Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ìgbọràn Sàn Ju Ẹbọ Lọ’

‘Ìgbọràn Sàn Ju Ẹbọ Lọ’

‘Ìgbọràn Sàn Ju Ẹbọ Lọ’

SỌ́Ọ̀LÙ ni ọba àkọ́kọ́ tó jẹ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run tòótọ́ ló yan Sọ́ọ̀lù sípò ọba, nígbà tó yá, ó di aláìgbọràn.

Ìwà búburú wo ni Sọ́ọ̀lù hù? Ṣé ohun kan wà tí ì bá ti ṣe kó má bàa hu irú ìwà bẹ́ẹ̀? Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú gbígbé àpẹẹrẹ rẹ̀ yẹ̀ wò?

Jèhófà Sọ Ẹni Tóun Fẹ́ Kó Jẹ́ Ọba

Kí Sọ́ọ̀lù tó di ọba, wòlíì Sámúẹ́lì ló ń ṣojú fún Ọlọ́run ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Sámúẹ́lì ti dàgbà báyìí, àwọn ọmọ rẹ̀ sì ti di aláìṣòótọ́. Ní àkókò yẹn kan náà, àwọn ọ̀tá ń halẹ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Nígbà tí àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì ní kí Sámúẹ́lì yan ọba kan táá máa ṣe ìdájọ́ wọn, táá sì máa ṣáájú wọn lójú ogun, Jèhófà ní kí wòlíì náà fòróró yan Sọ́ọ̀lù ṣe aṣáájú wọn, Ọlọ́run sì sọ pé: “Òun yóò sì gba àwọn ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Filísínì.”—1 Sám. 8:4-7, 20; 9:16.

Sọ́ọ̀lù “jẹ́ ọ̀dọ́, ó sì rẹwà.” Àmọ́, yàtọ̀ sí ìrísí Sọ́ọ̀lù, ó tún ní àwọn ànímọ́ míì tó mú kí Ọlọ́run yàn án gẹ́gẹ́ bí ọba. Ó tún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Sọ́ọ̀lù bi Sámúẹ́lì pé: “Èmi kì í ha ṣe ọmọ Bẹ́ńjámínì tí ó kéré jù lọ nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, tí ìdílé mi sì jẹ́ èyí tí ìjámọ́ pàtàkì rẹ̀ kéré jù lọ nínú gbogbo ìdílé ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì? Nítorí náà, èé ṣe tí o fi sọ irú ohun yìí fún mi?” Sọ́ọ̀lù kò ro ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá rẹ̀, Kíṣì jẹ́ ẹni tí “ọlà rẹ̀ yamùrá.”—1 Sám. 9:1, 2, 21.

Tún ronú nípa ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe nígbà tí Sámúẹ́lì kéde ní gbangba pé Sọ́ọ̀lù ni Jèhófà yàn gẹ́gẹ́ bí ọba lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Sámúẹ́lì kọ́kọ́ fi òróró yan Sọ́ọ̀lù ní ìkọ̀kọ̀, ó sì sọ fún un pé: “Kí o ṣe ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí pé ó ṣeé ṣe fún ara rẹ, nítorí pé Ọlọ́run tòótọ́ wà pẹ̀lú rẹ.” Lẹ́yìn náà, wòlíì yẹn pe àwọn èèyàn náà jọ kó lè sọ ẹni tí Jèhófà yàn fún wọn. Àmọ́ nígbà tó sọ fún wọn tán, kò rí Sọ́ọ̀lù mọ́. Ńṣe ni Sọ́ọ̀lù lọ fara pa mọ́ torí pé ojú ń tì í. Jèhófà sọ ibi tí Sọ́ọ̀lù wà, wọ́n sì kéde pé ó ti di ọba.—1 Sám. 10:7, 20-24.

Lójú Ogun

Kò pẹ́ tí Sọ́ọ̀lù fi mú kó ṣe kedere sí ẹnikẹ́ni tó bá ń rò pé kò tóótun pé òun tóótun. Nígbà tí àwọn ọmọ Ámónì fẹ́ wá gbéjà ko ọ̀kan lára àwọn ìlú tó wà ní Ísírẹ́lì, “ẹ̀mí Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára Sọ́ọ̀lù.” Ó pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn jagunjagun orílẹ̀-èdè náà kóra jọ, ó ṣètò wọn, ó sì ṣáájú wọn nínú ogun tí wọ́n fi borí àwọn ọ̀tá wọn. Síbẹ̀, Ọlọ́run ni Sọ́ọ̀lù gbà pé ó mú káwọn borí, ó ní: “Lónìí Jèhófà ti ṣe ìgbàlà ní Ísírẹ́lì.”—1 Sám. 11:1-13.

Sọ́ọ̀lù ní àwọn ànímọ́ tó dáa, Ọlọ́run sì bù kún un. Ó sì tún gbà pé agbára Jèhófà ló mú kí òun ṣàṣeyọrí. Àmọ́ ṣá o, bí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti ọba wọn bá fẹ́ máa bá a lọ láti ṣe àṣeyọrí, ohun pàtàkì kan wà tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe. Sámúẹ́lì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Bí ẹ óò bá bẹ̀rù Jèhófà, tí ẹ ó sì sìn ín ní ti tòótọ́, tí ẹ ó sì ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀, tí ẹ kì yóò sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, ẹ̀yin àti ọba náà tí yóò jẹ lé yín lórí, dájúdájú, yóò jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jèhófà Ọlọ́run yín.” Kí ló yẹ kó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú bí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run? Sámúẹ́lì sọ fún wọn pé: “Jèhófà kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀, nítorí pé Jèhófà ti dáwọ́ lé e láti fi yín ṣe ènìyàn rẹ̀.”—1 Sám. 12:14, 22.

Nígbà yẹn, ohun pàtàkì téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó lè rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run ni pé kó jẹ́ onígbọràn, bọ́ràn sì ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀, ó máa ń bù kún wọn. Àmọ́ bí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí Jèhófà ńkọ́?

Ìwọ Ti Hùwà Òmùgọ̀”

Wàyí o, ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe sí ẹgbẹ́ ogun àwọn Filísínì mú kí wọ́n dìde ogun sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun “bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó” wá láti gbéjà ko Sọ́ọ̀lù. “Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì fúnra wọn . . . rí i pé wọ́n wà nínú hílàhílo, nítorí pé a ni àwọn ènìyàn náà lára dé góńgó; àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara wọn pa mọ́ sínú àwọn hòrò àti sínú àwọn ibi jíjinkòtò àti àwọn àpáta gàǹgà àti ihò abẹ́lẹ̀ àti àwọn kòtò omi.” (1 Sám. 13:5, 6) Kí ni Sọ́ọ̀lù máa ṣe báyìí?

Sámúẹ́lì ti sọ fún Sọ́ọ̀lù pé kó pàdé òun ní Gílígálì, níbi tí wòlíì náà ti máa rúbọ. Sọ́ọ̀lù dúró de Sámúẹ́lì, àmọ́ ó pẹ́ kí Sámúẹ́lì tó dé, àwọn ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù sì ń tú ká. Ni Sọ́ọ̀lù bá fúnra rẹ̀ rú àwọn ẹbọ náà. Bó ṣe rúbọ tán ni Sámúẹ́lì dé. Lẹ́yìn tí Sámúẹ́lì gbọ́ ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe, Sámúẹ́lì sọ fún un pé: “Ìwọ ti hùwà òmùgọ̀. Ìwọ kò pa àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, èyí tí ó pa láṣẹ fún ọ, nítorí pé, ká ní o ti ṣe bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ì bá ti mú kí ìjọba rẹ fìdí múlẹ̀ gbọn-in lórí Ísírẹ́lì fún àkókò tí ó lọ kánrin. Wàyí o, ìjọba rẹ kì yóò pẹ́. Dájúdájú, Jèhófà yóò wá ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà rẹ̀ lọ́rùn fún ara rẹ̀; Jèhófà yóò sì fàṣẹ yàn án ṣe aṣáájú lórí àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún ọ mọ́.”—1 Sám. 10:8; 13:8, 13, 14.

Nítorí pé Sọ́ọ̀lù kò ní ìgbàgbọ́, ó fi ìkùgbù ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run pé kó dúró dé Sámúẹ́lì tó máa wá rú ẹbọ náà. Ìwà tí Sọ́ọ̀lù hù yìí yàtọ̀ gedegbe sí ti Gídíónì, tó jẹ́ ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì nígbà kan. Jèhófà ní kí Gídíónì dín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kù láti ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n [32,000] sí ọ̀ọ́dúnrún [300], Gídíónì sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí tó fi ṣègbọràn? Ìdí ni pé ó ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ó borí ẹgbẹ̀rún márùnléláàádóje [135,000] àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wá gbéjà kò ó. Jèhófà ì bá ran Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú lọ́wọ́. Àmọ́, àìgbọràn Sọ́ọ̀lù mú kí àwọn ọmọ ogun Filísínì kó Ísírẹ́lì lẹ́rù lọ.—1 Sám. 13:17, 18.

Nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro, báwo ló ṣe yẹ ká pinnu ohun tó yẹ ká ṣe? Ó lè dà bí ohun tó bọ́gbọ́n mu lójú àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ pé kéèyàn kọ ẹ̀yìn sí àwọn ìlànà Ọlọ́run. Torí pé Sámúẹ́lì kò tíì dé, Sọ́ọ̀lù lè ti ronú pé ohun tó bọ́gbọ́n mu lòun ṣe yẹn. Àmọ́, ní ti àwọn tó ń fẹ́ láti rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, títẹ̀ lé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó jẹ mọ́ ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ ni ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ láti ṣe.

Jèhófà Kọ Sọ́ọ̀lù Sílẹ̀

Nígbà kan tí Sọ́ọ̀lù lọ bá àwọn ọmọ Ámálékì jà, ó tún ṣe àṣìṣe kan tó burú jáì. Ọlọ́run ti dẹ́bi fún àwọn ọmọ Ámálékì torí bí wọ́n ṣe gbéjà ko Ísírẹ́lì láìnídìí lẹ́yìn tí wọ́n jáde kúrò ní Íjíbítì. (Ẹ́kís. 17:8; Diu. 25:17, 18) Bákan náà, àwọn ọmọ Ámálékì lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn míì láti gbéjà ko àwọn èèyàn tó jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run lákòókò àwọn Onídàájọ́. (Oníd. 3:12, 13; 6:1-3, 33) Jèhófà bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Ámálékì wò, ó sì pàṣẹ pé kí Sọ́ọ̀lù mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí wọn.—1 Sám. 15:1-3.

Dípò kí Sọ́ọ̀lù ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé kó pa àwọn ará Ámálékì àti àwọn ohun ìní wọn run, ńṣe ló mú ọba wọn lóǹdè tó sì tọ́jú èyí tó dáa jù nínú agbo ẹran wọn. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sámúẹ́lì béèrè ohun tó fà á tí Sọ́ọ̀lù fi ṣe bẹ́ẹ̀? Sọ́ọ̀lù gbìyànjú láti di ẹ̀bi ìṣìnà rẹ̀ ru àwọn míì nípa sísọ pé: “Àwọn ènìyàn náà ní ìyọ́nú sí èyí tí ó dára jù lọ nínú agbo ẹran àti nínú ọ̀wọ́ ẹran, fún ète rírúbọ sí Jèhófà.” Yálà Sọ́ọ̀lù fẹ́ fi àwọn ẹranko náà rúbọ sí Jèhófà lóòótọ́ tàbí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tó dájú ni pé ó ti ṣàìgbọràn. Sọ́ọ̀lù kò ‘kéré lójú ara rẹ̀’ mọ́. Torí náà, wòlíì Ọlọ́run sọ fún Sọ́ọ̀lù pé ó ti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Sámúẹ́lì wá sọ pé: “Jèhófà ha ní inú dídùn sí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ bí pé kí a ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣègbọràn sàn ju ẹbọ . . . Níwọ̀n bí o ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, òun kọ̀ ọ́ ní ọba.”—1 Sám. 15:15, 17, 22, 23.

Nígbà tí Jèhófà mú ẹ̀mí mímọ́ àti ìbùkún rẹ̀ kúrò lára Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì, “ẹ̀mí búburú” bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso rẹ̀. Sọ́ọ̀lù wá bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí Dáfídì, tí Jèhófà máa tó fi jọba, ó sì ń jowú rẹ̀. Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí Sọ́ọ̀lù gbìyànjú láti pa Dáfídì. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù rí i pé “Jèhófà wà pẹ̀lú Dáfídì,” Bíbélì sọ pé “Sọ́ọ̀lù sì wá jẹ́ ọ̀tá Dáfídì nígbà gbogbo.” Sọ́ọ̀lù gbìyànjú láti mú Dáfídì balẹ̀, ó tiẹ̀ tún pàṣẹ pé kí wọ́n pa àwọn àlùfáà márùnlélọ́gọ́rin [85] àtàwọn míì. Abájọ tí Jèhófà fi kọ Sọ́ọ̀lù sílẹ̀!—1 Sám. 16:14; 18:11, 25, 28, 29; 19:10, 11; 20:32, 33; 22:16-19.

Nígbà táwọn ọmọ ogun Filísínì tún gbéjà ko Ísírẹ́lì, Sọ́ọ̀lù tọ àwọn abẹ́mìílò lọ níbi tó ti ń wá ìrànlọ́wọ́ asán kiri. Ní ọjọ́ kejì, ó fara gbọgbẹ́ yánnayànna lójú ogun, ó sì pa ara rẹ̀. (1 Sám. 28:4-8; 31:3, 4) Nígbà tí Ìwé Mímọ́ ń sọ̀rọ̀ nípa Sọ́ọ̀lù, ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì, ó sọ pé: ‘Sọ́ọ̀lù kú nítorí ìwà àìṣòótọ́ rẹ̀ èyí tí ó fi hùwà lọ́nà àìnígbàgbọ́ sí Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ Jèhófà tí kò pa mọ́ àti pẹ̀lú fún bíbéèrè lọ́wọ́ abẹ́mìílò pé kí ó ṣe ìwádìí. Kò sì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.’—1 Kíró. 10:13, 14.

Àpẹẹrẹ búburú Sọ́ọ̀lù fi hàn kedere pé ṣíṣègbọràn sí Jèhófà sàn ju rírú ẹbọ èyíkéyìí sí i. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòh. 5:3) Ǹjẹ́ kí òtítọ́ pàtàkì yìí má ṣe kúrò lọ́kàn wa láé: Ṣíṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run ló lè mú kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ tọ́jọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Sọ́ọ̀lù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nígbà tí Jèhófà yàn án

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kí nìdí tí Sámúẹ́lì fi sọ fún Sọ́ọ̀lù pé “ṣíṣègbọràn sàn ju ẹbọ”?