A Rí Orúkọ Ọlọ́run Níbi Àfonífojì
A Rí Orúkọ Ọlọ́run Níbi Àfonífojì
ṢÓ O ti gbọ́ orúkọ ibì kan tí wọ́n ń pè ní St. Moritz rí? Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ ọ rí, torí pé ibi ìgbafẹ́ kan táwọn èèyàn ti máa ń lọ lo àkókò ìsinmi wọn ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀; ó wà ní ibi Àfonífojì Engadine, lórílẹ̀-èdè Switzerland. Láti ọ̀pọ̀ ọdún ló ti máa ń wu àwọn èèyàn láti lọ síbi ìgbafẹ́ St. Moritz yìí kí wọ́n lè rí àwọn àfonífojì tó rẹwà, èyí tó wà láàárín àwọn òkè Alps tí yìnyín bò náà. Àwọn òkè yìí wà ní gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Switzerland nítòsí ibodè orílẹ̀-èdè Ítálì. Ọgbà ìtura kan tó ń jẹ́ Swiss National Park tún wà níbẹ̀, ẹwà tí Ọlọ́run fi jíǹkí àgbègbè fífanimọ́ra yìí àti onírúurú òdòdó àtàwọn ẹranko tó jojúnígbèsè tó wà níbẹ̀ tún ń fi ìyìn fún Jèhófà tó jẹ́ Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa. (Sm. 148:7-10) Ní àfikún sí ìyẹn, àṣà kan tó wọ́pọ̀ níbi àfonífojì náà láti àárín ọ̀rúndún kẹtàdínlógún wá, tún ń fi ìyìn fún Jèhófà.
Ó ṣeé ṣe kó o kíyè sí ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n gbà dárà sára ọ̀pọ̀ ilé tó wà ní àfonífojì yìí. Ó sì tún wọ́pọ̀ kéèyàn rí i tí wọ́n kọ orúkọ Ọlọ́run sára ilé,
bíi lára ilẹ̀kùn àbáwọlé. Ìdí ni pé láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ni àwọn tó ń gbébẹ̀ ti fẹ́ràn láti máa kọ nǹkan sára ilé láti fi ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, wọ́n lè fi ọ̀dà kọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀, wọ́n lè kọ ọ́ sára ilé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fi símẹ́ńtì rẹ́ tàbí kí wọ́n gbẹ́ ẹ sára òkúta. Àwòrán ilé kan tó wà ní abúlé Bever nìyí lójú ìwé yìí. Ìtumọ̀ ohun tí wọ́n kọ sára ilé náà kà pé: “Ní ọdún 1715. Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀, Jèhófà ni òpin. Ọlọ́run ló ń mú kí ohun gbogbo ṣeé ṣe, kò sẹ́ni tó lè ṣe ohunkóhun lẹ́yìn Ọlọ́run.” Ó ga o, ìgbà méjì lorúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gangan fara hàn lára àkọlé tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ yìí.O tún lè rí àkọlé míì tọ́jọ́ rẹ̀ pẹ́ ju ìyẹn lọ ní abúlé Madulain. Ó kà pé: “Sáàmù 127. Bí kò ṣe pé Jèhófà bá kọ́ ilé náà, àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣe iṣẹ́ àṣekára lórí rẹ̀ lásán. Lucius Rumedius. Ọdún 1654.”
Kí nìdí tí wọ́n fi kọ orúkọ Ọlọ́run síbi téèyàn ti lè rí i ní àfonífojì yìí? Ní àkókò tí àtúnṣe ẹ̀sìn ń lọ lọ́wọ́, wọ́n tẹ Bíbélì ní èdè Romansh, ìyẹn èdè kan tó wá látinú èdè Látìn, èyí tí wọ́n ń sọ níbi àfonífojì Engadine. Kódà, òun ni ìwé tí wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ sí èdè yẹn. Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní àfonífojì náà kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ wọ́n lọ́kàn débi pé lẹ́yìn tí wọ́n bá kọ orúkọ ara wọn síwájú ilé wọn tán, wọ́n tún máa ń kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ní orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gangan síbẹ̀.
Láti ìgbà tí wọ́n ti kọ́kọ́ kọ àwọn orúkọ náà sára àwọn ilé yẹn ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, àwọn orúkọ náà ṣì ń kéde orúkọ Jèhófà, wọ́n sì tún ń fi ìyìn fún un títí dòní. Tonílé tàlejò tó wà ní àfonífojì yìí la gbà níyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run àgbàyanu náà, Jèhófà, nípa lílọ sí ilé míì tá à ń fi orúkọ rẹ̀ pè, ìyẹn ni Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní abúlé Bever.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]
© Stähli Rolf A/age fotostock