Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Má Ṣe Fi Èrò Èké Tan Ara Yín Jẹ

Ẹ Má Ṣe Fi Èrò Èké Tan Ara Yín Jẹ

Ẹ Má Ṣe Fi Èrò Èké Tan Ara Yín Jẹ

LẸ́YÌN tí Éfà ti jẹ lára èso igi tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un pé kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni ìwọ ṣe yìí?” Éfà dá a lóhùn pé: “Ejò—òun ni ó tàn mí, nítorí náà, mo sì jẹ.” (Jẹ́n. 3:13) Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Bíbélì pe Sátánì tó fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí lo ejò láti tan Éfà jẹ ní “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, . . . tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.”—Ìṣí. 12:9.

Ìtàn tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì fi Sátánì hàn bí ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, tó máa ń gbé irọ́ kalẹ̀ kó lè tan ẹni tí kò bá kíyè sára jẹ. Ó sì dájú pé Éfà kó sínú páńpẹ́ ẹ̀tàn rẹ̀. Síbẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ ronú pé Sátánì nìkan ṣoṣo ló lè tàn wá jẹ. Bíbélì tún kìlọ̀ fún wa nípa ewu tó wà nínú ‘fífi èrò èké tan ara wa jẹ.’—Ják. 1:22.

A lè máa ronú pé bóyá la lè tan ara wa jẹ tàbí pé kò tiẹ̀ ṣeé ṣe fún wa láti tan ara wa jẹ. Síbẹ̀, ó nídìí tí Ọlọ́run fi kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe fi èrò èké tan ara wa jẹ. Torí náà, ó dára ká ṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀nà tá a lè gbà tan ara wa jẹ àti irú èrò òdì tó lè ṣì wá lọ́nà. Àpẹẹrẹ kan wà nínú Ìwé Mímọ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́.

Àwọn Tó Tan Ara Wọn Jẹ

Ní nǹkan bí ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Kírúsì Ńlá ti ilẹ̀ ọba Páṣíà pàṣẹ fún àwọn Júù tí àwọn ará Bábílónì kó nígbèkùn pé kí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n sì tún tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ kọ́. (Ẹ́sírà 1:1, 2) Ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jèhófà, ọdún tó tẹ̀ lé e ni àwọn Júù tó pa dà sílé láti ìgbèkùn yìí fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì tuntun lélẹ̀. Inú wọn dùn gan-an, wọ́n sì fi ìyìn fún Jèhófà torí bó ṣe mú kí apá àkọ́kọ́ lára iṣẹ́ pàtàkì náà kẹ́sẹ járí. (Ẹ́sírà 3:8, 10, 11) Àmọ́, kò pẹ́ táwọn kan fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtakò sí wọn torí pé wọ́n ń tún tẹ́ńpìlì náà kọ́, ìyẹn sì mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì. (Ẹ́sírà 4:4) Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lẹ́yìn tí wọ́n ti pa dà láti ìgbèkùn, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ ọba Páṣíà fi òfin de gbogbo iṣẹ́ àtúnkọ́ tí wọ́n ń ṣe ní Jerúsálẹ́mù. Kódà, kí àwọn aṣojú ìjọba tó ń bójú tó ẹkùn ìpínlẹ̀ náà lè rí i pé ìfòfindè yìí fìdí múlẹ̀, wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù wọ́n sì “fi ohun ìjà dá [àwọn Júù náà] dúró.”—Ẹ́sírà 4:21-24.

Ìṣòro líle koko tó dojú kọ àwọn Júù yìí mú kí wọ́n fi èrò èké tan ara wọn jẹ. Wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Àkókò kò tíì tó, àkókò tí a óò kọ́ ilé Jèhófà.” (Hág. 1:2) Wọ́n gbà lọ́kàn ara wọn pé Ọlọ́run kò tíì fẹ́ kí àwọn kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Dípò kí wọ́n wá bí wọ́n ṣe máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run, wọ́n pa iṣẹ́ mímọ́ tó gbé fún wọn tì wọ́n sì gbájú mọ́ bí wọ́n ṣe máa tún ilé ara wọn ṣe. Hágáì tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run bi wọ́n láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ pé: “Àkókò ha nìyí fún ẹ̀yin láti máa gbé nínú àwọn ilé yín tí a fi igi pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí, nígbà tí ilé yìí [tẹ́ńpìlì Jèhófà] wà ní ipò ahoro?”—Hág. 1:4.

Ǹjẹ́ o rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Bí a kò bá fi ojú tó tọ́ wo àkókò tí Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn ohun kan di ṣíṣe, àwọn nǹkan tara lè gbà wá lọ́kàn, ká sì bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ tí kò ṣe pàtàkì mú àwọn ojúṣe tó tan mọ́ ìjọsìn wa. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé ò ń retí àwọn àlejò kan. Ìyẹn lásán lè ti tó láti mú kó o máa yára ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ilé kí wọ́n lè gbádùn ara wọn. Àmọ́, ṣàdédé lo gbọ́ pé ó máa pẹ́ díẹ̀ kí wọ́n tó dé. Ṣé wàá torí rẹ̀ pa ìmúrasílẹ̀ tó ò ń ṣe tì?

Àmọ́, má ṣe gbàgbé pé Hágáì àti Sekaráyà mú kó yé àwọn Júù pé Jèhófà ṣì fẹ́ kí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì náà láìjáfara. Hágáì rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ . . . jẹ́ alágbára, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà, . . . kí ẹ sì ṣiṣẹ́.” (Hág. 2:4) Ó pọn dandan kí wọ́n máa bá iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ nìṣó, kí wọ́n sì ní ìgbọ́kànlé pé Ọlọ́run máa fi ẹ̀mí rẹ̀ ti àwọn lẹ́yìn. (Sek. 4:6, 7) Ǹjẹ́ àpẹẹrẹ yìí lè ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa ní èrò tí kò yẹ nípa ọjọ́ Jèhófà?—1 Kọ́r. 10:11.

Bá A Ṣe Lè Fi Èrò Tó Yè Kooro Rọ́pò Èrò Èké

Nínú lẹ́tà kejì tí àpọ́sítélì Pétérù kọ, ó sọ̀rọ̀ nípa bí “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” ṣe máa wà nígbà tó bá tó àkókò lójú Jèhófà. (2 Pét. 3:13) Ó sọ pé àwọn olùyọṣùtì á máa ṣiyè méjì pé bóyá ni Ọlọ́run máa dá sí ọ̀ràn aráyé. Bí ohun tí wọ́n ń sọ kò tilẹ̀ tọ̀nà, síbẹ̀ wọ́n á máa jiyàn pé “ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.” (2 Pét. 3:4) Pétérù fẹ́ láti fi hàn pé èrò òdì yìí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Torí náà, ó kọ̀wé pé: “Èmi ń ru agbára ìrònú yín ṣíṣe kedere sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìránnilétí.” Ó rán àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni létí pé ohun tí àwọn olùyọṣùtì náà ń sọ kò tọ̀nà. Ó sọ fún wọn pé Ọlọ́run ti dá sí ọ̀ràn aráyé rí nípa mímú àkúnya omi tó fa ìparun kárí ayé wá.—2 Pét. 3:1, 5-7.

Ní ọdún 520 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Hágáì náà sọ irú ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí fún àwọn Júù tó rẹ̀wẹ̀sì, tí wọn kò sì ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ mọ́. Ó sọ pé: “Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí àwọn ọ̀nà yín.” (Hág. 1:5) Kó bàa lè ru agbára ìrònú wọn sókè, ó rán àwọn tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run létí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe àti ìlérí tó ṣe fún wọn. (Hág. 1:8; 2:4, 5) Kò pẹ́ lẹ́yìn tó sọ̀rọ̀ ìṣírí yẹn fún wọn tí wọ́n fi pa dà sídìí iṣẹ́ ìkọ́lé náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ṣì fi òfin dè wọ́n. Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn tó ṣàtakò sí wọn tún gbìyànjú láti dá kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà dúró, àmọ́ wọn kò kẹ́sẹ járí. Nígbà tó ṣe, wọ́n mú ìfòfindè náà kúrò, iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà sì parí ní ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà.—Ẹ́sírà 6:14, 15; Hág. 1:14, 15.

Bá A Ṣe Lè Fi Ọkàn-Àyà Wa Sí Àwọn Ọ̀nà Wa

Bíi ti àwọn Júù ọjọ́ Hágáì, ǹjẹ́ o rò pé àwa náà lè rẹ̀wẹ̀sì bí ìṣòro bá dé? Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè ṣòro fún wa láti jẹ́ kí ìtara tá a ní fún wíwàásù ìhìn rere máa bá a nìṣó. Àmọ́, kí ló lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì? A lè máa jìyà nítorí ìwà àìṣòdodo tó kún inú ètò àwọn nǹkan yìí. Ronú nípa Hábákúkù tó béèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá, tí ìwọ kò sì gbà là?” (Háb. 1:2) Torí pé àwọn kan lè máa rò pé Ọlọ́run ń fi àkókò falẹ̀, èyí lè mú kí Kristẹni kan gbàgbé pé àkókò kánjúkánjú la wà yìí kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ. Àbí ìwọ náà ti gbàgbé pé àkókò kánjúkánjú la wà yìí? Bá a bá ń fi òjò àwọn tó rò pé Ọlọ́run ń fi nǹkan falẹ̀ gbin ọkà, a jẹ́ pé ńṣe là ń tan ara wa jẹ. Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká fara mọ́ ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ká ‘fi ọkàn-àyà wa sí àwọn ọ̀nà wa’ ká sì ‘ru agbára ìrònú wa ṣíṣe kedere sókè’! A lè bi ara wa pé, ‘Ṣó yẹ kí n máa ṣe kàyéfì pé ìparun ètò àwọn nǹkan búburú yìí ti pẹ́ ju bí mo ṣe rò lọ?’

Àkókò Tí Bíbélì Sọ Pé A Fi Máa Dúró

Sinmẹ̀dọ̀, kó o wá ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa ìparí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àlàyé tí Máàkù ṣe nípa àsọtẹ́lẹ̀ náà sì mú ká mọ̀ pé ó gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú léraléra pé kí wọ́n máa wà lójúfò. (Máàkù 13:33-37) A rí irú ìkìlọ̀ yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣàpèjúwe bí ọjọ́ Jèhófà ṣe máa rí nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣí. 16:14-16) Kí nìdí tí ìkìlọ̀ yẹn fi ń dún léraléra? Ó ṣe pàtàkì pé ká máa rí àwọn ìkìlọ̀ tó jẹ́ ìránnilétí yìí gbà torí bó bá ti dà bíi pé ó pẹ́ táwọn èèyàn ti ń dúró, wọ́n lè gbàgbé pé àkókò kánjúkánjú la wà yìí.

Jésù ṣàpèjúwe ìdí tó fi yẹ ká máa wà lójúfò ní gbogbo ìgbà bá a ṣe ń dúró de òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ó fúnni ní àpẹẹrẹ ẹnì kan táwọn olè wá kó ilé rẹ̀. Kí ni ì bá ti ṣe káwọn olè má bàa ráyè wọ ilé rẹ̀? Àfi kó wà lójúfò ní gbogbo òru. Ní ìparí àkàwé náà, ìmọ̀ràn tí Jésù fún wa ni pé: “Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.”—Mát. 24:43, 44.

Àkàwé yẹn fi hàn bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká múra tán láti dúró, kódà fún àkókò gígùn pàápàá. Ìyẹn ò wá ní ká máa ṣàníyàn jù pé bóyá ìparun ètò àwọn nǹkan búburú yìí ti pẹ́ ju bá a ṣe rò lọ. Kò yẹ ká fi èrò èké tan ara wa jẹ pé ‘àkókò Jèhófà kò tíì tó.’ Irú èrò bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ kó wù wá mọ́ láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Róòmù 12:11.

Bá A Ṣe Lè Fa Èrò Èké Tu

Bá a bá ń ní èrò èké, ìlànà inú Gálátíà 6:7 lè ràn wá lọ́wọ́. Ó ní: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà . . . Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” Bá a bá fi ilẹ̀ kan sílẹ̀ láì gbin ohunkóhun sórí rẹ̀, kò ní pẹ́ táwọn èpò á fi hù sórí ilẹ̀ náà. Bákan náà, bí a kò bá ru agbára ìrònú wa ṣíṣe kedere sókè, èrò èké lè ta gbòǹgbò nínú ọkàn wa. Bí àpẹẹrẹ, a lè sọ fún ara wa pé, ‘Ó dájú pé ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ lóòótọ́, àmọ́ kì í ṣe ní kíákíá bẹ́ẹ̀ yẹn.’ Bí a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bẹ́ẹ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà, ó lè yọrí sí pé ká máa fi ọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bó bá sì yá, a lè pa lílọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tì. Nípa bẹ́ẹ̀, ọjọ́ Jèhófà á dé bá wa lójijì.—2 Pét. 3:10.

Àmọ́, èrò èké kò ní ta gbòǹgbò nínú ọkàn wa bí àwa fúnra wa bá ń ṣàwárí “ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Ọ̀kan lára ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ jù lọ láti ṣe èyí ni pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Ìwé Mímọ́ lè mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ fìdí múlẹ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń gbé ìgbésẹ̀ ní àkókò tó ti yàn kalẹ̀.—Háb. 2:3.

Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, tá à ń gbàdúrà, tí a kì í pa ìpàdé àti òde ẹ̀rí jẹ, tí ìfẹ́ sì ń sún wa láti ṣe ohun rere fáwọn èèyàn, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti máa ‘fi dídé ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.’ (2 Pét. 3:11, 12) Jèhófà máa kíyè sí bá a ṣe ń sapá lójoojúmọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”—Gál. 6:9.

Ó dájú nígbà náà pé àkókò kọ́ nìyí láti fi èrò èké tan ara wá jẹ débi tí a ó fi máa ronú pé Jèhófà ti sún dídé ọjọ́ rẹ̀ síwájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àkókò tó yẹ ká ṣe ọkàn wa gírí, torí pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Hágáì àti Sekaráyà rọ àwọn Júù pé kí wọ́n kọ́lé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Bí onílé bá mọ̀ pé olè ń bọ̀, kí ni ì bá ti ṣe?