Bọ̀wọ̀ fún Ìgbéyàwó Tó Jẹ́ Ẹ̀bùn Ọlọ́run
Bọ̀wọ̀ fún Ìgbéyàwó Tó Jẹ́ Ẹ̀bùn Ọlọ́run
“Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin yóò ṣe fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.”—JẸ́N. 2:24.
1. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà?
Ó YẸ ká máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run tó dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀. Òun ni Ẹlẹ́dàá wa, Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run àti Baba wa ọ̀run, torí náà ó tọ́ bí Bíbélì ṣe pè é ní Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Ják. 1:17; Ìṣí. 4:11) Èyí fi bí ìfẹ́ tó ní sí wa ṣe pọ̀ tó hàn. (1 Jòh. 4:8) Ire àti àǹfààní wa ni gbogbo ohun tó ti kọ́ wa, gbogbo ohun tó ń fẹ́ ká ṣe àti gbogbo nǹkan tó fi jíǹkí wa, wà fún.—Aísá. 48:17.
2. Àwọn ìtọ́ni wo ni Jèhófà fún àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́?
2 Bíbélì fi hàn pé ìgbéyàwó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn “rere” tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá yìí. (Rúùtù 1:9; 2:12) Nígbà tí Jèhófà so Ádámù àti Éfà pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya àkọ́kọ́, ó fún àwọn méjèèjì ní àwọn ìtọ́ni pàtó tó máa jẹ́ kí ìgbéyàwó wọn yọrí sí rere. (Ka Mátíù 19:4-6.) Ká ní wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí Ọlọ́run fún wọn ni, ayọ̀ wọn kò ní pẹ̀dín láé. Àmọ́ wọ́n hùwà òmùgọ̀ nípa kíkọ etí ikún sí àṣẹ Ọlọ́run, wọ́n sì jìyà àbájáde búburú.—Jẹ́n. 3:6-13, 16-19, 23.
3, 4. (a) Lóde òní, báwo ni ọ̀pọ̀ èèyàn kò ṣe bọ̀wọ̀ fún ìgbéyàwó àti Jèhófà Ọlọ́run mọ́? (b) Àwọn àpẹẹrẹ wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Bíi ti tọkọtaya àkọ́kọ́ yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí máa ń ṣe ìpinnu tó kan ìgbéyàwó láì fi bẹ́ẹ̀ bìkítà nípa ìtọ́sọ́nà Jèhófà tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ bìkítà nípa rẹ̀ rárá. Àwọn kan kò fẹ́ wọnú àdéhùn ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹnikẹ́ni, ẹni tí wọ́n á jọ máa gbé pọ̀ tàbí tí wọ́n á kàn jọ máa gbéra wọn sùn ni wọ́n ń wá. Ńṣe làwọn míì sì ń gbìyànjú láti yí ìlànà ìgbéyàwó pa dà kí wọ́n lè tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́rùn. (Róòmù 1:24-32; 2 Tím. 3:1-5) Wọ́n ti gbàgbé pé ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìgbéyàwó jẹ́ àti pé bí wọn kò bá sì bọ̀wọ̀ fún ẹ̀bùn yẹn, Jèhófà Ọlọ́run tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀ ni wọn kò bọ̀wọ̀ fún.
4 Nígbà míì àwọn èèyàn Ọlọ́run kan pàápàá kì í fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ìgbéyàwó wò ó. Àwọn tọkọtaya kan tó jẹ́ Kristẹni máa ń pínyà tàbí kí wọ́n kọra wọn sílẹ̀ bí kò tilẹ̀ sí ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu tí wọ́n fi ní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ni wọn ì bá ti ṣe tírú èyí kò fi ní wáyé? Báwo ni ìtọ́ni Ọlọ́run tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:24 ṣe lè ran àwọn Kristẹni tó jẹ́ tọkọtaya lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ ṣera wọn lọ́kan? Báwo sì làwọn tó ń gbèrò láti ṣègbéyàwó ṣe lè múra sílẹ̀ fún un? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ìgbéyàwó mẹ́ta tó yọrí sí rere nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, tó fi hàn bí bíbọ̀wọ̀ fún Jèhófà ṣe máa ń mú kí ìgbéyàwó wà pẹ́ títí.
Ẹ Jẹ́ Adúróṣinṣin
5, 6. Kí ni ohun tó ṣeé ṣe kó ti dán ìdúróṣinṣin Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì wo, èrè wo ni wọ́n sì rí gbà torí pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin?
5 Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì ṣe gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Torí pé àwọn méjèèjì fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà ni wọ́n ṣe fẹ́ra. Sekaráyà fòtítọ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà, àwọn méjèèjì sì pa Òfin Ọlọ́run mọ́ débi tí wọ́n lè ṣe é dé. Dájúdájú, ìdí ọpẹ́ wọn pọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ ká sọ pé o lọ sí ilé wọn ní ilẹ̀ Júdà, kò ní pẹ́ tí wàá fi kíyè sí i pé nǹkan kan wà tí wọn kò ní. Wọn kò bímọ. Èlísábẹ́tì yàgàn, àwọn méjèèjì sì ti darúgbó.—Lúùkù 1:5-7.
6 Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ojú pàtàkì ni wọ́n fi ń wo ọmọ bíbí, àwọn ìdílé sì máa ń ní ọmọ tó pọ̀ gan-an. (1 Sám. 1:2, 6, 10; Sm. 128:3, 4) Nígbà yẹn, ọmọ Ísírẹ́lì kan lè fi ẹ̀tàn kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ bí kò bá bí ọmọ kankan fún un. Síbẹ̀ Sekaráyà jẹ́ adúróṣinṣin ní ti pé kò kọ Èlísábẹ́tì sílẹ̀. Òun àti ìyàwó rẹ̀ kò wá àwáwí kankan torí kí wọ́n lè tú ìgbéyàwó wọn ká. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dùn mọ́ wọn nínú pé wọn kò bímọ, wọ́n jùmọ̀ ń bá a nìṣó láti máa fi òótọ́ sin Jèhófà. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, Jèhófà bù kún wọn torí ìdúróṣinṣin wọn, torí pé nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu, wọ́n bí ọmọkùnrin kan ní ọjọ́ ogbó wọn.—Lúùkù 1:8-14.
7. Ọ̀nà mìíràn wo ni Èlísábẹ́tì gbà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí ọkọ òun?
7 Ó yẹ ká gbóríyìn fún Èlísábẹ́tì torí ọ̀nà míì tó gbà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin. Nígbà tí Èlísábẹ́tì bí Jòhánù, Sekaráyà kò lè sọ̀rọ̀, áńgẹ́lì kan ti mú kó yadi torí pé ó ṣiyè méjì nípa ohun tí áńgẹ́lì náà sọ fún un. Síbẹ̀, Sekaráyà ti ní láti wá bó ṣe máa sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé “Jòhánù” ni áńgẹ́lì náà ní káwọn sọ ọmọkùnrin àwọn. Orúkọ bàbá ọmọ náà ni àwọn aládùúgbò àtàwọn ìbátan fẹ́ kí wọ́n sọ ọ́. Àmọ́ Èlísábẹ́tì jẹ́ adúróṣinṣin nípa títẹ̀lé ìtọ́ni tí ọkọ rẹ̀ fún un. Ó sọ pé: “Rárá o! ṣùgbọ́n Jòhánù ni a óò máa pè é.”—Lúùkù 1:59-63.
8, 9. (a) Báwo ní ìdúróṣinṣin ṣe máa ń mú kí tọkọtaya ṣera wọn lọ́kan? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà pàtó tí ọkọ àti aya lè gbà ṣera wọn lọ́kan?
8 Bíi ti Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì, àwọn tọkọtaya lónìí máa ń ní ìjákulẹ̀ àtàwọn ìṣòro míì. Bí tọkọtaya kò bá jẹ́ adúróṣinṣin, ìgbéyàwó wọn kò ní tọ́jọ́. Bíbá ẹlòmíì tage, wíwo àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, panṣágà àtàwọn ìṣòro míì tó ń dojú kọ ìgbéyàwó, lè mú kí tọkọtaya má lè fọkàn tán ara wọn mọ́. Bí tọkọtaya kò bá sì lè fọkàn tán ara wọn mọ́, ńṣe ni ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣá. Láwọn ọ̀nà kan, a lè fi ìdúróṣinṣin wé ọgbà tá a kọ́ yíká ilé kan, tí kì í jẹ́ kí àjèjì tàbí ohun tó léwu wọnú ilé wá, tó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ dáàbò bo àwọn tó wà nínú ilé náà. Bákan náà, bí tọkọtaya bá jẹ́ adúróṣinṣin tí wọn kò sì dalẹ̀ ara wọn, ohunkóhun kò ní ba àjọṣe wọn jẹ́, wọ́n á máa finú han ara wọn, wọ́n á sì túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Kò sí àní-àní pé ìdúróṣinṣin ṣe pàtàkì.
9 Jèhófà sọ fún Ádámù pé: ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀.’ (Jẹ́n. 2:24) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé ìyípadà má dé bá àjọṣe tó ti wà láàárín ọkọ tàbí aya náà pẹ̀lú àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Ọkọ àti aya náà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ máa lo àkókò pẹ̀lú ara wọn kí wọ́n sì máa wáyè tẹ́tí síra wọn. Wọn kò gbọ́dọ̀ máa fi àkókò tó yẹ kí wọ́n fi gbọ́ ti ìdílé wọn tuntun gbọ́ ti tẹbí tọ̀rẹ́; wọn kò sì gbọ́dọ̀ máa jẹ́ káwọn òbí dá sí ìpinnu ìdílé wọn tàbí kí wọ́n máa bá wọn parí aáwọ̀. Ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún tọkọtaya ni pé kí wọ́n ṣera wọn lọ́kan.
10. Kí ló máa ran tọkọtaya lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?
10 Nínú ìdílé tí tọkọtaya ti ń ṣe ẹ̀sìn tó yàtọ̀ síra pàápàá, ìdúróṣinṣin máa ń mú èrè wá. Arábìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí sọ pé: “Mo dúpẹ́ gan-an pé Jèhófà ti kọ́ mi láti máa tẹrí ba fún ọkọ mi àti láti máa ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un. Torí pé mo jẹ́ adúróṣinṣin, ó ti pé ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] báyìí tí mo ti ń fi ìfẹ́ bá ọkọ mi gbé, tí mo sì ń bọ̀wọ̀ fún un.” (1 Kọ́r. 7:10, 11; 1 Pét. 3:1, 2) Torí náà, sa gbogbo ipá rẹ kó o lè fi ọkọ tàbí aya rẹ lọ́kàn balẹ̀. Máa wá bó o ṣe lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ àti ìṣesí rẹ mú kó dá ọkọ tàbí aya rẹ lójú pé òun lẹni tó o kà sí pàtàkì jù lọ láyé. Torí náà, ọwọ́ rẹ ló kù sí láti má ṣe gba ẹnikẹ́ni láyè láti ba ìṣọ̀kan tó wà láàárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ jẹ́. (Ka Òwe 5:15-20.) Ron àti Jeannette, tí wọ́n ti ṣègbéyàwó ní ohun tó lé ní ọdún márùndínlógójì [35] sẹ́yìn, tí wọ́n sì ń láyọ̀, sọ pé, “Torí pé a jẹ́ adúróṣinṣin, tá a sì ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe, a láyọ̀, ìgbéyàwó wa sì yọrí sí rere.”
Ìṣọ̀kan Máa Ń Fún Ìgbéyàwó Lókun
11, 12. Báwo ni Ákúílà àti Pírísílà ṣe fọwọ́ sowọ́ pọ̀ (a) nínú ilé, (b) lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn àti (d) lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni?
11 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa Ákúílà àti Pírísílà tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, bó bá ti dárúkọ ọ̀kan kò lè ṣe kó máà dárúkọ ìkejì. Àwọn tọkọtaya tó wà níṣọ̀kan yìí jẹ́ àpẹẹrẹ rere nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ọkọ àti aya yóò di “ara kan.” (Jẹ́n. 2:24) Gbogbo ìgbà ni wọ́n jọ máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ nínú ilé wọn, lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn àti lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ dé sí ìlú Kọ́ríńtì, Ákúílà àti Pírísílà ní kó wá máa gbé nínú ilé àwọn, ó sì dájú pé, fún àwọn àkókò kan lẹ́yìn náà, ibẹ̀ ló fi ṣe ibùdó pàtàkì fún iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ní Éfésù, wọ́n yọ̀ǹda pé káwọn ará máa lo ilé wọn fún ṣíṣe àwọn ìpàdé ìjọ, wọ́n sì jùmọ̀ ń ran àwọn ẹni tuntun, irú bíi Àpólò lọ́wọ́, kí wọ́n lè lóye òtítọ́ dáadáa. (Ìṣe 18:2, 18-26) Lẹ́yìn náà ni tọkọtaya tó jẹ́ onítara yìí lọ sí ìlú Róòmù, wọ́n sì tún yọ̀ǹda pé káwọn ará máa lo ilé wọn tó wà níbẹ̀ fún ṣíṣe àwọn ìpàdé ìjọ. Nígbà tó yá, wọ́n pa dà wá sí Éfésù, wọ́n sì ń fún àwọn ará lókun.—Róòmù 16:3-5.
12 Fún àwọn àkókò kan, iṣẹ́ àgọ́ pípa ni Ákúílà, Pírísílà àti Pọ́ọ̀lù fi ń gbọ́ bùkátà ara wọn. Tọkọtaya yìí sì tún fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ náà, wọn kò bára wọn díje, kò sì sí gbọ́nmi-sí-i-omi-ò-to láàárín wọn. (Ìṣe 18:3) Àmọ́ ṣá o, ọwọ́ pàtàkì táwọn méjèèjì fi mú iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run ló mú kí ìgbéyàwó wọn fẹsẹ̀ múlẹ̀ tí wọ́n sì ń láyọ̀. Yálà ní ìlú Kọ́ríńtì ni o tàbí ní Éfésù tàbí ní Róòmù, gbogbo àwọn ará ló mọ̀ wọ́n sí ‘alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú Kristi Jésù.’ (Róòmù 16:3) Wọ́n ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tẹ̀ síwájú níbikíbi tí wọ́n bá ti sìn.
13, 14. (a) Àwọn nǹkan wo ló lè wu ìṣọ̀kan ìgbéyàwó léwu? (b) Àwọn nǹkan wo ni àwọn tọkọtaya lè ṣe kí wọ́n lè máa ṣe nǹkan pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí “ara kan”?
13 Bí tọkọtaya bá ní àfojúsùn kan náà tí wọ́n sì jọ ń ṣe nǹkan pa pọ̀, ó dájú pé wọ́n máa túbọ̀ ṣera wọn lọ́kan. (Oníw. 4:9, 10) Ó bani nínú jẹ́ pé àkókò tí ọ̀pọ̀ tọkọtaya ń lò pa pọ̀ lónìí kò tó nǹkan. Kálukú wọn ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ tirẹ̀. Ilé iṣẹ́ máa ń rán àwọn míì káàkiri tàbí kí wọ́n lọ máa dá ṣiṣẹ́ lókè òkun kí wọ́n sì máa fi owó ránṣẹ́ sílé. Kódà àwọn tọkọtaya kan kì í rí ti ẹnì kejì wọn rò nígbà tí wọ́n bá wà nílé torí àwọn nǹkan míì máa ń gba àkókò wọn, bíi kí wọ́n máa wo tẹlifíṣọ̀n, kí wọ́n máa ṣe ohun kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, ó sì lè jẹ́ eré ìdárayá, gbígbá géèmù orí kọ̀ǹpútà tàbí lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ṣé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nínú ìdílé tiyín náà nìyẹn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ẹ lè ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ, kẹ́ ẹ lè túbọ̀ máa wà pa pọ̀? Ṣé ẹ lè jọ máa lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ilé bíi gbígbọ́únjẹ, fífọ abọ́ tàbí kẹ́ ẹ jọ máa roko àárín ọgbà? Ṣé ẹ lè máa jùmọ̀ bójú tó àwọn ọmọ tàbí àwọn òbí yín tí wọ́n ti darúgbó?
14 Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kẹ́ ẹ jọ máa lọ́wọ́ déédéé nínú àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà. Jíjùmọ̀ ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ àti ṣíṣe Ìjọsìn Ìdílé jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ tí èrò yín fi lè dọ́gba, kẹ́ ẹ sì ní àfojúsùn kan náà. Ẹ tún jọ máa lọ sóde ẹ̀rí. Bó bá ṣeé ṣe, ẹ gbìyànjú láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé oṣù kan tàbí ọdún kan ní ipò yín yọ̀ǹda pé kẹ́ ẹ fi ṣe é. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:58.) Arábìnrin kan tí òun àti ọkọ rẹ̀ jọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sọ pé: “Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà lo àkókò pa pọ̀ ká sì bára wa sọ̀rọ̀. Torí pé àfojúsùn àwa méjèèjì ni pé ká máa ran àwọn tá a bá ń bá pàdé lóde ẹ̀rí lọ́wọ́, ó jẹ́ kí n nímọ̀lára pé a mọwọ́ ara wa gan-an. Mo túbọ̀ sún mọ́ ọkọ mi gan-an, a sì túbọ̀ di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.” Bẹ́ ẹ ṣe jùmọ̀ ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tó gbámúṣé, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ohun tẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ sí, àwọn ohun tẹ́ ẹ̀ ń fi sípò àkọ́kọ́ àti ìwà yín á túbọ̀ máa jọra, títí tí ẹ ó fi túbọ̀ máa ronú, tẹ́ ẹ ó máa nímọ̀lára, tẹ́ ẹ ó sì máa ṣe nǹkan pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí “ara kan” bó ti rí nínú ọ̀rọ̀ ti Ákúílà àti Pírísílà.
Fi Ọlọrun Ṣípò Àkọ́kọ́ Nínú Ìgbéyàwó Rẹ
15. Kí ló lè mú kí ìgbéyàwó yọrí sí rere? Ṣàlàyé.
15 Jésù mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn fi Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbéyàwó. Ó ṣojú rẹ̀ nígbà tí Jèhófà so Ádámù àti Éfà pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. Ó rí bí wọ́n ṣe láyọ̀ tó nígbà tí wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún wọn, ó sì rí wàhálà tí wọ́n kó sí nígbà tí wọn kò tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run mọ́. Torí náà, nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn míì, ó mẹ́nu ba ìtọ́ni Bàbá rẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:24. Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mát. 19:6) Nítorí náà, níní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà ṣì ni ohun tó lè mú kí ìgbéyàwó láyọ̀ kó sì yọrí sí rere. Jósẹ́fù àti Màríà, tí wọ́n jẹ́ òbí Jésù lórí ilẹ̀ ayé, fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ nípa èyí.
16. Báwo ni Jósẹ́fù àti Màríà ṣe fi Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nínú ìdílé wọn?
16 Jósẹ́fù fi inúure hàn sí Màríà ó sì bọ̀wọ̀ fún un. Nígbà tó kọ́kọ́ gbọ́ pé ó ti lóyún, ńṣe ló fẹ́ láti fi àánú hàn sí i, kó tó di pé áńgẹ́lì Ọlọ́run ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Màríà fún un. (Mát. 1:18-20) Gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya, wọ́n ṣègbọràn sí àṣẹ Késárì wọ́n sì ṣe ohun tí Òfin Mósè pa láṣẹ fún wọn. (Lúùkù 2:1-5, 21, 22) Bákan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin nìkan ni òfin sọ pé kí wọ́n máa lọ síbi àjọ̀dún ìsìn pàtàkì tí wọ́n máa ń ṣe ní Jerúsálẹ́mù, Jósẹ́fù àti Màríà, àtàwọn ará ilé rẹ̀, máa ń lọ síbẹ̀ lọ́dọọdún. (Diu. 16:16; Lúùkù 2:41) Lọ́nà yìí àti ní àwọn ọ̀nà míì, àwọn tọkọtaya tó jẹ́ olùfọkànsìn yìí sapá láti ṣe ohun tó máa múnú Jèhófà dùn, wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún àwọn ohun tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn rẹ̀. Abájọ tí Jèhófà fi yàn wọ́n láti bójú tó Ọmọ òun níbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.
17, 18. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni tọkọtaya lè gbà fi Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nínú ìdílé wọn? (b) Báwo lèyí ṣe máa ṣe wọ́n láǹfààní?
17 Ṣé Ọlọ́run ni ẹ̀yin náà fi sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìdílé yín? Bí àpẹẹrẹ, kẹ́ ẹ tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, ǹjẹ́ ẹ kọ́kọ́ máa ń ṣe ìwádìí nípa àwọn ìlànà Bíbélì, kẹ́ ẹ gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà, kẹ́ ẹ sì tún gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀? Àbí ohun tẹ́ ẹ bá rò nípa ọ̀rọ̀ náà tàbí ohun tí tẹbí tọ̀rẹ́ yín bá sọ lẹ máa ń fẹ́ fi yanjú ìṣòro? Ǹjẹ́ ẹ máa ń sapá láti fi ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tó dá lórí ìgbéyàwó àti ìdílé, tí ẹrú olóòótọ́ náà ń tẹ̀ jáde sílò? Àbí ńṣe lẹ̀ ń tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀ tàbí èrò tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn? Ṣé ẹ jọ máa ń gbàdúrà, ṣé ẹ sì jọ ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ déédéé? Ṣé ẹ ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí, ṣé ẹ sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ìdílé yín fi sípò àkọ́kọ́?
18 Ray, tí ayọ̀ wọn kò pẹ̀dín láti àádọ́ta [50] ọdún tí wọ́n ti ṣègbéyàwó sọ pé, “A kò tíì ní ìṣòro tí kò ṣeé yanjú, ìdí sì ni pé a kò yé fi Jèhófà ṣe ọ̀kan lára ‘okùn onífọ́nrán mẹ́ta’ wa.” (Ka Oníwàásù 4:12.) Danny àti Trina tí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ràn lọ́wọ́ sọ pé: “Bá a ṣe jùmọ̀ ń sin Ọlọ́run túbọ̀ ń fún ìgbéyàwó wa lókun.” Ó ti lé lọ́dún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] tí wọ́n ti ṣègbéyàwó báyìí, ayọ̀ wọn kò sì pẹ̀dín. Bó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ẹ̀ ń fi Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbéyàwó yín, Ó máa mú kẹ́ ẹ ṣàṣeyọrí, ó sì máa bù kún yín jìngbìnnì.—Sm. 127:1.
Máa Fi Hàn Pé Ò Ń Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀bùn Ìgbéyàwó
19. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fúnni ní ẹ̀bùn ìgbéyàwó?
19 Ohun kan ṣoṣo tó jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn lógún lónìí ni bí wọ́n ṣe máa láyọ̀. Àmọ́ ojú tí ìránṣẹ́ Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn náà yàtọ̀. Ó mọ̀ pé Ọlọ́run dá ìgbéyàwó sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn tó máa mú ohun tí Ó ní lọ́kàn ṣẹ. (Jẹ́n. 1:26-28) Ká ní Ádámù àti Éfà ti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀bùn yẹn ni, gbogbo ayé ì bá ti di Párádísè tó kún fún àwọn olódodo tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń láyọ̀.
20, 21. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kí a ka ìgbéyàwó sí ohun mímọ́? (b) Ẹ̀bùn wo la máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀?
20 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run rí ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fi ògo fún Jèhófà. (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:31.) Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, ìdúróṣinṣin, ìṣọ̀kan àti fífi Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbéyàwó máa ń múnú Jèhófà dùn ó sì máa ń fún ìgbéyàwó lókun. Torí náà, yálà à ń múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó ni o, tàbí à ń fún ìgbéyàwó wa lókun, tàbí à ń gbìyànjú láti yanjú ìṣòro tó wà nínú ìgbéyàwó wa, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ohun tí ìgbéyàwó jẹ́ gan-an, ìyẹn ni ètò tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ tó sì jẹ́ mímọ́. Bá a bá fi òtítọ́ yìí sọ́kàn, ó máa mú ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká lè máa gbé àwọn ìpinnu tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìgbéyàwó karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lọ́nà yìí, a ó máa fi hàn pé kì í ṣe ìgbéyàwó nìkan là ń bọ̀wọ̀ fún, ṣùgbọ́n a tún ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Olùfúnni ní ẹ̀bùn yẹn.
21 Àmọ́ ìgbéyàwó nìkan kọ́ ni ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa; kì í sì í ṣe òun nìkan ló máa mú kí ìgbésí ayé èèyàn láyọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ wa tó kàn, á máa jíròrò ẹ̀bùn iyebíye mìíràn tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ni ẹ̀bùn wíwà láìní ọkọ tàbí aya.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
• Báwo ni jíjẹ́ adúróṣinṣin ṣe lè ran àwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó lọ́wọ́?
• Bí tọkọtaya bá ṣera wọn lọ́kan, báwo ló ṣe máa fún ìgbéyàwó wọn lókun?
• Kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà tí àwọn tó ti ṣègbéyàwó lè gbà fi Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tó dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ṣíṣe nǹkan pa pọ̀ máa ń mú kí tọkọtaya ṣera wọn lọ́kan