Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Sá Di Orúkọ Jèhófà”

“Sá Di Orúkọ Jèhófà”

“Sá Di Orúkọ Jèhófà”

‘Dájúdájú, èmi yóò jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni rírẹlẹ̀ ṣẹ́ kù, wọn yóò sì sá di orúkọ Jèhófà ní ti tòótọ́.’ —SEF. 3:12.

1, 2. Ìjì ìṣàpẹẹrẹ wo ló máa tó jà?

 ǸJẸ́ ó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí pé kó o sá sábẹ́ afárá, bí irú èyí tó wà nínú àwòrán yìí, kó o lè bọ́ lọ́wọ́ ìjì òjò tàbí òjò yìnyín? Bó o bá sá sábẹ́ afárá, ó ṣeé ṣe kó o rí ààbò tó pọ̀ tó kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò tàbí òjò yìnyín, àmọ́ ààbò díẹ̀ lo lè rí lábẹ́ afárá bó bá jẹ́ pé ìjì àfẹ́yíká tàbí ìjì líle ló ń jà.

2 Irú ìjì kan tó yàtọ̀ ti ń gbára jọ báyìí, ó jẹ́ ọ̀kan tó lè fi òpin sí ìwàláàyè ìran ẹ̀dá èèyàn. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, Bíbélì pè é ní “ọjọ́ ìjì.” “Ọjọ́ ńlá Jèhófà” yìí sì máa kan gbogbo aráyé. Síbẹ̀, a lè rí ààbò tá a nílò. (Ka Sefanáyà 1:14-18.) Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè rí ààbò tá a nílò ní “ọjọ́ ìbínú kíkan Jèhófà,” tó máa tó bẹ̀rẹ̀ yìí?

Àwọn Ọjọ́ Ìjì Nígbà Tí Wọ́n Kọ Bíbélì

3. Nígbà ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, ‘ìjì tí ń sán ààrá’ wo ló jà?

3 Nígbà tí ọjọ́ Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run máa pa gbogbo ètò ìsìn èké tó wà lórí ilẹ̀ ayé run. Bá a bá ṣàyẹ̀wò ìtàn àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́, ó máa jẹ́ ká mọ ọ̀nà tá a lè gbà rí ààbò. Wòlíì Aísáyà, tó gbé láyé ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, fi ìdájọ́ tí Jèhófà ń mú bọ̀ wá sórí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà wé ‘ìjì tí ń sán ààrá’ tí àwọn èèyàn náà kò ní lè dá dúró. (Ka Aísáyà 28:1, 2.) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kọ́kọ́ ní ìmúṣẹ ní ọdún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí àwọn ọmọ ogun Ásíríà ya wọnú ilẹ̀ tó jẹ́ ti àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá náà, èyí tí ẹ̀yà Éfúráímù jẹ́ òléwájú lára wọn.

4. Báwo ni “ọjọ́ ńlá Jèhófà” ṣe wá sórí Jerúsálẹ́mù ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni?

4 Lẹ́yìn tí ìdájọ́ Ọlọ́run ti wá sórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́, “ọjọ́ ńlá Jèhófà” tó wá sórí Jerúsálẹ́mù àti ìjọba Júdà ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ló tẹ̀ lé e. Ohun tó sì mú kí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ni pé àwọn èèyàn Júdà pẹ̀lú ti di apẹ̀yìndà. Àwọn ará Bábílónì tí Nebukadinésárì jẹ́ aṣáájú wọn, ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ ilẹ̀ Júdà àti Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú rẹ̀. Àwọn ará Júdà wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí “ibi ìsádi irọ́,” ìyẹn orílẹ̀-èdè Íjíbítì tí wọ́n jọ bára wọn ṣàdéhùn. Síbẹ̀, bí òjò yìnyín tó ń pa nǹkan run ni àwọn ará Bábílónì ṣe pa “ibi ìsádi” náà run ráúráú.—Aísá. 28:14, 17.

5. Nígbà ìparun gbogbo ìsìn èké, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Ọlọ́run lápapọ̀?

5 Ọjọ́ ńlá Jèhófà tó wá sorí Jerúsálẹ́mù jẹ́ àpẹẹrẹ tó fi hàn pé ìdájọ́ Ọlọ́run ń bọ̀ wá sórí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti di apẹ̀yìndà ní àkókò wa yìí. Ìparun tún máa dé bá ìyókù “Bábílónì Ńlá,” tó jẹ́ ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gbogbo apá tó bá ṣẹ́ kù lára ètò àwọn nǹkan búburú ti Sátánì ni a ó pa run. Síbẹ̀, àwọn èèyàn Ọlọ́run lápapọ̀ máa là á já torí pé wọ́n ń fi Jèhófà ṣe ibi ìsádi wọn.—Ìṣí. 7:14; 18:2, 8; 19:19-21.

Ààbò Nípa Tẹ̀mí àti Ààbò Nípa Tara

6. Báwo làwọn èèyàn Jèhófà ṣe lè rí ààbò?

6 Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe lè rí ààbò pàápàá nísinsìnyí tó jẹ́ àkókò òpin? À ń rí ààbò tẹ̀mí bá a ṣe ń “ronú lórí orúkọ [Ọlọ́run]” tàdúràtàdúrà tá a sì ń fìtara sìn ín. (Ka Málákì 3:16-18.) Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ ṣe kọjá wíwulẹ̀ ronú lórí orúkọ Ọlọ́run. A kà pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” (Róòmù 10:13) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa ké pe orúkọ Jèhófà bá a bá fẹ́ rí ìgbàlà. Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn sì ń rí i pé àwọn Kristẹni tòótọ́ tí wọ́n ń “ronú lórí orúkọ [Jèhófà]” tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tí wọ́n sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀ yàtọ̀ gan-an sí aráyé tí kò sin Ọlọ́run.

7, 8. Báwo ni Ọlọ́run ṣe gba àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní là nípa tara, báwo ló sì ṣe máa ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí?

7 Kì í ṣe rírí ààbò tẹ̀mí nìkan ni ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà rí ìgbàlà. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa dáàbò bo àwọn èèyàn òun nípa tara. A rí àpẹẹrẹ èyí nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 66 Sànmánì Kristẹni, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Róòmù lábẹ́ ìdarí Cestius Gallus kọ lu Jerúsálẹ́mù. Jésù ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé a óò “ké” ọjọ́ ìpọ́njú yẹn “kúrú.” (Mát. 24:15, 16, 21, 22) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn, torí pé àwọn ọmọ ogun Róòmù tó wá gbógun ti ìlú náà dáwọ́ dúró láìròtẹ́lẹ̀, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún àwọn “ẹran ara” díẹ̀, ìyẹn àwọn Kristẹni tòótọ́, láti di ẹni tí a “gbà là.” Ó ṣeé ṣe fún wọn láti sá kúrò nínú ìlú náà àti àgbègbè rẹ̀. Àwọn kan sọdá odò Jọ́dánì wọ́n sì wá ààbò lọ sórí àwọn òkè ńlá tó wà ní apá ìlà oòrùn odò náà.

8 A lè fi ohun tí àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn ṣe wé ohun táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí náà máa ṣe. Nígbà àtijọ́, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lọ síbi tí wọ́n ti lè rí ààbò, ohun táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí náà máa ṣe nìyẹn. Àmọ́, lọ́tẹ̀ yìí wọn kò ní sá lọ sí ibì kan pàtó bí àwọn Kristẹni ti ṣe nígbà yẹn, torí pé àwọn Kristẹni tòótọ́ wà káàkiri ayé. Síbẹ̀, nígbà tí òpin bá dé bá àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti di apẹ̀yìndà, àwọn èèyàn Jèhófà lápapọ̀, ìyẹn “àwọn àyànfẹ́” àti àwọn adúróṣinṣin tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn, máa là á já nípa wíwá ààbò sọ́dọ̀ Jèhófà àti ètò rẹ̀ tó dà bí òkè ńlá.

9. Àwọn wo ló ti gbìyànjú láti mú káwọn èèyàn gbàgbé orúkọ Jèhófà? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan.

9 Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, ìparun tó ń bọ̀ wá náà tọ́ sí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì torí pé wọn kò jẹ́ káwọn ọmọ ìjọ wọn mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, ó sì tún hàn kedere pé wọ́n kórìíra orúkọ Ọlọ́run. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ọ̀làjú, àwọn èèyàn mọ orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gangan jákèjádò ilẹ̀ Yúróòpù. Orúkọ náà, tí lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin tí wọ́n sábà máa ń túmọ̀ sí YHWH (tàbí JHVH) dúró fún, fara hàn lára àwọn owó ẹyọ, àwọn ògiri rírẹwà tí wọ́n ṣe síwájú ilé, nínú ọ̀pọ̀ ìwé àti Bíbélì àti nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti ti Pùròtẹ́sítáǹtì kan pàápàá. Àmọ́, ohun tó wọ́pọ̀ lóde òní ni pé wọ́n ń yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì, wọn kì í sì í lò ó lọ́nà èyíkéyìí mìíràn. Ẹ̀rí kan tó fi èyí hàn ni lẹ́tà kan nípa ‘Orúkọ Ọlọ́run’ tí ìjọ kan tí wọ́n pè ní Congregation for Divine Worship and the Discipline of the Sacraments kọ sí Ìpàdé Àpérò Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù tó wáyé ní June 29, 2008. Nínú lẹ́tà náà, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sọ pé kí wọ́n fi “Olúwa” rọ́pò lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin náà ní ọ̀nà èyíkéyìí tó bá gbà fara hàn. Àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì sọ pé àwọn ọmọ ìjọ àwọn kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gangan nínú orin ìsìn wọn àti nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà lákòókò ìjọsìn. Bákan náà, àwọn aṣáájú ìsìn míì, yálà ti àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tàbí àwọn tí kò nígbàgbọ́ nínú Bíbélì pàápàá ti fi ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ pa mọ́ fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn.

Ọlọ́run Ń Dáàbò Bo Àwọn Tó Ń Sọ Orúkọ Rẹ̀ Di Mímọ́

10. Báwo la ṣe ń bọlá fún orúkọ Ọlọ́run lónìí?

10 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn ẹlẹ́sìn yòókù, torí pé wọ́n máa ń fi ògo àti ọlá fún orúkọ Ọlọ́run. Wọ́n ń sọ orúkọ náà di mímọ́ nípa lílò ó lọ́nà tó fi ọ̀wọ̀ hàn. Inú Jèhófà máa ń dùn sí àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e; ó máa ń di ohunkóhun tó bá yẹ kó bàa lè bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ kó sì dáàbò bò wọ́n. “Ó sì mọ àwọn tí ń wá ibi ìsádi lọ́dọ̀ rẹ̀.”—Náh. 1:7; Ìṣe 15:14.

11, 12. Àwọn wo ló gbé orúkọ Jèhófà lárugẹ ní Júdà ìgbàanì, àwọn wo ló sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ lóde òní?

11 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó pọ̀ jù lọ ní Júdà ìgbàanì ti di apẹ̀yìndà, àwọn kan wà tí wọ́n “sá di orúkọ Jèhófà.” (Ka Sefanáyà 3:12, 13.) Nígbà tí Ọlọ́run fi ìyà jẹ Júdà, torí pé àwọn èèyàn náà di aláìgbàgbọ́, tó sì jẹ́ kí àwọn ará Bábílónì ṣẹ́gun wọn kó sì kó àwọn èèyàn rẹ̀ nígbèkùn, ó dá àwọn èèyàn kan sí, àwọn bíi Jeremáyà, Bárúkù àti Ebedi-mélékì. Wọ́n ti gbé ní “àárín” orílẹ̀-èdè kan tó di apẹ̀yìndà. Àwọn mìíràn ń bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́ nígbà tí wọ́n wà ní ìgbèkùn. Ní ọdún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì lábẹ́ ìdarí Kírúsì. Nígbà tó ṣe, Kírúsì pàṣẹ pé kí àwọn Júù tó ṣẹ́ kù pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn.

12 Sefanáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn tó máa tipa bẹ́ẹ̀ gbádùn ìmúpadàbọ̀sípò ìjọsìn tòótọ́ pé Jèhófà máa gbà wọ́n là, ó sì máa yọ̀ nítorí wọn. (Ka Sefanáyà 3:14-17.) Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ lónìí náà nìyẹn. Lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run ti fìdí múlẹ̀ lọ́run, Jèhófà dá àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nídè kúrò nínú àwọn ẹ̀kọ́ èké Bábílónì Ńlá. Ó sì ń yọ̀ nítorí wọn títí di òní yìí.

13. Ìdáǹdè wo ni àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ń rí gbà báyìí?

13 Àwọn tó ní ìrètí láti máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ti jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá, a sì ti dá wọn nídè kúrò nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké. (Ìṣí. 18:4) Nípa báyìí, ọ̀rọ̀ inú Sefanáyà 2:3 wá ń ní ìmúṣẹ rẹ̀ pàtàkì ní àkókò tiwa. Ó sọ pé: “Ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé.” Ní báyìí, àwọn ọlọ́kàn tútù látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ń sá di orúkọ Jèhófà, yálà wọ́n ní ìrètí láti lọ sókè ọ̀run tàbí láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé.

Orúkọ Ọlọ́run Kì Í Ṣe Oògùn Tí Ń Dáàbò Boni

14, 15. (a) Kí làwọn kan rò pé ó ní agbára láti dáàbò boni? (b) Kí ni kò yẹ kéèyàn kà sí oògùn?

14 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan máa ń wo tẹ́ńpìlì bí ohun tó ní agbára tó lè dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. (Jer. 7:1-4) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kọ́kọ́ ń fìgbà kan wo àpótí májẹ̀mú gẹ́gẹ́ bí oògùn tó lè dáàbò bò wọ́n lójú ogun. (1 Sám. 4:3, 10, 11) Kọnsitatáìnì Ńlá fi àwọn ọ̀rọ̀ méjì tó bẹ̀rẹ̀ orúkọ náà “Kristi” lédè Gíríìkì, ìyẹn khi àti rho ṣe àmì sára apata àwọn ọmọ ogun rẹ̀; ó lérò pé ó máa dáàbò bò wọ́n lójú ogun. Àwọn kan sì rò pé ìhámọ́ra tí àwòrán rẹ̀ wà lójú ìwé 7 ni Ọba Gustav tí í ṣe Adolph Kejì ti orílẹ̀-èdè Sweden gbé wọ̀ nígbà tó ja Ogun Ọlọ́gbọ̀n-Ọdún náà. Orúkọ náà Iehova, sì fara hàn kedere níwájú ìhámọ́ra náà.

15 Díẹ̀ lára àwọn èèyàn Ọlọ́run tí àwọn ẹ̀mí èṣù ti gbéjà kò rí ti rí ààbò nípa kíké pe orúkọ Jèhófà. Síbẹ̀, kò yẹ ká máa wo ohunkóhun tí wọ́n bá kọ orúkọ Ọlọ́run sí lára bíi pé ó ní agbára láti dáàbò boni tàbí ká wá máa lò ó lójoojúmọ́ bí oògùn tó lè dáàbò bò wá. Ìyẹn kọ́ ló fi hàn pé èèyàn sá di orúkọ Jèhófà.

Bá A Ṣe Lè Rí Ààbò Lónìí

16. Báwo la ṣe lè rí ààbò tẹ̀mí lónìí?

16 Ọlọ́run ń dáàbò bo gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ lónìí nípa pípèsè ààbò tẹ̀mí fún wọn. (Sm. 91:1) Jèhófà máa ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” àti àwọn alàgbà nínú ìjọ láti mú ká wà lójúfò sí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé, èyí tó lè ṣàkóbá fún ààbò tẹ̀mí tá a ní. (Mát. 24:45-47; Aísá. 32:1, 2) Ronú nípa ìkìlọ̀ lemọ́lemọ́ tá à ń rí gbà nípa ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, kó o sì ṣàgbéyẹ̀wò bí àwọn ìkìlọ̀ náà ṣe dáàbò bò wá lọ́wọ́ àgbákò tẹ̀mí. Ẹ sì tún wo ìránnilétí tá a ti rí gbà pé ewu wà nínú gbígbé ìgbé ayé gbẹ̀fẹ́ tó lè mú ká di aláìṣiṣẹ́mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ìdẹra dẹngbẹrẹ àwọn arìndìn sì ni ohun tí yóò pa wọ́n run. Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.” (Òwe 1:32, 33) Bá a bá ń sapá láti má ṣe lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe, ìyẹn pẹ̀lú máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa gbádùn ààbò tẹ̀mí.

17, 18. Kí ló ń mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lónìí máa sá di orúkọ Jèhófà?

17 Tún ronú nípa ìṣírí tí ẹrú olóòótọ́ ń fún wa pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe pa á láṣẹ. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Sefanáyà sọ nípa ìyípadà kan tó máa mú kí àwọn èèyàn sá di orúkọ Ọlọ́run. Ó kà pé: “Nígbà náà ni èmi yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ gaara, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.”—Sef. 3:9.

18 Kí ni èdè mímọ́ yìí? Èdè mímọ́ náà jẹ́ òtítọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn ohun tó máa ṣe, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí. Bó o bá ń sọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, tí ò ń ṣàlàyé fún wọn nípa bó ṣe máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, tó ò ń sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run láre, tó o sì ń fìdùnnú sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún ayérayé táwọn èèyàn olóòótọ́ máa gbádùn, a jẹ́ pé ò ń lo èdè náà nìyẹn. Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń sọ èdè ìṣàpẹẹrẹ yìí ti mú kí àwọn tó ń ké “pe orúkọ Jèhófà” tí wọ́n sì ń sìn ín “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” máa pọ̀ sí i. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé ti wá ń sá di orúkọ Jèhófà báyìí.—Sm. 1:1, 3.

19, 20. Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, báwo ni “ibi ìsádi irọ́” táwọn kan wá ààbò lọ ṣe já wọn kulẹ̀?

19 Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó wà nínú ayé ń kojú àwọn ìṣòro tó dà bíi pé kò ṣeé borí. Ọ̀pọ̀ lára wọn ń wá ojútùú sáwọn ìṣòro náà ní gbogbo ọ̀nà, èyí sì mú kí wọ́n máa wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn aláìpé. Ó sì lè jẹ́ pé ètò òṣèlú ni wọ́n ń fọkàn sí pé ó máa pèsè ojútùú tí wọ́n ń wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ti ṣe, tó jẹ́ pé nígbà míì wọ́n máa ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó múlé gbè wọ́n, tí wọ́n sì ń wọnú àdéhùn pẹ̀lú wọn. Síbẹ̀, ìwọ náà mọ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò rí ìrànlọ́wọ́ kankan látọ̀dọ̀ wọn. Kò sì sí ìjọba orílẹ̀-èdè kankan lónìí, tó fi mọ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè, tó lè ṣe àwòtán ìṣòro aráyé. Torí náà, kí nìdí téèyàn á fi máa wo ètò òṣèlú àtàwọn orílẹ̀-èdè tó bára wọn ṣàdéhùn gẹ́gẹ́ bí ibi ìsádi? Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, Ọlọ́run pè wọ́n ní “ibi ìsádi irọ́.” Ibi ìsádi irọ́ ni wọ́n sì jẹ́ lóòótọ́ torí pé gbogbo àwọn tó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ wọn ni wọ́n máa já kulẹ̀ pátápátá.—Ka Aísáyà 28:15, 17.

20 Láìpẹ́, òjò yìnyín ìṣàpẹẹrẹ tó máa bá ọjọ́ Jèhófà rìn, máa rọ̀ sórí ilẹ̀ ayé. Kò ní ṣeé ṣe fún ètò tí àwọn ẹ̀dá èèyàn gbé kalẹ̀ láti dáàbò boni; pàbó làwọn ibi téèyàn lè forí pa mọ́ sí nígbà ogun runlérùnnà máa já sí, ọrọ̀ pẹ̀lú á sì já sí asán. Aísáyà 28:17 ṣàlàyé pé: “Yìnyín yóò sì gbá ibi ìsádi irọ́ lọ, àní omi yóò sì kún bo ibi ìlùmọ́ pàápàá.”

21. Kí la máa jàǹfààní rẹ̀ tá a bá ń ṣe ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2011?

21 Nísinsìnyí àti nígbà tí ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà bá nímùúṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run máa pèsè ojúlówó ààbò fún àwọn èèyàn rẹ̀. Orúkọ Sefanáyà, tó túmọ̀ sí “Jèhófà ti Pa Mọ́” jẹ́ ká mọ̀ dájú pé Jèhófà ló máa pa àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́. Ó bá a mu wẹ́kú nígbà náà pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2011 jẹ́ ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó sọ pé: “Sá di orúkọ Jèhófà.” (Sef. 3:12) Nísinsìnyí pàápàá, a lè sá di orúkọ Jèhófà ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá, ohun tá a sì gbọ́dọ̀ ṣe nìyẹn. (Sm. 9:10) Lójoojúmọ́, ẹ jẹ́ ká máa rántí ọ̀rọ̀ onímìísí tó fini lọ́kàn balẹ̀ náà pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.”—Òwe 18:10.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo la ṣe lè sá di orúkọ Jèhófà nísinsìnyí?

• Kí nìdí tí kò fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé “ibi ìsádi irọ́”?

• Ààbò wo ni Ọlọ́run ṣèlérí lọ́jọ́ iwájú?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2011 ni: “Sá di orúkọ Jèhófà.”—Sefanáyà 3:12.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]

Thüringer Landesmuseum Heidecksburg Rudolstadt, Waffensammlung “Schwarzburger Zeughaus”