Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Dúpẹ́ Pé Àdánwò Kò Mú Kí N dẹ́kun Láti Máa Sin Jèhófà

Mo Dúpẹ́ Pé Àdánwò Kò Mú Kí N dẹ́kun Láti Máa Sin Jèhófà

Mo Dúpẹ́ Pé Àdánwò Kò Mú Kí N dẹ́kun Láti Máa Sin Jèhófà

Gẹ́gẹ́ bí Maatje de Jonge-van den Heuvel ṣe sọ ọ́

ỌMỌ ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98] ni mí. Inú mi sì dùn pé mo ti lo àádọ́rin [70] lára ọdún náà láti fi sin Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a dán ìgbàgbọ́ mi wò. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, mo bára mi nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Nígbà kan láàárín àkókò ti mo lò níbẹ̀ ìrẹ̀wẹ̀sì mú kí n ṣe ìpinnu kan tí mo kábàámọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn náà. Ní àwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo dojú kọ àdánwò lílekoko mìíràn. Síbẹ̀, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo ní àǹfààní láti máa sìn ín bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo dojú kọ àdánwò.

Ìgbésí ayé mi yí pa dà ní oṣù October, ọdún 1940. Nígbà yẹn, mò ń gbé ní ìlú Hilversum, tó fi bíi kìlómítà mẹ́rìnlélógún jìn sí gúúsù ìlà oòrùn Amsterdam, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Netherlands. Abẹ́ ìjọba Násì ni orílẹ̀-èdè náà wà. Ó ti pé ọdún márùn-ún tí ọkọ mi Jaap de Jonge, tó máa ń ṣìkẹ́ mi ti gbé mi níyàwó, ọmọbìnrin wa ọ̀wọ́n, Willy, sì ti pé ọmọ ọdún mẹ́ta. Àwa àti ìdílé kan tó tòṣì la jọ múlé tira, agbára káká ni wọ́n sì fi ń tọ́ àwọn ọmọ wọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ. Síbẹ̀, ọ̀dọ́kùnrin kan ń gbé lọ́dọ̀ wọn, àwọn ni wọ́n sì ń bọ́ ọ. Mo máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ló mú kí wọ́n máa gbọ́ bùkátà tiẹ̀ mọ́ tiwọn?’ Nígbà kan tí mo gbé oúnjẹ díẹ̀ lọ fún wọn ni mo mọ̀ pé aṣáájú-ọ̀nà ni ọ̀dọ́kùnrin náà. Ó wàásù fún mi nípa Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ìbùkún tó máa mú wá. Ohun tí mo kọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin, mo sì yára gba òtítọ́. Ọdún yẹn gangan ni mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà tí mo sì ṣe ìrìbọmi. Ọdún kan lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi ni ọkọ mi náà wá sínú òtítọ́.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ Bíbélì tí mo ní kò tó nǹkan, ó yé mi yékéyéké pé bí mo bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo di apá kan ètò tí ìjọba fòfin dè nìyẹn. Mo tún mọ̀ pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ni wọ́n ti jù sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé, èmi àti ọkọ mi sì yọ̀ǹda pé kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò máa dé sí ilé wa. Bí àwọn ará wa ní ìlú Amsterdam bá ti kó àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì ránṣẹ́, ilé wa náà ni wọ́n máa ń kó o sí. Ńṣe ni àwọn alùpùpù tí wọ́n ṣe fún kíkó ẹrù wíwúwo máa ń kún fún ìwé, wọ́n á sì da tapólì bò ó. Ìfẹ́ àti ìgboyà táwọn arákùnrin tó ń fi alùpùpù kó àwọn ìwé náà ní mà pọ̀ gan-an o! Wọ́n ń fẹ̀mí ara wọn wewu torí àwọn ará wọn.—1 Jòh. 3:16.

“Mọ́mì Ṣé Ẹ Kò Ní Pẹ́ Dé?”

Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, àwọn ọlọ́pàá mẹ́ta wá sí ilé wa. Wọ́n wọnú ilé lọ, wọ́n sì tú gbogbo ẹrù wa wò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó kún ibi tá à ń kó aṣọ sí, wọ́n rí àwọn ìwé tá a kó pa mọ́ sábẹ́ bẹ́ẹ̀dì wa. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n pàṣẹ pé kí n tẹ̀ lé àwọn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní ìlú Hilversum. Nígbà tí mo gbé Willy mọ́ra kí n lè dágbére fún un, ó bi mí pé, “Mọ́mì ṣé ẹ kò ní pẹ́ dé?” Mo sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, olówó orí mi, Mọ́mì kò ní pẹ́ pa dà dé.” Àmọ́, ọdún kan àtààbọ̀ tó kún fún ìnira máa kọjá kí n tó tún lè gbé e mọ́ra.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé ọlọ́pàá kan mú mi wọ ọkọ̀ ojú irin tó gbé wa lọ sí ìlú Amsterdam níbi tí wọ́n ti lọ fi ọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò. Àwọn tó fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò béèrè bóyá mo mọ àwọn arákùnrin mẹ́ta kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ìlú Hilversum. Mo sọ pé: “Rárá o, ẹnì kan péré ni mo mọ̀ nínú wọn. Òun ló máa ń ta mílíìkì fún wa.” Bó sì ṣe rí nìyẹn lóòótọ́; mílíìkì ni arákùnrin yẹn ń tà. Mo wá sọ síwájú sí i pé, “Àmọ́ bóyá Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni o tàbí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun ni kẹ́ ẹ bi, ẹ má bi mí.” Nígbà tí mi ò sọ nǹkan kan mọ́, wọ́n gbá mi létí wọ́n sì fi mí sí àtìmọ́lé, mo sì wà níbẹ̀ fún oṣù méjì. Nígbà tí ọkọ mi gbọ́ pé ibẹ̀ ni mo wà, ó kó aṣọ àti oúnjẹ díẹ̀ wá fún mi. Nígbà tó di oṣù August, ọdún 1941, wọ́n gbé mi lọ sí Ravensbrück, àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ bíburú jáì kan tí wọ́n máa ń fi àwọn obìnrin sí, èyí tó fi ọgọ́rin [80] kìlómítà jìn sí àríwá ìlú Berlin, lórílẹ̀-èdè Jámánì.

“Tújú Ká, Arábìnrin Mi”

Nígbà tá a débẹ̀, wọ́n sọ fún wa pé a lè máa lọ sílé bá a bá lè fọwọ́ sí ìpolongo kan tó fi hàn pé a ti kọ ìgbàgbọ́ wa sílẹ̀. Mo kọ̀ láti fọwọ́ sí ìpolongo náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo kó ohun tó wà lọ́wọ́ mi fún wọn, mo sì lọ sílé ìwẹ̀ láti lọ bọ́ aṣọ tó wà lọ́rùn mi, mo sì bá àwọn arábìnrin kan tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Netherlands pà dé níbẹ̀. Wọ́n fún gbogbo wa ní aṣọ tí wọ́n rán àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò mọ́ lára ká lè máa wọ̀ ọ́ nínú àgọ́ náà; wọ́n fún wa ní abọ́ kan, ife omi kan àti ṣíbí kan. Ní alẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́, wọ́n kó wa sínú bárékè kan fúngbà díẹ̀. Ibẹ̀ ni mo sì ti kọ́kọ́ bú sẹ́kún látìgbà tí wọ́n ti mú mi. Omi ń dà pòròpòrò lójú mi bí mo ṣe ń bi ara mi pé: “Kí ló máa ṣẹlẹ̀ báyìí o? Báwo ni mo ṣe máa pẹ́ tó níbí?” Kí n sòótọ́, àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nígbà yẹn, torí pé kò tíì ju oṣù díẹ̀ lọ tí mo gba òtítọ́. Mo ṣì ní púpọ̀ láti mọ̀. Ní ọjọ́ kejì níbi tí wọ́n ti ń pe orúkọ wa, arábìnrin kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Netherlands ti ní láti kíyè sí i pé inú mi kò dùn. Ó sọ fún mi pé: “Tújú ká, arábìnrin mi, tújú ká! Kò sí ohun tó lè pa wá lára.”

Lẹ́yìn tí wọ́n pe orúkọ wa tán, wọ́n kó wa lọ sí bárékè mìíràn níbi tá a ti pàdé ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Jámánì àti Netherlands. Díẹ̀ lára àwọn arábìnrin tó jẹ́ ará Jámánì ti wà ní bárékè náà fún ohun tó lé ní ọdún kan. Kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn gbé mi ró gan-an ni, kódà, ó mú kí n tújú ká. Ohun tó tún wú mi lórí ni pé bárékè tí wọ́n kó àwọn arábìnrin wa sí mọ́ tónítóní ju àwọn bárékè mìíràn tó wà nínú àgọ́ náà. Yàtọ̀ sí pé àwọn bárékè wa mọ́ tónítóní, wọ́n tún mọ̀ pé a kì í jalè níbẹ̀, a kì í sì í ṣépè tàbí ká bára wa jà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń hùwà ìkà sí wa nínú àgọ́ náà, ńṣe ni bárékè wa dà bí erékùṣù mímọ́ tónítóní láàárín omi òkun tó kún fún àwọn nǹkan ẹlẹ́gbin.

Bí Nǹkan Ṣe Rí Nínú Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́

Ńṣe la máa ń ṣiṣẹ́ bí erin, tá a sì máa ń jẹun bí ẹ̀lírí nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. A ti máa ń jí láti aago márùn-ún ìdájí, ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn náà ni wọ́n á wá pe orúkọ wa. Àwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń mú ká dúró síta fún nǹkan bíi wákàtí kan, ì báà jẹ́ nínú òjò tàbí lábẹ́ oòrùn. Bó bá di agogo márùn-ún ìrọ̀lẹ́, lẹ́yìn iṣẹ́ àṣekára, wọ́n á tún pe orúkọ wa. Lẹ́yìn náà a máa fi ọbẹ̀ díẹ̀ jẹ búrẹ́dì, á sì ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu ká tó lọ sùn.

Ojoojúmọ́ ni mo máa ń ṣiṣẹ́ nínú oko, àyàfi ọjọ́ Sunday. Mo máa ń fi dòjé kórè àlìkámà, màá gbẹ́ kòtò, màá sì fọ ilé ẹlẹ́dẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ náà pàpọ̀jù tó sì jẹ́ iṣẹ́ ìdọ̀tí, agbára mi ń gbé e láti ṣe é lójoojúmọ́ torí pé mo ṣì kéré, ara mi sì le. Bákan náà, orin Ìjọba Ọlọ́run tó dá lórí Bíbélì tí mo máa ń kọ bí mo bá ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ tún máa ń gbé mi ró. Àmọ́ ṣá, ọjọ́ kan kò lè kọjá lọ kí àárò ọkọ mi àti ọmọ mi má sọ mí.

Oúnjẹ tí wọ́n máa ń fún wa kéré gan-an, ṣùgbọ́n gbogbo àwa arábìnrin máa ń gbìyànjú láti tọ́jú ègé búrẹ́dì kọ̀ọ̀kan pa mọ́ lójoojúmọ́ ká bàa lè fi kún tí ọjọ́ Sunday, nígbà tá a máa ń láǹfààní láti pé jọ ká sì jíròrò Bíbélì. A kò ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣùgbọ́n bí àwọn arábìnrin tí wọ́n ti pẹ́ nínú òtítọ́, tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Jámánì yẹn bá ń jíròrò Bíbélì, ó máa ń wù mí láti tẹ́tí sílẹ̀. Kódà, a ṣe Ìrántí Ikú Kristi níbẹ̀.

Ìdààmú Bá Mi, Mo Kábàámọ̀, Mo sì Rí Ìṣírí Gbà

Nígbà míì wọ́n máa ń sọ pé ká ṣiṣẹ́ tó máa mú ká kọ́wọ́ ti Ogun tí ìjọba Násì ń jà. Nítorí pé a kì í dá sí ọ̀ràn òṣèlú, gbogbo àwa arábìnrin kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ náà, èmi náà sì jẹ́ onígboyà bíi tiwọn. Gẹ́gẹ́ bí ìjìyà fún kíkọ̀ tá a kọ̀, a kò rí oúnjẹ gbà fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ wọ́n sì ń mú ká túbọ̀ pẹ́ sí í lórí ìlà bí wọ́n bá ń pe orúkọ wa. Lẹ́ẹ̀kan rí, nígbà òtútù, wọ́n tì wá mọ́ inú bárékè kan fún ogójì [40] ọjọ́ láìsí bá a ṣe lè jẹ́ kí ibẹ̀ móoru.

Léraléra ni wọ́n ń sọ fún àwa tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n lè fi wa sílẹ̀ ká máa lọ sílé bá a bá lè fọwọ́ sí ìpolongo tó fi hàn pé a ti kọ ìgbàgbọ́ wa sílẹ̀. Lẹ́yìn tó ti lé ní ọdún kan tí mo ti ń gbé ní Ravensbruck, ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi. Ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ọkọ àti ọmọ mi gan-an débi pé mo lọ bá àwọn ẹ̀ṣọ́, mo béèrè fún fọ́ọ̀mù tí màá fi sọ pé mi ò kí ń ṣe ọ̀kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́, mo sì buwọ́ lù ú.

Nígbà tí àwọn arábìnrin yòókù gbọ́ ohun tí mo ṣe, àwọn kan lára wọn bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fún mi. Àmọ́, àwọn arábìnrin àgbàlagbà méjì tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Jámánì, Arábìnrin Hedwig àti Gertrud, wá mi kàn wọ́n sì mú kó dá mi lójú pé àwọn nífẹ̀ẹ́ mi. Nígbà tá a jọ ń ṣiṣẹ́ nílé ẹlẹ́dẹ̀, wọ́n fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé fún mi bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká pa ìwà títọ́ wa sí Jèhófà mọ́ àti bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nípa ṣíṣàì juwọ́ sílẹ̀. Ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi àti bí wọ́n ṣe mú mi bí ọmọ wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni. * Mo mọ̀ pé ohun tí mo ṣe lòdì, mo sì fẹ́ kí wọ́n wọ́gi lé ìpolongo tí mo buwọ́ lù náà. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, mo sọ fún arábìnrin kan pé mo fẹ́ lọ sọ fún wọn pé kí wọ́n wọ́gi lé ìpolongo tí mo buwọ́ lù náà. Ọ̀rọ̀ wa ti ní láti ta sí ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ náà létí torí pé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an ni wọ́n ní kí n fi àgọ́ náà sílẹ̀, tí wọ́n sì fi mí lé ọkọ̀ ojú irin tó gbé mi pa dà lọ sí Netherlands. Ọ̀kan lára àwọn obìnrin tó ń bójú tó àgọ́ náà, tí mo ṣì lè dá mọ̀ bí mo bá rí i, sọ fún mi pé, “O ṣì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Bibelforscher (Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì), ọ̀kan lára wọn ni wàá sì máa jẹ́ títí ayé.” Mo fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, bí Jèhófà bá fẹ́.” Síbẹ̀, mi ò yé ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè wọ́gi lé ìpolongo tí mo buwọ́ lù yẹn?’

Ọ̀kan lára ohun tí wọ́n kọ sínú ìpolongo náà kà pé: “Mo mú kó dá yín lójú pé mi ò ní lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a mọ̀ sí International Bible Students Society mọ́.” Mo mọ ohun tí màá ṣe! Ní oṣù January, ọdún 1943, láìpẹ́ lẹ́yìn ti mo pa dà délé, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́, bí àwọn aláṣẹ ìjọba Násì bá fi lè mú mi lẹ́ẹ̀kejì tí mò ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, ìyà tí wọ́n máa fi jẹ mí á légbá kan sí i.

Láti fi hàn síwájú sí i pé mo nífẹ̀ẹ́ àtọkànwá láti jẹ́ adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jèhófà, èmi àti ọkọ mi tún yọ̀ǹda pé káwọn tó ń fi alùpùpù kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò máa dé sí ilé wa. Ìdí ọpẹ́ mi mà pọ̀ o, pé mo tún ní àǹfààní mìíràn láti fi ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ hàn!

Ẹ̀dùn Ọkàn Bá Wa

Ní oṣù mélòó kan kí ogun tó parí, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó kó ẹ̀dùn ọkàn bá èmi àti ọkọ mi. Ní oṣù October, ọdún 1944, ọmọ wa obìnrin Willy, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn. Àrùn gbọ̀fungbọ̀fun ló ń ṣe é. Àìsàn náà túbọ̀ ń burú sí i, ó sì kú ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn náà. Ọmọ ọdún méje péré ni nígbà tó kú.

Àdánù ńlá gbáà ni ikú ọmọ wa kan ṣoṣo náà jẹ́ fún wa. Ká sòótọ́, kékeré ni àdánwò tí mo dojú kọ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ravensbrück jẹ́ ní ìfiwéra pẹ̀lú ìrora tí ikú ọmọ wa mú bá mi. Àmọ́, bá a bá ní ìrora ọkàn, a máa ń rí ìtùnú látinú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 16:8, tó sọ pé: “Mo ti gbé Jèhófà sí iwájú mi nígbà gbogbo. Nítorí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.” Èmi àti ọkọ mi ní ìgbọ́kànlé tí kò lè yìnrìn nínú ìlérí Jèhófà pé òun máa jí àwọn òkú dìde. A dúró gbọ́n-in nínú òtítọ́, ìgbà gbogbo la sì ń fi ìtara wàásù ìhìn rere. Títí tí ọkọ mi fi kú ní ọdún 1969, mo dúpẹ́ pé ó ràn mí lọ́wọ́ gidigidi kí n lè máa fi ìmoore sin Jèhófà.

Àwọn Ìbùkún àti Ayọ̀ Tá A Ní

Ní àwọn ẹ̀wádún tó ti kọjá, àjọṣe tímọ́tímọ́ tí mo ní pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún máa ń fún mi láyọ̀ gan-an. Bíi ti ìgbà tí ogun ń lọ lọ́wọ́, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn ìyàwó wọn ṣì máa ń dé sí ilé wa ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń bẹ ìjọ wa wò. Tọkọtaya kan, Maarten àti Nel Kaptein, tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò tiẹ̀ gbé nínú ilé wa fún ọdún mẹ́tàlá! Nígbà tí àìsàn tó pa Arábìnrin Nel bẹ̀rẹ̀, mo láǹfààní láti máa bójú tó o nínú ilé wa fún oṣù mẹ́ta kó tó di pé ó kú. Ìfararora tí mo ní pẹ̀lú wọn àti pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ, tí wọ́n jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n ti mú kó ṣeé ṣe fún mi láti gbádùn Párádísè tẹ̀mí tá à ń gbé nínú rẹ̀ nísinsìnyí.

Ohun mánigbàgbé kan ṣẹlẹ̀ sí mi lọ́dún 1995. Mo rí ìwé ìkésíni gbà pé kí n wá síbi ìpàdé ìrántí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Ravensbrück. Níbẹ̀ ni mo ti pàdé àwọn arábìnrin tá a jọ wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó jẹ́ pé ó ti lé ní àádọ́ta [50] ọdún tí mo ti rí wọn gbẹ̀yìn! Ìrírí mánigbàgbé àti èyí tó ń múni lọ́kàn yọ̀ ló jẹ́ láti wà pa pọ̀ pẹ̀lú wọn, ó sì tún fún wa láǹfààní láti gbé ara wa ró ká sì máa fojú sọ́nà fún ọjọ́ tí àwọn òkú wa máa pa dà wà láàyè.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú Róòmù 15:4 pé, “nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó mú kí n ní ìrètí yìí, tó ti mú kó ṣeé ṣe fún mi láti kún fún ọpẹ́ pé àdánwò kò mú kí n dẹ́kun láti máa sin Jèhófà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Ní ìgbà yẹn, torí pé kò ṣeé ṣe láti kàn sí orílé iṣẹ́, ńṣe làwọn ará máa ń bójú tó ọ̀ràn tó bá jẹ mọ́ lílọ́wọ́ sí òṣèlú bó bá ṣe yé wọn mọ. Nítorí ìdí èyí, ọwọ́ tí olúkúlùkù fi mú ọ̀ràn náà yàtọ̀ síra díẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Èmi àti Jaap rèé, lọ́dún 1930

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ọmọbìnrin wa, Willy rèé, nígbà tó pé ọmọ ọdún méje

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ní ọdún 1995, ojú àwa ẹni àtijọ́ túnra rí. Ní ìlà iwájú, èmi ni ẹnì kejì láti apá òsì