Ẹ̀mí Mímọ́ Ni Ọlọ́run Lò Nígbà Ìṣẹ̀dá
Ẹ̀mí Mímọ́ Ni Ọlọ́run Lò Nígbà Ìṣẹ̀dá
“Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà ni a ṣe ọ̀run, nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ sì ni a ṣe gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀.”—SM. 33:6.
1, 2. (a) Báwo ni ìmọ̀ táwa èèyàn ní nípa àwọn ohun tó wà lójú sánmà àti ilẹ̀ ayé ti ṣe pọ̀ sí i látìgbà yìí wá? (b) Ìbéèré wo ló yẹ ká wá ìdáhùn sí?
NÍ ỌDÚN 1905, ògbógi onímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà, Albert Einstein àti ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì míì gbà gbọ́ pé ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kan ṣoṣo ni àgbáálá ayé wa ní, ìyẹn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà (Milky Way). Ojú kékeré ni wọ́n fi wo bí àgbáálá ayé wa ṣe tóbi tó. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti wá gbà pé ó lé ní ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà lójú sánmà, ìràwọ̀ tó wà nínú àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kan sì tó ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù. Bí wọ́n tún ṣe ń fi àwọn awò awọ̀nàjíjìn tó lágbára fíìfíì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ wo ojú sánmà láti orí ilẹ̀ ayé níbí tàbí láti ibi tí wọ́n gbé wọn sí lójú òfuurufú, ńṣe ni iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí wọ́n ń ṣàwárí rẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i.
2 Bó ṣe jẹ́ pé lọ́dún 1905 ìwọ̀nba ni ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mọ̀ nípa àwọn ohun tó wà lójú sánmà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìmọ̀ tí wọ́n ní nípa ilẹ̀ ayé wa ṣe kéré tó. Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn tó gbé láyé ní ọgọ́rùn-ún kan ọdún sẹ́yìn mọ ohun tó pọ̀ ju àwọn baba ńlá wọn ìgbàanì lọ. Àmọ́, ní báyìí, a ti wá ní òye tó pọ̀ sí i ju tìgbà yẹn lọ nípa ẹwà àti onírúurú àwọn nǹkan tó wé mọ́ ìwàláàyè àti àwọn ohun tó ń gbé ìwàláàyè ró. Síbẹ̀, ó dájú pé bí ọdún ti ń gorí ọdún, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì tún wà tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé àtàwọn ohun tó wà lójú sánmà. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì ká béèrè pé, Ibo ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí ti wá? Kìkì ohun tó lè mú ká rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ni pé Ẹlẹ́dàá ti ṣí ìdáhùn náà payá fún wa nínú Ìwé Mímọ́.
Iṣẹ́ Ìyanu Ni Ìṣẹ̀dá
3, 4. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ṣẹ̀dá àgbáálá ayé wa, báwo sì làwọn ohun tó dá ṣe ń fògo fún un?
3 Gbólóhùn àkọ́kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ ibi tí àgbáálá ayé wa yìí ti wá. Ó kà pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́n. 1:1) Kò tíì sí ohunkóhun lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan, ńṣe ló lo ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ tó lágbára láti dá àwọn ohun tó wà lójú sánmà àti ilẹ̀ ayé. Ọwọ́ àti irinṣẹ́ ni oníṣẹ́ ọnà fi máa ń ṣe iṣẹ́ ọnà rẹ̀, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ ni Ọlọ́run máa ń rán jáde láti fi ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ àgbàyanu.
4 Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ pe ẹ̀mí mímọ́ ní “ìka” Ọlọ́run. (Lúùkù 11:20; Mát. 12:28) “Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,” ìyẹn àwọn ohun tí Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ dá, sì tún ń fògo fún un. Onísáàmù náà, Dáfídì, kọrin pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.” (Sm. 19:1) Dájúdájú, ayé àtàwọn ohun tí Ọlọ́run dá sínú rẹ̀ jẹ́rìí sí bí agbára ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó. (Róòmù 1:20) Báwo ló ṣe jẹ́rìí sí i?
Agbára Ọlọ́run Ò Láàlà
5. Ṣàpèjúwe bí ẹ̀mí mímọ́ tí Jèhófà lò nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá ṣe lágbára tó.
5 Àgbáálá ayé wa tó lọ salalu jẹ́rìí sí i pé agbára àti okun Jèhófà kò láàlà. (Ka Aísáyà 40:26.) Bí àpẹẹrẹ, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ìgbàlódé ti fi hàn pé oòrùn, tó jẹ́ oríṣi ìràwọ̀ kan, lè mú kí ohun tó le gbagidi di yíyọ́ kó bàa lè pèsè ohun àmúṣagbára tá a nílò. Láàárín ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan, oòrùn máa ń sọ àwọn ohun tó pọ̀ tó láti kún ọkọ̀ akóyọyọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́fà di yíyọ́, kó lè mú ìmọ́lẹ̀ àtàwọn ohun àmúṣagbára míì jáde. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìwọ̀n orí abẹ́rẹ́ lásán lára ìmọ́lẹ̀ tí oòrùn ń mú jáde ti tó láti gbé ìwàláàyè ró lórí ilẹ̀ ayé. Kò sí àníàní pé Jèhófà lo agbára tó pọ̀ gan-an láti ṣẹ̀dá oòrùn àti ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìràwọ̀ yòókù tó dá. Jèhófà ní ànító àti àníṣẹ́kù agbára tó lè fi ṣẹ̀dá àwọn nǹkan.
6, 7. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lọ́nà tó wà létòlétò? (b) Kí ló fi hàn pé àgbáálá ayé yìí kò ṣàdédé wà?
6 Ẹ̀rí tó yí wa ká fi hàn pé Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lọ́nà tó wà létòlétò. Àpèjúwe kan rèé: Jẹ́ ká sọ pé o ní àpótí kan tí àwọn bọ́ọ̀lù tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ wà nínú rẹ̀. O wá ji àpótí náà pọ̀ dáadáa, káwọn bọ́ọ̀lù náà lè dà pọ̀ mọ́ra. Lẹ́yìn náà lo wá da gbogbo bọ́ọ̀lù náà sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Ṣé wàá retí pé kí àwọn bọ́ọ̀lù tí àwọ̀ wọn jọra kóra jọ sójú kan, àwọn tó ní àwọ̀ búlúù lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, àwọn tó ní àwọ̀ ìyeyè lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ? Rárá o! Ohun téèyàn ò bá fètò sí kò lè lójú. Níbi gbogbo lágbàáyé ni wọ́n ti gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. *
7 Síbẹ̀, bá a bá gbé ojú wa sókè tàbí tá a fi awò awọ̀nàjíjìn wo ojú sánmà, kí la máa rí níbẹ̀? A máa rí àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀, àwọn ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n pọ̀ yamùrá, tí wọ́n sì ń lọ yí po lọ́nà tó wà létòlétò láì gbún ara wọn. Gbogbo ìwọ̀nyí ò jẹ́ wáyé lọ́nà èèṣì tàbí lọ́nà wọ̀ǹdùrùkù àti láìsí ẹni olóye kan tó mú kó ṣeé ṣe. Torí náà, ó yẹ ká béèrè pé, Ipá wo ló mú kí àgbáálá ayé wa yìí wà létòlétò bó ṣe rí yìí? Àwa ẹ̀dá èèyàn ò lè tipasẹ̀ àyẹ̀wò àti ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nìkan ṣàwárí ipá yẹn. Àmọ́, Bíbélì ti jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni, ó sì jẹ́ ipá tó lágbára jù lọ láyé àtọ̀run. Onísáàmù náà kọrin pé: “Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà ni a ṣe ọ̀run, nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ sì ni a ṣe gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀.” (Sm. 33:6) Bá a bá wo ojú sánmà ní àṣálẹ́, ìwọ̀nba díẹ̀ lára “ẹgbẹ́” àwọn ìràwọ̀ yẹn la lè fi ojú ara wa rí!
Bí Ọlọ́run Ṣe Lo Ẹ̀mí Mímọ́ Nígbà Ìṣẹ̀dá Ilẹ̀ Ayé
8. Báwo lohun tá a mọ̀ nípa iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Jèhófà ṣe pọ̀ tó?
8 Ní báyìí, ńṣe ni ohun tá a ti mọ̀ nípa ìṣẹ̀dá kéré bí orí abẹ́rẹ́ tá a bá fi wé gbogbo ohun tá ò tíì mọ̀ nípa rẹ̀. Nígbà tí ọkùnrin olóòótọ́ náà, Jóòbù ń sọ nípa bí ìmọ̀ wa nípa iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Ọlọ́run ṣe kéré jọjọ tó, ó sọ pé: “Wò ó! Ìwọ̀nyí jẹ́ bèbè àwọn ọ̀nà rẹ̀, àhegbọ́ mà ni ohun tí a sì gbọ́ nípa rẹ̀!” (Jóòbù 26:14) Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì Ọba, tó fara balẹ̀ kíyè sí àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Jèhófà, sọ pé: “Ohun gbogbo ni [Ọlọ́run] ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀. Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn, kí aráyé má bàa rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.”—Oníw. 3:11; 8:17.
9, 10. Ipá wo ni Ọlọ́run lò nígbà tó dá ilẹ̀ ayé, àwọn nǹkan wo ló sì ṣe ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ní ọjọ́ mẹ́ta àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ̀dá àwọn nǹkan?
9 Àmọ́ ṣá o, Jèhófà jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ tó ṣe pàtàkì nípa àwọn iṣẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé ẹ̀mí Ọlọ́run wà lẹ́nu iṣẹ́ lórí ilẹ̀ ayé ní ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún sẹ́yìn. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:2.) Nígbà yẹn, kò tíì sí ilẹ̀ gbígbẹ, kò sí ìmọ́lẹ̀, ó sì dájú pé kò sí atẹ́gùn téèyàn lè mí símú pàápàá.
10 Bíbélì ń bá a nìṣó láti ṣàpèjúwe ohun tí Ọlọ́run ṣe láàárín àwọn ọjọ́ tó fi ṣẹ̀dá àwọn nǹkan ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Àwọn ọjọ́ yìí kì í ṣe ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún bí kò ṣe àkókò gígùn nínú èyí tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì ti wáyé. Ní ọjọ́ ìṣẹ̀dá kìíní, Jèhófà mú kí ìmọ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn lórí ilẹ̀ ayé, ó sì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí dìgbà tí oòrùn àti òṣùpá fi ṣeé rí kedere láti orí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́n. 1:3, 14) Ní ọjọ́ kejì, Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í dá òfuurufú. (Jẹ́n. 1:6) Nígbà yẹn, omi, ìmọ́lẹ̀ àti afẹ́fẹ́ ti wà lórí ilẹ̀ ayé, àmọ́ kò tíì sí ilẹ̀ gbígbẹ. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ìṣẹ̀dá kẹta, Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú kí ilẹ̀ gbígbẹ wà. Bóyá ohun tó ṣe ni pé ó jẹ́ kí ilẹ̀ rú jáde látinú omi tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́n. 1:9) Àwọn ohun àgbàyanu míì ṣì máa wáyé ní ọjọ́ kẹta yìí àti láwọn ọjọ́ ìṣẹ̀dá tó kù.
Bí Ọlọ́run Ṣe Lo Ẹ̀mí Mímọ́ Nígbà Ìṣẹ̀dá Àwọn Ohun Abẹ̀mí
11. Kí la rí kọ́ látinú bí àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí ṣe jẹ́ ọ̀kan-kò-jọ̀kan, tí wọ́n wà létòlétò, tí wọ́n sì lẹ́wà?
11 Ọlọ́run tún lo ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣe àwọn iṣẹ́ tí ìwàlétòlétò wọn pabanbarì nígbà tó dá àwọn ohun abẹ̀mí. Láàárín ọjọ́ ìṣẹ̀dá kẹta sí ìkẹfà, Ọlọ́run tún lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti dá ọ̀kan-kò-jọ̀kan ewéko àti ẹranko. (Jẹ́n. 1:11, 20-25) Torí náà, tá a bá wo àwọn ohun abẹ̀mí, a lè rí àpẹẹrẹ tí kò lóǹkà èyí tó jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n jẹ́ ọ̀kan-kò-jọ̀kan, wọ́n wà létòlétò, wọ́n sì lẹ́wà dé ìwọ̀n tó fi hàn pé a ṣẹ̀dá wọn lọ́nà tó fa kíki.
12. (a) Iṣẹ́ wo ni èròjà DNA ń ṣe? (b) Kí la lè rí kọ́ látinú bí èròjà DNA ṣe ń bá iṣẹ́ nìṣó?
12 Ronú nípa èròjà DNA (deoxyribonucleic acid), tó máa ń mú kó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá abẹ̀mí kọ̀ọ̀kan láti ta àtaré ànímọ́ àrà ọ̀tọ̀ tá a fi ń dá wọn mọ̀ láti ìran dé ìran. Èròjà yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo ẹ̀dá abẹ̀mí tó wà lórí ilẹ̀ ayé, tó fi mọ́ àwọn kòkòrò àrùn, ewéko, erin, ẹja àbùùbùtán àtàwọn ẹ̀dá èèyàn láti máa mú irú wọn jáde. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan-kò-jọ̀kan ẹ̀dá ló wà lórí ilẹ̀ ayé, èròjà DNA tó máa ń pinnu irú ànímọ́ tí wọ́n máa ní yìí ń bá iṣẹ́ nìṣó, òun ni kì í sì í jẹ́ kí ohun táwọn ẹ̀dá fi yàtọ̀ gedegbe síra yí pa dà láti ìran dé ìran. Torí náà, bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí, onírúurú ẹ̀dá alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé ń bá a nìṣó láti máa ṣe ipa tirẹ̀, wọ́n sì ń gbé ìwàláàyè ara wọn ró. (Sm. 139:16) Ìṣètò tó múná dóko, tó sì wà létòlétò yìí tún jẹ́ ẹ̀rí síwájú sí i pé ìṣẹ̀dá jẹ́ iṣẹ́ “ìka,” tàbí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.
Pabanbarì Ohun Tí Ọlọ́run Dá Sáyé
13. Báwo ni Ọlọ́run ṣe dá èèyàn?
13 Lẹ́yìn àìmọye ọdún tí Ọlọ́run ti dá àìlóǹkà àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí àti àwọn tí kò lẹ́mìí, ilẹ̀ ayé kò sí ní ‘bọrọgidi, kò sì ṣófo’ mọ́. Síbẹ̀, Jèhófà kò tíì dẹ́kun láti máa lo ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣẹ̀dá àwọn nǹkan. Ó ṣì ku èyí tó pabanbarì jù lọ lára àwọn nǹkan tó dá sáyé. Bí ọjọ́ kẹfà ìṣẹ̀dá ṣe ń parí lọ, Ọlọ́run dá èèyàn. Báwo ni Jèhófà ṣe dá èèyàn? Ó dá a nípa lílo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àtàwọn èròjà tó wà nínú ilẹ̀.—Jẹ́n. 2:7.
14. Ọ̀nà pàtàkì wo làwa èèyàn gbà yàtọ̀ sáwọn ẹranko?
14 Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 1:27 sọ pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” Dídá tí Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán rẹ̀ túmọ̀ sí pé Jèhófà dá wa lọ́nà táá fi ṣeé ṣe fún wa láti fi ìfẹ́ hàn, ká pinnu ohun tá a fẹ́ láti ṣe, ká sì ní àjọṣe pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa. Torí náà, ọpọlọ wa yàtọ̀ gedegbe sí ti àwọn ẹranko. Ní pàtàkì jù lọ, Jèhófà dá ọpọlọ àwa èèyàn lọ́nà tó fi jẹ́ pé a ó lè máa bá a nìṣó láti fayọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ àti nípa àwọn iṣẹ́ rẹ̀ títí láé.
15. Ìrètí wo ni Ọlọ́run gbé ka iwájú Ádámù àti Éfà?
15 Nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́, ó fi ilẹ̀ ayé àti gbogbo àwọn nǹkan àgbàyanu tó wà nínú rẹ̀ sí ìkáwọ́ wọn kí wọ́n lè ṣèwádìí wọn, kí wọ́n sì gbádùn wọn. (Jẹ́n. 1:28) Jèhófà pèsè oúnjẹ yanturu fún wọn, ó sì mú kí wọ́n máa gbé nínú Párádísè. Wọ́n ní àǹfààní láti máa wà láàyè títí láé kí wọ́n sì di òbí àtàtà fún ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àtọmọdọ́mọ tí wọ́n jẹ́ ẹni pípé. Síbẹ̀, àwọn nǹkan ò rí bó ṣe yẹ kó rí.
Mímọyì Ipa Tí Ẹ̀mí Mímọ́ Kó
16. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀, ìrètí wo la ṣì ní?
16 Kàkà kí ìmoore mú kí Ádámù àti Éfà máa ṣègbọràn sí Ẹlẹ́dàá wọn, ńṣe ni ìmọtara-ẹni-nìkan mú kí wọ́n ṣọ̀tẹ̀. Ọ̀dọ̀ wọn ni gbogbo ẹ̀dá èèyàn aláìpé ti ṣẹ̀ wá, ìyẹn ló sì fà á táwọn èèyàn fi ń jìyà. Ṣùgbọ́n Bíbélì ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe máa mú gbogbo ìpalára tí ìwà ọ̀tẹ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ fà kúrò. Ìwé Mímọ́ tún fi hàn pé Jèhófà máa mú ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ. Ilẹ̀ ayé á di Párádísè tó máa kún fún àwọn èèyàn aláyọ̀ tí ara wọn jí pépé, tí wọn yóò sì máa wà láàyè títí láé. (Jẹ́n. 3:15) A nílò ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run kí ìgbàgbọ́ wa nínú ìrètí tí ń fúnni lókun yìí má bàa ṣákìí.
17. Irú èrò wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún?
17 A gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Bá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, yóò túbọ̀ máa dá wa lójú pé ìṣẹ̀dá jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run. Lónìí, ńṣe ni èrò èké tó jìnnà sóòótọ́, tí kò sì nítumọ̀ pé kò sí Ọlọ́run àti pé ara ẹranko làwa èèyàn ti jáde wá ń gbilẹ̀ sí i. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èrò òdì tó ń gbilẹ̀ bí iná ọyẹ́ yìí dà wá lọ́kàn rú tàbí kí ó kó jìnnìjìnnì bá wa. Gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ múra tán láti má ṣe gba èrò òdì tó gbòde kan yìí láyè, wọn kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe mú kí wọ́n ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú rẹ̀.—Ka Kólósè 2:8.
18. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí àgbáálá ayé wa àti ìran èèyàn ṣe di èyí tó wà, kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti rò pé kò lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ olóye nínú?
18 Ó dájú pé bá a bá fòótọ́ ọkàn ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá ohun gbogbo, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Bíbélì àti Ọlọ́run fúnra rẹ̀ á túbọ̀ lágbára sí i. Nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá ń ṣàyẹ̀wò bí àgbáálá ayé wa àti aráyé ṣe di èyí tó wà, wọn kì í fẹ́ gbà pé ó lọ́wọ́ ohunkóhun tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè ṣàlàyé rẹ̀ nínú. Àmọ́, bá a bá gbé ìjíròrò nípa bí àwọn nǹkan ṣe di èyí tó wà karí irú èrò bẹ́ẹ̀, kò sí bá ò ṣe ní pọ̀n síbì kan. Èyí á sì tún mú ká di ojú wa sí òtítọ́ náà pé àwọn ohun tí Ọlọ́run dá wà “láìníye,” pé wọ́n wà létòlétò, ó sì ní ìdí pàtàkì tó fi dá wọn. (Jóòbù 9:10; Sm. 104:25) Ó dá àwa Kristẹni lójú pé ẹ̀mí mímọ́ ni ipá ìṣiṣẹ́ tí Jèhófà, tó jẹ́ olóye, lò láti ṣẹ̀dá àwọn nǹkan.
Bí Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Lè Mú Ká Túbọ̀ Nígbàgbọ́ Nínú Ọlọ́run
19. Kí ló mú ká gbà pé Ọlọ́run wà àti pé ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ń ṣiṣẹ́?
19 Kò dìgbà tá a bá mọ ohun gbogbo nípa ìṣẹ̀dá ká tó lè ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ká tó lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká sì tó lè ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un. Bó ṣe rí pẹ̀lú ẹni téèyàn ń bá ṣọ̀rẹ́, kò ṣeé ṣe láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà béèyàn ò bá mọ̀ ọ́n dáadáa. Bó ṣe jẹ́ pé bí ẹni méjì bá ṣe túbọ̀ ń mọwọ́ ara wọn ni àjọṣe wọn á túbọ̀ máa fìdí múlẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé bá a bá ṣe ń mọ púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run ni ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀ á túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Kódà, a tún máa ń gbà pé Ọlọ́run wà nígbà tó bá dáhùn àwọn àdúrà wa, tá a sì rí ipa rere tí fífi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò ń ní nínú ìgbésí ayé wa. A sì túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà bá a ṣe ń rí ẹ̀rí pelemọ tó fi hàn pé ó ń tọ́ ìṣísẹ̀ wa, ó ń dáàbò bò wá, ó ń bù kún ìsapá wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ó sì ń pèsè àwọn ohun tá a nílò fún wa. Gbogbo èyí jẹ́ ẹ̀rí lílágbára tó mú ká gbà pé Ọlọ́run wà àti pé ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ń ṣiṣẹ́.
20. (a) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá àgbáálá ayé àti ẹ̀dá èèyàn? (b) Kí ló máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ bá a bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa darí wa?
20 Bí wọ́n ṣe kọ Bíbélì jẹ́ àpẹẹrẹ àgbàyanu kan nípa bí Jèhófà ṣe ń lo ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ torí pé àwọn tó kọ ọ́ “sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.” (2 Pét. 1:21) Bá a bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ó lè mú ká túbọ̀ ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá ohun gbogbo. (Ìṣí. 4:11) Ìfẹ́ tó jẹ́ ànímọ́ fífani mọ́ra Jèhófà, ló mú kó di Ẹlẹ́dàá. (1 Jòh. 4:8) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká lè ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ tó sì tún jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa. Bí àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa, a máa láǹfààní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ títí ayé. (Gál. 5:16, 25) Ǹjẹ́ kí olúkúlùkù wa máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtàwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ ká sì jẹ́ kí ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa fi hàn pé a mọyì ìfẹ́ tí kò láàlà tí Ọlọ́run fi hàn nígbà tó lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti dá ọ̀run, ilẹ̀ ayé àti ìran èèyàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Wo ojú ìwé 24 àti 25 nínú ìwé tó sọ nípa bí Ẹlẹ́dàá ṣe bìkítà nípa wa, ìyẹn, Is There a Creator Who Cares About You?
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ni ọ̀run àti ilẹ̀ ayé kọ́ wa nípa bí Ọlọ́run ṣe ń lo ẹ̀mí mímọ́?
• Àǹfààní wo la ní nítorí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá àwọn nǹkan?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà fìdí múlẹ̀?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Kí ni bí àgbáálá ayé wa ṣe wà létòlétò kọ́ wa nípa ìṣẹ̀dá?
[Credit Line]
Àwọn ìràwọ̀: Anglo-Australian Observatory/David Malin Images
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Kí ni èròjà DNA mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ohun abẹ̀mí yìí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ṣé o ti múra tán láti gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ?