Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Bọ̀wọ̀ Fúnni
Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Bọ̀wọ̀ Fúnni
ÒWE Yorùbá kan sọ pé: “Ìwà rere ni ẹ̀ṣọ́ èèyàn.” Èyí fi hàn pé ó sàn láti jẹ́ èèyàn rere, torí pé àwọn èèyàn máa ń yẹ́ ẹni rere sí, wọ́n sì máa ń fẹ́ láti hùwà rere sí irú ẹni bẹ́ẹ̀.
Ó máa ń wúni lórí gan-an láti rí àwọn ọ̀dọ́ tó ní ìwà rere! Ní orílẹ̀-èdè Honduras, alábòójútó àyíká kan tó máa ń bá àwọn akéde tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí sọ pé, “Mo sábà máa ń rí i pé bí ọmọ kan tí wọ́n kọ́ dáadáa tó sì ń bọ̀wọ̀ fúnni bá ń bá onílé sọ̀rọ̀, ó máa ń wọ onílé náà lọ́kàn ju ọ̀rọ̀ tèmi lọ.”
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé lákòókò tá à ń gbé yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ bọ̀wọ̀ fúnni mọ́, ó bọ́gbọ́n mu ká máa hùwà tó dáa sáwọn èèyàn, ọ̀pọ̀ àǹfààní ló sì wà níbẹ̀. Síwájú sí i, Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé ká máa “hùwà lọ́nà tí ó yẹ ìhìn rere nípa Kristi.” (Fílí. 1:27; 2 Tím. 3:1-5) Ó ṣe pàtàkì pé ká kọ́ àwọn ọmọ wa láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíì. Báwo la ṣe lè kọ́ wọn láti máa bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn látọkàn wá, kó má wulẹ̀ jẹ́ lọ́nà àṣehàn lásán? *
Àwọn Ọmọ Máa Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Rere
Àwọn ọmọdé máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìwà táwọn ẹlòmíì ń hù. Torí náà, ọ̀nà pàtàkì kan táwọn òbí lè gbà kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa hùwà rere ni pé káwọn fúnra wọn níwà tó dáa. (Diu. 6:6, 7) Ó yẹ kó o fèrò wérò pẹ̀lú ọmọ rẹ nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé kó máa bọ̀wọ̀ fúnni, ṣùgbọ́n kò mọ síbẹ̀ o. Yàtọ̀ sí àwọn ìránnilétí tó ò ń fún un, ó tún ṣe pàtàkì gan-an pé kó o máa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀.
Gbé àpẹẹrẹ Arábìnrin Paula * yẹ̀ wò. Òbí anìkàntọ́mọ ni ìyá rẹ̀, inú ìdílé Kristẹni ni wọ́n sì bí i sí. Ó jẹ́ ìwà rẹ̀ láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn. Kí nìdí? Ó sọ pé, “Mọ́mì wa máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, ìyẹn ló fi mọ́ àwa ọmọ wọn lára láti máa bọ̀wọ̀ fúnni.” Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Walter kọ́ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti máa bọ̀wọ̀ fún ìyá wọn tí kì í ṣe Kristẹni. Ó sọ pé, “Mi ò kí ń sọ̀rọ̀ tí kò dára nípa ìyàwó mi, nípa bẹ́ẹ̀ mo fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ọmọ mi kí wọ́n lè máa bọ̀wọ̀ fún ìyá wọn.” Walter ń bá a nìṣó láti máa fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ìtọ́ni látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Ní báyìí, ọ̀kan lára wọ́n ti ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èkejì sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àwọn ọmọ náà fẹ́ràn àwọn òbí wọn méjèèjì, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn.
Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.” (1 Kọ́r. 14:33) Jèhófà máa ń ṣe gbogbo nǹkan rẹ̀ létòlétò. Torí náà ó yẹ kí àwọn Kristẹni sapá láti ní ànímọ́ Ọlọ́run yìí kí wọ́n sì jẹ́ káwọn nǹkan máa wà létòlétò nínú ilé wọn. Àwọn òbí kan ti kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n máa tẹ́ bẹ́ẹ̀dì wọn lójoojúmọ́ kí wọ́n tó lọ síléèwé, kí wọ́n máa tọ́jú aṣọ wọn síbi tó yẹ, kí wọ́n sì máa bá àwọn ṣiṣẹ́ ilé. Bí àwọn ọmọ bá rí i pé àyíká ilé máa ń wà létòlétò tó sì máa ń mọ́ tónítóní, àwọn náà á túbọ̀ máa fẹ́ kí yàrá wọn àtàwọn nǹkan wọn wà ní mímọ́.
Ojú wo làwọn ọmọ rẹ fi ń wo ohun tí wọ́n ń kọ́ níléèwé? Ǹjẹ́ wọ́n máa ń fi ìmọrírì hàn fún ẹ̀kọ́ tí àwọn olùkọ́ wọn ń kọ́ wọn? Gẹ́gẹ́ bí òbí, ṣé ìwọ náà ń fi irú ìmọrírì bẹ́ẹ̀ hàn? Ojú tí òbí bá fi ń wo iṣẹ́ iléèwé àti olùkọ́ àwọn ọmọ làwọn ọmọ náà sábà fi máa ń wò wọ́n. O ò ṣe fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ wọn? Ọ̀nà tó dára jù lọ téèyàn lè gbà bọ̀wọ̀ fún olùkọ́, dókítà, ẹni tó ń tajà tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn ni pé kéèyàn dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn bí wọ́n bá ṣe nǹkan fúnni. (Lúùkù 17:15, 16) Ó yẹ ká gbóríyìn fún àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tí ìwà rere wọn àti bí wọ́n ṣe máa ń bọ̀wọ̀ fúnni mú kí wọ́n dá yàtọ̀ láàárín àwọn ojúgbà wọn níléèwé.
Ó yẹ kí ìwà tí àwọn ará nínú ìjọ Kristẹni ń hù jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Ẹ wo bó ti dára tó kí àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ Kristẹni máa fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn nípa lílo àwọn ọ̀rọ̀ bí “ẹ jọ̀wọ́” àti “ẹ ṣeun”! Bí àwọn àgbàlagbà bá bọ̀wọ̀ fún Jèhófà nípa títẹ́tí sí àwọn ìtọ́ni tá à ń gbà láwọn ìpàdé ìjọ, èyí máa fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Àpẹẹrẹ ìwà rere tá à ń hù ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lè kọ́ àwọn ọmọdé láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn aládùúgbò wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún mẹ́rin kan tó ń jẹ́ Andrew ti kọ́ láti máa sọ pé, “Ẹ jọ̀wọ́” tó bá fẹ́ gba ibi tí àgbàlagbà wà kọjá.
Ọ̀nà míì wo làwọn òbí tún lè gbà ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ irú ìwà tó yẹ kí wọ́n máa hù? Ohun táwọn òbí lè ṣe tó sì yẹ kí wọ́n ṣe ni pé kí wọ́n wá àkókò láti fi jíròrò ẹ̀kọ́ táwọn ọmọ wọn lè rí kọ́ látinú ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Róòmù 15:4.
Fi Àpẹẹrẹ Inú Bíbélì Kọ́ Wọn
Ó ṣeé ṣe kí ìyá Sámúẹ́lì ti kọ́ ọ bí yóò ṣe máa tẹrí ba fún Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà. Sámúẹ́lì lè máà tíì ju ọmọ ọdún mẹ́ta tàbí mẹ́rin lọ nígbà tí ìyá rẹ̀ mú un lọ sí àgọ́ ìjọsìn. (1 Sám. 1:28) O ò ṣe kọ́ àwọn ọmọ rẹ ní àwọn ìkíni bí “ẹ káàárọ̀,” “ẹ káàsán,” “ẹ kú ìrọ̀lẹ́,” tàbí irú àwọn ìkíni míì tó wọ́pọ̀ ládùúgbò yín? Bíi ti ọ̀dọ́ náà Sámúẹ́lì, àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú lè “jẹ́ ẹni tí a fẹ́ràn ní ojú ìwòye Jèhófà àti ti àwọn ènìyàn.”—1 Sám. 2:26.
O ò ṣe lo àwọn ìtàn inú Bíbélì láti fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀wọ̀ àti àrífín han àwọn ọmọ rẹ? Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ahasáyà Ọba Ísírẹ́lì tó jẹ́ aláìṣòótọ́ fẹ́ rí wòlíì Èlíjà, ó rán ‘olórí àádọ́ta àti àwọn àádọ́ta ọkùnrin rẹ̀’ láti lọ pe Èlíjà wá. Ọ̀gágun náà sọ pé kí wòlíì náà bá òun ká lọ. Kò yẹ kó bá ẹni tó jẹ́ aṣojú Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lọ́nà yẹn. Kí ni Èlíjà sọ? Ó sọ pé: “Tóò, bí mo bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run, kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kí ó sì jẹ ìwọ àti àádọ́ta rẹ run.” Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. “Iná sì ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ wá, ó sì jẹ òun àti àádọ́ta rẹ̀ run.”—Ọba náà tún rán àwọn olórí àádọ́ta mìíràn láti lọ mú Èlíjà wá. Òun náà tún pàṣẹ pé kí Èlíjà bá òun ká lọ. Lẹ́ẹ̀kan sí i, iná tún sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run. Àmọ́ lẹ́yìn náà, olórí àádọ́ta kẹta wá bá Èlíjà. Ọ̀gágun yìí bọ̀wọ̀ fún Èlíjà ní tiẹ̀. Dípò kó pàṣẹ fún Èlíjà, ńṣe ló tẹ̀ ba lórí eékún rẹ̀, ó sì bẹ̀bẹ̀ pé: “Ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ọkàn mi àti ọkàn àádọ́ta ìránṣẹ́ rẹ wọ̀nyí ṣe iyebíye ní ojú rẹ. Kíyè sí i, iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, ó sì jẹ olórí àádọ́ta méjì ìṣáájú àti àádọ́ta-àádọ́ta wọn run, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, jẹ́ kí ọkàn mi ṣe iyebíye ní ojú rẹ.” Ṣé wòlíì Ọlọ́run máa ní kí iná tún sọ̀ kalẹ̀ sórí ẹni tó ṣeé ṣe kí ẹ̀rù máa bà ṣùgbọ́n tó sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ yìí? Kò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀! Kàkà bẹ́ẹ̀, áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Èlíjà pé kí ó tẹ̀ lé ọ̀gágun náà. (2 Ọba 1:11-15) Ǹjẹ́ ìtàn yìí kò mú ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa bọ̀wọ̀ fúnni?
Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù mú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti inú tẹ́ńpìlì lọ sí ibùdó wọn, kò ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀. Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ló fi bi ọ̀gágun tó wà níbẹ̀ pé: “A ha yọ̀ǹda fún mi láti sọ ohun kan fún ọ bí?” Torí bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ yìí, wọ́n gbà á láyè láti gbèjà ara rẹ̀.—Ìṣe 21:37-40.
Nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ Jésù lọ́wọ́, ẹnì kan gbá a lójú. Síbẹ̀, Jésù mọ béèyàn ṣe ń fi hàn pé nǹkan kò tẹ́ òun lọ́rùn, ó ní: “Bí mo bá sọ̀rọ̀ lọ́nà àìtọ́, jẹ́rìí ní ti ohun àìtọ́ náà; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ lọ́nà títọ́, èé ṣe tí ìwọ fi gbá mi?” Kò sẹ́ni tó lè sọ pé ohun tí Jésù sọ yìí burú.—Jòh. 18:22, 23.
Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a tún rí oríṣiríṣi àpẹẹrẹ tó jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ kéèyàn fèsì nígbà tó bá gba ìbáwí mímúná, ó sì tún jẹ́ ká mọ béèyàn ṣe lè fi hàn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé òun ti ṣe àṣìṣe tàbí pé òun kò ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe. (Jẹ́n. 41:9-13; Ìṣe 8:20-24) Bí àpẹẹrẹ, Ábígẹ́lì tọrọ àforíjì nígbà tí Nábálì ọkọ rẹ̀ ṣe àfojúdi sí Dáfídì. Lẹ́yìn tó tọrọ àforíjì tán, ó tún kó ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn oúnjẹ lọ fún Dáfídì. Ohun tí Ábígẹ́lì ṣe yìí wọ Dáfídì lọ́kàn débi pé nígbà tí Nábálì kú, ó fi Ábígẹ́lì ṣe aya.—1 Sám. 25:23-41.
Kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti máa bọ̀wọ̀ fúnni, yálà nípa fífi ọ̀wọ̀ hàn nígbà tí wọ́n bá bára wọn nípò tó nira tàbí kí wọ́n mọ béèyàn ṣe ń hùwà rere. Lọ́nà yìí, a ó máa jẹ́ ‘kí ìmọ́lẹ̀ wa tàn níwájú àwọn ènìyàn’ èyí á sì máa ‘fi ògo fún Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.’—Mát. 5:16.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Àmọ́ ṣá o, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín bíbọ̀wọ̀ fún àgbà àti ṣíṣe ohun tí ẹnì kan tó ní èrò tó lè ṣèpalára fún wọn lọ́kàn ní kí wọ́n ṣe. Wo Jí! October 2007, ojú ìwé 3 sí 11.
^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.