Ṣé Ò Ń jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí rẹ?
Ṣé Ò Ń jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí rẹ?
“Ẹ̀mí rẹ dára; kí ó máa ṣamọ̀nà mi ní ilẹ̀ ìdúróṣánṣán.”—SM. 143:10.
1, 2. (a) Sọ àwọn ìgbà díẹ̀ tí Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (b) Ṣé ìgbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì bá wáyé nìkan ni Ọlọ́run máa ń lo ẹ̀mí mímọ́ ni? Ṣàlàyé.
KÍ LÓ máa ń wá sí ẹ lọ́kàn bó o bá ń ronú nípa bí Ọlọ́run ṣe ń lo ẹ̀mí mímọ́? Ǹjẹ́ o máa ń ronú nípa àwọn ohun àgbàyanu tí Gídíónì àti Sámúsìnì gbé ṣe? (Oníd. 6:33, 34; 15:14, 15) Àbí ìgboyà àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tàbí bí ọkàn Sítéfánù ṣe balẹ̀ nígbà tó wà níwájú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn lo máa ń rántí. (Ìṣe 4:31; 6:15) Bó bá sì jẹ́ lóde òní, ṣé o máa ń ronú nípa ìdùnnú tó máa ń gbilẹ̀ láwọn àpéjọ àgbáyé wa, ìwà títọ́ àwọn ará wa tí wọ́n tì mọ́lé torí pé wọn kò dá sí ọ̀ràn ìṣèlú àti ìbísí kíkàmàmà tá à ń rí nínú iṣẹ́ ìwàásù wa? Àpẹẹrẹ díẹ̀ nìwọ̀nyí jẹ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.
2 Ṣé ìgbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì bá wáyé tàbí tí ipò tó kọjá agbára ẹ̀dá bá yọjú nìkan ni Ọlọ́run máa ń lo ẹ̀mí mímọ́ ni? Rárá o. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé àwọn Kristẹni ń “rìn nípa ẹ̀mí,” “ẹ̀mí . . . ń ṣamọ̀nà” wọn, wọ́n sì “wà láàyè nípa ẹ̀mí.” (Gál. 5:16, 18, 25) Àwọn gbólóhùn yìí fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ lè máa bá a nìṣó láti darí ìgbésí ayé wa. Ojoojúmọ́ ló yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. (Ka Sáàmù 143:10.) Bá a bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí gbogbo ohun tá a bá ń ṣe nígbèésí ayé wa, ó máa mú ká ní àwọn ànímọ́ táá máa mára tu àwọn mìíràn táá sì máa fi ìyìn fún Ọlọ́run.
3. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
3 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa? Ìdí ni pé agbára míì wà tó máa ń fẹ́ jẹ gàba lé wa lórí, agbára náà sì máa ń ta ko ọ̀nà tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbà ṣiṣẹ́. Agbára míì yẹn ni Ìwé Mímọ́ pè ní “ẹran ara,” èyí tó jẹ́ èròkérò tó máa ń wá síni lọ́kàn láti dẹ́ṣẹ̀, tó ní í ṣe pẹ̀lú àìpé tá a jogún látọ̀dọ̀ baba ńlá wa Ádámù. (Ka Gálátíà 5:17.) Nígbà náà, kí ló wé mọ́ jíjẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa? Ǹjẹ́ àwọn nǹkan kan wà tá a lè ṣe tó sì máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè dènà ipa tí ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ máa ń ní lórí wa? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò bá a ṣe ń jíròrò apá mẹ́fà tó kù lára “èso ti ẹ̀mí,” ìyẹn “ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”—Gál. 5:22, 23.
Ìwà Tútù àti Ìpamọ́ra Ń Mú Kí Àlàáfíà Jọba Nínú Ìjọ
4. Báwo ni ìwà tútù àti ìpamọ́ra ṣe ń mú kí àlàáfíà jọba nínú ìjọ?
4 Ka Kólósè 3:12, 13. Nínú ìjọ, ìwà tútù àti ìpamọ́ra máa ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ láti mú kí àlàáfíà jọba. Àwọn ànímọ́ méjèèjì tó jẹ́ ara èso ti ẹ̀mí yìí máa ń mú kéèyàn ṣoore fún àwọn ẹlòmíì, kéèyàn fọwọ́ wọ́nú bí wọ́n bá ṣe ohun tó lè múni bínú, kéèyàn má sì gbẹ̀san bí àwọn míì bá ṣe ohun tí kò dáa síni tàbí tí wọ́n sọ̀rọ̀ kòbákùngbé síni. Bí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀ láàárín àwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, ìpamọ́ra tàbí sùúrù kò ní jẹ́ ká pa arákùnrin tàbí arábìnrin wa tì, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la máa ṣe ohun tó lè yanjú aáwọ̀ náà. Ṣé òótọ́ la nílò ìwà tútù àti ìpamọ́ra nínú ìjọ? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé aláìpé ni gbogbo wa.
5. Kí ló wáyé láàárín Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, kí lèyí sì fi hàn?
5 Ronú nípa ohun tó wáyé láàárín Pọ́ọ̀lù àti Bánábà. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n jọ fi ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ láti mú kí ìhìn rere tàn kálẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní àwọn ànímọ́ tó dára. Síbẹ̀, ó ṣẹlẹ̀ nígbà kan pé “ìbújáde ìbínú mímúná wáyé, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n pínyà kúrò lọ́dọ̀ ara wọn.” (Ìṣe 15:36-39) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi hàn pé nígbà míì èdèkòyédè lè wáyé láàárín àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ olùfọkànsìn pàápàá. Bí èdèkòyédè bá wáyé láàárín Kristẹni kan àti ẹni tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́, kí ni wọ́n lè ṣe tí wọn kò fi ní ta ohùn síra wọn kí ìyẹn sì ba àárín wọn jẹ́?
6, 7. (a) Ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ wo la lè tẹ̀ lé kí ìjíròrò àárín àwa àti ẹni tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tó di ariwo? (b) Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú”?
6 Bó ṣe fara hàn nínú gbólóhùn náà, “ìbújáde ìbínú mímúná,” èdèkòyédè tó wáyé láàárín Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣàdéédéé ṣẹlẹ̀ ni, ó sì pọ̀. Bí Kristẹni kan bá rí i pé inú ti fẹ́ máa bí òun nígbà tí òun ń jíròrò ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́, ó máa bọ́gbọ́n mu pé kó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Jákọ́bù 1:19, 20 pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú; nítorí ìrunú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ yọrí sí òdodo Ọlọ́run.” Bí ipò náà bá gbà bẹ́ẹ̀, ó lè yí ọ̀rọ̀ náà pa dà, kó fòpin sí ìjíròrò náà tàbí kó fi ibẹ̀ sílẹ̀ kí ìjíròrò náà tó di ariwo.—Òwe 12:16; 17:14; 29:11.
7 Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú títẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí? Bí Kristẹni kan bá fiyè dénú, tó gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà, tó sì ronú nípa ọ̀nà tó dára jù lọ láti fèsì pa dà, ó ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí òun nìyẹn. (Òwe 15:1, 28) Bí ẹ̀mí Ọlọ́run sì ṣe ń darí rẹ̀ yẹn, á lè fi ìwà tútù àti ìpamọ́ra hàn. Ó sì tún máa ṣeé ṣe fún un láti pa ìtọ́ni tó wà nínú Éfésù 4:26, 29 mọ́, èyí tó kà pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀ . . . Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.” Ó dájú pé bá a bá fi ìwà tútù àti ìpamọ́ra wọ ara wa láṣọ, a ó máa pa kún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ.
Inú Rere àti Ìwà Rere Lè Mára Tu Ìdílé Rẹ
8, 9. Kí ni inú rere àti ìwà rere, ipa wo ni wọ́n sì máa ń ní lórí àwọn tó wà nínú ìdílé?
8 Ka Éfésù 4:31, 32; 5:8, 9. Bí atẹ́gùn tútù tó rọra ń fẹ́ yẹ́ẹ́ àti omi tútù ṣe ń mára tuni nígbà tí oòrùn bá ń mú ganrínganrín, bẹ́ẹ̀ ni inú rere àti ìwà rere náà ṣe máa ń mára tuni. Bí àwọn tó wà nínú ìdílé bá jẹ́ onínúure tí wọ́n sì ń hùwà rere, ìyẹn máa ń mú kí ilé tura. Inú rere jẹ́ ànímọ́ tó ń fani mọ́ra tó máa ń mú kí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹni lógún, kí èèyàn sì fi hàn nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ àti sísọ ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró fún wọn. Bíi ti inú rere, ìwà rere náà jẹ́ ànímọ́ rere tó máa ń fara hàn nínú ọ̀nà téèyàn ń gbà hùwà tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní. Ó máa ń jẹ́ kéèyàn hùwà ọ̀làwọ́. (Ìṣe 9:36, 39; 16:14, 15) Àmọ́, ìwà rere kò mọ síbẹ̀ yẹn o.
9 Ìwà rere jẹ́ ìwà ọmọlúwàbí. Ó kan ohun tá a bá ń ṣe, pàápàá jù lọ irú ẹni tá a jẹ́. Fojú inú wo obìnrin kan tó ń gé èso tí ìdílé rẹ̀ máa jẹ. Bó ti ń gé èso kọ̀ọ̀kan ó ń yẹ̀ ẹ́ wò kó lè mọ̀ bóyá ó pọ́n dénú tí ibì kankan kò sì bà jẹ́ ní inú tàbí lára èso náà. Bákan náà, ìwà rere tí ẹ̀mí mímọ́ ń mú kéèyàn ní máa ń kan gbogbo apá ìgbésí ayé Kristẹni kọ̀ọ̀kan látòkèdélẹ̀.
10. Kí la lè ṣe láti ran àwọn tó jẹ́ ara ìdílé wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fi èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù?
10 Nínú agbo ilé Kristẹni, kí ló lè ran àwọn tó jẹ́ ara ìdílé lọ́wọ́ láti máa fi inú rere hàn síra wọn kí wọ́n sì máa hùwà rere? Ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa kó ipa pàtàkì nínú èyí. (Kól. 3:9, 10) Àwọn olórí ìdílé kan máa ń fi ìjíròrò tó dá lórí èso ti ẹ̀mí kún Ìjọsìn Ìdílé wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Kò ṣòro láti ṣètò fún irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀. Nípa lílo àwọn ohun tó o ní lọ́wọ́ láti ṣe ìwádìí ní èdè rẹ, ṣe àkójọ ìsọfúnni lórí apá kọ̀ọ̀kan lára èso ti ẹ̀mí. Ẹ lè máa gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ìsọfúnni náà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ẹ sì lè tipa bẹ́ẹ̀ lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan lórí apá tẹ́ ẹ bá ń gbé yẹ̀ wò. Bẹ́ ẹ bá ṣe ń jíròrò àwọn àkójọ ìsọfúnni náà, ẹ máa ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀ kẹ́ ẹ sì máa jíròrò wọn. Ẹ wá bí ẹ ó ṣe máa fi ohun tẹ́ ẹ bá kọ́ sílò kẹ́ ẹ sì máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó bù sí ìsapá yín. (1 Tím. 4:15; 1 Jòh. 5:14, 15) Ǹjẹ́ irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ lè mú kí ìyàtọ̀ wà ní ti gidi nínú ọ̀nà táwọn tó jẹ́ ara ìdílé kan á máa gbà bá ara wọn lò?
11, 12. Nígbà tí tọkọtaya Kristẹni méjì kan kẹ́kọ̀ọ́ nípa inú rere, báwo ló ṣe ṣe wọ́n láǹfààní?
11 Tọkọtaya kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, tí wọ́n sì fẹ́ kí ìgbéyàwó wọn kẹ́sẹ járí, pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀ sí i nípa èso ti ẹ̀mí. Àǹfààní wo ni wọ́n ti rí gbà nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀? Èyí aya ṣàlàyé pé: “Bá a ṣe mọ̀ pé inú rere wé mọ́ ìṣòtítọ́ àti ìdúróṣinṣin ti mú kí ìyàtọ̀ wà nínú bá a ṣe ń ṣe síra wa títí di òní. Ó ti kọ́ wa láti máa gbà fúnra wa, ká sì máa dárí ji ara wa. Ó sì mú ká máa sọ pé ‘o ṣeun’ àti ‘forí jì mí’ nígbà tó bá yẹ.”
12 Tọkọtaya Kristẹni míì tí wọ́n ní ìṣòro nínú ìgbéyàwó wọn rí i pé àwọn kì í fi inú rere hàn síra àwọn. Wọ́n pinnu láti jùmọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa inú rere. Kí ni ìyẹn yọrí sí? Èyí ọkọ sọ pé: “Ẹ̀kọ́ tá a kọ́ nípa inú rere ràn wá lọ́wọ́ láti lóye pé dípò tá a ó fi máa ní èrò òdì, ńṣe ló yẹ ká gbà pé kò sí ẹni tó ní ohun búburú lọ́kàn nínú àwa méjèèjì. A wá ń jẹ́ kí ọ̀ràn ẹni kìíní kejì wa túbọ̀ jẹ wá lógún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Bí mo ṣe ń fi inú rere hàn ti mú kí n máa jẹ́ kí ìyàwó mi sọ ohun tó bá wà lọ́kàn rẹ̀ ní fàlàlà, mi ò sì ní bínú sí ohun tó bá sọ. Ó túmọ̀ sí pé mi ò gbọ́dọ̀ ro ara mi ju bó ṣe yẹ lọ. Bá a ṣe ń fi inú rere hàn nínú ìgbéyàwó wa, a kò tahùn síra wa mọ́ a sì ń mọ ẹ̀bi wa lẹ́bi. Èyí mú kí ara tù wá gan-an ni.” Ṣé kíkẹ́kọ̀ọ́ èso ti ẹ̀mí lè ṣe ìdílé tìrẹ náà láǹfààní?
Fi Hàn Pé O Ní Ìgbàgbọ́ Bó O Bá Wà ní Ìkọ̀kọ̀
13. Ohun wo tó lè ṣàkóbá fún àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ló yẹ ká yẹra fún?
13 Ó yẹ kí àwọn Kristẹni jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wọn ní gbangba àti ní ìkọ̀kọ̀. Nínú ayé Sátánì lónìí, àwọn àwòrán ìṣekúṣe àti eré ìnàjú tí ń tàbùkù síni ti gbayé kan. Èyí ń wu àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run léwu. Kí ló yẹ kí Kristẹni kan ṣe? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé: “Ẹ mú gbogbo èérí kúrò àti ohun àṣerégèé yẹn, ìwà búburú, kí ẹ sì fi ìwà tútù tẹ́wọ́ gba gbígbin ọ̀rọ̀ náà sínú, èyí tí ó lè gba ọkàn yín là.” (Ják. 1:21) Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bí ìgbàgbọ́, tó jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí, ṣe lè mú ká wà ní mímọ́ lójú Jèhófà.
14. Báwo ni àìní ìgbàgbọ́ ṣe lè yọrí sí híhùwà tí kò tọ́?
14 Ìgbàgbọ́ ló máa jẹ́ ká gbà pé Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi. Bí a kò bá gbà pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi, a ó máa tètè lọ́wọ́ sí ìwà tí kò dára. Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ìgbà àtijọ́. Jèhófà ṣí àwọn ohun ìríra táwọn èèyàn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀ payá fún wòlíì Ísíkíẹ́lì, ó sì sọ fún un pé: “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbàlagbà ilé Ísírẹ́lì ń ṣe nínú òkùnkùn, olúkúlùkù nínú yàrá inú lọ́hùn-ún ti ohun àfihàn rẹ̀? Nítorí wọ́n ń wí pé, ‘Jèhófà kò rí wa. Jèhófà ti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀.’” (Ìsík. 8:12) Ǹjẹ́ o kíyè sí ohun tó pa kún ìṣòro náà? Wọn kò gbà gbọ́ pé Jèhófà mọ ohun tí wọ́n ń ṣe. Wọn kò ka Jèhófà sí ẹni gidi.
15. Báwo ni ìgbàgbọ́ lílágbára nínú Jèhófà ṣe lè dáàbò bò wá?
15 Ọ̀ràn ti Jósẹ́fù yàtọ̀ pátápátá sí èyí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù ń gbé níbi tó jìnnà sí ìdílé rẹ̀ àtàwọn èèyàn rẹ̀, ó kọ̀ láti ṣe panṣágà pẹ̀lú ìyàwó Pọ́tífárì. Kí nìdí? Ó sọ pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” (Jẹ́n. 39:7-9) Ó dájú pé Jósẹ́fù ka Jèhófà sí ẹni gidi. Bí a bá ka Ọlọ́run sí ẹni gidi, a kò ní máa fi ohun àìmọ́ dá ara wa lára yá tàbí ká máa ṣe ohunkóhun tá a mọ̀ pé inú Ọlọ́run kò dùn sí ní ìkọ̀kọ̀. Àwa náà máa pinnu láti ṣe bíi ti onísáàmù tó kọ ọ́ lórin pé: “Èmi yóò máa rìn káàkiri nínú ìwà títọ́ ọkàn-àyà mi nínú ilé mi. Èmi kì yóò gbé ohun tí kò dára fún ohunkóhun ka iwájú mi.”—Sm. 101:2, 3.
Máa Pa Ọkàn-Àyà Rẹ Mọ́ Nípa Lílo Ìkóra-Ẹni-Níjàánu
16, 17. (a) Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Òwe, báwo ni “ọ̀dọ́kùnrin tí ọkàn-àyà kù fún” ṣe kó sínú ìdẹkùn ẹ̀ṣẹ̀? (b) Bí a ṣe fi hàn nínú àwòrán ojú ìwé 26, báwo ni ohun tó jọ èyí ṣe lè ṣẹlẹ̀ lónìí láìka ọjọ́ orí ẹnì kan sí?
16 Ìkóra-ẹni-níjàánu, apá tó kẹ́yìn lára èso ti ẹ̀mí, máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè yẹra fún àwọn nǹkan tí Ọlọ́run bá kà léèwọ̀. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà wa. (Òwe 4:23) Ronú nípa “ọ̀dọ́kùnrin tí ọkàn-àyà kù fún” èyí tí Òwe 7:6-23 sọ pé aṣẹ́wó kan fi ọ̀rọ̀ dídùn mú balẹ̀. Ó kó sínú ìdẹkùn nígbà tí “ó ń kọjá lọ ní ojú pópó nítòsí igun ọ̀nà rẹ̀.” Ó lè jẹ́ pé ojúmìító tó fẹ́ ṣe ló mú kó lọ sí àdúgbò yẹn. Ó ti yára gbàgbé láti fòye mọ̀ pé ojú ọ̀nà ìparun tó “wé mọ́ ọkàn òun gan-an” ni òun ń tọ̀.
17 Kí ni ọ̀dọ́kùnrin yẹn ì bá ti ṣe kó máa bàa ṣe àṣìṣe tó la ẹ̀mí rẹ̀ lọ yìí? Ńṣe ni ì bá ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ tó sọ pé: “Má rìn gbéregbère wọ àwọn òpópónà rẹ̀.” (Òwe 7:25) A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí. Ẹ̀kọ́ náà ni pé bá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa, a kò gbọ́dọ̀ máa rìn ní bèbè ìdẹwò. Ọ̀nà tí ẹnì kan fi lè rìn gbéregbère lọ sójú ọ̀nà ìparun bíi ti “ọ̀dọ́kùnrin tí ọkàn-àyà kù fún” náà ni pé kó máa rànmù kiri lórí ìkànnì tẹlifíṣọ̀n tàbí lórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì. Yálà onítọ̀hún dìídì fẹ́ wo ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe tàbí kò fẹ́, ó lè ṣàdédé rí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó lè wá di ẹni tó mọ́ lára láti máa wo àwòrán oníhòòhò, èyí tó máa ní ipa tó burú jáì lórí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ àti àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Kódà, ó lè tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ìwàláàyè rẹ̀.—Ka Róòmù 8:5-8.
18. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni Kristẹni kan lè gbé kó bàa lè pa ọkàn-àyà rẹ̀ mọ́, báwo lèyí sì ṣe kan lílo ìkóra-ẹni-níjàánu?
18 Láìsí àníàní, a lè lo ìkóra-ẹni-níjàánu, ó sì yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀, nípa yíyára gbé ìgbésẹ̀ bí àwòrán ìṣekúṣe bá yọ gannboro sí wa. Àmọ́, ẹ wo bí ì bá ti sàn tó ká máa tiẹ̀ ṣe ohun tó máa mú ká bára wa nírú ipò yẹn rárá! (Òwe 22:3) Gbígbé àwọn ìlànà tó lè dáàbò bò wá kalẹ̀ àti títẹ̀ lé àwọn ìlànà náà gba pé ká máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀nà kan tá a lè gbà dáàbò bo ara wa ni pé ká gbé kọ̀ǹpútà síbi tí gbogbo èèyàn ti lè rí i. Àwọn kan rí i bí ohun tó dára jù lọ láti lo kọ̀ǹpútà tàbí láti wo tẹlifíṣọ̀n kìkì táwọn ẹlòmíì bá wà nítòsí. Àwọn míì ti pinnu láti má ṣe lo Íńtánẹ́ẹ̀tì rárá. (Ka Mátíù 5:27-30.) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa ṣe ohunkóhun tá a bá rí pé ó pọn dandan láti lè dáàbò bo ara wa àti ìdílé wa ká bàa lè máa sin Jèhófà “láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́ àti láti inú ẹ̀rí-ọkàn rere àti láti inú ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè.”—1 Tím. 1:5.
19. Àwọn àǹfààní wo ló máa tìdí rẹ̀ wá tá a bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa?
19 Bí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń ṣiṣẹ́ lára wa, àkópọ̀ ànímọ́ tá a máa ní á ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ gan-an. Ìwà tútù àti ìpamọ́ra ń pa kún àlàáfíà ìjọ. Inú rere àti ìwà rere ń mú kí ayọ̀ tó wà nínú ìdílé pọ̀ sí i. Ìgbàgbọ́ àti ìkóra-ẹni-níjàánu ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ká sì jẹ́ mímọ́ lójú rẹ̀. Síwájú sí i, Gálátíà 6:8 mú kó dá wa lójú pé: “Ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn yóò ká ìyè àìnípẹ̀kun láti inú ẹ̀mí.” Bẹ́ẹ̀ ni, lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi, Jèhófà máa tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ fi ìyè àìnípẹ̀kun jíǹkí àwọn tó ń jẹ́ kí ẹ̀mí máa darí wọn.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni ìwà tútù àti ìpamọ́ra ṣe ń pa kún àlàáfíà ìjọ?
• Kí ló lè ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti máa fi inú rere hàn kí wọ́n sì máa hu ìwà rere nínú ilé?
• Báwo ni ìgbàgbọ́ àti ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe ń ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti pa ọkàn-àyà rẹ̀ mọ́?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Kí lo lè ṣe tí ìjíròrò kan kò fi ní di ariwo?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Kíkẹ́kọ̀ọ́ èso ti ẹ̀mí lè ṣe ìdílé rẹ láǹfààní
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn ewu wo la lè sá fún bí a bá ní ìgbàgbọ́ tá a sì ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu?