Ẹ̀mí Mímọ́ Ń fún Wa Lágbára Ká Lè Kojú Ìdẹwò Ká Sì Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì
Ẹ̀mí Mímọ́ Ń fún Wa Lágbára Ká Lè Kojú Ìdẹwò Ká Sì Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì
“Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín.”—ÌṢE 1:8.
1, 2. Ìrànlọ́wọ́ wo ni Jésù ṣèlérí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí sì nìdí tí wọ́n fi máa nílò ìrànlọ́wọ́ náà?
JÉSÙ mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa nílò ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n tó lè pa gbogbo ohun tó pa láṣẹ fún wọn mọ́. Iṣẹ́ ìwàásù wọn máa gbòòrò dé ibi tó pọ̀, àwọn tó ń ṣàtakò sí wọn pọ̀, wọ́n ní àìlera tó jẹ́ ti ẹ̀dá èèyàn, torí náà ó ṣe kedere pé wọ́n nílò agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó mú un dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8.
2 Ìlérí yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ láti Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi lágbára láti wàásù jákèjádò ìlú Jerúsálẹ́mù. Kò sí àtakò tó lè dá iṣẹ́ ìwàásù yẹn dúró. (Ìṣe 4:20) “Ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan,” àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Jésù yìí, àti àwa náà, máa rí i pé a nílò okun tí Ọlọ́run ń pèsè yìí ní kánjúkánjú.—Mát. 28:20.
3. (a) Ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀mí mímọ́ àti agbára. (b) Kí ni agbára tí Jèhófà ń pèsè lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe?
3 Jésù ṣèlérí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ‘wọ́n máa gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé wọn.’ “Agbára” àti “ẹ̀mí” jẹ́ ọ̀rọ̀ méjì tí ìtumọ̀ wọn yàtọ̀ síra. Ẹ̀mí Ọlọ́run, ìyẹn ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀, jẹ́ ohun tí Ọlọ́run máa ń rán jáde kó lè fún àwọn èèyàn tàbí ohun kan lágbára láti ṣe ohun tó fẹ́. Àmọ́, agbára ni “okun téèyàn ń lò tàbí tó fi ń ṣe nǹkan.” Agbára tí ẹnì kan tàbí ohun kan ní kò lè dá ṣe ohunkóhun àyàfi bí ẹni náà tàbí ohun náà bá lo agbára náà. Torí náà, a lè fi ẹ̀mí mímọ́ wé iná mànàmáná tó lè mú kí bátìrì fóònù tó ti kú pa dà ṣiṣẹ́, nígbà tí agbára ní tiẹ̀ dúró fún okun tí bátìrì náà gbà sára. Agbára tí Jèhófà máa ń tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa ń mú kí olúkúlùkù wa ní okun tá a lè fi ṣe ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́, nígbà tó bá pọn dandan, láti gbéjà ko agbára tó lè mú wa ṣe ohun tí kò tọ́.—Ka Míkà 3:8; Kólósè 1:29.
4. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí sì nìdí?
4 Báwo ni agbára tí Ọlọ́run tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ fún wa ṣe máa ń fara hàn? Bí ẹ̀mí mímọ́ bá ń ṣiṣẹ́ lára wa, àwọn nǹkan wo ló máa ń fún wa lókun láti ṣe? Bá a ti ń sapá láti fi òótọ́ sin Ọlọ́run, à ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro látọ̀dọ̀ Sátánì, ètò àwọn nǹkan rẹ̀ tàbí ẹran ara aláìpé tiwa fúnra wa. Ó ṣe pàtàkì pé ká borí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ ká lè máa bá a nìṣó bíi Kristẹni, ká máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù, ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè kojú ìdẹwò ká sì borí àárẹ̀ àti ìrẹ̀wẹ̀sì.
Ó Ń Fún Wa Lágbára Ká Lè Kojú Ìdẹwò
5. Báwo ni àdúrà ṣe lè fún wa lágbára?
5 Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (Mát. 6:13) Jèhófà kò ní kọ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n bá gba irú àdúrà yìí sílẹ̀. Jésù tún sọ ní àkókò mìíràn pé, “Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Ó mà fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an o, láti mọ̀ pé Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó máa jẹ́ ká lè ṣe ohun tó tọ́! Àmọ́, èyí kò túmọ̀ sí pé Jèhófà kò ní jẹ́ ká dán wa wò. (1 Kọ́r. 10:13) Ṣùgbọ́n bí a bá dojú kọ ìdẹwò, ìgbà yẹn gan-an ló yẹ ká túbọ̀ gbàdúrà kíkankíkan.—Mát. 26:42.
6. Báwo ni Jésù ṣe lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà tí Sátánì ń dán an wò?
6 Nígbà tí Èṣù ń dán Jésù wò, Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́. Ó hàn gbangba pé ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ́kàn nígbà tó fèsì pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé . . . A tún kọ̀wé rẹ̀ pé . . . Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’” Ìfẹ́ tí Jésù ní sí Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló mú kó kọ àwọn ohun tí Adẹniwò náà fẹ́ láti fi tàn án jẹ. (Mát. 4:1-10) Lẹ́yìn tí Jésù ti kọ àwọn ìdẹwò Sátánì léraléra, ńṣe ló fi Jésù sílẹ̀.
7. Báwo ni Bíbélì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè kojú ìdẹwò?
7 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ ni Jésù lò láti fi kojú àwọn ìdẹwò Èṣù, mélòó mélòó ló yẹ káwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀! Òótọ́ ibẹ̀ ni pé tá a bá fẹ́ dènà Èṣù àtàwọn ohun tó ń lò, a gbọ́dọ̀ ṣe tán láti mọ àwọn ìlànà Ọlọ́run ká sì jẹ́ kí wọ́n máa darí wa nígbà gbogbo. Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ ti mú kí wọ́n máa ṣègbọràn sí àwọn ìlànà Bíbélì, wọ́n sì ti wá mọrírì ọgbọ́n àti òdodo Ọlọ́run. Dájúdájú, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ń sa agbára tó lè fi òye mọ “ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Héb. 4:12) Béèyàn bá ṣe ń ka Ìwé Mímọ́ tó sì ń ronú lórí ohun tó ń kà tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe túbọ̀ máa ní ‘ìjìnlẹ̀ òye nípa òótọ́ Jèhófà.’ (Dán. 9:13) Nípa báyìí, ó máa ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ bá a bá ń ro àròjinlẹ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá sọ̀rọ̀ nípa ibi tí a kù sí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.
8. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà rí ẹ̀mí mímọ́ gbà?
8 Yàtọ̀ sí pé Jésù mọ Ìwé Mímọ́, ohun tó tún mú kó ṣeé ṣe fún un láti kojú ìdẹwò ni pé ó “kún fún ẹ̀mí mímọ́.” (Lúùkù 4:1) Kí àwa náà bàa lè ní okun àti agbára bíi ti Jésù, a gbọ́dọ̀ sún mọ́ Jèhófà nípa wíwá bá a ṣe lè jàǹfààní kíkún látinú àwọn ọ̀nà tó ń gbà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Ják. 4:7, 8) Lára àwọn ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àdúrà àti kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ará sì ti wá mọrírì àǹfààní tó wà nínú lílọ́wọ́ sí gbogbo àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni yìí, torí pé ó ń mú kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí èrò tẹ̀mí tí ń gbéni ró.
9, 10. (a) Àwọn ìdẹwò wo ló wọ́pọ̀ ní àdúgbò yín? (b) Báwo ni àṣàrò àti àdúrà ṣe lè fún ẹ lágbára kó o lè kojú ìdẹwò nígbà tí agbára rẹ kò bá tó nǹkan pàápàá?
9 Àwọn nǹkan tó lè sún ẹ dẹ́ṣẹ̀ wo ló yẹ kó o sá fún? Ṣó ti ṣe ẹ́ rí bíi kó o máa bá ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ tage? Bí o kò bá tíì ṣègbéyàwó, ṣó ti ṣe ẹ́ rí bíi kí ìwọ àti aláìgbàgbọ́ jọ máa fẹ́ra yín? Bí Kristẹni kan bá ń wo tẹlifíṣọ̀n tàbí tó bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó lè dojú kọ ìdẹwò láti wo ohun tó ń mọ́kàn fà sí ìṣekúṣe. Ṣé irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí? Tó bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, kí lo ṣe nípa rẹ̀? Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o ṣe àṣàrò lórí bí àṣìṣe kan ṣe lè yọrí sí àṣìṣe mìíràn kó tó wá yọrí sí dídá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. (Ják. 1:14, 15) Ronú lórí bó ṣe máa dun Jèhófà tó bó o bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì àti ìpalára tó máa mú bá ìjọ àti ìdílé rẹ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, bó o bá ń jẹ́ káwọn ìlànà Ọlọ́run máa darí rẹ, wàá ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Ka Sáàmù 119:37; Òwe 22:3.) Nígbàkigbà tó o bá dojú kọ irú àwọn ohun tó lè dánni wò bẹ́ẹ̀, múra tán láti gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ ní okun tí wàá fi lè dènà rẹ̀.
10 Ohun kan tún wà tó yẹ ká rántí nípa àwọn ìdẹwò Èṣù. Sátánì lọ bá Jésù lẹ́yìn tó ti ń gbààwẹ̀ fún ogójì ọjọ́ nínú aginjù. Èṣù ti ní láti rò pé èyí jẹ́ ‘àkókò tí ó wọ̀’ jù lọ láti dán ìwà títọ́ Jésù wò. (Lúùkù 4:13) Àkókò tó wọ̀ ni Sátánì ń wá, kó lè dán ìwà títọ́ tiwa náà wò. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ìgbà tí Sátánì bá rí i pé ọwọ́ òun lè tètè tẹ̀ wá jù lọ ló máa ń gbéjà kò wá. Torí náà, nígbàkigbà tó bá rẹ̀ wá tàbí tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, ó yẹ ká túbọ̀ múra tán láti bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ nípa dídáàbò bò wá, kó sì fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.—2 Kọ́r. 12:8-10.
Ó Ń Fún Wa Lágbára Ká Lè Borí Àárẹ̀ àti Ìrẹ̀wẹ̀sì
11, 12. (a) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí fi ń rẹ̀wẹ̀sì? (b) Kí ló lè fún wa lágbára ká má bàa rẹ̀wẹ̀sì?
11 Torí pé a jẹ́ ẹ̀dá aláìpé, a máa ń rẹ̀wẹ̀sì látìgbàdégbà. Bóyá ohun tó sì fà á tí ìyẹn fi wọ́pọ̀ gan-an lónìí ni pé ìnira pọ̀ gan-an ní àkókò tá à ń gbé yìí. Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé àkókò lílekoko jù lọ tí aráyé pátá tíì rí irú rẹ̀ rí là ń gbé yìí. (2 Tím. 3:1-5) Bí Amágẹ́dọ́nì ṣe ń sún mọ́lé, bẹ́ẹ̀ ni ìṣòro ìṣúnná owó, ìdààmú ọkàn, àtàwọn ìṣòro míì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Nígbà náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ó túbọ̀ ń ṣòro fún àwọn kan láti ṣe ojúṣe wọn bó bá dọ̀ràn kí wọ́n tọ́jú ìdílé wọn, kí wọ́n sì pèsè àwọn nǹkan tara tí wọ́n nílò. Ó máa ń sú wọn, ó máa ń rẹ̀ wọ́n, kódà agara máa ń dá wọn. Bó bá jẹ́ pé bí ọ̀ràn tìrẹ náà ṣe rí nìyẹn, báwo lo ṣe lè kojú àwọn ìṣòro náà?
12 Rántí pé Jésù mú kó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé òun máa fún wọn ní olùrànlọ́wọ́, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Ka Jòhánù 14:16, 17.) Ẹ̀mí mímọ́ yìí ni ipá tó ga jù lọ láyé àti lọ́run. Nípasẹ̀ rẹ̀ Jèhófà lè pèsè “ọ̀pọ̀ yanturu ré kọjá” okun tá a nílò láti fara da àdánwò èyíkéyìí. (Éfé. 3:20) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé bá a bá gbára lé ẹ̀mí mímọ́, a máa gba “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé a “há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà.” (2 Kọ́r. 4:7, 8) Jèhófà kò ṣèlérí pé òun máa mú ìnira kúrò, àmọ́ ó mú un dá wa lójú pé òun á máa lo ẹ̀mí mímọ́ òun láti fún wa lágbára ká lè fara dà á.—Fílí. 4:13.
13. (a) Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ran ọ̀dọ́ kan lọ́wọ́ láti kojú ipò tó le koko? (b) Ǹjẹ́ o mọ àwọn míì tí ẹ̀mí mímọ́ ti ràn lọ́wọ́ lọ́nà yìí?
13 Gbé àpẹẹrẹ Stephanie, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé yẹ̀ wò. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá, ó ní àrùn rọpárọsẹ̀, àyẹ̀wò ìṣègùn sì fi hàn pé kókó ọlọ́yún wà nínú ọpọlọ rẹ̀. Láti ìgbà náà wá, wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ fún un nígbà méjì, ó tún gba ìtọ́jú onítànṣán, ó sì tún ní àrùn rọpárọsẹ̀ nígbà méjì sí i, èyí tó mú kó ṣòro fún un láti lo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ òsì, kò sì ríran dáadáa mọ́. Ó wá di pé kí Stephanie máa lo ìwọ̀nba okun tó kù fún un láti máa ṣe àwọn nǹkan tó kà sí pàtàkì jù lọ, irú bíi lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni àti òde ẹ̀rí. Síbẹ̀, ó máa ń nímọ̀lára pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń fún òun lókun, ó sì ń ran òun lọ́wọ́ láti fara dà á ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà. Àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì tó sọ ìrírí àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, ti gbé e ró láwọn ìgbà tó rẹ̀wẹ̀sì. Àwọn ará ṣètìlẹ́yìn fún un nípa kíkọ lẹ́tà sí i tàbí nípa bíbá a sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ń gbéni ró ṣáájú àti lẹ́yìn ìpàdé. Àwọn olùfìfẹ́hàn pẹ̀lú fi ìmọrírì hàn fún ohun tí Stephanie ń kọ́ wọn nípa lílọ sí ilé rẹ̀ kó lè kọ́ wọ́n lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbogbo èyí ń jẹ́ kí Stephanie gbà pé ó yẹ kí òun máa dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó yàn láàyò jù lọ ni Sáàmù 41:3, tó gbà pé ó ti ṣẹ sí òun lára.
14. Kí ni a kò gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, kí sì nìdí?
14 Tó bá rẹ̀ wá tàbí tá a bá ń ní ohun tó pọ̀ jù láti ṣe, a kò gbọ́dọ̀ ronú pé fífa ọwọ́ ìgbòkègbodò tẹ̀mí sẹ́yìn ni ọ̀nà tó yẹ ká gbà bójú tó ìṣòro náà. Ìyẹn ni ohun tó burú jù lọ tá a lè ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé irú àwọn ìgbòkègbodò bíi dídá kẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, iṣẹ́ ìwàásù àti lílọ sí ìpàdé jẹ́ àwọn ọ̀nà tá a fi ń rí ẹ̀mí mímọ́ tó ń sọ agbára wa dọ̀tun gbà. Àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni sì máa ń tuni lára ní gbogbo ìgbà. (Ka Mátíù 11:28, 29.) Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé á ti rẹ àwọn ará kí wọ́n tó dé ìpàdé, àmọ́ tí wọ́n bá ń lọ sílé lẹ́yìn ìpàdé, ńṣe ló máa ń dà bíi pé a ti sọ agbára wọn dọ̀tun, tí ara wọn á sì yá gágá!
15. (a) Ǹjẹ́ Jèhófà ṣèlérí pé gbogbo nǹkan tí Kristẹni kan bá nílò lòun á máa fún un lọ́nà gbẹ̀fẹ́? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan látinú Ìwé Mímọ́. (b) Kí ni Ọlọ́run ṣèlérí fún wa, ìbéèrè wo nìyẹn sì mú wá?
15 Èyí kò túmọ̀ sí pé ó rọrùn láti jẹ́ Kristẹni. Ó gba ìsapá láti jẹ́ Kristẹni olóòótọ́. (Mát. 16:24-26; Lúùkù 13:24) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà lè fi okun fún ẹni tó bá rẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Wòlíì Aísáyà kọ̀wé pé: “Àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà. Wọn yóò fi ìyẹ́ apá ròkè bí idì. Wọn yóò sáré, agara kì yóò sì dá wọn; wọn yóò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.” (Aísá. 40:29-31) Torí náà, ó máa dára ká bi ara wa pé, Kí ló máa ń mú ká rò pé àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni ló ń mú kó rẹ̀ wá?
16. Kí la lè ṣe ká bàa lè dènà ohun tó lè fa àárẹ̀ tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì?
16 Ọ̀rọ̀ Jèhófà rọ̀ wá pé ká “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílí. 1:10) Nígbà tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé, ó fi ìgbésí ayé àwa Kristẹni wé eré ìje ẹlẹ́mìí ẹṣin, ó wá gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò . . . , ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.” (Héb. 12:1) Kókó inú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ni pé ká má ṣe máa lé àwọn nǹkan tí kò lè ṣe wá láǹfààní, ká má sì máa di ẹrù tí kò tọ́, tó lè mú kó rẹ̀ wá, ru ara wa. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni àwọn kan nínú wa wulẹ̀ ń ṣe ju ara wọn lọ. Torí náà, bó bá sábà máa ń rẹ̀ ẹ́, tó o sì ń ní ohun tó pọ̀ jù láti ṣe, ó lè ṣe ẹ́ láǹfààní bó o bá ń ṣe àgbéyẹ̀wò bí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ṣe ń gba àkókò rẹ tó, bó o ṣe ń rìnrìn àjò lemọ́lemọ́ tó láti lọ gbafẹ́ àti bó o ṣe ń lọ́wọ́ nínú eré ìdárayá àtàwọn eré ìtura míì sí. Bí gbogbo wá bá ń lo òye tá a sì mọ̀wọ̀n ara wa, ìyẹn á jẹ́ ká lè mọ ibi tí agbára wá mọ ká sì dín àwọn ìgbòkègbodò tí kò bá pọn dandan kù pátápátá.
17. Kí ló lè mú kí àwọn kan rẹ̀wẹ̀sì, kí ni Jèhófà sì mú kó dá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lójú?
17 Ó tún lè jẹ́ pé ohun tó ń mú kí àwọn kan lára wa rẹ̀wẹ̀sì ni bí òpin ètò àwọn nǹkan yìí kò ṣe tíì dé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe retí. (Òwe 13:12) Àmọ́ ṣá o, ẹnikẹ́ni tó bá ń ronú lọ́nà yìí lè rí ìṣírí látinú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Hábákúkù 2:3, tó sọ pé: “Ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, ó sì ń sáré lọ ní mímí hẹlẹhẹlẹ sí òpin, kì yóò sì purọ́. Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.” Ọ̀rọ̀ Jèhófà mú kó dá wa lójú pé òpin ètò àwọn nǹkan yìí máa dé ní àkókò tí Ọlọ́run fẹ́ kó dé gan-an!
18. (a) Àwọn ìlérí wo ló ń fún ẹ lókun? (b) Báwo ni àpilẹ̀kọ tó kàn ṣe máa ṣe wá láǹfààní?
18 Dájúdájú gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí kò ní sí àárẹ̀ àti ìrẹ̀wẹ̀sì mọ́, tí gbogbo èèyàn á sì máa gbádùn “okun inú ti ìgbà èwe.” (Jóòbù 33:25) Kódà, bá a ṣe ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí tó ń gbéni ró nísinsìnyí, ẹ̀mí mímọ́ lè sọ wa di alágbára ńlá ní ti ẹni tí a jẹ́ ní inú. (2 Kọ́r. 4:16; Éfé. 3:16) Má ṣe jẹ́ kí àárẹ̀ gba ìbùkún ayérayé mọ́ ẹ lọ́wọ́. Gbogbo àdánwò tí ìdẹwò, àárẹ̀ tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń fà, kò ní sí mọ́. Bí kò tiẹ̀ jẹ́ lójú ẹsẹ̀, ó dájú pé wọ́n kò ní sí nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa ṣàgbéyẹ̀wò bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń fún àwa Kristẹni lágbára ká lè fara da inúnibíni, ká lè dènà ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, ká sì lè fara da àwọn ìpọ́njú mìíràn ní ọlọ́kan-kò-jọ̀kan.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni Bíbélì kíkà ṣe ń fún wa lágbára?
• Báwo ni àdúrà àti àṣàrò ṣe ń fún wa lágbára?
• Báwo lo ṣe lè dènà àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó mú ẹ rẹ̀wẹ̀sì?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn ìpàdé ìjọ lè sọ agbára wa dọ̀tun nípa tẹ̀mí