Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ o Kórìíra Ìwà Àìlófin?

Ǹjẹ́ o Kórìíra Ìwà Àìlófin?

Ǹjẹ́ o Kórìíra Ìwà Àìlófin?

‘Jésù kórìíra ìwà àìlófin.’—HÉB. 1:9.

1. Kí ni Jésù kọ́ni nípa ìfẹ́?

 NÍGBÀ tí Jésù Kristi ń tẹnu mọ́ bí ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:34, 35) Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. Ìfẹ́ yẹn ni àmì táwọn èèyàn á fi máa dá wọn mọ̀. Jésù tún gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.”—Mát. 5:44.

2. Kí ló yẹ káwọn ọmọlẹ́yìn Kristi kórìíra?

2 Àmọ́, yàtọ̀ sí pé Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ní ìfẹ́, ó tún kọ́ wọn ni ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ kórìíra. Bíbélì sọ nípa Jésù pé: “Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà àìlófin [ìwà burúkú].” (Héb. 1:9; Sm. 45:7) Èyí fi hàn pé kì í ṣe pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ òdodo nìkan ni, àmọ́ a gbọ́dọ̀ kórìíra ẹ̀ṣẹ̀, tàbí ìwà àìlófin pẹ̀lú. Ó yẹ ká kíyè sí i pé àpọ́sítélì Jòhánù sọ ní pàtó pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà ń sọ ìwà àìlófin dàṣà pẹ̀lú, nítorí náà, ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ìwà àìlófin.”—1 Jòh. 3:4.

3. Àwọn ọ̀nà wo tá a lè gbà kórìíra ìwà àìlófin nínú ìgbésí ayé wa la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Torí náà, níwọ̀n bí a ti jẹ́ Kristẹni, ó dára ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mo kórìíra ìwà àìlófin?’ Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà mẹ́rin tá a lè gbà fi hàn nínú ìgbésí ayé wa pé a kórìíra ohun tó burú: (1) ojú tá a fi ń wo ọtí àmujù, (2) ojú tá a fi ń wo iṣẹ́ awo, (3) èrò wa nípa ìṣekúṣe àti (4) ojú tá a fi ń wo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ìwà àìlófin.

Má Ṣe Sọ Ara Rẹ Di Ẹrú Ọtí Líle

4. Kí nìdí tí Jésù fi ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ nígbà tó ń kìlọ̀ fúnni nípa ọtí àmujù?

4 Jésù máa ń mu wáìnì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, torí ó mọ̀ pé ó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Sm. 104:14, 15) Àmọ́, kò ṣi ẹ̀bùn yìí lò rí nípa mímu ọtí ní àmujù. (Òwe 23:29-33) Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ nígbà tó ń gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe máa mutí ní àmujù. (Ka Lúùkù 21:34.) Ọtí àmujù lè mú kéèyàn dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì tó burú jáì. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa mu wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí ìwà wọ̀bìà wà, ṣùgbọ́n ẹ máa kún fún ẹ̀mí.” (Éfé. 5:18) Ó tún gba àwọn àgbà obìnrin tó wà nínú ìjọ níyànjú pé kí wọ́n má ṣe “di ẹrú fún ọ̀pọ̀ wáìnì.”—Títù 2:3.

5. Àwọn ìbéèrè wo làwọn tó yàn láti máa mu ọtí líle lè bi ara wọn?

5 Bó o bá yàn láti máa mu ọtí líle, ó máa dára kó o bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ojú tí Jésù fi ń wo ọtí àmujù ni èmi náà fi ń wò ó? Bó bá pọn dandan kí n gba àwọn míì nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn yìí, ǹjẹ́ mo ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ? Ǹjẹ́ mo máa ń mu ọtí láti fi pa ìrònú rẹ́ tàbí láti fi wá ìtura kúrò lọ́wọ́ ìdààmú ọkàn? Báwo ni ọtí tí mò ń mu lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ṣe pọ̀ tó? Báwo ló ṣe máa ń rí lára mi bí ẹnì kan bá sọ ohun tó fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí n ti máa mutí jù? Ṣé mo máa ń dá ara mi láre ni àbí ńṣe ni mo tiẹ̀ máa ń bínú?’ Bá a bá sọ ara wa di ẹrú ọtí líle ó lè mú ká di ẹni tí kò lè ronú lọ́nà tó já gaara àti ẹni tí kò lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi máa ń sapá láti dáàbò bo agbára ìrònú wọn.—Òwe 3:21, 22.

Sá fún Iṣẹ́ Awo

6, 7. (a) Kí ni Jésù ṣe fún Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù? (b) Kí nìdí tí iṣẹ́ awo fi gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ lónìí?

6 Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó kọ ojú ìjà sí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù. Kò gbà kí Sátánì ba ìdúróṣinṣin òun jẹ́. (Lúùkù 4:1-13) Nígbà tí èṣù sì fẹ́ fọgbọ́n ẹ̀wẹ́ yí i lérò pa dà kó lè mú un ṣe ohun tí kò tọ́, ó mọ̀, kò sì gbà láti ṣe ohun tí èṣù fẹ́. (Mát. 16:21-23) Jésù ran àwọn tó yẹ lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù tó ń fìwà òǹrorò tẹ̀ wọ́n lórí ba.—Máàkù 5:2, 8, 12-15; 9:20, 25-27.

7 Lẹ́yìn tí Jèhófà ti gbé Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba lọ́dún 1914, ó fọ ọ̀run mọ́ nípa lílé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò kí wọ́n má bàa ní ipa búburú lórí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yòókù. Nítorí èyí, Sátánì ti wá múra tán, ju ti ìgbàkígbà rí lọ, láti máa “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣí. 12:9, 10) Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé iṣẹ́ awo ń gbilẹ̀ sí i, ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Kí la lè ṣe ká bàa lè dáàbò bo ara wa?

8. Àyẹ̀wò wo ló yẹ kí ẹni kọ̀ọ̀kan wa ṣe nípa irú eré ìnàjú tá a yàn?

8 Bíbélì fún wa ní ìkìlọ̀ tó ṣe kedere nípa ewu tó wà nínú ìbẹ́mìílò. (Ka Diutarónómì 18:10-12.) Lónìí, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ máa ń fi fíìmù, ìwé àtàwọn géèmù orí kọ̀ǹpútà tó ń gbé iṣẹ́ awo lárugẹ, darí ìrònú àwọn èèyàn. Torí náà, bá a bá ń yan eré ìnàjú, ó yẹ ká bi ara wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé: ‘Láwọn oṣù tó kọjá, ǹjẹ́ mo ti fi fíìmù, ètò orí tẹlifíṣọ̀n, géèmù orí kọ̀ǹpútà, ìwé tàbí eré àwòrẹ́rìn-ín tó ń gbé iṣẹ́ awo lárugẹ dá ara mi lára yá? Ǹjẹ́ mo lóye bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí n má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ awo nípa lórí mi, àbí ńṣe ni mò ń fojú kékeré wo ewu tó wà níbẹ̀? Ǹjẹ́ mo tiẹ̀ ti ronú nípa ojú tó ṣeé ṣe kí Jèhófà máa fi wo irú eré ìnàjú tí mo yàn? Bí mo bá sì ti fọwọ́ ara mi yan irú eré ìnàjú tó lè mú kí Sátánì nípa lórí ẹni bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ìfẹ́ tí mo ní sí Jèhófà àtàwọn ìlànà òdodo rẹ̀ máa mú kí n gbé ìgbésẹ̀ láìjáfara kí n sì jáwọ́ nínú wọn?’—Ìṣe 19:19, 20.

Fetí sí Ìkìlọ̀ Jésù Nípa Ìṣekúṣe

9. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè nífẹ̀ẹ́ sí ìwà àìlófin?

9 Jésù gbé ìlànà Jèhófà nípa ìṣekúṣe lárugẹ. Ó sọ pé: “Ẹ kò ha kà pé ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’? Tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mát. 19:4-6) Jésù mọ̀ pé ohun tí ojú wa bá rí lè nípa lórí ọkàn-àyà wa. Torí náà, ó sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mát. 5:27, 28) Ó dájú pé ńṣe làwọn tí kò fetí sí ìkìlọ̀ Jésù ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ìwà àìlófin.

10. Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé ẹnì kan lè jáwọ́ kúrò nínú wíwo àwòrán oníhòòhò.

10 Sátánì máa ń lo àwọn àwòrán oníhòòhò láti fi gbé ìṣekúṣe lárugẹ. Irú àwọn àwòrán bẹ́ẹ̀ sì pọ̀ gan-an nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ó máa ń ṣòro fún àwọn tó ń wo àwòrán oníhòòhò láti pa àwọn ohun tí wọ́n ti wò rẹ́ kúrò lọ́kàn wọn. Wíwo àwòrán náà tiẹ̀ lè di bárakú sí wọn lára. Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan. Ó sọ pé: “Mo máa ń wo àwòrán oníhòòhò ní ìkọ̀kọ̀. Lọ́kàn ara mi, mò ń gbé nínú ayé méjì; ọ̀kan tó fàyè gba wíwo ìṣekúṣe, èyí ti mo rò pé kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ayé kejì tí mo ti ń sin Jèhófà. Mo mọ̀ pé ohun tí kò dáa ni mò ń ṣe, àmọ́ mo máa ń mú un dá ara mi lójú pé Ọlọ́run ṣì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn mi.” Kí ló yí èrò arákùnrin yìí pa dà? Ó sọ pé: “Mo pinnu láti sọ ìṣòro tí mo ní yìí fún àwọn alàgbà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó tíì ṣòro jù lọ fún mi láti ṣe nìyẹn.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, arákùnrin náà jáwọ́ nínú àṣà tí ń rẹni sílẹ̀ yìí. Ó wá sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ti wẹ ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá gbà pé mo ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.” Àwọn tó bá kórìíra ìwà àìlófin gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ó yẹ káwọn kórìíra wíwo àwòrán oníhòòhò.

11, 12. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a kórìíra ìwà àìlófin tá a bá fẹ́ yan orin?

11 Orin àti àwọn ọ̀rọ̀ orin lè nípa tó lágbára lórí ìmọ̀lára wa, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ nípa lórí ọkàn-àyà wa. Orin fúnra rẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ó sì ti pẹ́ tá a ti ń lò ó nínú ìjọsìn tòótọ́. (Ẹ́kís. 15:20, 21; Éfé. 5:19) Àmọ́, ayé búburú Sátánì máa ń ṣagbátẹrù àwọn orin tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ. (1 Jòh. 5:19) Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá orin tó ò ń tẹ́tí sí lè sọ ẹ di oníwàkiwà?

12 O lè bẹ̀rẹ̀ nípa bíbi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ àwọn orin tí mò ń tẹ́tí sí ń gbé ìpànìyàn, panṣágà, àgbèrè àti ọ̀rọ̀ òdì lárugẹ? Bí mo bá ní láti ka àwọn ọ̀rọ̀ orin kan sí ẹnì kan létí, ǹjẹ́ ẹni yẹn máa gbà pé mo kórìíra ìwà àìlófin àbí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà máa fi hàn pé ọkàn mi ti di ẹlẹ́gbin?’ A kò lè sọ pé a kórìíra ìwà àìlófin, síbẹ̀ ká tún máa tẹ́tí sí orin tó ń gbé e lárugẹ. Jésù sọ pé: “Àwọn ohun tí ń jáde láti ẹnu ń jáde láti inú ọkàn-àyà, ohun wọnnì sì ni ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin. Fún àpẹẹrẹ, láti inú ọkàn-àyà ni àwọn èrò burúkú ti ń wá, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, àwọn èké gbólóhùn ẹ̀rí, àwọn ọ̀rọ̀ òdì.”—Mát. 15:18, 19; fi wé Jákọ́bù 3:10, 11.

Máa Fi Ojú Tí Jésù Fi Ń Wo Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Ìwà Àìlófin Wò Wọ́n

13. Ojú wo ni Jésù fi wo àwọn tó ti jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀?

13 Jésù sọ pé òun wá láti pe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí àwọn aláìlófin wá sí ìrònúpìwàdà. (Lúùkù 5:30-32) Àmọ́, ojú wo ló fi wo àwọn tó ti jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀? Jésù fún wa ní ìkìlọ̀ tó lágbára pé ká má ṣe jẹ́ kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nípa lórí wa. (Mát. 23:15, 23-26) Ó tún sọ lọ́nà tó ṣe kedere pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn [nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ ṣẹ], pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’” Àmọ́, ó máa fi hàn pé òun kò tẹ́wọ́ gba àwọn tí kò ronú pìwà dà tí wọ́n sì ń hùwà àìlófin, nípa sísọ fún wọn pé: “Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi.” (Mát. 7:21-23) Kí nìdí tí wọ́n fi máa gba irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò bọlá fún Ọlọ́run, wọ́n sì ń kó ìnira bá àwọn ẹlòmíì nípasẹ̀ ìwà àìlófin wọn.

14. Kí nìdí tá a fi ń yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ?

14 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pàṣẹ pé ká yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ. (Ka 1 Kọ́ríńtì 5:9-13.) Èyí sì ṣe pàtàkì fún ìdí mẹ́ta, ó kéré tán: (1) ká má bàa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà, (2) láti dáàbò bo ìjọ lọ́wọ́ ohun tó lè kó èèràn ran àwọn ará àti (3) bó bá ṣeé ṣe, láti ran ẹlẹ́ṣẹ̀ náà lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà.

15. Bá a bá fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ló yẹ ká wá ìdáhùn sí?

15 Ǹjẹ́ ojú tí Jésù fi ń wo àwọn tó ti jingíri sínú ìwà àìlófin làwa náà fi ń wò wọ́n? Ó yẹ ká ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí: ‘Ǹjẹ́ mo máa yàn láti máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé pẹ̀lú ẹnì kan tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni tàbí ẹni tó ti mú ara rẹ̀ kúrò lẹ́gbẹ́? Bí ẹni yẹn bá jẹ́ ìbátan wa tímọ́tímọ́ tí a kò jọ gbé nínú ilé kan náà mọ́ ńkọ́?’ Irú ipò bẹ́ẹ̀ lè dán ìfẹ́ tá a ní fún òdodo àti bá a ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run tó wò. *

16, 17. Ìṣòro wo ni ìyá kan tó jẹ́ Kristẹni dojú kọ, kí ló sì ràn án lọ́wọ́ tó fi fara mọ́ yíyọ oníwà àìtọ́ tí kò bá ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́?

16 Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tí ọmọ rẹ̀ tó ti dàgbà ti fìgbà kan rí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Nígbà tó yá ọmọ náà yàn láti máa hùwà àìlófin, kò sì ronú pìwà dà. Nítorí èyí, wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ. Arábìnrin wa yìí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àmọ́ ó tún nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ náà ó sì rí i pé ó ṣòro fún òun láti tẹ̀ lé àṣẹ Ìwé Mímọ́ pé kí òun má bá a kẹ́gbẹ́.

17 Ìmọ̀ràn wo lò bá fún arábìnrin yìí ná? Alàgbà kan jẹ́ kó yé e pé Jèhófà mọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ṣe dùn ún tó. Arákùnrin náà ní kó ronú nípa bó ṣe dun Jèhófà tó nígbà tí àwọn kan lára àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ rẹ̀ di ọlọ̀tẹ̀. Ó wá ṣàlàyé fún un pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà mọ bí irú ipò bẹ́ẹ̀ ti nira tó, síbẹ̀ ó sọ pé kí wọ́n yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. Ó fi àwọn ìránnilétí náà sọ́kàn ó sì fara mọ́ yíyọ tí wọ́n yọ ọmọ náà lẹ́gbẹ́. * Irú ìdúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ máa ń mú ọkàn-àyà Jèhófà yọ̀.—Òwe 27:11.

18, 19. (a) Bí a kò bá da nǹkan kan pọ̀ pẹ̀lú ẹni tó ń hùwà àìlófin, kí nìyẹn máa fi hàn pé a kórìíra? (b) Kí ló máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ bá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run tá a sì fara mọ́ ìṣètò rẹ̀?

18 Bí ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, jọ̀wọ́ rántí pé Jèhófà mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ. Bí o kò bá ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ tàbí ẹni tó mú ara rẹ̀ kúrò lẹ́gbẹ́, ńṣe lò ń fi hàn pé o kórìíra ohun tí onítọ̀hún ṣe àti ìṣarasíhùwà rẹ̀. O tún ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ oníwà àìtọ́ náà àti pé wàá fẹ́ láti ṣe ohun tó máa ṣe é láǹfààní jù lọ. Bó o ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà tún lè mú kó túbọ̀ ṣeé ṣe fún ẹni tí wọ́n bá wí náà láti ronú pìwà dà kó sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.

19 Ẹnì kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ tí wọ́n sì gbà pa dà lẹ́yìn náà kọ̀wé pé: “Mo láyọ̀ pé nítorí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn èèyàn rẹ̀ ó ń rí i dájú pé ètò òun wà ní mímọ́. Bí ìbáwí yìí tilẹ̀ dà bí ohun tó le koko jù lójú àwọn ará ìta, ó jẹ́ ohun tó pọn dandan àti ohun tó fìfẹ́ hàn ní tòótọ́ láti ṣe.” Ṣó o rò pé ẹni yìí ì bá ti gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyí ká sọ pé àwọn ará ìjọ, tó fi mọ́ àwọn ará ilé rẹ̀, ń bá a ṣe wọlé wọ̀de lákòókò tí wọ́n fi yọ ọ́ lẹ́gbẹ́? Bá a bá fara mọ́ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìyọlẹ́gbẹ́, ìyẹn máa jẹ́ ẹ̀rí pé a fẹ́ràn òdodo a sì mọyì ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti fún wa ní ìlànà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé.

“Kórìíra Ohun Búburú”

20, 21. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kọ́ láti kórìíra ìwà àìlófin?

20 Àpọ́sítélì Pétérù kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára.” Kí nìdí? Ìdí ni pé “elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pét. 5:8) Ṣé ìwọ ló máa rí pa jẹ? Ìyẹn sinmi lórí bó o bá ṣe kórìíra ìwà àìlófin tó.

21 Kò rọrùn láti kórìíra ohun tó burú. Inú ẹ̀ṣẹ̀ la bí wa sí, a sì ń gbé nínú ayé kan tó ń gbé ìfẹ́ ẹran ara lárugẹ. (1 Jòh. 2:15-17) Àmọ́, bá a bá ń fara wé Jésù Kristi tá a sì ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti kórìíra ìwà àìlófin. Ẹ jẹ́ ká pinnu láti “kórìíra ohun búburú” ká sì ní ìgbọ́kànlé kíkún pé Jèhófà “ń ṣọ́ . . . àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀; ó ń dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.”—Sm. 97:10.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí kókó yìí, wo Ilé Ìṣọ́ January 15, 1982, ojú ìwé 26 sí 31.

^ Tún wo Ilé Ìṣọ́ January 15, 2007, ojú ìwé 17 sí 20.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ojú tá a fi ń wo ọtí líle yẹ̀ wò?

• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ iṣẹ́ awo?

• Kí nìdí tó fi léwu láti máa wo àwòrán oníhòòhò?

• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a kórìíra ìwà àìlófin bí wọ́n bá yọ èèyàn wa kan lẹ́gbẹ́?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Bó o bá yàn láti máa mu ọtí líle, kí ló yẹ kó o gbé yẹ̀ wò?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ṣọ́ra fún eré ìnàjú tó lè mú kí Sátánì nípa lórí ẹni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kí lẹni tó bá ń wo àwòrán oníhòòhò ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ sí?