Ẹ̀mí Mímọ́ Ń fún Wa Lágbára Ká Lè Borí Àdánwò Èyíkéyìí
Ẹ̀mí Mímọ́ Ń fún Wa Lágbára Ká Lè Borí Àdánwò Èyíkéyìí
“Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” —FÍLÍ. 4:13.
1. Kí nìdí táwọn èèyàn Jèhófà fi ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìpọ́njú?
Ọ̀PỌ̀ ìgbà làwọn èèyàn Jèhófà máa ń dojú kọ ìpọ́njú tó yàtọ̀ síra. Àìpé tiwa tàbí ètò àwọn nǹkan tá à ń gbé nínú rẹ̀ yìí ló máa ń fa àwọn àdánwò kan. Ohun tó sì ń fa àwọn àdánwò míì ni ìṣọ̀tá tó wà láàárín àwọn tó ń sin Ọlọ́run àtàwọn tí kò sìn ín. (Jẹ́n. 3:15) Láti ìgbà láéláé ni Ọlọ́run ti ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fara da inúnibíni tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn, kí wọ́n dènà ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, kí wọ́n sì fara da àwọn ìpọ́njú mìíràn ní ọlọ́kan-kò-jọ̀kan. Ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lè ran àwa náà lọ́wọ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀.
Ó Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Fara Da Inúnibíni Tó Jẹ Mọ́ Ẹ̀sìn
2. Kí ló fà á tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sí wa nítorí ẹ̀sìn, àwọn ọ̀nà wo sì ni inúnibíni náà lè gbà wá?
2 Inúnibíni tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn túmọ̀ sí fífòòró àwọn èèyàn tàbí mímọ̀ọ́mọ̀ fìyà jẹ wọ́n nítorí ẹ̀sìn wọn tàbí nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ète irú inúnibíni bẹ́ẹ̀ jẹ́ láti fòpin sí irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, láti má ṣe jẹ́ kó tàn kálẹ̀ tàbí láti ba ìwà títọ́ àwọn tó ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni inúnibíni lè gbà wá, àwọn kàn lè wá ní tààràtà, àwọn míì sì lè wá lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́. Bíbélì fi ìgbéjàkò Sátánì wé bí ẹgbọrọ kìnnìún àti ejò ṣèbé ṣe máa ń gbéjà koni.—Ka Sáàmù 91:13.
3. Ọ̀nà wo ni inúnibíni tó jọ ìgbéjàkò kìnnìún àti ti ejò ṣèbé máa ń gbà wá?
3 Bíi kìnnìún tó rorò, Sátánì sábà máa ń gbéjà kò wá ní tààràtà tàbí lójúkojú; ó lè mú kí wọ́n hùwà ipá sí wa, kí wọ́n fi wá sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa. (Sm. 94:20) Ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ nípa bó ṣe ń lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí máa ń wà nínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook, tó ń ṣàlàyé ìgbòkègbodò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní. Àwọn jàǹdùkú tó jẹ́ pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tàbí àwọn tó gba òṣèlú kanrí ló kó àwọn kan lára wọn jọ ti hùwà ipá sáwọn èèyàn Ọlọ́run láwọn ibi púpọ̀. Àwọn inúnibíni tó jọ ìgbéjàkò kìnnìún yìí ti mú kí àwọn mélòó kan kọsẹ̀. Bíi ti ejò ṣèbé, Èṣù pẹ̀lú máa ń lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí kó lè gbéjà ko àwọn èèyàn láìròtẹ́lẹ̀, kó lè sọ ọkàn wọn dìbàjẹ́ kó sì tàn wọ́n jẹ láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó máa ń lo irú àtakò bẹ́ẹ̀ láti mú ká dẹwọ́ nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run tàbí láti ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Àmọ́, ẹ̀mí mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè kojú oríṣi inúnibíni méjèèjì náà.
4, 5. Ọ̀nà wo ló dára jù lọ láti gbà múra sílẹ̀ de inúnibíni, kí sì nìdí? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan.
4 Fífi ọkàn yàwòrán onírúurú ọ̀nà tí inúnibíni lè gbà wáyé lọ́jọ́ iwájú kọ́ ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà múra sílẹ̀ fún inúnibíni. Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé kò sí bá a ṣe lè mọ irú inúnibíni tó lè dojú kọ wá lọ́jọ́ iwájú, torí náà kò sí àǹfààní kankan nínú dída ara wa láàmú torí ohun tó lè má ṣẹlẹ̀. Àmọ́, ohun kan wà tá a lè ṣe. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ti ṣeé ṣe fún láti fara da inúnibíni ló jẹ́ pé ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé wọ́n ń ṣàṣàrò lórí bí àwọn olùpàwàtítọ́mọ́ tí Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa wọn ṣe sin Jèhófà láìyẹsẹ̀, wọ́n sì tún máa ń ronú lórí ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni àti àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀. Èyí ti mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Ìfẹ́ yẹn náà sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ ká lè kojú àdánwò èyíkéyìí tó bá dé bá wọn.
5 Gbé àpẹẹrẹ méjì lára àwọn arábìnrin wa tó wà ní orílẹ̀-èdè Màláwì yẹ̀ wò. Torí pé àwọn jàǹdùkú èèyàn kan fẹ́ kí wọ́n ra káàdì ẹgbẹ́ òṣèlú, wọ́n lù wọ́n, wọ́n bọ́ wọn láṣọ, wọ́n sì halẹ̀ mọ́ wọn pé àwọn máa fipá bá wọn lò pọ̀. Àwọn jàǹdùkú náà parọ́ fún wọn pé àwọn ará wọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì pàápàá ti ra káàdì ẹgbẹ́ òṣèlú. Èsì wo ni àwọn arábìnrin náà fún wọn? Wọ́n sọ fún wọn pé: “Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo là ń sìn. Torí náà, bí àwọn ará tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì bá tiẹ̀ ra káàdì, ìyẹn ò ní ká yí ìpinnu wa pa dà. Bẹ́ ẹ bá tiẹ̀ má pa wá pàápàá, a kò ní juwọ́ sílẹ̀!” Lẹ́yìn tí àwọn arábìnrin náà ti fi ìgboyà sọ̀rọ̀ báyìí, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀.
6, 7. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára kí wọ́n lè fara da inúnibíni?
6 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà gba ìhìn rere náà “lábẹ́ ìpọ́njú púpọ̀” àmọ́ “pẹ̀lú ìdùnnú ẹ̀mí mímọ́.” (1 Tẹs. 1:6) Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni látijọ́ àti lóde òní tí wọ́n ti dojú kọ inúnibíni tí wọ́n sì borí rẹ̀ ti ròyìn pé nígbà tó bá di pé àdánwò náà nira jù lọ, àwọn máa ń ní àlàáfíà àtọkànwá tó jẹ́ ara èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Gál. 5:22) Àlàáfíà yẹn sì máa ń ṣọ́ ọkàn-àyà àti agbára èrò orí wọn. Ó dájú pé Jèhófà máa ń lo ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ láti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára tí wọ́n lè fi kojú àwọn àdánwò kí wọ́n sì fọgbọ́n hùwà nígbà ìpọ́njú. *
7 Ó máa ń ya àwọn tó ń wo àwọn èèyàn Ọlọ́run lẹ́nu pé a máa ń múra tán láti pa ìwà títọ́ wa mọ́, kódà bá a bá dojú kọ inúnibíni líle koko. Ńṣe ló dà bíi pé a máa ń kún fún agbára kan tó ju ti ẹ̀dá lọ, bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn. Àpọ́sítélì Pétérù mú kó dá wa lójú pé: “Bí a bá ń gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀, nítorí pé ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọ́run, ti bà lé yín.” (1 Pét. 4:14) Ti pé wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa torí pé à ń gbé àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run lárugẹ fi hàn pé a ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. (Mát. 5:10-12; Jòh. 15:20) Ẹ sì wo bí ẹ̀rí tá à ń rí pé Jèhófà ń bù kún wa yìí ṣe ń fún wa láyọ̀!
Ó Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Dènà Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe
8. (a) Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún Jóṣúà àti Kálébù láti dènà ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe? (b) Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jóṣúà àti Kálébù?
8 Inúnibíni míì tó sábà máa ń wá lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ táwọn Kristẹni sì gbọ́dọ̀ dènà rẹ̀ ni ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tó lè ṣàkóbá fúnni. Àmọ́, torí pé ẹ̀mí Jèhófà lágbára púpọ̀ ju ẹ̀mí ayé lọ, kò ní jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì báwọn èèyàn bá ń fi wá ṣẹ̀sín, tí wọ́n ń tan irọ́ kálẹ̀ nípa wa tàbí tí wọ́n ń gbìyànjú láti fipá mú wa láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí wọ́n gbé kalẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, kí ló fà á tí Jóṣúà àti Kálébù kò fi fara mọ́ èrò àwọn amí mẹ́wàá yòókù tí wọ́n jọ lọ wó ilẹ̀ Kénáánì? Ẹ̀mí mímọ́ mú kí wọ́n ní “ẹ̀mí,” tàbí èrò tó yàtọ̀.—Ka Númérì 13:30; 14:6-10, 24.
9. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni kò fi gbọ́dọ̀ bẹ̀rù láti ṣe nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn?
9 Ẹ̀mí mímọ́ tún fún àwọn àpọ́sítélì Jésù lágbára láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run ju àwọn tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń bọ̀wọ̀ fún torí pé wọ́n kà wọ́n sí olùkọ́ ẹ̀sìn tòótọ́. (Ìṣe 4:21, 31; 5:29, 32) Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́ tẹ̀ sí ibi tí ayé bá tẹ̀ sí, kí wọ́n má bàa forí gbárí pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. Àmọ́, ó máa ń pọn dandan lọ́pọ̀ ìgbà pé kí àwọn Kristẹni tòótọ́ dúró lórí ohun tí wọ́n mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́. Síbẹ̀, ọpẹ́lọpẹ́ agbára tí Ọlọ́run ń fún wọn nípasẹ̀ ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ ni kì í jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù láti ṣe ohun tó yàtọ̀. (2 Tím. 1:7) Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà kan tí a kò ti gbọ́dọ̀ fàyè gba ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe.
10. Ìṣòro lílekoko wo ni àwọn Kristẹni kan lè dojú kọ?
10 Àwọn ọ̀dọ́ kan lè má mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe bí wọ́n bá mọ̀ pé ọ̀rẹ́ wọn kan ti hùwà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Ó lè máa ṣe wọ́n bíi pé báwọn bá ní kí àwọn alàgbà ran ọ̀rẹ́ àwọn lọ́wọ́ ńṣe ló máa dà bíi pé àwọn dalẹ̀ ọ̀rẹ́ àwọn; torí náà, wọ́n á fẹ́ pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ láṣìírí bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ò lè ran ọ̀rẹ́ wọn lọ́wọ́. Ẹnì kan tó hùwà àìtọ́ tiẹ̀ lè máa fúngun mọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tóun dá. Kì í ṣe àwọn ọ̀dọ́ nìkan ló nírú ìṣòro yìí ṣá o. Ó lè ṣòro fún àwọn kan tó jẹ́ àgbàlagbà náà láti sọ fún àwọn alàgbà bí ọ̀rẹ́ wọn tàbí ẹnì kan nínú ìdílé wọn bá hùwà àìtọ́. Àmọ́ kí ló yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe lórí irú ọ̀rọ̀ yìí?
11, 12. Kí ni ohun tó dára jù lọ láti ṣe bí ẹnì kan nínú ìjọ bá rọ̀ ẹ́ pé kó o má sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun ti hùwà àìtọ́, kí sì nìdí?
11 Ronú nípa ohun kan tó ṣeé ṣe kó wáyé. Ká sọ pé ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Kúnlé mọ̀ pé Fẹ́mi, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ òun nínú ìjọ, máa ń wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe. Kúnlé wá sọ fún Fẹ́mi tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí pé ohun tó ń ṣe ń kọ òun lóminú gan-an. Àmọ́, Fẹ́mi kò kọbi ara sí ohun tí Kúnlé sọ fún un. Nígbà tí Kúnlé tiẹ̀ sọ fún un pé kó sọ fún àwọn alàgbà, ńṣe ni Fẹ́mi fèsì pé bó bá gbà pé ọ̀rẹ́ làwọn jọ jẹ́ lóòótọ́, kò ní tú àṣírí òun fún àwọn alàgbà. Ṣó yẹ kí ẹ̀rù máa ba Kúnlé pé ọ̀rẹ́ àwọn lè bà jẹ́? Ó lè máa ṣe kàyéfì pé ọ̀rọ̀ náà lè yí lé òun lórí bí Fẹ́mi bá sẹ́ pé òun kò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀. Síbẹ̀, ọ̀ràn náà kò lè yanjú bí Kúnlé bá kọ̀ tí kò sọ fún àwọn alàgbà. Ó tiẹ̀ lè mú kí àjọṣe tí Fẹ́mi ní pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́. Ó máa dára kí Kúnlé rántí pé “wíwárìrì nítorí ènìyàn ni ohun tí ń dẹ ìdẹkùn, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni a óò dáàbò bò.” (Òwe 29:25) Kí ló tún yẹ kí Kúnlé ṣe? Ó yẹ kí ìfẹ́ sún un láti pa dà tọ Fẹ́mi lọ kó sì jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ̀. Ìyẹn gba ìgboyà. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Fẹ́mi pàápàá á fẹ́ káwọn jọ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà. Ó yẹ kí Kúnlé tún gba Fẹ́mi níyànjú láti lọ sọ fún àwọn alàgbà kó sì sọ fún un pé bó bá pẹ́ jù kó tó lọ sọ́ fún wọn, òun fúnra òun á lọ sọ fún wọn.—Léf. 5:1.
12 Bí o bá ní láti gbẹnu sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ lórí irú ọ̀rọ̀ yìí, ó lè má tètè mọrírì rẹ̀ pé ńṣe lò ń fẹ́ láti ran òun lọ́wọ́. Bópẹ́ bóyá, ó lè wá yé e pé ohun tó dára jù lọ fún òun lo ṣe yẹn. Bí oníwà àìtọ́ náà bá gba ìrànlọ́wọ́ tí àwọn alàgbà fún un tó sì ṣiṣẹ́ lé e lórí, a jẹ́ pé títí ayé lá máa kún fún ọpẹ́ torí pé o lo ìgboyà o sì jẹ́ adúróṣinṣin. Àmọ́, bó bá ń yàn ẹ́ lódì torí pé o lọ sọ fún àwọn alàgbà, ṣé ìwọ náà rò pé irú ẹni tó yẹ kó o máa bá ṣọ̀rẹ́ nìyẹn? Ìgbàkigbà tá a bá ṣe ohun tó dùn mọ́ Jèhófà tó jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa gíga jù lọ, la tó lè sọ pé a ṣe ohun tó tọ́. Bá a bá fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́, àwọn míì tí wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ a mọyì jíjẹ́ tá a jẹ́ adúróṣinṣin, wọ́n á sì di ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́. A kò gbọ́dọ̀ gba Èṣù láyè nínú ìjọ Kristẹni. Bá a bá gbà á láyè pẹ́nrẹ́n, ńṣe la máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. Àmọ́ a lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ nípa ṣíṣe ohun tó máa mú kí ìjọ Kristẹni wà ní mímọ́.—Éfé. 4:27, 30.
Ó Ń Fún Wa Lágbára Ká Lè Fara Da Onírúurú Ìpọ́njú
13. Onírúurú ìpọ́njú wo ló ń dojú kọ àwọn èèyàn Jèhófà, kí ló sì fà á tírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ fi wọ́pọ̀?
13 Ìpọ́njú lè dojú kọ wá ní onírúurú ọ̀nà. Ó lè jẹ́ ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀, kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹni, kí ìjábá ṣẹlẹ̀, kí èèyàn ẹni kú, kéèyàn ní ìṣòro àìlera àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Níwọ̀n bí a ti ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko,” ó yẹ ká máa retí pé bópẹ́ bóyá, gbogbo wa máa dojú kọ irú àdánwò kan tàbí òmíràn. (2 Tím. 3:1) Bí àdánwò náà bá dé, ó ṣe pàtàkì pé ká má ṣe jáyà. Ẹ̀mí mímọ́ lè fún wa lágbára ká lè fara da ìpọ́njú èyíkéyìí.
14. Kí ló fún Jóòbù lágbára láti fara da àwọn ìpọ́njú tó dé bá a?
14 Ńṣe ni Jóòbù ń ti inú ìpọ́njú kan bọ́ sínú òmíràn. Ó pàdánù àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ kú, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kẹ̀yìn sí i, àìsàn dá a gúnlẹ̀, ìyàwó rẹ̀ kò sì ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà mọ́. (Jóòbù 1:13-19; 2:7-9) Síbẹ̀, Jóòbù rí ojúlówó ìtùnú gbà lọ́dọ̀ Élíhù. Ọ̀rọ̀ tí Élíhù sọ fún Jóòbù náà ni kókó inú ọ̀rọ̀ Jèhófà pé: “Dúró jẹ́ẹ́, kí o sì fi ara rẹ hàn ní olùfiyèsílẹ̀ sí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run.” (Jóòbù 37:14) Kí ló ran Jóòbù lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò tó dé bá a? Kí ló sì lè ran àwa náà lọ́wọ́ ká lè fara da àdánwò tó bá dé bá wa? Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká máa rántí onírúurú ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà lo ẹ̀mí mímọ́ àti agbára rẹ̀ ká sì máa ṣe àṣàrò lé wọn lórí. (Jóòbù 38:1-41; 42:1, 2) Bóyá a lè rántí ohun kan nínú ìgbésí ayé tiwa fúnra wa tó fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ó ṣì nífẹ̀ẹ́ wa síbẹ̀.
15. Kí ló fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lágbára láti fara da àwọn àdánwò tó dé bá a?
15 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fara da ọ̀pọ̀ ìpọ́njú tó lè gbẹ̀mí ẹni nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. (2 Kọ́r. 11:23-28) Kí ló ràn án lọ́wọ́ tí kò fi ṣi inú rò tí kò sì bọ́hùn nígbà tó ń dojú kọ àwọn ipò tó dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò yẹn? Ó gbàdúrà sí Jèhófà torí pé ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń dojú kọ ìdánwò tó wá yọrí sí bó ṣe kú ikú ajẹ́rìíkú, ó kọ̀wé pé: “Olúwa dúró lẹ́bàá mi, ó sì fi agbára sínú mi, pé nípasẹ̀ mi, kí a lè ṣàṣeparí ìwàásù náà ní kíkún àti kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lè gbọ́ ọ; a sì dá mi nídè kúrò lẹ́nu kìnnìún.” (2 Tím. 4:17) Torí náà, látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù alára, ó ṣeé ṣe fún un láti mú kó dá àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lójú pé kò sí ìdí tí wọ́n fi ní láti máa “ṣàníyàn nípa ohunkóhun.”—Ka Fílípì 4:6, 7, 13.
16, 17. Fúnni ní àpẹẹrẹ kan nípa bí Jèhófà ṣe ń fún àwọn èèyàn rẹ̀ lágbára lónìí láti fara da ipò tí kò bára dé.
16 Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Roxana ti rí bí Jèhófà ṣe máa ń pèsè fún àwọn èèyàn rẹ̀. Nígbà tó bẹ ọ̀gá rẹ̀ pé kó fún òun ní ọjọ́ díẹ̀ láti fi lọ sí ọ̀kan lára àwọn àpéjọ àgbègbè wa, ó fìbínú dá a lóhùn pé tó bá lọ òun máa lé e kúrò níbi iṣẹ́. Bó ti wù kó rí, Roxana lọ sí àpéjọ náà, àmọ́ kò yé gbàdúrà kíkankíkan pé kí Jèhófà má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ òun. Lẹ́yìn àdúrà náà, ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá rẹ̀ ṣe sọ, ó lé e kúrò níbi iṣẹ́ náà ní ọjọ́ Monday lẹ́yìn tó pa dà dé láti àpéjọ náà. Èyí ba Roxana lọ́kàn jẹ́, torí pé iṣẹ́ náà ló fi ń gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó kékeré ni wọ́n ń san fún un níbẹ̀. Ó tún gbàdúrà, ó sì wá rántí pé Ọlọ́run ti pèsè fún òun nípa tẹ̀mí ní àpéjọ náà, torí náà ó dájú pé ó tún lè pèsè fún òun nípa tara. Bó ṣe ń pa dà lọ sí ilé, ó rí ibì kan tí wọ́n gbé àkọlé sí pé àwọn ń wá amojú ẹ̀rọ ńlá kan tí wọ́n fi ń rán nǹkan, bó ṣe wá iṣẹ́ lọ síbẹ̀ nìyẹn. Ọ̀gá iléeṣẹ́ náà rí i pé kò mọ̀ nípa iṣẹ́ náà àmọ́ ó gbà láti gbà á síṣẹ́, owó táá sì máa san fún un á fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì iye tó ń gbà níbi iṣẹ́ tó ń ṣe tẹ́lẹ̀. Roxana rí èyí gẹ́gẹ́ bí ìdáhùn sí àdúrà rẹ̀. Àmọ́, ìbùkún tó ga jù lọ tó rí gbà ni pé ó ṣeé ṣe fún un láti wàásù ìhìn rere fún àwọn mélòó kan lára àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Márùn-ún lára wọn, tó fi mọ́ ọ̀gá iléeṣẹ́ náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ wọ́n sì ṣèrìbọmi.
17 Nígbà míì, ó lè dà bíi pé Jèhófà kò dáhùn àwọn àdúrà wa, pàápàá bí a kò bá rí ìdáhùn gbà lójú ẹsẹ tàbí bá a ṣe fẹ́ ẹ. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ìdí rere kan wà tó fi rí bẹ́ẹ̀ nìyẹn. Jèhófà sì mọ ìdí rere náà, ó sì lè jẹ́ pé ọjọ́ iwájú ló tó máa ṣe kedere sí wa. Àmọ́, ọ̀kan lára ohun tó yẹ kó dá wa lójú ni pé, Ọlọ́run kì í pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tì.—Héb. 6:10.
Ó Ń Fún Wa Lágbára Ká Lè Borí Àwọn Àdánwò àti Ìdẹwò
18, 19. (a) Kí nìdí tá a fi lè retí láti dojú kọ àdánwò àti ìdẹwò? (b) Báwo lo ṣe lè kẹ́sẹ járí bó o bá dojú kọ àdánwò?
18 Kì í ya àwọn èèyàn Jèhófà lẹ́nu bí wọ́n bá dojú kọ àdánwò, ìrẹ̀wẹ̀sì, inúnibíni àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Ayé ò fìgbà kan fẹ́ràn àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Jòh. 15:17-19) Síbẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti borí ìpèníjà èyíkéyìí tó ṣeé ṣe ká bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Jèhófà kò ní jẹ́ kí a dán wa wò ju bí ó ti yẹ lọ. (1 Kọ́r. 10:13) Kò jẹ́ fi wá sílẹ̀ tàbí kó kọ̀ wá sílẹ̀ lọ́nàkọnà. (Héb. 13:5) Bá a bá ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí, ó máa dáàbò bò wá ó sì máa fún wa lókun. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀mí Ọlọ́run tún lè sún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láti ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá nílò irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ jù lọ.
19 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó láti béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ nípa gbígbàdúrà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Ǹjẹ́ ká sì tún máa bá a nìṣó láti di ẹni ‘tí a ń sọ di alágbára pẹ̀lú gbogbo agbára dé ìwọ̀n agbára ńlá [Ọlọ́run] ológo ká bàa lè fara dà á ní kíkún, ká sì máa ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.’—Kól. 1:11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Bí àpẹẹrẹ, wo Ilé Ìṣọ́, May 1, 2001, ojú ìwé 16; àti Jí! February 8, 1993, ojú ìwé 21 àti 22.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀ láti fara da inúnibíni?
• Kí ló yẹ kó o ṣe bí ẹnì kan bá sọ fún ẹ pé kó o má ṣe tú àṣírí ìwà àìtọ́ tí òun hù?
• Bí ìpọ́njú èyíkéyìí bá dojú kọ ẹ́, kí ló yẹ kó dá ẹ lójú?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Kí la lè rí kọ́ lára Jóṣúà àti Kálébù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Báwo lo ṣe lè ran ọ̀rẹ́ rẹ kan tó hùwà àìtọ́ lọ́wọ́?