:25, 26)—10/1, ojú ìwé 12.

• Kí ni díẹ̀ lára àwọn àwíjàre tí Ọlọ́run kò fara mọ́ bó bá dọ̀ràn ìjọsìn tòótọ́?

‘Ó ti le jù. Kò wù mí ṣe. Ọwọ́ mi ti dí jù. Mi ò kúnjú ìwọ̀n tó. Ẹnì kan ṣe ohun tó dùn mí.’ Ìwọ̀nyí jẹ́ àwíjàre tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ fún kíkùnà láti pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́.—10/15, ojú ìwé 12 sí 15.

• Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo lo lè gbà mú kí àwọn ìpàdé ìjọ máa gbé ìwọ àtàwọn míì ró?

Máa múra sílẹ̀. Máa lọ sí ìpàdé déédéé. Máa tètè dé. Kó gbogbo nǹkan tó o nílò dání. Ṣọ́ra fún ìpínyà ọkàn. Kópa nínú ìpàdé. Jẹ́ kí ìdáhùn rẹ máa ṣe ṣókí. Ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún ẹ. Gbóríyìn fún àwọn tó ṣiṣẹ́. Kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ṣáájú àti lẹ́yìn ìpàdé.—10/15, ojú ìwé 22.

• Ibo ni ìtàn Bíbélì tó kan ọmọdébìnrin kan ti sọ̀rọ̀ nípa àrùn ẹ̀tẹ̀, èyí tá à ń pè ní àrùn Hansen lónìí?

Ìwé Àwọn Ọba Kejì orí karùn-ún sọ nípa ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan, tó jẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé olórí ọmọ ogun Síríà kan tó ń jẹ́ Náámánì. Torí pé Náámánì ní àrùn ẹ̀tẹ̀, ọmọbìnrin náà sọ fún un pé kó lọ rí wòlíì Èlíṣà kó bàa lè rí ìwòsàn gbà.—11/1, ojú ìwé 22.

• Kí la lè rí kọ́ látinú bí Áárónì ṣe juwọ́ sílẹ̀ láti ṣe ohun táwọn ẹlòmíì fẹ́?

Nígbà tí Mósè kò sí níbẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rọ Áárónì pé kó ṣe òrìṣà kan fún àwọn. Ó gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ nìkan kọ́ ni ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe máa ń nípa lé lórí. Ó tún lè nípa lórí àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ń fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́. A gbọ́dọ̀ yẹra fún jíjẹ́ kí àwọn ẹlòmíì mú wa ṣe ohun tí kò tọ́.—11/15, ojú ìwé 8.

• Èwo ni òtítọ́, èwo sì ni irọ́?

Ẹni gidi ni Sátánì: òtítọ́. (2 Kọ́r. 11:14) Ọ̀run ni gbogbo èèyàn ń lọ lẹ́yìn ikú: irọ́. (Oníw. 9:5) Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ń wá ire wa: òtítọ́. (Sm. 34:7) Jésù bá Ọlọ́run dọ́gba: irọ́. (1 Kọ́r. 11:3)—12/1, ojú ìwé 8 sí 9.