Máa Ṣe Àṣàrò Lórí Ohun tí Jèhófà Ti Ṣe fún Ẹ
Máa Ṣe Àṣàrò Lórí Ohun tí Jèhófà Ti Ṣe fún Ẹ
KÉTÉ lẹ́yìn tí Ọlọ́run jí Jésù dìde, méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń rìn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Ẹ́máọ́sì. Ìwé Ìhìn Rere Lúùkù sọ pé: “Bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ pọ̀, tí wọ́n sì ń jíròrò, Jésù fúnra rẹ̀ sún mọ́ tòsí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn rìn; ṣùgbọ́n a pa ojú wọn mọ́ kúrò nínú dídá a mọ̀.” Lẹ́yìn náà ni Jésù sọ fún wọn pé: “‘Kí ni ọ̀ràn wọ̀nyí tí ẹ ń bá ara yín fà bí ẹ ti ń rìn lọ?’ Wọ́n sì dúró jẹ́ẹ́ pẹ̀lú ojú fífàro.” Kí ló fà á tí wọ́n fi fajú ro? Ohun tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn ń retí nígbà yẹn ni pé kí Jésù gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ àwọn Kèfèrí tó ń mú wọn sìn, àmọ́ ọ̀nà kò gba ibi tí wọ́n fojú sí. Dípò bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n pa Jésù. Ìyẹn ló mú kí wọ́n fajú ro.—Lúùkù 24:15-21; Ìṣe 1:6.
Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í fèrò wérò pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. “Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Mósè àti gbogbo àwọn Wòlíì, ó túmọ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹmọ́ ara rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn.” Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó ń fún ìgbàgbọ́ lókun sì wáyé lóòótọ́ nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀! Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ti gbọ́ àlàyé tí Jésù ṣe fún wọn, wọ́n tújú ká. Lẹ́yìn náà, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, wọ́n sọ pé: “Ọkàn-àyà wa kò ha ń jó fòfò bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ ní ojú ọ̀nà, bí ó ti ń ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún wa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́?” (Lúùkù 24:27, 32) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú bí ọ̀rọ̀ Jésù ṣe rí lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
Báwo Ló Ṣe Máa Ń Rí Lára Wa Bí Ohun Tá À Ń Retí Kò Bá Ṣẹlẹ̀?
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì tí wọ́n ń lọ sí Ẹ́máọ́sì náà fajú ro torí pé ohun tí wọ́n ń retí kò ṣẹlẹ̀. Ohun tí Òwe 13:12 sọ ló ṣẹlẹ̀ sí wọn. Ó sọ pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.” Bákan náà, a rí àwọn kan lára wa tó ti ń fòótọ́ sin Jèhófà láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn tí wọ́n retí pé ó yẹ kí “ìpọ́njú ńlá” náà ti wáyé. (Mát. 24:21; Ìṣí. 7:14) Ní báyìí, kò yani lẹ́nu pé irú ohun tí wọ́n ń retí, àmọ́ tí kò ṣẹlẹ̀ yìí lè mú kí wọ́n banú jẹ́.
Àmọ́, rántí pé ńṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn tújú ká lẹ́yìn tí Jésù ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ní ìmúṣẹ, tí díẹ̀ lára èyí sì ṣojú àwọn fúnra wọn. Bí a bá ṣe bíi tiwọn, àwa náà lè máa láyọ̀ ká sì borí ohun tó bá ń mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Arákùnrin kan tó ń jẹ́
Michael, tó ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ọ̀pọ̀ ọdún, sọ pé: “Má ṣe máa ronú ju bó ṣe yẹ lọ nípa ohun tí Jèhófà kò tíì ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o máa ṣe àṣàrò lórí ohun tó ti ṣe.” Ìmọ̀ràn àtàtà mà lèyí o!Ohun Tí Jèhófà Ti Ṣe
Gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ohun títayọ tí Jèhófà ti ṣe. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, ẹni yẹn pẹ̀lú yóò ṣe àwọn iṣẹ́ tí èmi ń ṣe; yóò sì ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí.” (Jòh. 14:12) Iṣẹ́ tó tóbi jù lọ ti Kristẹni èyíkéyìí tíì ṣe rí làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń ṣe lónìí. Àwọn èèyàn tó ti lé ní mílíọ̀nù méje báyìí ni wọ́n ń fojú sọ́nà fún líla ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ já. Ìyàlẹ́nu gbáà nìyẹn jẹ́, torí pé kò tíì ṣẹlẹ̀ rí pé kí iye àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ń fìtara sìn ín ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ káàkiri ayé pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí! Dájúdájú, Jèhófà ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti ṣe “àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí” lọ, bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀.
Ohun mìíràn wo ni Jèhófà tún ti ṣe fún wa? Ó ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ láti jáde kúrò nínú ayé burúkú yìí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó sì mú wọn kọjá sínú Párádísè tẹ̀mí tó fi jíǹkí àwọn èèyàn rẹ̀. (2 Kọ́r. 12:1-4) Wá àkókò láti ronú jinlẹ̀ lórí díẹ̀ lára àwọn ìpèsè tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa, èyí tá à ń gbádùn nínú Párádísè tẹ̀mí náà. Bí àpẹẹrẹ, wo ibi ìkówèésí tó wà nílé rẹ tàbí èyí tó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wo ìwé atọ́ka náà, Watch Tower Publications Index tàbí kó o ṣí Watchtower Library wò lórí kọ̀ǹpútà. Tẹ́tí sí àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tá a gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀. Rántí àwọn ohun tó o gbọ́ àtàwọn ohun tó o rí ní àpéjọ àgbègbè kan láìpẹ́ yìí. Ní àfikún sí ìyẹn, ronú nípa ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ gbígbámúṣé tá a máa ń gbádùn pẹ̀lú àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Àfi ká máa ṣọpẹ́ pé ìwà ọ̀làwọ́ Jèhófà ń mú kó pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí fún wa, ó sì tún jẹ́ ká wà lára ẹgbẹ́ ará tó ń fìfẹ́ hàn síra wọn. Inú Párádísè tẹ̀mí la wà lóòótọ́!
Onísáàmù náà Dáfídì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa.” (Sm. 40:5) Ó dájú pé bá a bá ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe fún wa tá a sì ń ronú jinlẹ̀ lórí èrò rere tó ní sí wa, ìyẹn máa sọ agbára wa dọ̀tun láti máa fi ìṣòtítọ́ fara dà á bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Baba wa ọ̀run, Jèhófà tọkàntọkàn.—Mát. 24:13.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Jésù ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti máa ṣe àṣàrò lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Rántí àwọn ohun tó o gbọ́ àtàwọn ohun tó o rí ní àpéjọ àgbègbè kan láìpẹ́ yìí